Categories
MIKA

MIKA 5

1 Nisinsinyii, a ti fi odi yi yín ká, ogun sì ti dótì wá; wọ́n fi ọ̀pá na olórí Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

Ọlọrun Ṣèlérí láti Yan Olórí ní Bẹtilẹhẹmu

2 OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”

3 Nítorí náà, OLUWA yóo kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ títí tí ẹni tí ń rọbí yóo fi bímọ; nígbà náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù yóo pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.

4 Yóo dìde, yóo sì mójútó àwọn eniyan rẹ̀ pẹlu agbára OLUWA, àní, ninu ọláńlá orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Wọn óo máa gbé ní àìléwu, nítorí yóo di ẹni ńlá jákèjádò gbogbo ayé.

5 Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia.

Ìdásílẹ̀ ati Ìjìyà

Nígbà tí àwọn ará Asiria bá wá gbógun tì wá, tí wọ́n bá sì wọ inú ilẹ̀ wa, a óo rán àwọn olórí wa ati àwọn akikanju láàrin wa láti bá wọn jà.

6 Idà ni wọn yóo fi máa ṣe àkóso ilẹ̀ Asiria ati ilẹ̀ Nimrodu; wọn yóo sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Asiria, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ilẹ̀ wa tí wọ́n sì gbógun tì wá.

7 Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ati bí ọ̀wààrà òjò lára koríko, tí kò ti ọwọ́ eniyan wá.

8 Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.

9 O óo lágbára ju àwọn ọ̀tá rẹ lọ, a óo sì pa wọ́n run.

10 Ní ọjọ́ náà, n óo pa àwọn ẹṣin yín run, n óo sì run gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun yín.

11 N óo pa àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ yín run, n óo sì wó ibi ààbò yín lulẹ̀.

12 N óo pa àwọn oṣó run ní ilẹ̀ yín, ẹ kò sì ní ní aláfọ̀ṣẹ kankan mọ́.

13 N óo run àwọn ère ati àwọn òpó oriṣa yín, ẹ kò sì ní máa bọ iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́.

14 N óo run àwọn ère oriṣa Aṣera láàrin yín, n óo sì run àwọn ìlú yín.

15 Ninu ibinu ati ìrúnú mi, n óo gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò pa àṣẹ mi mọ́.

Categories
MIKA

MIKA 6

Ọlọrun bá Israẹli Rojọ́

1 Ẹ gbọ́ ohun tí Ọlọrun sọ: Ẹ dìde, kí ẹ ro ẹjọ́ yín níwájú àwọn òkè ńlá, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohùn yín.

2 Ẹ̀yin òkè, ati ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayérayé, ẹ gbọ́ ẹjọ́ OLUWA, nítorí ó ń bá àwọn eniyan rẹ̀ rojọ́, yóo sì bá Israẹli jà.

3 Ọlọrun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, kí ni mo fi ṣe yín? Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi su yín? Ẹ dá mi lóhùn.

4 Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín.

5 Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”

Ohun Tí OLUWA Fẹ́ Kí Á Ṣe

6 Kí ni n óo mú wá fún OLUWA, tí n óo fi rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Ọlọrun, ẹni gíga? Ṣé kí n wá siwaju rẹ̀ pẹlu ẹbọ sísun ni tabi pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù ọlọ́dún kan?

7 Ǹjẹ́ inú OLUWA yóo dùn bí mo bá mú ẹgbẹẹgbẹrun aguntan wá, pẹlu ẹgbẹgbaarun-un garawa òróró olifi? Ṣé kí n fi àkọ́bí mi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ mi, àní kí n fi ọmọ tí mo bí rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi?

8 A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?

9 Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará, ati àpéjọ gbogbo ìlú; ohun tí ó ti dára ni pé kí eniyan bẹ̀rù OLUWA;

10 Ǹjẹ́ mo lè gbàgbé ìṣúra aiṣododo tí ó wà ninu ilé àwọn eniyan burúkú, ati òṣùnwọ̀n èké ó jẹ́ ohun ìfibú?

11 Báwo ni mo ṣe lè dáríjì àwọn tí ń lo òṣùnwọ̀n èké; tí àpò wọn sì kún fún ìwọ̀n tí kò péye?

12 Àwọn ọlọ́rọ̀ yín kún fún ìwà ipá; òpùrọ́ ni gbogbo àwọn ará ìlú, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì kún ẹnu wọn.

13 Nítorí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí pa yín run n óo sọ ìlú yín di ahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

14 Ẹ óo jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó, ebi yóo sì túbọ̀ máa pa yín, ẹ óo kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kò ní dúró lọ́wọ́ yín, ogun ni yóo sì kó ohun tí ẹ kó jọ lọ.

15 Ẹ óo fúnrúgbìn, ṣugbọn ẹ kò ní kórè rẹ̀; ẹ óo ṣe òróró olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí i fi para; ẹ óo ṣe ọtí waini, ṣugbọn ẹ kò ní rí i mu.

16 Nítorí pé ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà ọba Omiri, ati ti ìdílé ọba Ahabu, ẹ sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn; kí n lè sọ ìlú yín di ahoro, kí àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ sì di ohun ẹ̀gàn; kí àwọn eniyan sì máa fi yín ṣẹ̀sín.

Categories
MIKA

MIKA 7

Ìwà Ìbàjẹ́ Israẹli

1 Mo gbé! Nítorí pé, mo dàbí ìgbà tí wọn ti kórè èso àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tán, tí wọ́n ti ká èso àjàrà tán; tí kò sí èso àjàrà mọ́ fún jíjẹ, tí kò sì sí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́ tí mo fẹ́ràn mọ́.

2 Olóòótọ́ ti tán lórí ilẹ̀ ayé, kò sí olódodo mọ́ láàrin àwọn eniyan; gbogbo wọn ń wá ọ̀nà ìpànìyàn, olukuluku ń fi àwọ̀n dọdẹ arakunrin rẹ̀.

3 Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi í ṣe dáradára; àwọn ìjòyè ati àwọn onídàájọ́ wọn ń bèèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eniyan ńlá ń sọ èrò burúkú tí ó wà lọ́kàn wọn jáde; wọ́n sì ń pa ìmọ̀ wọn pọ̀.

4 Ẹni tí ó sàn jùlọ ninu wọn dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ láàrin wọn sì dàbí ẹ̀gún ọ̀gàn.

Ọjọ́ ìjìyà tí àwọn wolii wọn kéde ti dé; ìdàrúdàpọ̀ wọn sì ti kù sí dẹ̀dẹ̀.

5 Má gbára lé aládùúgbò rẹ, má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rẹ́; ṣọ́ra nípa ohun tí o óo máa bá iyawo rẹ sọ.

6 Nítorí ọmọkunrin ń tàbùkù baba rẹ̀, ọmọbinrin sì ń dìde sí ìyá rẹ̀, iyawo ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ará ilé ẹni sì ni ọ̀tá ẹni.

7 Ṣugbọn ní tèmi, n óo máa wo ojú OLUWA, n óo dúró de Ọlọrun ìgbàlà mi; Ọlọrun mi yóo sì gbọ́ tèmi.

OLUWA Mú Ìgbàlà Wá

8 Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi; bí mo bá ṣubú, n óo dìde; bí mo bá sì wà ninu òkùnkùn, OLUWA yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ mi.

9 N óo fara da ìyà tí OLUWA bá fi jẹ mí Nítorí pé mo ti ṣẹ̀ ẹ́, títí tí yóo fi gbèjà mi, tí yóo sì dá mi láre. Yóo mú mi wá sinu ìmọ́lẹ̀; ojú mi yóo sì rí ìdáǹdè rẹ̀.

10 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóo rí i, ojú yóo sì ti ẹni tí ń pẹ̀gàn mi pé, níbo ni OLUWA Ọlọrun mi wà? N óo fi ojú mi rí i; òun náà yóo wá di àtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìta gbangba.

11 Ní ọjọ́ tí a óo bá mọ odi ìlú yín, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ọjọ́ náà ni a óo sún ààlà yín siwaju.

12 Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan yóo wá sọ́dọ̀ yín láti ilẹ̀ Asiria títí dé ilẹ̀ Ijipti, láti ilẹ̀ Ijipti títí dé bèbè odò Yufurate, láti òkun dé òkun, ati láti òkè ńlá dé òkè ńlá.

13 Ṣugbọn ayé yóo di ahoro nítorí ìwàkiwà àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀; àní nítorí iṣẹ́kíṣẹ́ ọwọ́ wọn.

Àánú OLUWA Lórí Israẹli

14 OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.

15 N óo fi ohun ìyanu hàn wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

16 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí i, ojú agbára wọn yóo tì wọ́n; wọn óo pa ẹnu wọn mọ́; etí wọn óo sì di;

17 wọn óo fi ẹnu gbo ilẹ̀ bí ìgbín, pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì ni wọn yóo jáde bí ejò, láti ibi ààbò wọn; ninu ìbẹ̀rù, wọn óo pada tọ OLUWA Ọlọrun wá, ẹ̀rù rẹ yóo sì máa bà wọ́n.

18 Ta ló dàbí rẹ, Ọlọrun, tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan, tí ó sì ń fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan ìní rẹ̀ yòókù, ibinu rẹ kì í wà títí lae, nítorí pé a máa dùn mọ́ ọ láti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn.

19 O óo tún ṣàánú wa, o óo sì fẹsẹ̀ tẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa ní àtẹ̀parẹ́. O óo sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ìsàlẹ̀ òkun.

20 O óo fi òtítọ́ inú hàn sí Jakọbu, o óo sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún àwọn baba wa láti ìgbà àtijọ́.

Categories
NAHUMU

NAHUMU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Nahumu

jẹ́ àkọsílẹ̀ ewì ìdùnnú tí Wolii Nahumu fi sọ ìran tí ó rí nígbà tí ogun kó ìlú Ninefe, tí ó jẹ́ olú-ìlú ilẹ̀ Asiria, ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli. Ní nǹkan bíi ẹẹdẹgbẹrin ọdún kí á tó bí Oluwa wa (7th Century B.C.) ni ogun kó Ninefe tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Àwọn ọmọ Israẹli sì gbàgbọ́ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ninefe náà jẹ́ ìjẹníyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nítorí ìwà ìkà ati ìgbéraga Ninefe.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìdájọ́ lórí Ninefe 1:1-15

Ìṣubú Ninefe 2:1–3:19

Categories
NAHUMU

NAHUMU 1

1 Ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí; tí a kọ sinu ìwé ìran tí Nahumu ará Elikoṣi rí nípa ìlú Ninefe.

Ibinu OLUWA sí Ìlú Ninefe

2 OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun.

OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú.

OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,

a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀.

3 OLUWA kì í tètè bínú;

ó lágbára lọpọlọpọ,

kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre.

Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle,

awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.

4 Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ,

ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu;

koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ,

òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀.

5 Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀,

àwọn òkè kéékèèké sì yọ́.

Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀,

ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo.

6 Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró?

Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀?

Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná,

a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀.

7 OLUWA ṣeun,

òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú;

ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò.

8 Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀

ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀;

yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn.

9 Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA?

Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni;

kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan

tí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji.

10 Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí,

àní bíi koríko gbígbẹ.

11 Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú?

12 OLUWA wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Siria lágbára, tí wọ́n sì pọ̀, a óo pa wọ́n run, wọn yóo sì parẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ ẹ̀yin ọmọ Juda níyà tẹ́lẹ̀, n kò ní jẹ yín níyà mọ́.

13 N óo bọ́ àjàgà Asiria kúrò lọ́rùn yín, n óo sì já ìdè yín.”

14 OLUWA ti pàṣẹ nípa Asiria, pé: “A kò ní ranti orúkọ rẹ mọ́, ìwọ ilẹ̀ Asiria, n óo run àwọn ère tí ẹ̀yin ará Asiria gbẹ́, ati àwọn tí ẹ dà, tí wọ́n wà ní ilé oriṣa rẹ, n óo gbẹ́ ibojì rẹ, nítorí ẹlẹ́gbin ni ọ́.”

15 Wo ẹsẹ̀ ẹni tí ó ń mú ìyìn rere wá lórí àwọn òkè ńláńlá, ẹni tí ń kéde alaafia! Ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin ará Juda, kí ẹ sì san àwọn ẹ̀jẹ́ yín, nítorí ẹni ibi kò ní gbógun tì yín mọ́, a ti pa á run patapata.

Categories
NAHUMU

NAHUMU 2

Ìṣubú Ninefe

1 Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe.

Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò;

máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ,

kí o sì múra ogun.

2 (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada

bí ògo Israẹli,

nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn,

wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.)

3 Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀,

ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀

Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànà

bí ọwọ́ iná;

nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ,

àwọn ẹṣin wọn ń yan.

4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo,

wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede;

wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù,

wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.

5 Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ,

wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ,

wọ́n yára lọ sí ibi odi,

wọ́n sì fi asà dira ogun.

6 Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀,

ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin.

7 A tú ayaba sí ìhòòhò,

a sì mú un lọ sí ìgbèkùn,

àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀,

wọ́n káwọ́ lérí,

wọ́n ń rin bí oriri.

8 Ìlú Ninefe dàbí adágún odò

tí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ.

Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!”

Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada.

9 Ẹ kó fadaka,

ẹ kó wúrà!

Ìlú náà kún fún ìṣúra,

ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.

10 A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro!

Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú,

orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,

ìrora dé bá ọpọlọpọ,

gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

11 Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà?

Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun?

Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ,

tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà,

tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú?

12 Akọ kinniun a máa fa ẹran ya

fún àwọn ọmọ rẹ̀,

a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pa

fún àwọn abo rẹ̀;

a máa kó ẹran tí ó bá pa

ati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀.

13 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”

Categories
NAHUMU

NAHUMU 3

1 Ìlú tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé!

Ìlú tí ó kún fún irọ́ ati ìkógun,

tí àwọn adigunjalè kò fi ìgbà kan dáwọ́ dúró níbẹ̀!

2 Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan,

kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo!

3 Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà

pẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà.

Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀,

òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti;

òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye,

àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkú

bí wọn tí ń lọ!

4 Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe,

tí wọ́n fanimọ́ra,

ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró,

ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a;

nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ,

ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan.

5 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:

“Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe,

n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú;

n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹ

ojú yóo sì tì ọ́.

6 N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́;

n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò.

7 Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máa

wí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀?

Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ”

8 Ṣé ìwọ Ninefe sàn ju ìlú Tebesi lọ, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Naili, tí omi yíká, tí ó fi òkun ṣe ààbò, tí ó sì fi omi ṣe odi rẹ̀?

9 Etiopia ati Ijipti ni agbára rẹ̀ tí kò lópin; Puti ati Libia sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.

10 Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn.

11 Ninefe, ìwọ pàápàá yóo mu ọtí yó, o óo máa ta gbọ̀n- ọ́ngbọ̀n-ọ́n; o óo sì máa wá ààbò nítorí àwọn ọ̀tá rẹ.

12 Gbogbo ibi ààbò rẹ yóo dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí àkọ́so èso rẹ̀ pọ́n bí wọn bá ti gbọ̀n ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èso rẹ̀ yóo máa jábọ́ sí ẹnu ẹni tí yóo jẹ ẹ́.

13 Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dàbí obinrin! Gbogbo ẹnubodè rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná sì ti jó gbogbo ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ.

14 Ẹ pọn omi sílẹ̀ de àkókò tí ogun yóo dótì yín, ẹ ṣe ibi ààbò yín kí ó lágbára; ẹ lọ sí ibi ilẹ̀ alámọ̀, ẹ gún amọ̀, kí ẹ fi ṣe bíríkì!

15 Ibẹ̀ ni iná yóo ti jó yín run, idà yóo pa yín lọ bí eṣú. Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ pọ̀ bí eṣú!

16 O ti wá kún àwọn oníṣòwò rẹ, wọ́n sì pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ! Ṣugbọn wọ́n ti na ìyẹ́ wọn bí eṣú, wọ́n sì fò lọ.

17 Àwọn olórí yín dàbí tata, àwọn akọ̀wé yín sì dàbí ọ̀wọ́ eṣú, tíí bà sórí odi nígbà òtútù, nígbà tí oòrùn bá yọ wọn a fò lọ; kò sì ní sí ẹni tí yóo mọ ibi tí wọ́n lọ.

18 Àwọn olùṣọ́ rẹ ń sùn, ìwọ ọba Asiria, àwọn ọlọ́lá rẹ sì ń tòògbé; Àwọn eniyan rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè, láìsí ẹni tí yóo gbá wọn jọ.

19 Kò sí ẹni tí yóo wo ọgbẹ́ rẹ sàn nítorí egbò rẹ pọ̀. Àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn rẹ yóo pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí kò sí ẹni tí kò tíì faragbá ninu ìwà burúkú rẹ.

Categories
HABAKUKU

HABAKUKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó lé díẹ̀ kí á tó bí OLUWA wa, (7th Century B.C.), ni wolii Habakuku sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, orílẹ̀-èdè Babilonia ni aláṣẹ lórí gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù ní gbogbo àkókò yìí. Ìwà ipá tí àwọn aláṣẹ ìgbà náà ń hù sí àwọn ọmọ Israẹli ní pataki jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wolii Habakuku. Ó wá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ìdí tí OLUWA fi dákẹ́ tí àwọn aláṣẹ wọnyi sì ń pa àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ. (1:13) Èsì tí OLUWA fún un ni pé, àkókò tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun yóo gbé ìgbésẹ̀ tí ó bá yẹ, ṣugbọn sibẹ, “àwọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” (2:4)

Ìyókù orí keji ìwé yìí ń sọ nípa ìparun tí yóo dé bá àwọn alaiṣododo. Orin ni Habakuku fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Orin ọ̀hún sọ nípa títóbi Ọlọrun, ó sì fi ẹ̀mí igbagbọ tí kì í ṣákì, tí ẹni tí ó kọ ọ́ ní hàn.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àwọn ẹ̀sùn Habakuku ati àwọn èsì tí OLUWA fún un 1:1–2:4

Ìparun tí yóo bá àwọn alaigbagbọ 2:5-20

Adura Habakuku 3:1-19

Categories
HABAKUKU

HABAKUKU 1

1 Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí.

Ìráhùn Habakuku sí Ọlọrun

2 OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀?

3 Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo.

4 Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po.

Ìdáhùn Ọlọrun

5 Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ.

6 Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri.

7 Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n.

8 “Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ, wọ́n burú ju ìkookò tí ebi ń pa ní àṣáálẹ́ lọ. Pẹlu ìgbéraga ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn máa ń gun ẹṣin wọn lọ. Dájúdájú, ọ̀nà jíjìn ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ti ń wá; wọn a fò, bí idì tí ń sáré sí oúnjẹ.

9 “Tìjàtìjà ni gbogbo wọn máa ń rìn, ìpayà á bá gbogbo eniyan bí wọ́n bá ti ń súnmọ́ tòsí. Wọn a kó eniyan ní ìgbèkùn, bí ẹni kó yanrìn nílẹ̀.

10 Wọn a máa fi àwọn ọba ṣe ẹlẹ́yà, wọn a sì sọ àwọn ìjòyè di àmúṣèranwò. Wọn a máa fi àwọn ìlú olódi ṣe ẹlẹ́yà, nítorí òkítì ni wọ́n mọ sí ara odi wọn, wọn a sì gbà wọ́n.

11 Wọn a fẹ́ wá bí ìjì, wọn a sì tún fẹ́ lọ, àwọn olubi eniyan, tí agbára wọn jẹ́ ọlọrun wọn.”

Habakuku tún Ráhùn sí OLUWA

12 OLUWA, ṣebí láti ayérayé ni o ti wà? Ọlọrun mi, Ẹni Mímọ́ mi, a kò ní kú. OLUWA, ìwọ ni o yan àwọn ará Babiloni gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Ìwọ Àpáta, ni o gbé wọn kalẹ̀ bíi pàṣán, láti jẹ wá níyà.

13 Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ.

14 Nítorí o ti jẹ́ kí ọmọ eniyan dàbí ẹja inú òkun, ati bí àwọn kòkòrò tí wọn ń rìn nílẹ̀, tí wọn kò ní olórí.

15 Ọ̀tá fi ìwọ̀ fa gbogbo wọn sókè, ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn jáde. Ó kó wọn papọ̀ sinu àwọ̀n rẹ̀, Nítorí náà ó ń yọ̀, inú rẹ̀ sì dùn.

16 Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ.

17 Ṣé gbogbo ìgbà ni àwọn eniyan yóo máa bọ́ sinu àwọ̀n rẹ̀ ni? Ṣé títí lae ni yóo sì máa pa àwọn orílẹ̀-èdè run láìláàánú?

Categories
HABAKUKU

HABAKUKU 2

Ìdáhùn OLUWA sí Habakuku

1 N óo dúró sí ibìkan lórí ilé-ìṣọ́, n óo máa wòran. N óo dúró, n óo máa retí ohun tí yóo sọ fún mi, ati irú èsì tí èmi náà óo fún un.

2 OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á.

3 Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni; ọjọ́ náà kò ní pẹ́ dé, ohun tí o rí kì í ṣe irọ́, dájúdájú yóo ṣẹ. Bí ó bá dàbí ẹni pé ó ń pẹ́, ìwọ ṣá dúró kí o máa retí rẹ̀, dájúdájú, yóo ṣẹ, láìpẹ́.

4 Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”

Ìjìyà Àwọn Alaiṣododo

5 Ọrọ̀ a máa tan eniyan jẹ; onigbeeraga kò sì ní wà láàyè pẹ́. Ojúkòkòrò rẹ̀ dàbí isà òkú; nǹkan kì í sì í tó o, àfi bí ikú. Ó gbá gbogbo orílẹ̀-èdè jọ fún ara rẹ̀, ó sì sọ gbogbo eniyan di ti ara rẹ̀.

6 Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?”

7 Ǹjẹ́ àwọn onígbèsè rẹ kò ní dìde sí ọ lójijì, kí àwọn tí wọn yóo dẹ́rùbà ọ́ sì jí dìde, kí o wá di ìkógun fún wọn?

8 Nítorí pé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni o ti kó lẹ́rú, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọn yóo sì kó ìwọ náà lẹ́rú, nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan tí o ti pa, ati ìwà ipá tí o hù lórí ilẹ̀ ayé, ati èyí tí o hù sí oríṣìíríṣìí ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.

9 Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ipá kó èrè burúkú jọ tí ẹ óo fi kọ́ ibùgbé sí ibi gíga, kí nǹkan burúkú kankan má baà ṣẹlẹ̀ si yín!

10 O ti kó ìtìjú bá ilé rẹ nítorí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè tí o parun; ìwọ náà ti wá pàdánù ẹ̀mí rẹ.

11 Nítorí òkúta yóo kígbe lára ògiri, igi ìdábùú òpó ilé yóo sì fọhùn pẹlu.

12 Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìwà ìpànìyàn kó ìlú jọ, tí ẹ fi ìwà ọ̀daràn tẹ ìlú dó.

13 Wò ó, ṣebí ìkáwọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó wà, pé kí orílẹ̀-èdè kan ṣe làálàá tán, kí iná sì jó gbogbo rẹ̀ ní àjórun, kí wahala orílẹ̀-èdè náà sì já sí asán.

14 Nítorí ayé yóo kún fún ìmọ̀ ògo OLUWA, gẹ́gẹ́ bí omi ti kún inú òkun.

15 Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ fi ibinu fún aládùúgbò yín ní ọtí mu, tí ẹ jẹ́ kí inú wọn ru, kí ẹ lè rí ìhòòhò wọn.

16 Ìtìjú ni yóo bò yín dípò ògo. Ẹ máa mu àmupara kí ẹ sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, ife ìjẹníyà tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún OLUWA yóo kàn yín, ìtìjú yóo sì bo ògo yín.

17 Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.

18 Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀!

19 Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá.

20 Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀.