Categories
HABAKUKU

HABAKUKU 3

Adura Habakuku

1 Adura tí wolii Habakuku kọ lórinnìyí:

2 OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ,

mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́;

tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa;

sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ.

3 OLUWA wá láti Temani,

Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani.

Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run,

gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀.

4 Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan,

ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde;

níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5 Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,

ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.

6 Ó dúró, ó wọn ayé;

Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì;

àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká,

àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀.

Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀.

7 Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu,

àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì.

8 OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni,

àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí,

tabi òkun ni ò ń bá bínú,

nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ,

tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ?

9 Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun,

tí o fi ọfà lé ọsán ọrun;

tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé.

10 Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ,

wọ́n wárìrì;

àgbàrá omi wọ́ kọjá;

ibú òkun pariwo,

ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.

11 Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn,

nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò,

tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà,

bí wọ́n ti ń fò lọ.

12 O la ayé kọjá pẹlu ibinu,

o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.

13 O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là,

láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là.

O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú,

o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn.

14 O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun;

àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líle

láti tú wa ká,

tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀.

15 O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀;

wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀.

16 Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì,

ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀

nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀;

egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà,

ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀.

N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé

bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.

17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé,

tí àjàrà kò sì so,

tí kò sí èso lórí igi olifi;

tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko,

tí àwọn agbo aguntan run,

tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́,

18 sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA,

n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi.

19 Ọlọrun, OLUWA, ni agbára mi;

Ó mú kí ẹsẹ̀ mi yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,

ó mú mi rìn lórí àwọn òkè gíga.

(Sí ọ̀gá akọrin; pẹlu àwọn ohun èlò orin olókùn.)

Categories
SEFANAYA

SEFANAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Nǹkan bí ẹgbẹta ọdún ó lé díẹ̀ kí á tó bí OLUWA wa (7th Century B.C.) ni wolii Sefanaya waasu. Ó tó ọdún kẹwaa sí àkókò tí Josaya ọba ṣe àtúnṣe ẹ̀sìn ní nǹkan bí ẹgbẹta ọdún ó lé mọkanlelogun kí á tó bí OLUWA wa (621 B.C.) Kókó ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí rí bákan náà pẹlu àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé àwọn wolii ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù pé: Ọjọ́ ìparun ń bọ̀ lórí Juda nítorí ìbọ̀rìṣà; OLUWA yóo sì jẹ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn níyà pẹlu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jerusalẹmu ti parun, láìpẹ́ ìlú náà yóo pada bọ̀ sípò, àwọn onírẹ̀lẹ̀ ati olódodo yóo sì máa gbé ibẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọjọ́ ìdájọ́ OLUWA 1:1–2:3

Ìparun àwọn ará agbègbè Israẹli 2:4-15

Ìparun ati ìràpadà Jerusalẹmu 3:1-20

Categories
SEFANAYA

SEFANAYA 1

1 Èyí ni iṣẹ́ tí Ọlọrun rán Sefanaya, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedalaya, ọmọ Amaraya, ọmọ Hesekaya ní àkókò ìjọba Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda.

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọrun

2 OLUWA ní, “N óo pa gbogbo nǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run:

3 ati eniyan ati ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, ati gbogbo ẹja. N óo bi àwọn eniyan burúkú ṣubú; n óo pa eniyan run lórí ilẹ̀.

4 “N óo na ọwọ́ ibinu mi sí ilẹ̀ Juda, ati sí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo pa gbogbo oriṣa Baali tí ó kù níhìn-ín run, ati gbogbo àwọn babalóòṣà wọn;

5 ati àwọn tí ń gun orí òrùlé lọ láti bọ oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Wọ́n ń sin OLUWA wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ búra wọ́n sì tún ń fi oriṣa Milikomu búra;

6 àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

7 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA Ọlọrun! Nítorí ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé; OLUWA ti ṣètò ẹbọ kan, ó sì ti ya àwọn kan sọ́tọ̀, tí yóo pè wá jẹ ẹ́.

