Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 54

Adura Ààbò

1 Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun,

fi ipá rẹ dá mi láre.

2 Gbọ́ adura mi, Ọlọrun;

tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3 Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi,

àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi;

wọn kò bìkítà fún Ọlọrun.

4 Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,

OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.

5 Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi;

OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run.

6 N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ,

n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA,

nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.

7 O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi,

mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 55

Adura Ẹni tí Ọ̀rẹ́ Dà

1 Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun,

má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀.

2 Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn;

ìṣòro ti borí mi.

3 Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́,

nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú;

wọ́n kó ìyọnu bá mi,

wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá.

4 Ọkàn mi wà ninu ìrora,

ìpayà ikú ti dé bá mi.

5 Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí,

ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀.

6 Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!

Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi.

7 Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré,

kí n lọ máa gbé inú ijù;

8 ǹ bá yára lọ wá ibi ààbò

kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.”

9 Da èrò wọn rú, OLUWA,

kí o sì dà wọ́n lédè rú;

nítorí ìwà ipá ati asọ̀ pọ̀ ninu ìlú.

10 Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí orí odi rẹ̀ ká;

ìwà ìkà ati ìyọnu ni ó sì pọ̀ ninu rẹ̀.

11 Ìparun wà ninu rẹ̀;

ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀.

12 Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí,

ǹ bá lè fara dà á.

Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi,

ǹ bá fara pamọ́ fún un.

13 Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi,

alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.

14 À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;

a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.

15 Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa;

kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè;

kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà.

16 Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun;

OLUWA yóo sì gbà mí.

17 Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru,

mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi.

18 Yóo yọ mí láìfarapa,

ninu ogun tí mò ń jà,

nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí,

tí wọn ń bá mi jà.

19 Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́,

yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,

nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà,

wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun.

20 Alábàárìn mi gbógun ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,

ó yẹ àdéhùn rẹ̀.

21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ,

bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀;

ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ,

ṣugbọn idà aṣekúpani ni.

22 Kó gbogbo ìṣòro rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,

yóo sì gbé ọ ró;

kò ní jẹ́ kí á ṣí olódodo ní ipò pada.

23 Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apani

ati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun;

wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn.

Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 56

Adura Igbẹkẹle Ọlọrun

1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi;

ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru.

2 Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru,

ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga.

3 Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,

èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4 Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,

ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;

kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

5 Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;

ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.

6 Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,

wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,

bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.

7 Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;

ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀.

8 O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;

ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,

wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ.

9 A óo lé àwọn ọ̀tá mi pada

ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.

Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.

10 Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;

11 Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.

Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

12 Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun;

n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ.

13 Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú,

o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀,

kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrun

ninu ìmọ́lẹ̀ ìyè.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 57

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi,

nítorí ìwọ ni ààbò mi;

abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi,

títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá.

2 Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,

Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi.

3 Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,

yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.

Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀

ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!

4 Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,

àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;

eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,

ahọ́n wọn sì dàbí idà.

5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,

gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,

kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.

6 Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;

ìpọ́njú dorí mi kodò.

Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,

ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i.

7 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,

ọkàn mi dúró ṣinṣin!

N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.

8 Jí, ìwọ ọkàn mi!

Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,

èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu.

9 OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;

n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

10 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,

òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

11 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,

gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,

kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 58

Kí Ọlọrun jẹ Ìkà níyà

1 Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́?

2 Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò,

iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé.

3 Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,

láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,

tí wọn ń purọ́.

4 Wọ́n ní oró bí oró ejò,

wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,

5 kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,

tabi ìpè adáhunṣe.

6 Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;

OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun.

7 Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;

kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.

8 Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,

ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí.

9 Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;

ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ.

10 Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké,

yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú.

11 Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé,

“Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo;

nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 59

Adura Ààbò

1 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi;

dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí.

2 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi,

kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn.

3 Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí!

OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọ

láti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò.

4 Láìjẹ́ pé mo ṣẹ̀, wọ́n ń sáré kiri, wọ́n múra dè mí.

Paradà, wá ràn mí lọ́wọ́, kí o sì rí i fúnra rẹ.

5 Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,

Ọlọrun Israẹli,

jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà;

má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi.

6 Ní alaalẹ́, wọn á pada wá,

wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú.

7 Ẹ gbọ́ ohun tí wọn ń sọ jáde lẹ́nu,

ẹ wo ahọ́n wọn bí idà;

wọ́n sì ń wí ninu ara wọn pé, “Ta ni yóo gbọ́ ohun tí à ń sọ?”

8 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín,

o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́.

9 Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò,

nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi.

10 Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀;

Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi.

11 Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé;

fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n,

ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa!

12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá,

àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ,

jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn.

Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa,

13 fi ibinu pa wọ́n run.

Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́,

kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu,

ati títí dé òpin ayé.

14 Ní alaalẹ́ wọn á pada wá

wọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú.

15 Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri,

bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn.

16 Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ;

n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tí

kì í yẹ̀.

Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi mi

ìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú.

17 Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ,

nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi,

Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 60

Adura fún Ìgbàlà

1 Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,

o ti wó odi wa;

o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò.

2 O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;

o ti mú kí ó yanu;

dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì.

3 O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,

o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

4 O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá.

5 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,

fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa,

kí o sì dá wa lóhùn.

6 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,

ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,

n óo sì pín àfonífojì Sukotu.

7 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;

Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,

Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

8 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi;

lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé;

n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.”

9 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?

Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?

10 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?

Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

11 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,

nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.

12 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin,

nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 61

Adura Ààbò

1 Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun,

fetí sí adura mi.

2 Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́,

nígbà tí àárẹ̀ mú mi.

Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ,

3 nítorí ìwọ ni ààbò mi,

ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbára

láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá.

4 Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae,

kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ.

5 Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́;

o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn;

kí ó pẹ́ láyé kánrinkése.

7 Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae;

máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ.

8 Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae,

nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 62

Ọlọrun ni Ààbò Wa

1 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé;

ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.

2 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,

òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.

3 Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa,

ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya?

4 Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀.

Inú wọn a máa dùn sí irọ́.

Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,

ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́.

5 Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé,

nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.

6 Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,

òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.

7 Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà;

òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi.

8 Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan;

ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀;

OLUWA ni ààbò wa.

9 Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù;

ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá;

bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n;

àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ.

10 Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà,

má sì fi olè jíjà yangàn;

bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e.

11 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan,

mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé,

Ọlọrun ló ni agbára;

12 ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.

Ò máa san ẹ̀san fún eniyan

gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 63

Wíwá Ọlọrun

1 Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ,

ọkàn rẹ ń fà mí;

bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹ

ṣe máa ń kóǹgbẹ omi.

2 Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ,

mo ti rí agbára ati ògo rẹ.

3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ,

n óo máa yìn ọ́.

4 N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi;

n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ.

5 Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù;

n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.

6 Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,

tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru;

7 nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,

lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin.

8 Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ;

ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró.

9 Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi

yóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú.

10 A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun,

ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn.

11 Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun;

gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búra

yóo máa fògo fún un;

ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́.