Categories
MATIU

MATIU 2

Àwọn Amòye Wá Ọmọ náà Kàn

1 Nígbà tí wọ́n bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Judia, ní ayé Hẹrọdu ọba, àwọn amòye kan wá sí Jerusalẹmu láti ìhà ìlà oòrùn.

2 Wọ́n bèèrè pé, “Níbo ni ọmọ tí a bí tí yóo jẹ ọba àwọn Juu wà? A ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà oòrùn, nítorí náà ni a ṣe wá láti júbà rẹ̀.”

3 Nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ara gbogbo eniyan ìlú Jerusalẹmu náà kò sì balẹ̀.

4 Ọba bá pe gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin láàrin àwọn eniyan, ó wádìí nípa ibi tí a óo ti bí Kristi lọ́wọ́ wọn.

5 Wọ́n sọ fún un pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti ilẹ̀ Judia ni. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ wolii nì pé.

6 ‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda,

o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda.

Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde,

tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ”

7 Hẹrọdu bá pe àwọn amòye náà síkọ̀kọ̀, ó fọgbọ́n wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà yọ lọ́dọ̀ wọn.

8 Ó bá rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Ó ní, “Ẹ lọ, kí ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ọmọ náà. Nígbà tí ẹ bá rí i, ẹ wá ròyìn fún mi kí èmi náà lè lọ júbà rẹ̀.”

9 Nígbà tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí ní ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí lọ níwájú wọn títí ó fi dúró ní ọ̀gangan ibi tí ọmọ náà wà.

10 Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gan-an.

11 Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá.

12 Nítorí pé Ọlọrun ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ ní ojú àlá, wọn kò pada sọ́dọ̀ Hẹrọdu mọ́; ọ̀nà mìíràn ni wọ́n gbà pada lọ sí ìlú wọn.

Josẹfu Gbé Jesu Sálọ sí Ijipti

13 Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.”

14 Josẹfu bá dìde ní òru, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Ijipti.

15 Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.”

Hẹrọdu Ranṣẹ Lọ Pa Àwọn Ọmọde

16 Nígbà tí Hẹrọdu rí i pé àwọn amòye tan òun jẹ ni, inú bí i pupọ. Ó bá pàṣẹ pé kí wọn máa pa gbogbo àwọn ọmọ-ọwọ́ lọkunrin ní Bẹtilẹhẹmu ati ní gbogbo agbègbè ibẹ̀ láti ọmọ ọdún meji wálẹ̀ títí di ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó fọgbọ́n wádìí lọ́wọ́ àwọn amòye.

17 Èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Jeremaya sọ lè ṣẹ pé,

18 “A gbọ́ ohùn kan ní Rama,

ẹkún ati ọ̀fọ̀ gidi.

Rakẹli ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀;

ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀,

nítorí wọn kò sí mọ́.”

Josẹfu Pada láti Ijipti

19 Lẹ́yìn tí Hẹrọdu ti kú, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá ní Ijipti.

20 Ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ́, kí o pada lọ sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọmọ náà ti kú.”

21 Josẹfu bá dìde, ó gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀ pada sí ilẹ̀ Israẹli.

22 Nígbà tí Josẹfu gbọ́ pé Akelau ni ó jọba ní Judia ní ipò Hẹrọdu baba rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ sibẹ. Lẹ́yìn tí a ti kìlọ̀ fún un lójú àlá, ó yẹra níbẹ̀ lọ sí agbègbè Galili.

23 Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”

Categories
MATIU

MATIU 3

Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi

1 Nígbà tí ó yá, Johanu Onítẹ̀bọmi dé, ó ń waasu ní aṣálẹ̀ Judia.

2 Ó ní, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba Ọlọrun fẹ́rẹ̀ dé.”

3 Nítorí òun ni wolii Aisaya sọ nípa rẹ̀ pé,

“Ohùn ẹnìkan tí ó ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé,

‘Ẹ la ọ̀nà tí OLUWA yóo gbà,

ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ”

4 Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn.

5 Nígbà náà ni àwọn eniyan láti Jerusalẹmu ati gbogbo ilẹ̀ Judia ati ní gbogbo ìgbèríko odò Jọdani ń jáde tọ̀ ọ́ lọ.

6 Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.

7 Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀?

8 Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada.

9 Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi.

10 A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí, nítorí náà, igikígi tí kò bá so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo fi dáná.

11 Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́.

12 Àtẹ ìfẹ́kà rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó. Yóo kó ọkà rẹ̀ jọ sinu abà, ṣugbọn sísun ni yóo sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”

Jesu Ṣe Ìrìbọmi

13 Nígbà náà ni Jesu lọ láti ilẹ̀ Galili, sọ́dọ̀ Johanu ní odò Jọdani, kí Johanu lè ṣe ìrìbọmi fún un.

14 Ṣugbọn Johanu fẹ́ kọ̀ fún un, ó ní, “Èmi gan-an ni mo nílò pé kí o ṣe ìrìbọmi fún mi; ìwọ ni ó tún tọ̀ mí wá?”

15 Jesu dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí á ṣe é bẹ́ẹ̀ ná, nítorí báyìí ni ó yẹ fún wa bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ láṣepé.” Nígbà náà ni Johanu gbà fún un.

16 Bí Jesu ti ṣe ìrìbọmi tán, tí ó gòkè jáde kúrò ninu omi, ọ̀run pínyà lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá rí Ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, tí ó ń bà lé e.

17 Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.”

Categories
MATIU

MATIU 4

Satani Dán Jesu Wò

1 Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé Jesu lọ sí aṣálẹ̀ kí Èṣù lè dán an wò.

2 Lẹ́yìn tí ó ti gbààwẹ̀ tọ̀sán-tòru fún ogoji ọjọ́, ebi wá ń pa á.

3 Ni adánniwò bá yọ sí i, ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún àwọn òkúta wọnyi kí wọ́n di àkàrà.”

4 Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun bá sọ.’ ”

5 Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ nì, ó gbé e lé góńgó orí Tẹmpili.

6 Ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,

‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,

kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ọ́,

kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”

7 Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”

8 Èṣù tún mú un lọ sórí òkè gíga kan; ó fi gbogbo àwọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.

9 Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.”

10 Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”

11 Lẹ́yìn náà, Èṣù fi í sílẹ̀. Àwọn angẹli bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń ṣe iranṣẹ fún un.

Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ ní Galili

12 Nígbà tí Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ju Johanu sẹ́wọ̀n, ó yẹra lọ sí Galili.

13 Lẹ́yìn tí ó kúrò ní Nasarẹti, ó ń lọ gbè Kapanaumu tí ó wà lẹ́bàá òkun ní agbègbè Sebuluni ati Nafutali.

14 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé:

15 “Ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali,

ní ọ̀nà òkun,

ní òdìkejì Jọdani,

Galili àwọn àjèjì.

16 Àwọn eniyan tí ó jókòó ní òkùnkùn

rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.

Ìmọ́lẹ̀ mọ́ sórí àwọn tí ó jókòó

ní ilẹ̀ tí òjìji ikú wà.”

17 Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.”

Jesu Pe Apẹja Mẹrin

18 Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.

19 Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.”

20 Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

21 Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n.

22 Lẹsẹkẹsẹ, wọ́n fi ọkọ̀ ati baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀lé e.

Jesu Ń Ṣiṣẹ́ láàrin Ọpọlọpọ Eniyan

23 Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan.

24 Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Siria. Àwọn eniyan ń gbé gbogbo àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú, ati àwọn tí wárápá mú ati àwọn arọ; ó sì ń wò wọ́n sàn.

25 Ọpọlọpọ eniyan ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili ati Ìlú Mẹ́wàá ati Jerusalẹmu ati Judia, ati láti òdìkejì Jọdani.

Categories
MATIU

MATIU 5

Iwaasu Jesu lórí Òkè

1 Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Àwọn tí Ayọ̀ Wà fún

2 Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé:

3 “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí,

nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,

nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu.

5 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀,

nítorí wọn yóo jogún ayé.

6 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ,

nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.

7 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú,

nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn.

8 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́,

nítorí wọn yóo rí Ọlọrun.

9 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan,

nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀.

10 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo,

nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

11 “Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi.

12 Ẹ máa yọ̀, kí inú yín máa dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wolii tí ó ti wà ṣiwaju yín.

Iyọ̀ ati Ìmọ́lẹ̀

13 “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé; ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, kí ni yóo tún sọ ọ́ di iyọ̀ gidi mọ́? Kò wúlò fún ohunkohun mọ́ àfi kí á dà á nù, kí eniyan máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

14 “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè, kò ṣe é gbé pamọ́.

15 Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé.

16 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.

Ẹ̀kọ́ nípa Òfin Mose

17 “Ẹ má ṣe rò pé mo wá pa Òfin Mose ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii run ni. N kò wá láti pa wọ́n run; mo wá láti mú wọn ṣẹ ni.

18 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ.

19 Ẹnikẹ́ni tí ó bá rú èyí tí ó kéré jùlọ ninu àwọn òfin wọnyi, tí ó sì tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di ẹni ìkẹyìn patapata ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ wọnyi mọ́, tí ó tún ń kọ́ àwọn eniyan láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóo di aṣiwaju ní ìjọba ọ̀run.

20 Nítorí mo wí fun yín pé bí òdodo yín kò bá tayọ ti àwọn amòfin ati ti àwọn Farisi, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run.

Ẹ̀kọ́ nípa Ibinu

21 “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan; ẹni tí ó bá pa eniyan yóo bọ́ sinu ẹjọ́.’

22 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì.

23 Nítorí náà bí o bá fẹ́ mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ ìrúbọ, tí o wá ranti pé arakunrin rẹ ní ọ sinu,

24 fi ọrẹ rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ ìrúbọ, kí o kọ́kọ́ lọ bá arakunrin rẹ, kí ẹ parí ìjà tí ó wà ní ààrin yín ná. Lẹ́yìn náà kí o pada wá rú ẹbọ rẹ.

25 “Tètè bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ rẹ́ nígbà tí ẹ bá jọ ń lọ sí ilé ẹjọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo fà ọ́ fún onídàájọ́. Onídàájọ́ yóo fà ọ́ fún ọlọ́pàá, ọlọ́pàá yóo bá gbé ọ jù sẹ́wọ̀n.

26 Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ìwọ kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóo fi san gbogbo gbèsè rẹ láìku kọbọ.

Ẹ̀kọ́ nípa Àgbèrè

27 “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’

28 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀.

29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ.

30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ.

Ẹ̀kọ́ nípa Kíkọ Aya Ẹni Sílẹ̀

31 “Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’

32 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè.

Ẹ̀kọ́ nípa Ìbúra

33 “Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’

34 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni;

35 tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni;

36 tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú.

37 Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni.

Ẹ̀kọ́ nípa Ẹ̀san Gbígbà

38 “Ẹ ti gbọ́ tí a sọ pé, ‘Nígbà tí o bá fẹ́ gbẹ̀san, ojú dípò ojú ati eyín dípò eyín ni.’

39 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹ má ṣe gbẹ̀san bí ẹnikẹ́ni bá ṣe yín níbi. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹnìkan bá gbá yín létí ọ̀tún, ẹ kọ ti òsì sí i.

40 Ẹni tí ó bá fẹ́ pè ọ́ lẹ́jọ́ láti gba àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ó gba ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ náà.

41 Bí ẹnìkan bá fi agbára mú ọ pé kí o ru ẹrù òun dé ibùsọ̀ kan, bá a rù ú dé ibùsọ̀ keji.

42 Ẹni tí ó bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fi fún un. Má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ yá nǹkan lọ́wọ́ rẹ.

Ìfẹ́ sí Ọ̀tá Ẹni

43 “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ pé, ‘Fẹ́ràn aládùúgbò rẹ, kí o kórìíra ọ̀tá rẹ.’

44 Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí ó ṣe inúnibíni yín.

45 Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo.

46 Nítorí bí ẹ bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín, èrè wo ni ó wà níbẹ̀? Mo ṣebí àwọn agbowó-odè náà a máa ṣe bẹ́ẹ̀.

47 Tí ẹ bá ń kí àwọn arakunrin yín nìkan, kí ni ẹ ṣe ju àwọn ẹlòmíràn lọ? Mo ṣebí àwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe bẹ́ẹ̀!

48 Nítorí náà, bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ti pé ninu ìṣe rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà pé.

Categories
MATIU

MATIU 6

Ẹ̀kọ́ nípa Ìtọrẹ Àánú

1 “Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn yín, ẹ má máa hùwà ṣe-á-rí-mi, kí àwọn eniyan baà lè rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe. Bí ẹ bá ń hùwà ṣe-á-rí-mi, ẹ kò ní èrè lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.

2 “Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

3 Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe;

4 kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ.

Ẹ̀kọ́ nípa Adura

5 “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

6 Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ.

7 “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà.

8 Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

9 Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura:

‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run:

Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ,

10 kí ìjọba rẹ dé,

ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé

bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.

11 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.

12 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá

gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.

13 Má fà wá sinu ìdánwò,

ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’

14 “Nítorí bí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n, Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo dáríjì yín.

15 Ṣugbọn bí ẹ kò bá dáríjì àwọn eniyan, Baba yín kò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

Ẹ̀kọ́ nípa Ààwẹ̀ Gbígbà

16 “Nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ má máa ṣe bí àwọn aláṣehàn tí wọ́n máa ń fajúro, kí àwọn eniyan lè rí i lójú wọn pé wọ́n ń gbààwẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

17 Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, bọ́jú kí o sì fi nǹkan pa ara,

18 kí ó má baà hàn sí àwọn eniyan pé ò ń gbààwẹ̀, àfi sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san fún ọ.

Ìṣúra ní Ọ̀run

19 “Ẹ má ṣe kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò lè bà á jẹ́, tí ó sì lè dógùn-ún. Àwọn olè tún lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ.

20 Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀.

21 Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà.

Ìmọ́lẹ̀ Ara

22 “Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀.

23 Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran tààrà, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu rẹ bá wá di òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn náà yóo ti pọ̀ tó!

Ọlọrun ati Ohun Ìní Eniyan

24 “Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún máa bọ owó.

25 “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ tabi kí ni ẹ óo mu,tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Mo ṣebí ẹ̀mí yín ju oúnjẹ lọ; ati pé ara yín ju aṣọ lọ.

26 Ẹ wo àwọn ẹyẹ lójú ọ̀run. Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó nǹkan oko jọ sinu abà. Sibẹ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Mo ṣebí ẹ̀yin sàn ju àwọn ẹyẹ lọ!

27 Ta ni ninu yín tí ó lè ṣe àníyàn títí tí ó lè fi kún ọjọ́ ayé rẹ̀?

28 “Kí ní ṣe tí ẹ̀ ń ṣe àníyàn nípa ohun tí ẹ óo wọ̀? Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú.

29 Sibẹ mo sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu gbogbo ìgúnwà rẹ̀ kò lè wọ aṣọ tí ó lẹ́wà bíi ti ọ̀kan ninu àwọn òdòdó yìí.

30 Ǹjẹ́ bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré?

31 “Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn pé kí ni ẹ óo jẹ? Tabi, kí ni ẹ óo mu? Tabi kí ni ẹ óo fi bora?

32 Nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni àwọn abọ̀rìṣà ń lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo wọn.

33 Ṣugbọn ẹ kọ́kọ́ máa wá ìjọba Ọlọrun ná ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni a óo fi kún un fún yín.

34 Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn nípa nǹkan ti ọ̀la; nítorí ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wahala ti òní nìkan ti tó fún òní láì fi ti ọ̀la kún un.

Categories
MATIU

MATIU 7

Ẹ̀kọ́ nípa Dídá Ẹlòmíràn Lẹ́jọ́

1 “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́.

2 Nítorí irú ẹjọ́ tí ẹ bá dá eniyan ni Ọlọrun yóo dá ẹ̀yin náà. Irú ìwọ̀n tí ẹ bá lò fún eniyan ni Ọlọrun yóo lò fún ẹ̀yin náà.

3 Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi tí ó wà lójú ìwọ alára?

4 Tabi báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí ń bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ìtì igi wà ní ojú tìrẹ alára?

5 Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi tí ó wà lójú rẹ kúrò; nígbà náà o óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.

6 “Ẹ má ṣe fi nǹkan mímọ́ fún ajá, ẹ má sì ṣe fi ìlẹ̀kẹ̀ iyebíye yín siwaju ẹlẹ́dẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn yóo sì pada bù yín jẹ!

Ẹ̀kọ́ nípa Ìtẹramọ́ Adura

7 “Ẹ bèèrè, a óo sì fi fun yín. Ẹ wá kiri, ẹ óo sì rí. Ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín.

