Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 23

Yíyọ Orúkọ Eniyan kúrò ninu Orúkọ Àwọn Eniyan OLUWA

1 “Ọkunrin tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tabi tí wọ́n bá gé nǹkan ọkunrin rẹ̀, kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.

2 “Ọmọ àlè kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.

3 “Ará Amoni ati Moabu kankan kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ, arọmọdọmọ wọn títí dé ìran kẹwaa kò gbọdọ̀ bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ;

4 nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè.

5 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín kò fetí sí ti Balaamu, ó yí èpè náà sí ìre fun yín nítorí pé ó fẹ́ràn yín.

6 Ẹ kò gbọdọ̀ ro ire kàn wọ́n tabi kí ẹ wá ìtẹ̀síwájú wọn títí lae.

7 “Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ọmọ Edomu, nítorí pé arakunrin yín ni wọ́n. Ẹ kò gbọdọ̀ kórìíra àwọn ará Ijipti nítorí pé ẹ ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ wọn rí.

8 Bẹ̀rẹ̀ láti ìran kẹta wọn, wọ́n lè bá ìjọ eniyan OLUWA péjọ.

Jíjẹ́ Kí Àgọ́ Àwọn Ọmọ-ogun Wà ní Mímọ́

9 “Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí ẹ bá sì wà ninu àgọ́, ẹ níláti yẹra fún ohunkohun tíí ṣe ibi.

10 Bí ọkunrin kan bá wà ninu yín tí ó di aláìmọ́ nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i láàrin òru, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kúrò ninu àgọ́. Kò gbọdọ̀ wọ inú àgọ́ wá mọ́.

11 Ṣugbọn nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, kí ó wẹ̀. Nígbà tí oòrùn bá sì wọ̀, ó lè wọ inú àgọ́ wá.

12 “Ẹ gbọdọ̀ ní ibìkan lẹ́yìn àgọ́ tí ẹ óo máa yàgbẹ́ sí.

13 Kí olukuluku yín ní ọ̀pá kan, tí yóo máa dì mọ́ ara ohun ìjà rẹ̀, tí ó lè fi gbẹ́lẹ̀ nígbà tí ó bá fẹ́ yàgbẹ́; nígbà tí ó bá sì yàgbẹ́ tán, ọ̀pá yìí ni yóo fi wa erùpẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀.

14 Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín wà pẹlu yín ninu àgọ́ láti gbà yín là, ati láti jẹ́ kí ọwọ́ yín tẹ àwọn ọ̀tá yín. Nítorí náà, àgọ́ yín níláti jẹ́ mímọ́, kí OLUWA má baà rí ohunkohun tí ó jẹ́ àìmọ́ láàrin yín, kí ó sì yipada kúrò lọ́dọ̀ yín.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

15 “Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀.

16 Ẹ jẹ́ kí ó máa bá yín gbé, kí ó wà láàrin yín ninu èyíkéyìí tí ó bá yàn ninu àwọn ìlú yín. Ibi tí ó bá wù ú ni ó lè gbé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ni ín lára.

17 “Ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan Israẹli, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di alágbèrè ní ilé oriṣa kankan.

18 Ọkunrin tabi obinrin kankan kò gbọdọ̀ mú owó tí ó bá gbà ní ibi àgbèrè ṣíṣe wá sinu ilé OLUWA láti san ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́ tí ó bá jẹ́, nítorí pé, àgbèrè ṣíṣe jẹ́ ohun ìríra níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

19 “Tí ẹ̀yin ọmọ Israẹli bá yá ara yín lówó, tabi oúnjẹ tabi ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé lórí rẹ̀.

20 Bí ẹ bá yá àlejò ní nǹkan, ẹ lè gba èlé, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ yá arakunrin yín ní ohunkohun kí ẹ sì gba èlé, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.

21 “Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án.

22 Ṣugbọn tí ẹ kò bá jẹ́jẹ̀ẹ́ rárá, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fun yín.

23 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ti fínnúfẹ́dọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ ohunkohun fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti fi ẹnu yín ṣèlérí, ẹ sì níláti rí i pé, ẹ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.

24 “Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní ibi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, ẹ lè jẹ ìwọ̀nba èso àjàrà tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mú ẹyọkan lọ́wọ́ lọ.

25 Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 24

Kíkọ Iyawo sílẹ̀ ati Títún Igbeyawo ṣe

1 “Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ;

2 bí obinrin yìí bá lọ ní ọkọ mìíràn,

3 ṣugbọn tí kò tún wu ọkọ titun náà, tí òun náà tún já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì tún tì í jáde kúrò ninu ilé rẹ̀, tabi tí ọkọ keji tí obinrin yìí fẹ́ bá kú,

4 ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kò gbọdọ̀ gbà á pada mọ́ nítorí pé obinrin náà ti di aláìmọ́. Ohun ìríra ni èyí lójú OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

5 “Bí ọkunrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbeyawo, kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ojú ogun tabi kí á fún un ní iṣẹ́ ìlú ṣe, ó gbọdọ̀ wà ní òmìnira ninu ilé rẹ̀ fún ọdún kan gbáko, kí ó máa faramọ́ iyawo rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́.

6 “Bí ẹnikẹ́ni bá yá eniyan ní nǹkankan, kò gbọdọ̀ gba ọlọ tabi ọmọ ọlọ tí ẹni náà fi ń lọ ọkà gẹ́gẹ́ bíi ìdógò, nítorí pé bí ó bá gba èyíkéyìí ninu mejeeji, bí ìgbà tí ó gba ẹ̀mí eniyan ni.

