Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 2

Ìran nípa Okùn Ìwọ̀n

1 Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́.

2 Mo bi í pé, “Níbo ni ò ń lọ?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń lọ wọn Jerusalẹmu, kí n lè mọ òòró ati ìbú rẹ̀ ni.”

3 Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé,

4 “Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká.

5 Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ odi iná tí n óo yí i ká, tí n óo máa dáàbò bò ó, n óo sì fi ògo mi kún inú rẹ̀.”

Pípe Àwọn tí A kó lẹ́rú pada Wálé

6 OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ àríwá. Lóòótọ́ èmi ni mo fọn yín ká bí afẹ́fẹ́ sí igun mẹrẹẹrin ayé,

7 ṣugbọn nisinsinyii, ẹ sá àsálà lọ sí Sioni, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Babiloni.

8 Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán ni sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ko yín lẹ́rú, nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, fọwọ́ kan ẹyinjú èmi OLUWA.”

9 N óo bá àwọn ọ̀tá yín jà; wọn yóo sì di ẹrú àwọn tí ń sìn wọ́n.

Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA àwọn ọmọ ogun.

10 OLUWA ní, “Ẹ kọrin ayọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín máa dùn, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, nítorí pé mò ń bọ̀ wá máa ba yín gbé.

11 Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo parapọ̀ láti di eniyan mi nígbà náà. N óo máa gbé ààrin yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ranṣẹ si yín.

12 N óo jogún Juda bí ohun ìní mi ninu ilẹ̀ mímọ́, n óo sì yan Jerusalẹmu.”

13 Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀.

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 3

Ìran wolii náà nípa Olórí Alufaa

1 Lẹ́yìn náà, OLUWA fi Joṣua olórí alufaa hàn mí; ó dúró níwájú angẹli OLUWA, Satani sì dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti fi ẹ̀sùn kàn án.

2 Angẹli OLUWA sọ fún Satani pé, “OLUWA óo bá ọ wí, ìwọ Satani! OLUWA tí ó yan Jerusalẹmu óo bá ọ wí! Ṣebí ẹ̀ka igi tí a yọ jáde láti inú iná ni ọkunrin yìí?”

3 Joṣua dúró níwájú angẹli Ọlọrun, pẹlu aṣọ tí ó dọ̀tí ní ọrùn rẹ̀.

4 Angẹli náà bá sọ fún àwọn tí wọ́n dúró tì í pé, “Ẹ bọ́ aṣọ tí ó dọ̀tí yìí kúrò lọ́rùn rẹ̀.” Ó bá sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò, n óo sì fi aṣọ tí ó lẹ́wà wọ̀ ọ́.”

5 Ó bá pàṣẹ pé, “Ẹ fi aṣọ mímọ́ wé e lórí.” Wọ́n bá fi aṣọ mímọ́ wé e lórí, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, angẹli OLUWA sì dúró tì í.

6 Angẹli náà kìlọ̀ fún Joṣua pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní,

7 “Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi.

8 Gbọ́ nisinsinyii, ìwọ Joṣua, olórí alufaa, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin alufaa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin ni àmì ohun rere tí ń bọ̀, pé n óo mú iranṣẹ mi wá, tí a pè ní Ẹ̀ka.

9 Wò ó! Nítorí mo gbé òkúta kan tí ó ní ojú meje siwaju Joṣua, n óo sì kọ àkọlé kan sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ṣoṣo ni n óo mú ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ yìí kúrò.

10 Ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo pe aládùúgbò rẹ̀ láti wá bá a ṣe fàájì lábẹ́ àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 4

Ìran nípa Ọ̀pá Fìtílà

1 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn.

2 Ó bi mí pé kí ni mo rí.

Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje.

3 Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.”

4 Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?”

5 Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”

Ìlérí Ọlọrun fún Serubabeli

6 Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi.

7 Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ”

8 OLUWA tún rán mi pé,

9 “Serubabeli tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé Ọlọrun yìí ni yóo parí rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn eniyan mi yóo mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo rán ọ sí wọn.

10 Inú àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí yóo dùn, wọn yóo sì rí okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubabeli. Àwọn fìtílà meje wọnyi ni ojú OLUWA tí ń wo gbogbo ayé.”

11 Mo bá bi í pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn igi olifi meji tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà?”

12 Mo tún bèèrè lẹẹkeji pé, “Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀ka olifi meji, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrè wúrà meji, tí òróró olifi ń ṣàn jáde ninu wọn?”

13 Ó tún bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”

14 Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 5

Ìran nípa Ìwé Kíká Tí Ó Ń Fò

1 Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú.

2 Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).”

3 Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.”

4 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.”

Ìran nípa Obinrin Tó Wà ninu Apẹ̀rẹ̀

5 Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.”

6 Mo bèèrè pé, “Kí ni èyí?” Ó dáhùn pé, “Agbọ̀n òṣùnwọ̀n eefa kan ni. Ó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ yìí.”

7 Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà.

8 Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada.

9 Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ.

10 Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?”

11 Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 6

Ìran nípa Àwọn Kẹ̀kẹ́ Ogun Mẹrin

1 Mo tún gbé ojú sókè, mo rí kẹ̀kẹ́ ogun mẹrin tí ń bọ̀ láàrin òkè meji; òkè idẹ ni àwọn òkè náà.

2 Àwọn ẹṣin pupa ni wọ́n ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àkọ́kọ́, àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ ogun keji,

3 ẹṣin funfun ń fa ẹkẹta, àwọn tí wọn ń fa ẹkẹrin sì jẹ́ kàláńkìnní.

4 Mo bi angẹli náà pé, “Oluwa mi, kí ni ìtumọ̀ ìwọ̀nyí?”

5 Angẹli náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ń lọ sí igun mẹrẹẹrin ayé lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn han Ọlọrun ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.”

6 Àwọn ẹṣin dúdú ń fa kẹ̀kẹ́ tiwọn lọ sí ìhà àríwá, àwọn ẹṣin funfun ń lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ń lọ sí ìhà gúsù.

7 Bí àwọn ẹṣin tí wọ́n jẹ́ kàláńkìnní ti jáde, wọ́n ń kánjú láti lọ máa rin ayé ká. Angẹli náà bá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ; wọ́n sì lọ.

8 Angẹli náà bá ké sí mi, ó ní, “Àwọn ẹṣin tí wọn ń lọ sí ìhà àríwá ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ nípa ibẹ̀.”

Àṣẹ nípa ati Dé Joṣua ládé

9 OLUWA pàṣẹ fún mi pé,

10 “Lára àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ti oko ẹrú Babiloni dé, mú Helidai, Tobija ati Jedaaya lẹsẹkẹsẹ, kí o lọ sí ilé Josaya ọmọ Sefanaya.

11 Gba fadaka ati wúrà lọ́wọ́ wọn, kí o fi ṣe adé, kí o sì fi adé náà dé Joṣua olórí alufaa, ọmọ Jehosadaki lórí.

12 Kí o sì sọ ohun tí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí fún un, pé, ‘Wò ó! Ọkunrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka ni yóo gba ipò rẹ̀, òun ni yóo sì kọ́ ilé OLUWA.

13 Òun gan-an ni yóo kọ́ ọ, tí yóo sì gba ògo ati ẹ̀yẹ tí ó yẹ fún ọba, yóo sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀. Yóo ní alufaa gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn, wọn yóo sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní alaafia.’

14 Adé náà yóo wà ní ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún Helidai ati Tobija ati Jedaaya ati Josaya, ọmọ Sefanaya.

15 “Àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn réré yóo wá láti ba yín kọ́ ilé OLUWA. Ẹ óo wá mọ̀ dájú pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán mi si yín. Gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ patapata bí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 7

OLUWA Kọ Ààwẹ̀ Àgàbàgebè

1 Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan-an, tíí ṣe oṣù Kisilefi, ní ọdún kẹrin ìjọba Dariusi, ni OLUWA rán mi níṣẹ́ yìí.

2 Àwọn ará Bẹtẹli rán Ṣareseri ati Regemumeleki ati gbogbo àwọn eniyan wọn lọ sí ilé OLUWA; wọ́n lọ wá ojurere OLUWA,

3 wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?”

4 OLUWA àwọn ọmọ ogun bá rán mi pé,

5 “Sọ fún gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ati àwọn alufaa pé, nígbà tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, tí ẹ sì ń ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karun-un ati oṣù keje fún odidi aadọrin ọdún, ṣé èmi ni ẹ̀ ń gbààwẹ̀ fún?

6 Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?”

7 Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀?

Àìgbọràn ló fa Ìkólọ-sóko-Ẹrú

8 OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé,

9 “Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín.

10 Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.”

11 Ṣugbọn àwọn eniyan kò gbọ́, wọ́n ṣe oríkunkun, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ tèmi.

12 Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi.

13 “Nígbà tí mo pè wọ́n, wọn kò gbọ́, nítorí náà ni n kò fi ní fetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí.

14 Bí ìjì líle tí ń fọ́n nǹkan káàkiri bẹ́ẹ̀ ni mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì. Ilẹ̀ dáradára tí wọ́n fi sílẹ̀ di ahoro, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀ mọ́.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 8

Ọlọrun ṣèlérí láti Dá Ibukun Jerusalẹmu Pada

1 OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀ pé

2 Òun fẹ́ràn àwọn ará Sioni; nítorí náà ni inú òun ṣe ru sí àwọn ọ̀tá wọn.

3 Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́.

4 Àwọn arúgbó lọkunrin, lobinrin, tí wọn ń tẹ̀pá yóo jókòó ní ìgboro Jerusalẹmu,

5 ìta ati òpópónà yóo sì kún fún àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin tí wọn ń ṣeré.

6 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní bí eléyìí bá jẹ́ ohun ìyanu lójú àwọn eniyan yòókù, ǹjẹ́ ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ìyanu lójú òun náà?

7 Ó ní òun óo gba àwọn eniyan òun là láti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìlà oòrùn ati ti ìwọ̀ rẹ̀,

8 òun óo mú wọn pada wá sí Jerusalẹmu láti máa gbébẹ̀; wọn óo jẹ́ eniyan òun, òun náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, lóòótọ́ ati lódodo.

9 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ ṣara gírí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii tí ń sọ láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun lélẹ̀, kí ẹ baà lè kọ́ ilé náà parí.

10 Nítorí ṣáájú àkókò náà, kò sí owó iṣẹ́ fún eniyan tabi ẹranko, eniyan kò sì lè rin ìrìn àjò láìléwu; nítorí àwọn ọ̀tá tí wọ́n wà káàkiri, nítorí mo mú kí olukuluku lòdì sí ẹnìkejì rẹ̀.

11 Ṣugbọn nisinsinyii, n kò ní ṣe sí àwọn eniyan yòókù yìí bí mo ti ṣe sí àwọn ti iṣaaju.

12 Alaafia ni wọn yóo fi gbin èso wọn, àjàrà wọn yóo so jìnwìnnì, òjò yóo rọ̀, ilẹ̀ yóo sì mú èso jáde. Àwọn eniyan mi tí ó ṣẹ́kù ni yóo sì ni gbogbo nǹkan wọnyi.

13 Ẹ̀yin ilé Juda ati ilé Israẹli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ yín ni àwọn eniyan fi ń ṣépè lé àwọn mìíràn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbà yín, ẹ óo sì di orísun ibukun. Nítorí náà, ẹ mọ́kànle, ẹ má bẹ̀rù.”

14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti pinnu láti ṣe yín ní ibi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú, tí n kò sì yí ìpinnu mi pada,

15 bẹ́ẹ̀ ni mo tún pinnu nisinsinyii láti ṣe ẹ̀yin ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda ní rere. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù.

16 Àwọn nǹkan tí ó yẹ kí ẹ máa ṣe nìyí: ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ nílé ẹjọ́; èyí ni yóo máa mú alaafia wá.

17 Ẹ má máa gbèrò ibi sí ara yín, ẹ má sì fẹ́ràn ìbúra èké, nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni mo kórìíra.”

18 OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá Sakaraya sọ̀rọ̀, ó ní,

19 “Ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà ní oṣù kẹrin, oṣù karun-un, oṣù keje, ati oṣù kẹwaa yóo di àkókò ayọ̀ ati inú dídùn ati àkókò àríyá fun yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ ati alaafia.

20 “Ọ̀pọ̀ eniyan yóo ti oríṣìíríṣìí ìlú wá sí Jerusalẹmu,

21 àwọn ará ìlú kan yóo máa rọ àwọn ará ìlú mìíràn pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ kíákíá láti wá ojurere OLUWA, ati láti sin OLUWA àwọn ọmọ ogun; ibẹ̀ ni mò ń lọ báyìí.’

22 Ọpọlọpọ eniyan ati àwọn orílẹ̀-èdè ńlá yóo wá sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, wọn óo sì wá wá ojurere rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

23 Nígbà tó bá yá, eniyan mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè yóo rọ̀ mọ́ aṣọ Juu kanṣoṣo, wọn yóo sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí á máa bá ọ lọ, nítorí a gbọ́ pé Ọlọrun wà pẹlu yín.’ ”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 9

Ìdájọ́ lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Wọ́n Wà ní Agbègbè Israẹli

1 OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli.

2 Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

3 Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba.

4 Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun.

5 Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro.

6 Oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni yóo máa gbé Aṣidodu; ìgbéraga Filistia yóo sì dópin.

7 N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi.

8 Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ.

Ọba Tí Ń Bọ̀ Wá Jẹ

9 Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni!

Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!

Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín;

ajagun-ṣẹ́gun ni,

sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.

10 OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu,

òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu,

a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun.

Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia,

ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkun

ati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé.

Ìmúpadà sípò Àwọn Eniyan Mi

11 Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu,

n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi.

12 Ẹ pada sí ibi ààbò yín,

ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí;

mo ṣèlérí lónìí pé,

n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji.

13 Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi,

mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀.

Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà,

láti pa àwọn ará Giriki run,

n óo sì fi tagbára tagbára lò yín

bí idà àwọn jagunjagun.

14 OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀,

yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná.

OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogun

yóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù.

15 OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀.

Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn,

wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn,

ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ,

tí a dà sórí pẹpẹ,

láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran.

16 Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n,

bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀.

Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀,

bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé.

17 Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó?

Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbára

ọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 10

OLUWA Ṣèlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀.

2 Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.

3 OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun.

4 Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi.

5 Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.

6 “N óo sọ ilé Juda di alágbára,

n óo sì gba ilé Josẹfu là.

N óo mú wọn pada,

nítorí àánú wọn ń ṣe mí,

wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí;

nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn,

n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn.

7 Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára,

inú wọn yóo sì dùn

bí inú ẹni tí ó mu ọtí waini.

Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i,

inú wọn yóo dùn,

ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA.

8 “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn,

n óo sì kó wọn jọ sinu ilé.

Mo ti rà wọ́n pada,

nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn ká

sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,

sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà.

Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè,

wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn.

10 N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá,

n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria;

n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni,

wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́.

11 Wọn óo la òkun Ijipti kọjá,

ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀,

a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀,

agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.

12 N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA,

wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 11

Ìṣubú Àwọn Aninilára

1 Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanoni

kí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ!

2 Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi,

nítorí igi kedari ti ṣubú,

àwọn igi ológo ti parun.

Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani,

nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀!

3 Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran,

nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́.

Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù,

nítorí igbó tí wọn ń gbé

lẹ́bàá odò Jọdani ti parun!

Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Meji

4 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n.

5 Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.”

6 OLUWA ní, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n kò ní ṣàánú àwọn eniyan ilẹ̀ yìí mọ́. Fúnra mi ni n óo fi wọ́n lé àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba wọn lọ́wọ́. Wọn óo run ilẹ̀ náà, n kò sì ní gba ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ wọn.”

7 Mo ti di darandaran agbo ẹran tí à ń dà lọ fún àwọn alápatà. Mo mú ọ̀pá meji, mo sọ ọ̀kan ní “Oore-ọ̀fẹ́,” mo sì sọ ekeji ní “Ìṣọ̀kan.”

8 Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan.

9 Mo wá sọ fún àwọn agbo ẹran náà pé, “N kò ní ṣe olùṣọ́ yín mọ́. Èyí tí yóo bá kú ninu yín kí ó kú, èyí tí yóo bá ṣègbé, kí ó ṣègbé, kí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù sì máa pa ara wọn jẹ.”

10 Mo bá mú ọ̀pá mi tí ń jẹ́ “Oore-ọ̀fẹ́,” mo dá a, mo fi fi òpin sí majẹmu tí mo bá àwọn orílẹ̀-èdè dá.

11 Nítorí náà, majẹmu mi ti dópin lọ́jọ́ náà. Àwọn tí wọn ń ṣòwò aguntan, tí wọn ń wò mí, mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ṣe ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.

12 Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi.

13 Nígbà náà ni OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ pa owó náà mọ́ sílé ìṣúra.” Nítorí náà, mo da ọgbọ̀n owó fadaka tí wọ́n san fún mi, sinu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA.

14 Nígbà náà ni mo dá ọ̀pá mi keji tí ń jẹ́ “Ìṣọ̀kan,” mo fi fi òpin sí àjọṣe tí ó wà láàrin Juda ati Israẹli.

15 OLUWA tún sọ fún mi pé “Tún fi ara rẹ sí ipò darandaran tí kò wúlò fún nǹkankan.

16 Wò ó! N óo gbé darandaran kan dìde tí kò ní bìkítà fún àwọn ẹran tí wọ́n ń ṣègbé, kò ní tọpa àwọn tí wọn ń ṣáko lọ, tabi kí ó wo àwọn tí ń ṣàìsàn sàn, tabi kí ó fún àwọn tí ara wọn le ní oúnjẹ. Dípò kí ó tọ́jú wọn, pípa ni yóo máa pa àwọn tí ó sanra jẹ, tí yóo sì máa fa pátákò wọn ya.

17 Olùṣọ́-aguntan mi tí kò bá níláárí gbé! Tí ó ń fi agbo ẹran sílẹ̀. Idà ni yóo ṣá a ní apá, yóo sì bá a ní ojú ọ̀tún, apá rẹ̀ óo rọ patapata, ojú ọ̀tún rẹ̀ óo sì fọ́ patapata.”