1 Ẹlẹ́yà ni ọtí waini,
aláriwo ní ọtí líle,
ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2 Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,
ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.
3 Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà,
ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà.
4 Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò,
nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.
5 Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn,
ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.
6 Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́,
ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?
7 Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́,
ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.
8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀,
ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù.
9 Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́,
ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀?
10 Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA.
11 Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀,
bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà.
12 Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran,
OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
13 Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka,
lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù.
14 “Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí,
bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà.
15 Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.
16 Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,
gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.
17 Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan,
ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.
18 Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀,
gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.
19 Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí,
nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́.
20 Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú,
àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri.
21 Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀,
kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn.
22 Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú,
gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.
23 Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA,
ìwọ̀n èké kò dára.
24 OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni,
eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.
25 Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA,
kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀.
26 Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù,
a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
27 Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA,
tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.
28 Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́,
òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró.
29 Agbára ni ògo ọ̀dọ́,
ewú sì ni ẹwà àgbà.
30 Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò,
pàṣán a máa mú kí inú mọ́.