Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 3

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́

1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ,

sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ,

2 nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn

ati ọpọlọpọ alaafia.

3 Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀,

so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ,

kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.

4 Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì

lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan.

5 Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,

má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ.

6 Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ,

yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́.

7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ,

bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi.

8 Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ,

ati ìtura fún egungun rẹ.

9 Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA

pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ.

10 Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú,

ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.

11 Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA,

má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ.

12 Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí

gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí.

13 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí,

ati ẹni tí ó ní òye.

14 Nítorí èrè rẹ̀ dára

ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ.

15 Ọgbọ́n níye lórí

ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,

kò sí ohun tí o lè fi wé e,

ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́.

16 Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,

ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.

17 Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ,

alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀.

18 Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn,

ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.

19 Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀,

òye ni ó sì fi dá ọ̀run.

20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde,

tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu.

21 Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú,

má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,

22 wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,

ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.

23 Nígbà náà ni o óo máa rìn

láìléwu ati láìkọsẹ̀.

24 Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,

bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.

25 Má bẹ̀rù àjálù òjijì,

tabi ìparun àwọn ẹni ibi,

nígbà tí ó bá dé bá ọ,

26 nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ,

kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.

27 Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí,

nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é.

28 Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé,

“Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,”

nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ.

29 Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹ

tí ń fi inú kan bá ọ gbé.

30 Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí,

nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi.

31 Má ṣe ìlara ẹni ibi

má sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀.

32 Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè,

ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin.

33 Ègún OLUWA wà lórí ìdílé ẹni ibi,

ṣugbọn a máa bukun ibùgbé àwọn olódodo.

34 A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà,

ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.

35 Ọlọ́gbọ́n yóo jogún iyì,

ṣugbọn ojú yóo ti òmùgọ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 4

Anfaani Tí Ó Wà ninu Ọgbọ́n

1 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín,

ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀,

2 nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere,

ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi.

3 Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi,

tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi,

4 baba mi kọ́ mi, ó ní,

“Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn,

pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè.

5 Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀.

Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.

6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́,

fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.

7 Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n,

ohun yòówù tí o lè tún ní,

ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

8 Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga,

yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra.

9 Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí,

yóo sì dé ọ ní adé dáradára.”

10 Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi,

kí ẹ̀mí rẹ lè gùn.

11 Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n,

mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́.

12 Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà,

nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ.

13 Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin,

má jẹ́ kí ó bọ́,

pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.

14 Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi,

má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú.

15 Yẹra fún un,

má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀,

ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ.

16 Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi,

oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan.

17 Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn,

ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn.

18 Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́,

tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.

19 Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri,

wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù.

20 Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi,

tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ.

21 Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú,

fi wọ́n sọ́kàn.

22 Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn,

ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn.

23 Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ,

nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.

24 Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ,

sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè.

25 Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán,

kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà.

26 Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ,

gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là.

27 Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì,

yipada kúrò ninu ibi.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 5

Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè

1 Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ,

tẹ́tí rẹ sí òye mi,

2 kí o baà lè ní làákàyè,

kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀.

3 Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ,

4 ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ,

ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji.

5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú,

ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì.

6 Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè,

ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.

7 Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.

8 Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin,

kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀,

9 kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn,

kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́.

10 Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín,

kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò.

11 Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ,

nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni

12 nígbà náà ni o óo wí pé,

“Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni,

tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!

13 N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi

n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà.

14 Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun,

láàrin àwùjọ eniyan.”

15 Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi;

omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu.

16 Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri,

bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà.

17 Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́,

má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀.

18 Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun,

kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé.

19 Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin.

Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo,

kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà.

20 Kí ló dé, ọmọ mi,

tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn,

tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin?

21 Nítorí OLUWA rí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe,

ó sì ń ṣàkíyèsí gbogbo ìrìn rẹ̀.

22 Eniyan burúkú a máa jìn sinu ọ̀fìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

a sì bọ́ sinu ìyọnu nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

23 Yóo kú nítorí àìgba ìtọ́ni,

yóo sì sọnù nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 6

Àwọn Ìkìlọ̀ Mìíràn

1 Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,

tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì,

2 tí o bá bọ́ sinu tàkúté

tí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ,

tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ,

3 o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ.

Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi,

kí o lè gba ara rẹ là:

lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.

4 Má sùn,

má sì tòògbé,

5 gba ara rẹ sílẹ̀

bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ,

àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.

6 Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ,

ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n.

7 Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ

8 sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn;

a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè.

9 O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ?

Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun?

10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,

ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,

11 yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan.

Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni.

12 Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri,

a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè,

13 bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀,

tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe.

14 Ó ń fi inú burúkú pète ibi,

ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀,

15 nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì,

yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.

16 Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́:

wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:

17 Ìgbéraga, irọ́ pípa,

ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,

18 ọkàn tí ń pète ìkà,

ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi,

19 ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́,

ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.

Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè

20 Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,

má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.

21 Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,

kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.

22 Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ,

bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ,

bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀.

23 Nítorí fìtílà ni òfin,

ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,

24 láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú,

ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀.

25 Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́,

má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ.

26 Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ,

ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.

27 Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà,

kí aṣọ rẹ̀ má jó?

28 Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná,

kí iná má jó o lẹ́sẹ̀?

29 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí,

kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà.

30 Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi.

31 Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje,

ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án.

32 Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí,

ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun.

33 Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà,

ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae.

34 Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru,

kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san.

35 Kò ní gba owó ìtanràn,

ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 7

1 Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,

kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ.

2 Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè,

pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ,

3 wé wọn mọ́ ìka rẹ,

kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.

4 Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,”

kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ,

5 kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́,

kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin,

ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀.

Obinrin Oníṣekúṣe

6 Mo yọjú wo ìta,

láti ojú fèrèsé ilé mi.

7 Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí,

mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn,

ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n.

8 Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà,

9 ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí,

tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn.

10 Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀,

ó wọ aṣọ aṣẹ́wó,

ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn.

11 Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin,

kì í gbélé rẹ̀.

12 Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó,

bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà,

yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀.

13 Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu,

yóo wí pẹlu ainitiju pé,

14 “Mo ti rú ẹbọ alaafia,

mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí.

15 Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ,

mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ.

16 Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi.

17 Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi.

18 Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́

títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,

jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa.

19 Ọkọ mi kò sí nílé,

ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn.

20 Ó mú owó pupọ lọ́wọ́,

kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”

21 Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,

ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un.

22 Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,

bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,

tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,

23 títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninu

bí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,

láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.

24 Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi,

ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.

25 Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀,

ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

26 Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀,

ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa.

27 Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀,

ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 8

Yíyin Ọgbọ́n

1 Ọgbọ́n ń pe eniyan,

òye ń pariwo.

2 Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà,

ati ní ojú ọ̀nà tóóró,

3 ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú,

ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu,

ó ń wí pé:

4 “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè,

gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí.

5 Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n,

ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye.

6 Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.

Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ.

7 Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde,

nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú.

8 Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi,

kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn.

9 Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye,

wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀.

10 Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka,

ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà,

11 nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,

kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e.

12 Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé,

mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè.

13 Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi,

mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

14 Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro,

mo sì ní òye ati agbára.

15 Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba,

tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo.

16 Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso,

gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé.

17 Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi,

àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi.

18 Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi,

ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun.

19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ,

àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ.

20 Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn,

ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀.

21 Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀,

n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún.

22 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi,

kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.

23 Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,

láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá.

24 Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,

nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi.

25 Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,

kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà.

26 Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,

kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.

27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀,

tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú,

ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé,

28 nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀,

tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀,

29 nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá,

kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀.

Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà,

30 èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,

Inú mi a máa dùn lojoojumọ,

èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo.

31 Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé,

inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan.

32 “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi,

ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.

33 Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n,

ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀.

34 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi,

tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi,

tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi.

35 Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè,

ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,

36 ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára,

gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 9

Ọgbọ́n ati Wèrè

1 Ọgbọ́n ti kọ́lé,

ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró.

2 Ó ti pa ẹran rẹ̀,

ó ti pọn ọtí waini rẹ̀,

ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀.

3 Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀

kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé:

4 “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!”

Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé,

5 “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi,

kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò.

6 Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè,

kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.”

7 Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù,

ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀.

8 Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí,

kí ó má baà kórìíra rẹ,

bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ.

9 Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i,

kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀.

10 Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n,

ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè.

11 Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn.

Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè.

12 Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ,

Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀.

13 Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n,

oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú.

14 Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀,

á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú.

15 A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ,

àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé,

16 “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!”

Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé,

17 “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn,

oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.”

18 Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀,

ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 10

Àwọn Òwe Solomoni

1 Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí:

Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn,

ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀.

2 Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè,

ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú.

3 OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo,

ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú.

4 Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì,

ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀.

5 Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè,

ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè

a máa kó ìtìjú báni.

6 Ibukun wà lórí olódodo,

ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,

a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

7 Ayọ̀ ni ìrántí olódodo,

ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé.

8 Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́,

ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.

9 Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà,

ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.

10 Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀,

ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia.

11 Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè,

ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,

a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

12 Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè,

ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

13 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye,

ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.

14 Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra.

15 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀,

ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run.

16 Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè,

ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀.

17 Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè,

ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà.

18 Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan,

ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni.

19 Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́,

ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.

20 Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka,

ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan.

21 Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani,

ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n.

22 Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là,

kì í sì í fi làálàá kún un.

23 Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀,

ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye.

24 Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a,

ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà.

25 Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ,

ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

26 Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín,

ati bí èéfín ti rí sí ojú,

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.

27 Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn,

ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.

28 Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀,

ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo.

29 OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́,

ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi.

30 Gbọningbọnin ni olódodo yóo dúró,

ṣugbọn ẹni ibi kò ní lè gbé ilẹ̀ náà.

31 Ẹnu olódodo kún fún ọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

ṣugbọn ẹnu alaiṣootọ ni a pamọ́.

32 Olódodo mọ ohun tí ó dára láti sọ,

ṣugbọn ti eniyan burúkú kò ju ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 11

1 OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké,

òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí.

2 Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e,

ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀.

3 Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn,

ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n.

4 Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu,

ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú,

5 Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́,

ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀.

6 Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n,

ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn.

7 Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú,

ìrètí wọn yóo di asán,

bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo.

8 OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu,

ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.

9 Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máa

fi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,

ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀.

10 Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo,

gbogbo ará ìlú a máa yọ̀,

nígbà tí eniyan burúkú bá kú,

gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀.

11 Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú.

12 Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́.

13 Olófòófó a máa tú àṣírí,

ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.

14 Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.

15 Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,

ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.

16 Obinrin onínúrere gbayì,

ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní.

17 Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀,

ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.

18 Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà,

ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́.

19 Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú.

20 Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA,

ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un.

21 Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,

ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là.

22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀

ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè.

23 Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere,

ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu.

24 Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri,

sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní,

ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́,

sibẹsibẹ aláìní ni.

25 Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún,

ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀,

ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀.

26 Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà.

27 Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a.

28 Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó,

ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù.

29 Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo,

òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n.

30 Èso olódodo ni igi ìyè,

ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.

31 Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé,

mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀.

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 12

1 Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,

ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.

2 Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,

ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.

3 Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,

ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.

4 Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,

ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.

5 Èrò ọkàn olódodo dára,

ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.

6 Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.

7 A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,

ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.

8 À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó,

ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.

9 Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀

ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.

10 Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,

ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.

11 Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,

ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.

12 Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,

ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.

13 Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,

ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.

14 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,

a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

15 Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.

16 Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,

ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.

17 Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,

ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.

18 Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.

19 Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé

ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.

20 Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,

ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.

21 Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,

ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.

22 OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,

ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.

23 Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,

ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.

24 Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,

ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.

25 Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,

ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.

26 Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi,

ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.

27 Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé,

ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

28 Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà,

kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.