Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 16

Wọ́n Fi Àmì Òróró Yan Dafidi lọ́ba

1 OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.”

2 Samuẹli dáhùn pé, “Báwo ni n óo ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́, pípa ni yóo pa mí.”

OLUWA dá a lóhùn pé, “Mú ọ̀dọ́ mààlúù kan lọ́wọ́, kí o wí pé o wá rúbọ sí OLUWA ni.

3 Pe Jese wá sí ibi ẹbọ náà, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ. N óo dárúkọ ẹnìkan fún ọ, ẹni náà ni kí o fi jọba.”

4 Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”

5 Samuẹli dáhùn pé, “Alaafia ni. Ẹbọ ni mo wá rú sí OLUWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ bá mi lọ síbi ìrúbọ náà.” Ó ya Jese ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, ó sì pè wọ́n síbi ìrúbọ náà.

6 Nígbà tí wọ́n dé, ó wo Eliabu, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú ẹni tí OLUWA yàn nìyí.”

7 Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”

8 Lẹ́yìn náà, Jese sọ fún Abinadabu pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli wí pé, “OLUWA kò yan eléyìí.”

9 Lẹ́yìn náà Jese sọ fún Ṣama pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli tún ní, “OLUWA kò yan eléyìí náà.”

10 Jese mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeje kọjá níwájú Samuẹli. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, OLUWA kò yan ọ̀kankan ninu wọn.

11 Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?”

Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.”

Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.”

12 Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.”

13 Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama.

Dafidi ní Ààfin Saulu

14 Ẹ̀mí OLUWA kúrò lára Saulu, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA sì ń dà á láàmú.

15 Àwọn iranṣẹ Saulu wí fún un pé, “Wò ó! Ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń dà ọ́ láàmú;

16 fún àwa iranṣẹ rẹ tí a wà níwájú rẹ láṣẹ láti wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára. Ìgbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bá bà lé ọ, yóo máa fi hapu kọrin, ara rẹ yóo sì balẹ̀.”

17 Saulu bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára, kí wọ́n sì mú un wá siwaju òun.

18 Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.”

19 Saulu bá ranṣẹ sí Jese pé kí ó fi Dafidi, ọmọ rẹ̀ tí ń tọ́jú agbo ẹran ranṣẹ sí òun.

20 Jese di ẹrù burẹdi ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ati waini tí wọ́n rọ sinu ìgò aláwọ pẹlu ọmọ ewúrẹ́ kan, ó kó wọn rán Dafidi sí Saulu.

21 Dafidi wá sọ́dọ̀ Saulu, ó sì ń bá a ṣiṣẹ́. Saulu fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, ó sì di ẹni tí ń ru ihamọra Saulu.

22 Saulu ranṣẹ sí Jese, ó ní, “Jẹ́ kí Dafidi máa bá mi ṣiṣẹ́ nítorí ó ti bá ojurere mi pàdé.”

23 Nígbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú bá ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá sórí Saulu, Dafidi a máa ta hapu fún un, ara Saulu á balẹ̀, ẹ̀mí burúkú náà a sì fi í sílẹ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 17

Goliati Pe Àwọn Ọmọ Israẹli Níjà

1 Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka.

2 Saulu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ibùdó tiwọn sí àfonífojì Ela, wọ́n sì múra ogun de àwọn ọmọ ogun Filistini.

3 Àwọn Filistini dúró lórí òkè ní apá kan, àwọn Israẹli sì dúró lórí òkè ní apá keji. Àfonífojì kan sì wà láàrin wọn.

4 Akikanju ọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Goliati, ará ìlú Gati, jáde wá láti ààrin àwọn Filistini. Ó ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹfa ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.

5 Ó dé àṣíborí bàbà, ó wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi bàbà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) ṣekeli.

6 Ó ní ihamọra bàbà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ọ̀kọ̀ bàbà kan sí èjìká rẹ̀.

7 Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dàbí igi òfì, irin tí ó wà lórí ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹta (600) òṣùnwọ̀n ṣekeli. Ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì ń rìn níwájú rẹ̀.

8 Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà.

9 Bí ó bá pa mí, a óo di ẹrú yín. Ṣugbọn bí mo bá ṣẹgun rẹ̀, tí mo sì pa á, ẹ óo di ẹrú wa.

10 Mo pe ẹ̀yin ọmọ ogun Israẹli níjà lónìí, ẹ yan ọkunrin kan, kí ó wá bá mi jà.”

11 Nígbà tí Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.

Dafidi ní Ibùdó Saulu

12 Ọmọ Jese ni Dafidi, ará Efurati ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda; Ọmọkunrin mẹjọ ni Jese bí, ó sì ti di arúgbó nígbà tí Saulu jọba.

13 Àwọn mẹta tí wọ́n dàgbà jùlọ láàrin àwọn ọmọ Jese bá Saulu lọ sójú ogun. Eliabu ni orúkọ àkọ́bí. Abinadabu ni ti ekeji, Ṣama sì ni ti ẹkẹta.

14 Dafidi ni àbíkẹ́yìn patapata; àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹta náà sì wà ninu àwọn ọmọ ogun Saulu.

15 Dafidi a máa lọ sí Bẹtilẹhẹmu nígbà gbogbo láti tọ́jú agbo ẹran baba rẹ̀.

16 Odidi ogoji ọjọ́ ni Goliati fi pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà ní àràárọ̀ ati ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́.

17 Ní ọjọ́ kan, Jese sọ fún Dafidi pé, “Jọ̀wọ́, mú ìwọ̀n efa àgbàdo yíyan kan, ati burẹdi mẹ́wàá yìí lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó ogun.

18 Mú wàrà sísè mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún olórí ogun ikọ̀ wọn, kí o sì bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o gba nǹkankan bọ̀ lọ́dọ̀ wọn tí yóo fihàn mí pé alaafia ni wọ́n wà.”

19 Saulu ọba, ati àwọn ẹ̀gbọ́n Dafidi ati àwọn ọmọ ogun yòókù wà ní àfonífojì Ela níbi tí wọ́n ti ń bá àwọn Filistini jà.

20 Dafidi dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó fi ẹnìkan ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀, ó mú oúnjẹ náà, ó sì lọ gẹ́gẹ́ bí Jese ti pàṣẹ fún un. Ó dé ibùdó ogun ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ń lọ sójú ogun, wọ́n ń hó ìhó ogun.

21 Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Filistini dúró ní ipò wọn, wọ́n ń wo ara wọn.

22 Dafidi fún olùtọ́jú ẹrù àwọn ọmọ ogun ní oúnjẹ tí ó gbé lọ, ó sì sáré tọ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sójú ogun láti kí wọn.

23 Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Goliati wá láti pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà. Ó sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń sọ ọ́; Dafidi sì gbọ́.

24 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli rí Goliati, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n sì sá lọ.

25 Wọ́n ní, “Ẹ wo ọkunrin yìí, ẹ gbọ́ bí ó ti ń pe Israẹli níjà? Ọba sì ti sọ pé ẹni tí ó bá lè pa á yóo gba ẹ̀bùn lọpọlọpọ. Òun yóo sì fi ọmọbinrin òun fún olúwarẹ̀, ilé baba rẹ̀ yóo sì di òmìnira ní ilẹ̀ Israẹli: kò ní san owó orí mọ́.”

26 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?”

27 Àwọn ọkunrin náà sì sọ ohun tí ọba sọ pé òun yóo ṣe fún ẹni tí ó bá pa ọkunrin náà fún Dafidi.

28 Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.”

29 Dafidi sì dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe nisinsinyii? Ṣebí ọ̀rọ̀ lásán ni mò ń sọ.”

30 Dafidi yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, ó tún bèèrè ìbéèrè kan náà. Àwọn ọkunrin náà sì fún un ní èsì bíi ti iṣaaju.

31 Àwọn ọmọ ogun náà sọ ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ níwájú Saulu, Saulu bá ranṣẹ pè é.

32 Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ẹ má bẹ̀rù ọkunrin yìí; èmi, iranṣẹ rẹ óo lọ bá a jà.”

33 Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “O kò lè bá Filistini yìí jà, nítorí pé ọmọde ni ọ́, òun sì ti jẹ́ jagunjagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”

34 Dafidi dáhùn pé, “Ìgbàkúùgbà tí èmi iranṣẹ rẹ bá ń ṣọ́ agbo aguntan baba mi, tí kinniun tabi ẹranko beari bá gbé ọ̀kan ninu aguntan náà,

35 n óo tẹ̀lé e lọ, n óo lù ú, n óo sì gba aguntan náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Bí ó bá sì kọjú ìjà sí mi, n óo di ọ̀fun rẹ̀ mú, n óo sì pa á.

36 Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà.

37 OLUWA tí ó gbà mí lọ́wọ́ kinniun ati beari yóo gbà mí lọ́wọ́ Filistini yìí.”

Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “Máa lọ, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ.”

38 Saulu gbé ihamọra ogun rẹ̀ wọ Dafidi, ó fi àṣíborí idẹ kan dé e lórí, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ́.

39 Dafidi di idà Saulu mọ́ ihamọra náà, ó sì gbìyànjú láti rìn, ṣugbọn kò lè rìn nítorí pé kò wọ ihamọra ogun rí. Dafidi sọ fún Saulu pé, “N kò lè lo ihamọra yìí, nítorí pé n kò wọ̀ ọ́ rí.” Dafidi bá tú wọn kúrò lára rẹ̀.

40 Ó mú ọ̀pá darandaran rẹ̀, ó ṣa òkúta marun-un tí ń dán ninu odò, ó kó wọn sinu àpò rẹ̀, ó mú kànnàkànnà rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì lọ bá Filistini náà.

Dafidi Ṣẹgun Goliati

41 Filistini náà sì ń rìn bọ̀ wá pàdé Dafidi; ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.

42 Nígbà tí ó rí Dafidi dáradára, ó wò ó pé ọmọ kékeré kan lásán, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́wà ni, nítorí náà, ó fojú tẹmbẹlu rẹ̀.

43 Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀,

44 ó sì wí pé, “Sún mọ́ mi níhìn-ín, n óo sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ati ẹranko jẹ.”

45 Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn.

46 Lónìí yìí ni OLUWA yóo fà ọ́ lé mi lọ́wọ́, n óo pa ọ́, n óo gé orí rẹ, n óo sì fi òkú àwọn ọmọ ogun Filistini fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ati ẹranko ìgbẹ́. Gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé Ọlọrun wà fún Israẹli.

47 Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.”

48 Bí Filistini náà ṣe ń bọ̀ láti pàdé Dafidi, Dafidi sáré sí ààlà ogun láti pàdé rẹ̀.

49 Dafidi mú òkúta kan jáde láti inú àpò rẹ̀, ó fi kànnàkànnà rẹ̀ ta òkúta náà, òkúta náà wọ agbárí Goliati lọ, ó sì ṣubú lulẹ̀.

50 Dafidi ṣẹgun Filistini náà láìní idà lọ́wọ́; kànnàkànnà ati òkúta ni ó fi pa á.

51 Dafidi sáré sí Goliati, ó yọ idà Goliati kúrò ninu àkọ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀.

Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini rí i pé akikanju àwọn ti kú, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

52 Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda hó ìhó ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn Filistini lọ. Wọ́n lé wọn títí dé Gati ati dé ẹnu ibodè Ekironi. Àwọn Filistini tí wọ́n fara gbọgbẹ́ sì ṣubú láti Ṣaaraimu títí dé Gati ati Ekironi.

53 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli pada dé, wọ́n lọ kó ìkógun ninu ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.

54 Dafidi gbé orí ati ihamọra Goliati; ó gbé orí rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ṣugbọn ó kó ihamọra rẹ̀ sinu àgọ́ tirẹ̀.

Dafidi níwájú Saulu

55 Nígbà tí Saulu rí Dafidi tí ó ń lọ bá Goliati jà, ó bèèrè lọ́wọ́ Abineri, olórí ogun rẹ̀ pé, “Ọmọ ta ni ọmọkunrin yìí?”

Abineri dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, n kò mọ̀.”

56 Ọba pàṣẹ fún un pé kí ó wádìí ọmọ ẹni tí ọmọ náà í ṣe.

57 Nígbà tí Dafidi pada sí ibùdó lẹ́yìn tí ó ti pa Goliati, Abineri mú un lọ siwaju Saulu, pẹlu orí Goliati ní ọwọ́ rẹ̀.

58 Saulu bi í léèrè pé, “Ọmọ, ta ni baba rẹ?”

Dafidi dáhùn pé, “Ọmọ Jese ni mí, iranṣẹ rẹ, tí ń gbé Bẹtilẹhẹmu.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 18

1 Lẹ́yìn tí Dafidi ati Saulu parí ọ̀rọ̀ wọn, ọkàn Jonatani, ọmọ Saulu fà mọ́ Dafidi lọpọlọpọ ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.

2 Saulu gba Dafidi sọ́dọ̀ ní ọjọ́ náà, kò sì jẹ́ kí ó pada sílé baba rẹ̀.

3 Jonatani bá bá Dafidi dá majẹmu, nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.

4 Ó bọ́ aṣọ tí ó wọ̀ fún Dafidi, ó sì kó ihamọra rẹ̀ pẹlu idà ati ọfà ati àmùrè rẹ̀ fún un.

5 Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn.

Saulu Bẹ̀rẹ̀ sí Jowú Dafidi

6 Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin.

7 Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé,

“Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,

ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.”

8 Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.”

9 Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi.

10 Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu.

11 Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji.

12 Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀.

13 Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

14 Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀.

15 Saulu tún bẹ̀rù Dafidi sí i nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀.

16 Ṣugbọn gbogbo àwọn ará Israẹli ati Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó jẹ́ olórí tí ń ṣe àṣeyọrí.

Dafidi Fẹ́ Ọmọbinrin Saulu

17 Saulu sọ fún Dafidi pé, “Merabu ọmọbinrin mi àgbà nìyí, n óo fún ọ kí o fi ṣe aya, ṣugbọn o óo jẹ́ ọmọ ogun mi, o óo sì máa ja ogun OLUWA.” Nítorí Saulu rò ninu ara rẹ̀ pé, àwọn Filistini ni yóo pa Dafidi, òun kò ní fi ọwọ́ ara òun pa á.

18 Dafidi dáhùn pé, “Ta ni èmi ati ìdílé baba mi tí n óo fi di àna ọba?”

19 Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó yẹ kí Saulu fi Merabu fún Dafidi, Adirieli ará Mehola ni ó fún.

20 Ṣugbọn Mikali ọmọbinrin Saulu nífẹ̀ẹ́ Dafidi; nígbà tí Saulu gbọ́, inú rẹ̀ dùn sí i.

21 Ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo fi Mikali fún Dafidi kí ó lè jẹ́ ìdẹkùn fún un, àwọn Filistini yóo sì rí i pa.” Saulu ṣèlérí fún Dafidi lẹẹkeji pé, “O óo di àna mi.”

22 Saulu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ lọ bá Dafidi sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ pé, inú ọba dùn sí i lọpọlọpọ, ati pé gbogbo àwọn iranṣẹ ọba fẹ́ràn rẹ̀, nítorí náà ó yẹ kí ó fẹ́ ọmọ ọba.”

23 Nígbà tí wọ́n sọ èyí fún Dafidi, ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe nǹkan kékeré ni láti jẹ́ àna ọba, talaka ni mí, èmi kì í sì í ṣe eniyan pataki.”

24 Àwọn iranṣẹ náà sọ èsì tí Dafidi fún wọn fún Saulu.

25 Saulu sì rán wọn pé kí wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Ọba kò bèèrè ẹ̀bùn igbeyawo kankan lọ́wọ́ rẹ ju ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá ọba.” Saulu rò pé àwọn ará Filistia yóo tipa bẹ́ẹ̀ pa Dafidi.

26 Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu jíṣẹ́ fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn, ó sì gbà láti di àna ọba. Kí ó tó di ọjọ́ igbeyawo,

27 Dafidi ati àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ pa igba (200) Filistini, ó sì kó awọ adọ̀dọ́ wọn wá fún ọba, kí ó lè fẹ́ ọmọ ọba. Saulu sì fi ọmọbinrin rẹ̀, Mikali, fún Dafidi.

28 Saulu rí i dájúdájú pé OLUWA wà pẹlu Dafidi ati pé Mikali ọmọ òun fẹ́ràn Dafidi.

29 Nítorí náà, ó bẹ̀rù Dafidi sí i, ó sì ń bá Dafidi ṣe ọ̀tá títí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

30 Ninu gbogbo ogun tí wọ́n bá àwọn ara Filistia jà, Dafidi ní ìṣẹ́gun ju gbogbo àwọn olórí ogun Saulu yòókù lọ. Ó sì jẹ́ olókìkí láàrin wọn.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 19

Saulu Fẹ́ Pa Dafidi

1 Saulu sọ fún ọmọ rẹ̀ Jonatani ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣugbọn Jonatani fẹ́ràn Dafidi lọpọlọpọ.

2 Ó sì sọ fún Dafidi pé, “Baba mi fẹ́ pa ọ́, nítorí náà fi ara pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan lọ́la, kí o má ṣe wá sí gbangba.

3 N óo dúró pẹlu baba mi ní orí pápá lọ́la níbi tí o bá farapamọ́ sí, n óo sì bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ, ohunkohun tí mo bá sì gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, n óo sọ fún ọ.”

4 Jonatani sọ̀rọ̀ Dafidi ní rere níwájú Saulu, ó wí pé, “Kabiyesi, má ṣe nǹkankan burúkú sí iranṣẹ rẹ, Dafidi, nítorí kò ṣe ibi kan sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ń ṣe ni ó ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ọ.

5 Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu láti pa Goliati, OLUWA sì ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli. Nígbà tí o rí i inú rẹ dùn. Kí ló dé tí o fi ń wá ọ̀nà láti pa Dafidi láìṣẹ̀?”

6 Saulu gbọ́rọ̀ sí Jonatani lẹ́nu, ó sì búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, n kò ní pa á.”

7 Jonatani pe Dafidi ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. Ó mú Dafidi wá siwaju ọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ iranṣẹ fún ọba bíi ti àtẹ̀yìnwá.

8 Ogun tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Filistini ati Israẹli. Dafidi kọlu àwọn Filistini, ó pa pupọ ninu wọn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini fi sá lójú ogun.

9 Ní ọjọ́ kan, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tún bà lé Saulu, bí ó ti jókòó ninu ilé rẹ̀ tí ó mú ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, tí Dafidi sì ń lu dùùrù níwájú rẹ̀,

10 Saulu ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi mọ́ ògiri, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà wọ ara ògiri, Dafidi bá sá lọ.

11 Ní alẹ́ ọjọ́ náà, Saulu rán àwọn iranṣẹ kan láti máa ṣọ́ ilé Dafidi kí wọ́n lè pa á ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ṣugbọn Mikali iyawo rẹ̀ sọ fún Dafidi pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, nítorí pé bí o bá di ọ̀la níbí, wọn yóo pa ọ́.”

12 Mikali bá sọ Dafidi kalẹ̀ láti ojú fèrèsé kan, ó sì sá lọ láti fi ara pamọ́.

13 Mikali sì mú ère kan, ó tẹ́ ẹ sórí ibùsùn, ó gbé ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ sibẹ, ó fi ṣe ìrọ̀rí rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.

14 Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu dé láti mú Dafidi, Mikali sọ fún wọn pé, “Ara rẹ̀ kò yá.”

15 Saulu tún rán àwọn iranṣẹ náà lọ wo Dafidi, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé e wá fún mi ti òun ti ibùsùn rẹ̀, kí n pa á.”

16 Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà dé, wọ́n bá ère ní orí ibùsùn pẹlu ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ ní ìgbèrí rẹ̀.

17 Saulu sì bèèrè lọ́wọ́ Mikali pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí, tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sá àsálà?”

Mikali dá Saulu lóhùn pé, “Ó sọ wí pé òun yóo pa mí bí n kò bá jẹ́ kí òun sá lọ.”

18 Dafidi sá àsálà, ó sá lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama, ó sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe sí i fún un. Òun pẹlu Samuẹli sì lọ ń gbé Naioti.

19 Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Naioti ní Rama,

20 ó rán àwọn iranṣẹ láti mú un. Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà rí ẹgbẹ́ àwọn wolii tí wọn ń jó, tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, pẹlu Samuẹli ní ààrin wọn gẹ́gẹ́ bí olórí wọn, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé àwọn iranṣẹ náà, àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀.

21 Nígbà tí Saulu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, ó rán àwọn mìíràn, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ó rán àwọn oníṣẹ́ ní ìgbà kẹta, àwọn náà tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

22 Òun pàápàá dìde ó lọ sí Rama. Nígbà tí ó dé etí kànga jíjìn tí ó wà ní Seku, ó bèèrè ibi tí Samuẹli ati Dafidi wà. Wọ́n sì sọ fún un wí pé, wọ́n wà ní Naioti ti Rama.

23 Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sí Naioti ti Rama, bí ó ti ń lọ, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti.

24 Ó bọ́ aṣọ rẹ̀, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sùn ní ìhòòhò ní ọ̀sán ati òru ọjọ́ náà. Àwọn eniyan sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii?”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 20

Jonatani Ran Dafidi lọ́wọ́

1 Dafidi sá kúrò ní Naioti, ní Rama, lọ sọ́dọ̀ Jonatani, ó sì bi í pé, “Kí ni mo ṣe? Ìwà burúkú wo ni mo hù? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ baba rẹ tí ó fi ń wọ́nà láti pa mí?”

2 Jonatani dá a lóhùn pé, “Kí á má rí i, o kò ní kú. Kò sí nǹkankan ti baba mi ń ṣe, bóyá ńlá tabi kékeré, tí kì í sọ fún mi; kò sì tíì sọ èyí fún mi, nítorí náà ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀.”

3 Dafidi dáhùn pé, “Baba rẹ mọ̀ wí pé bí òun bá sọ fún ọ, inú rẹ kò ní dùn, nítorí pé o fẹ́ràn mi. Nítòótọ́ bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, tí ẹ̀mí rẹ náà sì ń bẹ láàyè, ìṣísẹ̀ kan ló wà láàrin èmi ati ikú.”

4 Jonatani bá dáhùn pé, “N óo ṣe ohunkohun tí o bá fẹ́.”

5 Dafidi sọ fún un pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, n kò sì gbọdọ̀ má bá ọba jókòó jẹun. Ṣugbọn jẹ́ kí n lọ farapamọ́ sinu pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta.

6 Bí baba rẹ bá bèèrè mi, sọ fún un pé mo ti gbààyè lọ́wọ́ rẹ láti lọ sí ìlú mi, ní Bẹtilẹhẹmu, nítorí pé àkókò yìí jẹ́ àkókò fún àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ìdílé wa.

7 Bí ó bá sọ pé kò burú, a jẹ́ wí pé alaafia ni fún iranṣẹ rẹ, ṣugbọn bí ó bá bínú gidigidi, èyí yóo fihàn ọ́ wí pé, ó ní ìpinnu burúkú sí mi.

8 Nítorí náà ṣe èmi iranṣẹ rẹ ní oore kan, nítorí o ti mú mi dá majẹmu mímọ́ pẹlu rẹ. Ṣugbọn bí o bá rí ohun tí ó burú ninu ìwà mi, ìwọ gan-an ni kí o pa mí; má wulẹ̀ fà mí lé baba rẹ lọ́wọ́ láti pa.”

9 Jonatani bá dáhùn wí pé, “Má ṣe ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ṣé mo lè mọ̀ dájú pé baba mi fẹ́ pa ọ́, kí n má sọ fún ọ?”

10 Dafidi bá bèèrè pé, “Báwo ni n óo ṣe mọ̀ bí baba rẹ bá bínú?”

11 Jonatani dáhùn pé, “Máa bọ̀, jẹ́ kí á lọ sinu pápá.” Àwọn mejeeji sì lọ.

12 Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣe ẹlẹ́rìí láàrin èmi pẹlu rẹ. Ní àkókò yìí lọ́la tabi ní ọ̀tunla n óo wádìí nípa rẹ̀ lọ́wọ́ baba mi. Bí inú rẹ̀ bá yọ́ sí ọ n óo ranṣẹ sí ọ.

13 Ṣugbọn bí ó bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ níbi, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí OLUWA pa mí bí n kò bá sọ fún ọ, kí n sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sá àsálà. Kí OLUWA wà pẹlu rẹ bí ó ti ṣe wà pẹlu baba mi.

14 Bí mo bá sì wà láàyè kí o fi ìfẹ́ òtítọ́ OLUWA hàn sí mi kí n má baà kú. Ṣugbọn bí mo bá kú,

15 má jẹ́ kí àánú rẹ kúrò ninu ilé mi títí lae. Nígbà tí OLUWA bá ti ké gbogbo àwọn ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀ ayé,

16 má jẹ́ kí orúkọ Jonatani di ìkékúrò ní ilé Dafidi. Kí OLUWA gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá Dafidi.”

17 Jonatani tún mú kí Dafidi ṣe ìbúra lẹ́ẹ̀kan sí i, pẹlu ìfẹ́ tí ó ní sí i. Nítorí pé, Jonatani fẹ́ràn rẹ̀ bí ó ti fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀.

18 Lẹ́yìn náà, Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, àwọn eniyan yóo sì mọ̀ bí o kò bá wá síbi oúnjẹ nítorí ààyè rẹ yóo ṣófo.

19 Bí wọn kò bá rí ọ ní ọjọ́ keji, wọn yóo mọ̀ dájú pé o kò sí láàrin wọn. Nítorí náà, lọ sí ibi tí o farapamọ́ sí ní ìjelòó, kí o sì farapamọ́ sẹ́yìn àwọn òkúta ọ̀hún nnì.

20 N óo sì ta ọfà mẹta sí ìhà ibẹ̀ bí ẹni pé mo ta wọ́n sí àmì kan.

21 N óo rán ọmọkunrin kan láti wá àwọn ọfà náà. Bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wò ó àwọn ọfà náà wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,’ kí o jáde wá, nítorí bí OLUWA tí ń bẹ, kò sí ewu kankan fún ọ.

22 Ṣugbọn bí mo bá sọ fún un pé, ‘Wo àwọn ọfà náà níwájú rẹ,’ máa bá tìrẹ lọ nítorí OLUWA ni ó fẹ́ kí o lọ.

23 Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi pẹlu rẹ jọ sọ, ranti pé OLUWA wà láàrin wa laelae.”

24 Dafidi farapamọ́ ninu pápá, ní ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, Saulu ọba jókòó láti jẹun.

25 Ọba jókòó níbi tí ó máa ń jókòó sí ní ẹ̀gbẹ́ ògiri, Jonatani jókòó ní iwájú rẹ̀. Abineri sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Saulu. Ṣugbọn ààyè Dafidi ṣófo.

26 Sibẹ Saulu kò sọ nǹkankan nítorí pé ó rò pé bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi, tí ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ ni.

27 Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?”

28 Jonatani dáhùn pé, “Ó gbààyè lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu.

29 Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.”

30 Inú bí Saulu gidigidi sí Jonatani, ó ní, “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ati aláìgbọràn obinrin yìí, mo mọ̀ wí pé ò ń gbè lẹ́yìn Dafidi, o sì ń ta àbùkù ara rẹ ati ìhòòhò ìyá rẹ.

31 Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.”

32 Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?”

33 Saulu bá ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn, ó fẹ́ pa á. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ dájú pé, baba òun pinnu láti pa Dafidi.

34 Jonatani sì fi ibinu dìde kúrò ní ìdí tabili oúnjẹ, kò sì jẹun ní ọjọ́ náà, tíí ṣe ọjọ́ keji oṣù. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.

35 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jonatani mú ọmọde kan lọ́wọ́, ó lọ sí orí pápá gẹ́gẹ́ bí àdéhùn òun ati Dafidi.

36 Ó sọ fún ọmọ náà pé, “Sáré lọ wá àwọn ọfà tí mo ta wá.” Bí ọmọ náà ti ń sáré lọ, Jonatani ta ọfà siwaju rẹ̀.

37 Nígbà tí ọmọ náà dé ibi tí ọfà náà balẹ̀ sí, Jonatani pè é, ó ní, “Ọfà náà wà níwájú rẹ,”

38 Jonatani tún sọ fún un pe, “Yára má ṣe dúró.” Ọmọ náà ṣa àwọn ọfà náà, ó sì pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,

39 kò mọ nǹkankan; Jonatani ati Dafidi nìkan ni wọ́n mọ ìtumọ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.

40 Jonatani kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ọmọ náà pé kí ó kó wọn lọ sílé.

41 Bí ọmọ náà ti lọ tán, ni Dafidi jáde láti ibi òkúta tí ó sápamọ́ sí, ó sì dojúbolẹ̀, ó tẹríba lẹẹmẹta. Àwọn mejeeji sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọn sọkún títí tí ara Dafidi fi wálẹ̀.

42 Lẹ́yìn náà ni Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí Ọlọrun wà pẹlu rẹ. Kí OLUWA ran àwa mejeeji lọ́wọ́ ati àwọn ọmọ wa, kí á lè pa majẹmu tí ó wà láàrin wa mọ́ laelae.” Lẹ́yìn tí Dafidi lọ, Jonatani pada sí ààrin ìlú.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 21

Dafidi Sá fún Saulu

1 Dafidi lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki alufaa, ní Nobu. Ahimeleki sì jáde pẹlu ìbẹ̀rù láti pàdé rẹ̀, ó sì bi í pé, “Ṣé kò sí nǹkan tí ìwọ nìkan fi dá wá, tí kò sí ẹnikẹ́ni pẹlu rẹ?”

2 Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan.

3 Kí ni ẹ ní lọ́wọ́? Fún mi ní ìṣù burẹdi marun-un tabi ohunkohun tí o bá ní.”

4 Alufaa náà sì dáhùn pé, “N kò ní burẹdi lásán, àfi èyí tí ó jẹ́ mímọ́. Mo lè fún ọ tí ó bá dá ọ lójú pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pa ara wọn mọ́, tí wọn kò sì bá obinrin lòpọ̀.”

5 Dafidi dáhùn pé, “Àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi a máa pa ara wọn mọ́ nígbà tí a bá ń lọ fún iṣẹ́ tí kò ṣe pataki, kí á tó wá sọ ti iṣẹ́ yìí, tí ó jẹ́ iṣẹ́ pataki?”

6 Alufaa kó àwọn burẹdi mímọ́ náà fún Dafidi, nítorí pé kò sí òmíràn níbẹ̀, àfi burẹdi ìfihàn tí wọ́n kó kúrò níwájú OLUWA láti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀.

7 Doegi, olórí darandaran Saulu, ará Edomu wà níbẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ó ń jọ́sìn níwájú OLUWA.

8 Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.”

9 Ahimeleki sì dáhùn pé, “Idà Goliati ará Filistia tí o pa ní àfonífojì Ela nìkan ni ó wà ní ibí. A fi aṣọ kan wé e sí ẹ̀yìn efodu. Bí o bá fẹ́, o lè mú un. Kò sì sí òmíràn níbí lẹ́yìn rẹ̀.”

Dafidi dáhùn pé, “Kò sí idà tí ó dàbí rẹ̀, mú un fún mi.”

10 Dafidi sá fún Saulu ní ọjọ́ náà. Ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

11 Àwọn iranṣẹ Akiṣi sì sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ Dafidi, ọba ilẹ̀ rẹ̀ kọ́ nìyí, tí àwọn obinrin ń kọrin nípa rẹ̀ pé:

‘Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀,

Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”

12 Dafidi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi sọ́kàn ó ṣe bí ẹni pé kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ṣugbọn ó bẹ̀rù Akiṣi, ọba Gati gidigidi.

13 Ó yí ìṣe rẹ̀ pada níwájú wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi wèrè. Ó ń fi ọwọ́ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà ààfin, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.

14 Akiṣi bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ kò rí i pé aṣiwèrè ni ọkunrin yìí ni, kí ló dé tí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi?

15 Ṣé n kò ní aṣiwèrè níhìn-ín ni, tí ẹ fi mú un wá siwaju mi kí ó wá ṣe wèrè rẹ̀? Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí ni ó yẹ kí ó wá sinu ilé mi?”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 22

Saulu Pa Àwọn Alufaa

1 Dafidi sá kúrò ní ìlú Gati, lọ sinu ihò òkúta kan lẹ́bàá Adulamu. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀ gbọ́, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

2 Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, ati àwọn tí wọ́n jẹ gbèsè ati àwọn tí wọ́n wà ninu ìbànújẹ́ sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400) ọkunrin, ó sì jẹ́ olórí wọn.

3 Dafidi kúrò níbẹ̀ lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Moabu, ó sọ fún ọba Moabu pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí baba ati ìyá mi dúró lọ́dọ̀ rẹ títí tí n óo fi mọ ohun tí Ọlọrun yóo ṣe fún mi.”

4 Dafidi fi àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba Moabu, wọ́n sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Dafidi wà ní ìpamọ́.

5 Wolii Gadi sọ fún Dafidi pé, “Má dúró níbi ìpamọ́ yìí mọ́, múra, kí o lọ sí ilẹ̀ Juda.” Dafidi bá lọ sí igbó Hereti.

6 Nígbà tí Saulu jókòó ní abẹ́ igi tamarisiki ní orí òkè kan ni Gibea, ọ̀kọ̀ rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀, àwọn olórí ogun rẹ̀ sì dúró yí i ká, ó gbọ́ pé wọ́n rí Dafidi ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

7 Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ará Bẹnjamini, ṣé ọmọ Jese yìí yóo fún olukuluku yín ní oko ati ọgbà àjàrà? Ṣé yóo sì fi olukuluku yín ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀?

8 Ṣé nítorí náà ni ẹ ṣe gbìmọ̀ burúkú sí mi, tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò fi sọ fún mi pé ọmọ mi bá ọmọ Jese dá majẹmu. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì káàánú mi láàrin yín, kí ó sì sọ fún mi pé, ọmọ mi ń ran iranṣẹ mi lọ́wọ́ láti ba dè mí, bí ọ̀rọ̀ ti rí lónìí yìí.”

9 Doegi ará Edomu, tí ó dúró láàrin àwọn olórí ogun Saulu dáhùn pé, “Mo rí Dafidi nígbà tí ó lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ní Nobu.

10 Ahimeleki bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, lẹ́yìn náà ó fún Dafidi ní oúnjẹ ati idà Goliati, ará Filistia.”

11 Nítorí náà Saulu ọba ranṣẹ pe Ahimeleki ati gbogbo ìdílé rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alufaa ní Nobu, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

12 Saulu ní, “Gbọ́ mi! Ìwọ ọmọ Ahitubu.”

Ó dáhùn pé, “Mò ń gbọ́, oluwa mi.”

13 Saulu bi í pé, “Kí ló dé tí ìwọ ati ọmọ Jese fi gbìmọ̀ burúkú sí mi? Tí o fún un ní oúnjẹ ati idà, tí o sì tún bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun. Dafidi ti lòdì sí mi báyìí, ó sì ti ba dè mí, láti pa mí.”

14 Ahimeleki dáhùn pé, “Ta ló jẹ́ olóòótọ́ bíi Dafidi láàrin gbogbo àwọn olórí ogun rẹ? Ṣebí àna rẹ ni, ó sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun tí wọn ń ṣọ́ ọ ati eniyan pataki ninu ilé rẹ.

15 Ǹjẹ́ èyí ha ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Rárá o! Nítorí náà kí ọba má ṣe ka ẹ̀sùn kankan sí èmi ati ìdílé baba mi lẹ́sẹ̀, nítorí pé, èmi iranṣẹ rẹ, kò mọ nǹkankan nípa ọ̀tẹ̀ tí Dafidi dì sí ọ.”

16 Ọba dáhùn pé, “Ahimeleki, ìwọ ati ìdílé baba rẹ yóo kú.”

17 Ọba bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ pa àwọn alufaa OLUWA nítorí pé wọ́n wà lẹ́yìn Dafidi, wọ́n mọ̀ pé ó ń sá lọ, wọn kò sì sọ fún mi.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun náà kọ̀ láti pa àwọn alufaa OLUWA.

18 Ọba bá pàṣẹ fún Doegi pé, “Ìwọ, lọ pa wọ́n.” Doegi ará Edomu sì pa alufaa marunlelọgọrin, tí ń wọ aṣọ efodu.

19 Saulu pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Nobu, ìlú àwọn alufaa, atọkunrin atobinrin, àtọmọdé, àtọmọ ọwọ́, ati mààlúù, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati aguntan, wọ́n sì pa gbogbo wọn.

20 Ṣugbọn Abiatari, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Ahimeleki sá àsálà, ó sì lọ sọ́dọ̀ Dafidi.

21 Ó sọ fún un bí Saulu ṣe pa àwọn alufaa OLUWA.

22 Dafidi dá a lóhùn pé, “Nígbà tí mo ti rí Doegi níbẹ̀ ní ọjọ́ náà ni mo ti fura pé yóo sọ fún Saulu. Nítorí náà, ẹ̀bi ikú àwọn eniyan rẹ wà lọ́rùn mi.

23 Dúró tì mí, má sì ṣe bẹ̀rù, nítorí pé Saulu tí ó fẹ́ pa ọ́, fẹ́ pa èmi pàápàá, ṣugbọn o óo wà ní abẹ ààbò níbí.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 23

Dafidi Gba Ìlú Keila Sílẹ̀

1 Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Filistia ń gbógun ti àwọn ará Keila, wọ́n sì ń jí ọkà wọn kó ní ibi ìpakà,

2 ó bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n gbógun ti àwọn ará Filistia?”

OLUWA dáhùn pé, “Gbógun tì wọ́n kí o sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀.”

3 Àwọn ọkunrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì sọ fún un pé, “Ní Juda tí a wà níhìn-ín, inú ewu ni a wà, báwo ni yóo ti rí nígbà tí a bá tún lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila?”

4 Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ OLUWA lẹ́ẹ̀kan sí i pé, bóyá kí òun lọ tabi kí òun má lọ. OLUWA sì dáhùn pé, “Lọ sí Keila nítorí n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Filistia.”

5 Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila, wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wọn, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe gba àwọn ará Keila sílẹ̀.

6 Nígbà tí Abiatari, ọmọ Ahimeleki sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó mú aṣọ efodu kan lọ́wọ́.

7 Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Keila, ó sọ pé, “Ọlọ́run ti fi Dafidi lé mi lọ́wọ́, nítorí ó ti ti ara rẹ̀ mọ́ inú ìlú olódi tí ó ní ìlẹ̀kùn, tí ó sì lágbára.”

8 Saulu bá pe gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti gbógun ti Keila kí wọ́n sì ká Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ìlú náà.

9 Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun.

10 Dafidi ní, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, èmi iranṣẹ rẹ gbọ́ pé Saulu ti pinnu láti wá gbógun ti Keila ati láti pa á run nítorí mi.

11 Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé Saulu lọ́wọ́? Ṣe Saulu yóo wá gẹ́gẹ́ bí mo ti gbọ́? Jọ̀wọ́, OLUWA Ọlọrun Israẹli, fún mi ní èsì.”

OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu yóo wá.”

12 Dafidi tún bèèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé e lọ́wọ́?”

OLUWA dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóo fà ọ́ lé e lọ́wọ́.”

13 Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́.

Dafidi Ń Gbé Orí Òkè

14 Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́.

15 Ẹ̀rù ba Dafidi nítorí pé Saulu ń wá ọ̀nà láti pa á.

Dafidi ń gbé aṣálẹ̀ Sifi ni Horeṣi.

16 Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú.

17 Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.”

18 Àwọn mejeeji dá majẹmu níwájú OLUWA; Dafidi dúró ní Horeṣi, Jonatani sì pada sílé.

19 Àwọn ará Sifi kan lọ sọ́dọ̀ Saulu ní Gibea, wọ́n sọ fún un pé, “Dafidi sá pamọ́ sáàrin wa ní Horeṣi ní orí òkè Hakila tí ó wà ní ìhà gúsù Jeṣimoni.

20 Nítorí náà, wá sọ́dọ̀ wa nígbà tí o bá fẹ́, a óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”

21 Saulu dáhùn pé, “OLUWA yóo bukun yín nítorí pé ẹ káàánú mi.

22 Ẹ lọ nisinsinyii kí ẹ sì tún ṣe ìwádìí dáradára nípa ibi tí ó wà, ati ẹni tí ó rí i níbẹ̀; nítorí mo gbọ́ pé alárèékérekè ẹ̀dá ni Dafidi.

23 Ẹ mọ gbogbo ibi tíí máa ń sá pamọ́ sí dájúdájú, kí ẹ sì wá ròyìn fún mi. N óo ba yín lọ; bí ó bá wà níbẹ̀, n óo wá a kàn, bí ó bá tilẹ̀ wà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ilẹ̀ Juda.”

24 Wọ́n bá pada sí Sifi ṣáájú Saulu. Ṣugbọn Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ti wà ní aṣálẹ̀ Maoni tí ó wà ní Araba lápá ìhà gúsù Jeṣimoni.

25 Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti wá Dafidi. Ṣugbọn Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì lọ sá pamọ́ sí ibi òkúta kan tí ó wà ní aṣálẹ̀ Maoni. Nígbà tí Saulu gbọ́, ó lépa Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Maoni.

26 Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ wà ní apá kan òkè náà, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì wà ní apá keji. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń múra láti sá fún Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ nítorí pé wọ́n ń rọ̀gbà yí wọn ká láti mú wọn.

27 Nígbà náà ni oníṣẹ́ kan wá sọ fún Saulu pé, “Pada wá kíákíá, nítorí pé àwọn ará Filistia ti gbógun ti ilẹ̀ wa.”

28 Nítorí náà, Saulu pada lẹ́yìn Dafidi, ó sì lọ bá àwọn ará Filistia jà. Nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ń pe òkè náà ní Àpáta Àsálà.

29 Láti ibẹ̀, Dafidi lọ farapamọ́ sí Engedi.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 24

Dafidi Dá Ẹ̀mí Saulu Sí

1 Nígbà tí Saulu bá àwọn ará Filistia jagun tán, wọ́n sọ fún un pé Dafidi wà ní aṣálẹ̀ Engedi.

2 Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ọmọ ogun lára àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n lọ láti wá Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ní orí àwọn àpáta ewúrẹ́ ìgbẹ́.

3 Nígbà tí Saulu dé ibi tí àwọn agbo aguntan kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó rí ihò àpáta ńlá kan lẹ́bàá ibẹ̀, ó sì wọ inú rẹ̀ lọ láti sinmi. Ihò náà jẹ́ ibi tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ farapamọ́ sí.

4 Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀.

5 Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu.

6 Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.”

7 Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu.

Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

8 Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un.

9 Ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń gbọ́ ti àwọn tí wọ́n ń sọ pé mo fẹ́ pa ọ́?

10 Nisinsinyii, o rí i dájú pé OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ ninu ihò àpáta. Àwọn kan ninu àwọn ọkunrin mi rọ̀ mí pé kí n pa ọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo sọ fún wọn pé, n kò ní fọwọ́ mi kàn ọ́, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́.

11 Wò ó! Baba mi, wo etí aṣọ rẹ tí mo mú lọ́wọ́ yìí, ǹ bá pa ọ́ bí mo bá fẹ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, mo gé etí aṣọ rẹ. Ó yẹ kí èyí fihàn ọ́ pé n kò ní ìfẹ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, tabi láti pa ọ́. Ṣugbọn ìwọ ń lé mi kiri láti pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ọ́ níbi.

12 Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ. Kí ó sì jẹ ọ́ níyà fún ìwà burúkú tí ò ń hù sí mi, nítorí pé n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan.

13 Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, àwọn eniyan burúkú a máa hùwà burúkú, ṣugbọn n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan.

14 Ta ni ìwọ odidi ọba Israẹli ń gbìyànjú láti pa? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá lásán! Eṣinṣin lásánlàsàn!

15 Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ, kí ó gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò, kí ó gbèjà mi, kí ó sì gbà mí, lọ́wọ́ rẹ.”

16 Nígbà tí Dafidi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Saulu dáhùn pé, “Ṣé ohùn rẹ ni mò ń gbọ́, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

17 Ó wí fún Dafidi pé, “Eniyan rere ni ọ́, èmi ni eniyan burúkú, nítorí pé oore ni ò ń ṣe mí, ṣugbọn èmi ń ṣe ọ́ ní ibi.

18 Lónìí, o ti fi bí o ti jẹ́ eniyan rere sí mi tó hàn mí, nítorí pé o kò pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA fi mí lé ọ lọ́wọ́.

19 Ǹjẹ́ bí eniyan bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní alaafia? Kí OLUWA bukun ọ nítorí ohun tí o ṣe fún mi lónìí.

20 Nisinsinyii, mo mọ̀ dájú pé o óo jọba ilẹ̀ Israẹli, ìjọba Israẹli yóo sì tẹ̀síwájú nígbà tìrẹ.

21 Nítorí náà, búra fún mi pé o kò ní pa ìdílé mi run lẹ́yìn mi, ati pé o kò ní pa orúkọ mi rẹ́ ní ìdílé baba mi.”

22 Dafidi bá búra fún Saulu.

Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sílé, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì pada sí ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 25

Ikú Samuẹli

1 Nígbà tí Samuẹli kú, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kó ara wọn jọ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí ilé rẹ̀ ní Rama.

Dafidi ati Abigaili

Lẹ́yìn náà, Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Parani.

2 Ọkunrin kan wà ní ìlú Maoni tí ń ṣe òwò ní Kamẹli. Ọkunrin náà ní ọrọ̀ lọpọlọpọ; ó ní ẹgbẹẹdogun aguntan (3,000) ati ẹgbẹrun (1,000) ewúrẹ́, Kamẹli níí ti máa ń gé irun aguntan rẹ̀.

3 Orúkọ ọkunrin náà ni Nabali, iyawo rẹ̀ sì ń jẹ́ Abigaili. Obinrin náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n ati arẹwà, ṣugbọn ọkọ rẹ̀ jẹ́ òǹrorò ati eniyan burúkú. Ìdílé Kalebu ni ìdílé rẹ̀.

4 Dafidi gbọ́ ninu aṣálẹ̀ pé Nabali ń gé irun aguntan rẹ̀,

5 ó bá rán ọdọmọkunrin mẹ́wàá lọ sí Kamẹli láti lọ rí Nabali, kí wọ́n sì kí i ní orúkọ òun.

6 Ó ní kí wọ́n kí i báyìí pé, “Alaafia fún ọ, ati fún ilé rẹ ati fún gbogbo ohun tí o ní.

7 Mo gbọ́ pé ò ń gé irun àwọn aguntan rẹ, mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ aguntan rẹ wà lọ́dọ̀ wa fún ìgbà pípẹ́, n kò sì ṣe wọ́n ní ibi kankan. Kò sí ohun tí ó jẹ́ tiwọn tí ó sọnù ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà ní Kamẹli.

8 Bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọdọmọkunrin rẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ. Ọjọ́ ọdún ni ọjọ́ òní, nítorí náà jẹ́ kí àwọn ọmọkunrin yìí rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́ mú ohunkohun tí ó bá wà ní àrọ́wọ́tó rẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, ati fún èmi Dafidi, ọmọ rẹ.”

9 Nígbà tí àwọn tí Dafidi rán dé ibẹ̀, wọ́n jíṣẹ́ fún Nabali, ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì dúró.

10 Nabali dá àwọn iranṣẹ náà lóhùn pé, “Ta ni Dafidi? Ta ni ọmọ Jese? Ọpọlọpọ iranṣẹ ni ó wà nisinsinyii tí wọn ń sá kúrò ní ọ̀dọ̀ oluwa wọn.

11 Ṣé kí n wá mú oúnjẹ mi ati omi mi ati ẹran tí mo pa fún àwọn tí wọn ń gé irun aguntan mi, kí n sì gbé e fún àwọn tí n kò mọ ibi tí wọ́n ti wá?”

12 Àwọn ọdọmọkunrin náà bá pada lọ sọ gbogbo ohun tí Nabali sọ fún wọn fún Dafidi.

13 Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn.

14 Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Nabali sọ fún Abigaili, iyawo Nabali pé, “Dafidi rán àwọn iranṣẹ láti aṣálẹ̀ wá sọ́dọ̀ oluwa wa, ṣugbọn ó kanra mọ́ wọn.

15 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọkunrin náà tọ́jú wa, wọn kò sì ṣe ibi kankan sí wa, nǹkankan tí ó jẹ́ tiwa kò sì sọnù nígbà tí a wà pẹlu wọn ní oko.

16 Wọ́n dáàbò bò wá tọ̀sán tòru, ní gbogbo ìgbà tí a wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú agbo ẹran wa.

17 Jọ̀wọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáradára, kí o sì pinnu ohun tí o bá fẹ́ ṣe; nítorí pé wọ́n ti gbèrò ibi sí oluwa wa ati ìdílé rẹ̀, ọlọ́kàn líle sì ni oluwa wa, ẹnikẹ́ni kò lè bá a sọ̀rọ̀.”

18 Abigaili bá yára mú igba (200) burẹdi ati ìgò ọtí waini meji ati aguntan marun-un tí wọ́n ti sè ati òṣùnwọ̀n ọkà yíyan marun-un ati ọgọrun-un ìdì àjàrà gbígbẹ ati igba (200) àkàrà tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ dín, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

19 Ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa lọ ṣiwaju, èmi náà ń bọ̀ lẹ́yìn,” ṣugbọn kò sọ fún ọkọ rẹ̀.

20 Bí ó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, tí ó dé abẹ́ òkè kan, ó rí i tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń bọ̀ níwájú.

21 Dafidi ti wí pé, “Ṣé lásán ni mo dáàbò bo agbo ẹran Nabali ninu aṣálẹ̀, tí kò sí ohun ìní rẹ̀ kan tí ó sọnù. Ṣé bí ó ti yẹ kí ó fi ibi san ire fún mi nìyí.

22 Kí Ọlọrun pa mí bí mo bá fi ẹnikẹ́ni sílẹ̀ láìpa ninu àwọn eniyan Nabali títí di òwúrọ̀ ọ̀la.”

23 Nígbà tí Abigaili rí Dafidi, ó sọ̀kalẹ̀ kíákíá, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ lẹ́bàá

24 ẹsẹ̀ Dafidi, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, gbọ́ ti èmi iranṣẹbinrin rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ru ẹ̀bi àṣìṣe Nabali.

25 Jọ̀wọ́ má ṣe ka aláìmòye yìí sí, nítorí Nabali ni orúkọ rẹ̀, bí orúkọ rẹ̀ tí ń jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwà rẹ̀ rí. Oluwa mi, n kò rí àwọn iranṣẹ rẹ nígbà tí wọ́n wá.

26 OLUWA tìkararẹ̀ ni ó ti ká ọ lọ́wọ́ kò láti má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ati láti má gbẹ̀san. Nisinsinyii, oluwa mi, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ati àwọn tí wọn ń ro ibi sí ọ yóo dàbí Nabali.

27 Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí èmi iranṣẹbinrin rẹ mú wá fún ọ kí o sì fi fún àwọn ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé ọ.

28 Jọ̀wọ́ dáríjì mí fún gbogbo àìṣedéédé mi. Dájúdájú OLUWA yóo jẹ́ kí o jọba ati àwọn ọmọ rẹ pẹlu. Nítorí pé ogun OLUWA ni ò ń jà, o kò sì hùwà ibi kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

29 Bí ẹnikẹ́ni bá sì ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní ibi tabi láti pa ọ́, OLUWA yóo dáàbò bò ọ́ bí eniyan ti ń dáàbò bo ohun ìní olówó iyebíye. Ṣugbọn àwọn ọ̀tá rẹ ni a óo parun.

30 Nígbà tí OLUWA bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tí ó sì fi ọ́ jọba ní Israẹli,

31 o kò ní ní ìbànújẹ́ ọkàn pé o ti paniyan rí láìnídìí tabi pé o ti gbẹ̀san ara rẹ. Nígbà tí OLUWA bá sì bukun ọ, jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé èmi iranṣẹbinrin rẹ.”

32 Dafidi dáhùn pé, “Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó rán ọ sí mi lónìí.

33 Ibukun ni fún ọ, fún ọgbọ́n tí o lò ati ohun tí o ṣe lónìí, tí o fà mí sẹ́yìn kúrò ninu ìpànìyàn ati ìgbẹ̀san.

34 OLUWA ti dá mi dúró láti má ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí mi, bí o kò bá yára láti pàdé mi ni, gbogbo àwọn ọkunrin ilé Nabali ni ìbá kú kí ilẹ̀ ọ̀la tó mọ́.”

35 Dafidi gba ẹ̀bùn tí ó mú wá, ó sì sọ fún un pé, “Máa lọ sílé ní alaafia, kí o má sì ṣe bẹ̀rù, n óo ṣe ohun tí o sọ.”

36 Nígbà tí Abigaili pada dé ilé ó bá Nabali ninu àsè bí ọba. Inú rẹ̀ dùn nítorí pé ó ti mu ọtí ní àmupara. Abigaili kò sì sọ nǹkankan fún un títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

37 Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀ tán; Abigaili sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.

38 Ní ọjọ́ kẹwaa lẹ́yìn náà, OLUWA pa Nabali.

39 Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA tí ó gbẹ̀san lára Nabali nítorí àfojúdi tí ó ṣe sí mi. Ìyìn ni fún OLUWA tí ó sì fa èmi iranṣẹ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣe ibi. OLUWA ti jẹ Nabali níyà fún ìwà burúkú rẹ̀.”

Dafidi bá ranṣẹ sí Abigaili pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ.

40 Àwọn iranṣẹ Dafidi lọ sọ́dọ̀ Abigaili ní Kamẹli, wọ́n ní, “Dafidi ní kí á mú ọ wá, kí o lè jẹ́ aya òun.”

41 Abigaili bá wólẹ̀ ó ní, “Iranṣẹ Dafidi ni mí, mo sì ti ṣetán láti ṣan ẹsẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀.”

42 Ó yára gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, òun pẹlu àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun-un, wọ́n sì tẹ̀lé àwọn iranṣẹ Dafidi lọ, Abigaili sì di aya Dafidi.

43 Dafidi ti fẹ́ Ahinoamu ará Jesireeli, ó sì tún fẹ́ Abigaili pẹlu.

44 Ṣugbọn Saulu ti mú Mikali, ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ iyawo Dafidi, ó ti fún Paliti ọmọ Laiṣi tí ó wá láti Galimu pé kí ó fi ṣe aya.