Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 3

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Ogu Ọba

1 “Lẹ́yìn náà, a gbéra, a doríkọ ọ̀nà Baṣani. Ogu, ọba Baṣani, ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ṣígun wá pàdé wa ní Edirei.

2 Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’

3 “OLUWA Ọlọrun wa bá fi Ogu, ọba Baṣani, lé wa lọ́wọ́, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. A pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan rẹ̀.

4 A gba gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, kò sí ìlú kan tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn ninu gbogbo àwọn ìlú wọn. Gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta, gbogbo agbègbè Arigobu ati ìjọba Ogu ní Baṣani ni a gbà.

5 Wọ́n mọ odi gíga gíga yípo gbogbo àwọn ìlú ọ̀hún, olukuluku wọ́n sì ní odi tí ó ga ati ẹnubodè pẹlu ọ̀pá ìdábùú, láìka ọpọlọpọ àwọn ìlú kéékèèké tí kò ní odi.

6 A run gbogbo wọn patapata gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sí Sihoni, ọba Heṣiboni, tí a run gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ati ọkunrin, ati obinrin, ati ọmọde.

7 Ṣugbọn a kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati àwọn ohun tí a rí ninu ìlú wọn bí ìkógun.

8 “A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni.

9 (Herimoni Sirioni ni àwọn ará Sidoni ń pe òkè náà, ṣugbọn àwọn ará Amori ń pè é ní Seniri.)

10 A sì tún gba gbogbo àwọn ìlú wọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati gbogbo ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka ati Edirei, àwọn ìlú tí ó wà ninu ìjọba Ogu, ọba Baṣani.”

11 (Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.)

Àwọn Ẹ̀yà Tí Wọ́n Tẹ̀dó sí Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

12 “Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀.

13 Ìdajì tí ó kù lára ilẹ̀ àwọn ará Gileadi, ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Baṣani tíí ṣe ìjọba Ogu, ati gbogbo agbègbè Arigobu, ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase.”

(Gbogbo ilẹ̀ Baṣani ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ àwọn Refaimu.

14 Jairi láti inú ẹ̀yà Manase ni ó gba gbogbo agbègbè Arigobu tí à ń pè ní Baṣani, títí dé etí ààlà ilẹ̀ àwọn Geṣuri, ati ti àwọn Maakati. Ó sọ àwọn ìlú náà ní orúkọ ara rẹ̀; ó pè wọ́n ní Hafoti Jairi. Orúkọ náà ni wọ́n ń jẹ́ títí di òní olónìí.)

15 Makiri, láti inú ẹ̀yà Manase ni mo fún ní ilẹ̀ Gileadi.

16 Àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo sì fún ní agbègbè Gileadi títí dé àfonífojì Anoni, ààrin gbùngbùn àfonífojì náà ni ààlà ilẹ̀ wọn, títí lọ kan odò Jaboku, tíí ṣe ààlà àwọn ará Amoni;

17 ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn.

18 “Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín.

19 Ṣugbọn àwọn aya yín ati àwọn ọmọ yín kéékèèké ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ pé wọ́n ti di pupọ nisinsinyii) yóo wà ninu àwọn ìlú tí mo ti fun yín

20 títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’

21 “Mo sọ fún Joṣua nígbà náà pé; ‘Ṣé ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe sí àwọn ọba meji wọnyi? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA yóo ṣe sí ìjọba yòókù tí ẹ óo gbà.

22 Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn rárá, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín.’

Ọlọrun Kò Jẹ́ kí Mose Wọ Ilẹ̀ Kenaani

23 “Mo bẹ OLUWA nígbà náà, mo ní,

24 ‘OLUWA Ọlọrun, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi ati agbára rẹ han èmi iranṣẹ rẹ ni; nítorí pé, oriṣa wo ló wà, lọ́run tabi láyé yìí tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi tìrẹ?

25 Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’

26 “Ṣugbọn OLUWA bínú sí mi nítorí yín, kò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, ‘Ó tó gẹ́ẹ́, má ṣe bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.

27 Gun orí òkè Pisiga lọ, gbé ojú sókè, kí o sì wo apá ìwọ̀ oòrùn, ati apá àríwá, ati apá gúsù, ati apá ìlà oòrùn. Ojú ni o óo fi rí i, nítorí pé, o kò ní kọjá odò Jọdani yìí sí òdìkejì.

28 Ṣugbọn pàṣẹ fún Joṣua, mú un lọ́kàn le, kí o sì kì í láyà; nítorí pé, òun ni yóo ṣiwaju àwọn eniyan wọnyi lọ, tí wọn yóo fi gba ilẹ̀ tí o óo rí.’

29 “Nítorí náà a bá dúró sí àfonífojì, ní òdìkejì Betipeori.”

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 4

Mose Rọ Àwọn Ọmọ Israẹli Pé kí Wọn Máa Gbọ́ràn

1 Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ fi ọkàn sí àwọn ìlànà ati òfin tí mò ń kọ yín yìí, kí ẹ máa tẹ̀lé wọn, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ń mu yín lọ, kí ẹ sì lè gbà á.

2 Ẹ kò gbọdọ̀ fi kún òfin tí mo fun yín yìí, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀, kí ẹ lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun yín tí mo fun yín mọ́.

3 Ẹ̀yin náà ti fi ojú yín rí ohun tí OLUWA ṣe ní Baali Peori, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori run kúrò láàrin yín.

