Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀
1 Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”
2 Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA,
3 ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
4 OLUWA bá sọ fún Aisaya pé
5 kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀.
6 OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó.
21 Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn.
22 Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa?
7 Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí:
8 Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.
Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ
9 Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:
10 Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,
ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,
níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.
11 Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,
ati pé n kò ní sí láàyè mọ́
láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.
12 A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,
a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.
Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.
Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.
Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.
13 Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́
ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.
Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.
14 Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,
mò ń ké igbe arò bí àdàbà.
Mo wòkè títí ojú ń ro mí,
ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.
15 Ṣugbọn kí ni mo lè sọ?
Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀,
òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe é
Oorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́.
16 OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè,
ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè.
Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè.
17 Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ;
ìwọ ni o dì mí mú,
tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun,
nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé.
18 Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́;
kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú,
wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́.
19 Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́
bí mo ti yìn ọ́ lónìí.
Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ.
20 OLUWA yóo gbà mí là,
a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA,
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.