Categories
PETERU KINNI

PETERU KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ẹni tí ó kọ

Ìwé Kinni láti Ọ̀dọ̀ Peteru

kọ ọ́ sí àwọn onigbagbọ tí a pè ní “àṣàyàn eniyan Ọlọrun” ninu ìwé yìí tí wọ́n fọ́n káàkiri apá kan ilẹ̀ Esia tí a lè pè ní Esia kékeré ní èdè Yoruba (Asia Minor). Ìdí pataki tí a fi kọ ìwé náà ni láti fún àwọn olùkà rẹ̀ ní ìwúrí ní àkókò tí wọ́n wà ninu inúnibíni ati ìjìyà nítorí igbagbọ wọn. Ọ̀nà tí ẹni tí ó kọ ìwé yìí gbà fún àwọn olùkà rẹ̀ ní ìwúrí ni pé ó rán wọn létí Ìròyìn Ayọ̀ nípa Jesu Kristi, ẹni tí ikú rẹ̀, ajinde rẹ̀, ati ìpadàbọ̀ rẹ̀ fún wọn ní ìrètí. Ó ní ti Jesu yìí ni kí wọ́n wò kí wọ́n fi gba ìjìyà wọn, kí wọ́n faradà á, pẹlu ìdánilójú pé ìdánwò ní ó jẹ́, láti mọ̀ bí igbagbọ wọn bá jẹ́ ojúlówó, ati pé wọn óo gba èrè rẹ̀ ní “Ọjọ́ tí Jesu bá farahàn.”

Bí ẹni tí ó kọ ìwé yìí ti ń dá àwọn eniyan lọ́kàn le ní àkókò ìyọnu, ó tún ń rọ̀ wọ́n láti máa gbé ìgbé-ayé irú àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ ti Kristi.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2

Ìránnilétí ìgbàlà Ọlọrun 1:3-12

Ìgbani-níyànjú fún ìgbé-ayé mímọ́ 1:13–2:10

Iṣẹ́ onigbagbọ ní àkókò ìjìyà 2:11–4:19

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ati iṣẹ́ onigbagbọ 5:1-11

Ọ̀rọ̀ ìparí 5:12-14

Categories
PETERU KINNI

PETERU KINNI 1

1 Èmi Peteru, aposteli Jesu Kristi ni mò ń kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin tí ẹ fọ́n káàkiri àwọn ìlú àjèjì bíi Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia.

2 Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́.

Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín.

Ìrètí tí Ó Wà Láàyè

3 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú.

4 Ó fún wa ni ogún ainipẹkun, ogún tí kò lè díbàjẹ́, tí kò lè ṣá, tí a ti fi pamọ́ fun yín ní ọ̀run.

5 Ẹ̀yin ni a ti dáàbò bò nípa agbára Ọlọrun nípa igbagbọ sí ìgbàlà tí a ti ṣe ètò láti fihàn ní ọjọ́ ìkẹyìn.

6 Ẹ máa yọ̀ nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún àkókò díẹ̀, ẹ níláti ní ìdààmú nípa oríṣìíríṣìí ìdánwò.

7 Wúrà níláti kọjá ninu iná, bẹ́ẹ̀ sì ni ó pẹ́ ni, ó yá ni, yóo ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a níláti dán igbagbọ yín tí ó ní iye lórí ju wúrà lọ wò. Irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ yóo gba ìyìn, ògo, ati ọlá nígbà tí Jesu Kristi bá dé.

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i, sibẹ ẹ fẹ́ràn rẹ̀. Ẹ kò rí i sójú nisinsinyii, sibẹ ẹ gbà á gbọ́, ẹ sì ń yọ ayọ̀ tí ẹnu kò lè sọ, ayọ̀ tí ó lógo,

9 nítorí pé ẹ jèrè igbagbọ yín nípa ìgbàlà ọkàn yín.

10 Àwọn wolii tí wọ́n ṣe ìkéde oore-ọ̀fẹ́ tún fẹ̀sọ̀ wádìí nípa ìgbàlà yìí.

11 Wọ́n ń wádìí nípa ẹni náà ati àkókò náà, tí Ẹ̀mí Kristi tí ó wà ninu wọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà tí Kristi níláti jẹ, ati bí yóo ti ṣe bọ́ sinu ògo lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀.

12 Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi.

Ìpè sí Ìgbé-Ayé Mímọ́

13 Nítorí náà, ẹ ṣe ọkàn yìn gírí. Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́. Ẹ máa retí oore-ọ̀fẹ́ tí yóo jẹ́ tiyín nígbà tí Jesu Kristi bá tún dé.

14 Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ń gbọ́ràn, ẹ má gbé irú ìgbé-ayé yín ti àtijọ́, nígbà tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín tí ẹ kò mọ̀ pé àìdára ni.

15 Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pè yín ti jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín.

16 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Ọlọrun ní, “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí èmi náà jẹ́ mímọ́.”

17 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń pe Ọlọrun ní Baba tí kì í ṣe ojuṣaaju, tí ó jẹ́ pé bí iṣẹ́ olukuluku bá ti rí ní ó fi ń ṣe ìdájọ́, ẹ máa fi ìbẹ̀rù gbé ìgbé-ayé yín ní ìwọ̀nba àkókò tí ẹ ní.

18 Nítorí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí ó lè bàjẹ́, bíi fadaka ati wúrà, ni a fi rà yín pada kúrò ninu ìgbé-ayé asán tí ẹ jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.

19 Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n.

20 Kí á tó dá ayé ni a ti yan Kristi fún iṣẹ́ yìí. Ṣugbọn ní àkókò ìkẹyìn yìí ni ó tó fi ara hàn nítorí tiyín.

21 Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun.

22 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín.

23 A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí.

24 Nítorí,

“Gbogbo ẹlẹ́ran-ara dàbí Koríko,

gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó.

Koríko a máa gbẹ,

òdòdó a máa rẹ̀,

25 ṣugbọn ọ̀rọ̀ Oluwa yóo wà títí lae.”

Òun ni ọ̀rọ̀ tí à ń waasu rẹ̀ fun yín.

Categories
PETERU KINNI

PETERU KINNI 2

Òkúta Ààyè ati Orílẹ̀-Èdè Mímọ́

1 Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù.

2 Ẹ ṣe bí ọmọ-ọwọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí òùngbẹ wàrà gidi ti ẹ̀mí ń gbẹ, kí ó lè mu yín dàgbà fún ìgbàlà.

3 Ó ṣá ti hàn si yín pé olóore ni Oluwa.

4 Ẹ wá sọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe òkúta ààyè tí eniyan kọ̀ sílẹ̀ ṣugbọn tí Ọlọrun yàn, tí ó ṣe iyebíye lójú rẹ̀.

5 Ẹ fi ara yín kọ́ ilé ẹ̀mí bí òkúta ààyè, níbi tí ẹ óo jẹ́ alufaa mímọ́, tí ẹ óo máa rú ẹbọ ẹ̀mí tí Ọlọrun yóo tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jesu Kristi.

6 Nítorí ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé,

“Mo fi òkúta lélẹ̀ ní Sioni,

àṣàyàn òkúta igun ilé tí ó ṣe iyebíye.

Ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”

7 Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí,

“Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀,

òun ni ó di pataki igun ilé.”

8 Ati,

“Òkúta tí yóo mú eniyan kọsẹ̀,

ati àpáta tí yóo gbé eniyan ṣubú.”

Àwọn tí ó ṣubú ni àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́. Bẹ́ẹ̀, bí ti irú wọn ti níláti rí nìyí.

9 Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.

10 Ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe eniyan nígbà kan, ṣugbọn nisinsinyii ẹ di eniyan Ọlọrun. Ẹ̀yin tí ẹ kò tíì rí àánú gbà tẹ́lẹ̀ ṣugbọn nisinsinyii ẹ di ẹni tí Ọlọrun ṣàánú fún.

Ẹ Jẹ́ Iranṣẹ Ọlọrun

11 Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun.

12 Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.

13 Ẹ fi ara yín sábẹ́ òfin ìjọba ilẹ̀ yín nítorí ti Oluwa, ìbáà ṣe ọba gẹ́gẹ́ bí olórí,

14 tabi aṣojú ọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rán láti jẹ àwọn tí ó bá ń ṣe burúkú níyà, ati láti yin àwọn tí ó bá ń ṣe rere.

15 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọrun pé nípa ìwà rere yín, kí kẹ́kẹ́ pamọ́ àwọn aṣiwèrè ati àwọn òpè lẹ́nu.

16 Ẹ máa hùwà bí ẹni tí ó ní òmìnira, ṣugbọn kì í ṣe òmìnira láti bo ìwà burúkú mọ́lẹ̀. Ẹ máa hùwà bí iranṣẹ Ọlọrun.

17 Ẹ máa yẹ́ gbogbo eniyan sí. Ẹ máa fẹ́ràn àwọn onigbagbọ. Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun. Ẹ máa bu ọlá fún ọba.

Àpẹẹrẹ Ìjìyà Jesu

18 Ẹ̀yin ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀gá yín ninu gbogbo nǹkan pẹlu ìbẹ̀rù, kì í ṣe fún àwọn ọ̀gá tí ó ní inú rere, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ si yín nìkan, ṣugbọn fún àwọn tí wọ́n rorò pẹlu.

19 Nítorí ó dára kí eniyan farada ìyà tí kò tọ́ sí i tí ó bá ronú ti Ọlọrun.

20 Nítorí ẹ̀yẹ wo ni ó wà ninu pé ẹ ṣe àìdára, wọ́n lù yín, ẹ wá faradà á? Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ jìyà tí ẹ faradà á, èyí jẹ́ ẹ̀yẹ lójú Ọlọrun.

21 Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun.

22 Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí.

23 Nígbà tí àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, kò désì pada; wọ́n jẹ ẹ́ níyà, kò ṣe ìlérí ẹ̀san, ṣugbọn ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé Onídàájọ́ òdodo lọ́wọ́.

24 Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.

25 Nítorí pé nígbà kan ẹ dàbí aguntan tí ó sọnù. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti yipada sí olùṣọ́ yín ati alabojuto ọkàn yín.

Categories
PETERU KINNI

PETERU KINNI 3

Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Ọkọ ati Aya

1 Bákan náà ni kí ẹ̀yin aya máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín. Ìdí rẹ̀ ni pé bí a bá rí ninu àwọn ọkọ tí kò jẹ́ onigbagbọ, wọ́n lè yipada nípa ìwà ẹ̀yin aya wọn láìjẹ́ pé ẹ bá wọn sọ gbolohun kan nípa ẹ̀sìn igbagbọ,

2 nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà mímọ́ ati ìwà ọmọlúwàbí yín.

3 Ẹwà yín kò gbọdọ̀ jẹ́ ti òde ara nìkan bíi ti irun-dídì, ati nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí ẹ kó sára ati aṣọ-ìgbà.

4 Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun.

5 Nítorí ní ìgbà àtijọ́ irú ẹwà báyìí ni àwọn aya tí a yà sọ́tọ̀, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ninu Ọlọrun, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn.

6 Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín.

7 Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára to yín. Ẹ ranti pé wọ́n jẹ́ alábàápín ẹ̀bùn ìyè pẹlu yín. Tí ẹ bá ń ṣe èyí, kò ní sí ìdènà ninu adura yín.

Ìjìyà nítorí Òdodo

8 Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.

9 Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.

10 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,

“Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú,

tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára,

ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánu

pẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ,

kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

11 Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú,

kí ó máa hu ìwà rere.

Ó níláti máa wá alaafia,

kí ó sì máa lépa rẹ̀.

12 Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo,

ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn.

Ṣugbọn ojú Oluwa kan sí

àwọn tí ó ń ṣe burúkú.”

13 Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere?

14 Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú.

15 Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní.

16 Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

17 Nítorí ó sàn fun yín tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kí ẹ jìyà, nítorí pé ẹ̀ ń ṣe rere, jù pé ẹ̀ ń ṣe ibi lọ.

18 Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.

19 Nípa ẹ̀mí, ó lọ waasu fún àwọn ẹ̀mí tí ó wà lẹ́wọ̀n.

20 Àwọn wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹni tí kò gbàgbọ́ nígbà kan rí, nígbà ayé Noa, nígbà tí Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ mú sùúrù tí Noa fi kan ọkọ̀ tán. Ninu ọkọ̀ yìí ni àwọn eniyan díẹ̀ wà, àwọn mẹjọ, tí a fi gbà wọ́n là ninu ìkún omi.

21 Èyí jẹ́ àkàwé ìrìbọmi tí ó ń gba eniyan là nisinsinyii. Kì í ṣe láti wẹ ìdọ̀tí kúrò lára, bíkòṣe ọ̀nà tí ẹ̀bẹ̀ eniyan fi lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ẹ̀rí ọkàn rere, nípa ajinde Jesu Kristi,

22 ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó ti kọjá lọ sọ́run, lẹ́yìn tí àwọn angẹli ati àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára ojú ọ̀run ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

Categories
PETERU KINNI

PETERU KINNI 4

Ìríjú Rere

1 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Kristi ti jìyà ninu ara, kí ẹ̀yin náà di ọkàn yín ní àmùrè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá jìyà nípa ti ara ti bọ́ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀.

2 Má tún máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀dá mọ́, ṣugbọn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun ninu gbogbo ìgbé-ayé rẹ tí ó kù.

3 Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀.

4 Nisinsinyii ó jẹ́ ohun ìjọjú fún àwọn ẹlẹgbẹ́ yín àtijọ́, nígbà tí ẹ kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọn óo wá máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà.

5 Ṣugbọn wọn óo dáhùn fún ìwà wọn níwájú ẹni tí ó ṣetán láti ṣe ìdájọ́ alààyè ati òkú.

6 Nítorí rẹ̀ ni a ṣe waasu ìyìn rere fún àwọn òkú, pé bí wọ́n bá tilẹ̀ gba ìdájọ́ bí gbogbo eniyan ti níláti gbà ninu ara, sibẹ wọn óo wà láàyè ninu ẹ̀mí nípa ti Ọlọrun.

7 Òpin ohun gbogbo súnmọ́ tòsí. Nítorí náà ẹ fi òye ati ìwà pẹ̀lẹ́ gbé ìgbé-ayé yín ninu adura.

8 Ju ohun gbogbo lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ sí ara yín, nítorí ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

9 Ẹ lawọ́ sí ara yín láìní ìkùnsínú.

10 Olukuluku yín ní ẹ̀bùn tirẹ̀. Ẹ máa lo ẹ̀bùn yín fún ire ọmọnikeji yín, gẹ́gẹ́ bí ìríjú oríṣìíríṣìí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

11 Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin.

Ìjìyà Gẹ́gẹ́ Bí Onigbagbọ

12 Ẹ̀yin olùfẹ́ mi, ẹ má jẹ́ kí ó jọ yín lójú bí wọ́n bá wa iná jó yín láti dán yín wò, bí ẹni pé ohun tí ojú kò rí rí ni ó dé.

13 Èyí sọ yín di alábàápín ninu ìjìyà Kristi. Ẹ máa yọ̀. Nígbà tí ó bá pada dé ninu ògo rẹ̀, ayọ̀ ńlá ni ẹ óo yọ̀.

14 Bí wọn bá ń fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí orúkọ Kristi, ẹ ṣe oríire, nítorí Ẹ̀mí tí ó lógo nnì, Ẹ̀mí Ọlọrun, ti bà lé yín lórí.

15 Tí ẹ bá níláti jìyà, kí ó má jẹ́ gẹ́gẹ́ bí apànìyàn, tabi olè, tabi eniyan burúkú, tabi ẹni tí ń tojú bọ nǹkan-oní-nǹkan.

16 Ṣugbọn bí ẹ bá jìyà gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ẹ má jẹ́ kí ó tì yín lójú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa yin Ọlọrun lógo fún orúkọ tí ẹ̀ ń jẹ́.

17 Nítorí ó tó àkókò tí ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, láàrin ìdílé Ọlọrun ni yóo sì ti bẹ̀rẹ̀. Tí ó bá wá bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ wa, báwo ni yóo ti rí fún àwọn tí kò gba ìyìn rere Ọlọrun gbọ́?

18 Tí ó bá jẹ́ pé pẹlu agbára káká ni olódodo yóo fi là, báwo ni yóo ti rí fún àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?

19 Nítorí náà, kí àwọn tí ó ń jìyà nípa ìfẹ́ Ọlọrun fi ọkàn wọn fún Ọlọrun nípa ṣíṣe rere. Ọlọrun Ẹlẹ́dàá kò ní dójú tì wọ́n.

Categories
PETERU KINNI

PETERU KINNI 5

Bíbọ́ Agbo Aguntan Ọlọrun

1 Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn.

2 Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.

3 Ẹ má ṣe é bí ẹni tí ó fẹ́ jẹ́ aláṣẹ lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ yín ṣugbọn ẹ ṣe é bí àpẹẹrẹ fún ìjọ.

4 Nígbà tí Olú olùṣọ́-aguntan bá dé, ẹ óo gba adé ògo tí kì í ṣá.

5 Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí,

“Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga,

ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀.

