Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 144

Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi,

ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà,

tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun.

2 Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi,

asà mi, ẹni tí mo sá di.

Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀.

3 OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?

Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀?

4 Eniyan dàbí èémí,

ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ.

5 OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,

fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín.

6 Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,

ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká.

7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,

kí o yọ mí ninu ibú omi;

kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

8 tí ẹnu wọn kún fún irọ́,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

9 Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,

n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ.

10 Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,

tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là.

11 Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,

gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

12 Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,

jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,

kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,

tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.

13 Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,

kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,

àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa.

14 Kí àwọn mààlúù wa lóyún,

kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;

kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa.

15 Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;

ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 145

Orin Ìyìn

1 Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi,

n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.

2 Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́,

tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.

3 OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ;

àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀.

4 Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ,

tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ.

5 Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ,

ati iṣẹ́ ìyanu rẹ.

6 Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu,

èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ.

7 Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó,

wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ.

8 Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni;

kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.

9 OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan,

àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá.

10 OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,

àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́.

11 Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ,

wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ,

12 láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ,

ati ẹwà ògo ìjọba rẹ.

13 Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,

yóo sì máa wà láti ìran dé ìran.

Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀,

olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.

14 OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde,

ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró.

15 Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́,

o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò.

16 Ìwọ la ọwọ́ rẹ,

o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn.

17 Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀,

aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.

18 OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é,

àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.

19 Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn;

ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n.

20 OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí,

ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run.

21 Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA;

kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 146

Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.

2 N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé;

n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.

3 Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè;

eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.

4 Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀,

ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé.

5 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,

tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀.

6 Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,

òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;

Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,

7 ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;

tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,

OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀.

8 A máa la ojú àwọn afọ́jú,

a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró;

ó fẹ́ràn àwọn olódodo.

9 OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò,

òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba,

ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú.

10 OLUWA yóo jọba títí lae,

Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.

Ẹ yin OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 147

Ọlọrun Alágbára

1 Ẹ yin OLUWA!

Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;

nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́.

2 OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;

òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ.

3 Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,

ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn.

4 Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,

òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ.

5 OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọ

òye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n.

6 OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,

òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

7 Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,

ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa.

8 Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,

ó pèsè òjò fún ilẹ̀,

ó mú koríko hù lórí òkè.

9 Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,

tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké.

10 Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,

kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà.

11 Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

12 Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!

Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!

13 Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,

ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.

14 Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,

ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.

15 Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,

àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.

16 Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,

ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.

17 Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,

ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?

18 Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,

ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.

19 Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,

ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.

20 Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,

wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 148

Kí gbogbo ẹ̀dá Yin OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,

ẹ yìn ín lókè ọ̀run.

2 Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀;

ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.

3 Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá;

ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn.

4 Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;

yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.

5 Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,

nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.

6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;

ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá.

7 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,

ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;

8 iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,

ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.

9 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,

ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;

10 ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,

ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò.

11 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,

ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;

12 ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,

ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,

nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;

ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.

14 Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára,

ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn;

ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 149

Orin Ìyìn sí OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,

ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́.

2 Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀,

kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba.

3 Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀,

kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i.

4 Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,

a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

5 Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá;

kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.

6 Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun;

kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn,

7 láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà;

8 láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn,

ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn;

9 láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀.

Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí.

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 150

Ẹ yin OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀;

ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára.

2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀;

ẹ yìn ín nítorí pé ó tóbi pupọ.

3 Ẹ fi ariwo fèrè yìn ín;

ẹ fi fèrè ati hapu yìn ín.

4 Ẹ fi ìlù ati ijó yìn ín;

ẹ fi gòjé ati dùùrù yìn ín.

5 Ẹ fi aro olóhùn òkè yìn ín;

ẹ fi aro olóhùn gooro yìn ín.

6 Kí gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí yin OLUWA!

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Òwe

jẹ́ àkọsílẹ̀ àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ìwà ati ẹ̀sìn tí a ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ lówe lówe. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn òwe wọnyi jẹ mọ́ ìhùwàsí ati ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojumọ. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìránnilétí pé, “Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpìlẹ̀ ọgbọ́n.” Lẹ́yìn náà ó mẹ́nuba oríṣìíríṣìí ìhùwàsí tí ó tọ̀nà nípa ti ẹ̀sìn ati ti ọgbọ́n ati ti ìwà ọmọlúwàbí. Ọpọlọpọ àwọn ọ̀rọ̀ ṣókíṣókí inú ìwé yìí fi àròjinlẹ̀ àwọn olùkọ́ ní ilẹ̀ Israẹli ní ayé àtijọ́ hàn, nípa ohun tí ó tọ́ kí ọlọ́gbọ́n eniyan ṣe tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tabi òmíràn bá ṣẹlẹ̀. Díẹ̀ ninu àwọn òwe wọnyi níí ṣe pẹlu àjọṣepọ̀ láàrin ẹbí, àwọn mìíràn níí ṣe pẹlu òwò ṣíṣe. Díẹ̀ níí ṣe pẹlu ìhùwàsí ní àwùjọ, àwọn mìíràn níí ṣe pẹlu ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ mọ́ iyì tí ó wà ninu ìwà ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, ẹ̀mí ọ̀wọ̀ fún àwọn talaka, ati ìṣòtítọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ ẹni.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Orin ìyìn nípa ìwà ọgbọ́n 1:1–9:18

Àwọn òwe Solomoni 10:1–29:27

Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri 30:1-33

Oniruuru ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ 31:1-31

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 1

Anfaani Àwọn Òwe

1 Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa,

2 kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́,

kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn,

3 láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n,

òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú,

4 láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n,

kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́,

5 kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀,

kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu.

6 Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀,

ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀.

Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́

7 Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,

ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́.

8 Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ,

má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ,

9 nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ,

ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.

10 Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,

o ò gbọdọ̀ gbà.

11 Bí wọn bá wí pé,

“Tẹ̀lé wa ká lọ,

kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,

kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,

12 jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè

kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,

13 a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,

ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.

14 Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,

kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”

15 Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́,

má sì bá wọn rìn,

16 nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,

wọ́n a sì máa yára láti paniyan.

17 Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,

nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,

18 ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,

ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.

19 Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,

ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.

Ọgbọ́n Ń pè

20 Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà,

ó ń pariwo láàrin ọjà,

21 ó ń kígbe lórí odi ìlú,

ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní,

22 “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín?

Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn,

tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?

23 Ẹ fetí sí ìbáwí mi,

n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín,

n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.

24 Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́,

mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn,

25 ẹ ti pa gbogbo ìmọ̀ràn mi tì,

ẹ kò sì gbọ́ ọ̀kankan ninu ìbáwí mi.

26 Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ín

nígbà tí ìdààmú bá dé ba yín,

n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà

nígbà tí ìpayà bá dé ba yín.

27 Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì,

tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle,

tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀.

28 Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,

ṣugbọn n kò ní dáhùn.

Ẹ óo wá mi láìsinmi,

ṣugbọn ẹ kò ní rí mi.

29 Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀,

ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.

30 Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi,

ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi.

31 Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín,

ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára.

32 Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́

aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run.

33 Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ tèmi,

yóo máa wà láìléwu,

yóo máa gbé pẹlu ìrọ̀rùn, láìsí ìpayà ibi.”

Categories
ÌWÉ ÒWE

ÌWÉ ÒWE 2

Èrè Tó Wà ninu Ọgbọ́n

1 Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi,

tí o sì pa òfin mi mọ́,

2 tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n,

tí o sì fi ọkàn sí òye,

3 bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀,

tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀,

4 bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka,

tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́,

5 nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ.

O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.

6 Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n,

ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá.

7 Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n,

òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́.

8 Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́,

ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́.

9 Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ

ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere.

10 Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ,

ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára,

11 ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ,

òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́,

12 yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe,

ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn,

13 àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀

tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn;

14 àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibi

tí wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi;

15 àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́,

tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè.

16 A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe,

àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀.

17 Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀,

tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀.

18 Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun,

tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú.

19 Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè.

20 Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere,

sì máa bá àwọn olódodo rìn.

21 Nítorí àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin ni wọn yóo máa gbé ilẹ̀ náà,

àwọn olóòótọ́ inú ni yóo máa wà níbẹ̀,

22 ṣugbọn a óo pa ẹni ibi run lórí ilẹ̀ náà,

a óo sì fa alárèékérekè tu kúrò níbẹ̀.