Ìmọ̀ràn fún Ọba
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ:
2 Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi,
ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí.
3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin,
má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́.
4 Gbọ́, ìwọ Lemueli,
ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí,
àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle.
5 Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin,
kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po.
6 Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu,
fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle,
7 jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn,
kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.
8 Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò,
ati ti àwọn tí a sọ di aláìní.
9 Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,
bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn.
Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere
10 Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?
Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.
11 Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,
kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.
12 Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un
kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,
a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.
14 Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,
tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.
15 Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,
ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.
16 Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,
a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.
17 A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,
a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.
18 A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,
fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.
19 Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,
ó sì ń ran òwú.
20 Ó lawọ́ sí àwọn talaka,
a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.
21 Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,
nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.
22 A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,
òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.
23 Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,
nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.
24 A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,
a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.
25 Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,
ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.
26 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,
a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.
27 A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,
kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,
ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,
29 “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,
ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”
30 Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,
obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.
31 Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,
jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.