Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 94

Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé

1 OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san,

ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn!

2 Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé;

san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn!

3 OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní?

4 Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù,

gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu.

5 Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA,

wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú.

6 Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò,

wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba;

7 wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa;

Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.”

8 Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,

ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!

Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n?

9 Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?

Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran?

10 Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,

ni kò ní jẹ yín níyà?

Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀?

11 OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,

ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni.

12 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,

tí o sì kọ́ ní òfin rẹ,

13 kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,

títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú.

14 Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;

kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;

15 nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,

àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

16 Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?

Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi?

17 Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,

ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú.

18 Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,”

OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró.

19 Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,

ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le.

20 Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,

àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?

21 Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo;

wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.

22 Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi,

Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi.

23 Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn,

yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn.

OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 95

Orin Ìyìn

1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;

ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa!

2 Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;

ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.

3 Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,

ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.

4 Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;

gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.

5 Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;

ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,

ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!

7 Nítorí òun ni Ọlọrun wa,

àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,

àwa ni agbo aguntan rẹ̀.

Ọlọrun Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ sọ̀rọ̀

Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,

8 ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,

ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀

9 nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò,

tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí

ohun tí mo ti ṣe rí.

10 Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi,

tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa,

wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.”

11 Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé,

wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 96

Ọlọrun Ọba Àwọn Ọba

1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;

gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA.

2 Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;

ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.

3 Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;

ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan.

4 Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ;

ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ.

5 Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn,

ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run.

6 Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;

agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀.

7 Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé;

ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀.

8 Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀,

ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀.

9 Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́;

gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀.

10 Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!

A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;

OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.”

11 Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;

kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.

12 Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀.

Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin,

13 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀;

ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;

yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 97

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀;

jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.

2 Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká;

òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3 Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀,

ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.

4 Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé,

ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì.

5 Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,

àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.

6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;

gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.

7 Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,

àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;

gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.

8 Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.

Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,

nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.

9 Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,

o ju gbogbo ayé lọ,

a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.

10 Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;

OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,

a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.

11 Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,

ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.

12 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,

kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 98

Ọlọrun, Ọba gbogbo Ayé

1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,

nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu;

agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun.

2 OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀,

ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.

3 Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀

sí àwọn ọmọ Israẹli;

gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa.

4 Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;

ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.

5 Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,

àní, hapu ati ohùn orin dídùn.

6 Ẹ fun fèrè ati ìwo

kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba.

7 Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,

kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

8 Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;

kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀

9 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;

yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 99

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;

ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.

2 OLUWA tóbi ní Sioni,

ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

3 Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,

mímọ́ ni OLUWA!

4 Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,

o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;

o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu.

5 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,

ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;

mímọ́ ni OLUWA!

6 Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀;

Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀;

wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn.

7 Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;

wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;

wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn.

8 OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;

Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;

ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn.

9 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,

kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;

nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 100

Orin Ìyìn

1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.

2 Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.

Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.

3 Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,

òun ló dá wa, òun ló ni wá;

àwa ni eniyan rẹ̀,

àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.

4 Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,

kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,

kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.

5 Nítorí OLUWA ṣeun;

ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,

òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 101

Ìlérí Ọba

1 N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,

OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí.

2 N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;

nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?

N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.

3 N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.

Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.

N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan.

4 Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,

n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan,

5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi,

n óo pa á run,

n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè.

6 N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà,

kí wọ́n lè máa bá mi gbé;

ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí.

7 Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi;

bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi.

8 Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà,

n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 102

Adura Olùpọ́njú

1 Gbọ́ adura mi, OLUWA;

kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ.

2 Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro!

Dẹtí sí adura mi;

kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́.

3 Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín,

eegun mi gbóná bí iná ààrò.

4 Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko,

tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun.

5 Nítorí igbe ìrora mi,

mo rù kan eegun.

6 Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀,

àní, bí òwìwí inú ahoro.

7 Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn,

mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.

8 Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,

àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè.

9 Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,

mo sì ń mu omijé mọ́ omi

10 nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;

o gbé mi sókè,

o sì jù mí nù.

11 Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,

mo sì ń rọ bíi koríko.

12 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,

ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran.

13 Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,

nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.

Àkókò tí o dá tó.

14 Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,

àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,

gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.

16 Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,

yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.

17 Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,

kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn.

18 Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀,

kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA,

19 pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀,

láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé;

20 láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn,

ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀.

21 Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni,

kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu,

22 nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,

láti sin OLUWA.

23 Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,

ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú.

24 Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,

ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”

25 Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.

26 Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae;

gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ,

o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ;

wọn yóo sì di ohun ìpatì.

27 Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà,

ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin.

28 Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé;

bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 103

Ìfẹ́ Ọlọrun

1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,

fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

2 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,

má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

3 ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,

tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn;

4 ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,

tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.

5 Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,

tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.

6 OLUWA a máa dáni láre

a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo

àwọn tí a ni lára.

7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose,

ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli.

8 Aláàánú ati olóore ni OLUWA,

kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.

9 Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí,

bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé.

10 Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,

bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa.

11 Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó

sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,

bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn

tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.

14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;

ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.

15 Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,

eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;

16 ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,

á rẹ̀ dànù,

ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.

17 Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,

sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.

18 Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,

tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.

19 OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,

ó sì jọba lórí ohun gbogbo.

20 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,

tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

21 Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,

ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

22 Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,

níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀.

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.