Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 34

Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀

1 N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;

ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.

2 OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;

kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.

3 Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,

ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!

4 Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,

ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.

5 Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀;

ojú kò sì tì wọ́n.

6 Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,

ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

7 Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,

a sì máa gbà wọ́n.

8 Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA!

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í!

9 Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀,

nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀!

10 Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní,

ebi a sì máa pa wọ́n;

ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA

kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan.

11 Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi,

n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.

12 Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,

tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,

tí ó fẹ́ pẹ́ láyé?

13 Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,

ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.

14 Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;

ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.

15 OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo,

Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn.

16 OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,

láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.

17 Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,

a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn.

18 OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,

a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.

19 Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;

ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.

20 A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́;

kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn.

21 Ibi ni yóo pa eniyan burúkú;

a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi.

22 OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada;

ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 35

Adura ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí;

gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà!

2 Gbá asà ati apata mú,

dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́!

3 Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi!

Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi.

4 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi,

kí wọn ó tẹ́!

Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú,

kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn!

5 Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́,

kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ!

6 Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀,

kí angẹli OLUWA máa lépa wọn!

7 Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí,

wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí.

8 Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì,

jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn;

jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun!

9 Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA,

n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀.

10 N óo fi gbogbo ara wí pé,

“OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ?

Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbára

lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára

tí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìní

lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.”

11 Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi;

wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí.

12 Wọ́n fi ibi san oore fún mi,

ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.

13 Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn,

aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀;

mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà;

mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata,

14 bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi;

mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀,

mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀.

15 Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ,

wọ́n ń yọ̀,

wọ́n kó tì mí;

pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ rí

bẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra.

16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà;

wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú.

Adura Ìdáláre

17 OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran?

Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí,

gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun!

18 Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan;

láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́.

19 Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí,

má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín.

20 Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn

àfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn.

21 Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí,

wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!”

22 O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́.

OLUWA, má jìnnà sí mi.

23 Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi,

gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi!

24 Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ;

má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí!

25 Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé,

“Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!”

Má jẹ́ kí wọn wí pé,

“A rẹ́yìn ọ̀tá wa.”

26 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi;

kí ìdààmú bá wọn;

bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi.

27 Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mi

máa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn,

kí wọ́n máa wí títí ayé pé,

“OLUWA tóbi,

inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.”

28 Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,

n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 36

Ìwà ìkà

1 Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú,

kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀.

2 Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀,

pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun,

ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi.

3 Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.

Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;

kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.

4 A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀;

a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́;

kò sì kórìíra ibi.

Oore Ọlọrun

5 OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run;

òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

6 Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá;

ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi.

OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà.

7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun!

Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

8 Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ;

nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò,

ni o sì ń fún wọn mu.

9 Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;

ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.

10 Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀

han àwọn tí ó mọ̀ ọ́,

sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́.

11 Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi,

má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò.

12 Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;

wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 37

Ìgbẹ̀yìn Àwọn Eniyan Burúkú

1 Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú;

má sì jowú àwọn aṣebi;

2 nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko;

wọn óo sì rọ bí ewé.

3 Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere.

Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.

4 Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA;

yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.

5 Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́;

gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ.

6 Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀;

ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan.

7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e.

Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún;

tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.

8 Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú.

Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀.

9 Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run;

ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA

ni yóo jogún ilẹ̀ náà.

10 Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá;

ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀.

11 Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà:

wọn óo máa gbádùn ara wọn;

wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ.

12 Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo;

ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè.

13 Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín,

nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀.

14 Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn

láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní,

láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́.

15 Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n,

ọrun wọn yóo sì dá.

16 Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní

dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

17 Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú,

ṣugbọn yóo gbé olódodo ró.

18 OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi;

ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae.

19 Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé;

bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé;

àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko

wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́.

21 Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san;

ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́.

22 Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà,

ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun.

23 OLUWA níí darí ìgbésẹ̀ ẹni;

a sì máa fi ẹsẹ̀ ẹni tí inú rẹ̀ bá dùn sí múlẹ̀.

24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú, kò ní lulẹ̀ lógèdèǹgbé,

nítorí OLUWA yóo gbé e ró.

25 Mo ti jẹ́ ọmọde rí; mo sì ti dàgbà:

n kò tíì ri kí á kọ olódodo sílẹ̀,

tabi kí ọmọ rẹ̀ máa tọrọ jẹ.

26 Olódodo ní ojú àánú, a sì máa yáni ní nǹkan,

ayọ̀ ń bẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27 Ẹ yẹra fún ibi; ẹ sì máa ṣe rere;

kí ẹ lè wà ní ààyè yín títí lae.

28 Nítorí OLUWA fẹ́ràn ẹ̀tọ́;

kò ní kọ àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sílẹ̀.

Yóo máa ṣọ́ wọn títí lae,

ṣugbọn a óo pa àwọn ọmọ eniyan burúkú run.

29 Àwọn ẹni rere ni yóo jogún ilẹ̀ náà;

wọn óo sì máa gbé orí rẹ̀ títí lae.

30 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa jáde lẹ́nu ẹni rere,

a sì máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́.

31 Òfin Ọlọrun rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;

ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í yà kúrò níbẹ̀.

32 Eniyan burúkú ń ṣọ́ olódodo,

ó ń wá ọ̀nà ati pa á.

33 OLUWA kò ní fi olódodo lé e lọ́wọ́,

tabi kí ó jẹ́ kí á dá olódodo lẹ́bi ní ilé ẹjọ́.

34 Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, sì máa tọ ọ̀nà rẹ̀,

yóo gbé ọ ga, kí o lè jogún ilẹ̀ náà;

nígbà tí a bá pa àwọn eniyan burúkú run, o óo fojú rẹ rí i.

35 Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni,

tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni.

36 Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá,

mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́;

mo wá a, ṣugbọn n kò rí i.

37 Ṣe akiyesi ẹni pípé;

sì wo olódodo dáradára,

nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára.

38 Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata,

a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú.

39 Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá;

òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro.

40 OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n;

a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,

a sì máa gbà wọ́n là,

nítorí pé òun ni wọ́n sá di.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 38

Adura Ẹni tí Ìyà ń Jẹ

1 OLUWA, má fi ibinu bá mi wí!

Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà!

2 Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára,

ọwọ́ rẹ sì ti bà mí.

3 Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara mi

nítorí ibinu rẹ;

kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi,

nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.

4 Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀;

ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlá

tí ó wúwo jù fún mi.

5 Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn,

nítorí ìwà òmùgọ̀ mi,

6 Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,

mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru.

7 Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,

kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi.

8 Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;

mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi.

9 OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,

ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ.

10 Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá;

ojú mi sì ti di bàìbàì.

11 Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi,

àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré.

12 Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,

àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi,

wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru.

13 Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́,

mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀.

14 Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀,

tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu.

15 Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè;

OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn.

16 Nítorí tí mò ń gbadura pé,

kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mí

nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.

17 Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,

mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo.

18 Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi,

mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

19 Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára,

àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀.

20 Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí,

nítorí pé rere ni mò ń ṣe.

21 OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀,

Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi.

22 Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 39

Ìráhùn Ẹni tí Ìyà ń Jẹ

1 Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra,

kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀;

n óo kó ẹnu mi ní ìjánu,

níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.”

2 Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan;

n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá;

sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i

3 ìdààmú dé bá ọkàn mi.

Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú;

mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní:

4 “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi,

ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi,

kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.”

5 Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan,

ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ;

dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.

6 Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji,

asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀;

eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá,

láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ.

7 Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé?

Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì.

8 Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi;

má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀.

9 Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi;

nítorí pé ìwọ ni o ṣe é.

10 Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi,

mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí.

11 Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyà

pẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,

ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.

Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.

12 “OLUWA, gbọ́ adura mi,

tẹ́tí sí igbe mi,

má dágunlá sí ẹkún mi,

nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́;

àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.

13 Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi,

kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ;

àní, kí n tó ṣe aláìsí.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 40

Orin ìyìn

1 Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA,

ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi.

2 Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,

láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;

ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,

ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.

3 Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,

àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.

Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,

wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,

tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,

tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,

àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.

5 OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,

o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.

Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;

bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,

kí n máa ròyìn wọn,

wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ.

6 O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,

ṣugbọn o là mí ní etí;

o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

7 Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;

a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:

8 mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;

mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”

9 Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.

Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,

gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.

10 Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.

Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;

n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

ninu àwùjọ ńlá.

11 Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,

sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.

Adura Ìrànlọ́wọ́

12 Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,

ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,

tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.

Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,

ọkàn mi ti dàrú.

13 OLUWA, dákun gbà mi;

yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

14 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́

gba ẹ̀mí mi,

kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,

jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,

kí wọ́n sì tẹ́.

15 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,

kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,

àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi.

16 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,

kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;

kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ

máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!”

17 Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;

ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,

má pẹ́, Ọlọrun mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 41

Adura Ẹni tí ń Ṣàìsàn

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní:

OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú.

2 OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.

Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;

OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

3 Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,

OLUWA yóo fún un lókun;

ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.

4 Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;

mo ti ṣẹ̀ ọ́.”

5 Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,

“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”

6 Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,

ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí

ni yóo máa sọ;

bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.

Nígbà tí ó bá jáde,

yóo máa rò mí kiri.

7 Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi

jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi;

ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi.

8 Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀;

kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.”

9 Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé,

tí ó ń jẹun nílé mi,

ó ti kẹ̀yìn sí mí.

10 Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi;

gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un.

11 Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi,

nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi.

12 O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi,

o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae.

13 Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli,

lae ati laelae.

Amin! Amin!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 42

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,

bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.

2 Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,

àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.

Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?

3 Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,

nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,

“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

4 Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,

bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:

bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,

tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́

lọ sí ilé Ọlọrun;

pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,

láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.

5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?

Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?

Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,

olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

6 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,

nítorí náà mo ranti rẹ

láti òkè Herimoni,

ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,

7 ìbànújẹ́ ń já lura wọn,

ìdààmú sì ń dà gììrì,

wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.

8 Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,

ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,

àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.

9 Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé,

“Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi?

Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri

nítorí ìnilára ọ̀tá?”

10 Bí ọgbẹ́ aṣekúpani

ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi,

nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,

“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

11 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì?

Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?

Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,

olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 43

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi,

lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́;

gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ.

2 Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di.

Kí ló dé tí o fi ta mí nù?

Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kiri

nítorí ìnilára ọ̀tá?

3 Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde,

jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà;

jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ,

ati ibùgbé rẹ.

4 Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun,

àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi.

Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu,

Ọlọrun, Ọlọrun mi.

5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?

Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?

Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,

olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.