Categories
AISAYA

AISAYA 19

Ọlọrun Yóo Jẹ Ijipti Níyà

1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí:

OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti.

Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀,

ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.

2 N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti,

olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà,

àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà,

ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji,

ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn.

3 Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti,

n óo sọ ète wọn di òfo.

Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹ

ati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.

4 Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́

ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí,

bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.

5 Omi odò Naili yóo gbẹ,

yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀.

6 Gbogbo odò wọn yóo máa rùn,

gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti,

ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ:

Gbogbo koríko odò yóo rà.

7 Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀,

gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ,

ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù.

8 Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Naili

yóo ṣọ̀fọ̀,

wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn;

àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora.

9 Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun,

ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun.

10 Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀,

ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe.

11 Òmùgọ̀ ni àwọn olórí wọn ní Soani;

ìmọ̀ràn wèrè sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbìmọ̀ Farao ń fún eniyan.

Báwo ni eniyan ṣe lè sọ fún Farao pé,

“Ọmọ Ọlọ́gbọ́n eniyan ni mí,

ọmọ àwọn ọba àtijọ́.”

12 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ dà?

Níbo ni wọ́n wà kí wọ́n sọ fún ọ,

kí wọ́n sì fi ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti ṣe sí Ijipti hàn ọ́.

13 Àwọn olórí wọn ní Soani ti di òmùgọ̀,

àwọn olórí wọn ní Memfisi sì ti gba ẹ̀tàn;

àwọn tí wọ́n jẹ́ òpómúléró ní ilẹ̀ Ijipti ti ṣi Ijipti lọ́nà.

14 OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn,

wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀,

bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀.

15 Kò sí nǹkankan tí ẹnìkan lè ṣe fún Ijipti,

kì báà jẹ́ ọlọ́lá tabi mẹ̀kúnnù,

kì báà jẹ́ eniyan pataki tabi ẹni tí kò jẹ́ nǹkan.

Ijipti Yóo Sin OLUWA

16 Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú.

17 Ilẹ̀ Juda yóo di ẹ̀rù fún àwọn ará Ijipti, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóo bẹ̀rù nítorí ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu láti ṣe sí Ijipti.

18 Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun.

Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn.

19 Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA láàrin ilẹ̀ Ijipti, ọ̀wọ̀n OLUWA kan yóo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ààlà ilẹ̀ rẹ̀.

20 Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn.

21 OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.

22 OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.

23 Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria.

24 Ní àkókò náà, Israẹli yóo ṣìkẹta Ijipti ati Asiria, wọn yóo sì jẹ́ ibukun lórí ilẹ̀ fún àwọn ará Ijipti, àwọn eniyan mi.

25 Tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti súre fún pé, “Ibukun ni fún Ijipti, àwọn eniyan mi, ati fún Asiria tí mo fi ọwọ́ mi dá, ati fún Israẹli ìní mi.”

Categories
AISAYA

AISAYA 20

Àmì Wolii tó Wà Níhòhò

1 Ní ọdún tí Sagoni, ọba Asiria, rán olórí ogun rẹ̀ pé kí ó lọ bá ìlú Aṣidodu jagun, tí ó gbógun ti ìlú náà, tí ó sì gbà á,

2 OLUWA sọ fún Aisaya ọmọ Amosi pé, “Dìde, bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ tí o lọ́ mọ́ra, sì bọ́ bàtà tí o wọ̀ sí ẹsẹ̀.” Aisaya bá ṣe bí OLUWA ti wí: ó bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ lára, ó sì bọ́ bàtà kúrò lẹ́sẹ̀. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà.

3 Lẹ́yìn ọdún mẹta, OLUWA dáhùn pé, “Bí Aisaya, iranṣẹ mi, ti rìn ní ìhòòhò tí kò sì wọ bàtà fún ọdún mẹta yìí, jẹ́ àmì ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kuṣi:

4 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria yóo ṣe kó àwọn ará Ijipti ati àwọn ará Kuṣi lẹ́rú, ati ọmọde ati àgbàlagbà wọn, ní ìhòòhò, láì wọ bàtà. A óo bọ́ aṣọ kúrò lára wọn, kí ojú ó lè ti Ijipti.

5 Ìbẹ̀rù-bojo yóo dé ba yín, ojú yóo sì tì yín; nítorí Kuṣi ati Ijipti tí ẹ gbójú lé.

6 Àwọn tí ń gbé etí òkun ilẹ̀ yìí yóo wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ẹ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a gbójú lé, àwọn tí à ń sá tọ̀ lọ pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n gbà wá lọ́wọ́ ọba Asiria. Báwo ní àwa óo ṣe wá là báyìí?’ ”

Categories
AISAYA

AISAYA 21

Ìran nípa Ìṣubú Babiloni

1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí:

àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀,

láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù,

ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀.

2 Ìran tí a fi hàn mí yìí le:

Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun,

abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́.

Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ!

Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun!

Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan.

3 Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí,

gbogbo ara ní ń ro mí

bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.

A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan,

wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran.

4 Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí;

wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́.

5 Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀

wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu.

Ariwo bá ta pé

“Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun!

Ẹ fepo pa asà yín.”

6 Nítorí OLUWA wí fún mi pé:

“Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà,

kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí.

7 Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣin

tí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí i

tí àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

tí àwọn kan gun ràkúnmí,

kí ó fara balẹ̀ dáradára,

kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.”

8 Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé:

“OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ,

níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru.

9 Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀,

wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!”

“Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó!

Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀,

ó ti wó lulẹ̀ patapata.”

10 Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀,

bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà,

ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun,

Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu

11 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu nìyí:

Ẹnìkan ń pè mí láti Seiri

Ó ní: “Aṣọ́nà, Òru ti rí o?

Aṣọ́nà, àní òru ti rí?”

12 Aṣọ́nà bá dáhùn, ó ní:

“Ilẹ̀ ń ṣú, ilẹ̀ sì ń mọ́.

Bí ẹ bá tún fẹ́ bèèrè,

ẹ pada wá, kí ẹ tún wá bèèrè.”

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia

13 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia nìyí:

Ninu igbó Arabia ni ẹ óo sùn, ẹ̀yin èrò ará Didani.

14 Ẹ bu omi wá fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ.

Ẹ gbé oúnjẹ pàdé ẹni tí ń sá fógun, ẹ̀yin ará ilẹ̀ Tema.

15 Wọ́n ń sá fún idà,

wọ́n sá fún idà lójú ogun.

Wọ́n ń sá fún àwọn tafàtafà,

wọ́n sá fún líle ogun.

16 OLUWA sọ fún mi pé, “Kí ó tó tó ọdún kan, ní ìwọ̀n ọdún alágbàṣe kan, gbogbo ògo Kedari yóo dópin;

17 díẹ̀ ni yóo sì kù ninu àwọn tafàtafà alágbára ọmọ Kedari; nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
AISAYA

AISAYA 22

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu

1 Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran:

Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ,

2 ẹ̀yin tí ìlú yín kún fún ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá?

Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun.

3 Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ,

láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn.

Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà.

4 Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé,

“Ẹ ṣíjú kúrò lára mi

ẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò,

ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún,

nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.”

5 Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,

ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran.

Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀

ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá.

6 Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká,

pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin,

àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn.

7 Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogun

àwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè;

8 ó ti tú aṣọ lára Juda.

Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó,

9 ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ.

10 Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe.

11 Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá.

12 Ní ọjọ́ náà,

OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé,

kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀,

kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

13 Ṣugbọn dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀,

ẹ̀ ń yọ̀, inú yín ń dùn.

Ẹ̀ ń pa mààlúù, ẹ̀ ń pa aguntan,

ẹ̀ ń jẹ ẹran, ẹ̀ ń mu ọtí waini.

Ẹ̀ ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu!

Nítorí pé lọ́la ni a óo kú.”

14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé:

“A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yín

títí tí ẹ óo fi kú.”

Ìkìlọ̀ fún Ṣebina

15 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé:

16 ‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta?

17 Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá.

18 Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ.

19 N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’

20 “Ní ọjọ́ náà, n óo pe Eliakimu, iranṣẹ mi, ọmọ Hilikaya.

21 N óo gbé aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n óo sì dì í ní àmùrè rẹ; n óo gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́, yóo sì di baba fún àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda.

22 N óo fi í ṣe alákòóso ilé Dafidi. Ìlẹ̀kùn tí ó bá ṣí, kò ní sí ẹni tí yóo lè tì í; èyí tí ó bá tì, kò ní sí ẹni tí yóo lè ṣí i.

23 N óo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí èèkàn tí a kàn mọ́ ilẹ̀ tí ó le, yóo di ìtẹ́ iyì fún ilé baba rẹ̀.

24 “Gbogbo ẹbí rẹ̀ ní agboolé baba rẹ̀ yóo di ẹrú rẹ̀, ati àwọn ọmọ ati àwọn ohun èlò, láti orí ife ìmumi, títí kan ìgò ọtí.”

25 OLUWA àwọn ọmọ-ogun ní, “Ní ọjọ́ náà, èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gbọningbọnin yóo yọ, wọn yóo gé e, yóo sì wó lulẹ̀, ẹrù tí wọn fi kọ́ lórí rẹ̀ yóo sì já dànù.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.

Categories
AISAYA

AISAYA 23

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire

1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire nìyí:

Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọlọ́kọ̀ ojú omi ìlú Taṣiṣi;

nítorí pé Tire ti di ahoro,

láìsí ilé tabi èbúté!

Ní ilẹ̀ Kipru ni a ti fi eléyìí hàn wọ́n.

2 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,

ẹ̀yin oníṣòwò ará Sidoni;

àwọn iranṣẹ yín ti kọjá sí òdìkejì òkun,

3 wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ.

Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori,

ìkórè etí odò Naili.

Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé.

4 Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoni

nítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:

“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;

n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà rí

kì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”

5 Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijipti

àwọn ará Ijipti yóo kérora.

6 Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi.

Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,

ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun.

7 Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,

tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!

Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,

tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ!

8 Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,

Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?

Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;

gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.

9 OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,

ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.

10 Ẹ̀yin ará Taṣiṣi,

ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili,

kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́.

11 OLUWA ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun

Ó ti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì.

Ó ti pàṣẹ nípa ilẹ̀ Kenaani

pé kí wọ́n pa gbogbo ibi ààbò rẹ̀ run.

12 Ó ní, “Àríyá yín ti dópin,

ẹ̀yin ọmọ Sidoni tí à ń ni lára.

Ò báà dìde kí o lọ sí Kipru,

ara kò ní rọ̀ ọ́ níbẹ̀.”

13 Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro.

14 Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi, nítorí àwọn ilé ìṣọ́ yín tí ó lágbára ti wó.

15 Nígbà, tó bá yá, Tire yóo di ìgbàgbé fún aadọrin ọdún gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ ọba kan; lẹ́yìn aadọrin ọdún ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Tire yóo dàbí orin kan tí àwọn aṣẹ́wó máa ń kọ pé:

16 “Mú hapu, kí o máa káàkiri ààrin ìlú,

ìwọ aṣẹ́wó, ẹni ìgbàgbé.

Máa kọ orin dídùn ní oríṣìíríṣìí,

kí á lè ranti rẹ.”

17 Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, OLUWA yóo ranti Tire. Yóo pada sídìí òwò aṣẹ́wó rẹ̀, yóo sì máa bá gbogbo ìjọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe òwò àgbèrè.

18 Yóo ya ọjà tí ó ń tà ati èrè tí ó bá jẹ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò ní máa to èrè rẹ̀ jọ, tabi kí ó máa kó o pamọ́; ṣugbọn yóo máa lò wọ́n láti pèsè oúnjẹ ati aṣọ fún àwọn tí ó bá ń sin OLUWA.

Categories
AISAYA

AISAYA 24

OLUWA Yóo Jẹ Ilẹ̀ Ayé Níyà

1 Ẹ wò ó! OLUWA yóo fọ́ gbogbo ayé wómúwómú

yóo sì sọ ọ́ di ahoro.

Yóo dojú rẹ̀ rú,

yóo sì fọ́n àwọn eniyan inú rẹ̀ ká.

2 Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìlú ni yóo ṣẹlẹ̀ sí alufaa;

ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú yóo ṣẹlẹ̀ sí olówó rẹ̀;

ohun tí ó ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ ni yóo ṣe ọ̀gá rẹ̀;

ohun tí ó ṣe ẹni tí ń rà ni yóo ṣe ẹni tí ń tà.

Ohun tí ó ṣe ẹni tí ń yá ni lówó

ni yóo ṣe ẹni tí à ń yá lówó.

Ohun tí ó ṣe onígbèsè ni yóo ṣe ẹni tí a jẹ lówó.

3 Ogun yóo kó ilé ayé,

yóo di òfo patapata.

Nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

4 Ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo nǹkan ń rọ.

Ayé ń joró, ó sì ń ṣá

àwọn ọ̀run ń joró pẹlu.

5 Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́,

nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfin

wọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànà

wọ́n sì da majẹmu ayérayé.

6 Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ.

Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀,

eniyan díẹ̀ ni ó sì kù.

7 Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀.

Igi èso àjàrà ń joró,

gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn.

8 Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́,

ariwo àwọn alárìíyá ti dópin.

Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró.

9 Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́

ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún.

10 Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo,

gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé.

11 Ariwo ta lóde nítorí kò sí ọtí waini,

oòrùn ayọ̀ ti wọ̀;

ayọ̀ di àwátì ní ilẹ̀ náà.

12 Gbogbo ìlú ti di ahoro,

wọ́n ti wó ẹnu ibodè ìlú wómúwómú.

13 Bẹ́ẹ̀ ní yóo rí ní ilẹ̀ ayé,

láàrin àwọn orílẹ̀-èdè

bí igi olifi tí a ti gbọn gbogbo èso rẹ̀ sílẹ̀,

lẹ́yìn tí a ti kórè tán ninu ọgbà àjàrà.

14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ń kọrin ayọ̀,

wọ́n ń yin OLUWA lógo láti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá.

15 Nítorí náà ẹ fi ògo fún OLUWA ní ìhà ìlà-oòrùn;

ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,

ẹ fògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

16 Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn,

wọ́n ń fi ògo fún Olódodo.

Ṣugbọn èmi sọ pé:

“Mò ń rù, mò ń joro,

mò ń joro, mo gbé!

Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,

wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.”

17 Ẹ̀rù ati kòtò, ati tàkúté ń bẹ níwájú yín ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ ayé.

18 Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá,

yóo já sinu kòtò,

ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtò

yóo kó sinu tàkúté.

Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí,

àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì.

19 Ayé ti fọ́, ayé ti fàya,

ayé sì mì tìtì.

20 Ayé ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí,

ó ń mì bí abà oko.

Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́rùn,

ó wó lulẹ̀, kò ní dìde mọ́.

21 Ní àkókò náà,

OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ogun ọ̀run, lọ́run;

ati àwọn ọba ayé, lórí ilẹ̀ ayé.

22 A óo gbá gbogbo wọn jọ pọ̀ sinu kòtò bí ẹlẹ́wọ̀n,

wọn óo wà ní àtìmọ́lé ninu ẹ̀wọ̀n.

Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, a óo fìyà jẹ wọ́n.

23 Òṣùpá yóo dààmú,

ìtìjú yóo sì bá oòrùn.

Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọba

lórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu.

Yóo sì fi ògo rẹ̀ hàn

níwájú àwọn àgbààgbà wọn.

Categories
AISAYA

AISAYA 25

Orin Ìyìn

1 OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi.

N óo gbé ọ ga:

n óo yin orúkọ rẹ.

Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu,

o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́,

o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.

2 O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpà

o sì ti pa àwọn ìlú olódi run.

O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú,

ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́.

3 Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́

ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ.

4 Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka,

ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro.

Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò,

ati ìbòòji ninu oòrùn.

Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiri

bẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí;

5 ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀.

O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́;

bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu.

Ọlọrun se Àsè Ńlá

6 OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára.

7 Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.

8 Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

9 Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.”

Ọlọrun Yóo Jẹ Moabu Níyà

10 Nítorí OLUWA yóo na ọwọ́ ààbò rẹ̀ sórí òkè yìí. Ṣugbọn àwọn ará Moabu yóo di àtẹ̀mọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ wọ́n, bíi koríko tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ lórí ààtàn.

11 Wọn óo na ọwọ́ ní ààrin rẹ̀ bí ìgbà tí ẹni tí ń lúwẹ̀ẹ́ bá nawọ́ ninu omi. Ṣugbọn OLUWA yóo rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀, ọwọ́ wọn yóo sì rọ.

12 OLUWA yóo bi odi gíga rẹ̀ wó, yóo wó o palẹ̀, yóo sì sọ ọ́ di erùpẹ̀ ilẹ̀.

Categories
AISAYA

AISAYA 26

Orin Ìgbàlà

1 Ní àkókò náà,

orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé:

“A ní ìlú tí ó lágbára,

ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò.

2 Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè,

kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé.

3 O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé,

nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4 Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae,

nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun.

5 Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀,

ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀,

ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata,

ó fà á sọ sinu eruku.

6 Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,

bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.”

7 Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodo

ó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán.

8 Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA,

orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́.

9 Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́,

mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọ

nítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyé

ni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo.

10 Bí a bá ṣàánú ẹni ibi,

kò ní kọ́ láti ṣe rere.

Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo,

kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA.

11 OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà,

ṣugbọn wọn kò rí i.

Jẹ́ kí wọn rí i pé

ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún,

kí ojú sì tì wọ́n.

Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.

12 OLUWA ìwọ yóo fún wa ní alaafia,

nítorí pé ìwọ ni o ṣe gbogbo iṣẹ́ wa fún wa.

