Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè
1 Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi,
nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,
láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.
Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,
kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,
kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.
2 Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA,
ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;
kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.
3 Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,
ní inú dídùn dípò ìkáàánú,
kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,
kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,
kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,
tí OLUWA gbìn,
kí á lè máa yìn ín lógo.
4 Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,
wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,
wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.
5 Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,
àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;
6 ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,
àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.
Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.
7 Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,
dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.
Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,
ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.
8 OLUWA ní,
“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,
mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.
Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,
n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.
9 Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,
a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,
gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,
yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”
10 N óo máa yọ̀ ninu OLUWA,
ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.
Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,
ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ;
bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.
11 Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde,
tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù,
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde
níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.