Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 52

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀.

2 Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe.

3 Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀.

Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.

4 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká.

5 Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya.

6 Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn mú ní ààrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́.

7 Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani.

8 Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀.

9 Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un.

10 Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila.

11 Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú.

Wọ́n Wó Tẹmpili Lulẹ̀

12 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu.

13 Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun.

14 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.

15 Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́.

16 Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko.

17 Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni.

18 Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.

19 Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.

20 Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n.

21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òpó náà ga ní igbọnwọ mejidinlogun, àyíká wọn jẹ́ igbọnwọ mejila, wọ́n nípọn, ní ìka mẹrin, wọ́n sì ní ihò ninu.

22 Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká.

23 Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.

Wọ́n Kó Àwọn Ará Juda ní Ìgbèkùn Lọ sí Babiloni

24 Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta.

25 Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro.

26 Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.

27 Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.

Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn.

28 Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu.

29 Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu.

30 Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600).

31 Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé.

32 Ó bá a sọ ọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga jùlọ, àní ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ.

33 Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

34 Ọba Babiloni sì rí i pé òun ń pèsè gbogbo ohun tí ó nílò lojoojumọ fún un títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Categories
ẸKÚN JEREMAYA

ẸKÚN JEREMAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ orin arò marun-un nípa ìṣubú Jerusalẹmu ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa, (586 B.C.), ati ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ogun kó Jerusalẹmu, tí a sì kó àwọn Juu lọ sí ìgbèkùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohùn arò kún inú ìwé yìí, ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ati ìrètí ninu Ọlọrun ṣì tún wà níbẹ̀. Wọn a máa lo àwọn orin arò wọnyi lọdọọdun ní àkókò ààwẹ̀ ati ìrònú nípa ìrántí ìṣòro tí orílẹ̀-èdè wọn ní, ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa, (586 B.C.), tí ogun kó Jerusalẹmu.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àwọn ìṣòro tí ó kojú Jerusalẹmu 1:1-22

Ìjìyà Jerusalẹmu 2:1-22

Ìjìyà ati ìrètí 3:1-66

Jerusalẹmu parun 4:1-22

Adura àánú 5:1-22

Categories
ẸKÚN JEREMAYA

ẸKÚN JEREMAYA 1

Ìbànújẹ́ Jerusalẹmu

1 Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro,

tí ó wá dàbí opó!

Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀!

Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrin

láàrin àwọn ìlú yòókù.

Ó ti wá di ẹni àmúsìn.

2 Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru,

omijé ń dà lójú rẹ̀,

kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀.

Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á,

wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn,

wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀.

3 Juda ti lọ sí ìgbèkùn,

wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn.

Nisinsinyii, ó ń gbé

ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

kò sì ní ibi ìsinmi.

Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́,

ninu ìdààmú rẹ̀.

4 Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò,

nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọ

síbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́.

Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro,

àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn.

Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú,

òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ.

5 Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀,

nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú,

wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ.

6 Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀,

àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nrín

tí kò rí koríko tútù jẹ;

agbára kò sí fún wọn mọ́,

wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn.

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú ati ìbànújẹ́,

Jerusalẹmu ranti àwọn nǹkan iyebíye tí ó ní ní ìgbà àtijọ́.

Nígbà tí àwọn eniyan rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,

tí kò sì sí ẹni tí yóo ràn wọ́n lọ́wọ́.

Àwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́,

wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín nítorí ìṣubú rẹ̀.

8 Jerusalẹmu ti dẹ́ṣẹ̀ burúkú,

nítorí náà ó ti di eléèérí.

Àwọn tí wọn ń bu ọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti ń kẹ́gàn rẹ̀,

nítorí pé wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.

Òun pàápàá ń kérora, ó sì fi ojú pamọ́.

9 Ìwà èérí rẹ̀ hàn níbi ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀,

kò sì bìkítà fún ìparun tí ń bọ̀.

Nítorí náà ni ìṣubú rẹ̀ fi pọ̀, tí kò sì fi ní olùtùnú.

Ó ké pe OLUWA pé kí ó ṣíjú wo ìnira òun,

nítorí pé ọ̀tá ti borí rẹ̀.

10 Ọ̀tá ti tọwọ́ bọ ilé ìṣúra rẹ̀,

wọ́n sì ti kó gbogbo nǹkan iyebíye inú rẹ̀ lọ;

ó ń wo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

tí wọn ń wọ ibi mímọ́ rẹ̀.

Àwọn tí ó pàṣẹ pé

wọn kò gbọdọ̀ dé àwùjọ àwọn eniyan rẹ̀.

11 Gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ń kérora

bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;

wọ́n ń fi ìṣúra wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ

kí wọ́n baà lè lágbára.

Jerusalẹmu ń sunkún pé,

“Bojúwò mí, OLUWA,

nítorí pé mo di ẹni ẹ̀gàn.”

12 Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ?

Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀,

bóyá ìbànújẹ́ kan wà

tí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí;

tí OLUWA mú kí ó dé bá mi,

ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.

13 “Ó rán iná láti òkè ọ̀run wá;

ó dá a sí egungun mi;

ó dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;

ó sì dá mi pada.

Mo dàbí odi,

mo sì fi ìgbà gbogbo dákú.

14 “Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà,

ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn,

ó sì sọ mí di aláìlágbára.

OLUWA ti fi mí lé

àwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.

15 “OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀;

ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi,

ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi;

OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́,

bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.

16 “Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún;

tí omijé ń dà lójú mi;

olùtùnú jìnnà sí mi,

kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le.

Àwọn ọmọ mi ti di aláìní,

nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa.

17 “Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́,

Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́,

OLUWA ti pàṣẹ pé,

kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀;

Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn.

18 “Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe,

nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀;

ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan,

ẹ kíyèsí ìjìyà mi;

wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin mi

lọ sí ìgbèkùn.

19 “Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi,

ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí;

àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú,

níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri,

tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára

20 “Bojúwò mí, OLUWA,

nítorí mo wà ninu ìpọ́njú,

ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́,

nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ.

Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ;

bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé.

21 “Gbọ́ bí mo ti ń kérora,

kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu.

Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi;

inú wọn sì dùn,

pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi.

Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé,

kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà.

22 “Ranti gbogbo ìwà ibi wọn,

kí o sì jẹ wọ́n níyà;

bí o ti jẹ mí níyà,

nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.

Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

Categories
ẸKÚN JEREMAYA

ẸKÚN JEREMAYA 2

Ìyà Tí OLUWA Fi Jẹ Jerusalẹmu

1 Ẹ wò bí OLUWA ti fi ibinu

fi ìkùukùu bo Sioni mọ́lẹ̀.

Ó ti wọ́ ògo Israẹli lu

láti òkè ọ̀run sórí ilẹ̀ ayé;

kò tilẹ̀ ranti àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.

2 OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú.

Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀.

Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀,

ó fi àbùkù kàn wọ́n.

3 Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,

pa àwọn alágbára Israẹli;

ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́,

nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n.

Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná,

ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run.

4 Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá,

ó múra bí aninilára.

Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa,

ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni.

5 OLUWA ṣe bí ọ̀tá,

ó ti pa Israẹli run.

Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run,

ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpà

ó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ.

6 Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀,

bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko.

Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run.

OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni.

Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,

kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.

7 OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́,

ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́;

wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWA

gẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀.

8 OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀.

Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n,

kò sì rowọ́ láti parun.

Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́,

wọ́n sì di àlàpà papọ̀.

9 Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀;

ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè;

ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn;

òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.

10 Àwọn àgbààgbà Sioni jókòó lórí ilẹ̀, wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́,

wọ́n ku eruku sórí,

wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.

Àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu doríkodò.

11 Ẹkún sísun ti sọ ojú mi di bàìbàì,

ìdààmú bá ọkàn mi;

ìbànújẹ́ sì mú kí ó rẹ̀wẹ̀sì

nítorí ìparun àwọn eniyan mi,

nítorí pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́

ati àwọn ọmọ ọwọ́ ń dákú lójú pópó láàrin ìlú.

12 Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú,

bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́,

tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn,

wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé:

“Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.”

13 Kí ni mo lè sọ nípa rẹ,

kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu?

Kí ni mo lè fi wé ọ,

kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni?

Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò;

ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?

14 Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ;

wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́,

kí wọ́n lè dá ire rẹ pada,

ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ.

15 Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọ

ń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,

wọ́n ń pòṣé,

wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu.

Wọ́n ń sọ pé:

“Ṣé ìlú yìí ni à ń pè ní

ìlú tí ó lẹ́wà jùlọ,

tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?”

16 Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín,

wọ́n ń pòṣé,

wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.

Wọ́n ń wí pé:

“A ti pa á run!

Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí;

ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí!

A ti rí ohun tí à ń wá!”

17 OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu,

ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ,

bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́.

Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ;

ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́,

ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára.

18 Ẹ kígbe sí OLUWA,

ẹ̀yin ará Sioni!

Ẹ jẹ́ kí omi máa dà lójú yín pòròpòrò tọ̀sán-tòru;

ẹ má sinmi,

ẹ má sì jẹ́ kí oorun kùn yín.

19 Ẹ dìde, ẹ kígbe lálẹ́,

ní àkókò tí àwọn aṣọ́de ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́!

Ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín jáde bí omi níwájú OLUWA!

Ẹ gbé ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sókè sí i,

nítorí ẹ̀mí àwọn ọmọ yín tí ebi ń pa kú lọ ní gbogbo ìkóríta.

20 Wò ó! OLUWA,

ṣe akiyesi ohun tí ń ṣẹlẹ̀!

Wo àwọn tí ò ń ṣe irú èyí sí!

Ṣé ó yẹ kí àwọn obinrin máa jẹ ọmọ wọn?

Ọmọ ọwọ́ tí wọn ń tọ́jú!

Ṣé ó yẹ kí á pa alufaa ati wolii, ní ibi mímọ́ OLUWA?

21 Àtàwọn ọ̀dọ́, àtàwọn arúgbó

wọ́n kú kalẹ̀ lọ lójú pópó,

àtàwọn ọdọmọbinrin, àtàwọn ọdọmọkunrin mi,

gbogbo wọn ni idà ti pa.

Ní ọjọ́ ibinu rẹ ni o pa wọ́n,

o pa wọ́n ní ìpakúpa láìṣàánú wọn.

22 O pe àwọn ọ̀tá mi jọ sí mi

bí ẹni peniyan síbi àjọ̀dún;

kò sì sí ẹni tí ó yè

ní ọjọ́ ibinu rẹ, OLUWA.

Ọ̀tá mi pa àwọn ọmọ mi run,

àwọn tí mo tọ́, tí mo sì fẹ́ràn.

Categories
ẸKÚN JEREMAYA

ẸKÚN JEREMAYA 3

Ìjìyà, Ìrònúpìwàdà ati Ìrètí

1 Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú,

tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán.

2 Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri.

3 Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí,

ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru.

4 Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun,

ó sì ti fọ́ egungun mi.

5 Ó dótì mí,

ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri.

6 Ó fi mí sinu òkùnkùn

bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.

7 Ó mọ odi yí mi ká,

ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí,

kí n má baà lè sálọ.

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́,

sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi.

9 Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi,

ó mú kí ọ̀nà mí wọ́.

10 Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀,

ó lúgọ bíi kinniun,

11 Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,

ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,

ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.

12 Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,

ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.

13 Ó mú gbogbo ọfà

tí ó wà ninu apó rẹ̀

ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.

14 Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́

lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,

ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.

15 Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,

ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.

16 Ó fẹnu mi gbolẹ̀,

títí yangí fi ká mi léyín;

ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku

17 Ọkàn mi kò ní alaafia,

mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.

18 Nítorí náà, mo wí pé,

“Ògo mi ti tán,

ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”

19 Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,

ati ìrora ọkàn mi!

20 Mò ń ranti nígbà gbogbo,

ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.

21 Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,

mo sì ní ìrètí.

22 Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun,

àánú rẹ̀ kò sì lópin;

23 ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀,

òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.

24 Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi,

nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”

25 OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,

tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.

26 Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.

27 Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe.

28 Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye,

nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn.

29 Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀,

bóyá ìrètí lè tún wà fún un.

30 Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí,

kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án.

31 Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae.

32 Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa,

yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu,

gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

33 Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára

tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí.

34 OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé,

35 kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo,

36 tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo.

37 Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀,

láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i?

38 Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo

ni rere ati burúkú ti ń jáde?

39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn

nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

40 Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò,

kí á tún ọ̀nà wa ṣe,

kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA.

41 Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè,

kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run:

42 “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun,

ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá.

43 “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù,

ò ń lépa wa,

o sì ń pa wá láì ṣàánú wa.

44 O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ,

tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ.

45 O ti sọ wá di ààtàn

ati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan.

46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára.

47 Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa.

48 Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi,

nítorí ìparun àwọn eniyan mi.

49 “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú mi

láì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi.

50 Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá,

tí yóo sì rí wa.

51 Ìbànújẹ́ bá mi,

nígbà tí mo rí ibi tí ó ṣẹlẹ̀

sí àwọn ọmọbinrin ìlú mi.

52 “Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí ń dọdẹ mi

bí ìgbà tí eniyan ń dọdẹ ẹyẹ.

53 Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè,

wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀.

54 Omi bò mí mọ́lẹ̀,

mo ní, ‘Mo ti gbé.’

55 “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn.

56 O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé,

‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’

57 O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́,

o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’

58 “OLUWA, o ti gba ìjà mi jà,

o ti ra ẹ̀mí mi pada.

59 O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi,

OLUWA, dá mi láre.

60 O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn,

ati gbogbo ète wọn lórí mi.

61 “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA,

ati gbogbo ète wọn lórí mi.

62 Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi:

ibi ni lojoojumọ.

63 Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó,

wọn ìbáà dìde dúró,

èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin.

64 “O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA,

gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

65 Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́,

kí ègún rẹ sì wà lórí wọn.

66 Fi ibinu lépa wọn, OLUWA,

sì pa wọ́n run láyé yìí.”

Categories
ẸKÚN JEREMAYA

ẸKÚN JEREMAYA 4

Jerusalẹmu, Lẹ́yìn Ìṣubú Rẹ̀

1 Wo bí wúrà ti dọ̀tí,

tí ojúlówó wúrà sì yipada;

tí àwọn òkúta Tẹmpili mímọ́ sì fọ́nká ní gbogbo ìkóríta.

2 Ẹ wo àwọn ọdọmọkunrin Sioni,

àwọn ọmọ tí wọn níye lórí bí ojúlówó wúrà,

tí a wá ń ṣe bí ìkòkò amọ̀;

àní, bí ìkòkò amọ̀ lásánlàsàn.

3 Àwọn ajáko a máa fún àwọn ọmọ wọn lọ́mú.

Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti di ìkà,

bí ògòǹgò inú aṣálẹ̀.

4 Ahọ́n ọmọ ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.

Àwọn ọmọde ń tọrọ oúnjẹ,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fún wọn.

5 Àwọn tí wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn

di ẹni tí ń ṣa ilẹ̀ jẹ kiri ní ìgboro.

Àwọn tí wọn tí ń fi aṣọ àlàárì bora

di ẹni tí ń sùn lórí òkítì eérú.

6 Ìjìyà àwọn eniyan mi pọ̀ ju ti àwọn ará Sodomu lọ,

Sodomu tí ó parun lójijì,

láìjẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn án.

7 Àwọn olórí wọn kò ní àléébù kankan,

Ọwọ́ wọn mọ́, inú wọn funfun nini,

wọ́n dára ju egbin lọ,

ẹwà wọn sì dàbí ẹwà iyùn.

8 Ṣugbọn nisinsinyii, ojú wọn dúdú ju èédú lọ,

kò sí ẹni tí ó dá wọn mọ̀ láàrin ìgboro,

awọ ara wọn ti hunjọ lórí egungun wọn,

wọ́n wá gbẹ bí igi.

9 Ti àwọn tí wọ́n kú ikú ogun sàn ju àwọn tí wọ́n kú ikú ebi lọ,

àwọn tí ebi pa joró dójú ikú,

nítorí àìsí oúnjẹ ninu oko.

10 Àwọn obinrin tí wọn ní ojú àánú ti fi ọwọ́ ara wọn se ọmọ wọn jẹ,

wọ́n fi ọmọ wọn ṣe oúnjẹ jẹ,

nígbà tí ìparun dé bá àwọn eniyan mi.

11 OLUWA bínú gidigidi,

ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ jáde.

OLUWA dá iná kan ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12 Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,

bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aráyé kò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀,

pé ọ̀tá lè wọ ẹnubodè Jerusalẹmu.

13 Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wolii rẹ̀ ló fa èyí,

ati àìdára àwọn alufaa rẹ̀,

tí wọ́n pa olódodo láàrin ìlú.

14 Wọ́n ń káàkiri bí afọ́jú láàrin ìgboro,

ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sọ wọ́n di aláìmọ́

tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè fọwọ́ kan aṣọ wọn.

15 Àwọn eniyan ń kígbe lé wọn lórí pé;

“Ẹ máa lọ! Ẹ̀yin aláìmọ́!

Ẹ máa kóra yín lọ! Ẹ má fi ọwọ́ kan nǹkankan!”

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe di ìsáǹsá ati alárìnkiri,

nítorí àwọn eniyan ń wí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè pé,

“Àwọn wọnyi kò gbọdọ̀ bá wa gbé pọ̀ mọ́.”

16 OLUWA fúnrarẹ̀ ti tú wọn ká,

kò sì ní náání wọn mọ́.

Kò ní bọlá fún àwọn alufaa wọn,

kò sì ní fi ojurere wo àwọn àgbààgbà.

17 A wọ̀nà títí ojú wa di bàìbàì,

asán ni ìrànlọ́wọ́ tí à ń retí jásí.

A wọ̀nà títí fún ìrànlọ́wọ́

lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbani là.

18 Àwọn eniyan ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa,

tóbẹ́ẹ̀ tí a kò lè rìn gaara ní ìgboro.

Ìparun wa súnmọ́lé,

ọjọ́ ayé wa ti níye,

nítorí ìparun wa ti dé.

19 Àwọn tí wọn ń lépa wa yára

ju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ.

Wọ́n ń lé wa lórí òkè,

wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀.

20 Ẹ̀mí àwa ẹni àmì òróró OLUWA bọ́ sinu kòtò wọn,

OLUWA tí à ń sọ nípa rẹ̀ pé,

lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni a óo máa gbé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

21 Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin ará Edomu,

tí ń gbé ilẹ̀ Usi.

Ṣugbọn ife náà yóo kọjá lọ́dọ̀ yín,

ẹ óo mu ún ní àmuyó,

ẹ óo sì tú ara yín síhòòhò.

22 Ẹ ti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín ní àjẹpé,

ẹ̀yin ará Sioni,

OLUWA kò ní fi yín sílẹ̀ ní ìgbèkùn mọ́.

Ṣugbọn yóo jẹ ẹ̀yin ará Edomu níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín,

yóo tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

Categories
ẸKÚN JEREMAYA

ẸKÚN JEREMAYA 5

Adura fún Àánú

1 OLUWA, ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa,

Ṣe akiyesi ẹ̀sín wa.

2 Àwọn ilẹ̀ àjogúnbá ẹni ẹlẹ́ni,

ilé wa sì ti di ti àwọn àjèjì.

3 A ti di aláìníbaba, ọmọ òrukàn

àwọn ìyá wa kò yàtọ̀ sí opó.

4 Owó ni a fi ń ra omi tí à ń mu,

rírà ni a sì ń ra igi tí a fi ń dáná.

5 Àwọn tí wọn ń lépa wa ti bá wa,

ó ti rẹ̀ wá, a kò sì ní ìsinmi.

6 A ti fa ara wa kalẹ̀ fún àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Asiria

nítorí oúnjẹ tí a óo jẹ.

7 Àwọn baba wa ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀, àwọn sì ti kú,

ṣugbọn àwa ni à ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8 Àwọn ẹrú ní ń jọba lé wa lórí,

kò sì sí ẹni tí yóo gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9 Ẹ̀mí wa ni à ń fi wéwu, kí á tó rí oúnjẹ,

nítorí ogun tí ó wà ninu aṣálẹ̀.

10 Awọ ara wa gbóná bí iná ààrò,

nítorí ìyàn tí ó mú lọpọlọpọ.

11 Tipátipá ni wọ́n fi ń bá àwọn obinrin lòpọ̀ ní Sioni,

ati àwọn ọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin ní Juda.

12 Wọ́n fi okùn so ọwọ́ àwọn olórí rọ̀,

wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbààgbà.

13 Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ,

àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn!

14 Àwọn àgbààgbà ti sá kúrò ní ẹnubodè;

àwọn ọdọmọkunrin sì ti dákẹ́ orin kíkọ.

