Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 6

Wọ́n Dá Àpótí Ẹ̀rí Pada

1 Lẹ́yìn tí àpótí OLUWA ti wà ní ilẹ̀ Filistini fún oṣù meje,

2 àwọn ará ilẹ̀ náà pe àwọn babalóòṣà wọn ati àwọn adáhunṣe wọn jọ, wọ́n bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí OLUWA? Bí a óo bá dá a pada sí ibi tí wọ́n ti gbé e wá, kí ni kí á fi ranṣẹ pẹlu rẹ̀?”

3 Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ óo bá dá àpótí Ọlọrun Israẹli pada, ẹ gbọdọ̀ dá a pada pẹlu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àpótí ẹ̀rí náà kò gbọdọ̀ pada lọ lásán, láìsí nǹkan ètùtù. Bẹ́ẹ̀ ni ara yín yóo ṣe yá, ẹ óo sì mọ ìdí tí Ọlọrun fi ń jẹ yín níyà.”

4 Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?”

Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun.

5 Ẹ gbọdọ̀ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún yín ati ti èkúté tí ń ba ilẹ̀ yín jẹ́, kí ẹ sì fi ògo fún Ọlọrun Israẹli bóyá ó lè dáwọ́ ìjìyà rẹ̀ dúró lórí ẹ̀yin ati oriṣa yín, ati ilẹ̀ yín.

6 Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ ṣe oríkunkun, bí ọba ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará Ijipti. Ẹ ranti bí Ọlọrun ti fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà títí tí wọ́n fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. Wọ́n kúkú lọ!

7 Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé.

8 Ẹ gbé àpótí OLUWA lé orí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. Ẹ kó àwọn kókó ọlọ́yún ati àwọn èkúté tí ẹ fi wúrà ṣe, tí ẹ fẹ́ fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù sinu àpótí kan, kí ẹ wá gbé e sí ẹ̀gbẹ́ àpótí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ẹ ti kẹ̀kẹ́ ẹrù yìí sójú ọ̀nà, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ fúnrarẹ̀.

9 Ẹ máa kíyèsí i bí ó bá ti ń lọ. Bí ó bá doríkọ ọ̀nà ìlú Beti Ṣemeṣi, a jẹ́ pé Ọlọrun àwọn ọmọ Israẹli ni ó kó gbogbo àjálù yìí bá wa. Bí kò bá doríkọ ibẹ̀, a óo mọ̀ pé kì í ṣe òun ló rán àjálù náà sí wa, a jẹ́ pé ó kàn dé bá wa ni.”

10 Àwọn eniyan náà ṣe bí àwọn babalóòṣà ti wí. Wọ́n mú mààlúù meji tí wọn ń fún ọmọ lọ́mú lọ́wọ́, wọ́n so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ti àwọn ọmọ wọn mọ́lé.

11 Wọ́n gbé àpótí OLUWA sinu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, pẹlu àpótí tí wọ́n kó àwọn èkúté wúrà ati kókó ọlọ́yún wúrà náà sí.

12 Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.

13 Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.

14 Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

15 Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà.

16 Àwọn ọba Filistini ń wò wọ́n bí wọ́n ti ń ṣe, lẹ́yìn náà, wọ́n yipada sí ìlú Ekironi ní ọjọ́ náà gan-an.

17 Àwọn ará Filistia fi kókó ọlọ́yún marun-un náà tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ìlú kọ̀ọ̀kan; Aṣidodu, Gasa, Aṣikeloni, Gati ati Ekironi.

18 Wọ́n sì fi àwọn èkúté marun-un tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ. Èkúté kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ìlú àwọn ọba Filistini maraarun. Àwọn maraarun wà fún àwọn ìlú olódi àwọn ọba Filistini, pẹlu àwọn ìletò kéékèèké wọn, tí kò ní odi. Àpáta ńlá tí ó wà ninu oko Joṣua ará Beti Ṣemeṣi, tí àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí OLUWA náà lé wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di òní olónìí.

19 Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn.

Àpótí Ẹ̀rí ní Kiriati Jearimu

20 Àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ní, “Ta ló lè dúró níwájú OLUWA Ọlọrun mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni yóo fẹ́ lọ, tí yóo fi kúrò lọ́dọ̀ wa?”

21 Wọ́n bá ranṣẹ sí àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu pé, “Àwọn ará Filistia ti dá àpótí OLUWA pada. Ẹ wá gbé e.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 7

1 Àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu wá, wọ́n gbé àpótí OLUWA náà lọ sí ilé Abinadabu, tí ń gbé orí òkè kan. Wọ́n ya Eleasari, ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, láti máa bojútó àpótí OLUWA náà.

Samuẹli Ń Ṣe Àkóso Israẹli

2 Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.

3 Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”

4 Àwọn ọmọ Israẹli bá kó gbogbo oriṣa Baali ati ti Aṣitarotu wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA nìkan.

5 Samuẹli ní kí wọ́n kó gbogbo eniyan Israẹli jọ sí Misipa, ó ní òun óo gbadura sí OLUWA fún wọn níbẹ̀.

6 Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa.

7 Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli péjọ sí Misipa, àwọn ọba Filistini kó àwọn eniyan wọn jọ láti gbógun tì wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n.

8 Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Má dákẹ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”

9 Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.

10 Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà.

11 Àwọn ọmọ Israẹli bá kó ogun jáde láti Misipa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ ogun Filistini lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìsàlẹ̀ Betikari, wọ́n ń pa wọ́n bí wọ́n ti ń lé wọn lọ.

12 Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni,ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri,ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.”

13 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli.

14 Gbogbo ìlú tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, láti Ekironi títí dé Gati, ni wọ́n dá pada fún wọn. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ilẹ̀ wọn pada lọ́wọ́ àwọn ará Filistia. Alaafia wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará Amori.

15 Samuẹli jẹ́ adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí tí ó fi kú.

16 Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́.

17 Lẹ́yìn náà, yóo pada lọ sí ilé rẹ̀, ní Rama, nítorí pé a máa dájọ́ fún àwọn eniyan níbẹ̀ pẹlu. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 8

Àwọn Ọmọ Israẹli Bèèrè fún Ọba

1 Nígbà tí àgbà dé sí Samuẹli, ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.

2 Joẹli ni orúkọ àkọ́bí, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Abija. Beeriṣeba ni wọ́n ti ń ṣe adájọ́.

3 Ṣugbọn wọn kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere baba wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń dájọ́ èké.

4 Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama;

5 wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.”

6 Ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ Samuẹli ninu, pé àwọn eniyan náà ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí wọn. Samuẹli bá gbadura sí OLUWA.

7 OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba.

8 Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí.

9 Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.”

10 Samuẹli bá sọ gbogbo ohun tí OLUWA bá a sọ fún àwọn tí wọ́n ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí àwọn.

11 Ó ṣe àlàyé fún wọn pé, “Bí ọba yín yóo ti máa ṣe yín nìyí: Yóo sọ àwọn ọmọkunrin yín di ọmọ ogun, àwọn kan ninu wọn yóo máa wa kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn kan yóo wà ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń fi ẹsẹ̀ rìn, àwọn kan yóo máa gun ẹṣin níwájú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

12 Yóo fi àwọn kan ṣe ọ̀gágun fún ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, àwọn kan yóo máa ṣe ọ̀gágun fún araadọta ọmọ ogun. Àwọn kan yóo máa ro oko rẹ̀, àwọn kan yóo sì máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀. Àwọn kan yóo máa rọ ohun ìjà fún un, ati àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

13 Àwọn ọmọbinrin yín ni yóo máa ṣe turari fún un, wọn óo sì máa se oúnjẹ fún un.

14 Yóo gba ilẹ̀ oko yín tí ó dára jùlọ ati ọgbà àjàrà ati ti olifi yín, yóo sì fi fún àwọn iranṣẹ rẹ̀.

15 Yóo gba ìdámẹ́wàá ọkà yín ati ti ọgbà àjàrà yín fún àwọn ẹmẹ̀wà ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.

16 Yóo gba àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, ati àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí wọ́n dára jùlọ, yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́.

17 Yóo gba ìdámẹ́wàá agbo aguntan yín, ẹ̀yin gan-an yóo sì di ẹrú rẹ̀.

18 Nígbà tí ó bá yá, ẹ̀yin gan-an ni ẹ óo tún máa pariwo ọba yín tí ẹ yàn fún ara yín, ṣugbọn OLUWA kò ní da yín lóhùn.”

19 Ṣugbọn àwọn eniyan náà kọ̀, wọn kò gba ohun tí Samuẹli wí gbọ́. Wọ́n ní, “Rárá o! A ṣá fẹ́ ní ọba ni.

20 Kí àwa náà lè dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ọba wa lè máa ṣe àkóso wa, kí ó máa ṣiwaju wa lójú ogun, kí ó sì máa jà fún wa.”

21 Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n wí, ó lọ sọ fún OLUWA.

22 OLUWA sọ fún Samuẹli pé, “Ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, kí o sì yan ọba fún wọn.” Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 9

Saulu Pàdé Samuẹli

1 Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afaya láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini.

2 Ó ní ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Saulu. Saulu yìí jẹ́ arẹwà ọkunrin. Láti èjìká rẹ̀ sókè ni ó fi ga ju ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ, ó sì lẹ́wà ju ẹnikẹ́ni ninu wọn lọ.

3 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kiṣi, baba Saulu sọnù. Kiṣi bá sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ lẹ́yìn, kí ẹ lọ wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá.”

4 Wọ́n wá gbogbo agbègbè olókè Efuraimu káàkiri, ati gbogbo agbègbè Ṣaliṣa, ṣugbọn wọn kò rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Wọ́n wá gbogbo agbègbè Ṣaalimu, ṣugbọn wọn kò rí wọn níbẹ̀. Lẹ́yìn náà wọ́n wá gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini, sibẹsibẹ wọn kò rí wọn.

5 Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún iranṣẹ tí ó wà pẹlu rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á pada sílé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi lè má ronú nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, kí ó máa páyà nítorí tiwa.”

6 Iranṣẹ náà dá a lóhùn, ó ní, “Dúró ná, eniyan Ọlọrun kan wà ní ilẹ̀ yìí, tí gbogbo eniyan ń bu ọlá fún, nítorí pé gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ níí máa ń ṣẹ. Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, bóyá ó lè sọ ibi tí a óo ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún wa.”

7 Saulu dá a lóhùn pé, “Bí a bá tọ eniyan Ọlọrun yìí lọ nisinsinyii, kí ni a óo mú lọ́wọ́ lọ fún un? Oúnjẹ tí ó wà ninu àpò wa ti tán, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkankan lọ́wọ́ wa tí a lè fún un. Àbí kí ni a óo fún un?”

8 Iranṣẹ náà dá Saulu lóhùn, ó ní, “Mo ní idamẹrin owó ṣekeli fadaka kan lọ́wọ́, n óo fún un, yóo sì sọ ibi tí a óo ti rí wọn fún wa.”

9 (Ní àtijọ́, ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo wí pé, òun ń lọ sí ọ̀dọ̀ aríran; nítorí àwọn tí àwa ń pè ní wolii lónìí, aríran ni wọ́n ń pè wọ́n nígbà náà.)

10 Saulu bá dá a lóhùn pé, “O ṣeun, jẹ́ kí á lọ.” Wọ́n bá lọ sí ìlú tí eniyan Ọlọrun yìí wà.

11 Bí wọ́n ti ń gun òkè lọ láti wọ ìlú, wọ́n pàdé àwọn ọmọbinrin tí wọ́n ń jáde lọ pọn omi. Wọ́n bi àwọn ọmọbinrin náà pé, “Ǹjẹ́ aríran wà ní ìlú?”

12 Àwọn ọmọbinrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ní ìlú. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá nisinsinyii ni. Bí ó ti ń wọ ìlú bọ̀ tààrà nìyí, ẹ yára lọ bá a. Àwọn eniyan ní ẹbọ kan tí wọn óo rú ní orí òkè lónìí.

13 Bí ẹ bá tí ń wọ ìlú ni ẹ óo rí i. Ẹ yára kí ẹ lè bá a, kí ó tó lọ sí orí òkè lọ jẹun; nítorí pé àwọn eniyan kò ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóo fi dé. Òun ni ó gbọdọ̀ súre sí ẹbọ náà, kí àwọn tí wọ́n bá pè tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ẹ tètè máa lọ, ẹ óo bá a.”

14 Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ bá gòkè wọ ìlú lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n rí Samuẹli tí ń jáde bọ̀ wá sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ wọn, ó ń lọ sí orí òkè tí wọ́n ti ń rúbọ.

15 Ó ku ọ̀la kí Saulu dé ni OLUWA ti sọ fún Samuẹli pé,

16 “Ní ìwòyí ọ̀la, n óo rán ọkunrin kan sí ọ láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. O óo ta òróró sí i lórí láti yàn án ní ọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Ọkunrin náà ni yóo gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, nítorí mo ti rí àwọn eniyan mi tí ń jìyà, mo sì ti gbọ́ igbe wọn.”

17 Nígbà tí Samuẹli fi ojú kan Saulu, OLUWA wí fún un pé, “Ọkunrin tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọ nìyí. Òun ni yóo jọba lórí àwọn eniyan mi.”

18 Saulu tọ Samuẹli lọ, lẹ́nu ibodè, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, níbo ni ilé aríran?”

19 Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi aríran náà nìyí. Ẹ máa lọ sí ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ, nítorí ẹ óo bá mi jẹun lónìí. Bí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n óo sì sọ gbogbo ohun tí ẹ fẹ́ mọ̀ fun yín.

20 Nípa ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n sọnù láti ìjẹta, ẹ má da ara yín láàmú, wọ́n ti rí wọn. Ṣugbọn ta ni ẹni náà tí àwọn eniyan Israẹli ń fẹ́ tóbẹ́ẹ̀? Ṣebí ìwọ ati ìdílé baba rẹ ni.”

21 Saulu dá a lóhùn, ó ní, “Inú ẹ̀yà Bẹnjamini tí ó kéré jù ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli ni mo ti wá, ati pé ìdílé baba mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Bẹnjamini. Kí ló dé tí o fi ń bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?”

22 Samuẹli bá mú Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn ńlá lọ, ó fi wọ́n jókòó sí ààyè tí ó ṣe pataki jùlọ níbi tabili oúnjẹ tí wọ́n fi àwọn àlejò bí ọgbọ̀n jókòó sí.

23 Ó sọ fún alásè pé kí ó gbé ẹran tí òun ní kí ó fi sọ́tọ̀ wá.

24 Alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ati itan ẹran náà wá, ó gbé e kalẹ̀ níwájú Saulu. Samuẹli wí fún Saulu pé, “Wò ó, ohun tí a ti pèsè sílẹ̀ dè ọ́ ni wọ́n gbé ka iwájú rẹ yìí. Máa jẹ ẹ́, ìwọ ni a fi pamọ́ dè, pé kí o jẹ ẹ́ ní àkókò yìí pẹlu àwọn tí mo pè.”

Saulu ati Samuẹli bá jọ jẹun pọ̀ ní ọjọ́ náà.

25 Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá sinu ìlú láti ibi ìrúbọ náà, wọ́n tẹ́ ibùsùn kan fún Saulu lórí òrùlé, ó sì sùn sibẹ.

Samuẹli Ta Òróró sí Saulu lórí láti Yàn án ní Ọba

26 Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́, Samuẹli pe Saulu lórí òrùlé, ó ní, “Dìde kí n sìn ọ́ sọ́nà.” Saulu dìde, òun ati Samuẹli bá jáde sí òpópónà.

27 Nígbà tí wọ́n dé ibi odi ìlú, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún iranṣẹ rẹ kí ó máa nìṣó níwájú dè wá.” Iranṣẹ náà bá bọ́ siwaju, ó ń lọ. Samuẹli sọ fún Saulu pé, “Dúró díẹ̀ níhìn-ín kí n sọ ohun tí Ọlọrun wí fún ọ.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 10

1 Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí:

2 Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’

3 Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́.

4 Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.

5 Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

6 Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀.

7 Nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣe ohunkohun tí ó bá wá sọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ.

8 Máa lọ sí Giligali ṣiwaju mi. N óo wá bá ọ níbẹ̀ láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meje, títí tí n óo fi dé, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”

9 Yíyí tí Saulu yipada kúrò lọ́dọ̀ Samuẹli, Ọlọrun sọ ọ́ di ẹ̀dá titun. Gbogbo àwọn àmì tí Samuẹli sọ fún un patapata ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà.

10 Nígbà tí Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ dé Gibea, ọ̀wọ́ àwọn wolii kan pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ láàrin wọn.

11 Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”

12 Ọkunrin kan tí ń gbé ibẹ̀ bèèrè pé, “Ta ni baba àwọn wolii wọnyi?” Láti ìgbà náà ni ó ti di àṣà kí àwọn eniyan máa wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”

13 Lẹ́yìn tí Saulu ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, ó lọ sí ibi pẹpẹ, ní orí òkè.

14 Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?”

Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.”

15 Arakunrin baba Saulu bá bi í pé, “Kí ni Samuẹli sọ fun yín?”

16 Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba.

Wọ́n Fi Ìhó Ayọ̀ Gba Saulu ní Ọba

17 Samuẹli pe àwọn eniyan náà jọ siwaju OLUWA ní Misipa.

18 Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’

19 Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, Ọlọrun tí ó gbà yín kúrò lọ́wọ́ ìṣòro ati ìyọnu. Ẹ wí fún mi pé, ‘Yan ẹnìkan, tí yóo jọba lórí wa.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.”

20 Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini.

21 Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a.

22 Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?”

OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.”

23 Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn.

24 Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.”

Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”

25 Samuẹli ṣe àlàyé àwọn ẹ̀tọ́ ati iṣẹ́ ọba fún àwọn eniyan náà. Ó kọ àwọn àlàyé náà sinu ìwé kan, ó sì gbé e siwaju OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó ní kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀.

26 Saulu náà bá pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea. Àwọn akọni ọkunrin bíi mélòó kan tí Ọlọrun ti fi sí ní ọkàn bá Saulu lọ.

27 Ṣugbọn àwọn oníjàngbọ̀n kan dáhùn pé, “Báwo ni eléyìí ṣe lè gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣugbọn Saulu kò sọ̀rọ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 11

Saulu Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni

1 Nahaṣi, ọba Amoni, kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Jabeṣi Gileadi. Àwọn ará Jabeṣi bá sọ fún Nahaṣi pé, “Jẹ́ kí á jọ dá majẹmu, a óo sì máa sìn ọ́.”

2 Nahaṣi dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo fi lè ba yín dá majẹmu ni pé, kí n yọ ojú ọ̀tún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, kí ó lè jẹ́ ìtìjú fún gbogbo Israẹli.”

3 Àwọn àgbààgbà Jabeṣi dáhùn pé, “Fún wa ní ọjọ́ meje, kí á lè ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Bí kò bá sí ẹni tí yóo gbà wá, a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ.”

4 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà dé Gibea, níbi tí Saulu ń gbé, wọ́n ròyìn fún àwọn ará ìlú náà, gbogbo wọn sì pohùnréré ẹkún.

5 Ní àkókò yìí gan-an ni Saulu ń ti oko rẹ̀ bọ̀, pẹlu àwọn akọ mààlúù rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ tí gbogbo eniyan fi ń sọkún?” Wọ́n bá sọ ohun tí àwọn ará Jabeṣi sọ fún un.

6 Nigba tí Saulu gbọ́ èyí, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Saulu inú sì bí i gidigidi.

7 Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.”

Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan.

8 Saulu bá kó wọn jọ ní Beseki. Ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ni àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n wá láti Juda sì jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun (30,000).

9 Wọ́n sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wá láti Jabeṣi-Gileadi pé, “Ẹ sọ fún àwọn eniyan yín pé, ní ọ̀sán ọ̀la, a óo gbà wọ́n kalẹ̀.” Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi gbọ́ ìròyìn náà, inú wọn dùn gidigidi.

10 Wọ́n wí fún Nahaṣi pé, “Lọ́la ni a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ, ohunkohun tí ó bá sì wù ọ́ ni o lè fi wá ṣe.”

11 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Saulu pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ọ̀nà mẹta, wọ́n kọlu ibùdó àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n títí di ọ̀sán ọjọ́ náà. Àwọn tí kò kú lára wọn fọ́nká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí eniyan meji tí wọ́n dúró papọ̀.

12 Àwọn ọmọ Israẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Samuẹli pé, “Níbo ni àwọn tí wọ́n sọ pé kò yẹ kí Saulu jẹ ọba wa wà? Ẹ kó wọn jáde, kí á pa wọ́n.”

13 Ṣugbọn Saulu dá wọn lóhùn pé, “A kò ní pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí pé, òní ni ọjọ́ tí OLUWA gba Israẹli là.”

14 Samuẹli wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Giligali, kí á lè túbọ̀ fi ìdí ìjọba Saulu múlẹ̀.”

15 Gbogbo wọn bá pada lọ sí Giligali, wọ́n sì fi Saulu jọba níwájú OLUWA. Wọ́n rú ẹbọ alaafia, Saulu ati àwọn ọmọ Israẹli sì jọ ṣe àjọyọ̀ ńlá.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 12

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli

1 Lẹ́yìn náà, Samuẹli wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Mo ti ṣe ohun tí ẹ ní kí n ṣe. Mo ti fi ẹnìkan jọba lórí yín.

2 Nisinsinyii, ọba ni yóo máa ṣe olórí yín. Ní tèmi, mo ti dàgbà, ogbó sì ti dé sí mi. Àwọn ọmọ mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ yín. Láti ìgbà èwe mi ni mo ti jẹ́ olórí fun yín títí di àkókò yìí.

3 Èmi nìyí níwájú yín yìí, bí mo bá ti ṣe nǹkankan tí kò tọ́, ẹ fi ẹ̀sùn kàn mí níwájú OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀. Ǹjẹ́ mo gba mààlúù ẹnikẹ́ni ninu yín rí? Àbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Tabi ta ni mo ni lára rí? Ǹjẹ́ mo gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí? Bí mo bá ti ṣe èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan wọnyi rí, mo ṣetán láti san ohun tí mo gbà pada.”

4 Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Rárá o, o kò rẹ́ wa jẹ rí, o kò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí.”

5 Samuẹli dáhùn pé, “OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ gbà pé ọwọ́ mi mọ́ patapata.”

Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA ni ẹlẹri wa.”

6 Samuẹli tún sọ fún wọn pé, “OLUWA tí ó yan Mose ati Aaroni, tí ó kó àwọn baba ńlá yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti ni ẹlẹ́rìí.

7 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, n óo sì fi ẹ̀sùn kàn yín níwájú OLUWA n óo ran yín létí gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe láti gba àwọn baba ńlá yín kalẹ̀.

8 Nígbà tí Jakọbu ati ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ará Ijipti ń ni wọ́n lára, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA sì rán Mose ati Aaroni, wọ́n kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Ó sì mú kí wọ́n máa gbé orí ilẹ̀ yìí.

9 Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn.

10 Lẹ́yìn náà, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní, ‘A ti ṣẹ̀, nítorí pé a ti kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń sin oriṣa Baali, ati ti Aṣitarotu. Nisinsinyii, gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, a óo sì máa sìn ọ́.’

11 OLUWA bá rán Jerubaali ati Baraki, ati Jẹfuta ati èmi, Samuẹli, láti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín káàkiri, ó sì jẹ́ kí ẹ wà ní alaafia.

12 Ṣugbọn nígbà tí ẹ rí i pé Nahaṣi, ọba Amoni fẹ́ gbé ogun tì yín, ẹ kọ OLUWA lọ́ba, ẹ wí fún mi pé, ẹ fẹ́ ọba tí yóo jẹ́ alákòóso yín.

13 “Ọba tí ẹ bèèrè fún náà nìyí, ẹ̀yin ni ẹ bèèrè rẹ̀, OLUWA sì ti fun yín nisinsinyii.

14 Bí ẹ bá bẹ̀rù OLUWA, tí ẹ̀ ń sìn ín, tí ẹ̀ ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, tí ẹ̀yin ati ọba tí ń ṣe àkóso yín bá ń tẹ̀lé àwọn ìlànà OLUWA Ọlọrun yín, ohun gbogbo ni yóo máa lọ déédé fun yín.

15 Ṣugbọn bí ẹ kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, yóo dojú ìjà kọ ẹ̀yin ati ọba yín.

16 Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí OLUWA yóo ṣe.

17 Àkókò ìkórè ọkà nìyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? N óo gbadura, OLUWA yóo sì jẹ́ kí ààrá sán, kí òjò sì rọ̀. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ óo mọ̀ pé bíbèèrè tí ẹ bèèrè fún ọba, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ẹ dá sí OLUWA.”

18 Samuẹli bá gbadura, ní ọjọ́ náà gan-an, OLUWA sán ààrá, ó sì rọ òjò. Ẹ̀rù OLUWA ati ti Samuẹli sì ba gbogbo àwọn eniyan náà.

19 Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún wa, kí á má baà kú. Nítorí pé a mọ̀ nisinsinyii pé, yàtọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá tẹ́lẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tún ni bíbèèrè tí a bèèrè fún ọba tún jẹ́ lọ́rùn wa.”

20 Samuẹli dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹ ṣe burú, sibẹsibẹ ẹ má ṣe yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹ máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín.

21 Ẹ má tẹ̀lé àwọn oriṣa; ohun asán tí kò lérè, tí kò sì lè gbani ni wọ́n.

22 OLUWA kò ní ta eniyan rẹ̀ nù, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé ó wù ú láti ṣe yín ní eniyan rẹ̀.

23 Ní tèmi, n kò ní ṣẹ̀, nípa aigbadura sí OLUWA fun yín. N óo sì máa kọ yín ní ohun tí ó dára láti máa ṣe ati ọ̀nà tí ó tọ́ fun yín láti máa rìn.

24 Ẹ máa bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín. Ẹ ranti àwọn nǹkan ńláńlá tí ó ti ṣe fun yín.

25 Ṣugbọn bí ẹ bá tún ṣe nǹkan burúkú, yóo pa ẹ̀yin ati ọba yín run.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 13

Àwọn Ọmọ Israẹli Gbógun ti Àwọn Ará Filistia

1 Saulu jẹ́ bíi ọmọ ọgbọ̀n ọdún…nígbà tí ó jọba lórí Israẹli. Ó sì wà lórí oyè fún bíi ogoji ọdún.

2 Saulu yan ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Ó fi ẹgbaa (2,000) ninu wọn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Mikimaṣi, ní agbègbè olókè ti Bẹtẹli. Ẹgbẹrun (1,000) yòókù wà lọ́dọ̀ Jonatani, ọmọ rẹ̀, ní Gibea, ní agbègbè ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó bá dá àwọn yòókù pada sí ilé wọn.

3 Jonatani ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini tí wọ́n wà ní Geba; gbogbo àwọn ará Filistia sì gbọ́ nípa rẹ̀. Saulu bá fọn fèrè ogun jákèjádò ilẹ̀ náà, wí pé “Ẹ jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́ èyí.”

4 Gbogbo Israẹli gbọ́ pé Saulu ti ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini ati pé àwọn ọmọ Israẹli ti di ohun ìríra lójú àwọn ará Filistia. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá jáde láti wá darapọ̀ mọ́ Saulu ní Giligali.

5 Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ.

6 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé ilẹ̀ ti ká àwọn mọ́, nítorí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini dùn wọ́n, wọ́n bá ń farapamọ́ káàkiri; àwọn kan sá sinu ihò ilẹ̀, àwọn mìíràn sì sá sinu àpáta, inú ibojì ati inú kànga.

7 Àwọn mìíràn ninu wọn ré odò Jọdani kọjá sí agbègbè Gadi ati Gileadi.

Gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu Saulu sì wà ninu ìbẹ̀rù ńlá.

8 Ọjọ́ meje ni ó fi dúró de Samuẹli, bí Samuẹli ti wí. Ṣugbọn Samuẹli kò wá sí Giligali. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn Saulu.

9 Nítorí náà, Saulu ní kí wọ́n gbé ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia wá fún òun, ó sì rú ẹbọ.

10 Bí ó ti parí rírú ẹbọ sísun náà tán ni Samuẹli dé. Saulu lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀.

11 Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?”

Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi.

12 Mo wá rò ó wí pé, àwọn ará Filistia tí ń bọ̀ wá gbógun tì mí ní Giligali níhìn-ín, n kò sì tíì wá ojurere OLUWA. Ni mo bá rú ẹbọ sísun.”

13 Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae.

14 Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”

15 Samuẹli kúrò ní Giligali, ó lọ sí Gibea ní Bẹnjamini. Saulu ka àwọn eniyan tí wọ́n kù lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600).

16 Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, pẹlu àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pàgọ́ sí Geba ní agbègbè Bẹnjamini. Àgọ́ ti àwọn ará Filistia wà ní Mikimaṣi.

17 Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà, mẹta ninu ọmọ ogun Filistini jáde láti inú àgọ́ wọn, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Ofira ní agbègbè Ṣuali,

18 àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀.

19 Kò sí ẹyọ alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí pé àwọn ará Filistia ti pinnu pé, àwọn kò ní gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti rọ idà ati ọ̀kọ̀ fúnra wọn.

20 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ pọ́n ohun ìtúlẹ̀ wọn ati ọkọ́ ati àáké ati dòjé, wọ́n níláti lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia.

21 Owó díẹ̀ ni àwọn Filistia máa ń gbà, láti bá wọn pọ́n ohun ìtúlẹ̀ ati ọkọ́, wọ́n ń gba ìdámẹ́ta owó ṣekeli láti pọ́n àáké ati láti tún irin tí ó wà lára ohun ìtúlẹ̀ ṣe.

22 Nítorí náà, ní ọjọ́ ogun yìí kò sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ó ní idà tabi ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, àfi Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀.

23 Ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan sì lọ sí ọ̀nà Mikimaṣi.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 14

Jonatani Hùwà Akikanju

1 Ní ọjọ́ kan, Jonatani, ọmọ Saulu, wí fún ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí òdìkejì ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.” Ṣugbọn Jonatani kò sọ fún Saulu, baba rẹ̀.

2 Ní àkókò yìí, baba rẹ̀ pàgọ́ ogun rẹ̀ sí abẹ́ igi pomegiranate kan ní Migironi, nítòsí Gibea. Àwọn ọmọ ogun bíi ẹgbẹta (600) wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

3 Ẹni tí ó jẹ́ alufaa tí ó ń wọ ẹ̀wù efodu nígbà náà ni Ahija, ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, tíí ṣe alufaa OLUWA ní Ṣilo. Àwọn ọmọ ogun kò mọ̀ pé Jonatani ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn.

4 Àwọn òkúta ńláńlá meji kan wà ní ọ̀nà kan, tí ó wà ní àfonífojì Mikimaṣi. Pàlàpálá òkúta wọnyi ni Jonatani gbà lọ sí ibùdó ogun àwọn Filistini. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òkúta náà wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ọ̀nà náà. Orúkọ ekinni ń jẹ́ Bosesi, ekeji sì ń jẹ́ Sene.

5 Èyí ekinni wà ní apá àríwá ọ̀nà náà, ó dojú kọ Mikimaṣi. Ekeji sì wà ní apá gúsù, ó dojú kọ Geba.

6 Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.”

7 Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Ohunkohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́ ni kí o ṣe. Mo wà lẹ́yìn rẹ, bí ọkàn rẹ ti rí ni tèmi náà rí.”

8 Jonatani bá dáhùn pé, “Ó dára, a óo rékọjá sọ́hùn-ún, a óo sì fi ara wa han àwọn ará Filistia.

9 Bí wọ́n bá ní kí á dúró kí àwọn tọ̀ wá wá, a óo dúró níbi tí a bá wà, a kò ní lọ sọ́dọ̀ wọn.

10 Ṣugbọn bí wọ́n bá ní kí á máa bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn, a óo tọ̀ wọ́n lọ. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún wa, pé OLUWA ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”

11 Nítorí náà, wọ́n fi ara wọn han àwọn ará Filistia. Bí àwọn ara Filistia ti rí wọn, wọ́n ní, “Ẹ wò ó! Àwọn Heberu ń jáde bọ̀ wá láti inú ihò òkúta tí wọ́n farapamọ́ sí.”

12 Wọ́n bá nahùn pe Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀; wọ́n ní, “Ẹ máa gòkè tọ̀ wá bọ̀ níhìn-ín, a óo fi nǹkankan hàn yín.”

Jonatani bá wí fún ọdọmọkunrin náà pé, “Tẹ̀lé mi, OLUWA ti fún Israẹli ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”

13 Jonatani bá rápálá gun òkè náà, ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Jonatani bá bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará Filistia jà, wọ́n sì ń ṣubú níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣubú ni ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ń pa wọ́n.

14 Ní àkókò tí wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, Jonatani ati ọdọmọkunrin yìí pa nǹkan bí ogún eniyan. Ààrin ibi tí wọ́n ti ja ìjà yìí kò ju nǹkan bí ìdajì sarè oko kan lọ.

15 Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn ará Filistia tí wọ́n wà ní ibùdó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, ati gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ ogun Filistini ati àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n ń digun-jalè wárìrì, ilẹ̀ mì tìtì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo wọn.

Àwọn Ọmọ Ogun Israẹli Ṣẹgun Àwọn ti Filistini

16 Àwọn ọmọ ogun Saulu tí wọn ń ṣọ́nà ní Gibea, ní agbègbè Bẹnjamini, rí i tí àwọn ọmọ ogun Filistini ń sá káàkiri.

17 Saulu bá pàṣẹ fún àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ka gbogbo àwọn ọmọ ogun, láti mọ àwọn tí wọ́n jáde kúrò láàrin wọn. Wọ́n bá ka àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì rí i pé Jonatani ati ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ kò sí láàrin wọn.

18 Saulu wí fún Ahija, alufaa pé, “Gbé àpótí Ọlọrun wá níhìn-ín.” Nítorí àpótí Ọlọrun ń bá àwọn ọmọ ogun Israẹli lọ ní àkókò náà.

19 Bí Saulu ti ń bá alufaa náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìdàrúdàpọ̀ tí ó wà ninu àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, Saulu wí fún un pé kí ó dáwọ́ dúró.

20 Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sójú ogun náà. Wọ́n bá àwọn ọmọ ogun ninu ìdàrúdàpọ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ara wọn.

21 Àwọn Heberu tí wọ́n ti wà lẹ́yìn àwọn ará Filistia tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì bá wọn lọ sí ibùdó ogun wọn, yipada kúrò lẹ́yìn wọn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n wà pẹlu Saulu ati Jonatani.

22 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti farapamọ́ káàkiri agbègbè olókè Efuraimu gbọ́ pé àwọn ará Filistia ti bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ; wọ́n yára dara pọ̀ mọ́ Saulu, wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ọmọ ogun Filistini.

23 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì ja ogun náà kọjá Betafeni.

Àwọn Ohun tí Ó Ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn Ogun

24 Ara àwọn ọmọ ogun Israẹli ti hù ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ sì mú wọn, nítorí pé Saulu ti fi ìbúra pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan títí di àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, títí tí òun yóo fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá òun, olúwarẹ̀ gbé! Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wọn tí ó fi ẹnu kan nǹkankan.

25 Gbogbo wọn dé inú igbó, wọ́n rí oyin nílẹ̀.

26 Nígbà tí wọ́n wọ inú igbó náà, wọ́n rí i tí oyin ń kán sílẹ̀, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè fi ọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra Saulu.

27 Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ ń fi ìbúra pàṣẹ fún àwọn eniyan náà. Nítorí náà, ó na ọ̀pá tí ó mú lọ́wọ́, ó tì í bọ inú afárá oyin kan, ó sì lá a. Lẹsẹkẹsẹ ojú rẹ̀ wálẹ̀.

28 Ọ̀kan ninu àwọn eniyan náà wí fún un pé, “Ebi ń pa gbogbo wa kú lọ, ṣugbọn baba rẹ ti búra pé, ‘Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan lónìí.’ ”

29 Jonatani dáhùn pé, “Ohun tí baba mi ṣe sí àwọn eniyan wọnyi kò dára, wò ó bí ojú mi ti wálẹ̀ nígbà tí mo lá oyin díẹ̀.

30 Báwo ni ìbá ti dára tó lónìí, bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan jẹ lára ìkógun àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí. Àwọn ará Filistia tí wọn ìbá pa ìbá ti pọ̀ ju èyí lọ.”

31 Wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini ní ọjọ́ náà, láti Mikimaṣi títí dé Aijaloni; ó sì rẹ àwọn eniyan náà gidigidi.

32 Nítorí náà, wọ́n sáré sí ìkógun, wọ́n pa àwọn aguntan ati mààlúù ati ọmọ mààlúù, wọ́n sì ń jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.

33 Wọ́n bá lọ sọ fún Saulu pé, “Àwọn eniyan ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”

Saulu bá wí pé, “Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni ẹ hù yìí. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.”

34 Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

35 Saulu bá tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA. Pẹpẹ yìí ni pẹpẹ kinni tí Saulu tẹ́ fún OLUWA.

36 Saulu wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kọlu àwọn ará Filistia ní òru kí á kó ẹrù wọn, kí á sì pa gbogbo wọn títí ilẹ̀ yóo fi mọ́ láì dá ẹnikẹ́ni sí.”

Àwọn eniyan náà dá a lóhùn pé, “Ṣe èyí tí ó bá dára lójú rẹ.”

Ṣugbọn alufaa wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun ná.”

37 Saulu bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé, “Ṣé kí n lọ kọlu àwọn ará Filistia? Ṣé o óo fún Israẹli ní ìṣẹ́gun?” Ṣugbọn Ọlọrun kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

38 Saulu bá pe gbogbo olórí àwọn eniyan náà jọ, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á wádìí ohun tí ó fa ẹ̀ṣẹ̀ òní.

39 Mo fi OLUWA alààyè tí ó fún Israẹli ní ìṣẹ́gun búra pé, pípa ni a óo pa ẹni tí ó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, kì báà jẹ́ Jonatani ọmọ mi.” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá a lóhùn ninu wọn.

40 Saulu bá wí fún gbogbo Israẹli pé, “Gbogbo yín, ẹ dúró ní apá kan, èmi ati Jonatani, ọmọ mi, yóo dúró ní apá keji.”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ.”

41 Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu,

42 Saulu ní, “Ẹ ṣẹ́ gègé láàrin èmi ati Jonatani, ọmọ mi.” Gègé bá mú Jonatani.

43 Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé kí ó sọ ohun tí ó ṣe fún òun.

Jonatani dá a lóhùn pé, “Mo ti ọ̀pá tí mo mú lọ́wọ́ bọ inú oyin, mo sì lá a. Èmi nìyí, mo ṣetán láti kú.”

44 Saulu dá a lóhùn pé, “Láì sí àní àní, pípa ni wọn yóo pa ọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí Ọlọrun lù mí pa.”

45 Nígbà náà ni àwọn eniyan wí fún Saulu pé, “Ṣé a óo pa Jonatani ni, ẹni tí ó ti ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli? Kí á má rí i. Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, ẹyọ irun orí rẹ̀ kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Agbára Ọlọrun ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan náà ṣe gba Jonatani kalẹ̀, tí wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n pa á.

46 Lẹ́yìn èyí, Saulu kò lépa àwọn ará Filistia mọ́. Àwọn Filistini sì pada lọ sí agbègbè wọn.

Ìjọba ati Ìdílé Saulu

47 Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa.

48 Ó jagun gẹ́gẹ́ bí akikanju, ó ṣẹgun àwọn ará Amaleki. Ó sì gba Israẹli kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ogun kó wọn.

49 Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali.

50 Ahinoamu ọmọ Ahimaasi ni aya Saulu. Abineri ọmọ Neri, arakunrin baba Saulu, sì ni balogun rẹ̀.

51 Kiṣi ni baba Saulu. Neri, baba Abineri jẹ́ ọmọ Abieli.

52 Gbogbo ọjọ́ ayé Saulu ni ó fi bá àwọn ará Filistia jagun kíkankíkan. Nígbà gbogbo tí Saulu bá sì ti rí ọkunrin tí ó jẹ́ alágbára tabi akikanju, a máa fi kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 15

Àwọn Ọmọ Israẹli Bá Àwọn Ará Amaleki Jagun

1 Samuẹli sọ fún Saulu pé, “OLUWA rán mi láti fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, eniyan rẹ̀. Nisinsinyii gbọ́ ohun tí OLUWA wí.

2 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo jẹ àwọn ará Amaleki níyà nítorí pé wọ́n gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti.

3 Lọ gbógun ti àwọn ará Amaleki, kí o sì run gbogbo nǹkan tí wọ́n ní patapata. O kò gbọdọ̀ dá nǹkankan sí, pa gbogbo wọn, atọkunrin, atobinrin; àtàwọn ọmọ kéékèèké; àtàwọn ọmọ ọmú; ati mààlúù, ataguntan, ati ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, gbogbo wọn pátá ni kí o pa.’ ”

4 Saulu bá kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó ka iye wọn ní Telaimu. Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000).

5 Òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá lọ sí ìlú Amaleki, wọ́n ba ní ibùba, ní àfonífojì.

6 Saulu ranṣẹ ìkìlọ̀ kan sí àwọn ará Keni pé, “Ẹ jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki, kí n má baà pa yín run, nítorí pé ẹ̀yin ṣàánú àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.” Àwọn ará Keni bá jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki.

7 Saulu ṣẹgun àwọn ará Amaleki láti Hafila títí dé Ṣuri ní ìhà ìlà oòrùn Ijipti.

8 Ó mú Agagi, ọba àwọn ará Amaleki láàyè, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.

9 Ṣugbọn Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ dá Agagi sí, wọn kò sì pa àwọn tí wọ́n dára jùlọ ninu àwọn aguntan, mààlúù, ati ọ̀dọ́ mààlúù ati ọ̀dọ́ aguntan wọn, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó dára. Wọn kò pa wọ́n run, ṣugbọn wọ́n pa àwọn ohun tí kò níláárí run.

Ọlọrun Kọ Saulu lọ́ba

10 OLUWA sọ fún Samuẹli pé,

11 “Ó dùn mí pé mo fi Saulu jọba. Ó ti yipada kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa òfin mi mọ́.” Inú bí Samuẹli, ó sì gbadura sí OLUWA ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

12 Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ó jáde, ó lọ rí Saulu. Ó gbọ́ pé Saulu ti lọ sí Kamẹli, níbi tí ó ti gbé ọ̀wọ̀n kan kalẹ̀, ní ìrántí ara rẹ̀, ati pé ó ti gba ibẹ̀ lọ sí Giligali.

13 Samuẹli bá lọ sọ́dọ̀ Saulu. Saulu sọ fún un pé, “Kí OLUWA kí ó bukun ọ, Samuẹli, mo ti pa òfin OLUWA mọ́.”

14 Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ni igbe àwọn aguntan ati ti àwọn mààlúù tí mò ń gbọ́ yìí?”

15 Saulu dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan mi ni wọ́n kó wọn lọ́dọ̀ àwọn ará Amaleki. Wọ́n ṣa àwọn aguntan ati àwọn mààlúù tí wọ́n dára jùlọ pamọ́ láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ. A sì ti pa gbogbo àwọn yòókù run patapata.”

16 Samuẹli bá sọ fún un pé, “Dákẹ́! Jẹ́ kí n sọ ohun tí OLUWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”

Saulu dáhùn pé, “Mò ń gbọ́.”

17 Samuẹli ní, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò jámọ́ nǹkankan lójú ara rẹ, sibẹsibẹ ìwọ ni olórí gbogbo ẹ̀yà Israẹli. Ìwọ ni OLUWA fi òróró yàn ní ọba wọn.

18 Ó sì rán ọ jáde pẹlu àṣẹ pé kí o pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ará Amaleki run. Ó ní kí o gbógun tì wọ́n títí o óo fi pa wọ́n run patapata.

19 Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ OLUWA mọ? Kí ló dé tí o fi kó ìkógun, tí o sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA?”

20 Saulu dá a lóhùn pé, “Mo ti pa òfin OLUWA mọ́, mo jáde lọ bí o ti wí fún mi pé kí n jáde lọ, mo mú Agagi ọba pada bọ̀, mo sì pa gbogbo àwọn ará Amaleki run.

21 Ṣugbọn àwọn eniyan mi ni wọ́n kó ìkógun aguntan ati àwọn mààlúù tí ó dára jùlọ lára àwọn ohun tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti fi wọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ ní Giligali.”

22 Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ.

23 Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.”

24 Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.

25 Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì mí, kí o sì bá mi pada, kí n lọ sin OLUWA níbẹ̀.”

26 Samuẹli dá a lóhùn pé, “N kò ní bá ọ pada lọ. O ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, OLUWA sì ti kọ ìwọ náà ní ọba Israẹli.”

27 Samuẹli bá yipada, ó fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn Saulu fa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, ó sì ya.

28 Samuẹli bá wí fún un pé, “OLUWA ti fa ìjọba Israẹli ya mọ́ ọ lọ́wọ́ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ tí ó sàn jù ọ́ lọ.

29 Ọlọrun Ológo Israẹli kò jẹ́ parọ́, kò sì jẹ́ yí ọkàn rẹ̀ pada; nítorí pé kì í ṣe eniyan, tí ó lè yí ọkàn pada.”

30 Saulu dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀, ṣugbọn bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan mi ati gbogbo Israẹli. Bá mi pada lọ, kí n lọ sin OLUWA Ọlọrun rẹ.”

31 Samuẹli bá bá a pada, Saulu sì sin OLUWA níbẹ̀.

32 Samuẹli pàṣẹ pé kí wọ́n mú Agagi, ọba Amaleki wá, Agagi bá jáde tọ̀ ọ́ lọ pẹlu ìbàlẹ̀ ọkàn, ó ní, “Dájúdájú oró ikú ti rékọjá lórí mi.”

33 Samuẹli bá sọ fún un pé, “Bí idà rẹ ti sọ ọpọlọpọ ìyá di aláìlọ́mọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyá tìrẹ náà yóo di aláìlọ́mọ láàrin àwọn obinrin.” Samuẹli bá gé Agagi wẹ́lẹwẹ̀lẹ níwájú pẹpẹ ní Giligali.

34 Lẹ́yìn náà, Samuẹli pada lọ sí Rama, Saulu ọba sì pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea ti Saulu.

35 Samuẹli kò tún fi ojú kan Saulu mọ títí tí Samuẹli fi kú, ṣugbọn inú Samuẹli bàjẹ́ nítorí rẹ̀. Ọkàn OLUWA sì bàjẹ́ pé òun fi Saulu jọba Israẹli.