Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 44

Adura Ààbò

1 Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́,

àwọn baba wa sì ti sọ fún wa,

nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,

àní, ní ayé àtijọ́:

2 Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn,

tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀;

o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà,

o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa.

3 Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,

kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun;

agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ati ojurere rẹ;

nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.

4 Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi;

ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun.

5 Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn,

orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀.

6 Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;

idà mi kò sì le gbà mí.

7 Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,

o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa.

8 Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;

a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.

9 Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,

o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

10 O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;

àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.

11 O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,

o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

12 O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,

o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.

13 O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;

a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.

14 O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.

15 Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,

ìtìjú sì ti bò mí.

16 Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,

lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.

17 Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ.

18 Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,

19 sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,

o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,

tabi tí a bá bọ oriṣa,

21 ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?

Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.

22 Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,

tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà.

23 Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn?

Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae.

24 Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?

Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa?

25 Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;

àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́.

26 Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́!

Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 45

Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba

1 Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn,

mò ń kọ orin mi fún ọba

ahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́.

2 Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin;

ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ,

nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé.

3 Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára,

ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ.

4 Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ,

máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́,

kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá.

5 Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn,

àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ.

6 Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae.

Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni.

7 O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkà

nítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́.

Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ ga

ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ.

8 Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,

láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́

ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.

9 Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ,

ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára.

10 Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀,

gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ;

11 ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba;

òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un.

12 Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ,

àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ.

13 Yóo máa wá ojurere rẹ,

pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀.

Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀,

14 ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba,

pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ.

15 Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ,

bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba.

16 Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ;

o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé.

17 N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran;

nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 46

Ọlọrun Wà pẹlu Wa

1 Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa,

olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú.

2 Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí,

bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun;

3 bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru,

tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtì

nítorí agbára ríru rẹ̀.

4 Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn,

ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo.

5 Ọlọrun wà láàrin rẹ̀,

kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò;

Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu.

6 Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru,

àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n;

OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́.

7 OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa;

Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.

8 Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA,

irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé.

9 Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé,

ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀,

ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun.

10 “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun.

A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

a gbé mi ga ní ayé.”

11 OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa,

Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 47

Ọba Àwọn Ọba

1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;

ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun.

2 Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,

Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

3 Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,

ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa.

4 Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,

èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn.

5 A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀,

a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè.

6 Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn;

Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn!

7 Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;

Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn!

8 Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;

Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.

9 Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ

pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu.

Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé;

òun ni ọlọ́lá jùlọ!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 48

OLUWA Tóbi

1 OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ

ní ìlú Ọlọrun wa.

2 Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà,

ni ayọ̀ gbogbo ayé.

Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré,

ìlú ọba ńlá.

3 Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi.

4 Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;

wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í.

5 Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,

ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;

6 ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;

ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.

7 Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi.

8 Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,

ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ní ìlú Ọlọrun wa:

Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

9 Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,

à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

10 Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,

bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,

iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.

11 Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,

kí gbogbo Juda sì máa yọ̀

nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;

ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀;

13 ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;

ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,

kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀

14 pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,

lae ati laelae.

Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 49

Ìwà Òmùgọ̀ ni Igbẹkẹle Ọrọ̀

1 Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!

Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé,

2 ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,

àtolówó ati talaka!

3 Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;

àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.

4 N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;

n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.

5 Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,

nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,

6 àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,

tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?

7 Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,

tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun;

8 nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.

Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀,

9 tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,

kí ó má fojú ba ikú.

10 Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,

òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;

wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.

11 Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,

ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,

wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn.

12 Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé,

bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú.

13 Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí,

òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn.

14 Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn,

ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn;

ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà.

Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́,

Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀,

ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn.

15 Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikú

nítorí pé yóo gbà mí.

16 Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó,

tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i.

17 Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú,

kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ;

dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì.

18 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè,

ó rò pé Ọlọrun bukun òun,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyan

nígbà tí nǹkan bá ń dára fún un,

19 yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú,

kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́.

20 Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé;

bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 50

Ìsìn Tòótọ́

1 OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀:

ó ké sí gbogbo ayé

láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

2 Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni,

ìlú tó dára, tó lẹ́wà.

3 Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́:

iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀;

ìjì líle sì ń jà yí i ká.

4 Ó ké sí ọ̀run lókè;

ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀.

5 Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi,

àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!”

6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ pé

Ọlọrun ni onídàájọ́.

7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀,

Israẹli, n óo takò yín.

Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín.

8 N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú;

nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi.

9 N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín,

tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín.

10 Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó,

tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè.

11 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ni mo mọ̀,

tèmi sì ni gbogbo nǹkan tí ń rìn ninu pápá.

12 “Bí ebi bá tilẹ̀ pa mí, ẹ̀yin kọ́ ni n óo sọ fún,

nítorí èmi ni mo ni gbogbo ayé ati àwọn nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.

13 Ṣé èmi a máa jẹ ẹran akọ mààlúù?

Àbí mà máa mu ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?

14 Ọpẹ́ ni kí ẹ fi rúbọ sí Ọlọrun,

kí ẹ sì máa san ẹ̀jẹ́ yín fún Ọ̀gá Ògo.

15 Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro;

n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”

16 Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé,

“Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi,

tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi?

17 Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́;

ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù.

18 Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́;

ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́.

19 “Ọ̀rọ̀ ibi dùn lẹ́nu yín pupọ;

ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì yọ̀ létè yín.

20 Ẹ̀ ń jókòó sọ̀rọ̀ arakunrin yín níbi:

ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ọmọ ìyá yín.

21 Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ti ṣe tí mo sì dákẹ́;

ẹ wá ń rò ninu yín pé, èmi yín rí bákan náà.

Ṣugbọn nisinsinyii mò ń ba yín wí,

mo sì ń fi ẹ̀sùn kàn yín.

22 “Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun,

kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀.

23 Ẹni tí ó bá mu ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi, ni ó bu ọlá fún mi;

ẹni tí ó bá sì rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni èmi Ọlọrun yóo gbà là.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 51

Adura Ìdáríjì

1 Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;

nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ pa ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.

2 Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi,

kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!

3 Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀,

nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi.

4 Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀,

tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ,

kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́,

kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́.

5 Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi,

ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi.

6 O fẹ́ràn òtítọ́ inú;

nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.

7 Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;

wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.

8 Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,

kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.

9 Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,

kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́.

10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun,

kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.

11 Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.

12 Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi,

kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró.

13 Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ,

àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ.

14 Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun,

ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi,

n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ.

15 OLUWA, là mí ní ohùn,

n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ.

16 Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ;

ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun.

17 Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́,

ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn.

18 Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ;

tún odi Jerusalẹmu mọ.

19 Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́,

ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi;

nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 52

Ìdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun

1 Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu,

kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru?

Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun.

2 Ò ń pète ìparun;

ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè.

3 O fẹ́ràn ibi ju ire lọ,

o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.

4 O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́,

Ìwọ ẹlẹ́tàn!

5 Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀,

yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ;

yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.

6 Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,

wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé,

7 “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀,

ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀,

ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.”

8 Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútù

tí ń dàgbà ninu ilé OLUWA,

mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae.

9 N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae,

nítorí ohun tí o ṣe,

n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ,

nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 53

Èrè Òmùgọ̀

1 Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé,

“Kò sí Ọlọrun.”

Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe,

kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.

2 Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá,

ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé,

àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun.

3 Gbogbo wọn ni ó ti yapa;

tí wọn sì ti bàjẹ́,

kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,

kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo.

4 Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?

Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,

àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun.

5 Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá,

ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí!

Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká;

ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n.

6 Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!

Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,

Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.