15 Inú wa kò dùn mọ́;

ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀.

16 Adé ti ṣíbọ́ lórí wa!

A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀,

17 nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì;

ojú wa sì ti di bàìbàì.

18 Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro;

tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀.

19 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé,

ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran.

20 Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata?

Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́?

21 Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA,

kí á lè pada sí ipò wa.

Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada.

22 Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni?

Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀?

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa (586 B.C.), ni ogun kó Jerusalẹmu. Wolii Isikiẹli wà ní ìgbèkùn ní Babiloni ní ọdún bíi mélòó kan ṣáájú àkókò yìí, ati lẹ́yìn rẹ̀. Ìpín mẹfa pataki ni ó wà ninu

Ìwé Isikiẹli

: (1) Ìpè Isikiẹli sí iṣẹ́ wolii. (2) Àwọn ìkìlọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn eniyan náà ati nípa ìṣubú ati ìparun Jerusalẹmu. (3) Ìdájọ́ OLUWA lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ni àwọn eniyan OLUWA lára, ati àwọn tí wọ́n ṣì wọ́n lọ́nà. (4) Lẹ́yìn tí ogun kó Jerusalẹmu, OLUWA ranṣẹ ìtùnú sí àwọn eniyan rẹ̀ ó sì ṣèlérí pé ọjọ́ iwájú yóo dára. (5) Àsọtẹ́lẹ̀ ibi nípa Gogu. (6) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Tẹmpili tí wọn yóo tún kọ́ yóo ti rí, ati pé ó gbọdọ̀ wà ní mímọ́.

Isikiẹli jẹ́ ẹni tí ó ní igbagbọ tó jinlẹ̀ ati òye tó ga. Ọ̀pọ̀ ninu awọn àròfín rẹ̀ ni ó wá nipa ìran, tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ eyi tí a ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ninu ìṣe alápẹẹrẹ tó fi ara hàn gbangba. Isikiẹli tẹnumọ ṣíṣe pataki lati ní ọkàn ati ẹ̀mí titun, ati pé olúkúlùkù ni yóò dáhùn fun ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. Bakan náà ni ó kéde ìrètí rẹ̀ fun ìmúdọ̀tun ìgbé-ayé orilẹ-èdè Israeli. Gẹ́gẹ́ bí alufaa ati wòlíì, ó ní ìfẹ́ pataki fun Tẹmpili ati bí a ṣe nilo lati gbé ìgbé-ayé ìwà mímọ́.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọlọrun pe Isikiẹli 1:1–3:27

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun tí yóo dé bá Jerusalẹmu 4:1–24:27

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn orílẹ̀-èdè 25:1–32:32

Ìlérí Ọlọrun nípa àwọn eniyan rẹ̀ 33:1–37:28

Àsọtẹ́lẹ̀ ibi nípa Gogu 38:1–39:29

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Tẹmpili ati ilẹ̀ náà ní ọjọ́ iwájú yóo ti rí 40:1–48:35

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 1

Ìtẹ́ Ọlọrun

1 Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹrin, ní ọgbọ̀n ọdún, èmi, Isikiẹli, ọmọ Busi, wà láàrin àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Babiloni. A wà lẹ́bàá odò Kebari, mo bá rí i tí ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀; mo sì rí ìran Ọlọrun.

2 Lọ́jọ́ karun-un oṣù náà, tíí ṣe ọdún karun-un tí wọ́n ti mú ọba Jehoiakini lọ sí ìgbèkùn,

3 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára.

4 Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà.

5 Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan.

6 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin.

7 Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ.

8 Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin.

9 Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ.

10 Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn.

11 Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora.

12 Olukuluku kọjú sí ìhà mẹrin, ó sì lè lọ tààrà sí ìhà ibi tí ẹ̀mí rẹ̀ bá darí sí láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada kí ó tó máa lọ.

13 Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà.

14 Àwọn ẹ̀dá alààyè náà ń já lọ sókè sódò bí ìgbà tí manamana bá ń kọ.

15 Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, àgbá kọ̀ọ̀kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan.

16 Ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ati bí a ti ṣe wọ́n nìyí: wọ́n ń dán yànrànyànràn bí òkúta kirisolite. Bákan náà ni àwọn mẹrẹẹrin rí. A ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí ìgbà tí àgbá meji bá wọ inú ara wọn.

17 Bí wọ́n ti ń lọ, ìhà ibi tí wọn bá fẹ́ ninu ìhà mẹrẹẹrin ni wọ́n lè máa lọ láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yíjú pada, kí wọ́n tó máa lọ.

18 (Àgbá mẹrẹẹrin ní irin tẹẹrẹtẹẹrẹ tí ó so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀). Wọ́n ga, wọ́n ba eniyan lẹ́rù. Àwọn àgbá mẹrẹẹrin ní ojú yíká wọn.

19 Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ti ń lọ ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a máa yí tẹ̀lé wọn, bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá gbéra nílẹ̀ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì gbéra nílẹ̀ pẹlu.

20 Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ ni àwọn ẹ̀dá náà máa ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì máa yí lọ pẹlu wọn, nítorí pé ninu àwọn àgbá náà ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà.

21 Bí wọn bá ń lọ àwọn àgbá náà a máa yí lọ pẹlu wọn. Bí wọ́n bá dúró àwọn àgbá náà a dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn àgbá náà a gbéra nílẹ̀, nítorí pé ninu àwọn àgbá wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà.

22 Kinní kan bí awọsanma tí ó ń dán bíi Kristali wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó tàn bo gbogbo orí wọn.

23 Lábẹ́ kinní bí awọsanma yìí ni àwọn ìyẹ́ wọn ti nà jáde, wọ́n kan ara wọn, àwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ìyẹ́ meji meji tí wọ́n fi bora.

24 Bí wọ́n ti ń lọ, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn, ó dàbí ariwo odò ńlá, bí ààrá Olodumare, bí ariwo ìdágìrì ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Bí wọ́n bá dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀,

25 nǹkankan a sì máa dún lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn. Bí wọn bá ti dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀.

26 Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà.

27 Mo wò ó láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó rí bíi bàbà dídán, ó dàbí iná yíká. Mo wò ó láti ibi ìbàdí lọ sí ìsàlẹ̀, ó dàbí iná. Ìmọ́lẹ̀ sì wà ní gbogbo àyíká rẹ̀.

28 Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí.

Ọlọrun Pe Isikiẹli Láti jẹ́ Wolii

Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo bá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ń sọ̀rọ̀.

Categories
ISIKIẸLI

ISIKIẸLI 2

1 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, dìde dúró, mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”

2 Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí OLUWA wọ inú mi, ó gbé mi nàró, mo sì gbọ́ bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀.

3 Ó ní, “Ọmọ eniyan, mo rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, orílẹ̀-èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Àwọn ati àwọn baba ńlá wọn ṣì tún ń bá mi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.

4 Aláfojúdi ati olóríkunkun ẹ̀dá ni wọ́n. Mò ń rán ọ sí wọn kí o lè sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun wí fún wọn.

5 Bí wọn bá fẹ́ kí wọn gbọ́, bí wọn sì fẹ́, kí wọn má gbọ́. (Nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n), ṣugbọn wọn yóo mọ̀ pé Wolii kan ti wà láàrin wọn.

6 “Ṣugbọn ìwọ ọmọ eniyan, má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́, má sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún ọ̀gàn ati ẹ̀wọ̀n agogo yí ọ ká, tí o sì jókòó láàrin àwọn àkeekèé, má ṣe bẹ̀rù ohunkohun tí wọn bá wí. Má jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

7 O óo sọ ohun tí mo bá wí fún wọn, wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má gbọ́; nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n.

8 “Ṣugbọn ìwọ, ọmọ eniyan, fetí sí ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má dìtẹ̀ bí àwọn ọmọ ìdílé ọlọ̀tẹ̀ wọnyi. La ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí n óo fún ọ.”

9 Nígbà tí mo wò, mo rí ọwọ́ tí ẹnìkan nà sí mi, ìwé kan tí a ká sì wà ninu rẹ̀.

10 Ó tẹ́ ìwé náà siwaju mi; mo sì rí i pé wọ́n kọ nǹkan sí i ní àtojú àtẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ ẹkún, ati ọ̀rọ̀ ọ̀fọ̀, ati ègún ni wọ́n kọ sinu rẹ̀.