Categories
JONA

JONA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Jona

yàtọ̀ sí àwọn ìwé wolii yòókù. Ìwé yìí sọ ìtàn ohun tí ojú wolii kan, tí ń sá fún àṣẹ Ọlọrun rí. Ọlọrun rán an lọ sí ìlú Ninefe, olú-ìlú ilẹ̀ Asiria, tí àwọn ará ibẹ̀ jẹ́ ọ̀tá aṣekúpani fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn lọ́kàn Jona ó gbàgbọ́ pé Ọlọrun kò ní pa ìlú náà run bí ó ti ń lérí. Nítorí náà, Jona kò fẹ́ lọ sí Ninefe. Lẹ́yìn ọpọlọpọ nǹkan tí ojú rẹ̀ rí, ó lọ jíṣẹ́ tí Ọlọrun rán an. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kò ṣẹ, ó takété sí àwọn eniyan yòókù.

Ìwé yìí fi ìfẹ́ Ọlọrun sí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ hàn ketekete. Ní pataki jùlọ, ó fi Ọlọrun hàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ati pé ó tẹ́ ẹ lọ́rùn kí ó dáríjì ọ̀tá àwọn eniyan rẹ̀ kí ó sì gbà wọ́n là, ju pé kí ó fìyà jẹ wọ́n, kí ó sì pa wọ́n run lọ.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìpè Jona ati bí ó ti kọ̀ láti jẹ́ ìpè náà 1:1-17

Jona ronupiwada ó sì rí ìgbàlà 2:1-10

Iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun fún àwọn ará Ninefe 3:1-10

Àánú Ọlọrun lórí Ninefe 4:1-11

Categories
JONA

JONA 1

Jona Ṣe Àìgbọràn sí OLUWA

1 OLUWA bá Jona ọmọ Amitai sọ̀rọ̀, ó ní,

2 “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kéde, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé mo rí gbogbo ìwà burúkú wọn!”

3 Ṣugbọn Jona gbéra ó fẹ́ sálọ sí Taṣiṣi, kí ó lè kúrò níwájú OLUWA. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jọpa, ó sì rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń lọ sí Taṣiṣi níbẹ̀. Ó san owó ọkọ̀, ó bá bọ́ sinu ọkọ̀, ó fẹ́ máa bá a lọ sí Taṣiṣi kí ó sì sá kúrò níwájú OLUWA.

4 Ṣugbọn OLUWA gbé ìjì kan dìde lójú omi òkun, afẹ́fẹ́ náà le tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ ojú omi fẹ́rẹ̀ ya.

5 Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn.

6 Olórí àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí ò ń sùn, olóorun? Dìde, ké pe ọlọrun rẹ, bóyá a jẹ́ ṣàánú wa, kí á má baà ṣègbé.”

7 Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona.

8 Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nítorí ta ni nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni o ti wá? Níbo ni orílẹ̀-èdè rẹ? Inú ẹ̀yà wo ni o sì ti wá?”

9 Ó bá dá wọn lóhùn pé: “Heberu ni mí, ẹ̀rù OLUWA ni ó bà mí, àní Ọlọrun ọ̀run, tí ó dá òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ.”

10 Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gidigidi, wọ́n sọ fún un pé, “Kí ni o dánwò yìí?” Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jona ń sá kúrò níwájú OLUWA ni, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn.

11 Wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni kí á ṣe sí ọ, kí ìjì omi òkun lè dáwọ́ dúró? Nítorí ìjì náà sá túbọ̀ ń le sí i ni.”

12 Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi jù sinu òkun, ìjì náà yóo sì dáwọ́ dúró, nítorí mo mọ̀ pé nítorí mi ni òkun fi ń ru.”

13 Sibẹsibẹ, àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ náà gbìyànjú láti tu ọkọ̀ wọn pada sórí ilẹ̀, ṣugbọn kò ṣeéṣe, nítorí pé, afẹ́fẹ́ líle dojú kọ wọ́n, ìjì náà sì ń pọ̀ sí i.

14 Wọ́n bá gbadura sí OLUWA, wọ́n ní, “A bẹ̀ ọ́, OLUWA, má jẹ́ kí á ṣègbé nítorí ti ọkunrin yìí, má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn; nítorí bí o ti fẹ́ ni ò ń ṣe.”

15 Wọ́n bá gbé Jona jù sinu òkun, òkun sì dákẹ́rọ́rọ́.

16 Ẹ̀rù OLUWA ba àwọn tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ lọpọlọpọ, wọ́n rúbọ, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA.

17 OLUWA bá pèsè ẹja ńlá kan tí ó gbé Jona mì. Jona sì wà ninu ẹja náà fún ọjọ́ mẹta.

Categories
JONA

JONA 2

Adura Jona

1 Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà,

2 ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA,

ó sì dá mi lóhùn,

mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi.

3 Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun,

omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀;

ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi.

4 Nígbà náà ni mo sọ pé,

‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ;

báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’

5 Omi bò mí mọ́lẹ̀,

ibú omi yí mi ká,

koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí.

6 Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun,

àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí.

Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi,

o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.

7 Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ,

mo gbadura sí ìwọ OLUWA,

o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ.

8 Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀,

wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́.

9 Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́,

n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi.

Ti OLUWA ni ìgbàlà!”

10 OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Categories
JONA

JONA 3

Jona Gbọ́ràn sí OLUWA Lẹ́nu

1 OLUWA tún bá Jona sọ̀rọ̀ nígbà keji, ó ní:

2 “Dìde, lọ sí Ninefe, ìlú ńlá nì, kí o sì kéde iṣẹ́ tí mo rán ọ fún gbogbo eniyan ibẹ̀.”

3 Jona bá dìde, ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. Ninefe jẹ́ ìlú tí ó tóbi, ó gbà tó ìrìn ọjọ́ mẹta láti la ìlú náà já.

4 Jona rin ìlú náà fún odidi ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Níwọ̀n ogoji ọjọ́ sí i, Ninefe óo parun.”

5 Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

6 Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọba Ninefe ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù oyè sílẹ̀, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì jókòó ninu eérú.

7 Ó bá ní kí wọn kéde fún àwọn ará Ninefe, pé, “Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ pàṣẹ pé, eniyan tabi ẹranko, tabi ẹran ọ̀sìn kankan kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ, wọn kò sì gbọdọ̀ mu.

8 Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì.

9 A kì í mọ̀, bóyá Ọlọrun lè yí ọkàn rẹ̀ pada, kí ó má jẹ wá níyà mọ́. Bóyá yóo tilẹ̀ dá ibinu rẹ̀ dúró, kò sì ní pa wá run.”

10 Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti pa ìwà burúkú wọn tì, Ọlọrun náà bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, kò sì jẹ wọ́n níyà mọ́.

Categories
JONA

JONA 4

Ibinu Jona ati Àánú Ọlọrun

1 Ṣugbọn bí Ọlọrun ti ṣe yìí kò dùn mọ́ Jona ninu rárá, inú bí i.

2 Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada.

3 Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi, nítorí pé, ó sàn fún mi láti kú ju pé kí n wà láàyè lọ.”

4 OLUWA bá dá Jona lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí o bínú?”

5 Jona bá jáde kúrò láàrin ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí ìhà ìlà oòrùn ìlú náà. Ó pa àtíbàbà kan sibẹ, ó jókòó ní ìbòòji lábẹ́ rẹ̀, ó ń retí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.

6 OLUWA bá rán ìtàkùn kan, ó fà á bo ibẹ̀, o sì ṣíji bo orí ibi tí Jona wà kí ó lè fún un ní ìtura ninu ìnira rẹ̀. Inú Jona dùn gidigidi nítorí ìtàkùn yìí.

7 Ṣugbọn Ọlọrun rán kòkòrò kan ní àárọ̀ ọjọ́ keji, ó jẹ ìtàkùn náà, ó sì rọ.

8 Nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn fẹ́, oòrùn sì pa Jona tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́rẹ̀ dákú. Ó sọ fún Ọlọrun pé kí ó gba ẹ̀mí òun. Ó ní, “Ó sàn kí n kú ju pé kí n wà láàyè lọ.”

9 Ọlọrun bá bi Jona pé, “Ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú nítorí ìtàkùn yìí?” Jona dáhùn, ó ní: “Ó tọ́ kí n bínú títí dé ojú ikú.”

10 Nígbà náà ni OLUWA dá a lóhùn pé, “ìwọ ń káàánú ìtàkùn lásánlàsàn, tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í sìí ṣe ìwọ ni o mú un dàgbà, àní ìtàkùn tí ó hù ní òru ọjọ́ kan, tí ó sì gbẹ ní ọjọ́ keji.

11 Ṣé kò yẹ kí èmi foríji Ninefe, ìlú ńlá nì, tí àwọn ọmọde inú rẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) lọ, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn tí ó wà ninu ìlú náà?”

Categories
MIKA

MIKA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ní àkókò wolii Aisaya ni Mika, ará ìlú kan ní ilẹ̀ Juda, jẹ́ wolii. Ó dá a lójú pé, àsọtẹ́lẹ̀ Amosi nípa ìyà tí yóo dé bá Israẹli kò ní ṣaláì ṣẹlẹ̀ sí Juda náà, fún ìdí kan náà–Ọlọrun yóo fìyà jẹ àwọn náà nítorí ìríra ìwà ìdájọ́ èké wọn. Ṣugbọn Mika ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ati àwọn àpẹẹrẹ fún ìrètí lọ́jọ́ iwájú.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí ó yẹ kí eniyan kíyèsí ni alaafia tí ó wà fún eniyan nípa sísúnmọ́ Ọlọrun (4:1-4); àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọba pataki kan tí wọn yóo bí láti inú ìran Dafidi, tí yóo sì mú alaafia wá sí orílẹ̀-èdè náà (5:2-5a); ní orí 6:8, Mika ṣe àlàyé ní ṣókí lórí ohun tí ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn wolii Israẹli dá lé lórí pé: “Ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí á ṣe nìyí: kí á ṣe ohun tí ó tọ́, kí á fi ìfẹ́ tí ó dúró ṣinṣin hàn, kí á sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun wa.”

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìdájọ́ lórí Israẹli ati Juda 1:1–3:12

Ìyípadà sí rere ati alaafia 4:1–5:15

Ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ ati ìrètí 6:1–7:20

Categories
MIKA

MIKA 1

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Mika, ará Moreṣeti nípa Jerusalẹmu ati Samaria nìyí, ní àkókò ìjọba Jotamu, ati ti Ahasi ati ti Hesekaya, àwọn ọba Juda.

Ìpohùnréré Ẹkún nítorí Samaria ati Jerusalẹmu

2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.

Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín,

àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́.

3 Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀,

yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé.

4 Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná;

àwọn àfonífojì yóo pínyà

gẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.

5 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni.

6 OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta.

7 Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè.

8 “Nítorí èyí, n óo sọkún, n óo sì pohùnréré ẹkún; n óo rìn káàkiri ní ìhòòhò láìwọ bàtà. N óo máa ké kiri bí ọ̀fàfà, n óo sì ṣọ̀fọ̀ bí ẹyẹ ògòǹgò.

9 Nítorí pé egbò Samaria kò lè ṣe é wò jinná; egbò náà sì ti ran Juda, ó ti dé ẹnubodè àwọn eniyan mi, àní, Jerusalẹmu.”

Ọ̀tá Súnmọ́ Jerusalẹmu

10 Ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ìṣubú wa ní ìlú Gati, ẹ má sọkún rárá; ẹ̀yin ará ìlú Beti Leafira, ẹ máa gbé ara yílẹ̀.

11 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn.

12 Àwọn ará Marotu ń retí ire pẹlu gbogbo ọkàn wọn, nítorí pé ibi ti dé sí bodè Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ OLUWA.

13 Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀.

14 Nítorí náà, ẹ óo fún àwọn ará Moreṣeti Gati ní ẹ̀bùn ìdágbére; ilé Akisibu yóo sì jẹ́ ohun ìtànjẹ fún àwọn ọba Israẹli.

15 Ẹ̀yin ará Mareṣa, n óo tún jẹ́ kí àwọn ọ̀tá borí yín; ògo Israẹli yóo sì lọ sí ọ̀dọ̀ Adulamu.

16 Ẹ̀yin ará Juda, ẹ fá irun orí yín láti ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ yín tí ẹ fẹ́ràn; kí orí yín pá bí orí igún, nítorí a óo kó àwọn ọmọ yín ní ìgbèkùn kúrò lọ́dọ̀ yín.

Categories
MIKA

MIKA 2

Ìjìyà fún Àwọn Tí Wọn ń Ni Àwọn Talaka Lára

1 Ègbé ni fún àwọn tí wọn ń gbìmọ̀ ìkà, tí wọ́n sì ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn. Nígbà tí ilẹ̀ bá sì mọ́, wọn á ṣe ibi tí wọn ń gbèrò. Nítorí pé ó wà ní ìkáwọ́ wọn láti ṣe é.

2 Bí ilẹ̀ kan bá wọ̀ wọ́n lójú, wọn á gbà á lọ́wọ́ onílẹ̀; bí ilé kan ló bá sì wù wọ́n, wọn á fi ipá gbà á lọ́wọ́ onílé; wọ́n ń fìyà jẹ eniyan ati ilé rẹ̀, àní eniyan ati ohun ìní rẹ̀.

3 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí; ó ní, “Wò ó, mò ń gbèrò ibi kan sí ìdílé yìí; tí ẹ kò ní lè bọ́rí ninu rẹ̀; ẹ kò ní rìn pẹlu ìgbéraga, nítorí pé àkókò burúkú ni yóo jẹ́.

4 Ní ọjọ́ náà, wọn yóo máa fi yín kọrin ẹlẹ́yà, wọn yóo sì sọkún le yín lórí tẹ̀dùntẹ̀dùn. Wọn yóo wí pé, ‘A ti parun patapata; ó ti pa ìpín àwọn eniyan mi dà; ẹ wò bí ó ti yí i kúrò lọ́dọ̀ mi, ó pín ilẹ̀ wa fún àwọn tí wọ́n ṣẹgun wa.’ ”

5 Nítorí náà kò ní sí ìpín fún ẹnikẹ́ni ninu yín mọ́ nígbà tí a bá dá ilẹ̀ náà pada fún àwọn eniyan Ọlọrun.

6 Àwọn eniyan náà ń pàrọwà fún mi pé, “Má waasu fún wa. Kò yẹ kí eniyan máa waasu nípa irú nǹkan báwọ̀nyí, Ọlọrun kò ní dójútì wá.

7 Ṣé irú ọ̀rọ̀ tí eniyan máa sọ nìyí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu? Ṣé OLUWA kò ní mú sùúrù mọ́ ni? Àbí ẹ rò pé òun ni ó ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi? Àbí ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn tí wọ́n bá ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́ ní rere?”

8 OLUWA ní: “Ṣugbọn ẹ dìde sí àwọn eniyan mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, ẹ gba ẹ̀wù lọ́rùn àwọn tí wọn ń lọ lalaafia, àwọn tí wọn ń rékọjá lọ láìronú ogun.

9 Ẹ lé àwọn aya àwọn eniyan mi jáde kúrò ninu ilé tí wọ́n fẹ́ràn; ẹ sì gba ògo mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn títí lae.

10 Ẹ dìde, ẹ máa lọ, nítorí pé ìhín yìí kì í ṣe ibi ìsinmi; nítorí pé ẹ ti hùwà ìríra tí ń mú ìparun ńlá báni.

11 “Wolii tí yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ati ẹ̀tàn ni àwọn eniyan wọnyi ń fẹ́, tí yóo sì máa waasu pé, ‘Ẹ óo ní ọpọlọpọ waini ati ọtí líle.’

12 “Dájúdájú, n óo kó gbogbo yín jọ, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, n óo kó àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ: n óo kó wọn pọ̀ bí aguntan, sinu agbo, àní bí agbo ẹran ninu pápá, ariwo yóo sì pọ̀ ninu agbo náà, nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.”

13 Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn.

Categories
MIKA

MIKA 3

Mika Bá Àwọn Olórí Israẹli Wí

1 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli! Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ̀ nípa ìdájọ́ òtítọ́?

2 Ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ohun rere, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi, ẹ̀yin tí ẹ bó awọ lára àwọn eniyan mi, tí ẹ sì ya ẹran ara egungun wọn;

3 ẹ̀yin ni ẹ jẹ ẹran ara àwọn eniyan mi, ẹ bó awọ kúrò lára wọn, ẹ sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́, ẹ gé wọn lékìrí lékìrí bí ẹran inú ìsaasùn, àní, bí ẹran inú ìkòkò.

4 Nígbà tí ó bá yá, wọn yóo ké pe OLUWA, ṣugbọn kò ní dá wọn lóhùn; yóo fi ojú pamọ́ fún wọn, nítorí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe.

5 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn wolii tí wọn ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà, tí wọn ń kéde “Alaafia” níbi tí wọ́n bá ti ń rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn tí wọn ń kéde ogun níbi tí kò bá ti sí oúnjẹ.

6 Nítorí náà, alẹ́ yín yóo lẹ́ ṣugbọn àwọn aríran yín kò ní rí nǹkankan, òkùnkùn yóo kùn, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín kò ní rí iṣẹ́ wò. Ògo àwọn wolii yóo wọmi, òkùnkùn yóo sì bò wọ́n.

7 A óo dójúti àwọn aríran, ojú yóo sì ti àwọn woṣẹ́woṣẹ́; gbogbo wọn yóo fi ọwọ́ bo ẹnu wọn, nítorí pé, Ọlọrun kò ní dá wọn lóhùn.

8 Ṣugbọn ní tèmi, mo kún fún agbára, ati ẹ̀mí OLUWA, ati fún ìdájọ́ òdodo ati ipá, láti kéde ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli fún wọn.

9 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń gbé ẹ̀bi fún aláre.

10 Ẹ̀yin tí ẹ fi owó ẹ̀jẹ̀ kọ́ Sioni, tí ẹ sì fi èrè ìwà burúkú kọ́ Jerusalẹmu.

11 Àwọn aláṣẹ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́, àwọn alufaa ń gba owó iṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kọ́ni, àwọn wolii ń gba owó kí wọ́n tó ríran; sibẹsibẹ, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, wọ́n ń wí pé, “Ṣebí OLUWA wà pẹlu wa? Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.”

12 Nítorí náà, nítorí yín, a óo ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóo di àlàpà, ahoro tẹmpili yóo sì di igbó kìjikìji.

Categories
MIKA

MIKA 4

Ìjọba Alaafia OLUWA Tí Ó Kárí Ayé

1 Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀

bí òkè tí ó ga jùlọ,

a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ,

àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ.

2 Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé,

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA,

ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,

kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,

kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.”

Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde,

ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.

3 Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,

ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré;

wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,

wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé;

àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,

wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.

4 Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀,

ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n;

nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

5 Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae.

Israẹli Yóo Pada láti Oko Ẹrú

6 OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú.

7 N óo dá àwọn arọ sí, kí wọ́n lè wà lára àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n ṣẹ́kù, àwọn tí a túká yóo sì di orílẹ̀-èdè ńlá; OLUWA yóo sì jọba lórí wọn ní òkè Sioni láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.”

8 Jerusalẹmu, ìwọ ilé ìṣọ́ agbo aguntan Sioni, ilé ọba rẹ àtijọ́ yóo pada sọ́dọ̀ rẹ, a óo dá ìjọba pada sí Jerusalẹmu.

9 Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí?

10 Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

11 Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè dojú ìjà kọ yín nisinsinyii, wọ́n sì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sọ Sioni di aláìmọ́, kí á sì dójúlé e.”

12 Ṣugbọn àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò mọ èrò OLUWA, ìpinnu rẹ̀ kò sì yé wọn, pé ó ti kó wọn jọ láti pa wọ́n bí ẹni pa ọkà ní ibi ìpakà.

13 Ẹ dìde kí ẹ tẹ àwọn ọ̀tá yín mọ́lẹ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Nítorí n óo mú kí ìwo rẹ lágbára bí irin, pátákò ẹsẹ̀ rẹ yóo sì dàbí idẹ; o óo fọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè túútúú, o óo sì ya ọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún OLUWA, nǹkan ìní wọn yóo jẹ́ ti OLUWA àgbáyé.