Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 26

Dafidi Dá Ẹ̀mí Saulu sí lẹẹkeji

1 Àwọn ọkunrin kan, ará Sifi lọ sọ fún Saulu ní Gibea pé, “Dafidi farapamọ́ sí òkè Hakila tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jeṣimoni.”

2 Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi.

3 Wọ́n pabùdó wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà ní òkè Hakila, Dafidi sì wà ninu aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí Dafidi mọ̀ pé Saulu ń wá òun kiri,

4 ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀.

5 Dafidi lọ lẹsẹkẹsẹ láti rí ibi tí Saulu ati Abineri, ọmọ Neri, olórí ogun Saulu, dùbúlẹ̀ sí. Saulu wà ninu àgọ́, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pàgọ́ yí i ká.

6 Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?”

Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.”

7 Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká.

8 Abiṣai bá sọ fún Dafidi pé, “Ọlọrun ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ ní òní yìí, gbà mí láàyè kí n yọ ọ̀kọ̀, kí n sì gún un ní àgúnpa lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.”

9 Ṣugbọn Dafidi sọ fún Abiṣai pé, “O kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi kan, nítorí ẹni tí ó bá pa ẹni àmì òróró OLUWA yóo jẹ̀bi.

10 Níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, OLUWA yóo pa á; tabi kí ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, tabi kí ó kú lójú ogun.

11 Kí OLUWA má ṣe jẹ́ kí n pa ẹni àmì òróró rẹ̀. Nítorí náà, jẹ́ kí á mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ati ìgò omi rẹ̀ kí á sì máa lọ.”

12 Dafidi bá mú ọ̀kọ̀ ati ìgò omi Saulu ní ìgbèrí rẹ̀, òun pẹlu Abiṣai sì jáde lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni ninu Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ tí ó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tabi tí ó jí nítorí OLUWA kùn wọ́n ní oorun.

13 Dafidi kọjá sí òdìkejì àfonífojì ní orí òkè níbi tí ó jìnnà díẹ̀.

14 Ó sì ké sí àwọn ọmọ ogun Saulu ati Abineri pé, “Abineri! Ǹjẹ́ ò ń gbọ́ ohùn mi bí!”

Abineri sì dáhùn pé, “Ìwọ ta ni ń pariwo! Tí o fẹ́ jí ọba?”

15 Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ.

16 Ohun tí o ṣe yìí kò dára, mo fi OLUWA ṣe ẹ̀rí pé, ó yẹ kí o kú, nítorí pé o kò dáàbò bo oluwa rẹ, ẹni àmì òróró OLUWA. Níbo ni ọ̀kọ̀ ọba wà? Ibo sì ni ìgò omi tí ó wà ní ìgbèrí rẹ̀ wà pẹlu?”

17 Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?”

Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi.

18 Kí ló dé tí o fi ń lépa èmi iranṣẹ rẹ? Kí ni mo ṣe? Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi?

19 Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa.

20 Má jẹ́ kí n kú sílẹ̀ àjèjì níbi tí OLUWA kò sí. Kí ló dé tí ọba Israẹli fi ń lépa èmi kékeré yìí, bí ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè?”

21 Saulu dáhùn pé, “Mo ti ṣe ibi, máa bọ̀ Dafidi, ọmọ mi. N kò ní ṣe ọ́ ní ibi mọ́, nítorí pé ẹ̀mí mi níye lórí lójú rẹ lónìí. Mo ti hùwà òmùgọ̀, ohun tí mo ṣe burú pupọ.”

22 Dafidi dáhùn pé, “Ọ̀kọ̀ rẹ nìyí, oluwa mi, jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ wá gbà á.

23 OLUWA a máa san ẹ̀san rere fún àwọn tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ ati olódodo. Lónìí, OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe ọ́ ní ibi, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́.

24 Gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ẹ̀mí rẹ sí lónìí, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì yọ mí kúrò ninu gbogbo ìṣòro.”

25 Saulu dáhùn pé, “Ọlọ́run yóo bukun ọ, ọmọ mi, o óo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.”

Dafidi bá bá tirẹ̀ lọ, Saulu sì pada sí ilé rẹ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 27

Dafidi láàrin Àwọn Ará Filistia

1 Dafidi rò ní ọkàn rẹ̀ pé Saulu yóo pa òun ní ọjọ́ kan, nítorí náà ohun tí ó dára jù ni kí òun sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ó ní Saulu yóo dẹ́kun láti máa wá òun kiri ní ilẹ̀ Israẹli, òun óo sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

2 Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600), bá lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.

3 Wọ́n ń gbé Gati pẹlu àwọn ará ilé wọn. Àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili ará Kamẹli, opó Nabali, sì wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀.

4 Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti sá àsálà lọ sí Gati, ó dẹ́kun láti máa wá a kiri.

5 Dafidi sì sọ fún Akiṣi pé, “Bí mo bá rí ojurere rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò agbègbè yìí kí n máa gbé. Kí ló dé tí èmi iranṣẹ rẹ yóo máa gbé inú ìlú kan náà pẹlu rẹ?”

6 Akiṣi fún un ní ìlú Sikilagi, nítorí náà ni Sikilagi fi jẹ́ ti àwọn ọba Juda títí di òní yìí.

7 Dafidi gbé ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún kan ati oṣù mẹrin.

8 Ní àkókò náà, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti àwọn ará Geṣuri, ati àwọn ará Girisi ati àwọn Amaleki, tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, títí dé Ṣuri ati ilẹ̀ Ijipti.

9 Dafidi pa gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin, ó sì kó àwọn aguntan, mààlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ràkúnmí wọn, ati aṣọ wọn, ó sì pada lọ bá Akiṣi.

10 Bí Akiṣi bá bèèrè pé, “Àwọn wo ni ẹ kógun lọ bá lónìí?” Dafidi á sì dáhùn pé, “Ìhà gúsù Juda ni, tabi kí ó sọ wí pé ìhà gúsù Jerameeli tabi ìhà gúsù Keni.”

11 Dafidi kò dá ẹnìkankan sí yálà ọkunrin tabi obinrin kí wọ́n má baà mú ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ sí Gati, bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí ó ń gbé ààrin àwọn ará Filistia.

12 Ṣugbọn Akiṣi gba Dafidi gbọ́, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀, kórìíra rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí náà yóo jẹ́ iranṣẹ mi laelae.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 28

1 Nígbà tí ó ṣe, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Akiṣi sọ fún Dafidi pé, “Ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo jà fún mi.”

2 Dafidi dáhùn pé, “Ó dára, o óo sì rí ohun tí èmi iranṣẹ rẹ lè ṣe.”

Akiṣi bá ní, òun óo fi Dafidi ṣe olùṣọ́ òun títí lae.

Saulu Lọ Ṣe Àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Abókùúsọ̀rọ̀

3 Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli.

4 Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa.

5 Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ.

6 Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.

7 Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.”

8 Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”

9 Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.”

10 Saulu bá búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, ibi kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ nítorí èyí.”

11 Obinrin náà dáhùn pé, “Ta ni kí n pè fún ọ?”

Saulu dáhùn pe, “Pe Samuẹli fún mi.”

12 Nígbà tí obinrin náà rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Àṣé Saulu ọba ni ọ́.”

13 Saulu bá sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, sọ ohun tí o rí fún mi.”

Obinrin náà dáhùn pé, “Mo rí ẹbọra kan, tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.”

14 Saulu bèèrè pé, “Báwo ló rí?”

Obinrin náà dáhùn pé, “Ọkunrin arúgbó kan ló ń bọ̀, ó sì fi aṣọ bora.”

Saulu mọ̀ pé Samuẹli ni, ó sì tẹríba.

15 Samuẹli bi Saulu pé, “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu? Kí ló dé tí o fi gbé mi dìde?”

Saulu dáhùn pé, “Mo wà ninu ìpọ́njú ńlá nítorí pé àwọn ará Filistia ń bá mi jagun, Ọlọrun sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí pé kò fún mi ní ìtọ́sọ́nà, yálà láti ẹnu wolii kan ni, tabi lójú àlá. Nítorí náà ni mo ṣe pè ọ́, pé kí o lè sọ ohun tí n óo ṣe fún mi.”

16 Samuẹli dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bi mí, nígbà tí OLUWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó sì ti di ọ̀tá rẹ?

17 OLUWA ti ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu mi. Ó ti gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ, ó sì ti fún Dafidi, aládùúgbò rẹ.

18 O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí.

19 OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.”

20 Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà.

21 Nígbà tí obinrin náà rí i pé ó wà ninu ọpọlọpọ ìbànújẹ́, ó sọ fún un pé, “Oluwa mi, mo fi ẹ̀mí mi wéwu láti ṣe ohun tí o bèèrè.

22 Ǹjẹ́, nisinsinyii, jọ̀wọ́ ṣe ohun tí mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ fún mi. Jẹ́ kí n tọ́jú oúnjẹ fún ọ, kí o jẹ ẹ́, kí o lè lókun nígbà tí o bá ń lọ.”

23 Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn.

24 Obinrin náà yára pa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí ó ń sìn, ó sì ṣe burẹdi díẹ̀ láì fi ìwúkàrà sí i.

25 Ó gbé e kalẹ̀ níwájú wọn; Saulu ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ ẹ́, wọ́n sì jáde lọ ní òru náà.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 29

Àwọn Ará Filistia Kọ Dafidi

1 Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli.

2 Bí àwọn ọba Filistini ti ń kọjá pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn ní ọgọọgọrun-un ati ẹgbẹẹgbẹrun, Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ tò sẹ́yìn ọba Akiṣi.

3 Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?”

Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

4 Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni.

5 Àbí nítorí Dafidi yìí kọ́ ni àwọn ọmọbinrin Israẹli ṣe ń jó tí wọ́n sì ń kọrin pé,

‘Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,

ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”

6 Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ.

7 Nítorí náà, jọ̀wọ́ pada ní alaafia, kí o má baà múnú bí wọn.”

8 Dafidi dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ìdí rẹ̀ tí n kò fi ní lè lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jà, nígbà tí o kò rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ mi láti ìgbà tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?”

9 Akiṣi sì dáhùn pé, “Nítòótọ́ ni, mo mọ̀ pé o jẹ́ ẹni rere bí angẹli OLUWA, ṣugbọn àwọn olórí ogun ti sọ pé, o kò lè bá wa lọ sójú ogun.

10 Nítorí náà, dìde ní òwúrọ̀, ìwọ ati àwọn iranṣẹ oluwa rẹ, tí wọ́n bá ọ wá, kí ẹ sì máa lọ ní kété tí ilẹ̀ bá ti mọ́.”

11 Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá dìde, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Filistini, àwọn ọmọ ogun Filistini sì lọ sí Jesireeli.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 30

Dafidi Bá Àwọn Ará Amaleki Jagun

1 Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ pada dé Sikilagi ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i pé àwọn ará Amaleki ti gbógun ti Nẹgẹbu ati Sikilagi, wọ́n ṣẹgun Sikilagi, wọ́n sì sun ìlú náà níná;

2 wọ́n kó gbogbo obinrin ati àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ lẹ́rú, àtọmọdé, àtàgbà, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni.

3 Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé, wọ́n rí i pé wọ́n ti dáná sun ìlú náà, wọ́n sì ti kó àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin lẹ́rú.

4 Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sọkún títí tí ó fi rẹ̀ wọ́n.

5 Wọ́n kó àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili opó Nabali lẹ́rú pẹlu.

6 Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7 Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá.

8 Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?”

OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”

9 Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà.

10 Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò.

11 Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi,

12 èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn.

13 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?”

Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá.

14 A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.”

15 Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?”

Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.”

16 Ó mú Dafidi lọ bá wọn.

Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda.

17 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ.

18 Dafidi sì gba àwọn eniyan rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki náà kó, ati àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji.

19 Kò sí ohun kan tí ó nù, Dafidi gba gbogbo àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki kó.

20 Ó gba gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn pẹlu. Àwọn eniyan náà sì ń dá àwọn ẹran ọ̀sìn náà jọ níwájú Dafidi, wọ́n ń sọ pé, “Ìkógun Dafidi nìyí.”

21 Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára.

22 Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.”

23 Ṣugbọn Dafidi dáhùn pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ ẹ̀ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí gbogbo ohun tí OLUWA fifún wa. Òun ni ó pa wá mọ́ tí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dojú ìjà kọ wá.

24 Kò sí ẹni tí yóo fara mọ́ àbá yín yìí. Gbogbo wa ni a óo jọ pín ìkógun náà dọ́gba-dọ́gba, ati àwọn tí ó lọ ati àwọn tí ó dúró ti ẹrù.”

25 Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí.

26 Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.”

27 Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri;

28 ati àwọn tí wọ́n wà ní Aroeri, Sifimoti, ati ní Eṣitemoa;

29 ní Rakali, ní àwọn ìlú Jerameeli, àwọn ìlú Keni,

30 ní Homa, Boraṣani, ati ní Ataki,

31 ní Heburoni ati ní gbogbo ìlú tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti rìn kiri.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 31

Ikú Saulu ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 Àwọn ará Filistia bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní orí òkè Giliboa. Ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli kú, àwọn yòókù sì sá. Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá sá lójú ogun.

2 Ṣugbọn àwọn ará Filistia lé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n pa Jonatani ati Abinadabu ati Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.

3 Ogun náà le fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà ta á ní ọfà, ó sì farapa lọpọlọpọ.

4 Ó sọ fún ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn aláìkọlà wọnyi má baà pa mí, kí wọ́n sì fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ẹ̀rù ba ọmọkunrin náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Saulu fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí, ó sì kú.

5 Nígbà tí ọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí ó sì kú.

6 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe kú ní ọjọ́ kan náà.

7 Nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli tí wọn ń gbé òdìkejì àfonífojì Jesireeli ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá lójú ogun, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú; wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn. Àwọn ará Filistia bá lọ tẹ̀dó sibẹ.

8 Ní ọjọ́ keji tí àwọn ará Filistia wá láti bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára àwọn tí wọ́n kú, wọ́n rí òkú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta ní òkè Giliboa.

9 Wọ́n gé orí Saulu, wọ́n sì bọ́ ihamọra rẹ̀, wọ́n ranṣẹ lọ sí gbogbo ilẹ̀ Filistini, pé kí wọ́n kéde ìròyìn ayọ̀ náà fún gbogbo eniyan ati ní gbogbo ilé oriṣa wọn.

10 Wọ́n kó ihamọra Saulu sílé Aṣitarotu, oriṣa wọn, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ara odi Beti Ṣani.

11 Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ ohun tí àwọn ará Filistia ṣe sí Saulu,

12 àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ninu wọ́n lọ sí Beti Ṣani lóru, wọ́n sì gbé òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára odi Beti Ṣani, wá sí Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì sin wọ́n sibẹ.

13 Wọ́n sin egungun wọn sí abẹ́ igi tamarisiki, ní Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Samuẹli Keji

fara pẹ́ra pẹlu ti

Samuẹli Kinni,

ìtàn kan náà ni àwọn Ìwé mejeeji sọ. Ibi tí

Ìwé Samuẹli Kinni

bá ìtàn náà dé kí ó tó parí, ni

Ìwé Samuẹli Keji

ti bẹ̀rẹ̀.

Samuẹli Keji

yìí sọ nípa Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba Juda ti ìhà gúsù (orí 1-4) ati ìgbà tí ó jọba lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli pẹlu àwọn ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n wà ní ìhà àríwá (orí 5-24). Ìwé yìí jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ akitiyan tí Dafidi ṣe láti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, bí ó ṣe ń kojú àwọn ọ̀tá rẹ̀ láàrin orílẹ̀-èdè rẹ̀ ati àwọn ti orílẹ̀-èdè mìíràn. A rí Dafidi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí igbagbọ rẹ̀ jinlẹ̀ tí ó sì ń fi gbogbo ọkàn sin Ọlọrun, ati ẹni tí ó rí ojurere àwọn eniyan rẹ̀. Sibẹsibẹ, a rí Dafidi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ní amumọra, tí í sì máa ń dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú pupọ láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí Natani, wolii OLUWA, bá fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kàn án, a máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a sì máa gba ìdájọ́ ati ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọrun bá fún un.

Ìgbésí ayé Dafidi ati àṣeyọrí rẹ̀ jọ àwọn eniyan Israẹli lójú, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n panu pọ̀ ní àkókò ìṣòro pé, ninu àwọn ọmọ Dafidi ni àwọn yóo tún ti yan ọba mìíràn tí yóo dàbí rẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Dafidi jọba Juda 1:1–4:12

Dafidi jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli 5:1–24:25

a. Àwọn ọdún tí Dafidi kọ́kọ́ lò lórí oyè 5:1–10:19

b. Dafidi ati Batiṣeba 11:1–12:25

d. Wahala ati ìnira 12:26–20:26

e. Àwọn ọdún tí Dafidi lò kẹ́yìn lórí oyè 21:1–24:25

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 1

Dafidi Gbọ́ nípa Ikú Saulu

1 Lẹ́yìn ikú Saulu, nígbà tí Dafidi pada dé láti ojú ogun, níbi tí ó ti ṣẹgun àwọn ará Amaleki, ó dúró ní ìlú Sikilagi fún ọjọ́ meji.

2 Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

3 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”

Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.”

4 Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.”

Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.”

5 Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?”

6 Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀.

7 Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’

8 Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’

9 Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’

10 Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.”

11 Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn.

12 Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun.

13 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?”

Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.”

14 Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?”

15 Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á.

16 Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.”

Orin Arò tí Dafidi Kọ fún Saulu ati Jonatani

17 Dafidi bá kọ orin arò fún Saulu, ati Jonatani, ọmọ rẹ̀,

18 ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àwọn eniyan Juda ní orin náà. (Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ninuÌwé Jaṣari.) Orin arò náà lọ báyìí:

19 “A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ!

Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú!

20 Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati,

ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni;

kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn,

kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀.

21 “Ẹ̀yin òkè Giliboa,

kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí,

bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín,

kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa,

nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà;

a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́.

22 Ọrun Jonatani kì í pada lásán,

bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada,

láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa,

ati ọ̀rá àwọn akikanju.

23 “Saulu ati Jonatani,

àyànfẹ́ ati eniyan rere,

wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn,

nígbà tí ikú sì dé,

wọn kò ya ara wọn.

Wọ́n yára ju àṣá lọ,

wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ.

24 “Ẹ̀yin obinrin Israẹli,

ẹ sọkún nítorí Saulu,

ẹni tí ó ro yín ní aṣọ elése àlùkò,

tí ó sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́.

25 “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú lójú ogun!

Jonatani ti ṣubú lulẹ̀,

wọ́n ti pa á lórí òkè.

26 “Mò ń ṣe ìdárò rẹ,

Jonatani arakunrin mi;

o ṣọ̀wọ́n fún mi lọpọlọpọ.

Ìfẹ́ tí o ní sí mi, kò ṣe é fi ẹnu sọ,

ó ju ìfẹ́ obinrin lọ.

27 “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú,

tí àwọn ohun ìjà ogun sì ń ṣègbé!”

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 2

Wọ́n fi Dafidi Jọba Juda

1 Lẹ́yìn èyí, Dafidi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, ṣé kí ń lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú Juda?”

OLUWA sì dá a lóhùn pé, “Lọ.”

Dafidi bá tún bèèrè pé, “Ìlú wo ni kí n lọ?”

OLUWA ní, “Lọ sí ìlú Heburoni.”

2 Dafidi bá mú àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji; Ahinoamu ará Jesireeli, ati Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli lọ́wọ́ lọ.

3 Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ pẹlu, ati gbogbo ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè Heburoni.

4 Lẹ́yìn náà, àwọn ará Juda wá sí Heburoni, wọ́n fi òróró yan Dafidi ní ọba wọn.

Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Jabeṣi Gileadi ni wọ́n sin òkú Saulu,

5 ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀.

6 Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.

7 Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.”

Wọ́n Fi Iṣiboṣẹti Jọba Israẹli

8 Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu sá lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani.

9 Níbẹ̀ ni ó ti fi Iṣiboṣẹti jọba lórí gbogbo agbègbè Gileadi, Aṣuri, Jesireeli, Efuraimu, Bẹnjamini, ati lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli.

10 Ẹni ogoji ọdún ni nígbà tí wọ́n fi jọba lórí Israẹli, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji.

Ṣugbọn ẹ̀yìn Dafidi ni gbogbo ẹ̀yà Juda wà.

11 Ọdún meje ààbọ̀ ni Dafidi fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní ìlú Heburoni.

Ogun Bẹ́ Sílẹ̀ láàrin Israẹli ati Juda

12 Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni.

13 Joabu, tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Seruaya, ati àwọn iranṣẹ Dafidi yòókù lọ pàdé wọn níbi adágún Gibeoni. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé Joabu jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún náà, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Abineri náà sì jókòó sí òdìkejì.

14 Abineri bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn ọmọkunrin láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji bọ́ siwaju, kí wọ́n fi ohun ìjà dánrawò níwájú wa.”

Joabu sì gbà bẹ́ẹ̀.

15 Àwọn mejila bá jáde láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji; àwọn mejila ẹ̀gbẹ́ kan dúró fún ẹ̀yà Bẹnjamini ati Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu, wọ́n sì bá àwọn iranṣẹ Dafidi mejila, tí wọ́n jáde láti inú ẹ̀yà Juda jà.

16 Ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ kinni, dojú kọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ keji, wọ́n sì gbá ara wọn lórí mú. Ẹnìkínní ti idà rẹ̀ bọ ẹnìkejì rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́, àwọn mẹrẹẹrinlelogun ṣubú lulẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Helikati-hasurimu. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Pápá Idà”; ó wà ní Gibeoni.

17 Ogun gbígbóná bẹ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ṣẹgun Abineri ati àwọn eniyan Israẹli.

18 Àwọn ọmọ Seruaya mẹtẹẹta, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli, wà lójú ogun náà. Ẹsẹ̀ Asaheli yá nílẹ̀ pupọ, àfi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín.

19 Asaheli bẹ̀rẹ̀ sí lé Abineri lọ, bí ó sì ti ń lé e lọ, kò wo ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni kò wo òsì.

20 Abineri bá bojúwo ẹ̀yìn, ó bèèrè pé, “Asaheli, ṣé ìwọ ni ò ń lé mi?”

Asaheli sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”

21 Abineri wí fún un pé, “Yà sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí o mú ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin, kí o sì kó gbogbo ìkógun rẹ̀.” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

22 Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?”

23 Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró.

24 Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni.

25 Àwọn ọmọ ogun yòókù láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini kó ara wọn jọ sẹ́yìn Abineri, wọ́n sì dúró káàkiri lórí òkè, pẹlu ìmúra ogun.

26 Lẹ́yìn náà Abineri pe Joabu, ó ní, “Ṣé títí lae ni a óo máa ja ìjà yìí lọ ni? Àbí ìwọ náà kò rí i pé, bí a bá ja ogun yìí títí a fi pa ara wa tán, kò sí nǹkankan tí ẹnikẹ́ni yóo rí gbà, àfi ọ̀tá! Nígbà wo ni o fẹ́ dúró dà, kí o tó dá àwọn eniyan rẹ lẹ́kun pé kí wọ́n yé lépa àwọn arakunrin wọn?”

27 Joabu bá dáhùn pé, “Ọlọrun mọ̀, bí o bá dákẹ́ tí o kò sọ̀rọ̀ ni, àwọn eniyan mi kì bá máa le yín lọ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.”

28 Joabu bá fọn fèrè ogun, láti fi pe àwọn eniyan rẹ̀ pada. Nígbà náà ni wọ́n tó pada lẹ́yìn àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n sì dáwọ́ ogun dúró.

29 Gbogbo òru ọjọ́ náà ni Abineri ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ń rìn pada lọ ní àfonífojì Jọdani, wọ́n kọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ keji ni wọ́n sì fi rìn kí wọ́n tó pada dé Mahanaimu.

30 Nígbà tí Joabu pada lẹ́yìn Abineri, tí ó sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, ó rí i pé, lẹ́yìn Asaheli, àwọn mejidinlogun ni wọn kò rí mọ́.

31 Ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ti pa ọtalelọọdunrun (360) ninu àwọn eniyan Abineri.

32 Joabu ati àwọn eniyan rẹ̀ bá gbé òkú Asaheli, wọ́n sì lọ sin ín sí ibojì ìdílé wọn ní Bẹtilẹhẹmu. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni wọ́n fi rìn; ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ni wọ́n pada dé Heburoni.

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 3

1 Àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Saulu, ati àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Dafidi bá ara wọn jagun fún ìgbà pípẹ́. Bí agbára Dafidi ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni agbára àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu ń dínkù.

Àwọn Ọmọ Dafidi

2 Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí.

3 Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri.

4 Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali.

5 Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi.

Abineri Darapọ̀ Mọ́ Dafidi

6 Ní àkókò tí ogun wà láàrin àwọn eniyan Dafidi ati àwọn eniyan Saulu, agbára Abineri bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láàrin àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu.

7 Ní ọjọ́ kan, Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu fi ẹ̀sùn kan Abineri pé ó bá obinrin Saulu kan, tí wọn ń pè ní Risipa, ọmọ Aya, lòpọ̀.

8 Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin.

9 Kí Ọlọrun lù mí pa, bí n kò bá ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ìkáwọ́ mi, láti mú ìlérí tí OLUWA ṣe fún Dafidi ṣẹ,

10 pé, òun yóo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ ìdílé Saulu, yóo sì fi Dafidi jọba lórí Juda jákèjádò, láti Dani títí dé Beeriṣeba.”

11 Iṣiboṣẹti kò sì lè dá Abineri lóhùn nítorí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.”

13 Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.”

14 Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun.

15 Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀.

16 Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada.

17 Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín.

18 Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.”

19 Abineri bá àwọn ará Bẹnjamini sọ̀rọ̀ pẹlu. Lẹ́yìn náà ó lọ bá Dafidi ní Heburoni láti sọ ohun tí àwọn ará Bẹnjamini ati gbogbo ọmọ Israẹli ti gbà láti ṣe fún Dafidi.

20 Nígbà tí Abineri dé ọ̀dọ̀ Dafidi ní Heburoni pẹlu ogún ọkunrin tí ń bá a lọ, Dafidi se àsè ńlá fún wọn.

21 Abineri bá sọ fún Dafidi pé, “N óo lọ, n óo wá ọ̀nà tí gbogbo Israẹli yóo fi wà lẹ́yìn rẹ, oluwa mi, (ọba), tí wọn yóo bá ọ dá majẹmu tí o óo sì jọba lórí gbogbo ibi tí ọkàn rẹ bá fẹ́.” Dafidi ní kí ó máa lọ, ó sì lọ ní alaafia.

Wọ́n Pa Abineri

22 Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni Joabu ati àwọn ọmọ ogun Dafidi pada dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ja ogun kan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun bọ̀. Ṣugbọn Abineri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi, ní Heburoni, nígbà tí wọ́n dé, nítorí pé Dafidi ti ní kí ó máa pada lọ, ó sì ti lọ ní alaafia.

23 Nígbà tí Joabu ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e dé, wọ́n sọ fún Joabu pé, “Abineri ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ọba sì ti jẹ́ kí ó lọ ní alaafia.”

24 Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀?

25 Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.”

26 Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

27 Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu.

28 Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ní, “OLUWA mọ̀ pé, èmi ati àwọn eniyan mi kò lọ́wọ́ sí ikú Abineri rárá, ọwọ́ wa mọ́ patapata ninu ọ̀ràn náà.

29 Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.”

30 Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni.

Wọ́n Sin Òkú Abineri

31 Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀.

32 Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu.

33 Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé:

“Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè?

34 Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀;

o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.”

Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún.

35 Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú.

36 Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan.

37 Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri.

38 Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?”

39 Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.”