8 Ní ọjọ́ ìrúbọ OLUWA, “N óo fi ìyà jẹ àwọn alákòóso ati àwọn ọmọ ọba, ati àwọn tí ń fi aṣọ orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.

9 Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ àwọn tí ń fo ẹnu ọ̀nà kọjá bí àwọn abọ̀rìṣà níyà,ati àwọn tí ń fi ìwà ipá, ati olè jíjà kó nǹkan kún ilé oriṣa wọn.”

10 OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, ariwo ńlá ati ìpohùnréré ẹkún yóo sọ ní Ẹnubodè Ẹja ní Jerusalẹmu; ní apá ibi tí àwọn eniyan ń gbé, ati ariwo bí ààrá láti orí òkè wá.

11 Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Mota, ní Jerusalẹmu; nítorí pé àwọn oníṣòwò ti lọ tán patapata; a ti pa àwọn tí ń wọn fadaka run.

12 “Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’

13 A óo kó wọn lẹ́rù lọ, a óo sì wó ilé wọn lulẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ kọ́ ọpọlọpọ ilé, wọn kò ní gbébẹ̀; bí wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà, wọn kò ní mu ninu waini rẹ̀.”

14 Ọjọ́ ńlá OLUWA súnmọ́lé, ó súnmọ́ etílé, ó ń bọ̀ kíákíá. Ọjọ́ náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn akikanju ọkunrin yóo kígbe lóhùn rara.

15 Ọjọ́ ibinu ni ọjọ́ náà yóo jẹ́, ọjọ́ ìpọ́njú ati ìrora, ọjọ́ ìyọnu ati ìparun, ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.

16 Ọjọ́ ipè ogun ati ariwo ogun sí àwọn ìlú olódi ati àwọn ilé-ìṣọ́ gíga.

17 N óo mú hílàhílo bá ọmọ eniyan, kí wọ́n baà lè rìn bí afọ́jú. Nítorí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóo ṣàn dànù bí omi, a óo sì sọ ẹran ara wọn nù bí ìgbẹ́.

18 Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA, gbogbo ayé ni yóo jó àjórun ninu iná owú rẹ̀; nítorí pé yóo mú òpin dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orílẹ̀ ayé.

Categories
SEFANAYA

SEFANAYA 2

Ìpè sí Ìrònúpìwàdà

1 Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ gbìmọ̀ pọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú.

2 Kí á tó fẹ yín dànù, bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ ìyàngbò káàkiri, kí ibinu Ọlọrun tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìrúnú OLUWA tó dé ba yín.

3 Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.

Ìparun tí Yóo Dé Bá Àwọn Ìlú tí Wọ́n Yí Israẹli Ká

4 Àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ìlú Gasa; ìlú Aṣikeloni yóo dahoro; a óo lé àwọn ará ìlú Aṣidodu jáde lọ́sàn-án gangan, a óo sì tú ìlú Ekironi ká.

5 Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè Kereti! Ọ̀rọ̀ OLUWA ń ba yín wí, Kenaani, ilẹ̀ àwọn ará Filistia; n óo pa yín run patapata láìku ẹnìkan.

6 Ilẹ̀ etí òkun yóo di pápá oko fún àwọn darandaran, ati ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo ti máa jẹko.

7 Etí òkun yóo sì di ilẹ̀-ìní fún àwọn ọmọ Juda tí ó kù, níbi tí àwọn ẹran wọn yóo ti máa jẹko, ní alẹ́, wọn yóo sùn sinu àwọn ilé ninu ìlú Aṣikeloni, nítorí OLUWA Ọlọrun wọn yóo wà pẹlu wọn, yóo sì dá ohun ìní wọn pada.

8 OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè,

9 mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.”

10 Wọn yóo sì gba ilẹ̀ wọn, ohun tí yóo dé bá wọn nìyí nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn eniyan èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n ń fi wọ́n fọ́nnu.

11 OLUWA óo dẹ́rùbà wọ́n, yóo sọ gbogbo oriṣa ilé ayé di òfo, olukuluku eniyan yóo sì máa sin OLUWA ní ààyè rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

12 Ẹ̀yin ará Etiopia, n óo fi idà mi pa yín.

13 Èmi OLUWA yóo dojú ìjà kọ ìhà àríwá, n óo pa ilẹ̀ Asiria run; n óo sọ ìlú Ninefe di ahoro, ilẹ̀ ibẹ̀ yóo sì gbẹ bí aṣálẹ̀.

14 Àwọn agbo ẹran yóo dùbúlẹ̀ láàrin rẹ̀, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́, àwọn ẹyẹ igún ati òòrẹ̀ yóo sì máa gbé inú olú-ìlú rẹ̀. Ẹyẹ òwìwí yóo máa dún lójú fèrèsé, ẹyẹ ìwò yóo máa ké ní ibi ìpakà wọn tí yóo dahoro; igi kedari rẹ̀ yóo sì ṣòfò.

15 Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìlú tí ó jókòó láìléwu, tí ń fọ́nnu wí pé, “Kò sí ẹlòmíràn mọ́, àfi èmi nìkan.” Wá wò ó, ó ti dahoro, ó ti di ibùgbé fún àwọn ẹranko burúkú! Gbogbo àwọn tí wọn ń gba ibẹ̀ kọjá ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn.

Categories
SEFANAYA

SEFANAYA 3

Ẹ̀ṣẹ̀ Jerusalẹmu ati Ìràpadà Rẹ̀

1 Ìwọ ìlú ọlọ̀tẹ̀, o gbé! Ìlú oníbàjẹ́ ati aninilára.

2 Ìlú tí kò gba ìmọ̀ràn ati ìbáwí, tí kò gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí kò sì súnmọ́ Ọlọrun rẹ̀.

3 Àwọn olóyè rẹ̀ ní ìwọ̀ra bíi kinniun tí ń bú ramúramù; àwọn onídàájọ́ rẹ̀ dàbí ìkookò tí ń jẹ ní aṣálẹ̀ tí kì í jẹ ẹran tí ó bá pa lájẹṣẹ́kù di ọjọ́ keji.

4 Oníwọ̀ra ati alaiṣootọ eniyan ni àwọn wolii rẹ̀, àwọn alufaa rẹ̀ sì ti sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́, wọ́n yí òfin Ọlọrun po fún anfaani ara wọn.

5 Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ.

6 OLUWA wí pé: “Mo ti pa àwọn orílẹ̀-èdè run; ilé-ìṣọ́ wọn sì ti di àlàpà; mo ti ba àwọn ìgboro wọn jẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè rìn níbẹ̀; àwọn ìlú wọn ti di ahoro, láìsí olùgbé kankan níbẹ̀.

7 Mo ní, ‘Dájúdájú, wọn óo bẹ̀rù mi, wọn óo gba ìbáwí, wọn óo sì fọkàn sí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn.’ Ṣugbọn, ń ṣe ni wọ́n ń múra kankan,

8 tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Ẹ dúró dè mí di ọjọ́ tí n óo dìde bí ẹlẹ́rìí. Mo ti pinnu láti kó àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ìjọba jọ, láti jẹ́ kí wọn rí ibinu mi, àní ibinu gbígbóná mi; gbogbo ayé ni yóo sì parun nítorí ìrúnú gbígbóná mi.

9 “N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan.

10 Láti ọ̀nà jíjìn, níkọjá àwọn odò Etiopia, àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan mi tí a fọ́n káàkiri yóo mú ọrẹ ẹbọ wá fún mi.

11 “Ní ọjọ́ náà, a kò ní dójútì yín nítorí ohun tí ẹ ṣe, tí ẹ dìtẹ̀ mọ́ mi; nítorí pé n óo yọ àwọn onigbeeraga kúrò láàrin yín, ẹ kò sì ní ṣoríkunkun sí mi mọ́ ní òkè mímọ́ mi.

12 Nítorí pé, n óo fi àwọn onírẹ̀lẹ̀ ati aláìlera sílẹ̀ sí ààrin yín, orúkọ èmi OLUWA ni wọn yóo gbẹ́kẹ̀lé.

13 Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.”

Orin Ayọ̀

14 Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó;

ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi,

ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!

15 OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò,

ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ.

OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín;

ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́.

16 Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé:

“Ẹ má ṣe fòyà;

ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù.

17 OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín,

akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni;

yóo láyọ̀ nítorí yín,

yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín,

yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè

18 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.”

OLUWA ní:

“N óo mú ibi kúrò lórí yín,

kí ojú má baà tì yín.

19 N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín,

n óo gba àwọn arọ là,

n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ.

N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògo

gbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn.

20 N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà,

nígbà tí mo bá ko yín jọ tán:

n óo sọ yín di eniyan pataki

ati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé,

nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín,

Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Categories
HAGAI

HAGAI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Hagai ní nǹkan bíi ẹẹdẹgbẹta ọdún ó lé ogún kí á tó bí OLUWA wa (520 B.C.) Àwọn eniyan náà ti pada ti oko ẹrú dé ṣugbọn wọn kò tíì tún Tẹmpili kọ́. Iṣẹ́ tí OLUWA rán ni pé kí àwọn eniyan náà tún Tẹmpili kọ́, ó sì ṣèlérí alaafia ati ìtẹ̀síwájú fún wọn nítorí pé wọ́n ti di ẹ̀dá titun ati eniyan mímọ́.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àṣẹ láti tún Tẹmpili kọ́ 1:1-15

OLUWA ranṣẹ ìtùnú ati ìrètí sí wọn 2:1-23

Categories
HAGAI

HAGAI 1

OLUWA pàṣẹ láti tún Tẹmpili Kọ́

1 Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Hagai sí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa.

2 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Àwọn eniyan wọnyi ní, kò tíì tó àkókò láti tún Tẹmpili kọ́.”

3 Nítorí náà ni OLUWA ṣe rán wolii Hagai sí wọn ó ní,

4 “Ẹ̀yin eniyan mi, ṣé àkókò nìyí láti máa gbé inú ilé tiyín tí ẹ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí Tẹmpili wà ní àlàpà?

5 Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín:

6 Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí.

7 Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

8 Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.

9 “Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀.

10 Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ.

11 Mo mú ọ̀gbẹlẹ̀ wá sórí ilẹ̀, ati sórí àwọn òkè, ati oko ọkà, ati ọgbà àjàrà ati ọgbà igi olifi. Bẹ́ẹ̀ náà ló kan gbogbo ohun tí ń hù lórí ilẹ̀, ati eniyan ati ẹran ọ̀sìn, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ eniyan.”

Àwọn Eniyan náà gbọ́ràn sí Àṣẹ OLUWA

12 Ni Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa, ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù bá gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun wọn lẹ́nu, wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wolii Hagai, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wọn ti rán an; wọ́n sì bẹ̀rù OLUWA.

13 Ni Hagai, òjíṣẹ́ OLUWA, bá jẹ́ iṣẹ́ tí OLUWA rán an sí àwọn eniyan náà pé òun OLUWA ní òun wà pẹlu wọn.

14 OLUWA bá fi ìtara rẹ̀ sí ọkàn Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí ọkàn Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wọn.

15 Ọjọ́ kẹrinlelogun, oṣù kẹfa, ọdún keji ìjọba Dariusi, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà.

Categories
HAGAI

HAGAI 2

Ẹwà Tẹmpili Tuntun náà

1 Ní ọjọ́ kọkanlelogun oṣù keje, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA tún sọ fún wolii Hagai, pé:

2 “Tún lọ sọ́dọ̀ Serubabeli ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù, kí o bèèrè pé,

3 ‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín?

4 Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.

5 Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí mo ṣe fun yín, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, mo wà láàrin yín; nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù.’

6 “Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀.

7 N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.

8 Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”

Wolii náà Lọ Bá Àwọn Alufaa jíròrò

10 Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA sọ fún wolii Hagai pé,

11 “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ní kí o lọ bèèrè ìdáhùn lórí ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa.

12 Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá mú ẹran tí a fi rúbọ, tí ó ti di mímọ́, tí ó dì í mọ́ ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀wù náà kan burẹdi, tabi àsáró, tabi waini, tabi òróró, tabi oúnjẹ-kóúnjẹ, ṣé ọ̀kan kan ninu àwọn oúnjẹ yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ di mímọ́?” Àwọn alufaa bá dáhùn pé, “Rárá.”

13 Nígbà náà ni Hagai tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá di aláìmọ́ nítorí pé ó farakan òkú, tí ó sì fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun tí a kà sílẹ̀ wọnyi ǹjẹ́ kò ní di aláìmọ́?” Wọ́n dáhùn pé: “Dájúdájú, yóo di aláìmọ́.”

14 Hagai bá dáhùn, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi ati fún orílẹ̀-èdè yìí pẹlu iṣẹ́ ọwọ́ wọn níwájú OLUWA; gbogbo ohun tí wọ́n fi ń rúbọ jẹ́ aláìmọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.

OLUWA Ṣe Ìlérí Ibukun

15 OLUWA ní, “Nisinsinyii, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀ láti àkókò yìí lọ. Ẹ ranti bí ó ti rí fun yín kí ẹ tó fi ìpìlẹ̀ tẹmpili yìí lélẹ̀.

16 Ninu oko tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí ogún òṣùnwọ̀n ọkà, mẹ́wàá péré ni ẹ rí; níbi tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí aadọta ìgò ọtí, ogún péré ni ẹ rí níbẹ̀.

17 Mo kọlù yín, mo sì mú kí atẹ́gùn gbígbóná ati yìnyín wó ohun ọ̀gbìn yín lulẹ̀, sibẹsibẹ ẹ kò ronupiwada, kí ẹ pada sọ́dọ̀ mi.

18 Lónìí ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ni ẹ fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀; láti òní lọ, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀.

19 Kò sí ọkà ninu abà mọ, igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ kò sì tíì so; bẹ́ẹ̀ ni igi pomegiranate, ati igi olifi. Ṣugbọn láti òní lọ, n óo bukun yín.”

Ìlérí OLUWA fún Serubabeli

20 Ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, OLUWA tún rán Hagai, pé kí ó

21 sọ fún Serubabeli, gomina ilẹ̀ Juda pé òun OLUWA ní, “N óo mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì.

22 N óo lé àwọn ìjọba kúrò ní ipò wọn; n óo sì ṣẹ́ àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè lápá. N óo ta kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n lókìtì. Ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n yóo ṣubú, wọn óo sì fi idà pa ara wọn.

23 Ní ọjọ́ náà, n óo fi ìwọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ṣe aṣojú ninu ìjọba mi nítorí pé mo ti yàn ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú

Ìwé Sakaraya

pín sí ọ̀nà meji (1) Orí 1-8 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wolii Sakaraya láàrin ẹẹdẹgbẹta ọdún ó lé ogún (520 B.C.) títí di ẹẹdẹgbẹta ọdún ó lé ọdún mejidinlogun, (518 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. Ní ojúran ni OLUWA ti rán wolii yìí níṣẹ́. Ó ríran nípa ìlú Jerusalẹmu, pé ìlú náà yóo pada bọ̀ sípò ati pé wọn yóo tún tẹmpili kọ́, Ọlọrun yóo ya àwọn eniyan rẹ̀ sí mímọ́ ati pé àkókò kan ń bọ̀ tí olùgbàlà yóo dé. (2) Orí 9-14 Àkójọpọ̀ ìran nípa bíbọ̀ olùdáǹdè ati ìdájọ́ ìkẹyìn.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

OLUWA ranṣẹ ìkìlọ̀, ó sì sọ nípa ìrètí ọjọ́ iwájú 1:1–8:23

Ìdájọ́ lórí àwọn ará agbègbè Israẹli 9:1-8

Ìtẹ̀síwájú ati alaafia ní ọjọ́ iwájú 9:9–14:21

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 1

OLUWA Pe Àwọn Eniyan Rẹ̀ Pada Sọ́dọ̀

1 Ní oṣù kẹjọ, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Sakaraya, ọmọ Berekaya, ọmọ Ido, sí àwọn ọmọ Israẹli; ó ní,

2 “Èmi OLUWA bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà,

3 èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní kí ẹ pada wá sọ́dọ̀ mi, èmi náà yóo sì pada sọ́dọ̀ yín.

4 Ẹ má ṣe bí àwọn baba ńlá yín, tí àwọn wolii mi rọ̀ títí pé kí wọ́n jáwọ́ ninu ìgbé-ayé burúkú, kí wọ́n jáwọ́ ninu iṣẹ́ ibi, ṣugbọn tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́.

5 Níbo ni àwọn baba ńlá yín ati àwọn wolii wà nisinsinyii? Ǹjẹ́ wọ́n wà mọ́?

6 Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi ati ìlànà mi tí àwọn wolii, iranṣẹ mi, sọ kò ṣẹ sí àwọn baba ńlá yín lára?” Àwọn eniyan náà bá ronupiwada, wọ́n ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ṣe wá bí ó ti pinnu láti ṣe, nítorí ìwà burúkú ati iṣẹ́ ibi wa.”

Ìran nípa Àwọn Ẹṣin

7 Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kọkanla tíí ṣe oṣù Ṣebati, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA fi ìran kan han wolii Sakaraya ọmọ Berekaya, ọmọ Ido.

8 Mo rí ìran kan lóru. Ninu ìran náà, mo rí ọkunrin kan lórí ẹṣin pupa, láàrin àwọn igi kan tí wọ́n ń pè ní mitili, láàrin àfonífojì kan. Àwọn ẹṣin pupa, ati ẹṣin rẹ́súrẹ́sú ati ẹṣin funfun dúró lẹ́yìn rẹ̀.

9 Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?”

Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.”

10 Ọkunrin tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni àwọn tí OLUWA rán láti máa rin ilẹ̀ ayé wò.”

11 Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.”

12 Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?”

13 OLUWA sì dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn pẹlu ọ̀rọ̀ ìtùnú.

14 Angẹli náà bá sọ fún mi pé kí n lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Mo ní ìfẹ́ ati ìtara tí ó jinlẹ̀ pupọ fún Jerusalẹmu ati Sioni.

15 Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni.

16 Nítorí náà, mo ti pada sí Jerusalẹmu láti ṣàánú fún un: a óo tún ilé mi kọ́ sibẹ, a óo sì tún ìlú Jerusalẹmu kọ́.”

17 Angẹli náà tún sọ fún mi pé, “Lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, àwọn ìlú òun yóo tún kún fún ọrọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, òun OLUWA yóo tu Sioni ninu, òun óo sì tún yan Jerusalẹmu ní àyànfẹ́ òun.”

Ìran nípa Àwọn ìwo

18 Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin,

19 mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀.

Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.”

20 Lẹ́yìn náà, OLUWA fi àwọn alágbẹ̀dẹ mẹrin kan hàn mí.

21 Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?”

Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.”