Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 64

Adura Ààbò

1 Ọlọrun, gbọ́ ìráhùn mi;

pa mí mọ́ lọ́wọ́ ìdẹ́rùbà ọ̀tá;

2 dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú;

kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi.

3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,

wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà;

4 wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn,

láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì.

5 Wọ́n wonkoko mọ́ ète burúkú wọn;

wọ́n ń gbìmọ̀ àtidẹ okùn sílẹ̀ níkọ̀kọ̀,

wọ́n ń rò lọ́kàn wọn pé, “Ta ni yóo rí wa?

6 Ta ni yóo wá ẹ̀ṣẹ̀ wa rí?

Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni a ti fi pète.”

Áà, inú ọmọ eniyan jìn!

7 Ṣugbọn Ọlọrun yóo ta wọ́n lọ́fà;

wọn óo fara gbọgbẹ́ lójijì.

8 Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ;

gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn.

9 Ẹ̀rù yóo sì ba gbogbo eniyan;

wọn yóo máa sọ ohun tí Ọlọrun ti gbé ṣe,

wọn yóo sì máa ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀.

10 Kí àwọn olódodo máa yọ̀ ninu OLUWA,

kí wọ́n sì máa wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀!

Kí gbogbo ẹni pípé máa ṣògo.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 65

Ìyìn ati Ọpẹ́

1 Ọlọrun, ìwọ ni ìyìn yẹ ní Sioni,

ìwọ ni a óo san ẹ̀jẹ́ wa fún,

2 ìwọ tí ń gbọ́ adura!

Ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo eniyan ń bọ̀,

3 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá borí wa,

ìwọ a máa dáríjì wá.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn,

tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,

láti máa gbé inú àgbàlá rẹ.

Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn,

àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ!

5 Iṣẹ́ òdodo tí ó bani lẹ́rù ni o fi dá wa lóhùn,

Ọlọrun olùgbàlà wa.

Ìwọ ni gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́kẹ̀lé,

ati àwọn tí wọn wà lórí omi òkun ní ọ̀nà jíjìn réré.

6 Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀;

tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè.

7 O mú híhó òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́,

ariwo ìgbì wọn rọlẹ̀ wọ̀ọ̀;

o sì paná ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan.

8 Àwọn tí ń gbé ìpẹ̀kun ayé sì ń bẹ̀rù

nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ;

o mú kí àwọn eniyan, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, hó ìhó ayọ̀.

9 Ò ń ṣìkẹ́ ayé, o sì ń bomi rin ín,

o mú kí ilẹ̀ jí kí ó sì lẹ́tù lójú;

o mú kí omi kún inú odò ìwọ Ọlọrun,

o mú kí ọkà hù lórí ilẹ̀;

nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni o ṣe ṣètò rẹ̀.

10 O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ,

o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀;

o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀,

o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà.

11 O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún;

gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko.

12 Gbogbo pápá oko kún fún ẹran ọ̀sìn,

àwọn ẹ̀gbẹ́ òkè sì kún fún ohun ayọ̀,

13 ẹran ọ̀sìn bo pápá oko bí aṣọ,

ọkà bo gbogbo àfonífojì, ó sì so jìngbìnnì,

wọ́n ń hó, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 66

Orin Ìyìn ati Ọpẹ́

1 Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun.

2 Ẹ kọ orin ògo yin orúkọ rẹ̀;

ẹ yìn ín, ẹ fògo fún un!

3 Ẹ sọ fún Ọlọrun pé,

“Iṣẹ́ rẹ bani lẹ́rù pupọ,

agbára rẹ pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,

tí àwọn ọ̀tá rẹ fi ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ.

4 Gbogbo ayé ní ń sìn ọ́;

wọ́n ń kọ orin ìyìn fún ọ,

wọ́n ń kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”

5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọrun ṣe,

iṣẹ́ tí ó ń ṣe láàrin ọmọ eniyan bani lẹ́rù.

6 Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀,

àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò.

Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe.

7 Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae.

Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji,

kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.

8 Ẹ yin Ọlọrun wa, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ìró ìyìn rẹ̀;

9 ẹni tí ó dá wa sí tí a fi wà láàyè,

tí kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa yẹ̀.

10 Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti dán wa wò;

o ti dán wa wò bíi fadaka tí a dà ninu iná.

11 O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;

o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.

12 O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,

a ti la iná ati omi kọjá;

sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú.

13 N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;

n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ.

14 Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,

tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú.

15 N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ,

èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run,

n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ.

16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun,

n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi.

17 Mo ké pè é,

mo sì kọrin yìn ín.

18 Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi,

OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi.

19 Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́;

ó sì ti dáhùn adura mi.

20 Ìyìn ni fún Ọlọrun,

nítorí pé kò kọ adura mi;

kò sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ kúrò lórí mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 67

Orin Ọpẹ́

1 Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa;

kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára;

2 kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀;

kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀.

3 Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;

jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!

4 Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn,

kí wọn ó máa kọrin ayọ̀,

nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju;

o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé.

5 Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;

jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!

6 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde;

Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa.

7 Ọlọrun bukun wa,

kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 68

Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè

1 Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká.

Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀.

2 Bí èéfín tií pòórá,

bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́;

bí ìda tií yọ́ níwájú iná,

bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun.

3 Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn,

kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun;

kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.

4 Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀,

ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin.

OLUWA ni orúkọ rẹ̀;

ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

5 Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun,

ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́.

6 Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà;

ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra,

ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ.

7 Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ,

nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já,

8 ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò,

níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai,

àní, níwájú Ọlọrun Israẹli.

9 Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀;

o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò.

10 Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀;

Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.

11 OLUWA fọhùn,

ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀.

12 Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn;

àwọn obinrin tí ó wà nílé,

13 ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín:

fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà;

wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀.

14 Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká,

ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́.

15 Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá;

Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ.

16 Ẹ̀yin òkè olórí pupọ,

kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé,

ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae?

17 OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀

pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun,

ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun.

18 Ó gun òkè gíga,

ó kó àwọn eniyan nígbèkùn;

ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan,

ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá.

OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.

19 Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun ìgbàlà wa,

tí ń bá wa gbé ẹrù wa lojoojumọ.

20 Ọlọrun tí ń gbani là ni Ọlọrun wa;

OLUWA Ọlọrun ni ń yọni lọ́wọ́ ikú.

21 Dájúdájú, OLUWA yóo fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀;

yóo fọ́ àtàrí àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀.

22 OLUWA ní,

“N óo kó wọn pada láti Baṣani,

n óo kó wọn pada láti inú ibú omi òkun,

23 kí ẹ lè fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá yín,

kí àwọn ajá yín lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n.”

24 A ti rí ọ, Ọlọrun, bí o tí ń yan lọ,

pẹlu ọ̀wọ́ èrò tí ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn.

Ẹ wo Ọlọrun mi, ọba mi,

bí ó ti ń yan wọ ibi mímọ́ rẹ̀,

25 àwọn akọrin níwájú,

àwọn onílù lẹ́yìn,

àwọn ọmọbinrin tí ń lu samba láàrin.

26 “Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan,

ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.”

27 Ẹ wo Bẹnjamini tí ó kéré jù níwájú,

ẹ wo ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjòyè Juda,

ẹ wo àwọn ìjòyè Sebuluni ati ti Nafutali.

28 Fi agbára rẹ hàn, Ọlọrun,

fi agbára tí o ti fi jà fún wa hàn.

29 Nítorí Tẹmpili rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu,

àwọn ọba yóo gbé ẹ̀bùn wá fún ọ.

30 Bá àwọn ẹranko ẹ̀dá tí ń gbé inú èèsún ní Ijipti wí;

àwọn akọ mààlúù, láàrin agbo ẹran àwọn orílẹ̀-èdè.

Tẹ àwọn tí ó fẹ́ràn owó mọ́lẹ̀;

fọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ràn ogun ká.

31 Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti,

kí àwọn ará Kuṣitẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun.

32 Ẹ kọ orin sí Ọlọrun ẹ̀yin ìjọba ayé;

ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA.

33 Ẹni tí ń gun awọsanma lẹ́ṣin, àní awọsanma àtayébáyé;

ẹ gbọ́ bí ó ṣe ń sán ààrá, ẹ gbọ́ ohùn alágbára.

34 Ẹ bu ọlá fún Ọlọrun,

ẹni tí ògo rẹ̀ wà lórí Israẹli;

tí agbára rẹ̀ sì hàn lójú ọ̀run.

35 Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni Ọlọrun ní ibi mímọ́ rẹ̀,

Ọlọrun Israẹli;

òun ni ó ń fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọlá ati agbára.

Ìyìn ni fún Ọlọrun!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 69

Igbe fún Ìrànlọ́wọ́

1 Gbà mí, Ọlọrun,

nítorí omi ti mù mí dé ọrùn.

2 Mo ti rì sinu irà jíjìn,

níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀;

mo ti bọ́ sinu ibú,

omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀.

3 Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi,

ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ,

ojú mi sì di bàìbàì,

níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi.

4 Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀,

wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ.

Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára.

Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi,

àwọn nǹkan tí n kò jí

ni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada.

5 Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,

àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ.

6 Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,

OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,

má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù,

Ọlọrun Israẹli.

7 Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn,

tí ìtìjú sì bò mí.

8 Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,

mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi.

9 Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,

ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.

10 Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀,

ó di ẹ̀gàn fún mi.

11 Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀,

mo di ẹni àmúpòwe.

12 Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodè

fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ;

àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ.

13 Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura sí

ní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,

ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.

14 Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,

gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

15 Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,

kí ibú omi má gbé mi mì,

kí isà òkú má sì padé mọ́ mi.

16 Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ

tí kì í yẹ̀ dára;

fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ.

17 Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ,

nítorí tí mo wà ninu ìdààmú,

yára dá mi lóhùn.

18 Sún mọ́ mi, rà mí pada,

kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi!

19 O mọ ẹ̀gàn mi,

o mọ ìtìjú ati àbùkù mi;

o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi.

20 Ẹ̀gàn ti mú kí inú mi bàjẹ́,

tóbẹ́ẹ̀ tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì

mò ń retí àánú ṣugbọn kò sí;

mò ń retí olùtùnú, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.

21 Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi,

nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,

ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu.

22 Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún ara

wọn di ẹ̀bìtì fún wọn;

kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté.

23 Jẹ́ kí ojú wọn ṣú,

kí wọn má lè ríran;

kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì.

24 Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí,

kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ.

25 Kí ibùdó wọn ó di ahoro,

kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn.

26 Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;

ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú.

27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;

má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ.

28 Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;

kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.

29 Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;

Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè!

30 Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun;

n óo fi ọpẹ́ gbé e ga.

31 Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ,

àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀.

32 Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,

inú wọn yóo dùn;

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí.

33 Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní,

kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn.

34 Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín,

òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn.

35 Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là;

yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́;

àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀,

yóo sì di tiwọn.

36 Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀;

àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 70

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Ọlọrun, dákun, gbà mí,

yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

2 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mi

kí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;

jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,

kí wọn sì tẹ́.

3 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo

àwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;

kí wọn sì gba èrè ìtìjú.

4 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,

kí inú wọn sì máa dùn,

kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,

“Ọlọrun tóbi!”

5 Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí,

yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun!

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi,

má pẹ́ OLÚWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 71

Adura Àgbàlagbà kan

1 OLUWA, ìwọ ni mo sá di;

má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!

2 Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;

tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!

3 Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,

jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,

nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.

4 Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,

àwọn alaiṣootọ ati ìkà.

5 Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,

OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.

6 Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;

ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.

Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.

7 Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,

ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8 Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,

ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.

9 Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;

má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.

10 Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,

àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,

11 wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;

ẹ lé e, ẹ mú un;

nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”

12 Ọlọrun, má jìnnà sí mi;

yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!

13 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;

kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,

n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.

15 N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,

n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,

nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.

16 N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,

n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.

17 Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,

títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,

18 Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,

Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,

títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,

àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.

19 Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,

ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,

Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?

20 O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,

ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;

óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.

21 O óo fi kún ọlá mi,

o óo sì tún tù mí ninu.

22 Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́,

nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi;

n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́,

ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.

23 N óo máa kígbe fún ayọ̀,

nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ;

ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀.

24 Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru,

nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,

a sì ti dójú tì wọ́n.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 72

Adura Ọba

1 Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́;

kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ.

2 Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ,

kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́;

3 kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia,

kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké.

4 Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ;

kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀;

kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú.

5 Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran,

níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ.

6 Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti gé

àní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀.

7 Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀;

kí alaafia ó gbilẹ̀ títí

tí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́.

8 Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun,

ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé.

9 Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un;

àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀.

10 Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogbo

yóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un;

àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá.

11 Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un;

gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.

12 Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀;

a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,

ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

13 A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka,

a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀.

14 A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá,

ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.

15 Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn,

a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ,

a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo;

a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru.

16 Ọkà yóo pọ̀ lóko,

yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè;

èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni,

eniyan yóo pọ̀ ní ìlú,

bíi koríko ninu pápá.

17 Orúkọ ọba óo wà títí lae,

òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn;

àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn,

gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire.

18 Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli,

ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe.

19 Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí,

kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan!

Amin! Amin.

20 Níbi tí adura Dafidi ọmọ Jese parí sí nìyí.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 73

Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun

1 Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,

ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.

2 Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,

ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé.

3 Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga

nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

4 Wọn kì í jẹ ìrora kankan,

ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.

5 Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;

ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.

6 Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,

wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.

7 Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;

èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.

8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;

wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.

9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;

wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.

10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,

wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.

11 Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?

Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”

12 Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;

ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.

13 Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,

tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.

14 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;

láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.

15 Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”

n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.

16 Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,

mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.

17 Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,

ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

18 Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,

ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.

19 Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,

tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.

20 Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.

OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.

21 Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,

tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,

22 mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,

mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.

23 Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;

o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24 Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;

lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.

25 Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?

Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.

26 Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,

ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,

ati ìpín mi títí lae.

27 Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,

o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.

28 Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;

mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,

kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.