Categories
JOHANU KINNI

JOHANU KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìdí meji pataki ni ẹni tí ó kọ

Ìwé Kinni Johanu

fi kọ ọ́. Ìdí kinni ni láti gba àwọn olùkà rẹ̀ ní ìyànjú láti gbé ìgbé-ayé ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ati Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀. Ìdí keji ni láti kìlọ̀ fún wọn láti má tẹ̀lé ẹ̀kọ́ èké tí yóo ba ìrẹ́pọ̀ yìí jẹ́. Ìdí tí irú ẹ̀kọ́ yìí fi wáyé rárá ni pé àwọn eniyan ìgbà náà gbàgbọ́ pé fífi ara kan ayé yìí ní í ṣe okùnfà ibi. Nítorí ìdí èyí, Jesu tíí ṣe Ọmọ Ọlọrun kò lè tún jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara. Àwọn tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan ní irú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ yìí sọ pé kí á dá eniyan nídè kúrò ninu kíkó ayé yìí lékàn ni à ń pè ní ìgbàlà. Wọn kò fi mọ bẹ́ẹ̀, wọ́n tún fi kún un pé ìgbàlà kò ní ohunkohun ṣe pẹlu ọ̀ràn ìwà dáradára tabi ìfẹ́ ọmọnikeji ẹni.

Ẹni tí ó kọ ìwé yìí tako irú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ yìí, ó ní eniyan ẹlẹ́ran-ara gan-an ni Jesu, ó wá tẹnumọ́ ọn pé, gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba Jesu gbọ́, tí wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun níláti fẹ́ràn ọmọnikeji wọn.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-4

Ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn 1:5–2:29

Àwọn ọmọ Ọlọrun ati àwọn ọmọ Èṣù 3:1-24

Òtítọ́ ati èké 4:1-6

Iṣẹ́ ìfẹ́ 4:7-21

Igbagbọ tí ń ṣẹgun 5:1-21

Categories
JOHANU KINNI

JOHANU KINNI 1

Ọ̀rọ̀ Ìyè

1 Ohun tí ó ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, ohun tí a ti gbọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ ìyè, tí a ti fi ojú ara wa rí, tí a wò dáradára, tí a fi ọwọ́ wa dìmú, òun ni à ń sọ fun yín.

2 Ìyè yìí farahàn, a ti rí i, a sì ń jẹ́rìí rẹ̀. Ìyè ainipẹkun yìí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó ti farahàn fún wa, ni a wá ń kéde fun yín.

3 Ohun tí a ti rí, tí a sì ti gbọ́ ni à ń kéde fun yín, kí ẹ lè ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu wa. Ìrẹ́pọ̀ yìí ni a ní pẹlu Baba ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi.

4 À ń kọ àwọn nǹkan wọnyi si yín kí ayọ̀ wa lè kún.

Ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun

5 Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá.

6 Bí a bá wí pé a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀, tí a bá ń gbé inú òkùnkùn, òpùrọ́ ni wá, a kò sì ṣe olóòótọ́.

7 Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.

8 Bí a bá wí pé a kò lẹ́ṣẹ̀, ara wa ni à ń tàn jẹ, òtítọ́ kò sì sí ninu wa.

9 Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa.

10 Bí a bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀ rí, a mú Ọlọrun lékèé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí ninu wa.

Categories
JOHANU KINNI

JOHANU KINNI 2

Jesu Alágbàwí Wa

1 Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo.

2 Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kì í ṣe tiwa nìkan, ṣugbọn ti gbogbo ayé pẹlu.

3 Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a mọ Ọlọrun ni pé bí a bá ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

4 Òpùrọ́ ni ẹni tí ó bá wí pé òun mọ̀ ọ́n, ṣugbọn tí kò bá máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò sí òtítọ́ ninu olúwarẹ̀.

5 Ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọrun ti di pípé ninu ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé a wà ninu rẹ̀ nìyí

6 ẹni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú Ọlọrun níláti máa gbé irú ìgbé-ayé tí Jesu fúnrarẹ̀ gbé.

Òfin Titun

7 Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.

8 Ṣugbọn ní ìdàkejì, òfin titun ni mò ń kọ si yín, èyí tí a rí òtítọ́ rẹ̀ ninu Jesu Kristi ati ninu yín, nítorí pé òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti ń tàn.

9 Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ.

10 Ẹni tí ó bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, ohun ìkọsẹ̀ kò sí ninu olúwarẹ̀.

11 Ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀ wà ninu òkùnkùn; kò mọ ibi tí ó ń lọ, nítorí òkùnkùn ti fọ́ ọ lójú.

Àwọn Tí A Kọ Ìwé Yìí sí

12 Ẹ̀yin ọmọde, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ Jesu.

13 Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba.

14 Ẹ̀yin baba, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ lágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń gbé inú yín, ẹ sì ti ṣẹgun Èṣù.

Afẹ́ Ayé

15 Ẹ má fẹ́ràn ayé tabi àwọn nǹkan ayé. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ayé kò ní ìfẹ́ sí Baba.

16 Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé.

17 Ayé ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń kọjá lọ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóo wà títí lae.

Alátakò Kristi

18 Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.

19 Ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti kúrò ṣugbọn wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ara wa ni wọ́n, wọn ìbá dúró lọ́dọ̀ wa. Ṣugbọn kí ó lè hàn dájú pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa ni wọ́n ṣe kúrò lọ́dọ̀ wa.

20 Ẹ̀yin ni Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi òróró yàn, gbogbo yín sì mọ òtítọ́.

21 Kì í ṣe pé ẹ kò mọ òtítọ́ ni mo ṣe kọ ìwé si yín, ṣugbọn nítorí pé ẹ mọ̀ ọ́n ni, kò sí irọ́ kankan tí ó lè jáde láti inú òtítọ́.

22 Ta ni òpùrọ́ bí ẹni tí ó bá kọ̀ láti gbà pé Jesu ni Mesaya? Olúwarẹ̀ ni Alátakò Kristi, tí ó kọ Baba ati Ọmọ.

23 Ẹni tí ó bá kọ Ọmọ kò ní Baba. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ Ọmọ ní Baba pẹlu.

24 Ẹ̀yin ẹ jẹ́ kí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ máa gbé inú yín. Bí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin yóo máa gbé inú Ọmọ ati Baba.

25 Ìlérí tí òun fúnrarẹ̀ ṣe fún wa ni ìyè ainipẹkun.

26 Mò ń kọ nǹkan wọnyi si yín nípa àwọn kan tí wọn ń tàn yín jẹ;

27 ẹ jẹ́ kí òróró tí Jesu ta si yín lórí máa gbé inú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ yín lẹ́kọ̀ọ́. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí òróró rẹ̀ ninu yín ti ń kọ yín nípa ohun gbogbo, òtítọ́ ni, kì í ṣe irọ́, ẹ máa gbé inú rẹ̀, bí ó ti kọ yín.

Àwọn ọmọ Ọlọrun

28 Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbé inú rẹ̀, kí á lè ní ìgboyà nígbà tí ó bá farahàn, kí ojú má baà tì wá láti wá siwaju rẹ̀ nígbà tí ó bá dé.

29 Bí ẹ bá mọ̀ pé olódodo ni, ẹ mọ̀ pé gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo ni ọmọ rẹ̀.

Categories
JOHANU KINNI

JOHANU KINNI 3

1 Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fẹ́ wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọrun! Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a sì jẹ́. Nítorí náà, ayé kò mọ̀ wá, nítorí wọn kò mọ Ọlọrun.

2 Olùfẹ́, nisinsinyii ọmọ Ọlọrun ni wá. Ohun tí a óo dà kò ì tíì hàn sí wa. A mọ̀ pé nígbà tí Jesu Kristi bá yọ, bí ó ti rí ni àwa náà yóo rí, nítorí a óo rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti rí.

3 Gbogbo ẹni tí ó bá ní ìrètí yìí ninu Jesu yóo wẹ ara rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jesu fúnrarẹ̀, ti jẹ́ mímọ́.

4 Gbogbo ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ ń rú òfin, nítorí rírú òfin ni ẹ̀ṣẹ̀.

5 Ẹ sì mọ̀ pé Jesu wá láti kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun alára kò dá ẹyọ ẹ̀ṣẹ̀ kan.

6 Gbogbo ẹni tí ó bá ń gbé inú rẹ̀ kò ní máa dẹ́ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ kò ì tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n.

7 Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe òdodo ni olódodo, bí Jesu ti jẹ́ olódodo.

8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Èṣù ni ó ti wá, nítorí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọrun ṣe wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run.

9 Gbogbo ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí irú-ọmọ Ọlọrun yóo máa gbé inú olúwarẹ̀, nítorí náà, kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

10 Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọrun yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù nìyí: gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sì fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

Ẹ Fẹ́ràn Ẹnìkejì Yín

11 Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.

12 Kí á má dàbí Kaini tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí ó pa arakunrin rẹ̀. Kí ló dé tí ó fi pa á? Nítorí iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣugbọn ti arakunrin rẹ̀ dára.

13 Ẹ má jẹ́ kí ẹnu yà yín bí ayé bá kórìíra yín.

14 Àwa mọ̀ pé a ti rékọjá láti inú ikú sí inú ìyè, nítorí a fẹ́ràn àwọn arakunrin. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ wà ninu ikú.

15 Apànìyàn ni ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀. Ẹ sì ti mọ̀ pé kò sí apànìyàn kan tí ìyè ainipẹkun ń gbé inú rẹ̀.

16 Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.

17 Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀?

18 Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ẹnu tabi ti ètè lásán; ṣugbọn kí ó jẹ́ ti ìwà ati ti òtítọ́.

Ìgboyà Níwájú Ọlọrun

19 Ọ̀nà tí a óo fi mọ̀ pé a jẹ́ ẹni òtítọ́ nìyí; níwájú Ọlọrun pàápàá ọkàn wa yóo balẹ̀.

20 Bí ọkàn wa bá tilẹ̀ dá wa lẹ́bi, kí á ranti pé Ọlọrun tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.

21 Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní ìgboyà níwájú Ọlọrun.

22 À ń rí ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà, nítorí pé à ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀.

23 Àṣẹ rẹ̀ nìyí: pé kí á gba orúkọ Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi, gbọ́, kí á sì fẹ́ràn ẹnìkejì wa, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fi àṣẹ fún wa.

24 Ẹni tí ó bá ń pa òfin Ọlọrun mọ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé Ọlọrun ń gbé inú wa ni nípa Ẹ̀mí tí ó ti fi fún wa.

Categories
JOHANU KINNI

JOHANU KINNI 4

Ẹ̀mí Ọlọrun ati Ẹ̀mí Alátakò Kristi

1 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.

2 Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

3 Gbogbo ẹni tí kò bá jẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọrun. Alátakò Kristi tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀ ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ti dé inú ayé nisinsinyii.

4 Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyí, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ.

5 Láti inú ayé ni àwọn yìí ti wá; nítorí náà, wọ́n ń sọ nǹkan ti ayé, àwọn aráyé sì ń gbọ́ tiwọn.

6 Ti Ọlọrun ni àwa; Ẹni tí ó bá mọ Ọlọrun ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í bá ṣe ti Ọlọrun kò ní gbọ́ tiwa. Ọ̀nà tí a fi mọ Ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí ìtànjẹ yàtọ̀ nìyí.

Ìfẹ́ ni Ọlọrun

7 Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́, ó sì mọ Ọlọrun.

8 Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọrun nítorí ìfẹ́ ni Ọlọrun.

9 Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.

10 Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí: kì í ṣe pé àwa ni a fẹ́ràn Ọlọrun ṣugbọn òun ni ó fẹ́ràn wa, tí ó rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jẹ́ ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.

11 Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa.

12 Ẹnikẹ́ni kò rí Ọlọrun rí, bí a bá fẹ́ràn ọmọnikeji wa, Ọlọrun ń gbé inú wa, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti di pípé ninu wa.

13 A mọ̀ pé à ń gbé inú Ọlọrun ati pé òun náà ń gbé inú wa nítorí pé ó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀.

14 Àwa ti rí i, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ olùgbàlà aráyé.

15 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu, Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀, òun náà sì ń gbé inú Ọlọrun.

16 A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí.

Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.

17 Nípa bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ṣe di pípé ninu wa, kí á lè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́ pé bí ó ti rí ni àwa náà rí ninu ayé yìí.

18 Kò sí ẹ̀rù ninu ìfẹ́; ìfẹ́ pípé a máa lé ẹ̀rù jáde, nítorí ìjayà ni ó ń mú ẹ̀rù wá. Ẹni tí ó bá ń bẹ̀rù kò ì tíì di pípé ninu ìfẹ́.

19 A fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé Ọlọrun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.

20 Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí.

21 Àṣẹ tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi ni pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọrun, kí ó fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ pẹlu.

Categories
JOHANU KINNI

JOHANU KINNI 5

Igbagbọ ni Ìṣẹ́gun lórí Ayé

1 Gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba yóo fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀.

2 Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọrun ni pé kí á fẹ́ràn Ọlọrun kí á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.

3 Fífẹ́ràn Ọlọrun ni pé kí á pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́: àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì wọni lọ́rùn,

4 nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun ti ṣẹgun ayé. Igbagbọ wa ni ìṣẹ́gun lórí ayé.

5 Ta ni ó ti ṣẹgun ayé? Àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu.

Ẹ̀rí nípa Ọmọ

6 Òun yìí ni ó wà nípa omi ati ẹ̀jẹ̀, àní Jesu Kristi. Kì í ṣe nípa omi nìkan, ṣugbọn nípa omi ati ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀mí ni ó ń jẹ́rìí, nítorí òtítọ́ ni Ẹ̀mí.

7 Àwọn ẹlẹ́rìí mẹta ni ó wà:

8 Ẹ̀mí, omi ati ẹ̀jẹ̀. Nǹkankan náà ni àwọn mẹtẹẹta ń tọ́ka sí.

9 À ń gba ẹ̀rí eniyan, ṣugbọn ẹ̀rí Ọlọrun tóbi ju ti eniyan lọ; nítorí ẹ̀rí Ọlọrun ni, tí ó jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀.

10 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọrun gbọ́ ní ẹ̀rí yìí ninu ara rẹ̀. Ẹni tí kò bá gba Ọlọrun gbọ́ mú Ọlọrun lékèé, nítorí kò gba ẹ̀rí tí Ọlọrun ti jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀ gbọ́.

11 Ẹ̀rí náà ni pé Ọlọrun ti fún wa ní ìyè ainipẹkun, ìyè yìí sì wà ninu Ọmọ rẹ̀.

12 Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè.

Ìyè Ainipẹkun

13 Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun.

14 Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa.

15 Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà.

16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arakunrin rẹ̀ tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ kan, tí kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ mọ́ ti ikú, kí ó gbadura fún un, Ọlọrun yóo fún un ní ìyè. Mò ń sọ nípa àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò jẹ mọ́ ti ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ. N kò wí pé kí eniyan gbadura fún irú rẹ̀.

17 Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí kò jẹ mọ́ ti ikú.

18 A mọ̀ pé kò sí ọmọ Ọlọrun kan tíí máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ń pa á mọ́, Èṣù kò sì ní fọwọ́ kàn án.

19 A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.

20 A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.

21 Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má bá wọn bọ oriṣa.

Categories
JOHANU KEJI

JOHANU KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ẹnìkan tí àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ ń pè ní “Alàgbà” ni ó kọ

Ìwé Keji Johanu

sí arabinrin kan tí ó ṣọ̀wọ́n ati àwọn ọmọ rẹ̀. Bóyá ìjọ kan ati àwọn ọmọ ìjọ yìí ní ìtumọ̀ àdììtú èdè yìí. Kókó ohun tí ó wà ninu ìwé kúkúrú yìí ni ìgbani-níyànjú láti fẹ́ràn ọmọnikeji ẹni ati ìkìlọ̀ nípa àwọn olùkọ́ni èké ati ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1-3

Bí ìfẹ́ ṣe tayọ gbogbo nǹkan 4-6

Ìkìlọ̀ nípa ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ 7-11

Ọ̀rọ̀ ìparí 12-13

Categories
JOHANU KEJI

JOHANU KEJI 1

Ìkíni

1 Èmi Alàgbà ni mo kọ ìwé yìí sí àyànfẹ́ arabinrin ati àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Kì í ṣe èmi nìkan ni mo fẹ́ràn rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ ni;

2 nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae.

3 Oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi Ọmọ Baba yóo wà pẹlu wa ninu òtítọ́ ati ìfẹ́.

Ẹ Máa Gbé Inú Ẹ̀kọ́ Kristi

4 Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba.

5 Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.

6 Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.

7 Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi.

8 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa iṣẹ́ tí ẹ ti ṣe run, kí ẹ lè gba èrè kíkún.

9 Ẹnikẹ́ni tí kò bá máa gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi, ṣugbọn tí ó bá tayọ rẹ̀, kò mọ Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ẹ̀kọ́ Kristi mọ Baba ati Ọmọ.

10 Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín tí kò mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé. Ẹ má tilẹ̀ kí i, “Kú ààbọ̀.”

11 Ẹni tí ó bá kí i di alábàápín ninu àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.

Ìdágbére

12 Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún.

13 Àwọn ọmọ àyànfẹ́ arabinrin rẹ kí ọ.

Categories
JOHANU KẸTA

JOHANU KẸTA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Gaiyu, tí ó jẹ́ adarí ìjọ, ni “Alàgbà” kan kọ

Ìwé Kẹta Johanu

sí. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí yin Gaiyu nítorí ìrànlọ́wọ́ tí ó ṣe fún àwọn onigbagbọ mìíràn. Ó sì kìlọ̀ fún un nípa ọkunrin kan tí ń jẹ́ Diotirefe.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1-4

Yíyin Gaiyu 5-8

Bíbu ẹnu àtẹ́ lu Diotirefe 9-10

Ọ̀rọ̀ dáradára nípa Demeteriu 11-12

Ọ̀rọ̀ ìparí 13-15

Categories
JOHANU KẸTA

JOHANU KẸTA 1

Ìkíni

1 Èmi, Alàgbà, ni mo kọ ìwé yìí sí ọ, Gaiyu olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ràn nítòótọ́.

2 Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí.

3 Inú mi dùn nígbà tí àwọn arakunrin dé, tí wọ́n ròyìn rẹ pé o ṣe olóòótọ́ sí ọ̀nà òtítọ́, ati pé ò ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.

4 Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.

Àjọṣepọ̀

5 Olùfẹ́, ohun rere ni ò ń ṣe fún àwọn arakunrin, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àlejò.

6 Níwájú gbogbo ìjọ níhìn-ín wọ́n jẹ́rìí sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ fún òṣìṣẹ́ Ọlọrun.

7 Nítorí pé orúkọ Jesu ni ó mú wọn máa rin ìrìn àjò láì gba ohunkohun lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ.

8 Ó yẹ kí á máa ran irú wọn lọ́wọ́ kí á lè jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu wọn ninu iṣẹ́ òtítọ́.

Diotirefe Lòdì sí Wa

9 Mo kọ ìwé kan sí ìjọ ṣugbọn Diotirefe tí ó fẹ́ ipò aṣiwaju láàrin ìjọ kò gba ohun tí mo sọ.

10 Nítorí náà, nígbà tí mo bá dé, n óo ranti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, tí ó ń sọ ìsọkúsọ nípa mi. Kò fi ọ̀ràn mọ bẹ́ẹ̀; kò gba àwọn arakunrin tí wọ́n wá, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ gbà wọ́n, kò jẹ́ kí wọ́n gbà wọ́n, ó tún fẹ́ yọ wọ́n kúrò ninu ìjọ!

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú

11 Olùfẹ́, má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú, ṣugbọn tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti wá. Ẹni tí ó bá ń ṣe burúkú kò mọ Ọlọrun.

12 Gbogbo eniyan ni wọ́n ń ròyìn Demeteriu ní rere. Òtítọ́ pàápàá ń jẹ́rìí rẹ̀. Èmi náà jẹ́rìí sí i, o sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí mi.

Ó Dìgbà Díẹ̀

13 Mo ní ohun pupọ tí mo fẹ́ bá ọ sọ, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé.

14 Mo ní ìrètí ati rí ọ láìpẹ́, nígbà náà a óo lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju.

15 Kí alaafia máa bá ọ gbé. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa níhìn-ín kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́kọ̀ọ̀kan.