Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 12

Ìlérí ìdáǹdè fún Jerusalẹmu

1 Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé,

2 “N óo ṣe ìlú Jerusalẹmu bí ife ọtí àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Wọn óo dojú kọ ilẹ̀ Juda, wọn óo sì dóti ìlú Jerusalẹmu.

3 Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, n óo mú kí ilẹ̀ Jerusalẹmu le kankan bí òkúta tí ó wúwo, orílẹ̀-èdè tí ó bá dábàá pé òun óo ṣí i nídìí, yóo farapa yánnayànna. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo sì parapọ̀ láti bá a jà.

4 Ní ọjọ́ náà, n óo dẹ́rùba àwọn ẹṣin, n óo sì fi wèrè kọlu àwọn tí wọn ń gùn wọ́n. Ṣugbọn n óo máa ṣọ́ àwọn ará Juda, n óo sì fọ́ ojú ẹṣin àwọn ọ̀tá wọn.

5 Àwọn ará Juda yóo wá máa sọ láàrin ara wọn pé, ‘OLUWA, àwọn ọmọ ogun ti sọ àwọn ará Jerusalẹmu di alágbára.’

6 “Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

7 “OLUWA yóo kọ́kọ́ fún àwọn ogun Juda ní ìṣẹ́gun, kí ògo ilé Dafidi ati ògo àwọn ará Jerusalẹmu má baà ju ti Juda lọ.

8 Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA.

9 Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá gbógun ti ìlú Jerusalẹmu.

10 “N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.

11 Ní àkókò náà, ọ̀fọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu yóo pọ̀ bí ọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣe fún Hadadi Rimoni ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.

12 Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ náà yóo ṣọ̀fọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi yóo dá ọ̀fọ̀ tirẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Natani náà yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.

13 Ìdílé Lefi yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Ṣimei pàápàá yóo ṣọ̀fọ̀ tirẹ̀ lọ́tọ̀, àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà lọ́tọ̀;

14 gbogbo àwọn ìdílé yòókù ni wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn iyawo wọn náà yóo sì ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 13

1 OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.

2 “N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́.

3 Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa.

4 Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ.

5 Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’

6 Bí ẹnikẹ́ni bá bi í pé, ‘Àwọn ọgbẹ́ wo wá ni ti ẹ̀yìn rẹ?’ Yóo dáhùn pé, ‘Ọgbẹ́ tí mo gbà nílé àwọn ọ̀rẹ́ mi ni.’ ”

Àṣẹ pé kí Wọ́n Pa Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Ọlọrun

7 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké.

8 Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí.

9 N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 14

Jerusalẹmu ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín.

2 Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú.

3 OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun.

4 Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù.

5 Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀.

6 Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́,

7 kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.

8 Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn.

9 OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n.

10 A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba.

11 Àwọn eniyan yóo máa gbé inú ìlú Jerusalẹmu, kò ní sí ègún mọ́, ìlú Jerusalẹmu yóo sì wà ní alaafia.

12 Àjàkálẹ̀ àrùn tí OLUWA yóo fi bá àwọn tí wọ́n bá gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu jà nìyí: Ẹran ara wọn yóo rà nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, ojú wọn yóo rà ninu ihò rẹ̀, ahọ́n wọn yóo sì rà lẹ́nu wọn.

13 Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn;

14 Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ.

15 Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn.

16 Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́.

17 Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀.

18 Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí.

19 Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́.

20 Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ.

21 Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà.

Categories
MALAKI

MALAKI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Lẹ́yìn tí wọ́n ti tún Tẹmpili kọ́, ní nǹkan bí ẹẹdẹgbẹta ọdún ó dín díẹ̀ kí á tó bí OLUWA wa (5th century B.C), ni wọ́n kọ ìwé yìí. Ohun tí ó jẹ wolii Malaki lógún ni pé kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan ṣe àtúnṣe, kí wọ́n máa tẹ̀lé majẹmu tí wọ́n bá Ọlọrun dá pẹlu òtítọ́ ọkàn. Ó hàn ketekete pé ìwà ìbàjẹ́ ati aibikita kún ìgbé-ayé ati ìlànà ẹ̀sìn àwọn eniyan Ọlọrun. Àwọn alufaa ati àwọn eniyan kò fi àwọn nǹkan tí ó tọ́ rúbọ sí Ọlọrun mọ́, wọn kò sì pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn OLUWA yóo wá ṣèdájọ́ ayé, yóo wẹ àwọn eniyan rẹ̀ mọ́, yóo sì rán iranṣẹ rẹ̀ ṣiwaju láti tún ọ̀nà ṣe ati láti kéde majẹmu rẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli 1:1–2:16

Ìdájọ́ Ọlọrun ati àánú rẹ̀ 2:17–4:6

Categories
MALAKI

MALAKI 1

1 Iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Malaki sí àwọn ọmọ Israẹli nìyí.

Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli

2 OLUWA ní, “Mo fẹ́ràn yín pupọ.” Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló fihàn pé o fẹ́ràn wa?”

OLUWA dáhùn pé, “Ṣebí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni Esau ati Jakọbu?

3 Sibẹ mo fẹ́ràn Jakọbu, mo sì kórìíra Esau. Mo ti sọ gbogbo àwọn ìlú òkè Esau di ahoro, mo sì sọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ di ilé ajáko tí ó wà ní aṣálẹ̀.”

4 Bí Edomu bá sọ pé, “Ìlú wa ti di òkítì àlàpà, ṣugbọn a óo tún un kọ́.” Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo wá dáhùn pé, “Wọ́n lè máa kọ́ ọ, ṣugbọn n óo tún máa wó o lulẹ̀ títí tí àwọn eniyan yóo fi máa pè wọ́n ní orílẹ̀-èdè burúkú, àwọn ẹni tí OLUWA bínú sí títí lae.”

5 Ẹ óo fi ojú ara yín rí i ẹ óo sì sọ pé, “OLUWA tóbi lọ́ba, kódà títí dé ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ Israẹli!”

OLUWA Bá Àwọn Alufaa Wí

6 “Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’

7 Ìdí rẹ̀ tí mo fi ní ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi ni pé, ẹ̀ ń fi oúnjẹ àìmọ́ rúbọ lórí pẹpẹ mi. Ẹ tún bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi sọ pẹpẹ rẹ di àìmọ́?’ Ẹ ti tàbùkù pẹpẹ mi, nípa rírò pé ẹ lè tàbùkù rẹ̀.

8 Nígbà tí ẹ bá mú ẹran tí ó fọ́jú, tabi ẹran tí ó múkùn-ún, tabi ẹran tí ń ṣàìsàn wá rúbọ sí mi, ǹjẹ́ kò burú? Ṣé ẹ lè fún gomina ní irú rẹ̀ kí inú rẹ̀ dùn si yín, tabi kí ẹ rí ojurere rẹ̀?”

9 Nisinsinyii, ẹ̀yin alufaa, ẹ mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀ ń gbadura sí Ọlọrun, pé kí ó lè fi ojurere wò yín; Ṣé ẹ rò pé OLUWA yóo fi ojurere wo ẹnikẹ́ni ninu yín?

10 Ìbá ti dára tó kí ẹnìkan ninu yín ti ìlẹ̀kùn tẹmpili pa, kí ẹ má baà máa wá tanná mọ́, kí ẹ máa rú ẹbọ asán lórí pẹpẹ mi! Inú mi kò dùn si yín, n kò sì ní gba ọrẹ tí ẹ mú wá.

11 Nítorí pé, jákèjádò gbogbo ayé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ ni orúkọ mi ti tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ibi gbogbo ni wọ́n sì ti ń sun turari sí mi, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ mímọ́ sí mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

12 Ṣugbọn ẹ tàbùkù orúkọ mi nígbà tí ẹ sọ pé pẹpẹ OLUWA ti di àìmọ́, tí ẹ sì ń fi oúnjẹ tí ẹ pẹ̀gàn rúbọ lórí rẹ̀.