7 Ẹ kó gbogbo ìpayà yín tọ̀ ọ́ lọ, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún.

8 Ẹ ṣọ́ra. Ẹ dira yín gírí, Èṣù tíí ṣe ọ̀tá yín, ń rìn kiri bíi kinniun tí ń bú ramúramù, ó ń wá ẹni tí yóo pa jẹ.

9 Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé.

10 Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀.

11 Òun ni agbára wà fún laelae. Amin.

Ìdágbére

12 Silifanu ni ó bá mi kọ ìwé kúkúrú yìí si yín. Mo ka Silifanu yìí sí arakunrin tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Mò ń rọ̀ yín, mo tún ń jẹ́rìí pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tòótọ́ nìyí. Ẹ dúró lórí ohun tí mo kọ.

13 Ìjọ tí Ọlọrun yàn, ẹlẹgbẹ́ yín tí ó wà ní Babiloni ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maku, ọmọ mi.

14 Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín.

Kí alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ti Kristi.

Categories
PETERU KEJI

PETERU KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ tí wọ́n wà ní oríṣìíríṣìí ààyè ni a kọ

Ìwé Keji láti Ọ̀dọ̀ Peteru

sí. Pataki ohun tí ó fa kíkọ rẹ̀ ni ọ̀nà láti tako àwọn olùkọ́ni èké, ati irú ìwà ìṣekúṣe tí irú ẹ̀kọ́ èké wọn lè fà. Kí eniyan di ìmọ̀ tòótọ́ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi mú nìkan ni òògùn ìṣòro yìí. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí gbọdọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ti rí Jesu ní ojúkoojú tí wọ́n sì ti fi etí ara wọn gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nǹkankan tí ó gún ẹni tí ó kọ ìwé yìí lọ́kàn ni ohun tí àwọn kan ń sọ, pé Kristi kò ní pada wá mọ́. Ó ṣe àlàyé pé ìdí tí ó fi dàbí ẹni pé Kristi pẹ́ kí ó tó pada ni pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, ó fẹ́ kí gbogbo eniyan yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2

Ìpè onigbagbọ 1:3-21

Àwọn olùkọ́ni èké 2:1-22

Ìpadàbọ̀ ìkẹyìn Kristi 3:1-18

Categories
PETERU KEJI

PETERU KEJI 1

Ìkíni

1 Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.

2 Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa.

Ìpè ati Yíyàn Onigbagbọ

3 Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá.

4 Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé.

5 Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí.

6 Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà.

7 Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ.

8 Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi.

9 Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.

10 Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà.

11 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi.

12 Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀.

13 Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí.

14 Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́ n óo bọ́ àgọ́ ara mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí.

15 Ṣugbọn mò ń làkàkà pé nígbà tí mo bá lọ tán, kí ẹ ní ohun tí ẹ óo fi máa ṣe ìrántí nǹkan wọnyi nígbà gbogbo.

Ògo Kristi ati Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀

16 Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́.

17 Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé,

“Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi,

inú mi dùn sí ọ.”

18 Àwa fúnra wa gbọ́ ohùn yìí nígbà tí ó wá láti ọ̀run nítorí a wà pẹlu rẹ̀ lórí òkè mímọ́ nígbà náà.

19 A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín.

20 Ṣugbọn kí ẹ kọ́kọ́ mọ èyí pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ninu Ìwé Mímọ́ tí ẹnìkan lè dá túmọ̀.

21 Nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹnikẹ́ni ni àsọtẹ́lẹ̀ kan fi wá, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ni àwọn eniyan fi ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá.

Categories
PETERU KEJI

PETERU KEJI 2

Àwọn Wolii Èké ati Olùkọ́ni Èké

1 Ṣugbọn bí àwọn wolii èké ti dìde láàrin àwọn eniyan Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùkọ́ni èké yóo wà láàrin yín. Wọn óo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ wọ ààrin yín. Wọn óo sẹ́ Oluwa wọn tí ó rà wọ́n pada, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn óo mú ìparun wá sórí ara wọn kíákíá.

2 Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá wọn kẹ́gbẹ́ ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn; nítorí ìṣe wọn, àwọn eniyan yóo máa gan ọ̀nà òtítọ́.

3 Wọn óo fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín nítorí ojúkòkòrò, kí wọ́n lè fi yín ṣe èrè jẹ. Ìdájọ́ tí ó wà lórí wọn láti ìgbà àtijọ́ kò parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìparun tí ń bọ̀ wá bá wọn kò sùn.

4 Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́.

5 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là.

6 Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun.

7 Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.

8 Nítorí ohun tí ojú rẹ̀ ń rí ati ohun tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ń ba ọkàn ọkunrin olódodo yìí jẹ́ lojoojumọ bí ó ti ń gbé ààrin àwọn eniyan burúkú yìí.

9 Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́.

10 Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ.

Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run.

11 Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn angẹli tí wọ́n ní agbára ati ipá ju eniyan lọ, kò jẹ́ sọ ìsọkúsọ sí wọn nígbà tí wọn bá ń mú wọn lọ fún ìdájọ́ Ọlọrun.

12 Wọ́n dàbí ẹranko tí kò lè ronú, tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, tí a mú, tí a pa. Wọn a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ohun tí kò yé wọn. Ìparun yóo bá wọn ninu ọ̀nà ìparun wọn.

13 Ibi ni wọn yóo jèrè lórí ibi tí wọn ń ṣe. Wọ́n ka ati máa ṣe àríyá ní ọ̀sán gangan sí ìgbádùn. Àbùkù ati ẹ̀gàn ni wọ́n láàrin yín. Ẹ̀tàn ni àríyá tí wọn ń ṣe nígbà tí ẹ bá jọ jókòó láti jẹun.

14 Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n.

15 Wọ́n fi ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ránun-rànun kiri. Wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, tí ó fẹ́ràn èrè aiṣododo.

16 Ṣugbọn tí ó rí ìbáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹranko tí kò lè fọhùn sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó dí wolii náà lọ́wọ́ ninu ìwà aṣiwèrè rẹ̀.

17 Wọ́n dàbí ìsun omi tí ó ti gbẹ, ati ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. Ọlọrun ti pèsè ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri fún wọn.

18 Ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà lásán, tí kò ní ìtumọ̀, ní ń ti ẹnu wọn jáde. Nípa ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ati ìwà ìbàjẹ́ wọn, wọ́n ń tan àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kúrò láàrin ìwà ìtànjẹ ti ẹgbẹ́ wọ́n àtijọ́ jẹ.

19 Wọ́n ṣèlérí òmìnira fún àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹrú ohun ìbàjẹ́ wọn ni àwọn fúnra wọn jẹ́, nítorí tí ohunkohun bá ti borí eniyan, olúwarẹ̀ di ẹrú nǹkan náà.

20 Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ.

21 Nítorí ó sàn fún wọn kí wọn má mọ ọ̀nà òdodo ju pé kí wọn wá mọ̀ ọ́n tán kí wọn wá yipada kúrò ninu òfin mímọ́ tí a ti fi kọ́ wọn.

22 Àwọn ni òtítọ́ òwe yìí ṣẹ mọ́ lára pé, “Ajá tún pada lọ kó èébì rẹ̀ jẹ.” Ati òwe kan tí wọn máa ń pa pé, “Ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n fọ̀ nù yóo tún pada lọ yíràá ninu ẹrọ̀fọ̀.”

Categories
PETERU KEJI

PETERU KEJI 3

Ìlérí Pé Oluwa Yóo tún Pada Wá

1 Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀.

2 Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín.

3 Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.

4 Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!”

5 Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun.

6 Omi kan náà ni Ọlọrun fi pa ayé tí ó ti wà rí run.

7 Ṣugbọn àṣẹ kan náà ni Ọlọrun fi pa àwọn ọ̀run ati ayé ti àkókò yìí mọ́ kí ó lè dáná sun ún, ó ń fi wọ́n pamọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí a óo pa àwọn eniyan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun run.

8 Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan.

9 Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada.

10 Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò.

11 Nígbà tí ìparun ń bọ̀ wá bá gbogbo nǹkan báyìí, irú ìgbé-ayé wo ni ó yẹ kí ẹ máa gbé? Ẹ níláti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ ati olùfọkànsìn,

12 kí ẹ máa retí ọjọ́ Ọlọrun, kí ẹ máa ṣe akitiyan pé kí ó tètè dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parun, gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo yọ́ ninu iná.

13 Gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, à ń dúró de àwọn ọ̀run titun ati ayé titun níbi tí òdodo yóo máa wà.

14 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun.

15 Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un.

16 Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù.

17 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí.

18 Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin.