Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 3

1 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ Eniyan, jẹ ohun tí a fún ọ; jẹ ìwé tí a ká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”

2 Mo bá la ẹnu, ó sì fún mi ní ìwé náà jẹ.

3 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, jẹ ìwé tí a ká, tí mo fún ọ yìí, kí o sì yó.” Mo bá jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.

4 Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn.

5 Kì í sá ṣe àwọn tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí ó ṣòro gbọ́, ni mo rán ọ sí, àwọn ọmọ ilé Israẹli ni.

6 N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ.

7 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn.

8 Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn.

9 Bí òkúta adamanti ṣe le ju òkúta akọ lọ ni mo ṣe mú kí orí rẹ le ju orí wọn lọ. Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí ojú wọn já ọ láyà, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”

10 Ó tún sọ fún mi, pé, “Ọmọ eniyan, fi etí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí n óo bá ọ sọ, kí o sì fi wọ́n sọ́kàn.

11 Lọ bá àwọn eniyan rẹ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, kí o sọ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ fún wọn; wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má sì gbọ́.”

12 Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, mo sì gbọ́ ìró kan lẹ́yìn mi tí ó dàbí ariwo ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá, ó ní, “Ẹ fi ìyìn fún ìfarahàn ògo OLUWA ní ibùgbé rẹ̀.”

13 Ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà ni mò ń gbọ́ tí wọn ń kan ara wọn, ati ìró àgbá wọn; ó dàbí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá.

14 Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi dìde, ó sì gbé mi lọ. Tìbínú-tìbínú ni mo sì fi ń lọ. Ẹ̀mí OLUWA ni ó gbé mi lọ pẹlu agbára.

15 Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu.

OLUWA Yan Isikiẹli Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣọ́

16 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

17 “Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn.

18 Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

19 Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là.

20 “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.

21 Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.”

Isikiẹli yóo Ya Odi

22 Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

23 Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀.

24 Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ.

25 Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan.

26 N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.

27 Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 4

Isikiẹli Gbé Òfin Jáde lórí Ìwà Ìbàjẹ́ ní Jerusalẹmu

1 OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú bulọọku kan kí o gbé e ka iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sórí rẹ̀.

2 Kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń dóti ìlú tì í. Bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ọ̀nà dé ibẹ̀. Fi àgọ́ àwọn jagunjagun sí i, kí o wá gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká.

3 Wá irin pẹlẹbẹ kan tí ó fẹ̀, kí o gbé e sí ààrin ìwọ ati ìlú náà, kí ó dàbí ògiri onírin. Dojú kọ ọ́ bí ìlú tí a gbógun tì; kí o ṣebí ẹni pé ò ń gbógun tì í. Èyí yóo jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.

4 “Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀.

5 Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.

6 Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.

7 “Lẹ́yìn náà, kọjú sí Jerusalẹmu, ìlú tí a gbógun tì, ká aṣọ kúrò ní apá rẹ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i.

8 Wò ó! N óo dè ọ́ lókùn mọ́lẹ̀, tí o kò fi ní lè yí ẹ̀gbẹ́ pada títí tí o óo fi parí iye ọjọ́ tí o níláti fi gbé ogun tì í.

9 “Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.

10 Wíwọ̀n ni o óo máa wọn oúnjẹ tí o óo máa jẹ, ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ rẹ yóo jẹ́ ogún ṣekeli, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa jẹ ẹ́.

11 Wíwọ̀n ni o óo máa wọn omi tí o óo máa mu pẹlu; ìdá mẹfa òṣùnwọ̀n hini ni omi tí o óo máa mu ní ọjọ́ kan, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa mu ún.

12 O óo jẹ ẹ́ bí àkàrà ọkà baali dídùn; ìgbẹ́ eniyan ni o óo máa fi dá iná tí o óo máa fi dín in lójú wọn.”

13 OLUWA ní: “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn ní àìmọ́, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí òun óo lé wọn sí.”

14 Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, n kò sọ ara mi di aláìmọ́ rí láti ìgbà èwe mi títí di ìsinsìnyìí, n kò jẹ òkú ẹran rí, tabi ẹran tí ẹranko pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kankan kò kan ẹnu mi rí.”

15 OLUWA bá wí fún mi pé, “Kò burú, n óo jẹ́ kí o fi ìgbẹ́ mààlúù dáná láti fi dín àkàrà rẹ, dípò ìgbẹ́ eniyan.”

16 Ó tún fi kun fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, n óo mú kí oúnjẹ wọ́n ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rù ni wọn óo máa fi wá oúnjẹ tí wọn óo máa jẹ, wíwọ̀n ni wọn óo sì máa wọn omi mu pẹlu ìpayà.

17 N óo ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè ṣe aláìní oúnjẹ ati omi, kí wọ́n lè máa wo ara wọn pẹlu ìpayà, kí wọ́n sì parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 5

Isikiẹli Gé Irun Rẹ̀

1 OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú idà kan tí ó bá mú, lò ó gẹ́gẹ́ bí abẹ ìfárí, kí o fi fá orí ati irùngbọ̀n rẹ. Mú òṣùnwọ̀n tí a fi ń wọn nǹkan kí o fi pín irun tí o bá fá sí ọ̀nà mẹta.

2 Jó ìdámẹ́ta rẹ̀ ninu iná láàrin ìlú, ní ìgbà tí ọjọ́ tí a fi dóti ìlú náà bá parí. Máa fi idà gé ìdámẹ́ta, kí o sì fọ́n ọn káàkiri lẹ́yìn ìlú, fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri sinu afẹ́fẹ́, n óo sì fa idà yọ tẹ̀lé e.

3 Mú díẹ̀ ninu irun náà kí o dì í sí etí ẹ̀wù rẹ.

4 Mú díẹ̀ ninu èyí tí o dì sí etí ẹ̀wù, jù ú sinu iná kí ó jóná; iná yóo sì ti ibẹ̀ ṣẹ́ sí gbogbo ilé Israẹli.”

5 OLUWA Ọlọrun ní: “Jerusalẹmu nìyí. Mo ti fi í sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì ti fi àwọn agbègbè yí i ká.

6 Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi.

7 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé rúdurùdu yín ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká lọ, ati pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i yín ká.

8 Nítorí náà, èmi, OLUWA Ọlọrun fúnra mi, ni mo dójú le yín, n óo sì ṣe ìdájọ́ fun yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè.

9 Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae.

10 Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé.

11 “Bí mo ti wà láàyè, n óo pa yín run. N kò ní fojú fo ohunkohun, n kò sì ní ṣàánú yín rárá; nítorí ẹ ti fi àwọn nǹkan ẹ̀sìn ìríra ati àṣà burúkú yín sọ ilé mímọ́ mi di aláìmọ́.

12 Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n.

13 “Bẹ́ẹ̀ ni inú mi yóo ṣe máa ru si yín, tí n óo sì bínú si yín títí n óo fi tẹ́ ara mi lọ́rùn. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀ pẹlu owú nígbà tí mo bá bínú si yín tẹ́rùn.

14 N óo sọ yín di ahoro ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yi yín ká ati lójú gbogbo àwọn tí wọn ń rékọjá lọ.

15 “Ẹ óo di ẹni ẹ̀sín ati ẹni ẹ̀gàn, ẹni àríkọ́gbọ́n ati ẹni àríbẹ̀rù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká; nígbà tí mo bá fi ibinu ati ìrúnú dájọ́ fun yín, tí mo sì jẹ yín níyà pẹlu ibinu.

16 Nígbà tí mo bá ta ọfà burúkú mi si yín: ọfà ìyàn ati ọfà ìparun, tí n óo ta lù yín láti pa yín run, ìyàn óo mú lọpọlọpọ nígbà tí mo bá mú kí oúnjẹ yín tán pátá.

17 N óo rán ìyàn ati àwọn ẹranko burúkú si yín, wọn óo sì pa yín lọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, n óo sì jẹ́ kí ogun pa yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 6

Ọlọrun fi Ìbọ̀rìṣà Gégùn-ún

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn òkè Israẹli kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn.

3 Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí. OLUWA Ọlọrun ń bá àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké wí! Ó ń sọ fún àwọn ọ̀gbun ati àwọn àfonífojì pé, èmi fúnra mi ni n óo kó ogun wá ba yín, n óo sì pa àwọn ibi ìrúbọ yín run.

4 Àwọn pẹpẹ ìrúbọ yín yóo di ahoro, a óo fọ́ àwọn pẹpẹ turari yín, n óo sì da òkú yín sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín.

5 N óo da òkú ẹ̀yin ọmọ Israẹli sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín, n óo sì fọ́n egungun yín ká níbi pẹpẹ ìrúbọ yín.

6 Ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, àwọn ìlú yín yóo di ahoro, àwọn ibi ìrúbọ yín yóo di òkítì àlàpà, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn pẹpẹ oriṣa yín yóo di ahoro ati àlàpà. A óo fọ́ àwọn ère oriṣa yín, a óo pa wọ́n run, a óo wó pẹpẹ turari yín, iṣẹ́ yín yóo sì parẹ́.

7 Òkú yóo sùn lọ bẹẹrẹ láàrin yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

8 “ ‘Sibẹsibẹ n óo dá díẹ̀ sí ninu yín; kí ẹ lè ní àwọn tí yóo bọ́ lọ́wọ́ ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nígbà tí ẹ bá fọ́n káàkiri ilé ayé.

9 Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn.

10 Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA, ati pé kì í ṣe pé mo sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ẹnu lásán pé n óo ṣe wọ́n níbi.’ ”

11 OLUWA Ọlọrun ní: “Ẹ káwọ́ lérí kí ẹ máa fi ẹsẹ̀ janlẹ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Háà! Ó mà ṣe o!’ Ogun ati ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa ilé Israẹli nítorí ìwà ìríra wọn.

12 Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata.

13 Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ káàkiri láàrin àwọn ère oriṣa wọn yíká pẹpẹ ìrúbọ wọn, ní gbogbo ibi ìrúbọ ati lórí gbogbo òkè ńlá, lábẹ́ gbogbo igi tútù ati gbogbo igi oaku eléwé tútù; ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí àwọn oriṣa wọn.

14 Ọwọ́ mi óo tẹ̀ wọ́n; n óo sọ ilẹ̀ wọn di ahoro ati òkítì àlàpà, ní gbogbo ibùgbé wọn, láti ibi aṣálẹ̀ títí dé Ribila. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 7

Òpin ti dé Tán fún Israẹli

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa ilẹ̀ Israẹli ni pé: òpin ti dé. Òpin dé sórí igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ náà.

3 “Òpin ti dé ba yín báyìí, n óo bínú si yín, n óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín; n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín.

4 N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò sì ní ṣàánú yín. Ṣugbọn n óo jẹ yín níyà fún gbogbo ìwà yín níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

5 OLUWA Ọlọrun ní: “Àjálù dé! Ẹ wò ó! Àjálù ń ré lu àjálù.

6 Òpin dé! Òpin ti dé; ó ti dé ba yín.

7 Ẹ wò ó! Ó ti dé. Ìparun ti dé ba yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí. Àkókò tó, ọjọ́ ti súnmọ́lé, ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, tí kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí àwọn òkè.

8 “Ó yá tí n óo bínú si yín, tí inú mi óo ru si yín gidi. N óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín.

9 N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò ní ṣàánú yín. N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA, ni mò ń jẹ yín níyà.”

10 Ọjọ́ pé. Ẹ wò ó! Ọjọ́ ti pé! Ìparun yín ti dé. Ìwà àìṣẹ̀tọ́ ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga ń rúwé.

11 Ìwà ipá hù, ó dàgbà, ó di ọ̀pá ìwà ibi; bí ẹ ti pọ̀ tó, ẹ kò ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan, àtẹ̀yin ati àwọn ohun ìní yín, ati ọrọ̀ yín ati ògo yín.

12 Àkókò tó; ọjọ́ náà sì ti dé tán, kí ẹni tí ń ra nǹkan má ṣe yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ń tà má sì banújẹ́, nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn.

13 Ẹni tí ń tà kò ní sí láyé láti pada síbi ohun tí ó tà ní ìgbà ayé ẹni tí ó rà á. Nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Kò sì ní yipada, bẹ́ẹ̀ ni nítorí ẹ̀ṣẹ̀ olukuluku, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní sí láàyè.

14 Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn.

Ìjìyà Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Ọmọ Israẹli

15 Ogun ń bẹ lóde; àjàkálẹ̀-àrùn ati ìyàn wà ninu ilé. Ẹni tí ó bá wà lóko yóo kú ikú ogun. Ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn yóo pa ẹni tí ó bá wà ninu ìlú.

16 Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

17 Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára.

18 Wọn óo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ìpayà óo sì bá wọn. Ojú óo ti gbogbo wọn; gbogbo wọn óo sì di apárí.

19 Wọ́n óo fọ́n fadaka wọn dà sílẹ̀ láàrin ìgboro. Wúrà wọn yóo sì dàbí ohun àìmọ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA. Kò ní lè tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè jẹ ẹ́ yó. Nítorí pé wúrà ati fadaka ló mú wọn dẹ́ṣẹ̀.

20 Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn.

21 OLUWA ní, “N óo sọ wọ́n di ìjẹ fún àwọn àjèjì, n óo sì fi wọ́n ṣe ìkógun fún àwọn eniyan burúkú ilé ayé. Wọn óo sọ wọ́n di ohun eléèérí.

22 N óo mójú kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n lè sọ ibi dídára mi di eléèérí. Àwọn ọlọ́ṣà yóo wọnú rẹ̀, wọn yóo sì sọ ọ́ di eléèérí.

23 “Nítorí pé ìpànìyàn kún ilẹ̀ náà, ìlú wọn sì kún fún ìwà ipá.

24 N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí.

25 Nígbà tí ìrora bá dé, wọn yóo máa wá alaafia, ṣugbọn wọn kò ní rí i.

26 Àjálù yóo máa yí lu àjálù, ọ̀rọ̀ àhesọ yóo máa gorí ara wọn. Wọn yóo máa wo ojú wolii fún ìran ṣugbọn kò ní sí, alufaa kò ní náání òfin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìmọ̀ràn mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà.

27 Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 8

Ìwà Ìbọ̀rìṣà Ní Jerusalẹmu

1 Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀.

2 Nígbà tí mo wò, mo rí nǹkankan tí ó dàbí eniyan. Láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ dé ilẹ̀ jẹ́ iná, ibi ìbàdí rẹ̀ sókè ń kọ mànàmànà bí idẹ dídán.

3 Ó na nǹkankan tí ó dàbí ọwọ́, ó fi gbá ìdí irun orí mi mú, ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede meji ọ̀run ati ayé, ó gbé mi lọ sí Jerusalẹmu, ninu ìran Ọlọrun, ó gbé mi sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá gbọ̀ngàn ti inú tí ó kọjú sí ìhà àríwá, níbi tí wọ́n gbé ère tí ń múni jowú sí.

4 Mo rí ìfarahàn ògo Ọlọrun Israẹli níbẹ̀ bí mo ti rí i lákọ̀ọ́kọ́ ní àfonífojì.

5 Ó bá sọ fún mi, pé: “Ọmọ eniyan, gbójú sókè sí apá àríwá.” Mo bá gbójú sókè sí apá àríwá. Wò ó! Mo rí ère kan tí ń múni jowú ní ìhà àríwá ẹnu ọ̀nà pẹpẹ ìrúbọ.

6 OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.”

7 OLUWA bá tún gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn, nígbà tí mo wò yíká, mo rí ihò kan lára ògiri.

8 Ó bá sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, gbẹ́ ara ògiri yìí.” Nígbà tí mo gbẹ́ ara ògiri náà, mo rí ìlẹ̀kùn kan!

9 Ó bá sọ fún mi pé, “Wọlé kí o rí nǹkan ìríra tí wọn ń ṣe níbẹ̀.”

10 Mo bá wọlé láti wo ohun tí ó wà níbẹ̀. Mo rí àwòrán oríṣìíríṣìí kòkòrò ati ti ẹranko, tí ń rí ni lára, ati gbogbo oriṣa àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n yà sí ara ògiri yíká.

11 Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè.

12 OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ”

13 Ó tún sọ fún mi pé, “N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn tí ó jù báyìí lọ tí wọn ń ṣe hàn ọ́.”

14 Nígbà náà ni ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá ilé OLUWA. Wò ó, mo rí àwọn obinrin kan níbẹ̀, tí wọ́n jókòó, tí wọn ń sunkún nítorí Tamusi.

15 Ó sì bi mí pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? O óo tún rí nǹkan ìríra tí ó ju èyí lọ.”

16 Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn.

17 Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn.

18 Nítorí náà, n óo bínú sí wọn, n kò ní fojú fo iṣẹ́ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. Wọ́n ìbáà máa kígbe sí mi létí, n kò ní dá wọn lóhùn.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 9

Wọ́n Jẹ Jerusalẹmu Níyà

1 Lẹ́yìn náà, Ọlọrun kígbe sí mi létí, ó ní, “Ẹ súnmọ́bí, ẹ̀yin tí ẹ óo pa ìlú yìí run, kí olukuluku mú nǹkan ìjà rẹ̀ lọ́wọ́.”

2 Wò ó! Mo bá rí àwọn ọkunrin mẹfa kan tí wọn ń bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà òkè tí ó kọjú sí ìhà àríwá. Olukuluku mú ohun ìjà tí ó fẹ́ fi pa eniyan lọ́wọ́. Ọkunrin kan wà láàrin wọn tí ó wọ aṣọ funfun, ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. Wọ́n wọlé, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

3 Ògo Ọlọrun Israẹli ti gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu tí ó wà, ó dúró sí àbáwọlé. Ó ké sí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́.

4 OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.”

5 Mo sì gbọ́ tí ó wí fún àwọn yòókù pé: “Ẹ lọ káàkiri ìlú yìí, kí ẹ máa pa àwọn eniyan. Ẹ kò gbọdọ̀ dá ẹnikẹ́ni sí, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú ẹnikẹ́ni.

6 Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA.

7 Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ ilé náà di aláìmọ́, ẹ kó òkú eniyan kún gbọ̀ngàn rẹ̀, kí ẹ sì bọ́ síta.” Wọ́n bá bẹ́ sí ìgboro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn eniyan láàrin ìlú.

8 Bí wọ́n ti ń pa àwọn eniyan, tí èmi nìkan dá dúró, mo dojúbolẹ̀, mo kígbe. Mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o óo pa gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Israẹli nítorí pé ò ń bínú sí Jerusalẹmu ni?”

9 Ó dá mi lóhùn, ó ní: “Ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli ati ti Juda pọ̀jù. Ilẹ̀ náà kún fún ìpànìyàn, ìlú yìí sì kún fún ìwà àìṣẹ̀tọ́. Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA ti kọ ilẹ̀ yìí sílẹ̀, kò sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.’

10 N kò ní mójú fo ọ̀rọ̀ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. N óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn lé wọn lórí.”

11 Mo bá gbọ́ tí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́, ń jábọ̀ pé, “Mo ti ṣe bí o ti pàṣẹ fún mi.”

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 10

Ògo OLUWA Kúrò Ninu Tẹmpili Náà

1 Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́.

2 Ọlọrun bá sọ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé, “Bọ́ sí ààrin àwọn àgbá tí wọn ń yí, tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn Kerubu. Bu ẹ̀yinná tí ó wà láàrin wọn kún ọwọ́ rẹ, kí o sì fọ́n ọn sórí ìlú yìí káàkiri.”

Mo bá rí i tí ó wọlé lọ.

3 Ìhà gúsù ilé náà ni àwọn Kerubu dúró sí nígbà tí ọkunrin náà wọlé, ìkùukùu sì bo àgbàlá ààrin ilé náà.

4 Ìfarahàn ògo OLUWA gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu, ó lọ dúró sí àbáwọlé. Ìkùukùu kún gbogbo inú ilé náà, ìmọ́lẹ̀ ògo OLUWA sì kún gbogbo inú àgbàlá.

5 Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀.

6 Nígbà tí OLUWA pàṣẹ fún ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà pé kí ó mú iná láàrin àwọn àgbá tí ń yí, tí ó wà láàrin àwọn Kerubu, ọkunrin náà wọlé, ó lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá náà.

7 Ọ̀kan lára àwọn Kerubu náà na ọwọ́ sí inú iná tí ó wà láàrin wọn, ó bù ú sí ọwọ́ ọkunrin aláṣọ funfun náà. Ọkunrin náà gbà á, ó sì jáde.

8 Ó dàbí ẹni pé àwọn Kerubu náà ní ọwọ́ bíi ti eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn.

9 Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite.

10 Àwọn mẹrẹẹrin rí bákan náà, ó sì dàbí ìgbà tí àwọn àgbá náà wọnú ara wọn.

11 Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ.

12 Gbogbo ara wọn àtẹ̀yìn wọn, àtọwọ́, àtìyẹ́ ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ wọn kún fún ojú.

13 Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn àgbá náà ní àgbá tí ń sáré yí.

14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní iwájú mẹrin mẹrin. Iwájú kinni jẹ́ iwájú Kerubu, ekeji jẹ́ iwájú eniyan, ẹkẹta jẹ́ iwájú kinniun, ẹkẹrin sì jẹ́ iwájú ẹyẹ idì.

15 Àwọn Kerubu náà bá gbéra nílẹ̀, àwọn ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí ní etí odò Kebari.

16 Bí wọn tí ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbá náà ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn Kerubu náà bá fẹ́ fò, tí wọ́n bá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá náà kìí kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.

17 Bí wọn bá dúró, àwọn náà á dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn náà á gbéra, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà ninu wọn.

18 Ìtànṣán ògo OLUWA jáde kúrò ní àbáwọlé, ó sì dúró sí orí àwọn Kerubu náà.

19 Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

20 Àwọn wọnyi ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọrun Israẹli ní etí odò Kebari. Mo sì mọ̀ pé Kerubu ni wọ́n.

21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní iwájú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin, wọ́n sì ní ọwọ́ bí ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn.

22 Bí iwájú àwọn tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari ti rí gan-an ni iwájú wọn rí. Olukuluku ń rìn lọ siwaju tààrà.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 11

(OLUWA Bá Jerusalẹmu Wí)

1 Ẹ̀mí gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn. Àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan wà lẹ́nu ọ̀nà náà, mo rí i pé àwọn meji láàrin wọn jẹ́ ìjòyè: Jaasanaya, ọmọ Aṣuri, ati Pelataya, ọmọ Bẹnaya.

2 OLUWA sọ fún mi, pé, “Ìwọ Ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbèrò ibi nìyí; tí wọn ń fún àwọn eniyan ìlú yìí ní ìmọ̀ràn burúkú.

3 Wọ́n ń wí pé, ‘àkókò ilé kíkọ́ kò tíì tó. Ìlú yìí dàbí ìkòkò,àwa sì dàbí ẹran.’

4 Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nípa wọn, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀.”

5 Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn,

6 Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú.

7 “Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀.

8 Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.

9 N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín.

10 Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

11 Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín.

12 Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.”

13 Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?”

Ìlérí Ọlọrun sí Àwọn tí Wọ́n Wà Ní Ìgbèkùn

14 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

15 “Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’

16 “Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ.

17 “Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’

18 Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀.

19 Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;

20 kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

21 Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ògo OLUWA Kúrò ní Jerusalẹmu

22 Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

23 Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà.

24 Ẹ̀mí bá gbé mi sókè ní ojúran, ó gbé mi wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ìran tí mo rí bá kúrò lójú mi.

25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA fihàn mí fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 12

Wolii Gẹ́gẹ́ Bí Ẹni Tí Ó sá fógun

1 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

3 “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

4 Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn.

5 Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde.

6 Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.”

7 Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn.

8 Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀,

9 ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe?

10 Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’

11 Sọ fún wọn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wọn. Bí o ti ṣe ni wọ́n óo ṣe wọ́n, wọn óo lọ sí ìgbèkùn.

12 Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀.

13 N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí.

14 Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ.

15 “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé.

16 N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Àmì Wolii Tí Ń Gbọ̀n

17 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

18 “Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ.

19 Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù.

20 Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

Òwe tí Ó Lókìkí ati Iṣẹ́ tí Àwọn Eniyan kò Fẹ́ Gbọ́

21 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

22 “Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’

23 Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ.

24 “Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

25 Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

26 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

27 “Ìwọ ọmọ eniyan, gbọ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti ń wí pé, Ìran ọjọ́ iwájú ni ò ń rí, o sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ gbọọrọ.

28 Nítorí náà, wí fún wọn pé: mo ní n kò ní fi ọ̀rọ̀ mi falẹ̀ mọ́, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ yóo ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”