Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 23

1 Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,

kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára.

2 Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra,

kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun.

3 Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú,

nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn.

-7-

4 Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ,

fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.

5 Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ,

ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò,

bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.

-8-

6 Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun,

má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀;

7 nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni.

Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!”

ṣugbọn kò dé inú rẹ̀.

8 O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ,

gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù.

-9-

9 Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,

nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.

-10-

10 Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́,

má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;

11 nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára,

yóo gba ìjà wọn jà.

-11-

12 Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

-12-

13 Bá ọmọde wí;

bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú.

14 Bí o bá fi pàṣán nà án,

o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú.

-13-

15 Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n,

inú mi yóo dùn.

16 N óo láyọ̀ ninu ọkàn mi

nígbà tí o bá ń sọ òtítọ́.

-14-

17 Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo.

18 Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára,

ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.

-15-

19 Fetí sí mi, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,

darí ọkàn rẹ sí ọ̀nà títọ́.

20 Má bá àwọn ọ̀mùtí kẹ́gbẹ́;

tabi àwọn wọ̀bìà, tí wọn ń jẹ ẹran ní àjẹkì;

21 nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka,

oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà.

-16-

22 Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ,

má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i.

23 Ra òtítọ́, má sì tà á,

ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu.

24 Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ,

inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn.

25 Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn,

jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ.

-17-

26 Ọmọ mi, gbọ́ tèmi,

kí o sì máa kíyèsí ọ̀nà mi.

27 Nítorí aṣẹ́wó dàbí ọ̀fìn jíjìn,

obinrin onírìnkurìn sì dàbí kànga tí ó jìn.

28 A máa ba níbùba bí olè,

a sì máa sọ ọpọlọpọ ọkunrin di alágbèrè.

-18-

29 Ta ló ni òṣì? Ta ló ni ìbànújẹ́?

Ta ló ni ìjà? Ta ló ni asọ̀?

Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú pípọ́n koko?

30 Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni,

àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.

31 Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra,

nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife,

tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.

32 Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò,

oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.

33 Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì,

ọkàn rẹ á máa ro èròkerò.

34 O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun,

bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀.

35 O óo wí pé, “Wọ́n lù mi, ṣugbọn kò dùn mí;

wọ́n nà mí, ṣugbọn ń kò mọ̀.

Nígbà wo ni n óo tó jí?

N óo tún wá ọtí mìíràn mu.”

-19-

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 24

1 Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi,

má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́,

2 nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ìparun,

ẹnu wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìkà.

-20-

3 Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé,

òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

4 Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kó

oniruuru nǹkan ìní dáradára

olówó iyebíye

kún àwọn yàrá rẹ̀

-21-

5 Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ,

ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ.

6 Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun,

ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.

-22-

7 Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀,

kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ.

-23-

8 Ẹni tí ń pète àtiṣe ibi

ni a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi.

9 Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,

ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.

24

10 Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,

a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.

-25-

11 Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,

fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,

lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.

12 Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀,

ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i?

Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀,

àbí kò ní san án fún eniyan

gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?

-26-

13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,

oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.

14 Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ,

bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,

ìrètí rẹ kò sì ní di asán.

-27-

15 Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,

má fọ́ ilé rẹ̀.

16 Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde,

ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú.

-28-

17 Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú,

má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀,

18 kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ,

kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ.

-29-

19 Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi,

má sì ṣe jowú eniyan burúkú,

20 nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi,

a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú.

-30-

21 Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,

má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;

22 nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,

ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?

Àfikún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Tẹ̀síwájú sí i

23 Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:

Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.

24 Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,

àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,

àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.

25 Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,

ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.

26 Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́

dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.

27 Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta,

tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ,

lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28 Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí,

má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde.

29 Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi,

bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i,

n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.”

30 Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá,

mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye.

31 Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo,

igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀,

ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó.

32 Mo ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo ṣàkíyèsí,

mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí mo rí.

33 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,

ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,

34 bẹ́ẹ̀ ni òṣì yóo ṣe dé bá ọ

bíi kí olè yọ sí eniyan,

àìní yóo sì wọlé tọ̀ ọ́ bí ẹni tí ó di ihamọra ogun.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 25

Àwọn Òwe Mìíràn tí Solomoni Pa

1 Àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa,

tí àwọn òṣìṣẹ́ Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nìwọ̀nyí.

2 Ògo ni ó jẹ́ fún Ọlọrun láti fi nǹkan pamọ́,

ṣugbọn ògo ló sá tún jẹ́ fún ọba

láti wádìí nǹkan ní àwárí.

3 Bí ọ̀run ti ga, tí ilẹ̀ sì jìn,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọba.

4 Yọ́ gbogbo ìdọ̀tí tí ó wà lára fadaka kúrò,

alágbẹ̀dẹ yóo sì rí fadaka fi ṣe ohun èlò.

5 Mú àwọn olùdámọ̀ràn ibi kúrò lọ́dọ̀ ọba,

a óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu òdodo.

6 Má ṣe gbéraga níwájú ọba,

tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki,

7 nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé,

“Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”,

jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.

8 Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,

nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.

9 Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyàn

má ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,

10 kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,

kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.

11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹ

dàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.

12 Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà,

tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe,

fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.

13 Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè,

bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an,

a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.

14 Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títí

ṣugbọn tí kò rọ̀,

ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn,

tí kò sì fúnni ní nǹkankan.

15 Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn pada

ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun.

16 Bí o bá rí oyin, lá a níwọ̀nba,

má lá a ní àlájù, kí o má baà bì.

17 Má máa lọ sílé aládùúgbò rẹ lemọ́lemọ́,

kí ọ̀rọ̀ rẹ má baà sú u, kí ó sì kórìíra rẹ.

18 Ẹni tí ó jẹ́rìí èké nípa aládùúgbò rẹ̀

dàbí kùmọ̀ ọmọ ogun, tabi idà, tabi ọfà tí ó mú.

19 Igbẹkẹle ninu alaiṣootọ ní àkókò ìṣòro,

dàbí eyín tí ń ro ni, tabi ẹsẹ̀ tí ó rọ́.

20 Bí ẹni tí a bọ́ṣọ rẹ̀ ninu òtútù,

tabi tí a da ọtí kíkan sójú egbò rẹ̀,

ni ẹni tí à ń kọrin fún ní àkókò tí inú rẹ̀ bàjẹ́.

21 Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ,

bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.

22 Nípa bẹ́ẹ̀ o óo wa ẹ̀yinná lé e lórí,

OLUWA yóo sì san ẹ̀san rere fún ọ.

23 Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá,

bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni.

24 Ó sàn kí á máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,

ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.

25 Gẹ́gẹ́ bí omi tútù ti rí fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,

ni ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè rí.

26 Olódodo tí ó fi ààyè sílẹ̀ fún eniyan burúkú

dàbí odò tí omi rẹ̀ dàrú

tabi kànga tí a da ìdọ̀tí sí.

27 Kò dára kí eniyan lá oyin ní àlájù,

bẹ́ẹ̀ ni kò dára kí eniyan máa wá iyì ní àwájù.

28 Ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu,

dàbí ìlú tí ọ̀tá wọ̀,

tí wọ́n sì wó odi rẹ̀ lulẹ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 26

1 Bí yìnyín kò ṣe yẹ ní àkókò ooru,

ati òjò ní àkókò ìkórè,

bẹ́ẹ̀ ni iyì kò yẹ òmùgọ̀.

2 Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri,

ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká,

bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan.

3 Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀.

4 Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,

kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀.

5 Dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà agọ̀ rẹ̀,

kí ó má baà rò pé òun gbọ́n lójú ara òun.

6 Ẹni tí ó rán òmùgọ̀ níṣẹ́ gé ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀,

ó sì ń mu omi ìjàngbọ̀n.

7 Bí ẹsẹ̀ arọ, tí kò wúlò,

ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀.

8 Bí ẹni fi òkúta sinu kànnàkànnà,

ni ẹni tí ń yẹ́ òmùgọ̀ sí rí.

9 Bí ẹ̀gún tí ó gún ọ̀mùtí lọ́wọ́,

ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀.

10 Ẹni tí ó gba òmùgọ̀ tabi ọ̀mùtí sí iṣẹ́

dàbí tafàtafà tí ń pa eniyan lára kiri.

11 Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀

bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀.

12 Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀

ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.

13 Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà!

Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!”

14 Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀.

15 Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,

ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu.

16 Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀

ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ.

17 Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀,

dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú.

18 Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró,

19 ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà,

tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!”

20 Láìsí igi, iná óo kú,

bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán.

21 Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná,

bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀.

22 Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn

a máa wọni lára ṣinṣin.

23 Ètè mímú ati inú burúkú,

dàbí ìdàrọ́ fadaka tí a yọ́ bo ìkòkò amọ̀.

24 Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan,

lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí,

ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀,

25 bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́,

nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.

26 Ó lè gbìyànjú láti fi ẹ̀tàn pa àrankàn rẹ̀ mọ́,

ṣugbọn ìwà burúkú rẹ̀ yóo hàn ní àwùjọ gbogbo eniyan.

27 Ẹni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ni yóo já sinu rẹ̀,

ẹni tí ó bá sì ń yí òkúta ni òkúta yóo pada yí lù.

28 A-purọ́-mọ́ni a máa kórìíra àwọn tí ń parọ́ mọ́,

ẹni tí ń pọ́nni sì lè fa ìparun ẹni.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 27

1 Má lérí nípa ọ̀la,

nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

2 Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ,

jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde,

kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.

3 Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n,

ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.

4 Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ,

ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?

5 Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.

6 Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́;

ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.

7 Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,

ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,

lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8 Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,

dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.

9 Òróró ati turari a máa mú inú dùn,

ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.

10 Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;

má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.

Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.

11 Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,

kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.

12 Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,

ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.

13 Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,

kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,

tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.

14 Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀,

tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀,

kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.

15 Iyawo oníjà dàbí omi òjò,

tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;

16 ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kun

dàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,

tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.

17 Bí irin ti ń pọ́n irin,

bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.

18 Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,

ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.

19 Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni,

bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.

20 Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn,

bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.

21 Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,

ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.

22 Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,

kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,

ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

23 Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,

sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;

24 nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí,

kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.

25 Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù,

tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,

26 o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ,

o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.

27 O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu,

ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 28

1 Àwọn eniyan burúkú a máa sá,

nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn,

ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun.

2 Bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀,

léraléra ni wọ́n ó máa jọba,

ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ní àwọn eniyan tí wọn ní òye ati ìmọ̀,

yóo wà fún ìgbà pípẹ́.

3 Talaka tí ń ni aláìní lára

dàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́.

4 Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀

ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú,

ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n.

5 Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú,

ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké.

6 Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú

sàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ.

7 Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ọmọ tí ó pa òfin mọ́,

ṣugbọn ẹni tí ń bá àwọn wọ̀bìà rìn, ń dójúti baba rẹ̀.

8 Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èlé

ati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú,

ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka.

9 Ẹni tí ó kọ etí dídi sí òfin Ọlọrun,

adura rẹ̀ pàápàá yóo di ìríra sí Ọlọ́run.

10 Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi,

yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀,

ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.

11 Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀,

ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀.

12 Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,

ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.

13 Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere,

ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.

14 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo,

ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu.

15 Ọba burúkú tí ó jọba lórí àwọn talaka,

dàbí kinniun tí ń bú ramúramù,

tabi ẹranko beari tí inú ń bí.

16 Ìkà, aninilára ni olórí tí kò ní òye,

ṣugbọn ẹ̀mí ẹni tí ó bá kórìíra à ń jèrè lọ́nà èrú yóo gùn.

17 Bí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan bá ń da eniyan láàmú,

yóo di ìsáǹsá ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,

kí ẹnikẹ́ni má ṣe ràn án lọ́wọ́.

18 Ẹni tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú yóo rí ìgbàlà,

ṣugbọn ẹni tí ń rìn ségesège yóo ṣubú sinu kòtò.

19 Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ,

ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka.

20 Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ,

ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.

21 Ojuṣaaju kò dára,

sibẹ oúnjẹ lè mú kí eniyan ṣe ohun tí kò tọ́.

22 Ahun a máa sáré ati ní ọrọ̀,

láìmọ̀ pé òṣì ń bọ̀ wá ta òun.

23 Ẹni tí ó bá eniyan wí,

yóo rí ojurere níkẹyìn,

ju ẹni tí ń pọ́n eniyan lọ.

24 Ẹni tí ó ja ìyá tabi baba rẹ̀ lólè,

tí ó ní, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”,

ẹlẹgbẹ́ apanirun ni.

25 Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere.

26 Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀,

ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là.

27 Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní,

ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún.

28 Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde,

àwọn eniyan á sá pamọ́,

ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 29

1 Ẹni tí à ń báwí tí ó ń ṣoríkunkun,

yóo parun lójijì láìsí àtúnṣe.

2 Nígbà tí olódodo bá di eniyan pataki,

àwọn eniyan a máa yọ̀,

ṣugbọn nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè,

àwọn eniyan a máa kérora.

3 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,

ṣugbọn ẹni tí ń tẹ̀lé aṣẹ́wó kiri, ń fi ọrọ̀ ara rẹ̀ ṣòfò.

4 Ọba tí ó bá ń ṣe ìdájọ́ òdodo, a máa fìdí orílẹ̀-èdè múlẹ̀,

ṣugbọn ọba onírìbá a máa dojú orílẹ̀-èdè bolẹ̀.

5 Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀,

ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.

6 Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀.

7 Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka,

ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀.

8 Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú,

ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu.

9 Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́,

ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín,

yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́.

10 Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú,

wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

11 Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.

12 Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́,

gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan.

13 Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé,

OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran.

14 Ọba tí ó dájọ́ ẹ̀tọ́ fún talaka,

ní a óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí.

15 Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n,

ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀.

16 Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi,

ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú.

17 Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi,

yóo sì mú inú rẹ dùn.

18 Orílẹ̀-èdè tí kò bá ní ìfihàn láti ọ̀run, yóo dàrú,

ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń pa òfin mọ́.

19 Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kò tó láti fi bá ẹrú wí,

ó lè fi etí gbọ́ ṣugbọn kí ó má ṣe ohunkohun.

20 Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀,

tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ.

21 Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù,

yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.

22 Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀,

onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.

23 Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,

ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.

24 Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀,

ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni.

25 Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan,

ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.

26 Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí,

ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo.

27 Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ,

eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 30

Àwọn Ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ

1 Ọ̀rọ̀ Aguri, ọmọ Jake ará Masa nìyí:

Ọkunrin yìí sọ fún Itieli ati Ukali pé,

2 “Nítòótọ́ mo jẹ́ aláìmọ̀kan jùlọ ninu gbogbo eniyan,

n kò ní òye tí ó yẹ kí eniyan ní.

3 N kò tíì kọ́ ọgbọ́n,

n kò sì ní ìmọ̀ Ẹni Mímọ́.

4 Ta ló ti lọ sí ọ̀run rí, tí ó sì tún pada wá?

Ta ló ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ọwọ́ rẹ̀?

Ta ló ti fi aṣọ rẹ̀ di omi?

Ta ló fi ìdí gbogbo òpin ayé múlẹ̀?

Kí ni orúkọ olúwarẹ̀? Kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀?

Ṣé o mọ̀ ọ́n!

5 Kò sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun kankan tí ó ń yẹ̀,

òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

6 Má fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,

kí ó má baà bá ọ wí,

kí o má baà di òpùrọ́.”

Àwọn Òwe Mìíràn

7 Nǹkan meji ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ,

má ṣe fi wọ́n dù mí kí n tó kú.

8 Jẹ́ kí ìwà èké ati irọ́ pípa jìnnà sí mi,

má jẹ́ kí n talaka, má sì jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀,

fún mi ní ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi jẹ,

9 kí n má baà yó tán, kí n sẹ́ ọ,

kí n wí pé, “Ta ni ń jẹ́ OLUWA?”

Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n má baà jalè,

kí n sì kó ẹ̀gbin bá orúkọ Ọlọrun.

10 Má ba iranṣẹ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀,

kí ó má baà gbé ọ ṣépè, kí o sì di ẹlẹ́bi.

11 Àwọn kan wà tí wọn ń gbé baba wọn ṣépè,

tí wọn kò sì súre fún ìyá wọn.

12 Àwọn tí wọ́n mọ́ lójú ara wọn,

ṣugbọn a kò tíì wẹ èérí wọn nù.

13 Àwọn kan wà tí ojú wọ́n ga,

lókè lókè ni ojú wọn wà.

14 Àwọn kan wà tí eyín wọn dàbí idà,

kìkì ọ̀bẹ ló kún èrìgì wọn,

láti jẹ àwọn talaka run lórí ilẹ̀ ayé,

ati láti pa àwọn aláìní run láàrin àwọn eniyan.

15 Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni:

“Mú wá, Mú wá.”

Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,

wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó:

16 isà òkú ati inú àgàn,

ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná,

wọn kì í sọ pé, “Ó tó.”

17 Ẹni tí ń fi baba rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,

tí ó kọ̀ tí kò tẹríba fún ìyá rẹ̀,

ẹyẹ ìwò àfonífojì ati àwọn igún ni yóo yọ ojú rẹ̀ jẹ.

18 Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú,

àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi:

19 ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run,

ipa ejò lórí àpáta,

ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun,

ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin.

20 Ìwà obinrin alágbèrè nìyí:

bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú,

á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”

21 Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì,

ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra:

22 ẹrú tí ó jọba,

òmùgọ̀ tí ó jẹun yó,

23 obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́,

ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24 Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé,

sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ:

25 àwọn èèrà kò lágbára,

ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

26 Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára,

sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta.

27 Àwọn eṣú kò ní ọba,

sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

28 Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá,

sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba.

29 Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ,

àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan:

30 Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko,

kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni.

31 Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ,

ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀.

32 Bí o bá ti ń hùwà òmùgọ̀, tí ò ń gbé ara rẹ ga,

tabi tí o tí ń gbèrò ibi,

fi òpin sí i, kí o sì ronú.

33 Bí a bá po wàrà pọ̀ títí, yóo di òrí àmọ́,

bí ó bá pẹ́ tí a ti ń tẹ imú, imú yóo ṣẹ̀jẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ríru ibinu sókè, a máa mú ìjà wá!

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 31

Ìmọ̀ràn fún Ọba

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ:

2 Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi,

ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí.

3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin,

má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́.

4 Gbọ́, ìwọ Lemueli,

ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí,

àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle.

5 Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin,

kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po.

6 Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu,

fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle,

7 jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn,

kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.

8 Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò,

ati ti àwọn tí a sọ di aláìní.

9 Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,

bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn.

Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere

10 Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?

Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.

11 Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,

kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.

12 Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un

kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13 A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,

a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.

14 Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,

tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.

15 Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,

ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.

16 Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,

a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.

17 A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,

a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.

18 A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,

fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.

19 Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,

ó sì ń ran òwú.

20 Ó lawọ́ sí àwọn talaka,

a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

21 Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,

nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.

22 A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,

òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.

23 Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,

nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.

24 A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,

a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.

25 Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,

ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.

26 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,

a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.

27 A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,

kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.

28 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,

ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,

29 “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,

ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”

30 Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,

obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.

31 Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,

jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Categories
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé yìí jẹ́ àkójọpọ̀ èrò ọ̀jọ̀gbọ́n kan ẹni tí ó ṣe ìjìnlẹ̀ ìtọ́kasí bí ẹ̀mí eniyan ṣe kúrú tó, ati bí ìgbòkègbodò ṣe kún ìgbé-ayé ẹ̀dá. Ó mẹ́nuba ọ̀rọ̀ pẹlu àwọn ìdájọ́ tí kò tọ̀nà tí ó sì rúni lójú ati airojutuu ayé ẹni. Èyí ni ó mú kí ó sọ pé “asán ni ìgbé-ayé.” Kò yé e bí Ọlọrun ti ń darí àyànmọ́ ẹ̀dá. Sibẹ ó rọ àwọn eniyan láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n sì gbádùn àwọn ẹ̀bùn Ọlọrun tẹ́rùn.

Ọ̀pọ̀ ninu àwọn èrò ọ̀jọ̀gbọ́n náà ni ó dàbí ẹni pé kò ṣàǹfààní fúnni, tí ó sì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn, ṣugbọn nítorí pé irú ìwé yìí wà ninu Bibeli, ó fihàn pé igbagbọ inú Bibeli fẹjú, ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún ainigbagbọ ati ẹ̀mí iyèméjì. Ọpọlọpọ àwọn tí ó jẹ́ pé nípa fífi ojú Ìwé Oníwàásù wo ọ̀rọ̀ ìgbé-ayé wọn ni wọ́n ṣe máa ń ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún rí i pé Bibeli kan náà tí ó sọ nípa ainitumọ ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn wọn, ni ó tún fún wọn ní ìrètí nípa Ọlọrun, tí ó fún ìgbé ayé ní ìtumọ̀, tí ó ga ju èyí tí àwa ẹ̀dá mọ̀ lọ.