1 Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,
lórí ibùsùn mi lálẹ́,
mo wá a, ṣugbọn n kò rí i;
mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.
2 N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú,
n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,
ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede.
Mo wá a ṣugbọn n kò rí i.
3 Àwọn aṣọ́de rí mi,
bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú.
Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé,
“Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”
4 Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn,
ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ,
títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi,
ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.
5 Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,
pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí.
Orin Kẹta
6 Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,
tí ó dàbí òpó èéfín,
tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,
pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò?
7 Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,
ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,
ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká.
8 Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,
akọni sì ni wọ́n lójú ogun.
Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́.
9 Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀.
10 Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,
ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,
Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀.
11 Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbinrin Sioni,
ẹ lọ wo Solomoni ọba,
pẹlu adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e lórí,
ní ọjọ́ igbeyawo,
ní ọjọ́ ìdùnnú ati ọjọ́ ayọ̀ rẹ̀.