Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 13

1 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,

ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.

2 Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,

ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.

3 Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́,

ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.

4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,

ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.

5 Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,

ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.

6 Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́,

ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.

7 Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀,

bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan,

níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka,

ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

8 Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada,

ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.

9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,

ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.

10 Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,

ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.

11 Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,

ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.

12 Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,

ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.

13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,

ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.

14 Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè

a máa yọni ninu tàkúté ikú.

15 Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,

ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.

16 Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,

ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.

17 Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,

ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.

18 Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn,

ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.

19 Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀,

ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀.

20 Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.

21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.

22 Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,

ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.

23 Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde,

ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.

24 Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.

25 Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn,

ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 14

1 Ọlọ́gbọ́n obinrin a máa kọ́ ilé rẹ̀,

ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi ọwọ́ ara rẹ̀ tú tirẹ̀ palẹ̀.

2 Ẹni tí ń rìn pẹlu òótọ́ inú yóo bẹ̀rù OLUWA,

ṣugbọn ẹni tí ń rin ìrìn ségesège yóo kẹ́gàn rẹ̀.

3 Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ dàbí pàṣán ní ẹ̀yìn ara rẹ̀,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

4 Níbi tí kò bá sí mààlúù tí ń tu ilẹ̀, kò lè sí oúnjẹ,

ṣugbọn agbára ọpọlọpọ mààlúù níí mú ọpọlọpọ ìkórè wá.

5 Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́,

ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké.

6 Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i,

ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.

7 Yẹra fún òmùgọ̀,

nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.

8 Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n

ni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀,

ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ.

9 Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà,

ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere.

10 Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,

kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.

11 Ìdílé ẹni ibi yóo parun,

ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.

12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,

ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.

13 Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,

ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.

14 Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,

ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.

15 Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.

16 Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi,

ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà.

17 Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀,

ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù.

18 Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n,

ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.

19 Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere,

àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.

20 Àwọn aládùúgbò talaka pàápàá kórìíra rẹ̀,

ṣugbọn ọlọ́rọ̀ a máa ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́.

21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀,

ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí ó bá ṣàánú talaka.

22 Àwọn tí wọn ń pète ibi ti ṣìnà,

ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbèrò ire yóo rí ojurere ati òtítọ́.

23 Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní.

24 Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n,

ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀.

25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là,

ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́.

26 Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà,

níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.

27 Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè,

òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú.

28 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba,

olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun.

29 Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ,

ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

30 Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá,

ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun.

31 Ẹni tí ó bá ni talaka lára àbùkù Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni ó ń ta,

ṣugbọn ẹni tí ó ṣàánú fún àwọn aláìní ń bu ọlá fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

32 Eniyan burúkú ṣubú nítorí ìwà ibi rẹ̀,

ṣugbọn olódodo rí ààbò nípasẹ̀ òtítọ́ inú rẹ̀.

33 Ọgbọ́n kún inú ẹni tí ó mòye,

ṣugbọn kò sí ohun tí ó jọ ọgbọ́n lọ́kàn òmùgọ̀.

34 Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,

ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀gàn fún orílẹ̀-èdè.

35 Iranṣẹ tí ó bá hùwà ọlọ́gbọ́n a máa rí ojurere ọba,

ṣugbọn inú a máa bí ọba sí iranṣẹ tí ó bá hùwà ìtìjú.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 15

1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.

2 Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde,

ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.

3 Ojú OLUWA wà níbi gbogbo,

ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.

4 Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.

5 Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀,

ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni.

6 Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra,

ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.

7 Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀,

ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.

8 Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA,

ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.

9 OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú,

ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.

10 Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,

ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.

11 Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,

mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.

12 Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,

kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.

13 Inú dídùn a máa múni dárayá,

ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.

14 Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,

ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.

15 Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,

ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.

16 Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,

ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.

17 Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,

sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.

18 Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,

ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.

19 Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,

ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.

20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,

ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

21 Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,

ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.

22 Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,

ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.

23 Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀,

kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!

24 Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè,

kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.

25 OLUWA a máa wó ilé agbéraga,

ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.

26 Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,

ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.

27 Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,

ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.

28 Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.

29 OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú,

ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.

30 Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn,

ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.

31 Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rere

yóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.

32 Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.

33 Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n,

ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 16

1 Èrò ọkàn ni ti eniyan

ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn.

2 Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀,

ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn.

3 Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,

èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.

4 OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́,

ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu.

5 OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga,

dájúdájú kò ní lọ láìjìyà.

6 Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀,

ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.

7 Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn,

a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.

8 Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo,

sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.

9 Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀,

ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.

10 Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀,

ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde.

11 Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé,

iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.

12 Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe,

nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀.

13 Inú ọba a máa dùn sí olódodo,

ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́.

14 Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba,

ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.

15 Ìyè wà ninu ojurere ọba,

ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀.

16 Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ,

ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ.

17 Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi,

ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.

18 Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun,

agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.

19 Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talaka

ju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ.

20 Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn,

ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.

21 Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye,

ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada.

22 Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i,

agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀.

23 Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà,

ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada.

24 Ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára dàbí afárá oyin,

a máa mú inú ẹni dùn, a sì máa mú ara ẹni yá.

25 Ọ̀nà kan wà tí ó tọ́ lójú eniyan,

ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.

26 Ebi níí mú kí òṣìṣẹ́ múra síṣẹ́,

ohun tí a óo jẹ ní ń lé ni kiri.

27 Eniyan lásán a máa pète ibi,

ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni.

28 Ṣòkèṣodò a máa dá ìjà sílẹ̀,

ọ̀rọ̀ àhesọ a máa tú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.

29 Ìkà eniyan tan aládùúgbò rẹ̀,

ó darí rẹ̀ lọ sọ́nà tí kò tọ́.

30 Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa,

ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde.

31 Adé ògo ni ewú orí,

nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i.

32 Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ,

ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.

33 À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn,

ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 17

1 Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀,

ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ.

2 Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́,

yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni.

3 Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò,

ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò.

4 Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi,

òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà.

5 Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù,

ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà.

6 Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,

òbí sì ni ògo àwọn ọmọ.

7 Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.

8 Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni,

ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege.

9 Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́,

ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.

10 Ìbáwí a máa dun ọlọ́gbọ́n

ju kí wọ́n nà òmùgọ̀ ní ọgọrun-un pàṣán lọ.

11 Ọ̀tẹ̀ ṣá ni ti eniyan burúkú ní gbogbo ìgbà,

ìkà òjíṣẹ́ ni a óo sì rán sí i.

12 Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ,

ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ.

13 Ẹni tí ó fibi san oore,

ibi kò ní kúrò ninu ilé rẹ̀ lae.

14 Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí kí eniyan ya odò tí wọn sé,

dá a dúró kí ó tó di ńlá.

15 Ẹni tí ń gbé àre fún ẹlẹ́bi

ati ẹni tí ń gbé ẹ̀bi fún aláre,

OLUWA kórìíra ekinni-keji wọn.

16 Owó kò wúlò lọ́wọ́ òmùgọ̀ pé kí ó fi ra ọgbọ́n,

nígbà tí kò ní òye?

17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,

ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.

18 Ẹni tí kò bá gbọ́n níí jẹ́jẹ̀ẹ́,

láti ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

19 Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀,

ẹni tí ó bá fẹ́ràn kí á máa fi owó ṣe àṣehàn ń wá ìparun.

20 Ẹni tí ó ní ọkàn ẹ̀tàn kò ní ṣe àṣeyege,

ẹlẹ́nu meji yóo bọ́ sinu ìyọnu.

21 Ìbànújẹ́ ni kí eniyan bí ọmọ tí kò gbọ́n,

kò sí ayọ̀ fún baba òmùgọ̀.

22 Ọ̀yàyà jẹ́ òògùn tí ó dára fún ara,

ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí eniyan rù.

23 Eniyan burúkú a máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ níkọ̀kọ̀,

láti yí ìdájọ́ po.

24 Ẹni tí ó ní òye a máa tẹjúmọ́ ọgbọ́n,

ṣugbọn ojú òmùgọ̀ kò gbé ibìkan,

ó ń wo òpin ilẹ̀ ayé.

25 Òmùgọ̀ ọmọ jẹ́ ìbànújẹ́ baba rẹ̀,

ati ọgbẹ́ ọkàn fún ìyá tí ó bí i.

26 Kò tọ̀nà láti fi ipá mú aláìṣẹ̀ san owó ìtanràn,

nǹkan burúkú ni kí á na gbajúmọ̀ tí kò rú òfin.

27 Ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ a máa kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu,

ẹni tí ó bá jẹ́ olóye eniyan a máa ṣe jẹ́ẹ́.

28 A máa ka òmùgọ̀ pàápàá kún ọlọ́gbọ́n,

bí ó bá pa ẹnu rẹ̀ mọ́,

olóye ni àwọn eniyan yóo pè é,

bí ó bá panu mọ́ tí kò sọ̀rọ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 18

1 Onímọ-tara-ẹni-nìkan ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀,

láti tako ìdájọ́ òtítọ́.

2 Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀,

àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.

3 Nígbà tí ìwà burúkú bá dé, ẹ̀gàn yóo dé,

bí àbùkù bá wọlé ìtìjú yóo tẹ̀lé e.

4 Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan dàbí odò jíjìn,

orísun ọgbọ́n dàbí omi odò tí ń tú jáde.

5 Kò dára kí á ṣe ojuṣaaju sí eniyan burúkú,

tabi kí á dá olódodo ní ẹjọ́ ẹ̀bi.

6 Ẹnu òmùgọ̀ a máa dá ìjà sílẹ̀,

ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa bá a wá pàṣán.

7 Ẹnu òmùgọ̀ ni yóo tì í sinu ìparun,

ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ni yóo sì ṣe tàkúté mú un.

8 Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn,

a máa wọni lára ṣinṣin.

9 Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,

ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.

10 Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára,

olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.

11 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,

lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.

12 Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,

ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

13 Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni,

kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.

14 Eniyan lè farada àìsàn,

ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?

15 Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀,

etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri.

16 Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn,

a sì mú un dé iwájú ẹni gíga.

17 Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre,

títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè,

18 Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀

a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.

19 Ọkàn arakunrin tí eniyan bá ṣẹ̀ a máa le bí ìlú olódi,

àríyànjiyàn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ilé ìṣọ́.

20 Eniyan lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá oúnjẹ fún ara rẹ̀,

a lè jẹ oúnjẹ tí a bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá

ní àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.

21 Ahọ́n lágbára láti pani ati láti lani,

ẹni tí ó bá fẹ́ràn rẹ̀ yóo jèrè rẹ̀.

22 Ẹni tí ó bá rí aya fẹ́ rí ohun rere,

ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA.

23 Ẹ̀bẹ̀ ni talaka bẹ̀,

ṣugbọn ọlọ́rọ̀ á dáhùn tìkanra-tìkanra.

24 Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n,

ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 19

1 Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú,

ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

2 Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀,

ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà.

3 Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a,

ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú.

4 Ọrọ̀ a máa mú kí eniyan ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ titun,

ṣugbọn àwọn ọ̀rẹ́ talaka a máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,

bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀san ibi.

6 Ọ̀pọ̀ eniyan níí máa ń wá ojurere ẹni tó lawọ́,

gbogbo eniyan sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn.

7 Gbogbo àwọn arakunrin talaka ni wọ́n kórìíra rẹ̀,

kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jìnnà sí i!

Ó fọ̀rọ̀ ẹnu fà wọ́n títí, sibẹ wọn kò súnmọ́ ọn.

8 Ẹni tí ó ní ọgbọ́n fẹ́ràn ara rẹ̀,

ẹni tí ó bá sì ní òye, yóo ṣe rere.

9 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,

ẹni tí ó ń pa irọ́ yóo parun.

10 Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè.

11 Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú,

ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

12 Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,

ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.

13 Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀,

iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró.

14 A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni,

ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere.

15 Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn,

ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́.

16 Ẹni tí ó bá pa òfin mọ́, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó pamọ́,

ẹni tí ó kọ ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀ yóo kú.

17 Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún,

OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un.

18 Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí,

má sì ṣe wá ìparun rẹ̀.

19 Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀,

bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la.

20 Gbọ́ ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,

kí o lè rí ọgbọ́n lò lẹ́yìn ọ̀la.

21 Ọpọlọpọ ni èrò tí ó wà lọ́kàn ọmọ eniyan,

ṣugbọn ìfẹ́ OLUWA ni àṣẹ.

22 Ohun tí ayé ń fẹ́ lára eniyan ni òtítọ́ inú,

talaka sì sàn ju òpùrọ́ lọ.

23 Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú ìyè wá,

ẹni tí ó ní i yóo ní ìfọ̀kànbalẹ̀,

ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí i.

24 Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,

ṣugbọn kò lè bu oúnjẹ sí ẹnu ara rẹ̀.

25 Na pẹ̀gànpẹ̀gàn eniyan, òpè yóo sì kọ́gbọ́n.

Bá olóye wí, yóo sì ní ìmọ̀ sí i.

26 Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde,

ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni.

27 Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́,

o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀.

28 Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́,

eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun.

29 Ìjìyà ti wà nílẹ̀ fún ẹlẹ́yà,

a sì ti tọ́jú pàṣán sílẹ̀ fún ẹ̀yìn òmùgọ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 20

1 Ẹlẹ́yà ni ọtí waini,

aláriwo ní ọtí líle,

ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n.

2 Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,

ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.

3 Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà,

ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà.

4 Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò,

nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.

5 Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn,

ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.

6 Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́,

ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?

7 Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́,

ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.

8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀,

ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù.

9 Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́,

ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀?

10 Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA.

11 Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀,

bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà.

12 Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran,

OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.

13 Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka,

lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù.

14 “Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí,

bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà.

15 Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.

16 Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,

gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.

17 Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan,

ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.

18 Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀,

gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.

19 Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí,

nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́.

20 Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú,

àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri.

21 Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀,

kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn.

22 Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú,

gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.

23 Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA,

ìwọ̀n èké kò dára.

24 OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni,

eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.

25 Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA,

kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀.

26 Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù,

a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

27 Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA,

tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.

28 Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́,

òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró.

29 Agbára ni ògo ọ̀dọ́,

ewú sì ni ẹwà àgbà.

30 Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò,

pàṣán a máa mú kí inú mọ́.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 21

1 Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA,

ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí.

2 Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀,

ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò.

3 Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́,

sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA.

4 Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga,

ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n.

5 Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító.

6 Fífi èké kó ìṣúra jọ

dàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú.

7 Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù,

nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́.

8 Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,

ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́.

9 Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,

ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.

10 Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́,

àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀.

11 Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n,

tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i.

12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú,

eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun.

13 Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka,

òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn.

14 Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu,

àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà.

15 Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn,

ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi.

16 Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òye

yóo sinmi láàrin àwọn òkú.

17 Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka,

ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́.

18 Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibi

tíì bá dé bá olódodo.

Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.

19 Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀,

ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ.

20 Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye,

ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́.

21 Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánú

yóo rí ìyè, òdodo, ati iyì.

22 Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbára

a sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀.

23 Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́

pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu.

24 “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga,

tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí.

25 Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á,

nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.

26 Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà,

ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró.

27 Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú,

pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi.

28 Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́.

29 Eniyan burúkú a máa lo ògbójú,

ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò.

30 Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀,

tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè.

31 Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,

ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 22

1 Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ,

kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ.

2 Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé,

OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.

3 Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́,

ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà,

ó sì kó sinu ìyọnu.

4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè.

5 Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn,

ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn.

6 Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn,

bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀.

7 Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,

ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.

8 Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,

pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.

9 Olójú àánú yóo rí ibukun gbà,

nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.

10 Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀,

asọ̀ ati èébú yóo sì dópin.

11 Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́,

tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́.

12 Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́,

ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po.

13 Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta!

Yóo pa mí jẹ lójú pópó!”

14 Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá,

ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀.

15 Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde,

ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde.

16 Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ,

tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.

Ọgbọ̀n Gbolohun tí Ọlọ́gbọ́n Sọ

17 Tẹ́tí rẹ sílẹ̀ kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n,

kí o sì fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ mi,

18 nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ,

tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.

19 Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ,

kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé.

20 Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n,

21 láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́,

kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ.

-1-

22 Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka,

má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.

23 Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn,

yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.

-2-

24 Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́,

má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.

25 Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀,

kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ.

-3-

26 Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó,

má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè.

27 Tí o kò bá rí owó san fún olówó,

olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ.

-4-

28 Má hú ohun tí àwọn baba ńlá rẹ rì mọ́lẹ̀,

tí wọ́n fi pa ààlà kúrò.

-5-

29 Ṣe akiyesi ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ rẹ̀,

àwọn ọba ni yóo máa bá ṣiṣẹ́,

kì í ṣe àwọn eniyan lásán.

-6-