4 Ṣugbọn gbogbo ẹ̀yin tí ẹ di OLUWA Ọlọrun yín mú ṣinṣin ni ẹ wà láàyè títí di òní.

5 “Mo ti kọ yín ní ìlànà ati òfin gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún mi, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.

6 Ẹ máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn, wọn yóo sì sọ yín di ọlọ́gbọ́n ati olóye lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Orílẹ̀-èdè tí ó bá gbọ́ nípa àwọn ìlànà ati òfin wọnyi yóo wí pé, dájúdájú ọlọ́gbọ́n ati amòye eniyan ni yín.

7 “Ǹjẹ́, orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní oriṣa tí ó súnmọ́ ọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun tií súnmọ́ wa nígbàkúùgbà tí a bá pè é?

8 Tabi orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó tún wà, tí ó ní ìlànà ati òfin òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn tí mo gbé ka iwájú yín lónìí?

9 Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín,

10 gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’

11 “Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà.

12 Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́.

13 Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji.

14 OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.

Ìkìlọ̀ nípa Ìbọ̀rìṣà

15 “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu,

16 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ nípa yíyá ère fún ara yín, irú ère yòówù tí ó lè jẹ́; kì báà ṣe akọ tabi abo,

17 yálà àwòrán ẹrankokẹ́ranko tí ó wà ní orílẹ̀ ayé, tabi àwòrán ẹyẹkẹ́yẹ tí ń fò lójú ọ̀run,

18 kì báà ṣe àwòrán ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, tabi àwòrán ẹjakẹ́ja tí ń bẹ ninu omi.

19 Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá gbé ojú yín sókè sí ojú ọ̀run, tí ẹ bá rí oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ohun tí ó wà ní ojú ọ̀run, kí ọkàn yín má baà fà sí wọn, kí ẹ sì máa bọ àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fún gbogbo eniyan láyé.

20 Ọlọrun ti yọ yín kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó dàbí iná ìléru ńlá, ó ko yín jáde láti jẹ́ eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ lónìí.

21 Nítorí tiyín gan-an ni OLUWA ṣe bínú sí mi, tí ó sì fi ibinu búra pé, n kò ní kọjá sí òdìkejì Jọdani, n kò sì ní dé ilẹ̀ dáradára náà, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

22 Nítorí náà, mo níláti kú ní ìhín yìí, n kò gbọdọ̀ rékọjá sí òdìkejì Jọdani, ṣugbọn ẹ̀yin óo rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, ẹ óo sì gba ilẹ̀ dáradára náà.

23 Ẹ ṣọ́ra gidigidi, ẹ má gbàgbé majẹmu tí OLUWA Ọlọrun yín ba yín dá, ẹ má sì yá èrekére fún ara yín, ní àwòrán ohunkohun, nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín lòdì sí i.

24 Nítorí iná tí ń jó ni run ni OLUWA Ọlọrun yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú sì ni.

25 “Nígbà tí ẹ bá ní ọmọ, ati àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà; bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀, nípa yíyá ère ní àwòrán ohunkohun, ati nípa ṣíṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ó lè mú un bínú,

26 ọ̀run ati ayé ń gbọ́ bí mo ti ń sọ yìí, pé ẹ óo parun patapata lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ gbà ní òdìkejì Jọdani. Ẹ kò ní pẹ́ níbẹ̀ rárá, ṣugbọn píparun ni ẹ óo parun.

27 OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí.

28 Ẹ óo sì máa bọ oriṣa tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni àwọn oriṣa wọnyi; wọn kò lè gbọ́ràn, tabi kí wọn ríran; wọn kò lè jẹun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbóòórùn.

29 Níbẹ̀ ni ẹ óo ti wá OLUWA Ọlọrun yín tí ẹ óo sì rí i, tí ẹ bá wá a tọkàntọkàn pẹlu gbogbo ẹ̀mí yín.

30 Nígbà tí ẹ bá wà ninu ìpọ́njú, tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ń ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú, ẹ óo pada sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì gbọ́ tirẹ̀.

31 Nítorí pé, aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní já yín kulẹ̀, kò ní pa yín run, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbàgbé majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba ńlá yín dá.

32 “Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí.

33 Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kan gbọ́ kí oriṣa kan sọ̀rọ̀ láti ààrin gbùngbùn iná rí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì tún wà láàyè?

34 Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti?

35 OLUWA fi èyí hàn yín, kí ẹ lè mọ̀ pé òun ni Ọlọrun, ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi òun nìkan.

36 Ó mú kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, kí ó lè kọ yín; ó sì mú kí ẹ rí iná ńlá rẹ̀ láyé, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná náà.

37 Ìdí tí ó fi ṣe èyí ni pé, ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọmọ wọn; ó fi agbára ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ó sì wà pẹlu yín.

38 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ kúrò fun yín, kí ó baà lè ko yín wọlé kí ó sì fun yín ní ilẹ̀ wọn, kí ẹ sì jogún rẹ̀ bí ó ti wà lónìí.

39 Kí ẹ mọ̀ lónìí, kí ó sì da yín lójú pé, OLUWA ni Ọlọrun; kò sí ọlọrun mìíràn mọ́ ní ọ̀run ati ní ayé.

40 Nítorí náà, ẹ máa pa àwọn ìlànà ati òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ó lè dára fun yín, ati fún àwọn ọmọ yín; kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, títí lae.”

