Categories
JOBU

JOBU 27

1 Jobu tún dáhùn pé,

2 “Mo fi Ọlọrun tí ó gba ẹ̀tọ́ mi búra,

mo fi Olodumare tí ó mú kí ọkàn mi bàjẹ́ ṣẹ̀rí,

3 níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,

tí mo sì ń mí,

4 n kò ní fi ẹnu mi purọ́,

ahọ́n mi kò sì ní sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

5 Kí á má rí i, n kò jẹ́ pè yín ní olóòótọ́;

títí di ọjọ́ ikú mi ni n óo dúró lórí ọ̀rọ̀ mi,

pé mo wà lórí àre.

6 Mo dúró lórí òdodo mi láìyẹsẹ̀,

ọkàn mi kò ní dá mi lẹ́bi,

títí n óo fi kú.

7 “Kí ó rí fún ọ̀tá mi gẹ́gẹ́ bí í ti í rí fún ẹni ibi,

kí ó sì rí fún ẹni tí ó dojú kọ mí bí í ti í rí fún alaiṣododo.

8 Ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọrun ní nígbà tí Ọlọrun bá pa á run,

tí Ọlọrun sì gba ẹ̀mí rẹ̀?

9 Ǹjẹ́ Ọlọrun yóo gbọ́ igbe rẹ̀,

nígbà tí ìyọnu bá dé bá a?

10 Ǹjẹ́ yóo ní inú dídùn sí Olodumare?

Ǹjẹ́ yóo máa ké pe Ọlọrun nígbà gbogbo?

11 “N óo kọ yín ní ìmọ̀ agbára Ọlọ́run;

n kò sì ní fi ohun tíí ṣe ti Olodumare pamọ́.

12 Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti fojú yín rí i,

kí ló wá dé tí gbogbo yín fí ń sọ ìsọkúsọ?”

13 “Ìpín ẹni ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìyí,

òun ni ogún tí àwọn aninilára ń rí gbà lọ́dọ̀ Olodumare:

14 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń pọ̀ sí i,

kí ogun baà lè pa wọ́n ni,

oúnjẹ kò sì ní ká wọn lẹ́nu.

15 Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,

àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,

àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.

16 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kó fadaka jọ bí erùpẹ̀,

tí ó sì to aṣọ jọ bí amọ̀;

17 olódodo ni yóo wọ aṣọ tí ó bá kó jọ,

àwọn aláìṣẹ̀ ni yóo pín fadaka rẹ̀.

18 Ilé tí ó kọ́ dàbí òwú aláǹtakùn,

àní bí àgọ́ àwọn tí wọn ń ṣọ́nà.

19 A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́.

Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ.

20 Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi,

ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ.

21 Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè,

á sì gbé e lọ,

á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀.

22 Á dìgbò lù ú láìṣàánú rẹ̀,

á sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.

23 Ọlọrun á pàtẹ́wọ́ lé e lórí,

á sì pòṣé sí i láti ibi tí ó wà.

Categories
JOBU

JOBU 28

Ọ̀rọ̀ Ìyìn Nípa Ọgbọ́n

1 “Dájúdájú, ibìkan wà tí wọ́n ti ń wa fadaka,

ibìkan sì wà tí wọ́n ti ń yọ́ wúrà.

2 Inú ilẹ̀ ni a ti ń wa irin,

a sì ń yọ́ idẹ lára òkúta.

3 Eniyan á sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀,

a sì ṣe àwárí irin,

ninu ọ̀gbun ati òkùnkùn biribiri.

4 Wọn á gbẹ́ kòtò ninu àfonífojì,

níbi tí ó jìnnà sí ibi tí eniyan ń gbé,

àwọn arìnrìnàjò á gbàgbé wọn,

wọn á takété sí àwọn eniyan, wọn á sì máa rọ̀ dirodiro sọ́tùn-ún sósì.

5 Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde,

ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po,

ó gbóná janjan.

6 Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀,

wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀.

7 Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o.

8 Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà,

kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí.

9 “Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ,

á sì hú òkè ńlá tìdítìdí.

10 Á gbẹ́ ihò sinu àpáta,

ojú rẹ̀ a sì tó àwọn ìṣúra iyebíye.

11 Á dí orísun àwọn odò,

tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè sun,

á sì wá àwọn ohun tí ó pamọ́ jáde.

12 Ṣugbọn níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n?

Níbo sì ni ìmọ̀ wà?

13 “Ẹnikẹ́ni kò mọ ọ̀nà ibi tí ó wà;

bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ilẹ̀ alààyè.

14 Ibú sọ pé, ‘Kò sí ninu mi,’

òkun sì ní, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi.’

15 Wúrà iyebíye kò lè rà á,

fadaka kò sì ṣe é díwọ̀n iye rẹ̀.

16 A kò lè fi wúrà Ofiri díwọ̀n iye rẹ̀,

tabi òkúta onikisi tabi safire tí wọ́n jẹ́ òkúta olówó iyebíye.

17 Ọgbọ́n níye lórí ju wúrà ati dígí lọ,

a kò lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà dáradára ṣe dípò rẹ̀.

18 Kí á má tilẹ̀ sọ ti iyùn tabi Kristali,

ọgbọ́n ní iye lórí ju òkúta Pali lọ.

19 A kò lè fi wé òkúta topasi láti ilẹ̀ Etiopia,

tabi kí á fi ojúlówó wúrà rà á.

20 “Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá;

níbo sì ni ìmọ̀ wà?

21 Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè,

ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.

22 Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé,

‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’

23 “Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀,

òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀.

24 Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé,

ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

25 Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,

tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi,

26 nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,

tí ó sì lànà fún mànàmáná.

27 Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde,

ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.

28 Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé,

‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n,

kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”

Categories
JOBU

JOBU 29

Ìparí Ọ̀rọ̀ Jobu

1 Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé,

2 “Ìbá jẹ́ tún rí fún mi, bí ìgbà àtijọ́,

nígbà tí Ọlọrun ń tọ́jú mi;

3 nígbà tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn sí mi lórí,

tí mo kọjá ninu òkùnkùn pẹlu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀;

4 kí ó tún rí fún mi bí ìgbà tí ara dẹ̀ mí,

nígbà tí ìrẹ́pọ̀ wà láàrin Ọlọrun ati ìdílé mi;

5 tí Olodumare wà pẹlu mi,

tí gbogbo àwọn ọmọ mi yí mi ká;

6 tí mò ń rí ọpọlọpọ wàrà lára àwọn ẹran ọ̀sìn mi,

ati ọpọlọpọ òróró lára igi olifi tí ń dàgbà láàrin òkúta!

7 Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú,

tí mo jókòó ní gbàgede,

8 tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,

àwọn àgbà á sì dìde dúró;

9 àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́,

wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.

10 Àwọn olórí á panumọ́,

ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.

11 Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun,

àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi.

12 Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́,

ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́.

13 Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi,

mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀.

14 Mo fi òdodo bora bí aṣọ,

ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi.

15 Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú,

ati ẹsẹ̀ fún arọ.

16 Mo jẹ́ baba fún talaka,

mo gba ẹjọ́ àlejò rò.

17 Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá,

mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.

18 “Nígbà náà, mo rò pé, n óo gbòó, n óo tọ̀ọ́ láyé,

ati pé inú ilé mi ni n óo sì kú sí.

19 Mo ta gbòǹgbò lọ síbi omi,

ìrì sì ń sẹ̀ sí ẹ̀ka mi ní alaalẹ́.

20 Ọlá hàn lára mi,

agbára mi sì ń di titun nígbà gbogbo.

21 Àwọn eniyan á dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọn á farabalẹ̀ gbọ́ tèmi,

wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn mi pẹlu.

22 Lẹ́yìn tí mo bá ti sọ̀rọ̀ tán,

ẹnikẹ́ni kì í tún sọ̀rọ̀ mọ́,

ọ̀rọ̀ mi a máa wọ̀ wọ́n lára.

23 Wọ́n ń retí mi,

bí ẹni retí òjò àkọ́rọ̀.

24 Mo rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn ń ṣiyèméjì,

wọn kò sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.

25 Mo jókòó bí ọba, mò ń tọ́ wọn sọ́nà,

mo dàbí ọba láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ̀,

bí olùtùnú fún oníròbìnújẹ́.

Categories
JOBU

JOBU 30

1 “Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,

àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajá

tí ń ṣọ́ agbo ẹran mi.

2 Kí ni anfaani agbára wọn fún mi,

àwọn tí wọn kò lókun ninu?

3 Ninu ìyà ati ebi,

wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.

4 Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,

àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.

5 Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,

wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.

6 Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,

ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.

7 Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,

wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.

8 Àwọn aláìlóye ọmọ,

àwọn ọmọ eniyan lásán,

àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.

9 “Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn,

mo ti di àmúpòwe.

10 Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn,

wọ́n ń rí mi sá,

ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.

11 Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera,

ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀,

wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn.

12 Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi,

wọ́n lé mi kúrò,

wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi.

13 Wọ́n dínà mọ́ mi,

wọ́n dá kún wahala mi,

kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun.

14 Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé,

wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀.

15 Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi,

wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́,

ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.

16 “Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi,

ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi.

17 Ní òru, egungun ń ro mí,

ìrora mi kò sì dínkù.

18 Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi,

ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.

19 Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀,

mo dàbí eruku ati eérú.

20 “Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn,

mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.

21 O dojú ibinu kọ mí,

o fi agbára rẹ bá mi jà.

22 O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́,

ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-ún

láàrin ariwo ìjì líle.

23 Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú,

ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.

24 Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira,

dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó?

25 Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí,

tí mo sì káàánú àwọn aláìní.

26 Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere,

ibi ní ń bá mi.

Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀,

òkùnkùn ni mò ń rí.

27 Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀,

ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.

28 Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri,

mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ.

29 Mò ń kígbe arò bí ajáko,

mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò.

30 Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó,

egungun mi gbóná fún ooru.

31 Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi,

ẹkún sì dípò ohùn fèrè.

Categories
JOBU

JOBU 31

1 “Mo ti bá ojú mi dá majẹmu;

n óo ṣe wá máa wo wundia?

2 Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè?

Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare?

3 Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo,

àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀.

4 Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi,

ó sì mọ ìrìn mi.

5 Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo,

tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,

6 (kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́,

yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!)

7 Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà,

tí mò ń ṣe ojúkòkòrò,

tí ọwọ́ mi kò sì mọ́,

8 jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi,

kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu.

9 “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin,

tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi;

10 jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn,

kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀.

11 Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù,

ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún.

12 Iná ajónirun ni,

tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀.

13 “Bí mo bá kọ̀ láti fetí sí ẹjọ́ àwọn

iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin mi,

nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí,

14 báwo ni n óo ṣe dúró níwájú Ọlọrun?

Kí ni kí n wí nígbà tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi?

15 Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún,

òun kan náà ló dá iranṣẹ mi?

Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa.

16 “Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí,

tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní,

17 tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ,

láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ

18 (láti ìgbà èwe rẹ̀ ni mo ti ń ṣe bíi baba fún un,

tí mo sì ń tọ́jú rẹ̀ láti inú ìyá rẹ̀);

19 bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ,

nítorí àìrí aṣọ bora,

tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀,

20 kí ó sì súre fún mi,

nítorí pé ara rẹ̀ móoru

pẹlu aṣọ tí a fi irun aguntan mi hun,

21 bí mo bá fi ìyà jẹ aláìníbaba,

nítorí pé mo mọ eniyan ní ilé ẹjọ́,

22 jẹ́ kí apá mi já kúrò léjìká mi,

kí ó yọ ní oríkèé rẹ̀.

23 Nítorí ẹ̀rù ìpọ́njú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ń bà mí,

nítorí ògo rẹ̀, n kò lè dán irú rẹ̀ wò.

24 “Bí mo bá gbójú lé wúrà,

tí mo sì fi ojúlówó wúrà ṣe igbẹkẹle mi,

25 bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé mo ní ọrọ̀ pupọ,

tabi nítorí pé ọwọ́ mi ti ba ọpọlọpọ ohun ìní.

26 Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn,

tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀:

27 tí ọkàn mi fà sí wọn;

tí mo sì tẹ́wọ́ adura sí wọn.

28 Èyí pẹlu yóo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,

tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún;

nítorí yóo jẹ́ aiṣootọ sí Ọlọrun ọ̀run.

29 “Bí mo bá yọ̀ nítorí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi,

tabi kí inú mi dùn nígbà tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí i.

30 (N kò fi ẹnu mi ṣẹ̀

kí n gbé e ṣépè pé kí ó lè kú);

31 bí àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́ mi kò bá wí pé,

‘Ta ló kù tí kò tíì yó?’

32 (Kò sí àlejò tí ń sun ìta gbangba,

nítorí ìlẹ̀kùn ilé mi ṣí sílẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò);

33 bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan,

tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra,

34 nítorí pé mò ń bẹ̀rù ọpọlọpọ eniyan,

ẹ̀gàn ìdílé sì ń dẹ́rùbà mí,

tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi dákẹ́, tí n kò sì jáde síta.

35 Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi!

(Mo ti tọwọ́ bọ̀wé,

kí Olodumare dá mi lóhùn!)

Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí!

36 Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi,

ǹ bá fi dé orí bí adé;

37 ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun,

ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè.

38 “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí,

tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún;

39 tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀,

tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín,

40 kí ẹ̀gún hù lórí ilẹ̀ náà dípò ọkà,

kí koríko hù dípò ọkà baali.”

Ọ̀rọ̀ Jobu parí síhìn-ín.

Categories
JOBU

JOBU 32

Ọ̀rọ̀ Elihu

1 Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀.

2 Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun.

3 Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi.

4 Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀.

5 Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i.

6 Ó ní,

“Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí,

nítorí náà ni ojú fi ń tì mí,

tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi.

7 Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀,

kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín.

8 Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan,

tíí ṣe èémí Olodumare,

ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀.

9 Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,

tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.

10 Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,

kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’

11 “Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,

mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,

nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,

12 Mo farabalẹ̀ fun yín,

ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,

kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,

tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.

13 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,

Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’

14 Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,

n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.

15 “Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ.

16 Ṣé kí n dúró,

nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì?

17 Èmi náà óo fèsì lé e,

n óo sì sọ èrò ọkàn tèmi.

18 Mo ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ,

Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu mi ló ń kó mi ní ìjánu.

19 Ọ̀rọ̀ kún inú mi bí ọtí inú ìgò,

ó fẹ́ ru síta bí ọtí inú ìgò aláwọ.

20 Mo níláti sọ̀rọ̀ kí ara lè rọ̀ mí,

mo gbọdọ̀ la ẹnu mi kí n sì dáhùn.

21 N kò ní ṣe ojuṣaaju ẹnikẹ́ni,

bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní gbèjà eniyan.

22 Nítorí n kò mọ bí wọ́n ṣe ń pọ́n eniyan,

kí Ẹlẹ́dàá mi má baà pa mí run ní kíá.

Categories
JOBU

JOBU 33

1 “Jobu, tẹ́tí sílẹ̀ nisinsinyii kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

2 Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀,

ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ.

3 Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀,

ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ.

4 Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi,

èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè.

5 “Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn.

Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára,

kí o sì múra láti wí àwíjàre.

6 Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun,

amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.

7 Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.

8 “Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi,

mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

9 O ní o mọ́, o kò ní ẹ̀ṣẹ̀,

ara rẹ mọ́ o kò sì ṣe àìdára kankan.

10 Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀,

ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,

11 ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀,

ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.

12 “Jobu, n óo dá ọ lóhùn,

nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.

Ọlọrun ju eniyan lọ.

13 Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn án

pé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?

14 Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.

15 Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru,

nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,

16 Ọlọrun a máa ṣí wọn létí,

a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n,

17 kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn,

kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn;

18 kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun,

kí ó má baà kú ikú idà.

19 “OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀;

a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀.

20 Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ,

oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.

21 Eniyan á rù hangangan,

wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀.

22 Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì,

ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú.

23 Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀,

tí ó wà fún un bí onídùúró,

àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun,

tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un,

24 tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé,

‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì,

mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’

25 Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde,

kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́;

26 nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun,

Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀.

Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun,

yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé

27 Yóo wá sọ gbangba níwájú àwọn eniyan pé,

‘Mo ti ṣẹ̀, mo sì ti yí ẹ̀tọ́ po,

ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ mí níyà ẹ̀ṣẹ̀ mi.

28 Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú,

mo sì wà láàyè.’

29 “Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan,

lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta,

30 láti lè gba ọkàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ikú,

kí ó lè wà láàyè.

31 “Gbọ́, ìwọ Jobu, farabalẹ̀,

dákẹ́ kí o lè gbọ́ ohun tí n óo sọ.

32 Bí o bá ní ohunkohun láti sọ, dá mi lóhùn;

sọ̀rọ̀, nítorí pé mo fẹ́ dá ọ láre ni.

33 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tẹ́tí sí mi;

farabalẹ̀, n óo sì kọ́ ọ lọ́gbọ́n.”

Categories
JOBU

JOBU 34

1 Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,

2 “Ẹ gbọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n,

ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní ìmọ̀,

3 nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò,

bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò

4 Ẹ jẹ́ kí á yan ohun tí ó tọ́,

kí á jọ jíròrò ohun tí ó dára láàrin ara wa.

5 Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi,

ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre.

6 Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn.

7 “Ta ló dàbí Jobu,

tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo,

8 tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,

tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn?

9 Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan,

ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’

10 “Nítorí náà ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin olóye,

Ọlọrun kì í ṣe ibi,

Olodumare kì í ṣe ohun tí kò tọ́.

11 Nítorí a máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀

ati gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.

12 Nítòótọ́, Ọlọrun kì í ṣe ibi,

bẹ́ẹ̀ ni Olodumare kì í dájọ́ èké.

13 Ta ló fi í ṣe alákòóso ayé,

ta ló sì fi jẹ olórí gbogbo ayé?

14 Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀,

15 gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé,

tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀.

16 “Bí ẹ bá ní òye, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ.

17 Ǹjẹ́ ẹni tí ó kórìíra ìdájọ́ ẹ̀tọ́ lè jẹ́ olórí?

Àbí ẹ lè dá olódodo ati alágbára lẹ́bi?

18 Ẹni tí ó tó pe ọba ní eniyan lásán,

tí ó tó pe ìjòyè ní ẹni ibi;

19 ẹni tí kì í ṣe ojuṣaaju fún àwọn ìjòyè,

tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju talaka lọ,

nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.

20 Wọn á kú ikú òjijì, ní ọ̀gànjọ́ òru;

á mi gbogbo eniyan jìgìjìgì, wọn a sì kú.

Ikú á mú àwọn alágbára lọ láì jẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn wọ́n.

21 Nítorí pé ojú rẹ̀ tó gbogbo ọ̀nà tí eniyan ń tọ̀,

ó sì rí gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ wọn.

22 Kò sí ibi òkùnkùn biribiri kankan,

tí àwọn eniyan burúkú lè fi ara pamọ́ sí.

23 Nítorí Ọlọrun kò nílò láti yan àkókò kan fún ẹnikẹ́ni,

láti wá siwaju rẹ̀ fún ìdájọ́.

24 Á pa àwọn alágbára run láìṣe ìwádìí wọn,

á sì fi àwọn ẹlòmíràn dípò wọn.

25 Nítorí pé ó mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn,

á bì wọ́n ṣubú lóru, wọn á sì parun.

26 Á máa jẹ wọ́n níyà ní gbangba,

nítorí ìwà ibi wọn.

27 Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé e,

wọn kò náání ọ̀nà rẹ̀ kankan,

28 wọ́n ń jẹ́ kí àwọn talaka máa kígbe sí Ọlọrun,

a sì máa gbọ́ igbe àwọn tí a ni lára.

29 “Bí Ọlọrun bá dákẹ́,

ta ló lè bá a wí?

Nígbà tí ó bá fi ojú pamọ́,

orílẹ̀-èdè tabi eniyan wo ló lè rí i?

30 Kí ẹni ibi má baà lè ṣe àkóso,

kí ó má baà kó àwọn eniyan sinu ìgbèkùn.

31 “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé,

‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

32 Kọ́ mi ní ohun tí n kò rí,

bí mo bá ti ṣẹ̀ rí, n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́?’

33 Ṣé yóo san ẹ̀san fún ọ lọ́nà tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn,

nítorí pé o kọ̀ ọ́?

Nítorí ìwọ ni o gbọdọ̀ yan ohun tí ó bá wù ọ́, kì í ṣe èmi,

nítorí náà, sọ èrò ọkàn rẹ fún wa.

34 Àwọn tí wọ́n lóye yóo sọ fún mi,

àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọn ń gbọ́ mi yóo sọ pẹlu pé,

35 ‘Jobu ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,

ó ń sọ̀rọ̀ láìní òye tí ó jinlẹ̀.’

36 À bá lè gbé ọ̀rọ̀ Jobu yẹ̀wò títí dé òpin,

nítorí pé ó ń sọ̀rọ̀ bí eniyan burúkú.

37 Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá;

ó ń pàtẹ́wọ́ ẹlẹ́yà láàrin wa,

ó sì ń kẹ́gàn Ọlọrun.”

Categories
JOBU

JOBU 35

1 Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,

2 “Jobu, ṣé o rò pé ó tọ̀nà,

kí o máa sọ pé, ‘Ọ̀nà mi tọ́ níwájú Ọlọrun?’

3 Kí o tún máa bèèrè pé, ‘Anfaani wo ni mo ní?

Tabi kí ni mo fi sàn ju ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ?’

4 N óo dá ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lóhùn.

5 Gbójú sókè kí o wo ojú ọ̀run,

ati àwọn ìkùukùu tí ó wà lókè.

6 Bí o bá dẹ́ṣẹ̀, kò ṣe Ọlọrun ní àìrójú,

bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá pọ̀, kò jámọ́ nǹkankan fún un.

7 Bí o bá jẹ́ olódodo,

kí ni ó dà fún Ọlọrun,

tabi kí ni ó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ?

8 Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára,

àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún.

9 “Àwọn eniyan ń kígbe nítorí ọpọlọpọ ìnira,

wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́,

nítorí àwọn alágbára ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

10 Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó bèèrè pé,

‘Níbo ni Ọlọrun Ẹlẹ́dàá mi wà,

tíí fún ni ní orin ayọ̀ lóru,

11 ẹni tí ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ju àwọn ẹranko lọ,

Ó sì fún wa ní ọgbọ́n ju àwọn ẹyẹ lọ?’

12 Wọ́n kígbe níbẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lóhùn,

nítorí ìgbéraga àwọn eniyan burúkú.

13 Dájúdájú Ọlọrun kì í gbọ́ igbe asán,

Olodumare kò tilẹ̀ náání rẹ̀.

14 Kí á má tilẹ̀ sọ ti ìwọ Jobu, tí o sọ pé

o kò rí i,

ati pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀,

o sì ń dúró dè é!

15 Ṣugbọn nisinsinyii, nítorí pé inú kì í bí i kí ó jẹ eniyan níyà,

bẹ́ẹ̀ ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ kún lọ títí.

16 Jobu kàn ń la ẹnu,

ó sì ń sọ̀rọ̀ lásán ni.

Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀, ṣugbọn kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́.”

Categories
JOBU

JOBU 36

1 Elihu tún tẹ̀síwájú ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní,

2 “Ní sùúrù fún mi díẹ̀, n óo ṣe àlàyé fún ọ,

nítorí mo ní ohun kan tí mo fẹ́ gbẹnusọ fún Ọlọrun.

3 N óo gba ìmọ̀ mi láti ọ̀nà jíjìn,

n óo sì fi júbà Ẹlẹ́dàá mi, tí ó ní ìmọ̀ òdodo.

4 Nítorí òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ mi;

ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ péye ni èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.

5 “Ọlọrun lágbára, kì í kẹ́gàn ẹnikẹ́ni,

agbára ati òye rẹ̀ pọ̀ gan-an.

6 Kì í jẹ́ kí eniyan burúkú ó wà láàyè,

ṣugbọn a máa fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀.

7 Kìí mú ojú kúrò lára àwọn olódodo,

ṣugbọn a máa gbé wọn sórí ìtẹ́ pẹlu àwọn ọba,

á gbé wọn ga,

á sì fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae.

8 Ṣugbọn bí a bá fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,

tí ayé wọn kún fún ìpọ́njú,

9 a máa fi àṣìṣe wọn hàn wọ́n,

ati ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga wọn.

10 Ó fún wọn ní etígbọ̀ọ́,

ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

11 Bí wọ́n bá gbọ́ràn, tí wọ́n sì sìn ín,

wọn yóo lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìdẹ̀rùn,

wọn yóo ṣe ọ̀pọ̀ ọdún ninu ìgbádùn.

12 Ṣugbọn bí wọn kò bá gbọ́ràn,

a óo fi idà pa wọ́n,

wọn yóo sì kú láìní ìmọ̀.

13 “Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu,

wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́,

nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè.

14 Wọn á kú ikú ìtìjú,

nígbà tí wọ́n wà ní èwe.

15 A máa lo ìpọ́njú àwọn tí à ń pọ́n lójú láti gbà wọ́n là,

a sì máa lo ìdààmú wọn láti ṣí wọn létí.

16 A máa yọ ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú,

bọ́ sinu ìdẹ̀ra níbi tí kò sí wahala,

oúnjẹ tí a gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀ a sì jẹ́ kìkì àdídùn.

17 “Ṣugbọn, ìdájọ́ eniyan burúkú dé bá ọ,

ọwọ́ ìdájọ́ ati òdodo sì ti tẹ̀ ọ́.

18 Ṣọ́ra kí ibinu má baà sọ ọ́ di ẹlẹ́yà,

kí títóbi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì mú ọ ṣìnà.

19 Igbe ati agbára rẹ kò lè gbà ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú.

20 Má máa dúró, kí o máa retí ọjọ́ alẹ́,

nígbà tí à ń pa àwọn eniyan run.

21 Ṣọ́ra kí o má yipada sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀,

tí ó wù ọ́ ju ìjìyà lọ.

22 “Wò ó, a gbé OLUWA ga ninu agbára rẹ̀;

ta ni olùkọ́ tí ó dàbí rẹ̀?

23 Ta ló ń sọ ohun tí yóo ṣe fún un,

tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe yìí kò dára?’

24 Ranti láti gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,

tí àwọn eniyan ń kọrin nípa rẹ̀.

25 Gbogbo eniyan ti rí i;

àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè ń wò ó.

26 Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ,

kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí rẹ̀.

27 “Ó fa ìkán omi sókè láti inú ilẹ̀,

ó sọ ìkùukùu di òjò,

28 ó sì rọ òjò sílẹ̀ láti ojú ọ̀run

sórí ọmọ eniyan lọpọlọpọ.

29 Ta ló mọ bí ó ti tẹ́ ìkùukùu?

Tabi bí ó ṣe ń sán ààrá láti inú àgọ́ rẹ̀?

30 Ó fi mànàmáná yí ara rẹ̀ ká,

ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

31 Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè;

ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ lọpọlọpọ.

32 Ìkáwọ́ rẹ̀ ni mànàmáná wà,

ó sì ń rán ààrá láti sán lu ohun tí ó bá fẹ́.

33 Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ rẹ̀,

àwọn ẹran ọ̀sìn sì mọ̀ pé ó súnmọ́ tòsí.