Ọba Lọ́la
1 Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.
2 Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.
Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.
3 Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.
Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;
wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.
Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.
4 Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,
ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,
ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.
Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.
5 Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,
ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,
iná yóo sì jó wọn run.
6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fún wa ní ọmọkunrin kan.
Òun ni yóo jọba lórí wa.
A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,
Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,
Ọmọ-Aládé alaafia.
7 Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i,
alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.
Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,
yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,
láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.
Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí
OLUWA yóo Jẹ Israẹli Níyà
8 OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu,
àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli.
9 Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀,
àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria,
àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé:
10 Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀?
Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́.
Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó,
ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn.
11 Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn:
Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn:
12 Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn,
ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn;
wọn óo gbé Israẹli mì.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
13 Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun.
14 Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli.
Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù.
15 Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí,
àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù
16 Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni,
àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.
17 Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn,
àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é
nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun,
ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
18 Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,
tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.
Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.
19 Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná,
àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná
ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.
20 Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́,
sibẹ ebi ń pa wọ́n.
Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì,
sibẹ wọn kò yó,
àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ.
21 Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà.
Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.