Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 13

1 “Bí ẹnìkan bá di wolii láàrin yín, tabi tí ó ń lá àlá, tí ń sọ nípa àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí yóo ṣẹlẹ̀,

2 tí gbogbo nǹkan tí ó ń sọ sì ń rí bẹ́ẹ̀; bí ó bá wí pé kí ẹ wá lọ bọ oriṣa mìíràn tí ẹ kò mọ̀ rí,

3 ẹ kò gbọdọ̀ dá wolii tabi alálàá náà lóhùn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ń dán yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn òun tọkàntọkàn.

4 OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa tẹ̀lé, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù. Ẹ máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì máa gbọ́ tirẹ̀; ẹ máa sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.

5 Ṣugbọn pípa ni kí ẹ pa wolii tabi alálàá náà, nítorí pé ó ń kọ yín láti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú. Ẹ níláti pa olúwarẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ mú kí ẹ kọ ẹ̀yìn sí ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti là sílẹ̀ fun yín láti máa rìn, nítorí náà ẹ gbọdọ̀ yọ nǹkan burúkú náà kúrò láàrin yín.

6 “Bí ẹnikẹ́ni bá ń tàn ọ́ níkọ̀kọ̀ pé kí o lọ bọ oriṣa-koriṣa kan, tí ìwọ tabi àwọn baba rẹ kò bọ rí, olúwarẹ̀ kì báà jẹ́ arakunrin rẹ, tíí ṣe ọmọ ìyá rẹ, tabi ọmọ rẹ, lọkunrin tabi lobinrin, tabi aya rẹ, tí ó dàbí ẹyin ojú rẹ, tabi ọ̀rẹ́ rẹ tí o fẹ́ràn ju ẹ̀mí ara rẹ lọ;

7 oriṣa yìí kì báà jẹ́ èyí tí ó wà nítòsí, tí àwọn ará agbègbè yín ń bọ, tabi èyí tí ó jìnnà réré, tí àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèèrè ń bọ.

8 O kò gbọdọ̀ gbọ́ tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. O kò gbọdọ̀ ṣàánú fún un, o kò sì gbọdọ̀ bò ó.

9 Pípa ni kí o pa á, ìwọ gan-an ni kí o kọ́ sọ òkúta lù ú, kí àwọn eniyan yòókù tó kó òkúta bò ó.

10 Ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí tí ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti.

11 Gbogbo ọmọ Israẹli yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo sì bà wọ́n, ẹnikẹ́ni kò sì ní hu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín.

12 “Bí ẹ bá gbọ́, ní ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti máa gbé, pé,

13 àwọn eniyan lásán kan láàrin yín ń tan àwọn ará ìlú náà jẹ, wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ bọ oriṣa.’

14 Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ó sì dáa yín lójú pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín,

15 idà ni kí ẹ fi pa àwọn tí wọn ń gbé ìlú náà. Ẹ pa wọ́n run patapata, ati gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀; ẹ fi idà pa gbogbo wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.

16 Ẹ kó gbogbo ìkógun tí ẹ bá rí ninu ìlú náà jọ sí ààrin ìgboro rẹ̀, kí ẹ sì dáná sun gbogbo rẹ̀ bí ẹbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun yín. Ìlú náà yóo di àlàpà títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ tún un kọ́ mọ́.

17 Àwọn ìkógun yìí jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu wọn kí OLUWA lè yí ibinu gbígbóná rẹ̀ pada, kí ó ṣàánú fun yín, kí ó sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín.

18 Ẹ máa gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 14

Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀

1 “Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú.

2 Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.

Ẹran Tí Ó Mọ́ ati Èyí Tí Kò Mọ́

3 “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ ohun ìríra.

4 Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìwọ̀nyí: mààlúù, aguntan,

5 ewúrẹ́, àgbọ̀nrín ati èsúó ati ìgalà, ati oríṣìí ẹranko igbó kan tí ó dàbí ewúrẹ́, ati ẹranko kan tí wọn ń pè ní Pigarigi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu.

6 Àwọn ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji, tabi tí wọ́n bá ní ìka ẹsẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ àpọ̀jẹ, irú wọn ni kí ẹ máa jẹ.

7 Ṣugbọn ninu àwọn ẹran tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ ati àwọn tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji tabi tí wọ́n ní ìka ẹsẹ̀, àwọn wọnyi ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: ràkúnmí, ati ehoro ati ẹranko kan tí ó dàbí gara. Àwọn wọnyi ń jẹ àpọ̀jẹ lóòótọ́, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ wọn kò là, nítorí náà, wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

8 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn.

9 “Ninu gbogbo àwọn abẹ̀mí tí ó wà ninu omi, àwọn wọnyi ni kí ẹ máa jẹ: gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ.

10 Ṣugbọn èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n, nítorí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

11 “Ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ẹyẹ tí wọ́n bá mọ́.

12 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ wọnyi: ẹyẹ idì, igún ati idì tí ń jẹ ẹja,

13 ati àṣá gidi, ati oríṣìíríṣìí àṣá mìíràn, ati igún gidi, ati àwọn oríṣìíríṣìí igún yòókù,

14 ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ ìwò,

15 ati ògòǹgò, ati òwìwí, ati ẹ̀lulùú, ati oríṣìíríṣìí àwòdì,

16 ati òwìwí ńlá, ati òwìwí kéékèèké, ati ògbúgbú,

17 ati ẹyẹ òfù, ati àkàlà, ati ẹyẹ ìgo,

18 ati ẹyẹ àkọ̀, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ òòdẹ̀, ati ẹyẹ atọ́ka, ati àdán.

19 “Gbogbo àwọn kòkòrò tí wọn ń fò jẹ́ aláìmọ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.

20 Ṣugbọn ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní ìyẹ́, tí wọ́n sì mọ́.

21 “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrarẹ̀, ẹ lè fún àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín, kí ó jẹ ẹ́, tabi kí ẹ tà á fún àjèjì, nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ ẹni mímọ́ fún OLUWA Ọlọrun yín.

“Ẹ kò gbọdọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ ninu wàrà ọmú ìyá rẹ̀.

Òfin nípa Ìdámẹ́wàá

22 “Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún.

23 Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo.

24 Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ,

25 ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

26 Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín.

27 “Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin yín nítorí pé, wọn kò ní ìpín tabi ohun ìní láàrin yín.

28 Ní òpin ọdún kẹtakẹta, ẹ níláti kó ìdámẹ́wàá ìkórè gbogbo oko yín ti ọdún náà jọ, kí ẹ kó wọn kalẹ̀ ninu gbogbo àwọn ìlú yín.

29 Kí àwọn ọmọ Lefi, tí wọn kò ní ìpín ati ohun ìní láàrin yín, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó tí wọ́n wà ninu àwọn ìlú yín jẹ, kí wọ́n sì yó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 15

Ọdún Keje

1 “Ní ọdún keje-keje ni kí ẹ máa ṣe ìdásílẹ̀.

2 Bí ẹ óo ṣe máa ṣe ìdásílẹ̀ náà nìyí: ẹnikẹ́ni tí aládùúgbò rẹ̀, tíí ṣe arakunrin rẹ̀, bá jẹ ní gbèsè kò ní gba ohun tí aládùúgbò rẹ̀ jẹ ẹ́ mọ́, nítorí pé, a ti kéde ìdásílẹ̀ tíí ṣe ti OLUWA.

3 Bí ó bá jẹ́ pé àlejò ni ó jẹ ẹni náà ní gbèsè, olúwarẹ̀ lè gbà á, ṣugbọn ohunkohun tí ó bá jẹ́ tiyín, tí ó wà lọ́wọ́ arakunrin yín, ẹ kò gbọdọ̀ gbà á pada.

4 “Ṣugbọn kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo jẹ́ talaka, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín, ní ilẹ̀ tí ó fun yín láti gbà,

5 bí ẹ bá sá ti gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì farabalẹ̀, ti ẹ tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.

6 Nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Ẹ óo máa yá àwọn orílẹ̀-èdè ni nǹkan, ṣugbọn ẹ kò ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. Ẹ óo máa jọba lórí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ṣugbọn wọn kò ní jọba lórí yín.

7 “Bí ẹnìkan ninu yín, tí ó jẹ́ arakunrin yín, bá jẹ́ talaka, tí ó sì wà ninu ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ dijú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ háwọ́ sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka yìí.

8 Ẹ gbọdọ̀ lawọ́ sí i, kí ẹ sì yá a ní ohun tí ó tó láti tán gbogbo àìní rẹ̀, ohunkohun tí ó wù kí ó lè jẹ́.

9 Ẹ ṣọ́ra, kí èròkerò má baà gba ọkàn yín, kí ẹ wí pé, ọdún keje tíí ṣe ọdún ìdásílẹ̀ ti súnmọ́ tòsí, kí ojú yín sì le sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka, kí ẹ má sì fún un ní ohunkohun. Kí ó má baà ké pe OLUWA nítorí yín, kí ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ si yín lọ́rùn.

10 Ẹ fún un ní ohun tí ẹ bá fẹ́ fún un tọkàntọkàn, kì í ṣe pẹlu ìkùnsínú, nítorí pé, nítorí ìdí èyí ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín ati gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé.

11 Nítorí pé, talaka kò ní tán lórí ilẹ̀ yín, nítorí náà ni mo ṣe ń pàṣẹ fun yín pé kí ẹ lawọ́ sí arakunrin yín, ati sí talaka ati sí aláìní ní ilẹ̀ náà.

Ìlò Ẹrú

12 “Bí wọ́n bá ta arakunrin yín lẹ́rú fun yín, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, tí ó bá ti jẹ́ Heberu, ọdún mẹfa ni yóo fi sìn yín. Tí ó bá di ọdún keje, ẹ gbọdọ̀ dá a sílẹ̀, kí ó sì máa lọ.

13 Nígbà tí ẹ bá dá a sílẹ̀ pé kí ó máa lọ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ ní ọwọ́ òfo.

14 Ẹ gbọdọ̀ fún un ní ẹran ọ̀sìn lọpọlọpọ ati ọkà láti inú ibi ìpakà yín, ati ọtí waini. Bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe fún un tó.

15 Ẹ gbọdọ̀ ranti pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA Ọlọrun yín ni ó rà yín pada; nítorí náà ni mo fi ń pàṣẹ fun yín lónìí.

16 “Ṣugbọn tí ó bá wí fun yín pé, òun kò ní jáde ninu ilé yín, nítorí pé ó fẹ́ràn ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín, nítorí pé ó dára fún un nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ yín,

17 ẹ mú ìlutí kan, kí ẹ fi lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn. Yóo sì jẹ́ ẹrukunrin yín títí lae. Bí ó bá sì jẹ́ obinrin ni, bákan náà ni kí ẹ ṣe fún un.

18 Má jẹ́ kí ó ni ọ́ lára láti dá a sílẹ̀ kí ó sì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé, ìdajì owó ọ̀yà alágbàṣe ni ó ti fi ń sìn ọ́, fún odidi ọdún mẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

Àkọ́bí Mààlúù ati ti Aguntan

19 “Gbogbo àkọ́bí tí ẹran ọ̀sìn bá bí ninu agbo ẹran yín, tí ó bá jẹ́ akọ ni ẹ gbọdọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí ninu agbo mààlúù yín ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ rẹ́ irun àgbò tí ó jẹ́ àkọ́bí aguntan yín.

20 Níbikíbi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn, ni ẹ ti gbọdọ̀ máa jẹ wọ́n níwájú rẹ̀, ní ọdọọdún; ẹ̀yin ati gbogbo ilé yín.

21 Ṣugbọn bí ó bá ní àbààwọ́n kan, bóyá ó jẹ́ arọ ni, tabi afọ́jú, tabi ó ní àbààwọ́n kankan, ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín,

22 jíjẹ ni kí ẹ jẹ ẹ́ ní ààrin ìlú yín, ati àwọn tí wọ́n mọ́, ati àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ ni wọ́n lè jẹ ninu rẹ̀, bí ìgbà tí eniyan jẹ ẹran èsúó tabi àgbọ̀nrín ni.

23 Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ; dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 16

Àjọ Ìrékọjá

1 “Ẹ máa ranti láti máa ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá fún OLUWA Ọlọrun yín ninu oṣù Abibu nítorí ninu oṣù Abibu ni ó kó yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, lálẹ́.

2 Ẹ níláti máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá sí OLUWA Ọlọrun yín láti inú agbo mààlúù yín, tabi agbo aguntan yín, níbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

3 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.

4 Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

5 “Ẹ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ àjọ ìrékọjá láàrin èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín.

6 Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

7 Bíbọ̀ ni kí ẹ bọ̀ ọ́, kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nígbà tí ó bá sì di òwúrọ̀ ẹ óo pada lọ sinu àgọ́ yín.

8 Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní ọjọ́ keje, ẹ óo pe àpèjọ tí ó ní ọ̀wọ̀, ẹ óo sì sin OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà.

Àjọ̀dún Ìkórè

9 “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e.

10 Nígbà náà, ẹ óo ṣe àsè àjọ ọ̀sẹ̀, tíí ṣe àjọ̀dún ìkórè fún OLUWA Ọlọrun yín; pẹlu ọrẹ àtinúwá. Ẹ óo mú ọrẹ náà wá bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín.

11 Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín.

12 Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà wọnyi.

Àjọ̀dún Àgọ́

13 “Ọjọ́ meje ni ẹ gbọdọ̀ máa fi se àsè àjọ̀dún àgọ́ nígbà tí ẹ bá kó ọkà yín jọ láti ibi ìpakà, tí ẹ kó ọtí waini yín jọ láti ibi ìfúntí.

14 Ẹ máa yọ̀, bí ẹ ti ń gbádùn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin, ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin ati àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, àwọn ọmọ Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà ní àwọn ìlú yín.

15 Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi se àsè yìí fún OLUWA Ọlọrun yín níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun gbogbo èso yín, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo láyọ̀ gidigidi.

16 “Ìgbà mẹta láàrin ọdún kan ni gbogbo àwọn ọkunrin yín yóo máa farahàn níwájú OLUWA níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun; àkókò àjọ̀dún burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati àkókò àjọ̀dún ìkórè, ati àkókò àjọ̀dún àgọ́. Wọn kò gbọdọ̀ farahàn níwájú OLUWA ní ọwọ́ òfo.

17 Olukuluku ọkunrin yóo mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí ó bá ti fẹ́ ati gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun un.

Ìlànà nípa Ẹjọ́ Dídá

18 “Ẹ yan àwọn adájọ́ ati àwọn olórí tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà yín, ní àwọn ìlú yín, wọn yóo sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn eniyan.

19 Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, ẹ kò sì gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀; nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ọlọ́gbọ́n lójú, a sì máa yí ẹjọ́ aláre pada sí ẹ̀bi.

20 Ẹ̀tọ́ nìkan ṣoṣo ni kí ẹ máa ṣe, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ sì lè jogún ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

21 “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin igikígi bí igi oriṣa Aṣera sí ẹ̀bá pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, nígbà tí ẹ bá ń kọ́ ọ.

22 Ẹ kò sì gbọdọ̀ ri òpó mọ́lẹ̀ kí ẹ máa bọ ọ́, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín kórìíra wọn.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 17

1 “Ẹ kò gbọdọ̀ fi mààlúù tabi aguntan tí ó ní àbààwọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín nítorí pé ohun ìríra ni ó jẹ́ fún un.

2 “Bí ọkunrin kan tabi obinrin kan láàrin àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín bá ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA Ọlọrun yín, nípa pé ó da majẹmu rẹ̀,

3 bí ó bá lọ bọ oriṣa, kì báà ṣe oòrùn, tabi òṣùpá, tabi ọ̀kan ninu àwọn nǹkan mìíràn tí ó wà ní ojú ọ̀run, tí mo ti pàṣẹ pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ;

4 bí wọn bá sọ fun yín tabi ẹ gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ìdánilójú sì wà pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní Israẹli,

5 ẹ mú ẹni tí ó ṣe ohun burúkú náà jáde lọ sí ẹnu ibodè yín, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

6 Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo.

7 Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.

8 “Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn.

9 Ẹ tọ àwọn alufaa ọmọ Lefi lọ, kí ẹ sì kó ẹjọ́ yín lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà ní ipò onídàájọ́ ní àkókò náà. Ẹ ro ẹjọ́ yín fún wọn, wọn yóo sì bá yín dá a.

10 Ohunkohun tí wọ́n bá sọ fun yín ní ibi tí OLUWA bá yàn ni ẹ gbọdọ̀ ṣe. Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ní kí ẹ ṣe.

11 Ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín ni kí ẹ gbà, kí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí wọ́n bá là sílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ yà sí ọ̀tún tabi sí òsì ninu ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín.

12 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe oríkunkun sí ẹni tí ó jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà, tabi alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà, pípa ni kí ẹ pa á; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ohun burúkú náà kúrò láàrin Israẹli.

13 Gbogbo àwọn eniyan ni yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n; ẹnikẹ́ni kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

Ìkìlọ̀ nípa Yíyan Ọba

14 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’

15 ẹ lè fi ẹnikẹ́ni tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn fun yín jọba, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín ni ẹ gbọdọ̀ fi jọba, ẹ kò gbọdọ̀ fi àlejò, tí kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín jọba.

16 Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’

17 Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀.

18 “Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀.

19 Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn;

20 kí ó má baà rò ninu ara rẹ̀ pé òun ga ju àwọn arakunrin òun lọ, kí ó má baà yipada sí ọ̀tún tabi sí òsì kúrò ninu òfin OLUWA, kí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ lè pẹ́ lórí oyè ní Israẹli.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 18

Ìpín Àwọn Alufaa

1 “Gbogbo ẹ̀yà Lefi ni alufaa, nítorí náà wọn kò ní bá àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù pín ilẹ̀. Ninu ọrẹ fún ẹbọ sísun, ati àwọn ọrẹ mìíràn tí àwọn eniyan Israẹli bá mú wá fún OLUWA, ni àwọn ẹ̀yà Lefi yóo ti máa jẹ.

2 Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.

3 “Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀.

4 Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́.

5 Nítorí ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ẹ̀yà Lefi ati ti arọmọdọmọ wọn ni OLUWA Ọlọrun yín ti yàn láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún un.

6 “Bí ọ̀kan ninu ẹ̀yà Lefi bá dìde láti ilé rẹ̀, tabi ibikíbi tí ó wù kí ó ti wá ní Israẹli, tabi ìgbà yòówù tí ó bá fẹ́ láti wá sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìsìn rẹ̀,

7 ó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ níwájú OLUWA.

8 Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà.

Ìkìlọ̀ nípa Àwọn Àṣà Ìbọ̀rìṣà

9 “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń hù.

10 Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó;

11 tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀.

12 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi di ohun ìríra níwájú OLUWA, ati pé nítorí ohun ìríra wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín ṣe ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fun yín.

13 Gbogbo ìwà ati ìṣe yín níláti jẹ́ èyí tí ó tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

Ìlérí láti Rán Wolii Kan sí Israẹli

14 “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo gba ilẹ̀ wọn yìí a máa ṣe àyẹ̀wò, wọn a sì máa gbọ́ ti àwọn aláfọ̀ṣẹ, ṣugbọn ní tiyín, OLUWA Ọlọrun yín kò gbà fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀.

15 OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu.

16 “Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’

17 OLUWA wí fún mi nígbà náà pé, ‘Gbogbo ohun tí wọ́n sọ patapata ni ó dára.

18 N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn.

19 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí yóo máa sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi ni n óo jẹ olúwarẹ̀ níyà.

20 Ṣugbọn wolii tí ó bá fi orúkọ mi jẹ́ iṣẹ́ tí n kò rán an, tabi tí ó jẹ́ iṣẹ́ kan fun yín ní orúkọ àwọn oriṣa, wolii náà gbọdọ̀ kú ni.’

21 “Bí ẹ bá ń rò ninu ọkàn yín pé, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ ìgbà tí wolii kan bá ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọrun kò rán an.

22 Nígbà tí wolii kan bá jíṣẹ́ ní orúkọ OLUWA, bí ohun tí ó sọ pé yóo ṣẹlẹ̀ kò bá ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán an; wolii náà ń dá iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ ni, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 19

Àwọn ìlú Ààbò

1 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóo fun yín ní ilẹ̀ wọn run, tí ẹ bá gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn, ati ilé wọn,

2 ẹ ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ fún ara yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

3 Ẹ pín ilẹ̀ náà sí agbègbè mẹta, kí ẹ sì la ọ̀nà mẹta wọ inú àwọn ìlú náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìlú mẹtẹẹta tí ẹ yà sọ́tọ̀ gbọdọ̀ wà ní agbègbè kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo sì ṣí àwọn ọ̀nà tí ó wọ ìlú wọnyi kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè tètè sálọ sibẹ.

4 Èyí wà fún anfaani ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan. Bí ẹnìkan bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀, bí ó bá sálọ sí èyíkéyìí ninu àwọn ìlú náà, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

5 Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá lọ sinu igbó pẹlu aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó ti ń fi àáké gé igi lọ́wọ́, bí irin àáké náà bá yọ, tí ó lọ bá aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì pa á; irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú náà, kí ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

6 Kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ṣèèṣì pa bá ń lé e lọ pẹlu ibinu, bí ibi tí yóo sá àsálà lọ bá jìnnà jù, yóo bá a, yóo sì pa á; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan yìí, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé òun ati aládùúgbò rẹ̀ kìí ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀.

7 Nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín pé, ẹ níláti ya ìlú mẹta sọ́tọ̀.

8 “Bí OLUWA Ọlọrun yín bá sì mú kí ilẹ̀ yín tóbi síi gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín, tí ó bá fun yín ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún àwọn baba yín,

9 bí ẹ bá lè pa gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà náà, ẹ tún fi ìlú mẹta mìíràn kún àwọn ìlú mẹta ti àkọ́kọ́.

10 Kí ẹnikẹ́ni má baà ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti jogún, kí ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ má baà wà lórí yín.

11 “Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá kórìíra aládùúgbò rẹ̀, tí ó bá ba dè é, tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó sì sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi,

12 kí àwọn àgbààgbà ìlú rán ni lọ mú ẹni náà wá, kí wọ́n sì fi lé ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa lọ́wọ́, kí ó lè pa ẹni tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ paniyan yìí.

13 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá, ṣugbọn ẹ níláti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò láàrin Israẹli, kí ó lè dára fun yín.

Àwọn Ààlà Àtayébáyé

14 “Ninu ogún tìrẹ tí ó bá kàn ọ́ ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti gbà, o kò gbọdọ̀ sún ohun tí àwọn baba ńlá rẹ bá fi pààlà ilẹ̀.

Àlàyé nípa Ẹlẹ́rìí

15 “Ẹ̀rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo péré kò tó láti fi dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùnkẹ́sùn tí wọ́n bá fi kàn án, tabi ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ tí ó bá ṣẹ̀. Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta, kí ẹ tó lè dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí ẹ̀sùn kan.

16 Bí ẹlẹ́rìí èké kan bá dìde láti jẹ́rìí èké mọ́ ẹnìkan, tí ó bá fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe nǹkan burúkú,

17 kí àwọn mejeeji tí wọn ń ṣe àríyànjiyàn yìí wá siwaju OLUWA, níwájú àwọn alufaa ati àwọn tí wọ́n jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà.

18 Kí àwọn onídàájọ́ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí bí ọ̀rọ̀ ti rí, bí wọ́n bá rí i pé ẹ̀rí èké ni ọkunrin yìí ń jẹ́, tabi pé ẹ̀sùn èké ni ó fi kan arakunrin rẹ̀;

19 ohun tí ó fẹ́ kí wọ́n ṣe fún arakunrin rẹ̀ gan an ni kí ẹ ṣe fún òun náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú nǹkan burúkú kúrò láàrin yín.

20 Àwọn yòókù yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe irú nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín.

21 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú olúwarẹ̀ rárá, tó bá jẹ́ pé ó fẹ́ kí wọ́n pa arakunrin rẹ̀ ni, pípa ni kí ẹ pa òun náà; bí ó bá jẹ́ ẹyinjú tabi eyín rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n yọ, ẹ yọ ojú tabi eyín ti òun náà; bí ó bá sì jẹ́ pé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ó fẹ́ kí wọ́n gé, ẹ gé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ ti òun náà.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 20

Ọ̀rọ̀ nípa Ogun

1 “Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín.

2 Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé,

3 ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín.

4 Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’

5 “Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́.

6 Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀.

7 Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’

8 “Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’

9 Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun.

10 “Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn.

11 Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.

12 Ṣugbọn bí wọ́n bá kọ̀, tí àwọn náà dìde ogun si yín, ẹ dó ti ìlú náà.

13 Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi ìlú náà le yín lọ́wọ́, kí ẹ fi idà pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀.

14 Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín.

15 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín.

16 “Ṣugbọn gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín, gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ kò gbọdọ̀ dá ohun alààyè kan sí ninu wọn.

17 Rírun ni kí ẹ run gbogbo wọn patapata, gbogbo àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Kenaani, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi; gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti pa á láṣẹ.

18 Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín.

19 “Nígbà tí ẹ bá dó ti ìlú kan fún ìgbà pípẹ́, tí ẹ bá ń bá ìlú náà jagun tí ẹ fẹ́ gbà á, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ́ àwọn igi eléso wọn lulẹ̀ ní ìbẹ́kúbẹ̀ẹ́. Jíjẹ ni kí ẹ máa jẹ èso igi wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gé wọn lulẹ̀. Àbí eniyan ni igi inú igbó, tí ẹ óo fi máa gbé ogun tì í?

20 Àwọn igi tí ẹ bá mọ̀ pé èso wọn kìí ṣe jíjẹ nìkan ni kí ẹ máa gé, kí ẹ máa fi ṣe àtẹ̀gùn, tí ẹ fi lè wọ ìlú náà, títí tí ọwọ́ yín yóo fi tẹ̀ ẹ́.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 21

Tí Ikú Ẹnìkan Bá Rúni lójú

1 “Bí ẹ bá rí òkú eniyan tí wọ́n pa sinu igbó, lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ kò sì mọ ẹni tí ó pa á,

2 kí àwọn àgbààgbà ati àwọn adájọ́ yín jáde wá, kí wọ́n wọn ilẹ̀ láti ibi tí wọ́n pa ẹni náà sí títí dé gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká ibẹ̀.

3 Kí àwọn àgbààgbà ìlú tí ó bá súnmọ́ ibẹ̀ jùlọ wá ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì so àjàgà mọ́ lọ́rùn láti fi ṣiṣẹ́ rí,

4 kí wọ́n mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù náà lọ sí àfonífojì tí ó ní odò tí ń ṣàn, tí ẹnikẹ́ni kò gbin ohunkohun sí rí, kí wọ́n sì lọ́ ọ̀dọ́ mààlúù náà lọ́rùn pa níbẹ̀.

5 Kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, bá wọn lọ pẹlu; nítorí àwọn ni OLUWA Ọlọrun yín yàn láti máa ṣe alufaa ati láti máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA; ati pé àwọn ni OLUWA Ọlọrun yàn láti parí àríyànjiyàn ati ẹjọ́.

6 Kí gbogbo àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ní ìlú náà wẹ ọwọ́ wọn sórí mààlúù tí wọ́n ti lọ́ lọ́rùn pa yìí.

7 Kí wọ́n wí pé, ‘A kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ẹni tí ó pa á.

8 OLUWA, dáríjì Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí o ti rà pada, má sì ṣe jẹ àwọn eniyan Israẹli níyà nítorí ikú aláìṣẹ̀ yìí. Ṣugbọn dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà jì wọ́n.’

9 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ ara yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀, bí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA.

Àwọn Obinrin Tí Ogun Bá Kó

10 “Nígbà tí ẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì kó wọn lẹ́rú;

11 tí ẹ bá rí arẹwà obinrin kan láàrin àwọn ẹrú náà tí ó wù yín láti fi ṣe aya fún ara yín.

12 Ẹ mú un wá sí ilẹ̀ yín ẹ fá irun orí rẹ̀, kí ẹ sì gé èékánná ọwọ́ rẹ̀.

13 Ẹ bọ́ aṣọ ẹrú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó wà ní ilẹ̀ yín, kí ó sì máa ṣọ̀fọ̀ baba ati ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan. Lẹ́yìn náà ẹ lè wọlé tọ̀ ọ́, kí ẹ sì di tọkọtaya.

14 Lẹ́yìn náà, tí kò bá wù yín mọ́ ẹ níláti fún un láyè kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá wù ú, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ tà á bí ẹrú, ẹ kò sì gbọdọ̀ lò ó ní ìlò ẹrú, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bá a lòpọ̀ rí.

Ẹ̀tọ́ Àkọ́bí ninu Ogún Baba Rẹ̀

15 “Bí ẹnìkan bá ní iyawo meji, tí ó fẹ́ràn ọ̀kan, tí kò sì fẹ́ràn ekeji, tí àwọn mejeeji bímọ fún un, tí ó bá jẹ́ pé iyawo tí kò fẹ́ràn ni ó bí àkọ́bí ọmọkunrin rẹ̀ fún un,

16 ní ọjọ́ tí yóo bá ṣe ètò bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóo ṣe pín ogún rẹ̀, kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, kí ó pín ogún fún ọmọ ẹni tí ó fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, kí ó sì ṣe ọmọ ẹni tí kò fẹ́ràn bí ẹni pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí rẹ̀.

17 Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí.

Bí Ọmọ Ẹni Bá Ya Aláìgbọràn

18 “Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́,

19 kí baba ati ìyá rẹ̀ mú un wá siwaju àwọn àgbààgbà ìlú náà, ní ẹnu bodè ìlú tí ó ń gbé,

20 kí wọ́n wí fún àwọn àgbààgbà ìlú náà pé, ‘Ọmọ wa yìí ya olóríkunkun ati aláìgbọràn, kì í gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Oníjẹkújẹ ati onímukúmu sì ni.’

21 Lẹ́yìn náà kí àwọn ọkunrin ìlú sọ ọ́ ní òkúta pa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ ibi kúrò láàrin yín; gbogbo Israẹli yóo gbọ́, wọn yóo sì bẹ̀rù.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

22 “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ kan, tí ó jẹ́ pé ikú ni ìjìyà irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ẹ bá so ó kọ́ sórí igi,

23 òkú rẹ̀ kò gbọdọ̀ sun orí igi náà. Ẹ níláti sin ín ní ọjọ́ náà, nítorí ẹni ìfibú Ọlọrun ni ẹni tí a bá so kọ́ orí igi, ẹ kò gbọdọ̀ sọ ilẹ̀ yín tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín di aláìmọ́.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 22

1 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo mààlúù tabi aguntan arakunrin yín, kí ó máa ṣìnà lọ, kí ẹ sì mójú kúrò, ẹ níláti fà á tọ olówó rẹ̀ lọ.

2 Bí ibi tí olówó ẹran ọ̀sìn yìí ń gbé bá jìnnà jù, tabi tí ẹ kò bá mọ ẹni náà, ẹ níláti fa ẹran ọ̀sìn náà wálé, kí ó sì wà lọ́dọ̀ yín títí tí olówó rẹ̀ yóo fi máa wá a kiri. Nígbà tí ó bá ń wá a, ẹ níláti dá a pada fún un.

3 Bákan náà ni ẹ níláti ṣe, tí ó bá jẹ́ pé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni ó sọnù, tabi aṣọ rẹ̀, tabi ohunkohun tí ó bá jẹ́ ti arakunrin yín, tí ó bá sọnù tí ẹ sì rí i. Ẹ kò gbọdọ̀ mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i.

4 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù arakunrin yín, tí ó wó lulẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, kí ẹ sì mójú kúrò bí ẹni pé ẹ kò rí i. Ẹ níláti ràn án lọ́wọ́ láti gbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi akọ mààlúù rẹ̀ dìde.

5 “Obinrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti ọkunrin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkunrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti obinrin nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìríra ni ó jẹ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.

6 “Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn.

7 Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé.

8 “Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú.

9 “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sáàrin àwọn àjàrà tí ẹ bá gbìn sinu ọgbà àjàrà yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àjàrà náà, ati ohun tí ẹ gbìn sáàrin rẹ̀ yóo di ti ibi mímọ́.

10 “Ẹ kò gbọdọ̀ so àjàgà kan náà mọ́ akọ mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́rùn, láti fi wọ́n ṣiṣẹ́ ninu oko.

11 “Ẹ kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí wọ́n bá pa irun pọ̀ mọ́ òwú hun.

12 “Ẹ gbọdọ̀ fi oko wọnjanwọnjan sí igun mẹrẹẹrin aṣọ ìbora yín.

Òfin nípa Ìbálòpọ̀ Ọkunrin ati Obinrin

13 “Bí ẹnìkan bá gbé ọmọge níyàwó, ṣugbọn tí ó kórìíra rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀,

14 tí ó wá sọ pé ó ti ṣe ìṣekúṣe, tí ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ burúkú, tí ó bá wí pé, ‘Mo gbé obinrin yìí níyàwó ṣugbọn nígbà tí mo súnmọ́ ọn, n kò bá a nílé.’

15 “Kí baba ati ìyá ọmọbinrin yìí mú aṣọ ìbálé rẹ̀ jáde, kí wọ́n sì mú un tọ àwọn àgbààgbà ìlú náà lọ ní ẹnubodè.

16 Kí baba ọmọ náà wí fún wọn pé, ‘Mo fi ọmọbinrin mi yìí fún ọkunrin yìí ní aya, lẹ́yìn tí ó ti bá a lòpọ̀ tán,

17 ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe. Ó ní, “N kò bá ọmọ rẹ nílé.” ’ Kí baba ọmọbinrin tẹ́ aṣọ ìbálé rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn àgbààgbà, kí ó sì wí pé, ‘Èyí ni ẹ̀rí pé ó bá ọmọ mi nílé.’

18 Àwọn àgbààgbà ìlú náà yóo mú ọkunrin yìí, wọn yóo nà án dáradára.

19 Wọn yóo sì gba ọgọrun-un ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ́wọ́ rẹ̀ fún baba ọmọbinrin náà bíi owó ìtanràn; nítorí pé ó ti bá ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Israẹli lórúkọ jẹ́. Obinrin náà yóo sì tún jẹ́ iyawo rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

20 “Ṣugbọn bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan obinrin náà bá jẹ́ òtítọ́, pé wọn kò bá a nílé,

21 Wọn yóo fa obinrin náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé baba rẹ̀, àwọn ọkunrin ìlú yóo sì sọ ọ́ ní òkúta pa, nítorí pé ó ti hu ìwà òmùgọ̀ ní Israẹli níti pé ó ṣe àgbèrè ní ilé baba rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.

22 “Bí ọwọ́ bá tẹ ọkunrin kan ní ibi tí ó ti ń bá iyawo oníyàwó lòpọ̀, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa àwọn mejeeji; ati ọkunrin ati obinrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.

23 “Bí ẹnìkan bá rí ọmọge kan, tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà láàrin ìlú, tí ó sì bá a lòpọ̀,

24 ẹ mú àwọn mejeeji jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa. Ẹ̀ṣẹ̀ ti obinrin ni pé, nígbà tí wọ́n kì í mọ́lẹ̀ láàrin ìlú, kò pariwo kí aládùúgbò gbọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ti ọkunrin ni pé, ó ba àfẹ́sọ́nà arakunrin rẹ̀ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ibi yìí kúrò láàrin yín.

25 “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ninu igbó ni ọkunrin kan ti ki ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹnìkan mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, ọkunrin nìkan ni kí wọ́n pa.

26 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun sí ọmọbinrin náà, kò jẹ̀bi ikú rárá, nítorí ọ̀rọ̀ náà dàbí pé kí ọkunrin kan pàdé aládùúgbò rẹ̀ kan lójú ọ̀nà, kí ó sì lù ú pa.

27 Nítorí pé, inú igbó ni ó ti kì í mọ́lẹ̀. Bí ọmọbinrin àfẹ́sọ́nà yìí tilẹ̀ ké: ‘Gbà mí! Gbà mí!’ Kò sí ẹnikẹ́ni nítòsí tí ó lè gbà á sílẹ̀.

28 “Bí ọkunrin kan bá rí ọmọbinrin kan, tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó kì í mọ́lẹ̀, tí ó sì bá a lòpọ̀, bí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n,

29 ọkunrin tí ó bá obinrin yìí lòpọ̀ níláti fún baba ọmọbinrin náà ní aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ọmọbinrin yìí yóo sì di iyawo rẹ̀, nítorí pé ó ti fi ipá bá a lòpọ̀, kò sì gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

30 “Ọkunrin kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí ninu àwọn aya baba rẹ̀ ṣe aya, tabi kí ó bá a lòpọ̀.