13 Ẹ̀ ń sọ pé, “Èyí sú wa!” Ẹ̀ ń yínmú sí mi. Ẹran tí ẹ fi ipá gbà, tabi èyí tí ó yarọ, tabi èyí tí ń ṣàìsàn ni ẹ̀ ń mú wá láti fi rúbọ. Ṣé ẹ rò pé n óo gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yín?

14 Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi.

Categories
MALAKI

MALAKI 2

1 OLUWA ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa, ẹ̀yin ni àṣẹ yìí wà fún.

2 Bí ẹ kò bá ní gbọ́ràn, tí ẹ kò sì ní fi sọ́kàn láti fi ògo fún orúkọ mi, n óo mú ègún wá sórí yín, ati sórí àwọn ohun ìní yín. Mo tilẹ̀ ti mú ègún wá sórí àwọn ohun ìní yín, nítorí pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn.

3 Ẹ wò ó! N óo jẹ àwọn ọmọ yín níyà, n óo fi ìgbẹ́ ẹran tí ẹ fi ń rúbọ kùn yín lójú, n óo sì le yín kúrò níwájú mi.

4 Nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni mo pàṣẹ yìí fun yín, kí majẹmu mi pẹlu Lefi má baà yẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!

5 “Majẹmu ìyè ati alaafia ni majẹmu mi pẹlu Lefi. Mo bá a dá majẹmu yìí kí ó baà lè bẹ̀rù mi; ó sì bẹ̀rù mi, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.

6 Ó fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ni, kìí sọ̀rọ̀ àìtọ́. Ó bá mi rìn ní alaafia ati ìdúróṣinṣin, ó sì yí ọkàn ọpọlọpọ eniyan pada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

7 Láti ẹnu alufaa ni ó ti yẹ kí ìmọ̀ ti máa jáde, kí àwọn eniyan sì máa gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé, iranṣẹ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni.

8 “Ṣugbọn ẹ̀yin alufaa ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́, ẹ ti mú ọ̀pọ̀ eniyan kọsẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ yín, ẹ sì ti da majẹmu tí mo bá Lefi dá.

9 Nítorí náà, n óo pa yín dà sí àìdára, ẹ óo sì di yẹpẹrẹ lójú àwọn eniyan; nítorí pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ̀ ń fi ojuṣaaju bá àwọn eniyan lò nígbà tí ẹ bá ń kọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

Aiṣootọ Àwọn Eniyan sí Ọlọrun

10 Ṣebí baba kan náà ló bí wa? Ṣebí Ọlọrun kan náà ló dá wa? Kí ló dé tí a fi ń ṣe aiṣootọ sí ara wa, tí a sì ń sọ majẹmu àwọn baba wa di aláìmọ́?

11 Àwọn ará Juda jẹ́ alaiṣootọ sí OLUWA, àwọn eniyan ti ṣe ohun ìríra ní Israẹli ati ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Juda ti sọ ibi mímọ́ tí OLUWA fẹ́ràn di aláìmọ́; àwọn ọmọkunrin wọn sì ti fẹ́ àjèjì obinrin, ní ìdílé abọ̀rìṣà.

12 Kí OLUWA yọ irú eniyan bẹ́ẹ̀ kúrò ní àwùjọ Jakọbu, kí ó má lè jẹ́rìí tabi kí ó dáhùn sí ohun tíí ṣe ti OLUWA, kí ó má sì lọ́wọ́ ninu ẹbọ rírú sí OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ lae!

13 Ohun mìíràn tí ẹ tún ń ṣe nìyí. Ẹ̀ ń sọkún, omijé ojú yín ń ṣàn lára pẹpẹ OLUWA, ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ sì ń ké, nítorí pé OLUWA kò gba ọrẹ tí ẹ mú wá fún un.

14 Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu.

15 Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín.

16 “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

Ọjọ́ Ìdájọ́ Súnmọ́lé

17 Ọ̀rọ̀ yín ti sú Ọlọrun, sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, “Báwo ni a ṣe mú kí ọ̀rọ̀ wa sú u?” Nítorí ẹ̀ ń sọ pé, “Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe burúkú jẹ́ eniyan rere níwájú OLUWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn.” Tabi nípa bíbèèrè pé, “Níbo ni Ọlọrun onídàájọ́ òdodo wà?”

Categories
MALAKI

MALAKI 3

1 OLUWA ní, “Wò ó! Mo rán òjíṣẹ́ mi ṣiwaju mi láti tún ọ̀nà ṣe fún mi. OLUWA tí ẹ sì ń retí yóo yọ lójijì sinu tẹmpili rẹ̀; iranṣẹ mi, tí ẹ sì tí ń retí pé kí ó wá kéde majẹmu mi, yóo wá.”

2 Ṣugbọn, ta ló lè farada ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá dé? Àwọn wo ni wọn yóo lè dúró ní ọjọ́ tí ó bá yọ?

Nítorí pé ó dàbí iná alágbẹ̀dẹ tí ń yọ́ irin, ati bí ọṣẹ alágbàfọ̀ tí ń fọ nǹkan mọ́.

3 Yóo jókòó bí ẹni tí ń yọ́ fadaka, yóo fọ àwọn ọmọ Lefi mọ́ bíi wúrà ati fadaka, títí tí wọn yóo fi mú ẹbọ tí ó tọ́ wá fún OLUWA.

4 Inú OLUWA yóo wá dùn sí ẹbọ Juda ati ti Jerusalẹmu nígbà náà bíi ti àtẹ̀yìnwá.

5 OLUWA ní, “N óo wá ba yín láti ṣe ìdájọ́; n óo wá jẹ́rìí mọ́ àwọn oṣó ati àwọn alágbèrè, àwọn tí wọn ń búra èké ati àwọn tí wọn kì í san owó ọ̀yà pé, àwọn tí wọn ń ni àwọn opó ati àwọn aláìníbaba lára, ati àwọn tí wọn ń ṣi àwọn àlejò lọ́nà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi.”

Sísan ìdámẹ́wàá

6 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí pé èmi OLUWA kì í yipada, ni a kò fi tíì run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu patapata.

7 Láti ayé àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti yapa kúrò ninu ìlànà mi, tí ẹ kò sì tẹ̀lé wọn mọ́. Ẹ̀yin ẹ yipada sí mi, èmi náà óo sì yipada si yín.

8 Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Báwo ni a ti ṣe lè yipada?’ Ǹjẹ́ ó ṣeéṣe fún eniyan láti ja Ọlọrun lólè? Ṣugbọn ẹ̀ ń jà mí lólè. Ẹ sì ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni à ń gbà jà ọ́ lólè?’ Nípa ìdámẹ́wàá ati ọrẹ yín ni.

9 Ègún wà lórí gbogbo yín nítorí pé gbogbo orílẹ̀-èdè yín ní ń jà mí lólè.

10 Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á.

11 N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì.

12 Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

Ìlérí Àánú Tí Ọlọrun Ṣe

13 OLUWA ní, “Ẹ ti fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Sibẹsibẹ ẹ̀ ń wí pé, ‘Irú ọ̀rọ̀ burúkú wo ni a sọ sí ọ?’

14 Ẹ sọ pé, ‘Kí eniyan máa sin Ọlọrun kò jámọ́ nǹkankan. Kò sì sí èrè ninu pípa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ninu rírẹ ara wa sílẹ̀ níwájú OLUWA àwọn ọmọ ogun.

15 Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nisinsinyii ni pé: ó ń dára fún àwọn agbéraga; kì í sì í ṣe pé ó ń dára fún àwọn eniyan burúkú nìkan, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá fi ìwà burúkú wọn dán Ọlọrun wò, kò sí nǹkankan tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.’ ”

16 Nígbà tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, OLUWA a máa tẹ́tí sí wọn, yóo sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ó ní ìwé kan níwájú rẹ̀ ninu èyí tí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ wà.

17 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn, wọn yóo jẹ́ ohun ìní mi pataki. N óo ṣàánú fún wọn bí baba tií ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.

18 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ óo tún rí ìyàtọ̀ láàrin àwọn eniyan rere tí wọn ń sin Ọlọrun, ati àwọn ẹni ibi tí wọn kì í sìn ín.”

Categories
MALAKI

MALAKI 4

Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀

1 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀ bí iná ìléru, tí àwọn agbéraga ati àwọn oníṣẹ́ ibi yóo jóná bíi koríko gbígbẹ. Ráúráú ni wọn óo jóná. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!

2 Ṣugbọn ní ti ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù mi, oòrùn òdodo yóo tàn si yín pẹlu ìwòsàn mi, ẹ óo máa yan káàkiri bí ọmọ ẹran tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀.

3 Ẹ óo tẹ àwọn eniyan burúkú mọ́lẹ̀, nítorí wọn yóo di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn.

4 “Ẹ ranti òfin ati ìlànà tí mo ti fún Mose, iranṣẹ mi, fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Horebu.

5 “Ẹ wò ó! N óo rán wolii Elija si yín kí ọjọ́ ńlá OLUWA, tí ó bani lẹ́rù náà tó dé.

6 Yóo yí ọkàn àwọn baba pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn, yóo sì yí ti àwọn ọmọ, pada sọ́dọ̀ àwọn baba wọn; kí n má baà fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.”

Categories
MATIU

MATIU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé tí à ń pè ní

Ìyìn Rere Matiu

ni ó fún wa ní ìròyìn ayọ̀, pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí. Òun ni Ọlọrun lò láti mú àdéhùn tí Ọlọrun bá àwọn eniyan inú Majẹmu Laelae dá ṣẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láàrin àwọn Juu ni wọ́n ti bí Jesu, ìyìn rere yìí kì í ṣe fún àwọn Juu nìkan; ti gbogbo aráyé ni.

Létòlétò ni wọ́n kọ

Ìwé Matiu.

Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìtàn ìbí Jesu, lẹ́yìn náà ó sọ nípa bí ó ṣe gba ìrìbọmi ati bí èṣù ṣe dán an wò. Ó tún sọ nípa iṣẹ́ iwaasu ati ti ìkọ́ni ati ti ìwòsàn tí Jesu ṣe ní Galili. Lẹ́yìn náà, ìwé ìyìn rere yìí sọ nípa ìrìn àjò Jesu láti Galili títí dé Jerusalẹmu. Ó tún sọ nípa àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu láàrin ọ̀sẹ̀ tí ó kẹ́yìn ìgbé-ayé rẹ̀. Boríborí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ọ̀sẹ̀ náà tí a kọ sinu ìwé yìí ni nípa ìkàn-mọ́-àgbélébùú ati ajinde rẹ̀.

Ìwé Ìyìn Rere yìí júwe Jesu pé Olùkọ́ni pataki ni, ati pé ó ní àṣẹ láti túmọ̀ òfin Ọlọrun, ó sì kọ́ni nípa ìjọba Ọlọrun. Ìwé yìí pín àwọn ẹ̀kọ́ tí Jesu kọ́ni sí ọ̀nà marun-un. Ó tò wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí oríṣìí ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́. (1) Ọ̀kan ni iwaasu lórí òkè, tí ó sọ nípa ìwà àwọn ọmọ ìjọba Ọlọrun, iṣẹ́ wọn, àwọn anfaani tí wọn ní, ati àtubọ̀tán wọn (orí 5 títí dé 7); (2) Ìlànà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila nípa iṣẹ́ wọn (orí 10); (3) Àwọn òwe nípa ìjọba ọ̀run (orí 13); (4) Ẹ̀kọ́ nípa ìtumọ̀ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn (orí 18); (5) Ẹ̀kọ́ nípa òpin àkókò tí a wà yìí, ati bíbọ̀ ìjọba Ọlọrun (orí 24–25).

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àkọsílẹ̀ Àtìrandíran Jesu Kristi ati ìbí rẹ̀ 1:1–2:23

Àwọn ohun tí Johanu Onítẹ̀bọmi ṣe 3:1-12

Ìrìbọmi Jesu ati ìdánwò rẹ̀ 3:13–4:11

Iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba ní Galili 4:12–18:35

Láti Galili dé Jerusalẹmu 19:1–20:34

Ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn Jesu ní Jerusalẹmu ati ní agbègbè rẹ̀ 21:1–27:66

Ajinde Oluwa ati bí ó ṣe farahàn káàkiri 28:1-20

Categories
MATIU

MATIU 1

Ìran Jesu Kristi

1 Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu.

2 Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀.

3 Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu.

4 Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni.

5 Salimoni bí Boasi, ìyá Boasi ni Rahabu, Boasi bí Obedi. Ìyá Obedi ni Rutu. Obedi bí Jese.

6 Jese bí Dafidi ọba.

Dafidi bí Solomoni. Aya Uraya tẹ́lẹ̀ ni ìyá Solomoni.

7 Solomoni bí Rehoboamu, Rehoboamu bí Abija, Abija bí Asa.

8 Asa bí Jehoṣafati, Jehoṣafati bí Joramu, Joramu bí Usaya.

9 Usaya bí Jotamu, Jotamu bí Ahasi, Ahasi bí Hesekaya.

10 Hesekaya bí Manase, Manase bí Amosi, Amosi bí Josaya.

11 Josaya bí Jekonaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ní àkókò tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni.

12 Lẹ́yìn tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni, Jekonaya bí Ṣealitieli, Ṣealitieli bí Serubabeli.

13 Serubabeli bí Abihudi, Abihudi bí Eliakimu, Eliakimu bí Asori.

14 Asori bí Sadoku, Sadoku bí Akimu, Akimu bí Eliudi.

15 Eliudi bí Eleasari, Eleasari bí Matani, Matani bí Jakọbu.

16 Jakọbu bí Josẹfu ọkọ Maria, ẹni tí ó bí Jesu tí à ń pè ní Kristi.

17 Nítorí náà, gbogbo ìran Jesu láti ìgbà Abrahamu títí di ti Dafidi jẹ́ mẹrinla; láti ìgbà Dafidi títí di ìgbà tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni jẹ́ ìran mẹrinla; láti ìgbà tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni títí di àkókò Kristi jẹ́ ìran mẹrinla.

Ìtàn Ìbí Jesu Kristi

18 Bí ìtàn ìbí Jesu Kristi ti rí nìyí. Nígbà tí Maria ìyá rẹ̀ wà ní iyawo àfẹ́sọ́nà Josẹfu, kí wọn tó ṣe igbeyawo, a rí i pé Maria ti lóyún láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

19 Eniyan rere ni Josẹfu ọkọ rẹ̀, kò fẹ́ dójú tì í, ó fẹ́ rọra kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́.

20 Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní.

21 Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22 Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii nì lè ṣẹ pé,

23 “Wundia kan yóo lóyún,yóo bí ọmọkunrin kan; wọn yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.” (Ìtumọ̀, “Imanuẹli” ni “Ọlọrun wà pẹlu wa.”)

24 Nígbà tí Josẹfu jí láti ojú oorun, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Oluwa náà ti pàṣẹ fún un. Ó mú iyawo rẹ̀ sọ́dọ̀.

25 Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu.