Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 124

Ọlọrun Aláàbò Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa,

ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,

2 “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa

nígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá,

3 wọn ìbá gbé wa mì láàyè,

nígbà tí inú bí wọn sí wa;

4 àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ,

ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀;

5 ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.”

6 Ọpẹ́ ni fún OLUWA,

tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn.

7 A ti yọ, bí ẹyẹ tí ó yọ ninu okùn apẹyẹ:

okùn ti já; àwa sì ti yọ.

8 Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá,

ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 125

Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA

1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni,

tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae.

2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,

láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.

3 Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹ

lórí ilẹ̀ àwọn olódodo,

kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.

4 OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,

ati fún àwọn olódodo.

5 Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹ

àwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.

Alaafia fún Israẹli!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 126

Ẹkún Di Ayọ̀

1 Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada,

ó dàbí àlá lójú wa.

2 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀,

nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé,

“OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!”

3 Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.

4 Dá ire wa pada, OLUWA,

bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu.

5 Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú,

jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.

6 Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún,

yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 127

Abániṣé ni OLUWA

1 Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,

asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.

Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,

asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.

2 Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,

kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.

Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;

nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.

3 Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;

òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.

4 Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni.

5 Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn.

Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 128

Ìbẹ̀rù OLUWA lérè

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA,

tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.

2 O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ.

3 Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ;

bí ọmọ tií yí igi olifi ká,

ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká.

4 Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

5 Kí OLUWA bukun ọ láti Sioni!

Kí o máa rí ire Jerusalẹmu

ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

6 Kí o máa rí arọmọdọmọ rẹ.

Kí alaafia máa wà ní Israẹli.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 129

Kí ojú ti ọ̀tá

1 Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.

Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,

2 “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,

sibẹ, wọn kò borí mi.”

3 Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,

gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.

4 Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,

ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.

5 Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni,

a óo lé wọn pada sẹ́yìn.

6 Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,

tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ.

7 Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko;

kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí.

8 Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé:

“OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o!

Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 130

Adura Ẹlẹ́ṣẹ̀

1 Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA!

2 OLUWA, gbóhùn mi,

dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

3 Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,

ta ló lè yege?

4 Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,

kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.

5 Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,

mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀.

6 Mò ń retí rẹ, OLUWA,

ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,

àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.

7 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!

Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,

ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.

8 Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 131

Àṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀

1 OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga,

bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè.

N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá,

n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ.

2 Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́,

bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀.

Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́.

3 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA,

láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 132

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi

1 OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.

2 Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,

tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,

3 tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi;

4 n kò ní sùn,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé,

5 títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA,

àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.”

6 A gbúròó rẹ̀ ní Efurata,

a rí i ní oko Jearimu.

7 “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀;

ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.”

8 Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ,

tìwọ ti àpótí agbára rẹ.

9 Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo,

kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀.

10 Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ,

má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ.

11 OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi,

èyí tí kò ní yipada; ó ní,

“Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ

ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.

12 Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́,

tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn,

àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”

13 Nítorí OLUWA ti yan Sioni;

ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀:

14 Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae,

níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí.

15 N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ;

n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.

16 N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀,

àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀.

17 Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára;

mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn.

18 N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ,

ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 133

Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará

1 Ó dára, ó sì dùn pupọ,

bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀.

2 Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí,

tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n;

bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni,

àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀.

3 Ó dàbí ìrì òkè Herimoni,

tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni.

Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun,

àní, ìyè ainipẹkun.