13 OLUWA, Ọlọrun wa,

àwọn oluwa mìíràn ti jọba lórí wa

ṣugbọn orúkọ rẹ nìkan ni àwa mọ̀.

14 Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́,

ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú.

Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà,

o sì pa wọ́n run,

o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé.

15 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i,

OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà,

gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn,

o sì ti buyì kún ara rẹ.

16 OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ,

wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà.

17 Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ,

tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora,

nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsí

bẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA.

18 A wà ninu oyún, ara ń ro wá,

a ní kí a bí, òfo ló jáde.

A kò ṣẹgun ohunkohun láyé

bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú.

19 Àwọn òkú wa yóo jí,

wọn óo dìde kúrò ninu ibojì.

Ẹ tají kí ẹ máa kọrin,

ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀.

Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín,

ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.

Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò

20 Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,

ẹ wọ inú yàrá yín,

kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí;

ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀,

títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá.

21 OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀,

láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde,

kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́.

Categories
AISAYA

AISAYA 27

1 Ní ọjọ́ náà,

OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára,

pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò,

Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké,

yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun.

2 Ní ọjọ́ náà,

OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé,

3 “Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀,

lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín;

tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọ

kí ẹnìkan má baà bà á jẹ́.

4 Inú kò bí mi,

ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀,

ǹ bá gbógun tì wọ́n,

ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀.

5 Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò,

kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa;

kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.”

6 Ní ọjọ́ iwájú

Jakọbu yóo ta gbòǹgbò,

Israẹli yóo tanná, yóo rúwé,

yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé.

7 Ṣé OLUWA ti jẹ wọ́n níyà bí ó ti fìyà jẹ àwọn tí ó jẹ wọ́n níyà?

Ṣé ó ti pa wọ́n bí ó ti pa àwọn tí ó pa wọ́n?

8 OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀,

ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn;

ó lé wọn jáde ní ìlú,

bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn.

9 Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́,

tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé:

Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú,

bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná;

kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró.

10 Nítorí ìlú olódi ti di ahoro,

ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù;

ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko,

wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀.

11 Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dá

nígbà tí wọ́n bá gbẹ,

àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná.

Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá;

nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn,

Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn.

12 Ní ọjọ́ náà,

OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà,

láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti,

yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

13 Ní ọjọ́ náà,

a óo fun fèrè ogun ńlá,

àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria

ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti

yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Categories
AISAYA

AISAYA 28

Ìkìlọ̀ fún Ilẹ̀ Israẹli

1 Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé!

Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé!

Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,

ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó.

2 Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,

tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,

bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbára

tí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;

ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀.

3 Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéraga

àwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu.

4 Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdó

tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,

yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,

tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.

Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,

yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́.

5 Ní ọjọ́ náà,

OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,

fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀.

6 Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́

fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́,

yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè.

Aisaya ati Àwọn Ọ̀mùtí Wolii Ilẹ̀ Juda.

7 Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi,

ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii,

ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.

Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n;

wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́.

8 Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,

gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí

9 Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n?

Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún?

Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn,

àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?

10 Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni,

èyí òfin, tọ̀hún ìlànà.

Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”

11 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lò

láti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀.

12 Àwọn tí ó ti wí fún pé:

Ìsinmi nìyí,

ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi;

ìtura nìyí.

Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.

13 Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin,

èyí òfin tọ̀hún ìlànà.

Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,

kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn

kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́;

kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn,

kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.

Òkúta Igun Ilé fún Sioni

14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,

ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,

tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.

15 Nítorí ẹ wí pé:

“A ti bá ikú dá majẹmu,

a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn.

Nígbà tí jamba bá ń bọ̀,

kò ní dé ọ̀dọ̀ wa;

nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,

a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”

16 Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé,

“Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni,

yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára,

òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú:

Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an.

17 Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀,

òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.”

Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù,

omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.

18 Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo,

àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán.

Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri,

yóo máa dé ba yín.

19 Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀

ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ.

Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀,

yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru.

Ẹ̀rù yóo ba eniyan,

tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà.

20 Ibùsùn kò ní na eniyan tán.

Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora.

21 Nítorí pé OLUWA yóo dìde

bí ó ti ṣe ní òkè Firasi,

yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.

Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,

ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;

yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀

iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.

22 Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,

kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.

Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,

tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.

Ọgbọ́n Ọlọrun

23 Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,

ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

24 ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìn

lè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?

Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?

25 Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,

ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,

kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;

kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,

kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀?

26 Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,

nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.

27 Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini.

Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí;

igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini.

28 Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi?

Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró.

Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó,

ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná.

29 Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu,

ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu;

ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ.