Categories
AISAYA

AISAYA 57

OLUWA Dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli lẹ́bi

1 Olódodo ń ṣègbé,

kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i.

A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé,

pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.

2 Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia,

wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.

3 Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi,

ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́,

ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.

4 Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà?

Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sí

tí ẹ yọ ṣùtì sí?

Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín

irú ọmọ ẹ̀tàn;

5 ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,

ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,

ati ní abẹ́ àpáta?

6 Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,

àwọn ni ẹ̀ ń sìn,

àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,

àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.

Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?

7 Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ sí

níbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.

8 O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn.

O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀.

O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀,

ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.

9 O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,

o kó ọpọlọpọ turari lọ,

o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,

o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.

10 Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,

sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”

Ò ń wá agbára kún agbára,

nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.

11 Ta ni ń já ọ láyà,

tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;

tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?

Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,

ni o kò fi bẹ̀rù mi?

12 N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

13 Nígbà tí o bá kígbe,

kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.

Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ

Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.

Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,

ni yóo ni ilẹ̀ náà,

òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.

Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn

14 OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,

ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”

15 Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,

ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:

òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,

ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.

Láti sọ ọkàn wọn jí.

16 Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,

tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:

nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,

Èmi ni mo dá èémí ìyè.

17 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,

mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;

sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.

18 Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,

ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;

n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,

n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.

19 Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè,

ati àwọn tí ó wà nítòsí;

n óo sì wò wọ́n sàn.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun,

nítorí òkun kò lè sinmi,

omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.

21 Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”

Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *