Categories
RUTU

RUTU 1

Elimeleki ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ láti Máa Gbé ní Ilẹ̀ Moabu

1 Ní àkókò tí àwọn adájọ́ ń ṣe olórí ní ilẹ̀ Israẹli, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. Ọkunrin kan wà, ará Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji; wọ́n lọ ń gbé ilẹ̀ Moabu.

2 Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

3 Nígbà tí ó yá, Elimeleki kú, ó bá ku Naomi, opó rẹ̀, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji.

4 Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ Moabu, Iyawo ẹnikinni ń jẹ́ Opa, ti ẹnìkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti jọ ń gbé ilẹ̀ Moabu,

5 Maloni ati Kilioni náà kú, Naomi sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣòfò àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji ati ọkọ rẹ̀.

Naomi ati Rutu Pada sí Bẹtilẹhẹmu

6 Naomi ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji jáde kúrò ní ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń pada lọ sí ilẹ̀ Juda, nítorí ó gbọ́ pé OLUWA ti ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ati pé wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.

7 Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda.

8 Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run.

9 Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

10 Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.”

11 Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó?

12 Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin,

13 ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.”

14 Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀.

15 Naomi bá sọ fún Rutu, ó ní, “Ṣé o rí i pé arabinrin rẹ ti pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ati àwọn oriṣa rẹ̀, ìwọ náà pada, kí ẹ jọ máa lọ.”

16 Ṣugbọn Rutu dáhùn, ó ní, “Má pàrọwà fún mi rárá, pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, tabi pé kí n pada lẹ́yìn rẹ; nítorí pé ibi tí o bá ń lọ, ni èmi náà yóo lọ; ibi tí o bá ń gbé ni èmi náà yóo máa gbé; àwọn eniyan rẹ ni yóo máa jẹ́ eniyan mi, Ọlọrun rẹ ni yóo sì jẹ́ Ọlọrun mi.

17 Ibi tí o bá kú sí, ni èmi náà yóo kú sí; níbẹ̀ ni wọn yóo sì sin mí sí pẹlu. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí, kí OLUWA jẹ́ kí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ bá mi, bí mo bá jẹ́ kí ohunkohun yà mí kúrò lẹ́yìn rẹ, ìbáà tilẹ̀ jẹ́ ikú.”

18 Nígbà tí Naomi rí i pé Rutu ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀ láti bá òun lọ, kò sọ ohunkohun mọ́.

19 Àwọn mejeeji bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí wọ́n fi dé Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n wọ Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì nítorí wọn. Àwọn obinrin bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ṣé Naomi nìyí?”

20 Naomi bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ má pè mí ní Naomi mọ́, Mara ni kí ẹ máa pè mí nítorí pé Olodumare ti jẹ́ kí ayé korò fún mi.

21 Mo jáde lọ ní kíkún, ṣugbọn OLUWA ti mú mi pada ní ọwọ́ òfo, kí ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí OLUWA fúnra rẹ̀ ti dá mi lẹ́bi, tí Olodumare sì ti mú ìpọ́njú bá mi?”

22 Báyìí ni Naomi ati Rutu, ará Moabu, aya ọmọ rẹ̀, ṣe pada dé láti ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali ni wọ́n dé sí Bẹtilẹhẹmu.

Categories
RUTU

RUTU 2

Rutu Ṣiṣẹ́ ninu Oko Boasi

1 Ní àkókò yìí, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà ninu ìdílé Elimeleki, ẹbí kan náà ni ọkunrin yìí ati ọkọ Naomi. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi.

2 Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.”

3 Rutu bá gbéra, ó lọ sí oko ọkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà gbàgbé sílẹ̀. Oko tí ó lọ jẹ́ ti Boasi, ìbátan Elimeleki.

4 Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.”

5 Boasi bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ́ alákòóso àwọn tí ń kórè, ó ní, “Ọmọ ta ni ọmọbinrin yìí?”

6 Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni.

7 Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.”

8 Boasi bá pe Rutu, ó ní, “Gbọ́, ọmọ mi, má lọ sí oko ẹlòmíràn láti ṣa ọkà, má kúrò ní oko yìí, ṣugbọn faramọ́ àwọn ọmọbinrin mi.

9 Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.”

10 Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.”

11 Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí.

12 OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.”

13 Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.”

14 Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.

15 Nígbà tí Rutu dìde, láti tún máa ṣa ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí ó máa ṣa ọkà láàrin àwọn ìtí ọkà tí ẹ dì jọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.

16 Kí ẹ tilẹ̀ fa ọkà yọ fún un ninu ìtí, kí ẹ sì tún fi í sílẹ̀ láti ṣa ọkà, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.”

17 Rutu bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó pa ọkà tí ó ṣà, ohun tí ó rí tó ìwọ̀n efa ọkà baali kan.

18 Ó gbé e, ó sì lọ sílé. Ó fi ọkà tí ó rí han ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ tí ó jẹ kù.

19 Ìyá ọkọ rẹ̀ bi í léèrè, ó ní, “Níbo ni o ti ṣa ọkà lónìí, níbo ni o sì ti ṣiṣẹ́? OLUWA yóo bukun ẹni tí ó ṣàkíyèsí rẹ.”

Rutu bá sọ inú oko ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní, “Inú oko ọkunrin kan tí wọ́n ń pè ní Boasi ni mo ti ṣa ọkà lónìí.”

20 Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni.

21 Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.”

22 Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.”

23 Rutu bá ń bá àwọn ọmọbinrin Boasi lọ láti ṣa ọkà títí wọ́n fi parí ìkórè ọkà Baali, ó sì ń gbé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀.

Categories
RUTU

RUTU 3

Rutu rí Ọkọ Fẹ́

1 Lẹ́yìn náà, Naomi pe Rutu, ó ní, “Ọmọ mi, ó tó àkókò láti wá ọkọ fún ọ, kí ó lè dára fún ọ.

2 Ṣé o ranti pé ìbátan wa ni Boasi, tí o wà pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀? Wò ó, yóo lọ fẹ́ ọkà baali ní ibi ìpakà rẹ̀ lálẹ́ òní.

3 Nítorí náà, lọ wẹ̀, kí o sì fi nǹkan pa ara. Wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ibi ìpakà rẹ̀, ṣugbọn má jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí ó bá jẹ tí ó sì mu tán.

4 Nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, ṣe akiyesi ibi tí ó sùn sí dáradára, lẹ́yìn náà, lọ ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sùn tì í, lẹ́yìn náà, yóo sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”

5 Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.”

6 Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un.

7 Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í.

8 Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun.

9 Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?”

Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.”

10 Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka.

11 Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́.

12 Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ.

13 Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.”

14 Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.”

15 Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé.

16 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?”

Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un.

17 Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.”

18 Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

Categories
RUTU

RUTU 4

Boasi Ṣú Rutu Lópó

1 Boasi bá lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó jókòó níbẹ̀. Bí ìbátan ọkọ Rutu tí ó súnmọ́ ọn, tí Boasi sọ nípa rẹ̀ ti ń kọjá lọ, ó pè é, ó ní, “Ọ̀rẹ́, yà sí ibí, kí o sì jókòó.” Ọkunrin náà bá yà, ó sì jókòó.

2 Boasi pe àwọn mẹ́wàá ninu àwọn àgbààgbà ìlú, ó ní, “Ẹ wá jókòó sí ibí.” Wọ́n bá jókòó.

3 Lẹ́yìn náà, ó pe ìbátan ọkọ Rutu yìí, ó ní, “Naomi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ àwọn ará Moabu pada dé, fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Elimeleki ìbátan wa.

4 Nítorí náà, mo rò ó ninu ara mi pé, kí n kọ́ sọ fún ọ pé kí o rà á, níwájú àwọn tí wọ́n jókòó níhìn-ín, ati níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan wa; bí o bá gbà láti rà á pada, rà á. Ṣugbọn bí o kò bá fẹ́ rà á pada, sọ fún mi, kí n lè mọ̀, nítorí pé kò sí ẹni tí ó tún lè rà á pada, àfi ìwọ, èmi ni mo sì tẹ̀lé ọ.” Ọkunrin yìí dáhùn pé òun óo ra ilẹ̀ náà pada.

5 Boasi bá fi kún un pé, “Ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ yìí ní ọwọ́ Naomi, bí o bá ti ń ra ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni óo ra Rutu, ará ilẹ̀ Moabu, opó ọmọ Naomi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ogún rẹ̀.”

6 Ìbátan Elimeleki yìí dáhùn, ó ní, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, n kò ní lè ra ilẹ̀ náà pada, nítorí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ tèmi lè jogún mi bí ó ti yẹ. Bí o bá fẹ́, o lè fi ọwọ́ mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ mi yìí, nítorí pé n kò lè rà á pada.”

7 Ní àkókò yìí, ohun tí ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètò ìràpada ati pàṣípààrọ̀ ohun ìní ni pé ẹni tí yóo bá ta nǹkan yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo sì kó o fún ẹni tí yóo rà á. Bàtà yìí ni ó dàbí ẹ̀rí ati èdìdì láàrin ẹni tí ń ta nǹkan ati ẹni tí ń rà á, ní ilẹ̀ Israẹli.

8 Nítorí náà, nígbà tí ìbátan náà wí fún Boasi pé, “Rà á bí o bá fẹ́.” Ó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ fún Boasi,

9 Boasi bá sì sọ fún àwọn àgbààgbà ati gbogbo àwọn eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí pé mo ti ra gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Elimeleki ati ti Kilioni ati ti Maloni lọ́wọ́ Naomi.

10 Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.”

11 Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu.

12 Àwọn ọmọ tí OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí fún ọ yóo kún ilé rẹ fọ́fọ́, bí ọmọ ti kún ilé Peresi, tí Tamari bí fún Juda.”

Boasi ati Ìrandíran Rẹ̀

13 Boasi bá ṣú Rutu lópó, Rutu sì di aya rẹ̀. Nígbà tí Boasi bá a lòpọ̀, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan.

14 Àwọn obinrin bá sọ fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí kò ṣe ọ́ ní aláìní ìbátan, kí OLUWA ṣe ọmọ náà ní olókìkí ní Israẹli.

15 Ọmọ yìí yóo mú kí adùn ayé rẹ sọjí, yóo sì jẹ́ olùtọ́jú fún ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ, nítorí iyawo ọmọ rẹ tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ju ọmọkunrin meje lọ ni ó bímọ fún ọ.”

16 Naomi bá gba ọmọ náà, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì di olùtọ́jú rẹ̀.

17 Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi.

18 Àwọn atọmọdọmọ Peresi nìwọ̀nyí: Peresi ni baba Hesironi;

19 Hesironi bí Ramu, Ramu bí Aminadabu;

20 Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni;

21 Salimoni bí Boasi, Boasi bí Obedi;

22 Obedi bí Jese, Jese sì bí Dafidi.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Kókó ohun tí ó wà ninu

Ìwé Kinni ti Samuẹli

ni àkọsílẹ̀ àyípadà ètò ìjọba Israẹli, láti ìjọba Àwọn Onídàájọ́ sí ìjọba tí àwọn ọba gidi jẹ́ olórí ati aláṣẹ ìlú. Àwọn eniyan mẹta pataki ni àyípadà yìí kàn gbọ̀ngbọ̀n. Àyípadà ìjọba yìí ṣẹlẹ̀ ní àkókò Samuẹli, òun ni ó jẹ oyè onídàájọ́ kẹ́yìn ní Israẹli. Ẹnìkejì ni Saulu; òun ni ọba tí ó kọ́kọ́ jẹ ní ilẹ̀ Israẹli. Dafidi ni ẹni kẹta. Ó rí ọpọlọpọ ìrírí nípa àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ lákòókò Samuẹli ati Saulu, kí ìjọba rẹ̀ tó fi ìdí múlẹ̀.

Ní ṣókí, ohun tí ìwé yìí ń sọ, gẹ́gẹ́ bíi ti inú àwọn ìwé ìtàn Majẹmu Laelae yòókù ni pé, títẹ̀lé àṣẹ Ọlọrun a máa kó ire bá eniyan; ṣugbọn ìjìyà ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ ati lílòdì sí àṣẹ Ọlọrun. Èyí hàn ketekete ninu iṣẹ́ tí OLUWA rán sí wolii Eli ní orí 2 ẹsẹ 30, pé, “N óo buyì fún ẹni tí ó bá buyì fún mi, n óo sì kọ ẹni tí ó bá kọ̀ mí sílẹ̀.”

Ìwé yìí ṣe àkọsílẹ̀ ire ati ibi tí ó wà ninu yíyan ọba fún àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA ni Ọba lórí wọn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nígbà tí wọn bèèrè fún ọba láàrin ara wọn, OLUWA yàn án fún wọn. Ohun tí ó ṣe pataki jù ni pé, ati ọba tí wọ́n yàn ati àwọn ọmọ Israẹli yòókù, Ọlọrun ni aláṣẹ ati onídàájọ́ lórí gbogbo wọn (2:7-10). Ní abẹ́ òfin Ọlọrun, gbogbo eniyan pátá, ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ọ̀kan náà ni wọ́n, olukuluku ni ó sì ní ẹ̀tọ́ tirẹ̀, láìsí ìrẹ́jẹ.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Samuẹli gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ní Israẹli 1:1–7:17

Saulu jọba 8:1–10:27

Àwọn ọdún tí Saulu kọ́kọ́ lò lórí oyè 11:1–15:35

Dafidi ati Saulu 16:1–30:31

Ikú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin 31:1-13

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 1

Elikana ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ìlú Ṣilo

1 Ọkunrin kan wà ninu ẹ̀yà Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikana, ará Ramataimu-sofimu, ní agbègbè olókè Efuraimu. Orúkọ baba rẹ̀ ni Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, láti ìdílé Sufu, ará Efuraimu.

2 Iyawo meji ni Elikana yìí ní. Ọ̀kan ń jẹ́ Hana, ekeji sì ń jẹ́ Penina. Penina bímọ, ṣugbọn Hana kò bí.

3 Ní ọdọọdún ni Elikana máa ń ti Ramataimu-sofimu lọ sí Ṣilo láti lọ sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati láti rúbọ sí i. Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli, ni alufaa OLUWA níbẹ̀.

4 Ní ọjọ́ tí Elikana bá rú ẹbọ rẹ̀, a máa fún Penina ní ìdá kan ninu nǹkan tí ó bá fi rúbọ, a sì máa fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin ní ìdá kọ̀ọ̀kan.

5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ràn Hana, sibẹ ìdá kan ní í máa ń fún un, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí.

6 Penina, orogún Hana, a máa fín in níràn gidigidi, kí ó baà lè mú un bínú, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí.

7 Ní ọdọọdún tí wọ́n bá ti lọ sí ilé OLUWA ni Penina máa ń mú Hana bínú tóbẹ́ẹ̀ tí Hana fi máa ń sọkún, tí kò sì ní jẹun.

8 Ọkọ rẹ̀ a máa rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, a máa bi í pé, “Kí ní ń pa ọ́ lẹ́kún? Kí ló dé tí o kò jẹun? Kí ní ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ṣé n kò wá ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ ni?”

Hana ati Eli

9 Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.

10 Inú Hana bàjẹ́ gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura sí OLUWA, ó sì ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

11 Hana bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, bí o bá ṣíjú wo ìyà tí èmi iranṣẹ rẹ ń jẹ, tí o kò gbàgbé mi, tí o fún mi ní ọmọkunrin kan, n óo ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún ìwọ OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kàn án lórí.”

12 Bí Hana ti ń gbadura sí OLUWA, Eli ń wo ẹnu rẹ̀.

13 Hana ń gbadura ninu ọkàn rẹ̀, kìkì ètè rẹ̀ nìkan ní ń mì, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Nítorí náà, Eli rò pé ó ti mu ọtí yó ni.

14 Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “O óo ti mu ọtí waini pẹ́ tó? Sinmi ọtí mímu.”

15 Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA.

16 Má rò pé ọ̀kan ninu àwọn oníranù obinrin ni mí. Ninu ìbànújẹ́ ńlá ati àníyàn ni mò ń gbadura yìí.”

17 Eli bá dá a lóhùn, ó ní, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun Israẹli yóo fún ọ ní ohun tí ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.”

18 Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́.

Ìbí Samuẹli ati Ìyàsímímọ́ Rẹ̀

19 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.

20 Hana lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọmọ náà ní Samuẹli, ó ní, “Títọrọ ni mo tọrọ rẹ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”

21 Nígbà tí ó yá, àkókò tó fún Elikana ati ìdílé rẹ̀ láti lọ sí Ṣilo, láti lọ rú ẹbọ ọdọọdún, kí Elikana sì san ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ fún OLUWA.

22 Ṣugbọn Hana kò bá wọn lọ. Ó wí fún ọkọ rẹ̀ pé, “Bí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọ yìí ni n óo mú un lọ sí ilé OLUWA, níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí ọjọ́ ayé rẹ̀.”

23 Elikana dá a lóhùn pé, “Ṣe bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ. Dúró ní ilé, títí tí o óo fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí OLUWA jẹ́ kí o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ.” Hana bá dúró ní ilé, ó ń tọ́jú ọmọ náà.

24 Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà.

25 Lẹ́yìn tí wọ́n ti pa akọ mààlúù náà tán, wọ́n mú Samuẹli tọ Eli lọ.

26 Hana bèèrè lọ́wọ́ Eli pé, “Oluwa mi, ǹjẹ́ o ranti mi mọ́? Èmi ni obinrin tí o rí níjelòó, tí mo dúró níhìn-ín níwájú rẹ, tí mò ń gbadura sí OLUWA.

27 Ọmọ yìí ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ OLUWA, ó sì fún mi ní ohun tí mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

28 Nítorí náà, mo wá ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ yóo jẹ́ ti OLUWA.”

Lẹ́yìn náà, wọ́n sin OLUWAníbẹ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 2

Adura Hana

1 Hana bá gbadura báyìí pé:

“Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA,

Ó sọ mí di alágbára;

mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín,

nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là.

2 “Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA,

kò sí ẹlòmíràn,

àfi òun nìkan ṣoṣo.

Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa.

3 Má sọ̀rọ̀ pẹlu ìgbéraga mọ́,

má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu rẹ jáde,

nítorí Ọlọrun tí ó mọ ohun gbogbo ni OLUWA,

gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ni ó sì máa ń gbéyẹ̀wò.

4 Ọrun àwọn alágbára dá,

ṣugbọn àwọn aláìlágbára di alágbára.

5 Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó rí

ti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ,

ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó.

Àgàn ti di ọlọ́mọ meje,

ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní.

6 OLUWA ni ó lè pa eniyan tán,

kí ó sì tún jí i dìde;

òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú,

tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀.

7 OLUWA ni ó lè sọni di aláìní,

òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀.

Òun ni ó ń gbéni ga,

òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀.

8 OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀;

ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀,

láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba,

kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá.

Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,

òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.

9 “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́,

ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn;

nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun.

10 Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun;

OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá.

OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé,

yóo fún ọba rẹ̀ lágbára,

yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.”

11 Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli.

Àwọn Ọmọ Eli

12 Aláìníláárí ẹ̀dá ni àwọn ọmọ Eli mejeeji. Wọn kò bọ̀wọ̀ fún OLUWA rárá.

13 Ó jẹ́ àṣà àwọn alufaa pé nígbà tí ẹnìkan bá wá rúbọ, iranṣẹ alufaa yóo wá, ti òun ti ọ̀pá irin oníga mẹta tí wọ́n fi ń yọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń se ẹran náà lọ́wọ́ lórí iná,

14 yóo ti ọ̀pá irin náà bọ inú ìkòkò ẹran, gbogbo ẹran tí ó bá yọ jáde á jẹ́ ti alufaa. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá wá rúbọ ní Ṣilo.

15 Ati pé, kí wọ́n tilẹ̀ tó rẹ́ ọ̀rá tí wọ́n máa ń sun kúrò lára ẹran, iranṣẹ alufaa á wá, a sì wí fún ẹni tí ń rú ẹbọ pé kí ó fún òun ninu ẹran tí alufaa yóo sun jẹ, nítorí pé alufaa kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ olúwarẹ̀, àfi ẹran tútù.

16 Bí ẹni tí ń rú ẹbọ náà bá dá a lóhùn pé “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ sun ọ̀rá ẹran náà, lẹ́yìn náà kí o wá mú ohun tí ó bá wù ọ́.” Iranṣẹ alufaa náà á wí pé, “Rárá! Nisinsinyii ni kí o fún mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo mú un tipátipá.”

17 Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ọmọ Eli ń dá yìí burú pupọ lójú OLUWA, nítorí pé wọn kò náání ẹbọ OLUWA.

Samuẹli ní Ṣilo

18 Ní gbogbo àkókò yìí, Samuẹli ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, ó sì jẹ́ ọmọde nígbà náà, a máa wọ ẹ̀wù efodu funfun.

19 Ní ọdọọdún ni ìyá rẹ̀ máa ń dá ẹ̀wù kékeré, a sì mú un lọ́wọ́ lọ fún un, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ lọ, láti lọ rúbọ.

20 Eli a máa súre fún Elikana ati Hana aya rẹ̀ pé, “OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí ọmọ mìíràn fún ọ, dípò èyí tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.”

Lẹ́yìn náà, wọn yóo pada lọ sí ilé wọn.

21 OLUWA bukun Hana: ọmọkunrin mẹta, ati ọmọbinrin meji ni ó tún bí lẹ́yìn Samuẹli. Samuẹli sì ń dàgbà níbi tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA.

Eli ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

22 Eli ti di arúgbó gan-an ní àkókò yìí. Ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli, ati bí wọ́n ti ṣe ń bá àwọn obinrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ lòpọ̀.

23 A máa bi wọ́n léèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe báyìí? Gbogbo ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù sí àwọn eniyan ni mò ń gbọ́.

24 Ẹ̀yin ọmọ mi, ọ̀rọ̀ burúkú ni àwọn eniyan OLUWA ń sọ káàkiri nípa yín.

25 Bí ẹnìkan bá ṣẹ eniyan, Ọlọrun lè parí ìjà láàrin wọn; ṣugbọn bí eniyan bá ṣẹ OLUWA, ta ni yóo bá a bẹ̀bẹ̀?”

Ṣugbọn àwọn ọmọ Eli kò gbọ́ ti baba wọn, nítorí pé OLUWA ti pinnu láti pa wọ́n.

26 Samuẹli ń dàgbà sí i, ó sì ń bá ojurere OLUWA ati ti eniyan pàdé.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìdílé Eli

27 OLUWA rán wolii kan sí Eli, kí ó sọ fún un pé, “Mo fara han ìdílé baba rẹ nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú Farao ọba ní ilẹ̀ Ijipti.

28 Ninu gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní Israẹli, ìdílé baba rẹ nìkan ni mo yàn láti jẹ́ alufaa mi, pé kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ alufaa níbi pẹpẹ, kí ẹ máa sun turari kí ẹ máa wọ ẹ̀wù efodu, kí ẹ sì máa wádìí nǹkan lọ́wọ́ mi. Mo fún wọn ní gbogbo ẹbọ sísun tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí mi.

29 Kí ló dé tí o fi ń ṣe ojúkòkòrò sí ọrẹ ati ẹbọ tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn eniyan mi, tí o sì gbé àwọn ọmọ rẹ ga jù mí lọ; tí wọn ń jẹ àwọn ohun tí ó dára jùlọ lára ohun tí àwọn eniyan mi bá fi rúbọ sí mi ní àjẹyọkùn?

30 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ni mo sọ pé, mo ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé, ìdílé rẹ ati ìdílé baba rẹ ni yóo máa jẹ́ alufaa mi títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, èmi OLUWA náà ni mo sì tún ń sọ pé, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n bá bu ọlá fún mi ni n óo máa bu ọlá fún, àwọn tí wọn kò bá kà mí sí, n kò ní ka àwọn náà sí.

31 Wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí n óo run gbogbo àwọn ọdọmọkunrin ìdílé rẹ ati ti baba rẹ kúrò, débi pé kò ní sí àgbà ọkunrin kan ninu ìdílé rẹ mọ́.

32 Pẹlu ìbànújẹ́ ni o óo máa fi ìlara wo bí OLUWA yóo ṣe bukun Israẹli, kò sì ní sí àgbàlagbà ọkunrin ninu ìdílé rẹ mọ́ lae.

33 Ẹnìkan ninu ìdílé rẹ tí n kò ní mú kúrò ní ibi pẹpẹ mi, yóo sọkún títí tí ojú rẹ̀ yóo fi di bàìbàì, ọkàn rẹ̀ yóo sì kún fún ìbànújẹ́. Gbogbo ọmọ inú ilé rẹ ni wọn yóo fi idà pa ní ọjọ́ àìpé.

34 Ní ọjọ́ kan náà ni àwọn ọmọ rẹ mejeeji, Hofini ati Finehasi, yóo kú. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún ọ pé gbogbo ohun tí mo sọ ni yóo ṣẹ.

35 N óo yan alufaa mìíràn fún ara mi, tí yóo ṣe olóòótọ́ sí mi, tí yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá fẹ́ kí ó ṣe. N óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì máa ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú ẹni àmì òróró mi.

36 Èyíkéyìí tí ó bá wà láàyè ninu arọmọdọmọ rẹ yóo máa tọ alufaa yìí lọ láti tọrọ owó ati oúnjẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀bẹ̀ ni yóo sì máa bẹ̀, pé kí ó fi òun sí ipò alufaa kí òun baà lè máa rí oúnjẹ jẹ.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 3

OLUWA Fara Han Samuẹli

1 Ní gbogbo àkókò tí Samuẹli wà ní ọmọde, tí ó ń ṣiṣẹ́ fún OLUWA lábẹ́ Eli, OLUWA kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìran rírí láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.

2 Ní àkókò yìí, ojú Eli ti di bàìbàì, kò ríran dáradára mọ́. Òun sùn sinu yàrá tirẹ̀,

3 ṣugbọn Samuẹli sùn ninu ilé OLUWA, níbi tí àpótí Ọlọrun wà. Iná fìtílà ibi mímọ́ kò tíì jó tán.

4 OLUWA bá pe Samuẹli, ó ní, “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

5 Ó bá dìde, ó sáré tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”

Ṣugbọn Eli dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, pada lọ sùn.” Samuẹli bá pada lọ sùn.

6 OLUWA tún pe Samuẹli. Samuẹli dìde, ó tún tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli tún dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, ọmọ mi, pada lọ sùn.”

7 Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí.

8 OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”

Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà.

9 Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn.

10 OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!”

Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.”

11 OLUWA bá sọ fún un pé, “Mo múra tán láti ṣe nǹkankan ní Israẹli, ohun tí mo fẹ́ ṣe náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí yóo ya ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ lẹ́nu.

12 Ní ọjọ́ náà, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ pé n óo ṣe sí ìdílé Eli, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

13 Mo ti sọ fún un pé n óo jẹ ìdílé rẹ̀ níyà títí lae, nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú sí mi. Eli mọ̀ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lẹ́kun.

14 Nítorí náà, mo ti búra fún ilé Eli pé, kò sí ẹbọ kan tabi ọrẹ tí ó lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú náà kúrò laelae.”

15 Samuẹli dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó dìde, ó ṣí gbogbo ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ṣugbọn ẹ̀rù ń bà á láti sọ ìran tí ó rí fún Eli.

16 Eli pè é, ó ní, “Samuẹli, ọmọ mi!”

Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.”

17 Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.”

18 Samuẹli bá sọ gbogbo rẹ̀ patapata, kò fi nǹkankan pamọ́ fún un. Eli dáhùn pé, “OLUWA ni, jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ti tọ́ lójú rẹ̀.”

19 Samuẹli sì ń dàgbà, OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ṣẹ.

20 Gbogbo Israẹli láti Dani dé Beeriṣeba, ni wọ́n mọ̀ pé wolii OLUWA ni Samuẹli nítòótọ́.

21 OLUWA tún fi ara hàn ní Ṣilo, nítorí pé níbẹ̀ ni ó ti kọ́ fi ara han Samuẹli, tí ó sì bá a sọ̀rọ̀.

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 4

Wọ́n Gba Àpótí Ẹ̀rí Lọ́wọ́ Àwọn Ọmọ Israẹli

1 Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki.

2 Àwọn ọmọ ogun Filistini ni wọ́n kọ́ kọlu àwọn ọmọ ogun Israẹli, nígbà tí àwọn mejeeji gbógun pàdé ara wọn, tí wọ́n sì jà fitafita; àwọn ọmọ ogun Filistini ṣẹgun Israẹli, wọ́n sì pa nǹkan bíi ẹgbaaji (4,000) ninu wọn.

3 Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”

4 Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà.

5 Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì.

6 Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ híhó tí wọn ń hó, wọ́n ní, “Irú ariwo ńlá wo ni àwọn Heberu ń pa ní ibùdó wọn yìí?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àpótí ẹ̀rí OLUWA ni ó dé sí ibùdó àwọn Heberu,

7 ẹ̀rù ba àwọn ará Filistia. Wọ́n ní, “Oriṣa kan ti dé sí ibùdó wọn! A gbé! Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí.

8 A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀.

9 Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.”

10 Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn.

11 Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli mejeeji.

Ikú Eli

12 Ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ti ojú ogun sáré pada lọ sí Ṣilo, ó sì dé ibẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sórí láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

13 Ọkàn Eli dàrú gidigidi nítorí àpótí ẹ̀rí náà, ó sì jókòó lórí àga rẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń wo òréré. Ọkunrin tí ó ti ojú ogun wá bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn fún àwọn ará ìlú, ẹ̀rù ba olukuluku, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké.

14 Nígbà tí Eli gbọ́ igbe wọn, ó bèèrè pé, “Kí ni wọ́n ń kígbe báyìí fún?” Ọkunrin náà bá yára wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Eli.

15 Eli ti di ẹni ọdún mejidinlọgọrun-un ní àkókò yìí, ojú rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ má ríran mọ́ rárá.

16 Ọkunrin náà wí fún un pé, “Ojú ogun ni mo ti sá wá lónìí.”

Eli bá bi í pé, “Kí ló dé, ọmọ mi?”

17 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn ará Filistia. Wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wa, wọ́n pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ rẹ mejeeji pẹlu. Wọ́n sì gbé àpótí Ọlọrun lọ.”

18 Nígbà tí ọkunrin náà fẹnu kan àpótí Ọlọ́run, Eli ṣubú sẹ́yìn lórí àpótí tí ó jókòó lé ní ẹnu ọ̀nà, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti di arúgbó, ó sì sanra. Ogoji ọdún ni Eli fi ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.

Ikú Opó Finehasi

19 Iyawo Finehasi, ọmọ Eli, wà ninu oyún ní àkókò náà, ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ sì ti súnmọ́ etílé. Nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ, ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú, lẹsẹkẹsẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, tí ó sì bímọ.

20 Bí ó ti ń kú lọ, àwọn obinrin tí wọn ń gbẹ̀bí rẹ̀ wí fún un pé, “Ṣe ọkàn gírí, ọkunrin ni ọmọ tí o bí.” Ṣugbọn kò tilẹ̀ kọ ibi ara sí ohun tí wọ́n sọ, kò sì dá wọn lóhùn.

21 Ó bá sọ ọmọ náà ní Ikabodu, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀.” Nítorí pé wọ́n ti gba àpótí Ọlọrun ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú.

22 Ó ní, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀, nítorí pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ.”

Categories
SAMUẸLI KINNI

SAMUẸLI KINNI 5

Àpótí Ẹ̀rí Bọ́ Sọ́wọ́ Àwọn Ará Filistia

1 Lẹ́yìn tí àwọn ará Filistia gba àpótí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n gbé e láti Ebeneseri lọ sí Aṣidodu.

2 Wọ́n gbé e lọ sí ilé Dagoni, oriṣa wọn; wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère oriṣa náà.

3 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, àwọn ará ìlú Aṣidodu rí i pé ère Dagoni ti ṣubú lulẹ̀. Wọ́n bá a tí ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA. Wọ́n bá gbé e dìde, wọ́n gbé e pada sí ààyè rẹ̀.

4 Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.

5 Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé títí di òní olónìí, àwọn babalóòṣà oriṣa Dagoni ati gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń bọ ọ́ kò jẹ́ tẹ ẹnu ọ̀nà ilé oriṣa Dagoni tí ó wà ní ìlú Aṣidodu, dídá ni wọ́n máa ń dá a kọjá.

6 OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún.

7 Nígbà tí àwọn ará Aṣidodu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun Israẹli ni ó ń jẹ àwa ati Dagoni, oriṣa wa níyà. A kò lè jẹ́ kí àpótí Ọlọrun Israẹli yìí wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín mọ́ rárá.”

8 Wọ́n bá ranṣẹ lọ pe àwọn ọba Filistini jọ, wọ́n sì bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí Ọlọrun Israẹli yìí?”

Wọ́n dáhùn pé kí wọ́n gbé e lọ sí Gati; wọ́n bá gbé e lọ sibẹ.

9 Ṣugbọn nígbà tí àpótí Ọlọrun náà dé Gati, OLUWA jẹ ìlú náà níyà, ó mú kí gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún ati àgbà ati èwe wọn, ó sì mú ìpayà bá gbogbo wọn.

10 Wọ́n tún gbé àpótí Ọlọrun náà ranṣẹ sí ìlú Filistini mìíràn, tí wọn ń pè ní Ekironi. Ṣugbọn bí wọ́n ti gbé e dé Ekironi ni àwọn ará ìlú fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun Israẹli dé síhìn-ín, láti pa gbogbo wa run.”

11 Wọ́n bá ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí Ọlọrun Israẹli pada sí ibi tí ẹ ti gbé e wá, kí ó má baà pa àwa ati ìdílé wá run.” Ìpayà ńlá ti bá gbogbo ìlú nítorí OLUWA ń jẹ wọ́n níyà gidigidi.

12 Ara gbogbo àwọn tí kò kú ninu wọn kún fún kókó ọlọ́yún. Ariwo àwọn eniyan náà sì pọ̀ pupọ.