Categories
HOSIA

HOSIA 11

Ìfẹ́ Ọlọrun sí Àwọn Eniyan Rẹ̀, Ọlọ̀tẹ̀

1 OLUWA ní,

“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọde, mo fẹ́ràn rẹ̀,

láti ilẹ̀ Ijipti ni mo sì ti pe ọmọ mi jáde.

2 Ṣugbọn bí mo ti ń pè wọ́n tó,

bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń sá fún mi,

wọ́n ń rúbọ sí àwọn oriṣa Baali,

wọ́n ń sun turari sí ère.

3 Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn,

mo gbé wọn lé ọwọ́ mi,

ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn.

4 Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́,

mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn,

mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn.

5 “Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.

6 A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn.

7 Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ.

8 “Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu?

Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli?

Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run;

kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu?

Ọkàn mi kò gbà á,

àánú yín a máa ṣe mí.

9 N kò ní fa ibinu yọ mọ́,

n kò ní pa Efuraimu run mọ́,

nítorí pé Ọlọrun ni mí,

n kì í ṣe eniyan,

èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín,

n kò sì ní pa yín run.

10 “Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn;

11 wọn yóo fi ìbẹ̀rùbojo fò wá bí ẹyẹ láti ilẹ̀ Ijipti, ati bí ẹyẹ àdàbà láti ilẹ̀ Asiria; n óo sì dá wọn pada sí ilé wọn. Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Ìdájọ́ lórí Juda ati Israẹli

12 OLUWA ní, “Àwọn ọmọ Efuraimu parọ́ fún mi, ilẹ̀ Israẹli kún fún ẹ̀tàn, sibẹsibẹ mo mọ ilé Juda, nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí èmi, Ẹni Mímọ́.

Categories
HOSIA

HOSIA 12

1 “Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.”

2 OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn.

3 Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì.

4 Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀.

5 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀:

6 Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo.

Àwọn Ìdájọ́ Mìíràn

7 OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára.

8 Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’

9 Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ láti ilẹ̀ Ijipti; n óo tún mú ọ pada gbé inú àgọ́, bí àwọn ọjọ́ àjọ ìyàsọ́tọ̀.

10 “Mo bá àwọn wolii sọ̀rọ̀; èmi ni mo fi ọpọlọpọ ìran hàn wọ́n, tí mo sì tipasẹ̀ wọn pa ọpọlọpọ òwe.

11 Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.”

12 Jakọbu sálọ sí ilẹ̀ Aramu, níbẹ̀ ni ó ti singbà, tí ó ṣiṣẹ́ darandaran, nítorí iyawo tí ó fẹ́.

13 Nípasẹ̀ wolii kan ni OLUWA ti mú Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, nípasẹ̀ wolii kan ni a sì ti pa á mọ́.

14 Efuraimu ti mú èmi, OLUWA rẹ̀ bínú lọpọlọpọ, nítorí náà, n óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lé e lórí, òun tí ó gàn mí ni yóo di ẹni ẹ̀gàn.

Categories
HOSIA

HOSIA 13

Paríparí Ìdájọ́ Israẹli

1 Tẹ́lẹ̀ rí, bí ẹ̀yà Efuraimu bá sọ̀rọ̀, àwọn eniyan a máa wárìrì; wọ́n níyì láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, ṣugbọn nítorí pé wọ́n bọ oriṣa Baali, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú.

2 Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu!

3 Nítorí náà, wọn óo dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí máa ń yára gbẹ, wọ́n óo dàbí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kúrò ní ibi ìpakà, ati bí èéfín tí ń jáde láti ojú fèrèsé.

4 OLUWA ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, láti ìgbà tí ẹ ti wà ní ilẹ̀ Ijipti: ẹ kò ní Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ní olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi.

5 Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ;

6 ṣugbọn nígbà tí ẹ jẹun yó tán, ẹ̀ ń gbéraga, ẹ gbàgbé mi.

7 Nítorí náà, bíi kinniun ni n óo ṣe si yín, n óo lúgọ lẹ́bàá ọ̀nà bí àmọ̀tẹ́kùn;

8 n óo yọ si yín bí ẹranko beari tí wọ́n kó lọ́mọ lọ, n óo sì fa àyà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. N óo ya yín jẹ bíi kinniun, bí ẹranko burúkú ṣe ń fa ẹran ya.

9 “N óo pa yín run, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; ta ni yóo ràn yín lọ́wọ́?

10 Níbo ni ọba yín wà nisinsinyii, tí yóo gbà yín là? Níbo ni àwọn olórí yín wà, tí wọn yóo gbèjà yín? Àwọn tí ẹ bèèrè fún, tí ẹ ní, ‘Ẹ fún wa ní ọba ati àwọn ìjòyè.’

11 Pẹlu ibinu, ni mo fi fun yín ní àwọn ọba yín, ìrúnú ni mo sì fi mú wọn kúrò.

12 “A ti di ẹ̀ṣẹ̀ Efuraimu ní ìtí ìtí, a ti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pamọ́.

13 Àwọn ọmọ Israẹli ní anfaani láti wà láàyè, ṣugbọn ìwà òmùgọ̀ wọn kò jẹ́ kí wọ́n lo anfaani náà. Ó dàbí ọmọ tí ó kọ̀, tí kò jáde kúrò ninu ìyá rẹ̀ ní àkókò ìrọbí.

14 N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́.

15 Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò.

16 Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”

Categories
HOSIA

HOSIA 14

Ẹ̀bẹ̀ Hosia fún Israẹli

1 Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

2 Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo.

3 Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”

OLUWA Ṣèlérí Ìgbé-Ayé Titun fún Israẹli

4 Ọlọrun ní,

“N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn,

n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn,

nítorí n kò bínú sí wọn mọ́.

5 Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli,

ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì,

gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni.

6 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀;

ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi,

òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni.

7 Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi,

wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà;

wọn óo sì tanná bí àjàrà,

òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni.

8 Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’

Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀,

tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀.

Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn.

Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.”

Ọ̀rọ̀ Ìparí

9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.

Categories
JOẸLI

JOẸLI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Nǹkan díẹ̀ ni a mọ̀ nípa Joẹli nítorí pé kò sí ẹ̀rí tí ó dánilójú nípa ìgbé-ayé rẹ̀. Ṣugbọn, ó dàbí ẹni pé láàrin ẹẹdẹgbẹta ọdún kí á tó bí OLUWA wa, (5th or 4th B.C.) ni a kọ ìwé yìí, ní àkókò ìjọba orílẹ̀-èdè Pasia. Joẹli sọ nípa eṣú tí yóo ya wọ ìlú, ati pé ọ̀dá yóo run ilẹ̀ Palẹstini. Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, ó ṣe akiyesi pé ọjọ́ OLUWA ní ń bọ̀, nígbà tí OLUWA yóo jẹ àwọn tí wọ́n tako ọ̀nà òdodo rẹ̀ níyà. Wolii Joẹli jíṣẹ́ ìpè OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli, pé kí wọ́n ronupiwada, ati pé OLUWA ṣe ìlérí fún àwọn eniyan náà pé òun óo ṣì mú ohun gbogbo pada bọ̀ sípò fún wọn. Ìlérí kan tí Ọlọrun tún ṣe fún àwọn eniyan náà tí ó sì ṣe pataki pupọ ni pé òun óo rán ẹ̀mí mímọ́ òun sórí gbogbo eniyan: atọkunrin atobinrin, àtọmọdé àtàgbà, láìya ẹnikẹ́ni sọ́tọ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àdánù tí eṣú kó bá orílẹ̀-èdè náà 1:1–2:17

Ìlérí ati mú ohun gbogbo pada bọ̀ sípò 2:18–27

Ọjọ́ OLUWA 2:28–3:21

Categories
JOẸLI

JOẸLI 1

1 Iṣẹ́ tí OLUWA rán Joẹli, ọmọ Petueli nìyí:

Ìdárò nítorí Ìparun Nǹkan Ọ̀gbìn

2 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin àgbà,

ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí!

Ǹjẹ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ rí ní àkókò yín,

tabi ní àkókò àwọn baba yín?

3 Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín nípa rẹ̀,

kí àwọn náà sọ fún àwọn ọmọ wọn,

kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún àwọn ọmọ tiwọn náà.

4 Ohun tí eṣú wẹẹrẹ jẹ kù,

ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ ẹ́.

Èyí tí ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ kù,

àwọn eṣú wẹẹrẹ mìíràn jẹ ẹ́,

èyí tí àwọn eṣú wẹẹrẹ yìí jẹ kù,

àwọn eṣú tí ń jẹ nǹkan run jẹ ẹ́ tán.

5 Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí,

ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini,

nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín.

6 Orílẹ̀-èdè kan ti dojú kọ ilẹ̀ mi,

wọ́n lágbára, wọ́n pọ̀, wọn kò sì lóǹkà;

eyín wọn dàbí ti kinniun.

Ọ̀gàn wọn sì dàbí ti abo kinniun.

7 Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi,

wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi,

wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀,

wọ́n ti wó o lulẹ̀,

àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun.

8 Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,

nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀.

9 A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA,

àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀.

10 Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀,

nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ.

11 Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀,

ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà,

nítorí ọkà alikama ati ọkà baali,

ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé.

12 Èso àjàrà ti rọ,

igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ.

Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ,

inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́.

13 Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa,

ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ.

Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé,

kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn,

nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.

14 Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ.

Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín,

kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.

15 Ó ṣe! Ọjọ́ náà ń bọ̀,

ọjọ́ OLUWA dé tán!

Ọjọ́ náà yóo dé bí ọjọ́ ìparun láti ọ̀dọ̀ Olodumare.

16 A ti gba oúnjẹ lẹ́nu yín, níṣojú yín,

bẹ́ẹ̀ ni a gba ayọ̀ ati inú dídùn kúrò ní ilé Ọlọrun wa.

17 Irúgbìn díbàjẹ́ sinu ebè,

àwọn ilé ìṣúra ti di ahoro,

àwọn àká ti wó lulẹ̀,

nítorí kò sí ọkà láti kó sinu wọn mọ́.

18 Àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora,

àwọn agbo mààlúù dààmú,

nítorí pé kò sí pápá oko fún wọn;

àwọn agbo aguntan pàápàá dààmú.

19 Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,

nítorí iná ti jó gbogbo pápá oko run,

ó sì ti jó gbogbo igi oko run.

20 Àwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá ń kígbe sí ọ, Ọlọrun,

nítorí gbogbo àwọn odò ti gbẹ tán,

àwọn pápá oko sì ti jóná.

Categories
JOẸLI

JOẸLI 2

Ọ̀wọ́ Eṣú, gẹ́gẹ́ bí Àmì Ìkéde Ọjọ́ OLUWA

1 Ẹ fun fèrè ní Sioni,

ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi.

Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì,

nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán.

2 Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́,

ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.

Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá,

bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀.

Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́,

bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae.

3 Iná ń jó àjórun níwájú wọn,

ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn.

Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn,

ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro,

kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn.

4 Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin,

wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun.

5 Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun,

wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá.

Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá,

bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun.

6 Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n,

gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì.

7 Wọ́n ń sáré bí akọni,

wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun.

Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́,

ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀.

8 Wọn kò fi ara gbún ara wọn,

olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀;

wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró.

9 Wọ́n ń gun odi ìlú,

wọ́n ń sáré lórí odi.

Wọ́n ń gun orí ilé wọlé,

wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè.

10 Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn,

ọ̀run sì ń wárìrì,

oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn.

11 OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,

nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ,

alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA!

Ta ló lè faradà á?

Ìpè fún Ìrònúpìwàdà

12 OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii,

pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn,

13 Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́,

kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.”

Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín,

nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni.

Kì í yára bínú,

Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,

a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.

14 Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada,

kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀,

kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.

15 Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni,

ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ.

16 Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,

kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.

Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,

ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.

Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,

kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.

17 Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.

Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,

má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,

‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

Ọlọrun Yóo Dá Ìbísí Pada sórí Ilẹ̀ náà

18 Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,

ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19 OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,

“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,

ẹ óo ní ànítẹ́rùn.

N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

20 N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,

n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.

N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,

n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.

Òkú wọn yóo máa rùn;

n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.

21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀,

jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,

kí o sì máa yọ̀,

nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá.

22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó,

nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù,

igi gbogbo ti so èso,

igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.

23 “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni,

kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín;

nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò,

ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín:

ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.

24 Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà,

ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀.

25 Gbogbo ohun tí ẹ pàdánù

ní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín;

ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ,

gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín.

26 Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn,

ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín,

tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín,

ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

27 Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli;

ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín,

kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́.

Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

Ọjọ́ OLUWA

28 “Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá,

n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan,

àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin

yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀,

àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá,

àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran.

29 Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó,

n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín.

30 “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀,

n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run,

ati sórí ilẹ̀ ayé;

yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín.

31 Oòrùn yóo ṣókùnkùn,

òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀,

kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé.

32 Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà.

Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni,

ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ,

àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.

Categories
JOẸLI

JOẸLI 3

OLUWA Yóo Ṣe Ìdájọ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 “Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada,

2 n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati,

n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀;

nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi.

Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,

wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi.

3 Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi,

wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn,

wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó,

wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn,

wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini.

4 “Kí ni mo fi ṣe yín rí, ẹ̀yin ilẹ̀ Tire, ati ilẹ̀ Sidoni ati gbogbo agbègbè Filistini? Ṣé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan lára mi ni? Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan ni, n óo da ẹ̀san tí ẹ̀ ń gbà le yín lórí kíákíá;

5 nítorí ẹ ti kó fadaka ati wúrà ati àwọn ìṣúra mi olówó iyebíye lọ sí ilé oriṣa yín.

6 Ẹ ta àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu fún àwọn ará Giriki, ẹ kó wọn jìnnà réré sí ilẹ̀ wọn.

7 Ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé wọn dìde níbi tí ẹ tà wọ́n sí, n óo sì gbẹ̀san ìwà yín lára ẹ̀yin alára.

8 N óo ta àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin lẹ́rú fún àwọn ará Juda. Wọn yóo sì tà wọ́n fún àwọn ará Sabea, orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré; nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”

9 Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.

Ẹ múra ogun,

ẹ rú àwọn akọni sókè.

Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí,

ogun yá!

10 Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà,

ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀,

kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.”

11 Ẹ yára, ẹ wá,

gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí ẹ wà ní àyíká,

ẹ parapọ̀ níbẹ̀.

Rán àwọn ọmọ ogun rẹ wá, OLUWA.

12 Jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè dìde,

kí wọ́n wá sí àfonífojì Jehoṣafati,

nítorí níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká.

13 Ẹ ti dòjé bọ oko, nítorí àkókò ìkórè ti tó,

ẹ lọ fún ọtí waini nítorí ibi ìfúntí ti kún.

Ìkòkò ọtí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀,

nítorí ìkà wọ́n pọ̀.

14 Ogunlọ́gọ̀ wà ní àfonífojì ìdájọ́,

nítorí ọjọ́ OLUWA kù sí dẹ̀dẹ̀ níbẹ̀.

15 Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn,

àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́.

Ọlọrun Yóo Bukun Àwọn Eniyan Rẹ̀

16 OLUWA kígbe láti Sioni,

ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu;

ọ̀run ati ayé mì tìtì,

ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀,

òun ni ibi ààbò fún Israẹli.

17 “Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,

èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi.

Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́,

àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́.

18 “Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà,

agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké.

Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi.

Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA,

yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu.

19 “Ijipti yóo di aṣálẹ̀;

Edomu yóo sì di ẹgàn,

nítorí ìwà ipá tí wọ́n hù sí àwọn ará Juda,

nítorí wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ ní ilẹ̀ wọn.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan yóo máa gbé ilẹ̀ Juda títí lae,

wọn óo sì máa gbé ìlú Jerusalẹmu láti ìrandíran.

21 N óo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ẹ pa, n kò sì ní dá ẹlẹ́bi sí,

nítorí èmi OLUWA ni mò ń gbé Sioni.”

Categories
AMOSI

AMOSI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Amosi ni wolii àkọ́kọ́ tí wọn kọ pupọ ninu iṣẹ́ tí ó jẹ́ sinu Bibeli. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ará ìlú kan ní Juda ni, ó waasu fún àwọn ará ìhà àríwá Israẹli ní nǹkan bí ẹgbẹrin ọdún kí á tó bí OLUWA wa, (8th century B.C.) Àkókò ìlọsíwájú ni àkókò Amosi, ó dàbí ẹni pé àwọn eniyan ń sin Ọlọrun tọkàntọkàn, ààbò tí ó dájú sì wà lórí wọn. Ṣugbọn Amosi ṣàkíyèsí pé, ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ ni ìlọsíwájú náà fì sí, ati pé wọ́n ń ni àwọn talaka lára, kò sì sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn eniyan kò fi tọkàntọkàn ṣe ẹ̀sìn, ààbò kò sì dájú tó bí wọ́n ti lérò pé ó wà. Ó múra gírí, ó sì fi ìtara waasu pé Ọlọrun yóo jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọn jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo, “máa ṣàn bí odò” ati pé “Bóyá OLUWA lè ṣàánú àwọn ará orílẹ̀-èdè yìí tí ó kù láàyè.” (5:15)

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìdájọ́ lórí àwọn tí ń gbé agbègbè Israẹli 1:1–2:5

Ìdájọ́ lórí Israẹli 2:6–6:14

Ìran marun-un 7:1–9:15

Categories
AMOSI

AMOSI 1

1 Ìran tí Amosi, ọ̀kan ninu àwọn darandaran Tekoa, rí nípa Israẹli nìyí, nígbà ayé Usaya, ọba Juda, ati Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli, ní ọdún meji ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì jìgìjìgì.

2 Amosi ní:

“OLUWA bú ramúramù lórí Òkè Sioni,

ó fọhùn ní Jerusalẹmu;

àwọn pápá tútù rọ,

ewéko tútù orí òkè Kamẹli sì rẹ̀.”

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Ó yí Israẹli ká Siria

3 OLUWA ní, “Àwọn ará Damasku ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà. Wọ́n mú ohun èlò ìpakà onírin ṣómúṣómú, wọ́n fi pa àwọn ará Gileadi ní ìpa ìkà.

4 Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀.

5 N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Filistia

6 Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu.

7 N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.

8 N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Tire

9 Ó ní: “Àwọn ará Tire ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n kó odidi orílẹ̀-èdè kan lẹ́rú lọ tà fún àwọn ará Edomu. Wọn kò sì ranti majẹmu tí wọ́n bá àwọn arakunrin wọn dá.

10 Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.”

Edomu

11 OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn.

12 Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.”

Amoni

13 OLUWA ní: “Àwọn ará Amoni ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; wọ́n fi ìwà wọ̀bìà bẹ́ inú àwọn aboyún ilẹ̀ Gileadi, láti gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ wọn.

14 Nítorí náà, n óo sọ iná sí orí odi ìlú Raba, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun. Ariwo yóo sọ ní ọjọ́ ogun, omi òkun yóo ru sókè ní ọjọ́ ìjì;

15 ọba wọn ati àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo sì lọ sí ìgbèkùn.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.