Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 84

Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun

1 Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

2 ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí,

àárò rẹ̀ ń sọ mí;

tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀

sí Ọlọrun alààyè.

3 Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé,

àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́

níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ,

àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ọba mi, ati Ọlọrun mi.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ,

wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae!

5 Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn,

tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún.

6 Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ,

wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi;

àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀.

7 Wọn ó máa ní agbára kún agbára,

títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.

8 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi;

tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!

9 Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun,

fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ.

10 Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ,

ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ.

Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi

ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.

11 Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa,

òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá,

nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́

ní ohun tí ó dára.

12 OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 85

Adura Ire Orílẹ̀-Èdè

1 OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ;

o dá ire Jakọbu pada.

2 O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;

o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

3 O mú ìrúnú rẹ kúrò;

o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró.

4 Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;

dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.

5 Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?

Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni?

6 Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,

kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ?

7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA;

kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

8 Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí,

nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀,

àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀,

ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀.

9 Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;

kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé;

òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn.

11 Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀;

òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run.

12 Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára;

ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ.

13 Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀,

yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 86

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,

nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí.

2 Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;

gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;

ìwọ ni Ọlọrun mi.

3 Ṣàánú mi, OLUWA,

nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.

4 Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,

nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.

5 Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,

o máa ń dárí jini;

ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

6 Fetí sí adura mi, OLUWA,

gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi.

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́,

nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.

8 OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa;

kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ.

9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,

OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:

wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo.

10 Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;

ìwọ nìkan ni Ọlọrun.

11 OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,

kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;

kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12 Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;

n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.

13 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;

o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.

14 Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;

ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;

wọn kò sì bìkítà fún ọ.

15 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;

o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.

16 Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;

fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;

kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.

17 Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,

kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,

kí ojú sì tì wọ́n;

nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,

tí o sì tù mí ninu.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 87

Ìyìn Sioni

1 Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà.

2 OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlú

yòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu.

3 Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ,

ìwọ ìlú Ọlọrun.

4 Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi,

n óo dárúkọ Ijiptiati Babiloni,

Filistia ati Tire, ati Etiopia.

Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.”

5 A óo wí nípa Sioni pé,

“Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,”

nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

6 OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọn

nígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,

“Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.”

7 Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé,

“Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 88

Adura nígbà ìpọ́njú

1 OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán;

mo ké níwájú rẹ ní òru.

2 Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;

tẹ́tí sí igbe mi.

3 Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;

mo sì súnmọ́ isà òkú.

4 Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ;

mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ.

5 N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú,

mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì,

bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́,

nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ.

6 O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,

ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun.

7 Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,

ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.

8 O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;

mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:

mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;

9 ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.

Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;

tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.

10 Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?

Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?

11 Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?

Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?

12 Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?

Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?

13 Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;

ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.

14 OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?

Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,

tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,

mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;

agara sì ti dá mi.

16 Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;

ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú.

17 Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;

wọ́n ká mi mọ́ patapata.

18 O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀;

òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 89

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi

1 OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;

n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

2 Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;

o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run.

3 O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹlu

ẹni tí mo yàn,

mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé,

4 ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,

n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

5 Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;

kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.

6 Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?

Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?

7 Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,

o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?

8 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?

OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.

9 Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;

nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.

10 Ìwọ ni o wó Rahabumọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;

o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11 Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;

ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.

12 Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,

òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀

yin orúkọ rẹ.

13 Alágbára ni ọ́;

agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;

o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.

14 Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;

ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.

15 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,

àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,

16 àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,

tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.

17 Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;

nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.

18 Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;

ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.

Ìlérí Ọlọrun fun Dafidi

19 Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,

“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,

mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan.

20 Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;

mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án;

21 kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,

kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun.

22 Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba.

23 N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀;

n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀.

24 Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀;

orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun.

25 N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;

agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate

26 Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,

Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’

27 N óo fi ṣe àkọ́bí,

àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.

28 N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;

majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin.

29 Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae;

ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.

30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀,

tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi,

31 bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,

tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́;

32 n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.

33 Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.

34 N kò ni yẹ majẹmu mi,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.

35 “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:

n kò ní purọ́ fún Dafidi.

36 Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,

ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ.

37 A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,

yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.”

Ìdárò Ìṣubú Ọba

38 Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;

o ti ta á nù,

o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

39 O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,

o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀.

40 O ti wó gbogbo odi rẹ̀;

o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro.

41 Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;

ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.

42 O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;

o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́.

43 Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́,

o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun.

44 O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀;

o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀.

45 O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;

o sì ti da ìtìjú bò ó.

Adura ìdáǹdè

46 Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi?

Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná?

47 OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ,

ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan!

48 Ta ló wà láyé tí kò ní kú?

Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?

49 OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà,

tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ?

50 OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́;

ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan,

51 OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́,

wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀.

52 Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae!

Amin! Amin!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 90

Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ

1 OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.

2 Kí o tó dá àwọn òkè,

ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,

láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.

3 O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,

o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”

4 Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,

tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.

5 Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,

bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;

6 ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;

ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ.

7 Ibinu rẹ pa wá run;

ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀.

8 O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ;

àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.

9 Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ;

ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀.

10 Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;

pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;

sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;

kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.

11 Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?

Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí?

12 Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa,

kí á lè kọ́gbọ́n.

13 Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa?

Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ.

14 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,

kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn

ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

15 Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o

ti fi pọ́n wa lójú,

ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi.

16 Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ,

kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa,

fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀,

jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 91

Ọlọrun Aláàbò wa

1 Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo,

tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare,

2 yóo wí fún OLUWA pé,

“Ìwọ ni ààbò ati odi mi,

Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.”

3 Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun.

4 Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́,

lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò;

òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ.

5 O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru,

tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán,

6 tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn,

tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan.

7 Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ;

ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

8 Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn,

tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú.

9 Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ,

o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ,

10 ibi kankan kò ní dé bá ọ,

bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ.

11 Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ,

pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.

12 Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè,

kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.

13 O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀;

ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi,

n óo gbà á là;

n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi.

15 Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn;

n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro,

n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá.

16 N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,

n óo sì gbà á là.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 92

Orin Ìyìn

1 Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA;

kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo;

2 ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀,

kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́,

3 pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá,

ati hapu.

4 Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ;

OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

5 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA!

Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ!

6 Òpè eniyan kò lè mọ̀,

kò sì le yé òmùgọ̀:

7 pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko,

tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀,

ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn.

8 Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.

9 Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;

gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká.

10 Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;

o ti da òróró dáradára sí mi lórí.

11 Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,

mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí.

12 Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,

wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.

13 Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,

tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.

14 Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,

wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo;

15 láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA;

òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 93

Ọlọrun Ọba

1 OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù;

OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀,

ó sì di agbára ni àmùrè.

Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;

kò sì ní yẹ̀ laelae.

2 A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae;

láti ayérayé ni o ti wà.

3 Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA,

ibú omi gbé ohùn wọn sókè,

ó sì ń sán bí ààrá.

4 OLUWA lágbára lókè!

Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ,

ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ.

5 Àwọn òfin rẹ kìí yipada,

ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA.