Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 15

1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.

2 Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde,

ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.

3 Ojú OLUWA wà níbi gbogbo,

ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.

4 Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.

5 Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀,

ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni.

6 Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra,

ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.

7 Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀,

ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.

8 Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA,

ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.

9 OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú,

ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.

10 Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,

ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.

11 Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,

mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.

12 Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,

kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.

13 Inú dídùn a máa múni dárayá,

ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.

14 Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,

ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.

15 Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,

ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.

16 Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,

ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.

17 Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,

sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.

18 Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,

ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.

19 Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,

ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.

20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,

ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

21 Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,

ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.

22 Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,

ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.

23 Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀,

kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!

24 Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè,

kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.

25 OLUWA a máa wó ilé agbéraga,

ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.

26 Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,

ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.

27 Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,

ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.

28 Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.

29 OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú,

ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.

30 Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn,

ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.

31 Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rere

yóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.

32 Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.

33 Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n,

ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *