Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun
1 OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́,
kí ẹ sì máa ṣe òdodo;
nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́,
ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi.
2 Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,
ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,
tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,
tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”
3 Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,
“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”
Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,
“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”
4 Nítorí OLUWA ní,
“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,
tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,
5 n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,
ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.
Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.
6 “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,
tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,
gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,
tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,
7 n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,
n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.
Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;
nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”
8 OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,
“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,
kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”
A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli lẹ́bi
9 Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,
gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.
10 Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli
gbogbo wọn kò mọ nǹkankan.
Ajá tí ó yadi ni wọ́n,
wọn kò lè gbó;
oorun ni wọ́n fẹ́ràn.
Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.
11 Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì,
wọn kì í yó.
Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan.
Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn,
olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.
12 Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini,
ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó,
bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”