8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè ni ó ń rí gbà; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá nǹkan kiri ni ó ń rí i; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kanlẹ̀kùn ni à ń ṣí i sílẹ̀ fún.

9 Ta ni ninu yín, tí ọmọ rẹ̀ bá bèèrè àkàrà, tí ó jẹ́ fún un ní òkúta?

10 Tabi tí ó bà bèèrè ẹja, tí ó jẹ́ fún un ní ejò?

11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fi ohun tí ó dára fún ọmọ yín, mélòó-mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀.

12 “Nítorí náà, gbogbo bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà ṣe sí wọn. Kókó Òfin ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii nìyí.

Ẹnu-ọ̀nà tí Ó Fún

13 “Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run àpáàdì gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń gba ibẹ̀.

14 Ṣugbọn ọ̀nà ìyè há, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fún. Díẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n rí i.

Èso Igi ni A Fi Ń Mọ Igi

15 “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n.

16 Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn.

17 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú.

18 Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere.

19 Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.

20 Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n.

Ìjẹ́wọ́ Ẹnu Kò Tó

21 “Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa’ ni yóo wọ ìjọba ọ̀run, bíkòṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

22 Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wí fún mi ní ọjọ́ ìdájọ́ pé, ‘Oluwa, Oluwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.’

23 Ṣugbọn n óo wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi wọnyi!’

Ìpìlẹ̀ Meji

24 “Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.

25 Òjò rọ̀; àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà; ṣugbọn kò wó, nítorí ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà lórí àpáta.

26 “Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò bá fi ṣe ìwà hù, ó dàbí òmùgọ̀ eniyan kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn.

27 Òjò rọ̀, àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà. Ó bá wó! Wíwó rẹ̀ sì bani lẹ́rù lọpọlọpọ.”

Àṣẹ Jesu

28 Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ẹnu ya àwọn eniyan sí ẹ̀kọ́ rẹ̀;

29 nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn amòfin wọn.

Categories
MATIU

MATIU 8

Adẹ́tẹ̀ kan Rí Ìwòsàn

1 Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ń tẹ̀lé e.

2 Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sì wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Alàgbà bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”

3 Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀.

4 Jesu wá sọ fún un pé, “Má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn, lọ, fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ, bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”

Jesu Wo Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọ̀gágun kan Sàn

5 Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní,

6 “Alàgbà, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi kan wà ninu ilé tí àrùn ẹ̀gbà ń dà láàmú, ó sì ń joró gidigidi.”

7 Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.”

8 Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá.

9 Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.”

10 Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!

11 Mo tún ń sọ fun yín pé, ọpọlọpọ eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo bá Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run.

12 Ṣugbọn àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run ni a óo tì jáde sinu òkùnkùn biribiri, níbi tí ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.”

13 Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.”

Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

14 Nígbà tí Jesu wọ inú ilé Peteru, ó rí ìyá iyawo Peteru tí ibà dá dùbúlẹ̀.

15 Jesu bá fi ọwọ́ kàn án lọ́wọ́, ibà náà sì fi í sílẹ̀. Ó bá dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún un.

16 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu ni ó fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì tún wo gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá sàn.

17 Báyìí ni ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Òun fúnra rẹ̀ ni ó mú àìlera wa lọ, ó sì gba àìsàn wa fún wa.”

Àwọn tí Ó Fẹ́ Tẹ̀lé Jesu

18 Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n yí i ká, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn kọjá sí òdìkejì òkun.

19 Amòfin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ máa tẹ̀lé ọ níbikíbi tí o bá ń lọ.”

20 Jesu wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”

21 Ẹlòmíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi.”

22 Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ tẹ̀lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn.”

Jesu Bá Ìgbì Wí

23 Jesu wọ ọkọ̀ ojú omi kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e.

24 Ìgbì líle kan sì dé lójú omi òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé omi fẹ́rẹ̀ bo ọkọ̀; ṣugbọn Jesu sùnlọ.

25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ jí i; wọ́n ní, “Oluwa, gbà wá là, à ń ṣègbé lọ!”

26 Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣe lójo bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré wọnyi?” Ó bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá bá dé.

27 Ẹnu ya àwọn eniyan náà. Wọ́n ní, “Irú eniyan wo ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu?”

Jesu Wo Àwọn Ọkunrin Ẹlẹ́mìí Èṣù Ará Gadara Sàn

28 Nígbà tí ó dé òdìkejì òkun, ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, àwọn ọkunrin meji tí wọn ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú itẹ́ òkú, wọ́n wá pàdé rẹ̀. Wọ́n le tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè gba ọ̀nà ibẹ̀ kọjá.

29 Wọ́n bá kígbe pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, ìwọ Ọmọ Ọlọrun? Ṣé o dé láti wá dà wá láàmú ṣáájú àkókò wa ni?”

30 Agbo ọpọlọpọ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà tí wọn ń jẹ lókèèrè.

31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ Jesu pé, “Bí o óo bá lé wa jáde, lé wa lọ sinu agbo ẹlẹ́dẹ̀ ọ̀hún nnì.”

32 Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ lọ!” Wọ́n bá jáde lọ sí inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá dorí kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà, wọ́n sáré lọ, wọ́n sì rì sómi.

33 Àwọn tí wọn ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ sí ààrin ìlú, wọ́n lọ ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ó ní ẹ̀mí èṣù.

34 Gbogbo ìlú bá jáde lọ pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó kúrò ní agbègbè wọn.

Categories
MATIU

MATIU 9

Jesu Wo Arọ kan Sàn

1 Jesu wọ inú ọkọ̀, ó rékọjá sí òdìkejì òkun, ó bá dé ìlú ara rẹ̀.

2 Àwọn kan bá gbé arọ kan wá, ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ṣe ara gírí, ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

3 Àwọn amòfin kan ń rò ninu ara wọn pé, “Ọkunrin yìí ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun.”

4 Ṣugbọn Jesu mọ èrò inú wọn; ó bá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro èrò burúkú ninu ọkàn yín?

5 Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde, kí o máa rìn?’

6 Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni.” Nígbà náà ni ó wá wí fún arọ náà pé “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, máa lọ sí ilé rẹ.”

7 Arọ náà bá dìde, ó lọ sí ilé rẹ̀.

8 Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n fi ògo fún Ọlọrun tí ó fi irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún eniyan.

Jesu Pe Matiu

9 Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó rí ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Matiu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Kíá, ó bá dìde, ó ń tẹ̀lé e.

10 Matiu se àsè ní ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n wá, tí wọn ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun.

11 Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí ní ṣe tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

12 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá.

13 Ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ gbolohun yìí: Ọlọrun sọ pé, ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú.’ Nítorí náà kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Ìbéèrè nípa Ààwẹ̀

14 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí àwa ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”

15 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa ṣọ̀fọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà lọ́dọ̀ wọn. Àkókò ń bọ̀ nígbà tí a óo gba ọkọ iyawo lọ́wọ́ wọn; wọn yóo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.

16 “Kò sí ẹni tíí fi ìrépé aṣọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìrépé aṣọ titun náà yóo súnkì lára ògbólógbòó ẹ̀wù náà, yíya rẹ̀ yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.

17 Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ògbólógbòó àpò awọ náà yóo bẹ́; ati ọtí ati àpò yóo sì ṣòfò. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí, ati ọtí ati àpò yóo wà ní ìpamọ́.”

Ọmọdebinrin Ìjòyè kan ati Obinrin Onísun Ẹ̀jẹ̀

18 Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”

19 Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20 Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu;

21 nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.”

22 Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ.

23 Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké.

24 Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà.

25 Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde.

26 Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà.

Jesu La Àwọn Afọ́jú Meji Lójú

27 Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”

28 Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”

29 Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.”

30 Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.”

31 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà.

Jesu Wo Odi kan Sàn

32 Bí àwọn afọ́jú náà ti jáde, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan mú ọkunrin kan, tí ẹ̀mí èṣù mú kí ó yadi, wá sọ́dọ̀ Jesu.

33 Ṣugbọn bí ó ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ni odi náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń sọ pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”

34 Ṣugbọn àwọn Farisi ń sọ pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

Jesu Aláàánú

35 Jesu ń rìn kiri ní gbogbo àwọn ìlú ati àwọn ìletò, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó sì ń wo oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera sàn.

36 Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ eniyan náà, àánú wọn ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́, tí ọkàn wọn dààmú, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì.

37 Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn ohun tí ó tó kórè pọ̀, ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀.

38 Nítorí náà ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ sí ibi ìkórè rẹ̀.”

Categories
MATIU

MATIU 10

Jesu fún Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila Láṣẹ

1 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn.

2 Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀.

3 Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu.

4 Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Iṣẹ́ tí Jesu Rán Àwọn Aposteli Mejila

5 Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria.

6 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ.

7 Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’

8 Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n.

9 Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín.

10 Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.

11 “Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀.

12 Nígbà tí ẹ bá wọ inú ilé kan lọ, ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’

13 Bí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ bá wà ninu ilé náà, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó wà níbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó pada sọ́dọ̀ yín.

14 Bí ẹnìkan kò bá gbà yín sílé, tabi tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò ninu ilé tabi ìlú náà, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀.

15 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ!

Inúnibíni tí Ó Ń Bọ̀

16 “Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.

17 Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn.

18 Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19 Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà.

20 Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín.

21 “Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa.

22 Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.

23 Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé.

24 “Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ.

25 Ó tó fún ọmọ-ẹ̀yìn bí ó bá dàbí olùkọ́ rẹ̀. Ó tó fún ẹrú bí ó bá dàbí oluwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelisebulu, kí ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀!

Ẹni tí Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù

26 “Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù àwọn eniyan. Kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́, tí kò ní fara hàn. Kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀.

27 Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba. Ohun tí wọ́n yọ́ sọ fun yín, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé.

28 Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.

29 Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín.

30 Gbogbo irun orí yín ni ó níye.

31 Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.

Ìjẹ́wọ́ Kristi níwájú Eniyan

32 “Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

33 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

Ọ̀rọ̀ nípa Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

34 “Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá.

35 Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀.

36 Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.

37 “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.

38 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi.

39 Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀.

Èrè

40 “Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.

41 Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yóo gba èrè tí ó yẹ wolii. Ẹni tí ó bá gba olódodo ní orúkọ olódodo yóo gba èrè olódodo.

42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yìí tí ó kéré jùlọ ní ife omi tútù mu, nítorí pé ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Categories
MATIU

MATIU 11

1 Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu.

Johanu Onítẹ̀bọmi Ranṣẹ sí Jesu

2 Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé,

3 “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”

4 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé,

5 àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

6 Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”

7 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o!

8 Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ẹni tí ó wọ aṣọ iyebíye ni bí? Bí ẹ bá ń wá àwọn tí ó wọ aṣọ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba!

9 Ṣugbọn kí ni ẹ jáde lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ.

10 Òun ni àkọsílẹ̀ wà nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’

11 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ninu àwọn tí obinrin bí, kò ì tíì sí ẹnìkan tí ó ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jù lọ ní ìjọba Ọlọrun jù ú lọ.

12 Láti àkókò tí Johanu Onítẹ̀bọmi ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu títí di ìsinsìnyìí ni àwọn alágbára ti gbógun ti ìjọba ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ fi ipá gbà á.

13 Nítorí títí di àkókò Johanu gbogbo àwọn wolii ati òfin sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀.

14 Bí ẹ bá fẹ́ gbà á, Johanu ni Elija, tí ó níláti kọ́ wá.

15 Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

16 “Kí ni ǹ bá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà, tí wọn ń ké sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé.

17 ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, a pe òkú, ẹ kò ṣọ̀fọ̀.’

18 Nítorí Johanu dé, kò jẹ, kò mu. Wọ́n ní, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’

19 Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu. Wọ́n ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣugbọn àyọrísí iṣẹ́ Ọlọrun fihàn pé ọgbọ́n rẹ̀ tọ̀nà.”

Ìdájọ́ lórí Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada

20 Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ìlú wọ̀n-ọn-nì wí níbi tí ó ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu pupọ jùlọ, nítorí wọn kò ronupiwada.

21 Ó ní, “O gbé! Korasini. Ìwọ náà sì gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, tàwọn ti aṣọ ọ̀fọ̀ lára ati eérú lórí.

22 Mo sọ fun yín, yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fun yín lọ.

23 Ati ìwọ, Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o. Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Sodomu ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe ninu rẹ ni, ìbá wà títí di òní.

24 Mo sọ fún ọ pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ọ lọ.”

Jesu ni Ìtura Àwọn Olùpọ́njú

25 Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.

26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.

27 “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.

28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi.

29 Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀.

30 Nítorí àjàgà mi tuni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.”