Àwọn Ìlú Ààbò Tí Ó Wà ní Apá Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

41 Mose ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí ìlú ààbò,

42 kí ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan lè máa sálọ sibẹ; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n ní ìkùnsínú sí ara wọn tẹ́lẹ̀, lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí ó lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

43 Ó ya Beseri sọ́tọ̀ fún ẹ̀yà Reubẹni ninu aṣálẹ̀ láàrin ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Ó ya Ramoti sọ́tọ̀ ní Gileadi, fún ẹ̀yà Gadi, ó sì ya Golani sọ́tọ̀ ní Baṣani, fún ẹ̀yà Manase.

Àlàyé lórí Òfin Ọlọrun Tí Mose Fẹ́ fún Wọn

44 Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin;

45 ó sì fi àwọn ìlànà ati àṣẹ lélẹ̀ fún wọn nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti,

46 nígbà tí wọ́n dé òdìkejì odò Jọdani, ní àfonífojì tí ó dojú kọ Betipeori, ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni. Mose ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun Sihoni nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.

47 Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ ati ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani, Sihoni ati Ogu ni ọba àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani ní apá ìlà oòrùn

48 láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni títí dé òkè Sirioni (tí à ń pè ní òkè Herimoni),

49 ati gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani títí dé Òkun Araba, tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 5

Òfin Mẹ́wàá

1 Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn.

2 OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu kan ní òkè Horebu.

3 Kì í ṣe àwọn baba wa ni OLUWA bá dá majẹmu yìí, ṣugbọn àwa gan-an tí a wà láàyè níhìn-ín lónìí ni ó bá dá majẹmu náà.

4 OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ lojukooju lórí òkè ní ààrin iná.

5 Èmi ni mo dúró láàrin ẹ̀yin ati OLUWA nígbà náà, tí mo sì sọ ohun tí OLUWA wí fun yín; nítorí ẹ̀rù iná náà ń bà yín, ẹ kò sì gun òkè náà lọ.

“OLUWA ní,

6 ‘Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà:

7 “ ‘O kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, èmi OLUWA ni kí o máa sìn.

8 “ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.

9 O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi.

10 Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi, tí kì í yẹ̀, hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé òfin mi.

11 “ ‘O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán; nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi.

12 “ ‘Ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀, kí o sì ṣe é ní ọjọ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pàṣẹ fún ọ.

13 Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe gbogbo làálàá ati iṣẹ́ rẹ;

14 ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA Ọlọrun rẹ. Ní ọjọ́ náà, o kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati àwọn ọmọ rẹ obinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ, ati mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àlejò tí ń gbé ilẹ̀ rẹ; kí iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin rẹ lè sinmi bí ìwọ náà ti sinmi.

15 Ranti pé, ìwọ pàápàá ti jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti rí, ati pé OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó fi agbára rẹ̀ mú ọ jáde. Nítorí náà ni OLUWA Ọlọrun rẹ fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀.

16 “ ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ; kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, kí ó sì lè máa dára fún ọ.

17 “ ‘O kò gbọdọ̀ paniyan.

18 “ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga.

19 “ ‘O kò gbọdọ̀ jalè.

20 “ ‘O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ.

21 “ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya ẹlòmíràn, tabi ilé rẹ̀, tabi oko rẹ̀, tabi iranṣẹkunrin rẹ̀, tabi iranṣẹbinrin rẹ̀, tabi akọ mààlúù rẹ̀, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi ohunkohun tíí ṣe ti ẹlòmíràn.’

22 “Àwọn òfin tí OLUWA fún gbogbo yín nìyí, nígbà tí ẹ fi péjọ lẹ́sẹ̀ òkè, tí ó fi fi ohùn rara ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná ati ìkùukùu, ati òkùnkùn biribiri. Àwọn òfin yìí nìkan ni ó fun yín, kò sí òmíràn lẹ́yìn wọn, ó kọ wọ́n sára tabili òkúta meji, ó sì kó wọn fún mi.

Ẹ̀rù Ba Àwọn Ọmọ Israẹli

23 “Nígbà tí ẹ gbọ́ ohùn láti inú òkùnkùn biribiri, tí iná sì ń jó lórí òkè, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà yín ati àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi;

24 wọ́n ní, ‘OLUWA Ọlọrun wa ti fi títóbi ati ògo rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná. Lónìí ni a rí i tí Ọlọrun bá eniyan sọ̀rọ̀, tí olúwarẹ̀ sì tún wà láàyè.

25 Nítorí náà, kí ló dé tí a óo fi kú? Nítorí pé, iná ńlá yìí yóo jó wa run; bí a bá tún gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa sí i, a óo kú.

26 Nítorí pé ninu gbogbo ẹ̀dá alààyè, ta ni ó tíì gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun alààyè rí láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ yìí, tí ó sì wà láàyè?

27 Ìwọ Mose, súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yóo sọ, kí o wá sọ fún wa, a óo sì ṣe é.’

28 “OLUWA gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ̀ ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mo gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi bá ọ sọ; gbogbo ohun tí wọ́n sọ pátá ni ó dára.

29 Yóo ti dára tó, bí wọ́n bá ní irú ẹ̀mí yìí nígbà gbogbo, kí wọ́n bẹ̀rù mi, kí wọ́n sì pa gbogbo òfin mi mọ́, kí ó lè dára fún wọn, ati fún àwọn ọmọ wọn títí lae.

30 Lọ sọ fún wọn pé, kí wọ́n pada sinu àgọ́ wọn.

31 Ṣugbọn ìwọ dúró tì mí níhìn-ín, n óo sì sọ gbogbo òfin ati ìlànà ati ìdájọ́ tí o óo kọ́ wọn, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́, ní ilẹ̀ tí n óo fún wọn.’

32 “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìgbọràn ninu ohunkohun.

33 Gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín là sílẹ̀ ni kí ẹ máa tọ̀, kí ẹ lè wà láàyè, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ óo gbà.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 6

Òfin Ńlá

1 “Àwọn òfin ati ìlànà, ati ìdájọ́ tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fún mi láti fi kọ yín nìwọ̀nyí; kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà;

2 kí ẹ lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín, kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà ati òfin tí mo fun yín lónìí, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ lè pẹ́ láyé.

3 Ẹ gbọ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ máa tẹ̀lé àwọn òfin náà, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣe ìlérí fun yín.

4 “Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni.

5 Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín pẹlu gbogbo ọkàn yín, ati gbogbo ẹ̀mí yín, ati gbogbo agbára yín.

6 Ẹ fi àṣẹ tí mo pa fun yín lónìí sọ́kàn,

7 kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára. Ẹ máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín, ati nígbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati nígbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀, ati nígbà tí ẹ bá dìde.

8 Ẹ so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín.

9 Ẹ kọ wọ́n sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín, ati sí ara ẹnu ọ̀nà ìta ilé yín.

Ìkìlọ̀ nípa Ìwà Àìgbọràn

10 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mu yín wọ ilẹ̀ tí ó búra fún Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba yín, pé òun yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n dára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ tẹ̀ wọ́n dó,

11 ati àwọn ilé tí ó kún fún àwọn nǹkan dáradára, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ kó wọn sibẹ, ati kànga omi, tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbẹ́ ẹ, ati àwọn ọgbà àjàrà ati igi olifi tí kìí ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn ín. Nígbà tí ẹ bá jẹ, tí ẹ yó tán,

12 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà gbàgbé OLUWA tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti jẹ́ ẹrú.

13 Ẹ gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa sìn ín. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.

14 Ẹ kò gbọdọ̀ bọ èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín ń bọ,

15 nítorí pé, OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọrun tíí máa ń jowú ni; kí inú má baà bí OLUWA Ọlọrun yín sí yín, kí ó sì pa yín run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

16 “Ẹ kò gbọdọ̀ dán OLUWA Ọlọrun yín wò, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Masa.

17 Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ dáradára, kí ẹ sì máa tẹ̀lé àwọn òfin ati àwọn ìlànà rẹ̀, tí ó fi lélẹ̀ fun yín.

18 Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó tọ́, ati ohun tí ó yẹ lójú OLUWA; kí ó lè dára fun yín, kí ẹ lè lọ gba ilẹ̀ dáradára tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín,

19 kí OLUWA lè lé àwọn ọ̀tá yín jáde fun yín, bí ó ti ṣèlérí.

20 “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́jọ́ iwájú pé, kí ni ìtumọ̀ àwọn ẹ̀rí ati ìlànà ati òfin tí OLUWA pa láṣẹ fun yín.

21 Ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘A ti jẹ́ ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ijipti rí, ṣugbọn agbára ni OLUWA fi kó wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

22 Àwa pàápàá fi ojú wa rí i bí OLUWA ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí wọ́n bani lẹ́rù sí àwọn ará Ijipti ati sí Farao ọba wọn, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.

23 OLUWA sì kó wa jáde, kí ó lè kó wa wá sí orí ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba wa.

24 OLUWA pa á láṣẹ fún wa pé kí á máa tẹ̀lé gbogbo àwọn ìlànà wọnyi, kí á bẹ̀rù òun OLUWA Ọlọrun wa fún ire ara wa nígbà gbogbo, kí ó lè dá wa sí, kí á sì wà láàyè bí a ti wà lónìí yìí.

25 A óo kà wá sí olódodo bí a bá pa gbogbo àwọn òfin wọnyi mọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun wa, bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.’

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 7

Àwọn Eniyan OLUWA

1 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ;

2 nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì ṣẹgun wọn, píparun ni ẹ gbọdọ̀ pa wọ́n run. Ẹ kò gbọdọ̀ bá wọn dá majẹmu, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn rárá.

3 Ẹ kò gbọdọ̀ fi ọmọ yín fún àwọn ọmọkunrin wọn láti fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín.

4 Nítorí pé, wọn óo yí àwọn ọmọ yín lọ́kàn pada, wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé èmi OLUWA mọ́. Àwọn oriṣa ni wọn óo máa bọ, èmi OLUWA yóo bínú si yín nígbà náà, n óo sì pa yín run kíákíá.

5 Ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí: ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ rún àwọn òpó wọn, ẹ gé àwọn oriṣa Aṣera wọn lulẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo àwọn ère wọn níná.

6 Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun.

7 “Kì í ṣe pé ẹ pọ̀ ju àwọn eniyan yòókù lọ ni OLUWA fi fẹ́ràn yín, tí ó sì fi yàn yín. Ninu gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni ẹ kéré jùlọ.

8 Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti.

9 Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran,

10 a sì máa san ẹ̀san lojukooju fún àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀. Yóo pa wọ́n run, kò ní dáwọ́ dúró láti má gba ẹ̀san lára gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀, yóo san ẹ̀san fún wọn ní ojúkoojú.

11 Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra kí ẹ sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì tẹ̀lé ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.

Ibukun Tí Ó Wà ninu Ìgbọràn

12 “Bi ẹ bá fetí sí òfin wọnyi, tí ẹ sì pa wọ́n mọ́, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú majẹmu tí ó bá àwọn baba yín dá ṣẹ lórí yín, yóo sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.

13 Yóo fẹ́ràn yín, yóo bukun yín, yóo sọ yín di pupọ, yóo bukun àwọn ọmọ yín, ati èso ilẹ̀ yín, ati ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín; yóo bukun àwọn mààlúù yín, yóo sì mú kí àwọn ẹran ọ̀sìn yín kéékèèké pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fún àwọn baba yín.

14 OLUWA yóo bukun yín ju gbogbo àwọn eniyan yòókù lọ; kò ní sí ọkunrin kan tabi obinrin kan tí yóo yàgàn láàrin yín, tabi láàrin àwọn ẹran ọ̀sìn yín.

15 OLUWA yóo mú gbogbo àrùn kúrò lọ́dọ̀ yín, kò sì ní fi ẹyọ kan ninu gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ mọ̀, ba yín jà. Ṣugbọn yóo dà wọ́n bo àwọn tí wọ́n kórìíra yín.

16 Píparun ni ẹ óo pa gbogbo àwọn eniyan tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi lé yín lọ́wọ́ run, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ bọ àwọn oriṣa wọn, nítorí ohun ìkọsẹ̀ ni wọn yóo jẹ́ fun yín.

17 “Bí ẹ bá rò ní ọkàn yín pé àwọn eniyan wọnyi pọ̀ jù yín lọ, ati pé báwo ni ẹ ṣe lè lé wọn jáde,

18 ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Farao ati gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.

19 Ẹ ranti àwọn àrùn burúkú tí ẹ fi ojú ara yín rí, àwọn àmì ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ agbára tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe kí ó tó kó yín jáde. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe sí gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.

20 OLUWA Ọlọrun yín yóo rán agbọ́n sí wọn títí tí gbogbo àwọn tí wọ́n bá farapamọ́ fun yín yóo fi parun.

21 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín, nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín.

22 Díẹ̀díẹ̀ ni Ọlọrun yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ. Kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ẹ óo pa gbogbo wọn run, kí àwọn ẹranko burúkú má baà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ju agbára yín lọ.

23 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, yóo sì mú kí ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin wọn títí tí wọn yóo fi parun.

24 Yóo fi àwọn ọba wọn lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì pa orúkọ wọn run ní gbogbo ayé, kò ní sí ẹyọ ẹnìkan tí yóo lè dojú kọ yín títí tí ẹ óo fi pa wọ́n run.

25 Sísun ni kí ẹ sun gbogbo àwọn ère oriṣa wọn; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò wúrà tabi fadaka tí ó wà lára wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ kó wọn fún ara yín, kí wọn má baà di ohun ìkọsẹ̀ fun yín, nítorí ohun ìríra ni wọ́n lójú OLUWA Ọlọrun yín.

26 Ẹ kò sì gbọdọ̀ mú ohun ìríra wọ ilé yín, kí ẹ má baà di ẹni ìfibú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ohun ìfibú. Ẹ níláti kórìíra wọn, kí ẹ sì yàgò fún wọn, nítorí ohun ìfibú ni wọ́n.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 8

Ilẹ̀ Tí Ó Dára fún Ìní

1 “Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín.

2 Ẹ ranti gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti mú yín tọ̀ ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún yìí wá, láti tẹ orí yín ba; ó dán yín wò láti rí ọkàn yín, bóyá ẹ óo pa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ẹ kò ní pa á mọ́.

3 Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde.

4 Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ yín kò wú, fún odidi ogoji ọdún yìí.

5 Nítorí náà, ẹ mọ̀ ninu ara yín pé, gẹ́gẹ́ bí baba ti máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí ni OLUWA ń ba yín wí.

6 Nítorí náà, ẹ pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ ati bíbẹ̀rù rẹ̀.

7 Nítorí pé ilẹ̀ dáradára ni ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín ń mu yín lọ. Ó kún fún ọpọlọpọ adágún omi, ati orísun omi tí ó ń tú jáde ninu àwọn àfonífojì ati lára àwọn òkè.

8 Ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati baali, ọgbà àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́, ati igi pomegiranate, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin.

9 Ilẹ̀ tí ẹ óo ti máa jẹun, tí kò ní sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, níbi tí ẹ kò ní ṣe aláìní ohunkohun. Ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ jẹ́ irin, tí ẹ óo sì máa wa idẹ lára àwọn òkè rẹ̀.

10 Nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó, ẹ óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun yín fún ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín.

Ìkìlọ̀ nípa Gbígbàgbé OLUWA

11 “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, nípa àìpa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí,

12 kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó tán, tí ẹ ti kọ́ àwọn ilé dáradára, tí ẹ sì ń gbé inú wọn,

13 nígbà tí agbo mààlúù yín ati agbo aguntan yín bá pọ̀ sí i, tí wúrà ati fadaka yín náà sì pọ̀ sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní bá pọ̀ sí i,

14 kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú.

15 Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta,

16 ẹni tí ó fi mana tí àwọn baba yín kò jẹ rí bọ́ yín ninu aṣálẹ̀, kí ó lè tẹ orí yín ba, kí ó sì dán yín wò láti ṣe yín ní rere níkẹyìn.

17 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín.

18 Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí.

19 Ṣugbọn, mò ń kìlọ̀ fun yín dáradára lónìí pé, bí ẹ bá gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń sá káàkiri tọ àwọn oriṣa lẹ́yìn, tí ẹ sì ń bọ wọ́n, píparun ni ẹ óo parun.

20 Gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo parun, nítorí pé ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 9

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣe Àìgbọràn

1 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ óo la odò Jọdani kọjá sí òdìkejì lónìí, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, tí odi tí wọ́n mọ yí wọn ká sì ga kan ojú ọ̀run.

2 Àwọn eniyan náà pọ̀, wọ́n ṣígbọnlẹ̀. Àwọn òmìrán tíí ṣe ìran Anakimu ni wọ́n. Àwọn tí ẹ ti mọ̀, tí ẹ sì ti ń gbọ́ nípa wọn pé, ‘Ta ni ó lè dúró níwájú àwọn ìran Anaki?’

3 Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.

4 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá lé wọn jáde fun yín, ẹ má ṣe wí ninu ọkàn yín pé, ‘Nítorí òdodo wa ni OLUWA ṣe mú wa wá láti gba ilẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA ṣe lé wọn jáde fún wa.’

5 Kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín, tabi ìdúróṣinṣin ọkàn yín ni ẹ óo fi rí ilẹ̀ náà gbà; ṣugbọn nítorí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń lé wọn jáde fun yín, kí ó lè mú ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn baba yín, ṣẹ.

6 Nítorí náà, ẹ mọ̀ dájú pé, kì í ṣe nítorí ìwà òdodo yín ni OLUWA Ọlọrun yín fi ń fun yín ní ilẹ̀ dáradára yìí, nítorí pé, olórí kunkun eniyan ni yín.

7 “Ẹ ranti, ẹ má sì ṣe gbàgbé, bí ẹ ti mú OLUWA Ọlọrun yín bínú ninu aṣálẹ̀, láti ọjọ́ tí ẹ ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti títí tí ẹ fi dé ibí yìí ni ẹ̀ ń ṣe oríkunkun sí OLUWA.

8 Àní, ní òkè Horebu, ẹ mú kí inú bí OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ pa yín run.

9 Nígbà tí mo gun orí òkè lọ, láti gba tabili òkúta, tíí ṣe majẹmu tí OLUWA ba yín dá, mo wà ní orí òkè náà fún ogoji ọjọ́, láìjẹ, láìmu.

10 OLUWA fún mi ní àwọn tabili òkúta meji náà, tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ba yín sọ láti ààrin iná, ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà ni ó wà lára àwọn tabili náà.

11 Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, OLUWA kó àwọn tabili òkúta náà, tíí ṣe tabili majẹmu, fún mi.

12 “OLUWA bá sọ fún mi pé, ‘Dìde, sọ̀kalẹ̀ kíákíá, nítorí pé àwọn eniyan rẹ, tí o kó ti Ijipti wá ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère tí a fi iná yọ́ fún ara wọn.’

13 “OLUWA tún sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí i pé olórí kunkun ni àwọn eniyan wọnyi.

14 Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n pa wọ́n run, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò láyé. N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí yóo tóbi, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.’

15 “Mo bá gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu àwọn tabili òkúta mejeeji tí a kọ majẹmu náà sí ní ọwọ́ mi. Iná sì ń jó lórí òkè náà.

16 Ojú tí n óo gbé sókè, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti yá ère wúrà tí ẹ fi iná yọ́, ẹ ti yára yipada kúrò ní ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín.

17 Mo bá mú àwọn tabili mejeeji, mo là wọ́n mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn lójú yín.

18 Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú OLUWA bíi ti àkọ́kọ́, fún ogoji ọjọ́; n kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì mu, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti dá, tí ẹ ṣe ohun tí ó burú níwájú OLUWA, tí ẹ sì mú un bínú.

19 Nítorí inú tí OLUWA ń bí si yín ati inú rẹ̀ tí kò dùn sí yín bà mí lẹ́rù, nítorí ó ti ṣetán láti pa yín run. Ṣugbọn OLUWA tún gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà náà.

20 Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà.

21 Mo bá gbé ère ọmọ mààlúù tí ẹ yá, tí ó jẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀, mo dáná sun ún, mo lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, mo sì dà á sinu odò tí ń ṣàn wá láti orí òkè.

22 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ mú OLUWA bínú ní Tabera ati ní Masa, ati ni Kibiroti Hataafa.

23 Bákan náà ni ẹ ṣe ní Kadeṣi Banea, nígbà tí OLUWA ran yín lọ, tí ó ní kí ẹ lọ gba ilẹ̀ tí òun ti fi fun yín. Ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbà á gbọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.

24 Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín, kò sí ìgbà kan tí ẹ kò ṣe orí kunkun sí OLUWA.

25 “Mo bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀ fún ogoji ọjọ́ nítorí pé ó pinnu láti pa yín run.

26 Mo gbadura sí OLUWA, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun, má ṣe pa àwọn eniyan rẹ run. Ohun ìní rẹ ni wọ́n, àwọn tí o ti fi agbára rẹ rà pada, tí o fi ipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

27 Ranti Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu, àwọn iranṣẹ rẹ. Má wo ti oríkunkun àwọn eniyan wọnyi, tabi ìwà burúkú wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’

28 kí àwọn ará ilẹ̀ tí o ti kó wa wá má baà wí pé, ‘OLUWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn ati pé ó kórìíra wọn, ni ó ṣe kó wọn wá sinu aṣálẹ̀ láti pa wọ́n.

29 Nítorí pé, eniyan rẹ ni wọ́n, ohun ìní rẹ ni wọ́n sì jẹ́, àwọn tí o fi agbára ńlá ati ipá kó jáde.’

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 10

Mose Tún Gba Òfin

1 “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, fi igi kan àpótí kan kí o sì gun orí òkè tọ̀ mí wá.

2 N óo kọ ohun tí mo kọ sí ara àwọn tabili ti àkọ́kọ́ tí o fọ́ sí ara wọn, o óo sì kó wọn sinu àpótí náà.’

3 “Mo bá fi igi akasia kan àpótí kan, mo sì gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, mo gun orí òkè lọ pẹlu àwọn tabili náà lọ́wọ́ mi.

4 OLUWA bá kọ àwọn òfin mẹ́wàá tí ó kọ sí ara àwọn tabili àkọ́kọ́ sára àwọn tabili náà, ó sì kó wọn fún mi. Àwọn òfin mẹ́wàá yìí ni OLUWA sọ fun yín lórí òkè láti ààrin iná ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà.

5 Mo gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, mo sì kó àwọn tabili náà sinu àpótí tí mo kàn, wọ́n sì wà níbẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi.”

6 (Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀.

7 Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ sí Gudigoda. Láti Gudigoda, wọ́n lọ sí Jotibata, ilẹ̀ tí ó kún fún ọpọlọpọ odò tí ń ṣàn.

8 Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí.

9 Nítorí náà ni àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tabi ogún pẹlu àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti wí fún wọn.)

10 “Mo wà ní orí òkè fún odidi ogoji ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, OLUWA sì tún gbọ́ ohùn mi, ó gbà láti má pa yín run.

11 OLUWA wí fún mi pé, ‘Gbéra, kí o máa lọ láti ṣáájú àwọn eniyan náà, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún wọn pé n óo fún wọn.’

Ohun Tí Ọlọrun Ń Bèèrè

12 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, kò sí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fẹ́ kí ẹ ṣe, àfi pé kí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn yín ati ẹ̀mí yín,

13 kí ẹ sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀, tí mo paláṣẹ fun yín lónìí mọ́, fún ire ara yín.

14 Wò ó, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ni ọ̀run, ati ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;

15 sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé.

16 Nítorí náà, ẹ gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí ẹ má sì ṣe oríkunkun mọ́.

17 Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun àwọn ọlọ́run, ati OLUWA àwọn olúwa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù ni Ọlọrun yín, kì í ṣe ojuṣaaju, kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

18 A máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn aláìníbaba ati àwọn opó. Ó fẹ́ràn àwọn àlejò, a sì máa fún wọn ní oúnjẹ ati aṣọ.

19 Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn àwọn àlejò; nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Ijipti rí.

20 Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.

21 Òun ni kí ẹ máa yìn, òun ni Ọlọrun yín, tí ó ṣe nǹkan ńláńlá tí ó bani lẹ́rù wọnyi fun yín, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.

22 Aadọrin péré ni àwọn baba ńlá yín nígbà tí wọn ń lọ sí ilẹ̀ Ijipti; ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 11

Títóbi OLUWA

1 “Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo ìkìlọ̀ ati ìlànà, ati ìdájọ́, ati òfin rẹ̀ nígbà gbogbo.

2 (Kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí mò ń sọ ni mò ń bá sọ̀rọ̀); nítorí náà, ẹ máa ṣe akiyesi ìtọ́ni OLUWA Ọlọrun yín, ati títóbi rẹ̀, ati agbára rẹ̀, ati ipá rẹ̀.

3 Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe ní ilẹ̀ Ijipti sí ọba Farao, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

4 Ẹ ranti ohun tí ó ṣe sí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ijipti ati sí àwọn ẹṣin wọn ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn; bí ó ti jẹ́ kí omi Òkun Pupa bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń le yín bọ̀, ati bí OLUWA ti pa wọ́n run títí di òní olónìí.

5 Ẹ ranti ohun gbogbo tí ó ṣe fun yín ninu aṣálẹ̀ títí tí ẹ fi dé ìhín;

6 ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli.

7 Ẹ ti fi ojú rí gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA ṣe.

Ibukun Ilẹ̀ Ìlérí náà

8 “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà.

9 Kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fún wọn ati àwọn arọmọdọmọ wọn. Ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó sì ní ẹ̀tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin.

10 Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́.

11 Ṣugbọn ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè ati àfonífojì. Láti ojú ọ̀run ni òjò ti ń rọ̀ sí i.

12 OLUWA Ọlọrun yín tìkararẹ̀ ni ó ń tọ́jú rẹ̀, tí ó sì ń mójútó o láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí dé òpin.

13 “Tí ẹ bá tẹ̀lé òfin mi tí mo fun yín lónìí, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn ati ẹ̀mí yín,

14 yóo rọ òjò sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ baà lè kórè ọkà, ọtí waini, ati òróró olifi yín.

15 Yóo mú kí koríko dàgbà ninu pápá fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ óo jẹ, ẹ óo sì yó.

16 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ̀tàn má baà wọ inú ọkàn yín, kí ẹ má baà yipada sí àwọn oriṣa, kí ẹ sì máa bọ wọ́n.

17 Kí inú má baà bí Ọlọrun si yín, kí o má baà mú kí òjò dáwọ́ dúró, kí ilẹ̀ yín má sì so èso mọ́; kí ẹ má baà parun kíákíá lórí ilẹ̀ tí OLUWA fun yín.

18 “Nítorí náà, ohun tí mo sọ fun yín yìí, ẹ pa á mọ́ sinu ọkàn yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín gẹ́gẹ́ bí àmì, kí ẹ fi ṣe ọ̀já ìgbàjú, kí ó wà ní agbede meji ojú yín mejeeji.

19 Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín dáradára, ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí ẹ bá jókòó ninu ilé yín ati ìgbà tí ẹ bá ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ati ìgbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn yín ati nígbà tí ẹ bá dìde.

20 Ẹ kọ ọ́ sí ara òpó ìlẹ̀kùn ilé yín ati sí ara ẹnu ọ̀nà àbájáde ilé yín.

21 Kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun búra fún àwọn baba yín, pé òun yóo fún wọn títí lae, níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá wà lókè.

22 “Tí ẹ bá ṣọ́ra, tí ẹ sì pa gbogbo òfin tí mo fun yín mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,

23 OLUWA yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde fun yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ.

24 Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

25 Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.

26 “Ẹ wò ó, mo gbé ibukun ati ègún kalẹ̀ níwájú yín lónìí.

27 Ibukun ni fun yín bí ẹ bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí mo fun yín lónìí yìí.

28 Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí.

29 Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú yín dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ, tí ẹ óo sì gbà, ẹ kéde ibukun náà lórí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde ègún náà lórí òkè Ebali.

30 Òkè Gerisimu ati òkè Ebali wà ní òdìkejì Jọdani, ní ojú ọ̀nà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé Araba, ní òdìkejì Giligali, lẹ́bàá igi Oaku More.

31 Nítorí ẹ óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á tán, tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀,

32 ẹ ṣọ́ra, kí ẹ máa tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati òfin tí mo fi lélẹ̀ níwájú yín lónìí.

Categories
DIUTARONOMI

DIUTARONOMI 12

Ibi Ìjọ́sìn Kanṣoṣo Náà

1 “Àwọn ìlànà ati òfin, tí ẹ óo máa tẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fi fun yín láti gbà, nìyí:

2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo lé kúrò ti ń sin oriṣa wọn ni kí ẹ wó lulẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà lórí òkè ńlá, ati àwọn tí wọ̀n wà lórí àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ igi tútù.

3 Ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ fọ́ gbogbo òpó wọn, ẹ dáná sun àwọn ère oriṣa Aṣera wọn, ẹ gé gbogbo àwọn ère oriṣa wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò níbẹ̀.

4 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa sin OLUWA Ọlọrun yín káàkiri bí wọ́n ti ń ṣe.

5 Ṣugbọn ibi tí OLUWA bá yàn láti gbé ibùjókòó rẹ̀ kà láàrin gbogbo àwọn ẹ̀yà, ibẹ̀ ni kí ẹ máa lọ.

6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú gbogbo ẹbọ sísun yín, ati àwọn ẹbọ yòókù wá, ati ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA, ati àkọ́bí mààlúù yín, ati ti aguntan yín.

7 Ibẹ̀ ni ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín yóo ti jẹun níwájú OLUWA Ọlọrun yín, inú yín yóo sì dùn nítorí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín tí OLUWA ti fi ibukun sí.

8 “Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe bí a ti ń ṣe níbí lónìí, tí olukuluku ń ṣe èyí tí ó dára lójú ara rẹ̀.

9 Nítorí pé ẹ kò tíì dé ibi ìsinmi ati ilẹ̀ ìní tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín.

10 Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, nígbà tí ó bá sì fun yín ní ìsinmi, tí ẹ bá bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí yín ká, tí ẹ sì wà ní àìléwu,

11 ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn láti fi ibùgbé rẹ̀ sí nígbà náà, ni kí ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín wa, ẹbọ sísun yín ati àwọn ẹbọ mìíràn, ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ, ati gbogbo ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA.

12 Ẹ óo sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ati ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin yín, ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín ninu ilẹ̀ yín.

13 Ẹ ṣọ́ra, ẹ má máa rú ẹbọ sísun yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí.

14 Ṣugbọn ibi tí OLUWA yín bá yàn láàrin ẹ̀yà yín, ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín níbẹ̀.

15 “Ṣugbọn ẹ lè pa iye ẹran tí ó bá wù yín, kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbikíbi tí ẹ bá ń gbé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó. Ẹni tí ó mọ́, ati ẹni tí kò mọ́ lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

16 Ẹ̀jẹ̀ wọn nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí ẹni da omi.

17 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín.

18 Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

19 Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín.

20 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín.

21 Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín.

22 Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

23 Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nítorí pé ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀mí rẹ̀.

24 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

25 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA.

26 Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ.

27 Kí ẹ rú ẹbọ sísun yín ati ẹran ati ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ yín sórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì jẹ ara ẹran rẹ̀.

28 Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

Ìkìlọ̀ nípa Ìbọ̀rìṣà

29 “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run níbi gbogbo tí ẹ bá lọ, tí ẹ bá bá wọn jagun tí ẹ gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé ibẹ̀;

30 ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà ṣìnà, lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti pa wọ́n run tán, kí ẹ má baà bèèrè pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ṣe ń bọ àwọn oriṣa wọn? Kí àwa náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀.’

31 Ẹ kò gbọdọ̀ sin OLUWA Ọlọrun yín bí wọn ti ń bọ àwọn oriṣa wọn nítorí oríṣìíríṣìí ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú OLUWA ni wọ́n máa ń ṣe. Wọn a máa fi àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn rúbọ sí oriṣa wọn.

32 “Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín ni kí ẹ fọkàn sí, kí ẹ sì ṣe é, ẹ kò gbọdọ̀ fi kún un, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀.