Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 3

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Ṣẹ́kù lórí Ilẹ̀ Kenaani

1 OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò, pàápàá jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn kò tíì ní ìrírí ogun jíjà ní ilẹ̀ Kenaani.

2 Kí àwọn ọmọ Israẹli lè mọ̀ nípa ogun jíjà, pataki jùlọ, ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa ogun jíjà tẹ́lẹ̀.

3 Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati.

4 Àwọn ni OLUWA fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò, láti wò ó bóyá wọn óo mú àṣẹ tí òun pa fún àwọn baba wọn láti ọwọ́ Mose ṣẹ, tabi wọn kò ní mú un ṣẹ.

5 Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.

6 Àwọn ọmọ Israẹli ń fẹ́mọ lọ́wọ́ àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà, àwọn náà ń fi ọmọ fún wọn; àwọn ọmọ Israẹli sì ń bọ àwọn oriṣa wọn.

Otinieli

7 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali ati Aṣerotu.

8 Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ.

9 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n kígbe pé OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan dìde fún wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, òun ni ó gbà wọ́n kalẹ̀.

10 Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀.

11 Nítorí náà, ilẹ̀ náà wà ní alaafia fún ogoji ọdún, lẹ́yìn náà, Otinieli ọmọ Kenasi ṣaláìsí.

Ehudu

12 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, lágbára lórí wọn, nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.

13 Egiloni yìí kó àwọn ará Amoni ati àwọn ará Amaleki sòdí, wọ́n lọ ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, lọ́wọ́ wọn.

14 Àwọn ọmọ Israẹli sin Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, fún ọdún mejidinlogun.

15 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n tún ké pe OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan, ọlọ́wọ́ òsì, dìde, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ehudu, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini. Ní àkókò kan àwọn ọmọ Israẹli fi ìṣákọ́lẹ̀ rán an sí Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu.

16 Ehudu rọ idà olójú meji kan tí kò gùn ju igbọnwọ kan lọ, ó fi bọ inú àkọ̀, ó so ó mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún lábẹ́ aṣọ.

17 Ó fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Egiloni yìí jẹ́ ẹni tí ó sanra rọ̀pọ̀tọ̀.

18 Nígbà tí Ehudu fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ tán, ó ní kí àwọn tí wọ́n rù ú máa pada lọ.

19 Òun nìkan bá pada ní ibi òkúta tí wọ́n gbẹ́, tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó tọ ọba lọ, ó ní, “Kabiyesi, mo ní iṣẹ́ àṣírí kan tí mo fẹ́ jẹ́ fún ọ.”

Ọba bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn sì jáde.

20 Ehudu bá tọ̀ ọ́ lọ, níbi tí òun nìkan jókòó sí ninu yàrá tútù kan, lórí òrùlé ilé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Ọlọ́run rán mi ní iṣẹ́ kan sí ọ,” ọba bá dìde níbi tí ó jókòó sí.

21 Ehudu bá fi ọwọ́ òsì fa idà tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún yọ, ó sì tì í bọ ọba Egiloni níkùn.

22 Idà yìí wọlé tèèkùtèèkù, ọ̀rá sì padé mọ́ ọn, nítorí pé kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn ọba, ìfun ọba sì tú jáde.

23 Ehudu bá jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà.

24 Lẹ́yìn tí ó ti sá lọ ni àwọn iranṣẹ ọba pada dé. Nígbà tí wọn rí i pé wọ́n ti fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà, wọ́n rò ninu ara wọn pé, bóyá ọba wà ninu ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó wà ninu yàrá orí òrùlé náà ni.

25 Wọ́n dúró títí tí agara fi dá wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó kọ̀ tí kò ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n bá mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n ṣí àwọn ìlẹ̀kùn; wọ́n bá bá òkú oluwa wọn nílẹ̀.

26 Ní gbogbo ìgbà tí àwọn iranṣẹ wọnyi ń dúró pé kí ọba ṣílẹ̀kùn, Ehudu ti sá lọ, ó sì ti kọjá òkúta gbígbẹ́ tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó ti sá dé Seira.

27 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọn fèrè ní agbègbè olókè Efuraimu. Àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé e lẹ́yìn láti agbègbè olókè, ó sì ṣiwaju wọn.

28 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí pé OLUWA ti fi àwọn ará Moabu, tíí ṣe ọ̀tá yín le yín lọ́wọ́.” Wọ́n bá ń tẹ̀lé e lọ, wọ́n gba ibi tí ó ṣe é fi ẹsẹ̀ là kọjá níbi odò Jọdani mọ́ àwọn ará Moabu lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.

29 Wọ́n pa àwọn alágbára ati akikanju bí ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ará Moabu, kò sì sí ẹnìkan tí ó là ninu wọn.

30 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe ṣẹgun wọn ní ọjọ́ náà, ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ọgọrin ọdún.

Ṣamgari

31 Aṣiwaju tí ó tún dìde lẹ́yìn Ehudu ni Ṣamgari, ọmọ Anati, ẹni tí ó fi ọ̀pá tí wọ́n fi ń da mààlúù pa ẹgbẹta (600) ninu àwọn ará Filistia; òun náà gba Israẹli kalẹ̀.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 4

Debora ati Baraki

1 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA lẹ́yìn ikú Ehudu.

2 OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimuni olórí ogun rẹ̀.

3 Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́, nítorí pé ẹẹdẹgbẹrun (900) ni kẹ̀kẹ́ ogun Jabini tí wọ́n fi irin ṣe; ó sì ni wọ́n lára fún ogún ọdún.

4 Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà.

5 Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́.

6 Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ.

7 N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”

8 Baraki bá dá a lóhùn pé, “Bí o óo bá bá mi lọ ni n óo lọ, bí o kò bá ní bá mi lọ, n kò ní lọ.”

9 Debora dáhùn pé, “Láìṣe àní àní, n óo bá ọ lọ. Ṣugbọn ṣá o, ohun tí o fẹ́ ṣe yìí kò ní já sí ògo fún ọ, nítorí pé, OLUWA yóo fi Sisera lé obinrin kan lọ́wọ́.” Debora bá gbéra, ó bá Baraki lọ sí Kedeṣi.

10 Baraki bá pe àwọn ọmọ Sebuluni ati Nafutali sí Kedeṣi; ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ninu wọn ni wọ́n tẹ̀lé Baraki, Debora náà sì bá wọn lọ.

11 Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu.

12 Nígbà tí Sisera gbọ́ pé Baraki ti lọ sí orí òkè Tabori,

13 ó kó ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹ̀kẹ́ ogun onírin rẹ̀ jọ, ó sì pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti Haroṣeti-ha-goimu títí dé odò Kiṣoni.

14 Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀.

15 OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

16 Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan.

17 Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni.

18 Jaeli bá jáde lọ pàdé Sisera, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, oluwa mi. Yà wá sọ́dọ̀ mi, má bẹ̀rù.” Sisera bá yà sinu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ tí ó nípọn bò ó.

19 Sisera bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ òùngbẹ ń gbẹ mí, fún mi lómi mu.” Jaeli bá ṣí ìdérí ìgò tí wọ́n fi awọ ṣe, tí wọ́n da wàrà sí, ó fún un ní wàrà mu, ó sì tún da aṣọ bò ó.

20 Sisera wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá wá, tí ó sì bi ọ́ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbí?’ Wí fún olúwarẹ̀ pé, ‘Kò sí.’ ”

21 Ó ti rẹ Sisera tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sùn lọ fọnfọn. Jaeli bá mú òòlù kan, ati èèkàn àgọ́, ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Sisera sùn sí, ó kan èèkàn náà mọ́ ọn lẹ́bàá etí títí tí èèkàn náà fi wọlé, ó sì kú.

22 Bí Baraki ti ń wá Sisera kiri, Jaeli lọ pàdé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Máa bọ̀ níhìn-ín, n óo sì fi ẹni tí ò ń wá hàn ọ́.” Baraki bá bá a wọlé lọ, ó sì bá Sisera nílẹ̀ níbi tí ó kú sí, pẹlu èèkàn àgọ́ tí wọn gbá mọ́ ọn lẹ́bàá etí.

23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọrun bá àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Jabini, ọba àwọn ará Kenaani.

24 Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kọlu Jabini, ọba Kenaani lemọ́lemọ́ títí wọ́n fi pa á run.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 5

Orin Debora ati Baraki

1 Debora ati Baraki ọmọ Abinoamu bá kọrin ní ọjọ́ náà pé:

2 Ẹ fi ìyìn fún OLUWA,

nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli,

àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀.

3 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba;

ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè;

OLUWA ni n óo kọrin sí,

n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli.

4 OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,

nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,

ilẹ̀ mì tìtì,

omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,

ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.

5 Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA,

àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli.

6 Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati,

ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́,

àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀.

7 Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,

gbogbo ìlú di àkọ̀tì,

títí tí ìwọ Debora fi dìde,

bí ìyá, ní Israẹli.

8 Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun,

ogun bo gbogbo ẹnubodè.

Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli,

ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀?

9 Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli,

tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan.

Ẹ fi ìyìn fún OLUWA.

10 Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye,

ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn.

11 Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,

ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,

ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.

Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn.

12 Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!

Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!

Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,

ìwọ ọmọ Abinoamu!

13 Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,

àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,

láti gbógun ti alágbára.

14 Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà,

wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ.

Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri,

àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni.

15 Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá,

àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki,

wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì.

Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,

ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.

16 Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan?

Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn.

Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,

ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.

17 Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani,

kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi?

Àwọn ẹ̀yà Aṣeri jókòó létí òkun,

wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò.

18 Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú,

bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali,

wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun.

19 “Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megido

àwọn ọba wá, wọ́n jagun,

wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun,

ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó.

20 Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun,

àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn,

ni wọ́n ti bá Sisera jà.

21 Odò Kiṣoni kó wọn lọ,

odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya.

Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ.

22 Àwọn ẹṣin sáré dé, pẹlu ariwo pátákò ẹsẹ̀ wọn,

wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ kilẹ̀.”

23 Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,

ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,

nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;

wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”

24 Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin,

Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni,

ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́.

25 Omi ni Sisera bèèrè, wàrà ni Jaeli fún un,

àwo tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ fún ọba

ni ó fi gbé e fún un mu.

26 Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,

ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ,

ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo;

ó fọ́ ọ lórí,

ó lù ú ní ẹ̀bá etí,

ó sì fọ́ yángá-yángá.

27 Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀,

ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli,

ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀.

Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí.

28 Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé,

ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé.

Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé?

Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin

tí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?”

29 Àwọn ọlọ́gbọ́n jùlọ ninu àwọn obinrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ dá a lóhùn,

òun náà sì ń wí fún ara rẹ̀ pé,

30 “Ṣebí ìkógun ni wọ́n ń wá, tí wọ́n sì ń pín?

Obinrin kan tabi meji fún ọkunrin kọ̀ọ̀kan,

ìkógun àwọn aṣọ aláró fún Sisera,

ìkógun àwọn aṣọ aláró tí wọ́n dárà sí lára,

aṣọ ìborùn aláró meji tí wọ́n dárà sí lára fún èmi náà?”

31 Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ṣègbé, OLUWA;

ṣugbọn bí oòrùn ti máa ń fi agbára rẹ̀ ràn,

bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa tàn.

Ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ogoji ọdún.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 6

Gideoni

1 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje.

2 Àwọn ará Midiani lágbára ju àwọn ọmọ Israẹli lọ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli fi ṣe ibi tí wọn ń sápamọ́ sí lórí àwọn òkè, ninu ihò àpáta, ati ibi ààbò mìíràn ninu òkè.

3 Nítorí pé, nígbàkúùgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá gbin ohun ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani ati àwọn ará Amaleki ati àwọn kan láti inú aṣálẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, a máa kó ara wọn jọ, wọn a lọ ṣígun bá àwọn ọmọ Israẹli.

4 Wọn a gbógun tì wọ́n, wọn a sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà jẹ́ títí dé agbègbè Gasa. Wọn kì í fi oúnjẹ kankan sílẹ̀ rárá ní ilẹ̀ Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi aguntan tabi mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan sílẹ̀.

5 Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀, tilé-tilé ni wọ́n wá. Wọn á kó àwọn àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́, wọn á sì bo àwọn ọmọ Israẹli bí eṣú. Àwọn ati ràkúnmí wọn kò níye, nítorí náà nígbà tí wọ́n bá dé, wọn á jẹ gbogbo ilẹ̀ náà ní àjẹrun.

6 Àwọn ọmọ Israẹli di ẹni ilẹ̀ patapata, nítorí àwọn ará Midiani. Nítorí náà, wọ́n ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.

7 Nígbà tí wọ́n ké pe OLUWA, nítorí ìyọnu àwọn ará Midiani,

8 OLUWA rán wolii kan sí wọn. Wolii náà bá sọ fún wọn pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo ko yín wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo ko yín kúrò ní oko ẹrú.

9 Mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn tí wọn ń ni yín lára. Mo lé wọn jáde fún yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fun yín.

10 Mo kìlọ̀ fún yín pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, ati pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi.’ ”

11 Angẹli OLUWA kan wá, ó jókòó lábẹ́ igi Oaku tí ó wà ní Ofira, igi Oaku yìí jẹ́ ti Joaṣi, ará Abieseri. Bí Gideoni ọmọ Joaṣi, ti ń pa ọkà ní ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí, tí ó ń fi í pamọ́ fún àwọn ará Midiani,

12 ni angẹli OLUWA náà yọ sí i, ó sì wí fún un pé, “OLUWA wà pẹlu rẹ, ìwọ akikanju ati alágbára ọkunrin.”

13 Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”

14 Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.”

15 Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.”

16 OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.”

17 Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀.

18 Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.”

Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.”

19 Gideoni bá wọlé lọ, ó tọ́jú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Ó kó ẹran tí ó sè sinu agbọ̀n kan, ó da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sinu ìkòkò kan, ó gbé e tọ Angẹli OLUWA náà lọ ní abẹ́ igi Oaku, ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀.

20 Angẹli Ọlọrun náà wí fún un pé, “Da ẹran náà ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ náà lé gbogbo rẹ̀ lórí.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀.

21 Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú.

22 Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.”

23 Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.”

24 Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí.

25 Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

26 Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.”

27 Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.

28 Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́.

29 Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.”

30 Àwọn ará ìlú náà bá wí fún Joaṣi pé, “Mú ọmọ rẹ jáde kí á pa á, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ oriṣa Baali, ó sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”

31 Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.”

32 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.

33 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli.

34 Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọmọ Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e.

35 Ó ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Manase, wọ́n pe ara wọn jáde, wọ́n sì tẹ̀lé e. Ó tún ranṣẹ bákan náà sí ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Sebuluni, ati ẹ̀yà Nafutali, àwọn náà sì lọ pàdé rẹ̀.

36 Gideoni wí fún Ọlọrun pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí,

37 n óo fi irun aguntan lélẹ̀ ní ibi ìpakà, bí ìrì bà sẹ̀ sórí irun yìí nìkan, tí gbogbo ilẹ̀ tí ó yí i ká bá gbẹ, nígbà náà ni n óo gbà pé nítòótọ́, èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí.”

38 Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó jí ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, tí ó sì fún irun aguntan náà, ìrì tí ó fún ní ara rẹ̀ kún abọ́ kan.

39 Gideoni tún wí fún Ọlọrun pé, “Jọ̀wọ́, má jẹ́ kí inú bí ọ sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí ni ó kù tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀; jọ̀wọ́ jẹ́ kí n tún dán kinní kan wò pẹlu irun aguntan yìí lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí gbogbo irun yìí gbẹ ṣugbọn kí ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀, kí ó sì tutù.”

40 Ọlọrun tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, nítorí pé, orí irun yìí nìkan ṣoṣo ni ó gbẹ, ìrì sì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 7

Gideoni Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani

1 Nígbà tí ó yá, Gideoni, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jerubaali, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ kan, wọ́n lọ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ odò Harodu. Àgọ́ ti àwọn ará Midiani wà ní apá ìhà àríwá wọn ní àfonífojì lẹ́bàá òkè More.

2 OLUWA wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pọ̀jù fún mi, láti fi àwọn ará ilẹ̀ Midiani lé lọ́wọ́, kí àwọn ọmọ Israẹli má baà gbéraga pé agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun, wọn kò sì ní fi ògo fún mi.

3 Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000).

4 OLUWA tún wí fún Gideoni pé, “Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù yìí pọ̀jù sibẹsibẹ. Kó wọn lọ sí etí odò, n óo sì bá ọ dán wọn wò níbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí mo bá wí fún ọ pé yóo lọ, òun ni yóo lọ, ẹnikẹ́ni tí mo bá sì wí fún ọ pé kò ní lọ, kò gbọdọ̀ lọ.”

5 Gideoni bá kó àwọn eniyan náà lọ sí etí odò, OLUWA bá wí fún Gideoni pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ahọ́n lá omi gẹ́gẹ́ bí ajá, yọ ọ́ sọ́tọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, bákan náà ni kí o ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá kúnlẹ̀ kí ó tó mu omi.

6 Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ bomi, tí wọ́n sì fi ahọ́n lá a bí ajá jẹ́ ọọdunrun (300), gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n tó mu omi.

7 OLUWA bá wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọọdunrun (300) tí wọ́n fi ahọ́n lá omi ni n óo lò láti gbà yín là, n óo sì fi àwọn ará Midiani lé ọ lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn yòókù pada sí ilé wọn.”

8 Gideoni bá gba oúnjẹ àwọn eniyan náà ati fèrè ogun wọn lọ́wọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n pada sí ilé, ṣugbọn ó dá àwọn ọọdunrun (300) náà dúró. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Midiani wà ní àfonífojì lápá ìsàlẹ̀ ibi tí wọ́n wà.

9 OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́.

10 Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà.

11 O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà.

12 Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.

13 Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.”

14 Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.”

15 Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.”

16 Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́.

17 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe bí mo bá ti ń ṣe. Nígbà tí mo bá dé ìkangun àgọ́ náà, ẹ ṣe bí mo bá ti ṣe.

18 Nígbà tí èmi ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ mi bá fọn fèrè, ẹ̀yin náà ẹ fọn fèrè tiyín ní gbogbo àyíká àgọ́ náà, ẹ óo sì pariwo pé, ‘Fún OLUWA, ati fún Gideoni.’ ”

19 Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wọ́ wọn mọ́lẹ̀.

20 Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.”

21 Olukuluku wọn dúró sí ààyè wọn yípo àgọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun Midiani bá bẹ̀rẹ̀ sí sá káàkiri, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

22 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati.

23 Àwọn ọmọ ogun Israẹli pe àwọn ọkunrin Israẹli jáde láti inú ẹ̀yà Nafutali, ati ti Aṣeri ati ti Manase, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ará Midiani lọ.

24 Gideoni rán àwọn oníṣẹ́ jákèjádò agbègbè olókè Efuraimu, ó ní, “Ẹ máa bọ̀ wá bá àwọn ará Midiani jagun, kí ẹ sì gba ojú odò lọ́wọ́ wọn títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani.” Wọ́n pe gbogbo àwọn ọkunrin Efuraimu jáde, wọ́n sì gba gbogbo odò títí dé Bẹtibara ati odò Jọdani pẹlu.

25 Wọ́n mú Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji, wọ́n pa Orebu sí ibi òkúta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi ìfúntí Seebu, bí wọ́n ti ń lé àwọn ará Midiani lọ. Wọ́n gé orí Orebu ati ti Seebu, wọ́n sì gbé wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gideoni ní òdìkejì odò Jọdani.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 8

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Àwọn Ará Midiani ní Àṣẹ́tán

1 Àwọn ará Efuraimu bèèrè lọ́wọ́ Gideoni pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, tí o kò pè wá, nígbà tí o lọ gbógun ti àwọn ara Midiani?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i pẹlu ibinu.

2 Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ.

3 Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́.

4 Gideoni bá lọ sí odò Jọdani, ó sì kọjá odò náà sí òdìkejì rẹ̀, òun ati àwọn ọọdunrun (300) ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, sibẹsibẹ wọ́n ń lé àwọn ará Midiani lọ.

5 Ó bẹ àwọn ará Sukotu, ó ní, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún àwọn tí wọ́n tẹ̀lé mi ní oúnjẹ, nítorí pé ó ti rẹ̀ wọ́n, ati pé à ń lé Seba ati Salimuna, àwọn ọba Midiani mejeeji lọ ni.”

6 Àwọn ìjòyè Sukotu dá a lóhùn, wọ́n ní, “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba ati Salimuna ni, tí a óo fi fún ìwọ ati àwọn ọmọ ogun rẹ ní oúnjẹ?”

7 Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Kò burú, nígbà tí OLUWA bá fi Seba ati Salimuna lé mi lọ́wọ́, ẹ̀gún ọ̀gàn aṣálẹ̀ ati òṣùṣú ni n óo fi ya ẹran ara yín.”

8 Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Penueli, ó sọ ohun kan náà fún wọn, ṣugbọn irú èsì tí àwọn ará Sukotu fún un ni àwọn ará Penueli náà fún un.

9 Ó sọ fún àwọn ará Penueli pé, “Nígbà tí mo bá pada dé ní alaafia n óo wó ilé ìṣọ́ yìí.”

10 Seba ati Salimuna wà ní ìlú Karikori pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn yòókù, gbogbo àwọn ọmọ ogun ìlà oòrùn tí wọ́n ṣẹ́kù kò ju nǹkan bí ẹẹdẹgbaajọ (15,000) lọ, nítorí pé àwọn tí wọ́n ti kú ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n ń lo idà tó ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000).

11 Ọ̀nà èrò tí ó wà ní ìlà oòrùn Noba ati Jogibeha ni Gideoni gbà lọ, ó lọ jálu àwọn ọmọ ogun náà láì rò tẹ́lẹ̀.

12 Seba ati Salimuna bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ṣugbọn Gideoni lé àwọn ọba Midiani mejeeji yìí títí tí ó fi mú wọn. Jìnnìjìnnì bá dàbo gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn.

13 Ọ̀nà àtigun òkè Heresi ni Gideoni gbà nígbà tí ó ń ti ojú ogun pada bọ̀.

14 Ọwọ́ rẹ̀ tẹ ọdọmọkunrin ará Sukotu kan, ó sì bèèrè orúkọ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà ìlú Sukotu lọ́wọ́ rẹ̀. Ọdọmọkunrin yìí sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkunrin mẹtadinlọgọrin.

15 Ó bá wá sọ́dọ̀ àwọn ọkunrin Sukotu, ó ní, “Ẹ wo Seba ati Salimuna, àwọn ẹni tí ẹ tìtorí wọn pẹ̀gàn mi pé ọwọ́ mi kò tíì tẹ̀ wọ́n, tí ẹ kò sì fún àwọn ọmọ ogun mi tí àárẹ̀ mú ní oúnjẹ. Seba ati Salimuna náà nìyí o.”

16 Ó kó gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì mú ẹ̀gún ọ̀gàn ati òṣùṣú, ó fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n.

17 Lẹ́yìn náà ó lọ sí Penueli, ó wó ilé ìṣọ́ wọn, ó sì pa àwọn ọkunrin ìlú náà.

18 Lẹ́yìn náà, ó bi Seba ati Salimuna pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí ẹ pa ní Tabori wà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o ti rí gan-an ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn náà rí, gbogbo wọn dàbí ọmọ ọba.”

19 Ó dáhùn, ó ní, “Arakunrin mi ni wọ́n, ìyá kan náà ni ó bí wa. Bí OLUWA ti wà láàyè, bí ó bá jẹ́ pé ẹ dá wọn sí ni, ǹ bá dá ẹ̀yin náà sí.”

20 Ó bá pe Jeteri àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Dìde, kí o sì pa wọ́n,” ṣugbọn ọmọ náà kò fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á, nítorí ọmọde ni.

21 Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn.

22 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Israẹli wí fún Gideoni pé, “Máa jọba lórí wa, ìwọ ati ọmọ rẹ, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹlu, nítorí pé ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.”

23 Gideoni dá wọn lóhùn, ó ní “N kò ní jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ mi kò ní jọba lórí yín, OLUWA ni yóo máa jọba lórí yín.”

24 Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n pé kí olukuluku wọn fún òun ní yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀, nítorí pé àwọn ará Midiani a máa lo yẹtí wúrà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilẹ̀ Iṣimaeli yòókù.

25 Wọ́n dá a lóhùn pé, “A óo fi tayọ̀tayọ̀ kó wọn fún ọ.” Wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀, olukuluku sì bẹ̀rẹ̀ sí ju yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀ sibẹ.

26 Gbogbo ìwọ̀n yẹtí wúrà tí ó gbà jẹ́ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ṣekeli, láìka ohun ọ̀ṣọ́ ati aṣọ olówó iyebíye tí àwọn ọba Midiani wọ̀, ati àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn àwọn ràkúnmí wọn.

27 Gideoni bá fi wúrà yìí ṣe ère Efodu kan, ó gbé e sí ìlú rẹ̀ ní Ofira, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ ère oriṣa yìí, ó sì di tàkúté fún Gideoni ati ìdílé rẹ̀.

28 Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ará Midiani, wọn kò sì lè gbérí mọ́; àwọn ọmọ Israẹli sì sinmi ogun jíjà fún ogoji ọdún, nígbà ayé Gideoni.

Ikú Gideoni

29 Gideoni pada sí ilé rẹ̀, ó sì ń gbé ibẹ̀.

30 Aadọrin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ aya.

31 Obinrin rẹ̀ kan tí ń gbè Ṣekemu náà bí ọmọkunrin kan fún un, orúkọ ọmọ yìí ń jẹ́ Abimeleki.

32 Gideoni ọmọ Joaṣi ṣaláìsí lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, wọ́n sin ín sinu ibojì Joaṣi, baba rẹ̀, ní Ofira àwọn ọmọ Abieseri.

33 Bí Gideoni ti ṣaláìsí tán gẹ́rẹ́, àwọn ọmọ Israẹli tún bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali, wọ́n sì sọ Baali-beriti di Ọlọrun wọn.

34 Wọn kò ranti OLUWA Ọlọrun wọn tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo àyíká wọn.

35 Wọn kò ṣe ìdílé Gideoni dáradára bí ó ti tọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san gbogbo nǹkan dáradára tí òun náà ti ṣe fún Israẹli.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 9

Abimeleki

1 Abimeleki ọmọ Gideoni lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu, ó bá àwọn ati gbogbo ìdílé wọn sọ̀rọ̀, ó ní,

2 kí wọn bèèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu pé, èwo ni wọ́n fẹ́, tí wọ́n sì rò pé ó dára jù fún wọn, kí gbogbo aadọrin ọmọ Gideoni máa jọba lé wọn lórí ni, tabi kí ẹnìkan ṣoṣo jọba lórí wọn? Ó rán wọn létí pé, ìyekan wọn ni òun jẹ́.

3 Àwọn eniyan ìyá rẹ̀ bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu, wọn sì gbà láti tẹ̀lé Abimeleki tayọ̀tayọ̀. Wọ́n ní, “Arakunrin wa ni Abimeleki jẹ́.”

4 Wọ́n mú aadọrin owó fadaka ninu ilé oriṣa Baali-beriti fún Abimeleki. Ó fi owó yìí kó àwọn oníjàgídíjàgan ati ìpátá kan jọ wọ́n sì ń tẹ̀lé e kiri.

5 Ó bá lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, ó pa gbogbo aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀ lórí òkúta kan, àfi Jotamu àbíkẹ́yìn Gideoni nìkan ni ó ṣẹ́kù, nítorí pé òun sá pamọ́.

6 Gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo bá para pọ̀, wọ́n fi Abimeleki jọba níbi igi Oaku kan tí ó wà níbi ọ̀wọ̀n tí ó wà ní Ṣekemu.

7 Nígbà tí Jotamu gbọ́, ó gun orí òkè Gerisimu lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ọkunrin Ṣekemu, kí Ọlọrun lè gbọ́ tiyín.

8 Ní àkókò kan, àwọn igi oko kó ara wọn jọ pé wọ́n fẹ́ ọba, wọ́n lọ sọ́dọ̀ igi Olifi, wọ́n wí fún un pé kí ó máa jọba lórí wọn.

9 Ṣugbọn igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa òróró ṣíṣe tì, tí àwọn oriṣa ati àwọn eniyan fi ń dá ara wọn lọ́lá tì, kí n má ṣe é mọ́, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’

10 Àwọn igi bá lọ sí ọ̀dọ̀ igi ọ̀pọ̀tọ́, wọ́n sọ fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

11 Ṣugbọn igi ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa èso mi dáradára tí ó ládùn tì, kí n wá jọba lórí yín?’

12 Àwọn igi bá tún lọ sọ́dọ̀ igi àjàrà, wọ́n wí fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

13 Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’

14 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn igi sọ fún igi ẹ̀gún pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

15 Igi ẹ̀gún bá dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Tí ó bá jẹ́ pé tinútinú yín ni ẹ fi fẹ́ kí n jọba yín, ẹ wá sábẹ́ ìbòòji mi, n óo sì dáàbò bò yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, iná yóo yọ jáde láti ara ẹ̀gún mi, yóo sì jó igi kedari tí ó wà ní Lẹbanoni run.’

16 “Ǹjẹ́ òtítọ́ inú ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi fi Abimeleki jọba? Ṣé ohun tí ẹ ṣe sí ìdílé Gideoni tọ́? Gbogbo sísìn tí ó sìn yín, ǹjẹ́ irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún un nìyí?

17 Nítorí pé baba mi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu nígbà tí ó ń jà fun yín, ó sì gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.

18 Ṣugbọn lónìí, ẹ dìde sí ìdílé baba mi, ẹ sì pa aadọrin àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lórí òkúta, ẹ wá fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jọba lórí ìlú Ṣekemu, nítorí pé ó jẹ́ ìbátan yín.

19 Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé pẹlu òtítọ́ inú, ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe sí Gideoni ati ìdílé rẹ̀ lónìí, ẹ máa yọ̀ lórí Abimeleki kí òun náà sì máa yọ̀ lórí yín.

20 Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iná yóo jáde láti ara Abimeleki, yóo sì run gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati Bẹtimilo. Bẹ́ẹ̀ ni iná yóo jáde láti ara àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo, yóo sì jó Abimeleki run.”

21 Jotamu bá sá lọ sí Beeri, ó sì ń gbé ibẹ̀, nítorí ó bẹ̀rù Abimeleki arakunrin rẹ̀.

22 Abimeleki jọba lórí Israẹli fún ọdún mẹta.

23 Ọlọrun rán ẹ̀mí burúkú sí ààrin Abimeleki ati àwọn ara ìlú Ṣekemu. Àwọn ará ìlú Ṣekemu sì dìtẹ̀ mọ́ Abimeleki.

24 Kí ẹ̀san pípa tí Abimeleki pa àwọn aadọrin ọmọ baba rẹ̀ ati ẹ̀jẹ̀ wọn lè wá sórí Abimeleki, ati àwọn ará ìlú Ṣekemu tí wọ́n kì í láyà láti pa wọ́n.

25 Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki.

26 Gaali ọmọ Ebedi ati àwọn arakunrin rẹ̀ kó lọ sí Ṣekemu, àwọn ará ìlú Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé e.

27 Àwọn ará ìlú Ṣekemu lọ sinu oko wọn, wọ́n ká èso àjàrà, wọ́n fi pọn ọtí fún wọn. Wọ́n jọ ń ṣe àríyá, wọ́n jọ lọ sí ilé oriṣa wọn, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Abimeleki ṣe ẹlẹ́yà.

28 Gaali ọmọ Ebedi bá bèèrè pé, “Ta tilẹ̀ ni Abimeleki? Báwo sì ni àwa ará ìlú Ṣekemu ṣe jẹ́ sí i, tí a fi níláti máa sìn ín? Ṣebí àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, ni Gideoni ati Sebulu, iranṣẹ rẹ̀ máa ń sìn? Kí ló dé tí àwa fi níláti máa sin Abimeleki?

29 Ìbá ṣe pé ìkáwọ́ mi ni àwọn eniyan yìí wà, ǹ bá yọ Abimeleki kúrò lórí oyè. Ǹ bá sọ fún Abimeleki pé kí ó lọ wá kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó jáde wá bá mi jà.”

30 Nígbà tí Sebulu, olórí ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali, ọmọ Ebedi wí, inú bí i gidigidi.

31 Ó ranṣẹ sí Abimeleki ní Aruma, ó ní, “Gaali, ọmọ Ebedi, ati àwọn arakunrin rẹ̀ ti dé sí Ṣekemu, wọn kò sì ní gbà fún ọ kí o wọ ibí mọ́.

32 Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba.

33 Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, tí oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ, gbéra, kí o sì gbógun ti ìlú náà. Nígbà tí Gaali ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá sì jáde sí ọ, mú wọn dáradára, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn.”

34 Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá gbéra ní òru, wọ́n lọ ba níbùba lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ṣekemu, ní ìsọ̀rí mẹrin.

35 Gaali ọmọ Ebedi bá jáde, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ sì jáde níbi tí wọ́n ba sí.

36 Nígbà tí Gaali rí wọn, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti orí òkè.”

Sebulu dá a lóhùn pé, “Òjìji òkè ni ò ń wò tí o ṣebí eniyan ni.”

37 Gaali tún dáhùn, ó ní, “Tún wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti agbede meji ilẹ̀ náà, àwọn kan sì ń bọ̀ láti apá ibi igi Oaku àwọn tíí máa ń wo iṣẹ́.”

38 Ṣugbọn Sebulu dá a lóhùn, pé, “Gbogbo ẹnu tí ò ń fọ́n pin, tabi kò pin? Ṣebí ìwọ ni o wí pé, ‘Kí ni Abimeleki jẹ́ tí a fi ń sìn ín.’ Àwọn tí ò ń gàn ni wọ́n dé yìí, yára jáde kí o lọ gbógun tì wọ́n.”

39 Gaali bá kó àwọn ọkunrin Ṣekemu lẹ́yìn, wọ́n lọ gbógun ti Abimeleki.

40 Abimeleki lé Gaali, Gaali sì sá fún un, ọpọlọpọ eniyan fara gbọgbẹ́ títí dé ẹnu ibodè ìlú.

41 Abimeleki tún lọ ń gbé Aruma. Sebulu bá lé Gaali ati àwọn arakunrin rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́.

42 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Abimeleki gbọ́ pé àwọn ará Ṣekemu ń jáde lọ sinu pápá.

43 Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó pín wọn sí ìsọ̀rí mẹta, wọ́n sì ba níbùba ninu pápá. Bí ó ti rí i pé àwọn eniyan náà ń jáde bọ̀ láti inú ìlú, ó gbógun tì wọ́n, ó sì pa wọ́n.

44 Abimeleki ati àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sáré, wọ́n lọ gba ẹnu ọ̀nà bodè ìlú. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun meji yòókù sáré sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, wọ́n pa wọ́n.

45 Abimeleki gbógun ti ìlú náà ní gbogbo ọjọ́ náà, ó gbà á, ó sì pa àwọn eniyan inú rẹ̀; ó wó gbogbo ìlú náà palẹ̀, ó sì da iyọ̀ sí i.

46 Nígbà tí gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu gbọ́, wọ́n sá lọ sí ibi ààbò tí ó wà ní ilé Eli-beriti.

47 Wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu ti kó ara wọn jọ sí ibìkan.

48 Abimeleki bá lọ sí òkè Salimoni, òun ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mú àáké kan lọ́wọ́, ó fi gé ẹrù igi kan jọ, ó gbé e lé èjìká, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pé, “Ẹ yára ṣe bí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.”

49 Olukuluku wọn náà bá gé ẹrù igi kọ̀ọ̀kan, wọ́n tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n to ẹrù igi wọn jọ sí ara ibi ààbò náà, wọn sọ iná sí i. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé ìṣọ́ Ṣekemu sì kú patapata. Wọ́n tó ẹgbẹrun (1,000) eniyan, atọkunrin, atobinrin.

50 Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó gbógun tì í, ó sì gbà á.

51 Ṣugbọn ilé ìṣọ́ kan tí ó lágbára wà ninu ìlú náà, gbogbo àwọn ará ìlú sá lọ sinu rẹ̀, atọkunrin, atobinrin. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun òkè ilé ìṣọ́ náà lọ.

52 Nígbà tí Abimeleki dé ibi ilé ìṣọ́ náà, ó gbógun tì í. Ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún.

53 Obinrin kan bá gbé ọmọ ọlọ kan, ó sọ ọ́ sílẹ̀, ọmọ ọlọ yìí bá Abimeleki lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀.

54 Ó yára pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó wí fún un pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn eniyan má baà máa wí pé, ‘Obinrin kan ni ó pa á.’ ” Ọdọmọkunrin yìí bá gún un ní idà, ó sì kú.

55 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Abimeleki ti kú, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.

56 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbẹ̀san lára Abimeleki fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ baba rẹ̀, nítorí pé, ó pa aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀.

57 Ọlọrun sì mú kí gbogbo ìwà ibi àwọn ará Ṣekemu pada sórí wọn. Èpè tí Jotamu ọmọ Gideoni ṣẹ́ sì ṣẹ mọ́ wọn lára.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 10

Tola

1 Lẹ́yìn tí Abimeleki kú, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, láti inú ẹ̀yà Isakari ni ó dìde tí ó sì gba Israẹli kalẹ̀. Ìlú Ṣamiri tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ni ìlú rẹ̀.

2 Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹtalelogun, nígbà tí ó ṣaláìsí wọ́n sin ín sí Ṣamiri.

Jairi

3 Jairi ará Gileadi ni ó di adájọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mejilelogun.

4 Ó bí ọgbọ̀n ọmọkunrin, tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọgbọ̀n ìlú ni wọ́n sì tẹ̀dó, tí wọn ń pe orúkọ wọn ní Hafoti Jairi títí di òní olónìí. Wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi.

5 Nígbà tí Jairi ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ Kamoni.

Jẹfuta

6 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́.

7 Inú tún bí OLUWA sí Israẹli ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia ati àwọn ará Amoni lọ́wọ́.

8 Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

9 Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú.

10 Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.”

11 OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia.

12 Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn.

13 Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́.

14 Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.”

15 Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.”

16 Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli.

17 Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa.

18 Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.”

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 11

1 Jẹfuta ará Gileadi jẹ́ akikanju jagunjagun, ṣugbọn ọmọ aṣẹ́wó ni; Gileadi ni baba rẹ̀.

2 Ṣugbọn iyawo Gileadi gan-an bí àwọn ọmọkunrin mìíràn. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin wọnyi dàgbà, wọ́n lé Jẹfuta jáde, wọ́n sọ fún un pé, “O kò lè bá wa pín ninu ogún baba wa, nítorí ọmọ obinrin mìíràn ni ọ́.”

3 Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri.

4 Nígbà tí ó yá, àwọn ará Amoni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

5 Nígbà tí ogun yìí bẹ̀rẹ̀, àwọn àgbààgbà Gileadi lọ mú Jẹfuta wá láti ilẹ̀ Tobu.

6 Wọ́n bẹ Jẹfuta, wọ́n ní, “A fẹ́ lọ gbógun ti àwọn ará Amoni, ìwọ ni a sì fẹ́ kí o jẹ́ balogun wa.”

7 Ṣugbọn Jẹfuta dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ̀yin ni ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ fi lé mi jáde kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí ìyọnu dé ba yín?”

8 Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.”

9 Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?”

10 Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “OLUWA ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa pẹlu rẹ pé, ohun tí o bá wí ni a óo ṣe.”

11 Jẹfuta bá àwọn àgbààgbà Gileadi pada lọ, àwọn ará Gileadi sì fi jẹ balogun wọn. Ó lọ siwaju OLUWA ní Misipa, ó sì sọ àdéhùn tí ó bá àwọn àgbààgbà Gileadi ṣe.

12 Lẹ́yìn náà, Jẹfuta ranṣẹ sí ọba àwọn ará Amoni pé, “Kí ni mo ṣe tí o fi gbógun ti ilẹ̀ mi.”

13 Ọba Amoni bá rán àwọn oníṣẹ́ pada sí Jẹfuta pé, “Nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ gba ilẹ̀ mi, láti Anoni títí dé odò Jaboku, títí lọ kan odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yára dá ilẹ̀ náà pada ní alaafia.”

14 Jẹfuta tún ranṣẹ pada sí ọba Amoni pé,

15 “Gbọ́ ohun tí èmi Jẹfuta wí, Israẹli kò gba ilẹ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn ará Moabu tabi lọ́wọ́ àwọn ará Amoni.

16 Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi.

17 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi.

18 Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà.

19 Israẹli bá tún rán oníṣẹ́ sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ó wà ní ìlú Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí agbègbè ilẹ̀ tiwa.’

20 Ṣugbọn Sihoni kò ní igbẹkẹle ninu àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ̀. Ó bá kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jahasi, wọ́n sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

21 OLUWA Ọlọrun Israẹli bà fi Sihoni ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, Israẹli ṣẹgun wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé agbègbè náà.

22 Wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori láti Anoni títí dé odò Jaboku ati láti aṣálẹ̀ títí dé odò Jọdani.

23 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ó gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Amori fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣé ìwọ wá fẹ́ gbà á ni?

24 Ṣé ohun tí Kemoṣi, oriṣa rẹ fún ọ, kò tó ọ ni? Gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun wa ti gbà fún wa ni a óo fọwọ́ mú.

25 Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí?

26 Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà?

27 Nítorí náà, n kò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ ni o ṣẹ̀ mí, nítorí pé o gbógun tì mí. Kí OLUWA onídàájọ́ dájọ́ lónìí láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati Amoni.”

28 Ṣugbọn ọba àwọn ará Amoni kò tilẹ̀ fetí sí iṣẹ́ tí Jẹfuta rán sí i rárá.

29 Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé Jẹfuta, ó bá kọjá láàrin Gileadi ati Manase, ó lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Gileadi, láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

30 Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni,

31 nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.”

32 Jẹfuta bá rékọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Amoni láti bá wọn jagun, OLUWA sì fún un ní ìṣẹ́gun.

33 Ó bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láti Aroeri títí dé agbègbè Miniti tí ó fi wọ Abeli Keramimu. Àwọn ìlú tí ó run jẹ́ ogún. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣẹgun àwọn ará Amoni.

Ọmọbinrin Jẹfuta

34 Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí.

35 Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.”

36 Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.”

37 Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.”

38 Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin.

39 Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá.

Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli,

40 pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọọdun.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 12

Jẹfuta ati Àwọn Ará Efuraimu

1 Àwọn ọmọ Efuraimu múra ogun, wọ́n ré odò Jọdani kọjá lọ sí Safoni. Wọ́n bi Jẹfuta léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi rékọjá lọ sí òdìkejì láti bá àwọn ará Amoni jagun tí o kò sì pè wá pé kí á bá ọ lọ? Jíjó ni a óo jó ilé mọ́ ọ lórí.”

2 Jẹfuta bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Nígbà kan tí ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Amoni ati èmi pẹlu àwọn eniyan mi, tí mo ranṣẹ pè yín, ẹ kò gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn.

3 Mo sì ti mọ̀ pé ẹ kò tún ní gbà wá sílẹ̀, ni mo ṣe fi ẹ̀mí mi wéwu, tí mo sì kọjá sí òdìkejì lọ́dọ̀ àwọn ará Amoni; OLUWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Kí ló wá dé tí ẹ fi dìde sí mi lónìí láti bá mi jà?”

4 Jẹfuta bá kó gbogbo àwọn ọkunrin Gileadi jọ, wọ́n gbógun ti àwọn ará Efuraimu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, nítorí pé àwọn ará Efuraimu pe àwọn ará Gileadi ní ìsáǹsá Efuraimu, tí ó wà láàrin ẹ̀yà Efuraimu ati ẹ̀yà Manase.

5 Àwọn ará Gileadi gba àwọn ipadò odò Jọdani lọ́wọ́ àwọn ará Efuraimu. Nígbà tí ìsáǹsá ará Efuraimu kan bá ń sá bọ̀, tí ó bá sọ fún àwọn ará Gileadi pé, “Ẹ jẹ́ kí n rékọjá.” Àwọn ará Gileadi á bi í pé, “Ǹjẹ́ ará Efuraimu ni ọ́?” Bí ó bá sọ pé, “Rárá,”

6 wọn á ní kí ó pe, “Ṣiboleti.” Tí kò bá le pè é dáradára, tí ó bá wí pé, “Siboleti,” wọn á kì í mọ́lẹ̀, wọn á sì pa á létí odò Jọdani náà. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa (42,000) eniyan, ninu àwọn ará Efuraimu ní ọjọ́ náà.

7 Jẹfuta ṣe aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹfa. Nígbà tí ó ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Gileadi, ìlú rẹ̀.

Ibisani, Eloni ati Abidoni

8 Lẹ́yìn Jẹfuta, Ibisani ará Bẹtilẹhẹmu ni aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli.

9 Ó bí ọmọkunrin mejilelọgbọn, ó sì ní ọgbọ̀n ọmọbinrin. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin fọ́kọ láàrin àwọn tí wọn kì í ṣe ìbátan rẹ̀, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin láti inú ẹ̀yà mìíràn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ó jẹ́ aṣiwaju ní Israẹli fún ọdún meje.

10 Nígbà tí Ibisani ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Bẹtilẹhẹmu.

11 Lẹ́yìn Ibisani, Eloni, láti inú ẹ̀yà Sebuluni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹ́wàá.

12 Nígbà tí Eloni ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.

13 Lẹ́yìn rẹ̀, Abidoni, ọmọ Hileli, ará Piratoni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli.

14 Ó ní ogoji ọmọkunrin ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ lọkunrin, tí wọn ń gun aadọrin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹjọ.

15 Lẹ́yìn náà, Abidoni ọmọ Hileli ará Piratoni ṣaláìsí, wọ́n sì sin ín sí Piratoni, ní ilẹ̀ Efuraimu, ní agbègbè olókè àwọn ará Amaleki.