7 “Bí ẹnìkan bá jí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbé, tí ó sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrú, tabi tí ó tà á, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa olúwarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ohun burúkú yìí kúrò láàrin yín.

8 “Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn.

9 Ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Miriamu nígbà tí ẹ̀ ń jáde ti ilẹ̀ Ijipti bọ̀.

10 “Tí ẹ bá yá ẹnìkejì yín ní nǹkankan, ẹ kò gbọdọ̀ wọ ilé rẹ̀ lọ láti wá ohun tí yóo fi dógò.

11 Ìta ni kí ẹ dúró sí, kí ẹ sì jẹ́ kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un wá fun yín.

12 Bí ó bá jẹ́ aláìní ni olúwarẹ̀, aṣọ tí ó bá fi dógò kò gbọdọ̀ sùn lọ́dọ̀ yín.

13 Ẹ gbọdọ̀ dá a pada fún un ní alẹ́, kí ó lè rí aṣọ fi bora sùn, kí ó lè súre fun yín. Èyí yóo jẹ́ ìwà òdodo lójú OLUWA Ọlọrun yín.

14 “Ẹ kò gbọdọ̀ rẹ́ alágbàṣe yín tí ó jẹ́ talaka ati aláìní jẹ, kì báà jẹ́ ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ yín, tabi àlejò tí ó ń gbé ọ̀kan ninu àwọn ìlú yín.

15 Lojoojumọ, kí oòrùn tó wọ̀, ni kí ẹ máa san owó iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ fún un, nítorí pé ó nílò owó yìí, kò sì sí ohun mìíràn tí ó gbẹ́kẹ̀lé. Bí ẹ kò bá san án fún un, yóo ké pe OLUWA, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn.

16 “Ẹ kò gbọdọ̀ pa baba dípò ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ pa ọmọ dípò baba, olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá dá.

17 “Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.

18 Ṣugbọn ẹ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada níbẹ̀, nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.

19 “Nígbà tí ẹ bá ń kórè ọkà ninu oko yín, tí ẹ bá gbàgbé ìdì ọkà kan sinu oko, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ gbé e. Ẹ fi sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín.

20 Bí ẹ bá ti ká èso olifi yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn aláìní baba ati àwọn opó.

21 Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba.

22 Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín láti ṣe èyí.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 25

1 “Bí èdè-àìyedè kan bá bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ meji, tí wọ́n bá lọ sí ilé ẹjọ́, tí àwọn adájọ́ sì dá ẹjọ́ náà fún wọn, tí wọ́n dá ẹni tí ó jàre láre, tí wọ́n sì dá ẹni tí ó jẹ̀bi lẹ́bi,

2 bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

3 Ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ nà án ju ogoji ẹgba lọ, ohun ìtìjú ni yóo jẹ́ fún un ní gbangba, bí wọ́n bá nà án jù bẹ́ẹ̀ lọ.

4 “Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà.

Ojúṣe Ẹni sí Arakunrin Ẹni Tí Ó Ṣaláìsí

5 “Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà.

6 Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli.

7 Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’

8 Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’

9 Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’

10 Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀.

Àwọn Òfin Mìíràn

11 “Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí,

12 gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá.

13 “O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.

14 O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.

15 Ṣugbọn ìwọ̀n ati òṣùnwọ̀n rẹ gbọdọ̀ péye, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ.

16 Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe aiṣootọ, ìríra ni lójú OLUWA Ọlọrun yín.

Òfin láti Pa Àwọn Ará Amaleki

17 “Ẹ ranti ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí yín nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti Ijipti.

18 Wọn kò bẹ̀rù Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n gbógun tì yín lójú ọ̀nà nígbà tí ó ti rẹ̀ yín, wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn.

19 Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 26

Ọrẹ Ìkórè

1 “Nígbà tí o bá dé orí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, tí o gbà á, tí o sì ń gbé inú rẹ̀,

2 mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

3 Tọ alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Mò ń wí fún OLUWA Ọlọrun mi lónìí pé, mo ti dé ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wa láti fún wa.’

4 “Alufaa yóo gba agbọ̀n èso náà ní ọwọ́ rẹ, yóo sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ.

5 Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí.

6 Àwọn ará Ijipti lò wá ní ìlò ìkà, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sì mú wa sìn bí ẹrú.

7 A bá kígbe pe OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa; ó gbọ́ ohùn wa, ó rí ìpọ́njú, ati ìṣẹ́, ati ìjìyà wa.

8 OLUWA fi agbára rẹ̀ kó wa jáde láti Ijipti, pẹlu àwọn iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu.

9 Ó kó wa wá sí ìhín, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí; ilẹ̀ tí ó ní ọ̀rá tí ó kún fún wàrà ati oyin.

10 Nítorí náà, nisinsinyii, mo mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí ìwọ OLUWA ti fi fún mi wá.’

“Lẹ́yìn náà, gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì sìn ín;

11 kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ fún ohun tí OLUWA fún ìwọ ati ìdílé rẹ, kí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín náà sì máa bá ọ ṣe àjọyọ̀.

12 “Ní ọdún kẹtakẹta, tíí ṣe ọdún ìdámẹ́wàá, tí o bá ti dá ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko rẹ, kí o kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, kí wọ́n lè máa jẹ àjẹyó ninu ìlú yín.

13 Lẹ́yìn náà, kí o wí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá tíí ṣe ohun ìyàsímímọ́ ni mo ti mú kúrò ninu ilé mi, mo sì ti fi fún àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àṣẹ tí o pa fún mi. N kò rú èyíkéyìí ninu àwọn òfin rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì gbàgbé wọn.

14 N kò jẹ ninu ìdámẹ́wàá mi nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò kó èyíkéyìí jáde kúrò ninu ilé mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, tabi kí n fi èyíkéyìí ninu wọn bọ òkú ọ̀run. Gbogbo ohun tí o wí ni mo ti ṣe, OLUWA Ọlọrun mi, mo sì ti pa gbogbo àṣẹ rẹ mọ́.

15 Bojúwo ilẹ̀ láti ibùgbé mímọ́ rẹ lọ́run, kí o sì bukun Israẹli, àwọn eniyan rẹ, ati ilẹ̀ tí o ti fi fún wa gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wa, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.’

Àwọn Eniyan OLUWA

16 “OLUWA Ọlọrun rẹ pàṣẹ fún ọ lónìí, pé kí o máa pa gbogbo ìlànà ati òfin wọnyi mọ́. Nítorí náà, máa pa gbogbo wọn mọ́ tọkàntọkàn.

17 O ti fi ẹnu ara rẹ sọ lónìí pé, OLUWA ni Ọlọrun rẹ, ati pé o óo máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, o óo máa pa gbogbo ìlànà ati òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, o óo sì máa gbọ́ tirẹ̀.

18 OLUWA pàápàá sì ti sọ lónìí pé, eniyan òun ni ọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ, ati pé kí o pa gbogbo òfin òun mọ́.

19 Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.”

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 27

Ìlànà nípa Kíkọ Òfin Ọlọrun Sára Òkúta

1 Mose, pẹlu gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́.

2 Ní ọjọ́ tí ẹ bá kọjá odò Jọdani, tí ẹ bá ti wọ inú ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ẹ to òkúta ńláńlá jọ kí ẹ fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.

3 Ẹ kọ gbogbo òfin wọnyi sára rẹ̀, nígbà tí ẹ bá ń rékọjá lọ láti wọ ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣèlérí fun yín.

4 Nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, ẹ to àwọn òkúta tí mo paláṣẹ fun yín lónìí jọ lórí òkè Ebali, kí ẹ sì fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.

5 Ẹ fi òkúta kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀; ẹ kò gbọdọ̀ fi irin gbẹ́ òkúta náà rárá.

6 Òkúta tí wọn kò gbẹ́ ni kí ẹ fi kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun yín kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí i lórí rẹ̀.

7 Ẹ rú ẹbọ alaafia, kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

8 Ẹ kọ gbogbo àwọn òfin wọnyi sára òkúta náà, ẹ kọ wọ́n kí wọ́n hàn ketekete.”

9 Mose ati àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá wí fún gbogbo ọmọ Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, òní ni ẹ di eniyan OLUWA Ọlọrun yín.

10 Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.”

Àwọn Ègún fún Àìgbọràn

11 Mose bá pàṣẹ fún àwọn eniyan náà ní ọjọ́ kan náà, ó ní,

12 “Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre.

13 Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ti Aṣeri, ti Sebuluni, ti Dani ati ti Nafutali yóo sì dúró lórí òkè Ebali láti búra.

14 Àwọn ọmọ Lefi yóo wí ketekete fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé:

15 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’

“Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

16 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

17 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

18 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

19 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

20 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

21 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo dáhùn pé, ‘Amin.’

22 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tabi ọmọ baba rẹ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

23 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

24 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pa aládùúgbò rẹ̀ níkọ̀kọ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

25 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa aláìṣẹ̀.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

26 “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí kò bá pa gbogbo àwọn òfin yìí mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn.’

“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 28

Ibukun fún Ìgbọràn

1 “Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ.

2 Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ.

3 “OLUWA yóo bukun ọ ní ààrin ìlú, yóo sì bukun oko rẹ.

4 “Yóo bukun àwọn ọmọ rẹ, ati èso ilẹ̀ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àwọn ọmọ mààlúù rẹ, ati àwọn ọmọ aguntan rẹ.

5 “OLUWA yóo fi ibukun rẹ̀ sí orí ọkà rẹ, ati oúnjẹ rẹ.

6 “Yóo bukun ọ nígbà tí o bá ń wọlé, yóo sì tún bukun ọ nígbà tí o bá ń jáde.

7 “Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ.

8 “OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ.

9 “OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

10 Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ.

11 OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ.

12 OLUWA yóo fún ọ ní ọpọlọpọ òjò ní àkókò rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra rẹ̀ lójú ọ̀run, yóo sì bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ìwọ ni o óo máa yá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, o kò sì ní tọrọ lọ́wọ́ wọn.

13 OLUWA yóo fi ọ́ ṣe orí, o kò ní di ìrù; òkè ni o óo máa lọ, o kò ní di ẹni ilẹ̀; bí o bá pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ, tí mo pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, tí o mú gbogbo wọn ṣẹ lẹ́sẹẹsẹ,

14 tí o kò bá yipada ninu àwọn òfin tí mo ṣe fún ọ lónìí, tí o kò sì sá tọ àwọn oriṣa lọ, láti máa bọ wọ́n.

Ìjìyà fún Àìgbọràn

15 “Ṣugbọn bí o kò bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o kò sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, bí mo ti fi lélẹ̀ fún ọ lónìí, gbogbo àwọn ègún wọnyi ni yóo ṣẹ sí orí rẹ tí yóo sì mọ́ ọ.

16 “Ègún ni fún ọ ní ààrin ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.

17 “Ègún ni fún ọkà rẹ ati oúnjẹ rẹ.

18 “Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, ati fún èso ilẹ̀ rẹ ati fún àwọn ọmọ mààlúù rẹ ati àwọn ọmọ aguntan rẹ.

19 “Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé, ègún sì ni fún ọ nígbà tí o bá jáde.

20 “Bí o bá ṣe ibi, tí o kọ OLUWA sílẹ̀, ninu gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé, èmi OLUWA yóo da ègún lé ọ lórí, n óo sì mú ìdàrúdàpọ̀ ati wahala bá ọ, títí tí o óo fi parun patapata, láìpẹ́, láìjìnnà.

21 OLUWA yóo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ọ títí tí yóo fi pa ọ́ run patapata, lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti gbà.

22 OLUWA yóo fi àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ṣe ọ́, ati ibà, ìgbóná ati ooru; yóo sì rán ọ̀gbẹlẹ̀, ọ̀dá, ati ìrẹ̀dànù sí ohun ọ̀gbìn rẹ, títí tí o óo fi parun.

23 Òjò kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.

24 Dípò òjò, eruku ni yóo máa dà bò ọ́ láti ojú ọ̀run, títí tí o óo fi parun patapata.

25 “OLUWA yóo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ ṣẹgun rẹ. Bí o bá jáde sí wọn ní ọ̀nà kan, OLUWA yóo tú ọ ká níwájú wọn. Ọ̀rọ̀ rẹ yóo sì di ìyanu ati ẹ̀rù ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.

26 Òkú rẹ yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko tí ń káàkiri orí ilẹ̀ ayé, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí óo lé wọn kúrò.

27 OLUWA yóo da irú oówo tí ó fi bá àwọn ará Ijipti jà bò ọ́, ati egbò, èkúkú ati ẹ̀yi, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wòsàn.

28 OLUWA yóo da wèrè, ìfọ́jú, ati ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bò ọ́.

29 O óo máa táràrà lọ́sàn-án gangan bí afọ́jú. Kò ní dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọn yóo máa ni ọ́ lára, wọn yóo sì máa jà ọ́ lólè nígbà gbogbo; kò sì ní sí ẹnìkan láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

30 “O óo fẹ́ iyawo sọ́nà, ẹlòmíràn ni yóo máa bá a lòpọ̀. O óo kọ́ ilé, o kò sì ní gbé inú rẹ̀. O óo gbin ọgbà àjàrà, o kò sì ní jẹ ninu èso rẹ̀.

31 Wọn óo máa pa akọ mààlúù rẹ lójú rẹ, o kò ní fẹnu kàn ninu rẹ̀. Wọn óo fi tipátipá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lọ lójú rẹ, wọn kò sì ní dá a pada fún ọ mọ́. Àwọn aguntan yín yóo di ti àwọn ọ̀tá yín, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn yín lọ́wọ́.

32 Àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin óo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Ẹ óo retí wọn títí, ẹ kò ní gbúròó wọn, kò sì ní sí ohunkohun tí ẹ lè ṣe sí i.

33 Orílẹ̀-èdè tí ẹ kò mọ̀ rí ni yóo jẹ ohun ọ̀gbìn yín ati gbogbo làálàá yín ní àjẹrun. Ìnilára ati ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹ óo máa rí nígbà gbogbo,

34 tóbẹ́ẹ̀ tí ohun tí ẹ óo máa fi ojú yín rí yóo yà yín ní wèrè.

35 OLUWA yóo da oówo burúkú bò yín lẹ́sẹ̀ ati lórúnkún, yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wò yín sàn. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín títí dé àtàrí yín kìkì oówo ni yóo jẹ́.

36 “OLUWA yóo lé ẹ̀yin ati ẹni tí ẹ bá fi jọba yín lọ sí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa tí wọ́n fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀.

37 Ẹ óo di ẹni ìríra, ẹni àmúpòwe ati ẹni ẹ̀sín, láàrin gbogbo àwọn eniyan, níbi tí OLUWA yóo le yín lọ.

38 “Ọpọlọpọ èso ni ẹ óo máa gbìn sinu oko yín, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ óo máa rí ká, nítorí eṣú ni yóo máa jẹ wọ́n.

39 Ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò ní rí èso rẹ̀ ká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní mu ninu ọtí rẹ̀, nítorí pé àwọn kòkòrò yóo ti jẹ ẹ́.

40 Gbogbo ilẹ̀ yín yóo kún fún igi olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí òróró fi pa ara, nítorí pé rírẹ̀ ni èso olifi yín yóo máa rẹ̀ dànù.

41 Ẹ óo bí ọpọlọpọ ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn wọn kò ní jẹ́ tiyín, nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kó lẹ́rú lọ.

42 Gbogbo igi yín ati gbogbo èso ilẹ̀ yín ni yóo di ti àwọn eṣú.

43 “Àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín yóo máa níláárí jù yín lọ, ọwọ́ wọn yóo máa ròkè, ṣugbọn ní tiyín, ẹ óo di ẹni ilẹ̀ patapata.

44 Ọwọ́ àlejò yín ni ẹ óo ti máa tọrọ nǹkan, àwọn kò sì ní tọrọ ohunkohun lọ́wọ́ yín. Àwọn ni wọn yóo jẹ́ orí fun yín, ẹ̀yin yóo sì jẹ́ ìrù fún wọn.

45 “Gbogbo ègún wọnyi ni yóo ṣẹ si yín lára, tí yóo sì lẹ̀ mọ́ yín pẹ́kípẹ́kí títí tí ẹ óo fi parun, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò pa òfin rẹ̀ mọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tí ó pa láṣẹ fun yín.

46 Àwọn ègún náà yóo wà lórí yín gẹ́gẹ́ bí àmì ati ohun ìyanu, ati lórí àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

47 Nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun bukun yín, ẹ kọ̀, ẹ kò sìn ín pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn.

48 Nítorí náà, ní ìhòòhò, pẹlu ebi ati òùngbẹ, ati àìní ni ẹ óo fi máa sin àwọn ọ̀tá tí OLUWA yóo rán si yín, yóo sì la àjàgà irin bọ̀ yín lọ́rùn títí tí yóo fi pa yín run.

49 OLUWA yóo gbé orílẹ̀-èdè kan, tí ẹ kò gbọ́ èdè wọn, dìde si yín láti òpin ayé; wọn óo yára bí àṣá.

50 Ojú gbogbo wọn óo pọ́n kankan, wọn kò ní ṣàánú ọmọde, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní bọ̀wọ̀ fún àgbà.

51 Wọn yóo jẹ àwọn ọmọ ẹran yín ati èso ilẹ̀ yín títí tí ẹ óo fi parun patapata. Wọn kò ní ṣẹ́ nǹkankan kù fun yín ninu ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín, àwọn ọmọ mààlúù tabi ọmọ aguntan yín; títí tí wọn yóo fi jẹ yín run.

52 Gbogbo ìlú ńláńlá yín ni wọn óo dó tì, títí tí gbogbo odi gíga tí ẹ gbójúlé, tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá yín po, yóo fi wó lulẹ̀, ní gbogbo ilẹ̀ yín. Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín ni wọn yóo dó tì.

53 “Ojú yóo pọn yín tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá yin bá dó tì yín, tí yóo fi jẹ́ pé àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ni ẹ óo máa pa jẹ.

54 Ọkunrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn ọkunrin yín, yóo di ahun sí arakunrin rẹ̀, ati sí iyawo rẹ̀ tí ó fẹ́ràn jùlọ, ati sí ọmọ rẹ̀ tí ó kù ú kù,

55 tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní fún ẹnikẹ́ni jẹ ninu ẹran ara ọmọ rẹ̀ tí ó bá ń jẹ ẹ́; nítorí pé kò sí nǹkankan tí ó kù fún un mọ́, ninu ìnira tí àwọn ọ̀tá yín yóo kó yín sí nígbà tí wọ́n ba dó ti àwọn ìlú yín.

56 Obinrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn obinrin yín, tí kò jẹ́ fi ẹsẹ̀ lásán tẹ ilẹ̀ nítorí àwọ̀ rẹ̀ tí ó tutù ati ìwà afínjú rẹ̀, yóo di ahun sí ọkọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin.

57 Yóo bímọ tán, yóo sì jẹ ibi ọmọ tí ó jáde lára rẹ̀ ní kọ̀rọ̀, yóo sì tún jẹ ọmọ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, nítorí pé kò sí ohun tí ó lè jẹ mọ́, nítorí àwọn ọ̀tá yín tí yóo dó ti àwọn ìlú yín.

58 “Bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò tẹ̀lé gbogbo òfin tí a kọ sinu ìwé yìí, pé kí ẹ máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó lẹ́rù, tí ó sì lógo,

59 OLUWA yóo mú ìpọ́njú ńlá bá ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, ìpọ́njú ńlá ati àìsàn burúkú, tí yóo wà lára yín fún ìgbà pípẹ́.

60 Gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n bà yín lẹ́rù, ni OLUWA yóo dà bò yín, tí yóo sì wà lára yín.

61 Àwọn àìsàn mìíràn ati ìpọ́njú tí wọn kò kọ sinu ìwé òfin yìí ni OLUWA yóo dà bò yín títí tí ẹ óo fi parun.

62 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹ kò ni kù ju díẹ̀ lọ mọ́, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.

63 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ dídùn inú OLUWA láti ṣe yín ní rere ati láti sọ yín di pupọ, bákan náà ni yóo jẹ́ dídùn inú rẹ̀ láti ba yín kanlẹ̀ kí ó sì pa yín run. OLUWA yóo le yín kúrò lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.

64 OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí.

65 Ara kò ní rọ̀ yín rárá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí ìdí jókòó. OLUWA yóo mú jìnnìjìnnì ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ba yín, yóo sì mú kí ojú yín di bàìbàì.

66 Ninu hílàhílo ni ẹ óo máa wà nígbà gbogbo, ninu ẹ̀rù ati ìpayà ni ẹ óo máa wà tọ̀sán-tòru.

67 Àwọn ohun tí ojú yín yóo máa rí yóo kó ìpayà ati ẹ̀rù ba yín, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ilẹ̀ bá ti ṣú, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti mọ́; bí ilẹ̀ bá sì ti tún mọ́, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti ṣú.

68 Ọkọ̀ ojú omi ni OLUWA yóo fi ko yín pada sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí mo ti ṣèlérí pé ẹ kò ní pada sí mọ́ lae. Nígbà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ óo fa ara yín kalẹ̀ fún títà gẹ́gẹ́ bí ẹrú, lọkunrin ati lobinrin, ṣugbọn ẹ kò ní rí ẹni rà yín.”

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 29

Àdéhùn OLUWA pẹlu Israẹli ní Ilẹ̀ Moabu

1 OLUWA pàṣẹ fún Mose pé kí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu mìíràn ní ilẹ̀ Moabu, yàtọ̀ sí èyí tí ó ti bá wọn dá ní òkè Horebu.

2 Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí OLUWA ṣe sí Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti.

3 Ẹ fi ojú yín rí àwọn ìdààmú ńláńlá tí ó bá wọn, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe.

4 Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn.

5 Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀.

6 Ẹ kò jẹ oúnjẹ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA ni OLUWA Ọlọrun yín.

7 Nígbà tí ẹ dé ibí yìí, Sihoni, ọba Heṣiboni ati Ogu, ọba Baṣani gbógun tì wá, ṣugbọn a ṣẹgun wọn.

8 A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn.

9 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere.

10 “Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli.

11 Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àwọn aya yín, ati àwọn àlejò tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ yín; àwọn tí wọn ń wá igi fun yín, ati àwọn tí wọn ń pọnmi fun yín.

12 Kí gbogbo yín lè bá OLUWA Ọlọrun yín dá majẹmu lónìí,

13 kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín.

14 ‘Kìí ṣe ẹ̀yin nìkan ni mò ń bá dá majẹmu yìí, tí mo sì ń búra fún,

15 ṣugbọn ati àwọn tí wọn kò sí níhìn-ín lónìí, ati ẹ̀yin alára tí ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ni majẹmu náà wà fún.’

16 “Ẹ̀yin náà mọ̀ bí ayé wa ti rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati bí a ti la ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà kọjá.

17 Ẹ sì ti rí àwọn ohun ìríra wọn: àwọn oriṣa wọn tí wọ́n fi igi gbẹ́, èyí tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, èyí tí wọ́n fi fadaka ṣe, ati èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe.

18 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu.

19 Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere.

20 OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé.

21 OLUWA yóo dojú kọ òun nìkan, láti ṣe é ní ibi láàrin gbogbo ẹ̀yà Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ègún tí ó wà ninu majẹmu, tí a kọ sinu ìwé òfin yìí.

22 “Nígbà tí àwọn arọmọdọmọ yín tí wọn kò tíì bí, ati àwọn àlejò tí wọ́n bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè bá rí ìpọ́njú, ati àrùn tí OLUWA yóo dà bo ilẹ̀ náà,

23 tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́,

24 gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ ilẹ̀ yìí dà báyìí? Kí ló dé tí ibinu ńlá OLUWA fi dé sórí ilẹ̀ yìí?’

25 Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọn kò mú majẹmu OLUWA Ọlọrun ṣẹ, tí ó bá àwọn baba wọn dá nígbà tí ó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Ijipti.

26 Wọ́n ń bọ àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí OLUWA kò sì fi lé wọn lọ́wọ́.

27 Ìdí nìyí tí inú fi bí OLUWA sí ilẹ̀ yìí, tí ó sì mú gbogbo ègún tí a kọ sinu ìwé yìí ṣẹ lé wọn lórí.

28 OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’

29 “Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 30

Ìpadà-bọ̀-sípò ati Ibukun Israẹli

1 “Nígbà tí gbogbo àwọn ibukun tabi ègún tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín lónìí bá ṣẹ mọ́ yín lára, tí ẹ bá dé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí, tí ẹ bá ranti anfaani tí ẹ ti sọnù,

2 tí ẹ bá yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín; tí ẹ bá tún ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé gbogbo òfin tí mo ṣe fun yín lónìí,

3 OLUWA Ọlọrun yín yóo dá ibukun yín pada, yóo ṣàánú yín, yóo sì tún ko yín pada láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó fọn yín ká sí.

4 Ibi yòówù tí OLUWA bá fọn yín ká sí ninu ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ òpin ayé, OLUWA yóo wa yín rí, yóo sì ko yín jọ.

5 OLUWA Ọlọrun yín yóo tún da yín pada sí ilẹ̀ àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo tún pada di tiyín, OLUWA yóo mú kí ó dára fun yín, yóo mú kí ẹ pọ̀ ju àwọn baba yín lọ.

6 OLUWA Ọlọrun yín yóo fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín ní ẹ̀mí ìgbọràn tí ó fi jẹ́ pé ẹ óo fẹ́ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, ẹ óo sì wà láàyè.

7 OLUWA Ọlọrun yín yóo da àwọn ègún wọnyi sórí àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín.

8 Ẹ óo tún máa gbọ́ ti OLUWA, ẹ óo sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ tí mò ń fun yín lónìí mọ́.

9 OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín lọpọlọpọ, ati àwọn ọmọ yín; àwọn ọmọ mààlúù yín, ati àwọn ohun ọ̀gbìn yín, nítorí inú OLUWA yóo tún dùn láti bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe inú dídùn sí àwọn baba yín,

10 bí ẹ bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin yìí, tí ẹ bá sì yipada tọkàntọkàn.

11 “Nítorí pé òfin tí mo fun yín lónìí kò le jù fun yín, kì í sìí ṣe ohun tí apá yín kò ká.

12 Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

14 Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é.

15 “Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀.

16 Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín.

17 Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,

18 mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín.

19 Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè.

20 Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.”

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 31

Joṣua Gba Ipò Mose

1 Mose tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.

2 Ó ní, “Òní ni mo di ẹni ọgọfa ọdún (120), kò ní ṣeéṣe fún mi mọ́, láti máa fò síhìn-ín sọ́hùn-ún. OLUWA ti wí fún mi pé, n kò ní gun òkè odò Jọdani yìí.

3 OLUWA Ọlọrun yín tìkalára rẹ̀ ni yóo ṣiwaju yín lọ, yóo ba yín pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà run, tí ẹ ó fi lè gba ilẹ̀ wọn. Joṣua ni yóo sì jẹ́ olórí, tí yóo máa ṣiwaju yín lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.

4 Bí OLUWA ti ṣe sí Sihoni ati Ogu, ọba àwọn ará Amori, tí ó pa wọ́n run tàwọn ti ilẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni yóo ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí.

5 OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣe wọ́n bí mo ti pa á láṣẹ fun yín ninu òfin tí mo fun yín.

6 Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mú ọkàn gidigidi. Ẹ má bẹ̀rù rárá, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò yín; nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ. Kò ní já yín kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi yín sílẹ̀.”

7 Mose bá pe Joṣua, ó sọ fún un níwájú gbogbo àwọn eniyan Israẹli, pé, “Múra gírí, kí o sì mú ọkàn gidigidi nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn eniyan wọnyi lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun ti búra fún àwọn baba wọn pé òun yóo fi fún wọn. Ìwọ ni o óo sì fi lé wọn lọ́wọ́.

8 OLUWA Ọlọrun tìkalárarẹ̀ ni yóo máa ṣiwaju rẹ lọ, yóo sì máa wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí àyà fò ọ́.”

Kíka Òfin ní Ọdún Keje-keje

9 Mose bá kọ òfin yìí sílẹ̀, ó fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.

10 Mose bá pàṣẹ fún wọn pé, “Ní ìparí ọdún keje-keje, ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún ọdún ìdásílẹ̀, ní àkókò àjọ̀dún àgọ́,

11 nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sin OLUWA ní ibi tí ó yàn pé kí wọ́n ti máa sin òun, o gbọdọ̀ máa ka òfin yìí sí etígbọ̀ọ́ gbogbo wọn.

12 Pe àwọn eniyan náà jọ, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àgbà, ati onílé ati àlejò, tí ó wà ninu ìlú yín, kí wọ́n lè gbọ́, kí wọ́n sì kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí wọ́n sì máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ninu òfin yìí.

13 Kí àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ̀ ọ́n lè gbọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ sí òkè odò Jọdani láti gbà.”

Ìlànà Ìkẹyìn Tí OLUWA fún Mose

14 OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ.

15 OLUWA fi ara hàn wọ́n ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu ninu àgọ́ náà. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà wà ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àgọ́.

16 OLUWA tún sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ àtisùn rẹ kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn eniyan wọnyi yóo lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn ará ilẹ̀ náà ń bọ. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu tí mo bá wọn dá.

17 Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’

18 Láìṣe àní àní, n óo mú ojú kúrò lára wọn ní ọjọ́ náà, nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, nítorí pé wọ́n ti yipada, wọ́n sì ń bọ oriṣa.

19 “Nítorí náà, kọ orin yìí sílẹ̀ nisinsinyii kí o sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kí orin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi lọ́dọ̀ wọn.

20 Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi.

21 Nígbà tí ọpọlọpọ ibi ati wahala bá dé bá wọn, orin yìí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn (nítorí pé arọmọdọmọ wọn yóo máa kọ ọ́, wọn kò sì ní gbàgbé rẹ̀); nítorí pé mo mọ ète tí wọn ń pa, kí ó tilẹ̀ tó di pé mo mú wọn wọ ilẹ̀ tí mo búra láti fún wọn.”

22 Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

23 OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.”

24 Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata,

25 ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA,

26 ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín;

27 nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán.

28 Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn.

29 Nítorí mo mọ̀ dájú pé gẹ́rẹ́ tí mo bá kú tán, ìṣekúṣe ni ẹ óo máa ṣe, ẹ óo sì yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fun yín, ibi ni yóo sì ba yín ní ọjọ́ iwájú, nítorí pé ẹ óo ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Iṣẹ́ ọwọ́ yín yóo sì mú un bínú.”

Orin Mose

30 Mose ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà patapata sí etígbọ̀ọ́ àpéjọ àwọn ọmọ Israẹli.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 32

1 Ó ní:

“Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;

gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé.

2 Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò,

àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn;

kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì,

bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára.

3 Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA,

àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀.

4 “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín,

gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́.

Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe,

ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.

5 Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i,

ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́,

nítorí àbùkù yín;

ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí.

6 Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí,

ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi?

Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín,

Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀.

7 “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́,

ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá.

Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín,

Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín,

wọn yóo sì sọ fun yín.

8 Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè,

ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé,

gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

9 Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀,

ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀.

10 “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn,

níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn.

Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn,

Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀.

11 Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká,

láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò,

tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọn

tí wọ́n bá fẹ́ já bọ́,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli.

12 OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀,

láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan.

13 “Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé,

ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ.

Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta,

ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta.

14 Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn,

ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn,

ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò,

ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́,

ati ọkà tí ó dára jùlọ,

ati ọpọlọpọ ọtí waini.

15 “Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán,

ẹ wá tàpá sí àṣẹ;

ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára;

ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín,

ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín!

16 Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú;

wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè.

17 Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú,

Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí,

tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí.

18 Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín,

ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín.

19 “Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe,

ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀,

nítorí pé, wọ́n mú un bínú.

20 Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn,

n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.

Nítorí olóríkunkun ni wọ́n,

àwọn alaiṣootọ ọmọ!

21 Nítorí oriṣa lásánlàsàn,

wọn sọ èmi Ọlọrun di òjòwú;

wọn sì ti fi àwọn ère wọn mú mi bínú.

Nítorí náà, èmi náà óo lo àwọn eniyan lásánlàsàn

láti mu àwọn náà jowú,

n óo sì lo aṣiwèrè orílẹ̀-èdè lásánlàsàn kan

láti mú wọn bínú.

22 Nítorí iná ibinu mi ń jó,

yóo sì jó títí dé isà òkú.

Yóo jó ayé ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu rẹ̀ ní àjórun,

tó fi mọ́ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

23 “ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn,

n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn.

24 N óo fi ebi pa wọ́n ní àpakú,

iná yóo jó wọn ní àjórun,

n óo sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run.

N óo jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú pa wọ́n jẹ,

n óo sì jẹ́ kí àwọn ejò olóró bù wọ́n ṣán.

25 Bí idà tí ń pa àwọn kan lójú pópó,

bẹ́ẹ̀ ni ikú yóo di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀dẹ̀dẹ̀.

Bó ti ń pa àwọn ọdọmọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa pa àwọn ọdọmọbinrin,

ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ati àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́,

gbogbo wọn ni ikú gbígbóná yóo máa mú lọ.

26 Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri,

kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́,

27 ti àwọn ọ̀tá wọn ni mo rò,

nítorí pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọn yóo máa wí kiri.

Wọn yóo máa wí pé,

“Àwa ni a ṣẹgun wọn,

kìí ṣe OLUWA ló ṣe é rárá.” ’

28 “Nítorí pé aláìlérò orílẹ̀-èdè ni Israẹli,

òye kò sì yé wọn rárá.

29 Bí ó bá ṣe pé wọ́n gbọ́n ni,

tí òye sì yé wọn;

wọn ì bá ti mọ̀ bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí.

30 Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan?

Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá?

Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀,

tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.

31 Nítorí pé, àwọn ọ̀tá wọn pàápàá mọ̀ pé,

Ọlọrun, aláàbò Israẹli, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn oriṣa wọn.

32 Àwọn ọ̀tá wọn ti bàjẹ́ bíi Sodomu ati Gomora,

wọ́n dàbí àjàrà tí ń so èso tí ó korò tí ó sì lóró.

33 Oró ejò ni ọtí wọn,

àní oró paramọ́lẹ̀ tíí ṣe ikú pani.

34 “Èmi OLUWA kò gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá wọn ṣe,

ṣebí gbogbo rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ lọ́dọ̀ mi?

35 Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san,

nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú.

Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀,

ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá.

36 Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,

yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀,

nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́,

ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn,

tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn,

kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.

37 Nígbà náà ni yóo bi wọ́n pé,

‘Níbo ni àwọn oriṣa yin wà,

ati àpáta tí ẹ fi ṣe ààbò yin?

38 Ṣebí àwọn ni ẹ fún ní ọ̀rá ẹran ìrúbọ yín,

àwọn ni ẹ sì rú ẹbọ ohun mímu yín sí?

Kí wọ́n dìde, kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ nisinsinyii,

kí wọ́n sì dáàbò bò yín.

39 “ ‘Ṣé ẹ wá rí i nisinsinyii pé,

èmi nìkan ṣoṣo ni Ọlọrun,

kò sí ọlọrun mìíràn mọ, lẹ́yìn mi.

Mo lè pa eniyan,

mo sì lè sọ ọ́ di ààyè.

Mo lè ṣá eniyan lọ́gbẹ́,

mo sì lè wò ó sàn.

Bí mo bá gbá eniyan mú,

kò sí ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.

40 Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè,

mo fi ara mi búra.

41 Nígbà tí mo bá pọ́n idà mi,

tí ó ń kọ yànrànyànràn,

n óo fà á yọ láti fi ṣe ẹ̀tọ́.

N óo gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,

n óo sì jẹ àwọn tí wọ́n kórìíra mi níyà.

42 Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀,

yóo sì mu àmuyó.

Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi.

N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí,

ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́,

ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn,

gbogbo wọn ni n óo pa.’

43 “Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA,

gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀.

Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà,

yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”

44 Mose wá, ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan náà, òun ati Joṣua ọmọ Nuni.

Ìlànà Ìkẹyìn tí Mose fún Wọn

45 Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán,

46 ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ.

47 Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.”

48 OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé,

49 “Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli.

50 Orí òkè Nebo yìí ni o óo kú sí, bí Aaroni arakunrin rẹ ṣe kú lórí òkè Hori.

51 Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.

52 Nítorí náà, o óo fi ojú rí ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹsẹ̀ rẹ kò ní tẹ ilẹ̀ tí n ó fún àwọn eniyan Israẹli.”