1 OLUWA ní:
OLUWA ní:
“Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà?
Ta ni mo tà yín fún,
tí mo jẹ lówó?
Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín,
nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀.
2 “Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan;
mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn?
Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni;
àbí n kò lágbára láti gba ni là?
Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun,
tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀,
omi wọn gbẹ,
òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa,
wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.
3 Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ,
mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.”
Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA
4 OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu.
Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú.
Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀,
kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
5 OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí,
n kò sì ṣe oríkunkun,
tabi kí n pada sẹ́yìn.
6 Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba;
mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu.
N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn,
bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú.
7 OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,
nítorí náà ojú kò tì mí;
nítorí náà mo múra gírí,
mo jẹ́ kí ojú mi le koko,
mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí.
8 Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí,
ta ló fẹ́ bá mi jà?
Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí?
Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi,
kí á jọ kojú ara wa?
9 Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,
ta ni yóo dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ,
kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n.
10 Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín,
tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu,
tí ń rìn ninu òkùnkùn,
tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,
tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀.
11 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná,
tí ẹ tan iná yí ara yín ká,
ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá;
ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá.
Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín.
Ẹ óo wà ninu ìrora.