Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 43

Ọlọrun Pada Sinu Tẹmpili

1 Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn.

2 Wò ó! Ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli yọ láti apá ìlà oòrùn, ìró bíbọ̀ rẹ̀ dàbí ti omi òkun, ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ sì tàn sórí ilẹ̀.

3 Ìran tí mo rí yìí dàbí èyí tí mo rí nígbà tí Ọlọrun wá pa ìlú Jerusalẹmu run ati bí ìran tí mo rí létí odò Kebari; mo bá dojúbolẹ̀.

4 Ìtànṣán ògo OLUWA wọ inú Tẹmpili láti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn.

5 Ẹ̀mí bá gbé mi dìde, ó mú mi wá sinu gbọ̀ngàn inú; ìtànṣán ògo OLUWA sì kún inú Tẹmpili náà.

6 Bí ọkunrin náà ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Tẹmpili, ó ní:

7 “Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.

8 Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run.

9 Kí wọ́n pa ìwà ìbọ̀rìṣà wọn tì, kí wọ́n sì gbé òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, n óo sì máa gbé ààrin wọn títí lae.

10 “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe àpèjúwe Tẹmpili yìí, sọ bí ó ti rí ati àwòrán kíkọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè tì wọ́n.

11 Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́.

12 Òfin Tẹmpili nìyí, gbogbo agbègbè tí ó yí orí òkè ńlá tí ó wà ká gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ jùlọ.”

Pẹpẹ

13 Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan).

14 Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan).

15 Orí pẹpẹ náà ga ní igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ìwo mẹrin wà lára rẹ̀, wọ́n gùn ní igbọnwọ kọ̀ọ̀kan (ìdajì mita kan).

16 Orí pẹpẹ náà ní igun mẹrin, òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa) ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita mẹfa).

17 Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn.

Yíya Pẹpẹ Sí Mímọ́

18 Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára,

19 ẹ óo fún àwọn alufaa, ọmọ Lefi, láti inú ìran Sadoku, tí wọn ń rú ẹbọ sí mi, ní akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

20 Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ.

21 Ẹ óo mú akọ mààlúù ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ẹ óo sun ún ní ibi tí a yàn lára ilẹ̀ Tẹmpili ní ìta ibi mímọ́.

22 Ní ọjọ́ keji ẹ óo fi òbúkọ tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ya pẹpẹ náà sí mímọ́ bí ẹ ti fi ẹbọ akọ mààlúù yà á sí mímọ́.

23 Bí ẹ bá ti yà á sí mímọ́ tán, ẹ óo mú akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ati àgbò tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo fi rú ẹbọ.

24 Ẹ óo kó wọn wá siwaju OLUWA, alufaa yóo wọ́n iyọ̀ lé wọn lórí, yóo sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

25 Lojoojumọ, fún ọjọ́ meje, ẹ óo máa mú ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo máa fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

26 Fún ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún pẹpẹ náà tí ẹ óo sì máa yà á sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yà á sọ́tọ̀ fún lílò.

27 Tí ètò àwọn ọjọ́ wọnyi bá ti parí, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ, àwọn alufaa yóo máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí pẹpẹ náà, n óo sì máa tẹ́wọ́gbà wọ́n. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 44

Lílo Ẹnu Ọ̀nà Ìlà Oòrùn

1 Lẹ́yìn náà ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ìta ibi mímọ́ tí ó kọjú sí ìlà oòrùn, ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà wà ní títì.

2 OLUWA wí fún mi pé, “Ìlẹ̀kùn yìí yóo máa wà ní títì ni, wọn kò gbọdọ̀ ṣí i; ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé, nítorí èmi OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ti gba ibẹ̀ wọlé. Nítorí náà, títì ni yóo máa wà.

3 Ọba nìkan ni ó lè jókòó níbẹ̀ láti jẹun níwájú OLUWA. Yóo gba ẹnu ọ̀nà ìloro wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.”

Òfin tí Ó De Wíwọ Tẹmpili

4 Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wá siwaju tẹmpili; mo sì rí i tí ìtànṣán ògo OLUWA kún inú tẹmpili, mo bá dojúbolẹ̀.

5 OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé.

6 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olóríkunkun, pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ dáwọ́ àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe dúró.

7 Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́.

8 Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀.

9 “ ‘Nítorí náà, ẹni tí kò bá kọlà ọkàn ati ti ara ninu àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

A Yọ Àwọn Ọmọ Lefi Kúrò ninu Iṣẹ́ Alufaa

10 OLUWA ní, “Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada lẹ́yìn mi, tí wọ́n ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn nígbà tí Israẹli ṣáko lọ, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11 Wọ́n lè jẹ́ iranṣẹ ninu ibi mímọ́ mi, wọ́n lè máa ṣe alákòóso àwọn ẹnu ọ̀nà tẹmpili, wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, wọ́n lè máa pa ẹran ẹbọ sísun ati ẹran ẹbọ àwọn eniyan, wọ́n lè máa ṣe iranṣẹ fún àwọn eniyan.

12 Nítorí pé wọ́n ti jẹ́ iranṣẹ fún wọn níwájú àwọn oriṣa, wọ́n sì di ohun ìkọsẹ̀ tí ó mú ilé Israẹli dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, mo ti búra nítorí wọn pé wọ́n gbọdọ̀ jìyà.

13 Wọn kò gbọdọ̀ dé ibi pẹpẹ mi láti ṣe iṣẹ́ alufaa, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ mi ati àwọn ohun mímọ́ jùlọ; ojú yóo tì wọ́n nítorí ohun ìríra tí wọ́n ṣe.

14 Sibẹsibẹ, n óo yàn wọ́n láti máa tọ́jú tẹmpili ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ ní ṣíṣe ninu rẹ̀.

Àwọn Alufaa

15 “Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16 Àwọn ni wọn óo máa wọ ibi mímọ́ mi, wọn óo máa lọ sí ibi tabili mi, tí wọn óo máa ṣiṣẹ́ iranṣẹ, wọn óo sì máa pa àṣẹ mi mọ́.

17 Bí wọ́n bá ti dé àwọn ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú, wọn yóo wọ aṣọ funfun. Wọn kò ní wọ ohunkohun tí a fi irun aguntan hun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ lẹ́nu ọ̀nà ati ninu gbọ̀ngàn inú.

18 Wọn yóo wé lawani tí a fi aṣọ funfun rán, wọn yóo sì wọ ṣòkòtò aṣọ funfun. Wọn kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ń mú kí ooru mú eniyan di ara wọn ní àmùrè.

19 Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan ní gbọ̀ngàn ìta, wọn yóo bọ́ aṣọ tí wọ́n wọ̀ nígbà tí wọn ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sí àwọn yàrá mímọ́. Wọn yóo wọ aṣọ mìíràn kí wọn má baà sọ àwọn eniyan náà di mímọ́ nítorí ẹ̀wù wọn.

20 “Wọn kò gbọdọ̀ fá irun orí wọn tabi kí wọn jẹ́ kí oko irun wọn gùn, wọn yóo máa gé díẹ̀díẹ̀ lára irun orí wọn ni.

21 Kò sí alufaa kan tí ó gbọdọ̀ mu ọtí waini nígbà tí ó bá wọ gbọ̀ngàn inú.

22 Wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tabi obinrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, àfi wundia tí kò tíì mọ ọkunrin láàrin àwọn eniyan Israẹli tabi opó tí ó jẹ́ aya alufaa.

23 “Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ àwọn eniyan mi láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn nǹkan mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ ati àwọn nǹkan lásán. Wọ́n sì gbọdọ̀ kọ́ wọn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan tí kò mọ́ ati àwọn nǹkan mímọ́.

24 Bí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onídàájọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí èmi gan-an yóo ti ṣe é. Wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn òfin ati ìlànà mi mọ́ lákòókò gbogbo àṣàyàn àjọ̀dún wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́.

25 “Wọn kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di aláìmọ́ nípa sísúnmọ́ òkú, ṣugbọn wọ́n lè sọ ara wọn di aláìmọ́ bí ó bá jẹ́ pé òkú náà jẹ́ ti baba wọn tabi ìyá wọn tabi ti ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin tabi ti arakunrin wọn tí kò tíì gbeyawo tabi arabinrin wọn tí kò tíì wọ ilé ọkọ.

26 Lẹ́yìn tí alufaa bá di aláìmọ́, yóo dúró fún ọjọ́ meje, lẹ́yìn náà yóo di mímọ́.

27 Ní ọjọ́ tí ó bá lọ sí ibi mímọ́, tí ó bá lọ sinu gbọ̀ngàn inú láti ṣiṣẹ́ iranṣẹ ní ibi mímọ́, ó gbọdọ̀ rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

28 “Wọn kò ní ní ilẹ̀ ìní nítorí èmi ni ìní wọn, ẹ kò ní pín ilẹ̀ fún wọn ní Israẹli, èmi ni ìpín wọn.

29 Àwọn ni wọn óo máa jẹ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àwọn ni wọ́n ni gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ ní Israẹli.

30 Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín.

31 Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀ tabi tí ẹranko burúkú bá pa, kì báà jẹ́ ẹyẹ tabi ẹranko.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 45

Ìpín OLUWA ní Orílẹ̀-Èdè Náà

1 “Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́.

2 Ẹ óo fi ààyè sílẹ̀ ninu ilẹ̀ yìí fún Tẹmpili mímọ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ, ẹ óo sì tún fi aadọta igbọnwọ ilẹ̀ sílẹ̀ yí i ká.

3 Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo wọn apá kan tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10), níbẹ̀ ni ilé mímọ́ yóo wà, yóo jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ.

4 Yóo jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà, yóo wà fún àwọn alufaa, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, tí wọ́n sì ń dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ iranṣẹ. Ibẹ̀ ni wọn yóo kọ́ ilé wọn sí, ibẹ̀ ni yóo sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ fún ibi mímọ́ mi.

5 Ẹ wọn ibòmíràn tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10). Ibẹ̀ ni yóo wà fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, ibẹ̀ ni wọn óo máa gbé.

6 “Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo ya apá kan sọ́tọ̀ tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), ilẹ̀ yìí yóo wà fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Ilẹ̀ Àwọn Ọba

7 “Ọba ni yóo ni ilẹ̀ tí ó yí ilẹ̀ mímọ́ náà ká nì ẹ̀gbẹ́ kinni keji, ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ninu ìlú náà, ní ìwọ̀ oòrùn ati ìlà oòrùn, yóo gùn tó ilẹ̀ ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, yóo bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìwọ̀ oòrùn yóo sì dé òpin ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.

8 Yóo jẹ́ ìpín ti ọba ní Israẹli. Àwọn ọba kò gbọdọ̀ ni àwọn eniyan mi lára mọ́, wọ́n gbọdọ̀ fi ilẹ̀ yòókù sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.”

Òfin Fún Àwọn Ọba

9 OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́.

10 “Òṣùnwọ̀n eefa ati ti bati tí ó péye ni kí ẹ máa lò.

11 “Òṣùnwọ̀n eefa ati òṣùnwọ̀n bati náà gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà, eefa ati bati yín gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n homeri kan. Òṣùnwọ̀n homeri ni ó gbọdọ̀ jẹ́ òṣùnwọ̀n tí ẹ óo máa fi ṣiṣẹ́.

12 “Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli.

13 “Ohun tí ẹ óo máa fi rúbọ sí OLUWA nìwọ̀nyí: ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri ọkà yín kọ̀ọ̀kan, ati ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri alikama yín kọ̀ọ̀kan.

14 Ìwọ̀n òróró gbọdọ̀ péye gẹ́gẹ́ bí ìlànà; ìdámẹ́wàá ìwọ̀n bati mẹ́wàá ni òṣùnwọ̀n bati kan ninu òṣùnwọ̀n kori kọ̀ọ̀kan òṣùnwọ̀n kori gẹ́gẹ́ bíi ti homeri.

15 Ẹ níláti ya aguntan kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ ninu agbo ẹran kọ̀ọ̀kan tí ó tó igba ẹran, ninu àwọn agbo ẹran ìdílé Israẹli. Ẹ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16 “Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ kó àwọn nǹkan ìrúbọ náà fún àwọn ọba Israẹli.

17 Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

Àwọn Àjọ̀dún

18 OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ẹ pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ẹ fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ ibi mímọ́.

19 Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi sí ara òpó ìlẹ̀kùn tẹmpili, ati orígun mẹrẹẹrin pẹpẹ ati òpó ìlẹ̀kùn àbáwọlé gbọ̀ngàn ààrin ilé.

20 Bákan náà ni ẹ gbọdọ̀ ṣe ní ọjọ́ keje oṣù láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀; kí ẹ lè ṣe ètùtù fún tẹmpili.

21 “Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni, ẹ gbọdọ̀ ṣe ọdún Àjọ Ìrékọjá, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ óo máa jẹ fún ọjọ́ meje.

22 Ní ọjọ́ náà ọba yóo pa ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn ará ìlú.

23 Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

24 Fún ẹbọ ohun jíjẹ yóo pèsè òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati òṣùnwọ̀n hini òróró kọ̀ọ̀kan fún òṣùnwọ̀n eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.

25 “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje, tíí ṣe ọjọ́ keje àjọ̀dún náà, yóo pèsè irú ẹbọ kan náà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 46

Àwọn Ọba ati Àwọn Àjọ̀dún

1 OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹnu ọ̀nà àgbàlá inú tí ó kọjú sí ìlà oòrùn gbọdọ̀ wà ní títì fún ọjọ́ mẹfa tí a fi ń ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ẹ máa ṣí i ní ọjọ́ ìsinmi ati ọjọ́ oṣù tuntun.

2 Yàrá àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni ọba yóo gbà wọlé, yóo sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ẹnu ọ̀nà. Àwọn alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ti alaafia rẹ̀. Ọba yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbájáde, yóo sì jáde; ṣugbọn wọn kò ní ti ìlẹ̀kùn náà títí di ìrọ̀lẹ́.

3 Àwọn eniyan yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níwájú OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi ati ní ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.

4 Ọ̀dọ́ aguntan mẹfa tí kò lábàwọ́n ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n ni ọba yóo fi rú ẹbọ ọrẹ sísun sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi.

5 Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.

6 Ní ọjọ́ kinni oṣù, yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan mẹfa ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n rúbọ.

7 Fún ẹbọ ohun jíjẹ, yóo tọ́jú ìwọ̀n eefa ọkà kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ati eefa ọkà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n ọkà tí ó bá ti lágbára fún àwọn àgbò, yóo fi hini òróró kọ̀ọ̀kan ti eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.

8 Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà ni ọba yóo gbà wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.

9 “Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará ìlú bá wá siwaju OLUWA ní àkókò àjọ̀dún, ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà apá àríwá wọlé, ẹnu ọ̀nà gúsù ni ó gbọdọ̀ gbà jáde, ẹni tí ó bá sì gba ẹnu ọ̀nà gúsù wọlé, ẹnu ọ̀nà àríwá ni ó gbọdọ̀ gbà jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tó gbà wọlé jáde. Tààrà ni kí olukuluku máa lọ títí yóo fi jáde.

10 Ọba yóo bá wọn wọlé nígbà tí wọ́n bá wọlé, nígbà tí wọ́n bá sì jáde, yóo bá wọn jáde.

11 Ní ọjọ́ àsè ati ìgbà àjọ̀dún, ìwọ̀n eefa ọkà kan ni wọn óo fi rúbọ pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù kan, ìwọ̀n eefa ọkà kan pẹlu àgbò kan, ati ìwọ̀n eefa ọkà tí eniyan bá lágbára pẹlu ọ̀dọ́ aguntan, ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi ìwọ̀n òróró hini kọ̀ọ̀kan ti ìwọ̀n eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.

12 “Nígbà tí ọba bá pèsè ẹbọ ọrẹ àtinúwá, kì báà ṣe ẹbọ sísun, tabi ẹbọ alaafia, ni ọrẹ àtinúwá fún OLUWA tí ó pèsè, wọn yóo ṣí ẹnubodè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn fún un, yóo sì rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia rẹ̀ bíi ti ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà yóo jáde, wọn óo sì ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà náà.”

Ẹbọ Ojoojumọ

13 OLUWA ní, “Yóo máa pèsè ọ̀dọ́ aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n fún ẹbọ sísun sí OLUWA lojoojumọ. Láràárọ̀ ni yóo máa pèsè rẹ̀.

14 Ẹbọ ohun jíjẹ tí yóo máa pèsè pẹlu rẹ̀ láràárọ̀ ni: ìdámẹ́fà eefa ìyẹ̀fun ati ìdámẹ́ta hini òróró tí wọn yóo fi máa po ìyẹ̀fun náà fún ẹbọ ohun jíjẹ fún OLUWA. Èyí ni yóo jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

15 Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo ṣe máa pèsè aguntan ati ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró láràárọ̀, fún ẹbọ ọrẹ sísun ìgbà gbogbo.”

Ọba ati Ilẹ̀ Náà

16 OLUWA Ọlọrun ní, “Bí ọba bá fún ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di ti àwọn ọmọ rẹ̀, ó di ohun ìní wọn tí wọ́n jogún.

17 Ṣugbọn bí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ ní ẹ̀bùn lára ilẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ náà di tirẹ̀ títí di ọjọ́ tí yóo gba òmìnira; láti ọjọ́ náà ni ilẹ̀ náà yóo ti pada di ti ọba. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ni wọ́n lè jogún ilẹ̀ rẹ̀ títí lae.

18 Ọba kò gbọdọ̀ gbà ninu ilẹ̀ àwọn ará ìlú láti ni wọ́n lára; ninu ilẹ̀ tirẹ̀ ni kí ó ti pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má baà gba ilẹ̀ ọ̀kankan ninu àwọn eniyan mi kúrò lọ́wọ́ wọn.”

Àwọn Ilé Ìdáná Tẹmpili

19 Ọkunrin náà bá mú mi gba ọ̀nà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn, ó bá mú mi lọ sí ibi àwọn yàrá tí ó wà ní apá àríwá ibi mímọ́ náà, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa, mo sì rí ibìkan níbẹ̀ tí ó wà ní ìpẹ̀kun ní apá ìwọ̀ oòrùn.

20 OLUWA wá sọ fún mi pé, “Ní ibí yìí ni àwọn alufaa yóo ti máa se ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ibẹ̀ ni wọn yóo sì ti máa ṣe burẹdi fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọn má baà kó wọn jáde wá sí gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, kí wọn má baà fi ohun mímọ́ kó bá àwọn eniyan.”

21 Ọkunrin náà bá mú mi wá sí ibi gbọ̀ngàn tí ó wà ní ìta, ó mú mi yíká gbogbo igun mẹrẹẹrin gbọ̀ngàn náà, gbọ̀ngàn kéékèèké kọ̀ọ̀kan sì wà ní igun kọ̀ọ̀kan.

22 Ní igun mẹrẹẹrin ni àwọn gbọ̀ngàn kéékèèké yìí wà. Ó gùn ní ogoji igbọnwọ (mita 20), ó sì fẹ̀ ní ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 15) àwọn mẹrẹẹrin sì rí bákan náà.

23 Wọ́n fi òkúta kọ́ igun mẹrẹẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yípo. Wọ́n sì kọ́ ibi ìdáná wọn mọ́ ara ògiri.

24 Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Àwọn ilé ìdáná níbi tí àwọn alufaa tí óo wà níbi pẹpẹ yóo ti máa se ẹran ẹbọ àwọn eniyan mi nìyí.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 47

Odò tí Ń Ṣàn láti Tẹmpili

1 Ọkunrin náà bá mú mi pada wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili, mo sì rí i tí omi kan ń sun láti abẹ́ ìlẹ̀kùn àbájáde ó ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ìhà ìlà oòrùn ni tẹmpili kọjú sí. Omi náà ń ṣàn láti apá gúsù ibi ìlẹ̀kùn àbájáde tí ó wà ni ìhà gúsù pẹpẹ ìrúbọ.

2 Lẹ́yìn náà ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde, ó sì mú mi yípo ní ìta títí tí mo fi dé ẹnu ọ̀nà àbájáde tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Odò kékeré kan ń ṣàn jáde láti ìhà gúsù.

3 Ọkunrin náà lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn, ó mú okùn ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Ó fi wọn ẹgbẹrun igbọnwọ, (mita 450). Ó sì mú mi la odò kan tí ó mù mí dé kókósẹ̀ kọjá.

4 Ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó sì mú mi la odò náà kọjá: odò yìí sì mù mí dé orúnkún. Ọkunrin náà tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó tún mú mi la odò náà kọjá: ó sì mù mí dé ìbàdí.

5 Nígbà tí ó yá, ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), mìíràn sí ìsàlẹ̀, odò náà jìn ju ohun tí mo lè là kọjá lọ, nítorí pé ó ti kún sí i, ó jìn tó ohun tí eniyan lè lúwẹ̀ẹ́ ninu rẹ̀. Ó kọjá ohun tí eniyan lè là kọjá.

6 Ọkunrin náà bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o rí nǹkan?”

Nígbà náà ni ó mú mi gba etí odò náà pada.

7 Bí mo ṣe ń pada bọ̀, mo rí ọpọlọpọ igi ní bèbè kinni keji odò náà.

8 Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara.

9 Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè.

10 Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá.

11 Ṣugbọn ibi ẹrọ̀fọ̀ ati àbàtà rẹ̀ kò ní di mímọ́ gaara, iyọ̀ ni yóo wà níbẹ̀.

12 Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.”

Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà

13 OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji;

14 ọgbọọgba ni ẹ sì gbọdọ̀ pín in. Mo ti búra pé n óo fún àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ìní yín.

15 “Bí ààlà ilẹ̀ náà yóo ti lọ nìyí: ní apá àríwá, ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti Òkun Ńlá, yóo gba Etiloni títí dé ẹnubodè Hamati, títí dé ẹnu ibodè Sedadi,

16 àwọn ìlú Berota, Sibiraimu (tí ó wà ní ààlà Damasku ati Hamati), títí dé Haseri Hatikoni, tí ó wà ní ààlà Haurani.

17 Ààlà ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi òkun títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ìhà àríwá ààlà Damasku, ààlà ti Hamati yóo wà ní apá àríwá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà àríwá.

18 “Ní apá ìhà ìlà oòrùn, ààlà náà yóo lọ láti Hasari Enọni tí ó wà láàrin Haurani ati Damasku, ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọdani tí ó wà láàrin Gileadi ati ilẹ̀ Israẹli, títí dé òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì lọ títí dé Tamari. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn.

19 “Ní ìhà gúsù, ilẹ̀ yín yóo lọ láti Tamari dé àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí yóo fi kan odò Ijipti títí lọ dé Òkun-ńlá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà gúsù.

20 “Ní ìwọ̀ oòrùn, Òkun Ńlá ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín, yóo lọ títí dé òdìkejì ẹnu ọ̀nà Hamati. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.

21 “Báyìí ni ẹ óo ṣe pín ilẹ̀ náà láàrin ara yín, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà Israẹli.

22 Ẹ óo pín in fún ara yín ati fún àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tí wọ́n sì ti bímọ sí ààrin yín. Ẹ óo kà wọ́n sí ọmọ onílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ óo pín ilẹ̀ fún àwọn náà.

23 Ààrin ẹ̀yà tí àjèjì náà bá ń gbé ni kí ẹ ti pín ilẹ̀ ìní tirẹ̀ fún un. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 48

Pípín Ilẹ̀ Náà láàrin Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

1 Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí: Ààlà ilẹ̀ náà ní ìhà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etíkun, ó lọ ní apá ọ̀nà Hẹtiloni dé àbáwọ Hamati títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ààlà Damasku, ní òdìkejì Hamati. Ó lọ láti apá ìlà oòrùn títí dé apá ìwọ̀ oòrùn: Ìpín ti Dani yóo jẹ́ ìpín kan.

2 Ìpín ti Aṣeri yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Dani, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

3 Ìpín ti Nafutali yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Aṣeri, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

4 Ìpín ti Manase yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Nafutali, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,

5 Ìpín ti Efuraimu yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Manase, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

6 Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

7 Ìpín ti Juda yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Reubẹni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

Ìpín Pataki láàrin Ilẹ̀ Náà

8 Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín ti Juda ni ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo wà. Ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12.5), òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà pẹlu ti àwọn ìpín yòókù láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn. Ibi mímọ́ yóo wà láàrin rẹ̀.

9 Òòró ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ (kilomita 10).

10 Èyí yóo jẹ́ ilẹ̀ fún ibi mímọ́ mi, níbẹ̀ sì ni ìpín ti àwọn alufaa yóo wà, yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ní ìhà àríwá, ní ìwọ̀ oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), ní ìlà oòrùn, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5), òòró rẹ̀ ní ìhà gúsù yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½). Ibi mímọ́ OLUWA yóo wà ní ààrin rẹ̀.

11 Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ.

12 Lọ́tọ̀ ni a óo fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn. Yóo jẹ́ ìpín tiwọn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ilẹ̀ mímọ́ jùlọ; yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ti àwọn ọmọ Lefi.

13 Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5).

14 Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni.

15 Èyí tí ó kù lára ilẹ̀ náà tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), tí òòró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), yóo wà fún lílò àwọn ará ìlú, fún ibùgbé ati ilẹ̀ tí ó yí ìlú ká. Láàrin rẹ̀ ni ìlú yóo wà.

16 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà yóo gùn ní ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), ati ti ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati ti àríwá ati ti gúsù.

17 Ilẹ̀ pápá yóo sì wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà, ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan yóo gùn ní igba ó lé aadọta (250) igbọnwọ (mita 125).

18 Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú.

19 Àwọn òṣìṣẹ́ ààrin ìlú tí wọ́n bá wá láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli ni yóo máa dá oko níbẹ̀.

20 Gbogbo ilẹ̀ tí ẹ óo yà sọ́tọ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½) ní òòró ati ìbú. Èyí ni àròpọ̀ ibi mímọ́ ati ilẹ̀ ti gbogbo ìlú náà.

21 Ilẹ̀ tí ó kù lápá ọ̀tún ati apá òsì ilẹ̀ mímọ́ náà, ati ti ìlú yóo jẹ́ ti ọba. Ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí ilẹ̀ mímọ́ pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ati ibi tí ilẹ̀ mímọ́ náà pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilẹ̀ mímọ́ ati tẹmpili mímọ́ yóo sì wà láàrin rẹ̀.

22 Ilẹ̀ àwọn ọmọ Lefi ati ilẹ̀ gbogbo ìlú yóo wà láàrin ilẹ̀ ọba. Ilẹ̀ ọba yóo wà láàrin ilẹ̀ Juda ati ti Bẹnjamini.

Ilẹ̀ Àwọn Ẹ̀yà Israẹli Yòókù

23 Ní ti àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Bẹnjamini yóo ní ìpín kan.

24 Ìpín ti Simeoni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Bẹnjamini, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

25 Ìpín kan tí Isakari ní yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Simeoni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

26 Ìpín kan ti Sebuluni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Isakari, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

27 Ìpín kan ti Gadi yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Sebuluni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

28 Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè Gadi ní ìhà gúsù, ààlà ilẹ̀ náà yóo lọ láti Tamari títí dé ibi àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí dé àwọn odò Ijipti, tí ó fi lọ dé Òkun Ńlá.

29 Ilẹ̀ tí ẹ óo pín láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli nìyí; bẹ́ẹ̀ sì ni ètò bí ẹ óo ṣe pín in fún olukuluku wọn, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu

30 Ìwọ̀nyí ni yóo jẹ́ ẹnubodè àbájáde ìlú náà. Apá ìhà àríwá tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta.

31 Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Reubẹni, ẹnubodè Juda ati ẹnubodè Lefi. Orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli ni a fi sọ àwọn ẹnu ọ̀nà ìlú.

32 Apá ìlà oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Josẹfu, ẹnubodè Bẹnjamini ati ẹnubodè Dani.

33 Apá ìhà gúsù tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnu ọ̀nà mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Simeoni, ẹnubodè Isakari ati ẹnubodè Sebuluni.

34 Apá ìwọ̀ oòrùn tí ó jẹ́ ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), yóo ní ẹnubodè mẹta. Orúkọ wọn yóo máa jẹ́ ẹnubodè Gadi, ẹnubodè Aṣeri ati ẹnubodè Nafutali.

35 Àyíká ìlú náà yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) igbọnwọ (mita 9,000). Orúkọ ìlú náà yóo máa jẹ́, “OLUWA Ń Bẹ Níbí.”

Categories
DANIẸLI

DANIẸLI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìtàn inú ìwé yìí ṣẹlẹ̀ ní àkókò ọba kan tí kò ka ẹ̀sìn kún nǹkankan, tí ó sì ń fìyà jẹ àwọn tí wọn ń ṣe ẹ̀sìn. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí ń fi ọkàn àwọn eniyan rẹ̀ balẹ̀ pẹlu ìrètí pé Ọlọrun yóo gba ìjọba lọ́wọ́ aninilára tí ó wà lórí oyè, yóo sì fi ìjọba náà lé àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́, a máa fi ìtàn ati àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀.

Ìpín meji pataki ni ìwé yìí ní: (1) Àwọn ìtàn nípa Daniẹli ati àwọn tí wọ́n jọ wà ní ìgbèkùn tí wọ́n sì ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn nípa igbagbọ ati ìgbọràn sí Ọlọrun. Àkókò ìjọba ọba ti ìlú Babiloni ati ti Pasia ni wọ́n kọ àwọn ìtàn wọnyi. (2) Oríṣìíríṣìí ìran ni Daniẹli ń rí tí ó dúró fún àpẹẹrẹ ìjọba ati ìṣubú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. Orílẹ̀-èdè àwọn ará Babiloni ni orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú tí yóo dé bá ọba aninilára tí kò ka ẹ̀sìn kún, ati ìṣẹ́gun tí àwọn eniyan Ọlọrun yóo ní.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Daniẹli ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ 1:1–6:28

Àwọn ìran tí Daniẹli rí 7:1–11:45

a. Ẹranko mẹrin 7:1-28

b. Àgbò ati ewúrẹ́ 8:1–9:27

d. Iranṣẹ òde ọ̀run 10:1–11:45

e. Àkókò ìkẹyìn 12:1-13

Categories
DANIẸLI

DANIẸLI 1

Àwọn Ọdọmọkunrin kan ní Ààfin Nebukadinesari

1 Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í.

2 OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀.

3 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli,

4 kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea.

5 Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.

6 Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda.

7 Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.

8 Daniẹli pinnu pé òun kò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, tabi ọtí tí ó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Nítorí náà, ó lọ bẹ Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ọba, pé kí ó gba òun láàyè kí òun má sọ ara òun di aláìmọ́.

9 Ọlọrun jẹ́ kí Daniẹli bá ojurere ati àánú olórí àwọn ìwẹ̀fà náà pàdé.

10 Ṣugbọn Aṣipenasi sọ fún Daniẹli, pé, ẹ̀rù ń ba òun, kí ọba tí ó ṣètò jíjẹ ati mímu Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má baà lọ ṣe akiyesi pé Daniẹli rù ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, kí òun má baà fi ẹ̀mí òun wéwu lọ́dọ̀ ọba.

11 Nítorí náà, Daniẹli sọ fún ẹni tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn láti máa tọ́jú òun ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta pé,

12 “Dán àwa iranṣẹ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá, máa fún wa ní ẹ̀wà jẹ, kí o sì máa fún wa ní omi lásán mu.

13 Lẹ́yìn náà, kí o wá fi wá wé àwọn tí wọn ń jẹ lára oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ, bí o bá ti wá rí àwa iranṣẹ rẹ sí ni kí o ṣe ṣe sí wa.”

14 Ó gba ohun tí wọ́n wí, ó sì dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.

15 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, ojú wọn rẹwà, wọ́n sì sanra ju gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ lọ.

16 Nítorí náà, ẹni tí ń tọ́jú wọn bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ẹ̀wà, dípò oúnjẹ aládùn tí wọn ìbá máa jẹ ati ọtí tí wọn ìbá máa mu.

17 Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá.

18 Nígbà tí ó tó àkókò tí ọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn wá, olórí ìwẹ̀fà kó gbogbo wọn wá siwaju rẹ̀.

19 Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin.

20 Ninu gbogbo ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí ọba bi wọ́n, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn pidánpidán ati àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ó wà ní ìjọba rẹ̀ lọ.

21 Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kinni ìjọba Kirusi.

Categories
DANIẸLI

DANIẸLI 2

Àlá Nebukadinesari

1 Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà.

2 Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba.

3 Ọba sọ fún wọn pé, “Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù pupọ, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

4 Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.”

5 Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.

6 Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

7 Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

8 Ọba dá wọn lóhùn pé, “Mo mọ̀ dájú pé ẹ kàn fẹ́ máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò ni, nítorí ẹ ti mọ̀ pé bí mo ti wí ni n óo ṣe.

9 Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

10 Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí.

11 Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”

12 Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.

13 Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n.

Ọlọrun fi Àlá Ọba ati Ìtumọ̀ Rẹ̀ Han Daniẹli

14 Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, tí ọba pàṣẹ fún pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni; ó fi ọgbọ́n ati ìrẹ̀lẹ̀ bá a sọ̀rọ̀,

15 ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un.

16 Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.

17 Daniẹli bá lọ sí ilé, ó sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀: Hananaya, Miṣaeli, ati Asaraya,

18 pé kí wọ́n gbadura sí Ọlọrun ọ̀run fún àánú láti mọ àlá ọba ati ìtumọ̀ rẹ̀, kí wọ́n má baà pa òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ òun run pẹlu àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni.

19 Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo.

20 Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé,

ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára.

21 Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada;

òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́,

tíí sì í fi òmíràn jẹ.

Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n

tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.

22 Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn;

ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn,

ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.

23 Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi,

ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún,

nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára,

o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí,

nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.”

Daniẹli Rọ́ Àlá Ọba, Ó sì Sọ Ìtumọ̀ Rẹ̀

24 Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

25 Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.”

26 Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”

27 Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un.

28 Ṣugbọn Ọlọrun kan ń bẹ ní ọ̀run, tí ń fi àṣírí nǹkan ìjìnlẹ̀ hàn. Òun ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han Nebukadinesari ọba. Àlá tí o lá, ati ìran tí o rí ní orí ibùsùn rẹ nìyí:

29 “Kabiyesi! Bí o ti sùn, ò ń ronú ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la, ẹni tí ń fi ohun ìjìnlẹ̀ han ni sì fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.

30 Ní tèmi, kì í ṣe pé mo gbọ́n ju àwọn yòókù lọ ni a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí hàn mí, bíkòṣe pé kí ọba lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí òye ohun tí ó ń rò sì lè yé e.

31 “Kabiyesi, o rí ère kan níwájú rẹ ní ojúran, ère yìí tóbi gan-an, ó mọ́lẹ̀, ó ń dán, ìrísí rẹ̀ sì bani lẹ́rù.

32 Wúrà ni orí rẹ̀, àyà ati apá rẹ̀ jẹ́ fadaka, ikùn rẹ̀ títí dé itan sì jẹ́ idẹ.

33 Irin ni òkè ẹsẹ̀ rẹ̀, ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ irin tí a lú pọ̀ mọ́ amọ̀.

34 Bí o ti ń wò ó, òkúta kan là, ó sì ré bọ́ láti òkè, ó bá ère náà ní ẹsẹ̀ mejeeji tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, mejeeji sì fọ́ túútúú.

35 Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.

36 “Àlá náà nìyí; nisinsinyii, n óo sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

37 Kabiyesi, ìwọ ọba àwọn ọba ni Ọlọrun ọ̀run fún ní ìjọba, agbára, ipá ati ògo.

38 Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà.

39 Lẹ́yìn rẹ ni ìjọba mìíràn yóo dìde tí kò ní lágbára tó tìrẹ. Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kẹta, tí ó jẹ́ ti idẹ, yóo jọba lórí gbogbo ayé.

40 Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú.

41 Bí o sì ti rí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ ati ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣugbọn agbára irin yóo hàn lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀.

42 Bí ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ti jẹ́ àdàlú amọ̀ ati irin, bẹ́ẹ̀ ni apá kan ìjọba náà yóo lágbára, apá kan kò sì ní lágbára.

43 Bí o ti rí amọ̀ tí ó dàpọ̀ mọ́ irin, bẹ́ẹ̀ ni àwọn apá kinni keji yóo máa dàpọ̀ ní igbeyawo, ṣugbọn wọn kò ní darapọ̀, gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè darapọ̀ mọ́ amọ̀.

44 Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae.

45 Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.”

Ọba fún Daniẹli ní Ẹ̀bùn

46 Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli.

47 Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”

48 Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.

49 Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.

Categories
DANIẸLI

DANIẸLI 3

Nebukadinesari Pàṣẹ pé kí Gbogbo Eniyan máa Sin Ère Wúrà tí ó gbé kalẹ̀

1 Nebukadinesari fi kìkì wúrà yá ère kan tí ó ga ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 2.7). Ó gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè Babiloni.

2 Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀.

3 Nítorí náà, gbogbo wọn wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère náà, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.

4 Akéde bá kígbe sókè, ó kéde pé, “Ọba ní kí á pàṣẹ fun yín, gbogbo eniyan, ẹ̀yin orílẹ̀, ati oniruuru èdè

5 pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ẹ dojúbolẹ̀ kí ẹ sin ère wúrà tí ọba Nebukadinesari gbé kalẹ̀.

6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.”

7 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró àwọn ohun èlò orin náà, gbogbo wọn wólẹ̀, wọ́n sì sin ère wúrà tí Nebukadinesari, ọba gbé kalẹ̀.

Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Àìgbọràn Kan Àwọn Ọ̀rẹ́ Daniẹli Mẹtẹẹta

8 Àwọn ará Kalidea kan wá siwaju ọba, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Juu pẹlu ìríra, wọ́n ní,

9 “Kí ọba kí ó pẹ́!

10 Ìwọ ọba ni o pàṣẹ pé nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ti gbọ́ ìró fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, kí ó wólẹ̀, kí ó tẹríba fún ère tí o gbé kalẹ̀,

11 ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó.

12 Àwọn Juu mẹta kan tí ń jẹ́ Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, tí o fi ṣe alákòóso àwọn agbègbè ní ìjọba Babiloni tàpá sí àṣẹ ọba, wọn kò sin ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”

13 Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba.

14 Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀?

15 Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

16 Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí.

17 Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá.

18 Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”

Wọ́n Dá Ẹjọ́ Ikú fún Àwọn Ọ̀rẹ́ Daniẹli Mẹtẹẹta

19 Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ.

20 Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná.

21 Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó.

22 Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa.

23 Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà.

24 Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”

25 Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.”

A Dá Àwọn Ọkunrin Mẹtẹẹta sílẹ̀ a sì gbé wọn ga

26 Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ.

27 Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.

28 Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn.

29 “Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.”

30 Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni.