Categories
HEBERU

HEBERU 10

1 Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé.

2 Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ẹbọ yìí ti sọ àwọn tí ń rú wọn di pípé ni, wọn kì bá tí rú wọn mọ́, nítorí ẹ̀rí-ọkàn wọn kì bá tí dá wọn lẹ́bi mọ́ bí ó bá jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n rú lẹ́ẹ̀kan bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́.

3 Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun,

4 nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ.

5 Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé,

“Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́,

ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi.

6 Kì í ṣe ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀

ni o ní inú dídùn sí.

7 Nígbà náà ni mo sọ pé,

‘Èmi nìyí.

Àkọsílẹ̀ wà ninu Ìwé Mímọ́ nípa mi pé,

Ọlọrun, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.’ ”

8 Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin.

9 Lẹ́yìn náà ó wá sọ pé, “Èmi nìyí, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.” Èyí ni pé ó mú ti àkọ́kọ́ kúrò kí ó lè fi ekeji lélẹ̀.

10 Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

11 Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà.

12 Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

13 Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀.

14 Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae.

15 Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé,

16 “Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dá

nígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀,

Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn,

n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.”

17 Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.”

18 Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú ati Ìkìlọ̀

19 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu,

20 nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀.

21 A tún ní alufaa àgbà tí ó wà lórí ìdílé Ọlọrun.

22 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.

23 Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí.

24 Ẹ jẹ́ kí á máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ ati láti ṣe iṣẹ́ rere.

25 Ẹ má jẹ́ kí á máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn mìíràn, ṣugbọn kí á máa gba ara wa níyànjú, pataki jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti rí i pé ọjọ́ ńlá ọ̀hún súnmọ́ tòsí.

26 Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

27 Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun.

28 Bí ẹni meji tabi mẹta bá jẹ́rìí pé ẹnìkan ṣá Òfin Mose tì, pípa ni wọn yóo pa olúwarẹ̀ láì ṣàánú rẹ̀.

29 Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́?

30 Nítorí a mọ ẹni tí ó sọ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ati pé, “Oluwa ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀.”

31 Ohun tí ó bani lẹ́rù gidigidi ni pé kí ọwọ́ Ọlọrun alààyè tẹ eniyan.

32 Ẹ ranti bí a ti ja ìjà líle, tí ẹ farada ìrora, látijọ́, nígbà tí ẹ kọ́kọ́ rí ìmọ́lẹ̀ igbagbọ.

33 Nígbà mìíràn wọ́n fi yín ṣẹ̀sín, wọ́n jẹ yín níyà, àwọn eniyan ń fi yín ṣe ìran wò. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ dúró láì yẹsẹ̀ pẹlu àwọn tí wọ́n ti jẹ irú ìyà bẹ́ẹ̀.

34 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ.

35 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfọkàntán tí ẹ ní bọ́, nítorí ó ní èrè pupọ.

36 Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe.

37 Nítorí náà, bí Ìwé Mímọ́ ti wí,

“Nítorí láìpẹ́ jọjọ,

ẹni tí ń bọ̀ yóo dé,

kò ní pẹ́ rárá.

38 Ṣugbọn àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ tèmi

yóo wà láàyè nípa igbagbọ.

Ṣugbọn bí èyíkéyìí ninu wọn bá fà sẹ́yìn

inú mi kò ní dùn sí i.”

39 Ṣugbọn àwa kò sí ninu àwọn tí wọn ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Ṣugbọn àwa ní igbagbọ, a sì ti rí ìgbàlà.

Categories
HEBERU

HEBERU 11

Igbagbọ

1 Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí.

2 Igbagbọ ni àwọn àgbà àtijọ́ ní, tí wọ́n fi ní ẹ̀rí rere.

3 Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí.

4 Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀.

5 Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.”

6 Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè.

7 Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo.

8 Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ.

9 Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà.

10 Nítorí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀, tí ó jẹ́ pé Ọlọrun ni ó ṣe ètò rẹ̀ tí ó sì kọ́ ọ.

11 Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé.

12 Nítorí èyí, láti ọ̀dọ̀ ẹyọ ọkunrin kan, tí ó ti dàgbà títí, tí ó ti kú sára, ni ọpọlọpọ ọmọ ti jáde, wọ́n pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi iyanrìn etí òkun.

13 Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé.

14 Àwọn eniyan tí ó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí fihàn pé wọ́n ń wá ìlú ti ara wọn.

15 Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n tún ń ronú ti ibi tí wọ́n ti jáde wá, wọn ìbá ti wá ààyè láti pada sibẹ.

16 Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn.

17 Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi Isaaki rúbọ nígbà tí Ọlọrun dán an wò. Ó fi ààyò ọmọ rẹ̀ rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún un nípa rẹ̀,

18 tí Ọlọrun ti sọ fún un pé, “Láti inú Isaaki ni ìdílé rẹ yóo ti gbilẹ̀.”

19 Èrò rẹ̀ ni pé Ọlọrun lè tún jí eniyan dìde ninu òkú. Nítorí èyí, àfi bí ẹni pé ó tún gba ọmọ náà pada láti inú òkú.

20 Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.

21 Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀.

22 Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun.

23 Nígbà tí wọ́n bí Mose, nípa igbagbọ ni àwọn òbí rẹ̀ fi gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta nítorí wọ́n rí i pé ọmọ tí ó lẹ́wà ni, wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

24 Nígbà tí Mose dàgbà tán, nípa igbagbọ ni ó fi kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n pe òun ní ọmọ ọmọbinrin Farao.

25 Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ.

26 Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú.

27 Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn.

28 Nípa igbagbọ ni ó fi ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ètò láti fi ẹ̀jẹ̀ ra ara ìlẹ̀kùn, kí angẹli tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ àwọn ará Ijipti má baà fọwọ́ kan ọmọ àwọn eniyan Israẹli.

29 Nípa igbagbọ ni àwọn ọmọ Israẹli fi gba ààrin òkun pupa kọjá bí ìgbà tí eniyan ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ará Ijipti náà gbìyànjú láti kọjá, rírì ni wọ́n rì sinu omi.

30 Nípa igbagbọ ni odi ìlú Jẹriko fi wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti yí i ká fún ọjọ́ meje.

31 Nípa igbagbọ ni Rahabu aṣẹ́wó kò fi kú pẹlu àwọn alaigbagbọ, nígbà tí ó ti fi ọ̀yàyà gba àwọn amí.

32 Kí ni kí n tún wí? Àyè kò sí fún mi láti sọ nípa Gideoni, Baraki, Samsoni, Jẹfuta, Dafidi, Samuẹli ati àwọn wolii.

33 Nípa igbagbọ, wọ́n ṣẹgun ilẹ̀ àwọn ọba, wọn ṣiṣẹ́ tí òdodo fi gbilẹ̀, wọ́n rí ìlérí Ọlọrun gbà. Wọ́n pa kinniun lẹ́nu mọ́.

34 Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn.

35 Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú.

A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ.

36 A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n.

37 A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira.

38 Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀.

39 Gbogbo àwọn wọnyi ni ẹ̀rí rere nípa igbagbọ, ṣugbọn wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí gbà.

40 Nítorí pé àwa ni Ọlọrun ní lọ́kàn tí ó fi ṣe ètò tí ó dára jùlọ, pé kí àwa ati àwọn lè jọ rí ẹ̀kún ibukun gbà.

Categories
HEBERU

HEBERU 12

Ìtọ́ni ti Oluwa

1 Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa.

2 Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.

3 Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì.

4 Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú.

5 Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé,

Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹ

má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí.

6 Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà,

ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ,

ni ó ń nà ní pàṣán.

7 Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà?

8 Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́.

9 Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè?

10 Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀.

11 Ní àkókò tí a bá ń sọ fún eniyan pé: má ṣe èyí, má ṣe tọ̀hún, kì í dùn mọ́ ẹni tí à ń tọ́. Pẹlu ìnira ni. Ṣugbọn ní ìgbẹ̀yìn a máa so èso alaafia ti ìgbé-ayé òdodo fún àwọn tí a bá ti tọ́ sọ́nà.

12 Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára;

13 ẹ ṣe ọ̀nà títọ́ fún ara yín láti máa rìn, kí ẹsẹ̀ tí ó bá ti rọ má baà yẹ̀, ṣugbọn kí ó lè mókun.

Ìkìlọ̀ Kí Eniyan má Kọ Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun

14 Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa.

15 Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.

16 Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má jẹ́ oníṣekúṣe tabi alaigbagbọ bíi Esau, tí ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré ta anfaani tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àrólé baba rẹ̀.

17 Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àrólé, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà.

18 Nítorí kì í ṣe òkè Sinai ni ẹ wá, níbi tí iná ti ń jó, tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ tí ó ṣókùnkùn tí afẹ́fẹ́ líle sì ń fẹ́,

19 tí fèrè ń dún kíkankíkan, tí ohùn kan wá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbọ́ ọ bẹ̀bẹ̀, pé kí àwọn má tún gbọ́ irú rẹ̀ mọ́.

20 Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!”

21 Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.”

22 Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan,

23 ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé,

24 ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ.

25 Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.

26 Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.”

27 Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì.

28 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù;

29 nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa.

Categories
HEBERU

HEBERU 13

Ìsìn Tí Ó Wu Ọlọrun

1 Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn.

2 Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n.

3 Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà.

4 Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè.

5 Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!”

6 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé,

“Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi,

ẹ̀rù kò ní bà mí.

Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.”

7 Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn.

8 Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae.

9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani.

10 A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀.

11 Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó.

12 Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀.

13 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà.

14 Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀!

15 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

16 Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí.

17 Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani.

18 Ẹ máa gbadura fún wa. Ó dá wa lójú pé ọkàn wa mọ́. Ohun tí ó dára ni a fẹ́ máa ṣe nígbà gbogbo.

19 Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín.

Ìdágbére

20-21 Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin.

22 Mo bẹ̀ yín, ará, kí ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa yìí nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ si yín.

23 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti dá Timoti, arakunrin wa, sílẹ̀: ó ti jáde lẹ́wọ̀n. Bí ó bá tètè dé, èmi ati òun ni a óo jọ ri yín.

24 Ẹ kí gbogbo àwọn aṣiwaju yín ati gbogbo àwọn onigbagbọ. Àwọn ará láti Itali ki yín.

25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu gbogbo yín.

Categories
JAKỌBU

JAKỌBU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé láti Ọ̀dọ̀ Jakọbu

jẹ́ àkójọ oríṣìíríṣìí ìlànà ati ẹ̀kọ́ tí a kọ “sí gbogbo eniyan Ọlọrun tí ó fọ́n káàkiri gbogbo ayé.” Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ àpèjúwe tí ó múni lọ́kàn ni ẹni tí ó kọ ìwé yìí lò láti gbé ìlànà rẹ̀ kalẹ̀ nípa ọgbọ́n tí ó ṣe é múlò ati ìtọ́ni fún ìhùwàsí ati ìṣe onigbagbọ. Ọpọlọpọ kókó ọ̀rọ̀ ni ó mẹ́nubà, ó sì sọ ìhà tí onigbagbọ níláti kọ sí àwọn nǹkan bí ọrọ̀, àìní, ìdánwò, ìwà rere, igbagbọ ati iṣẹ́, fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ọgbọ́n, ìjà, ìgbéraga ati ìrẹ̀lẹ̀; dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnu fífọ́n, sùúrù ati adura.

Ìwé yìí tẹnumọ́ ọn pé ó ṣe pataki pé kí iṣẹ́ kún igbagbọ ninu mímú ẹ̀sìn igbagbọ lò.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju 1:1

Igbagbọ ati ọgbọ́n 1:2-8

Àìní ati ọrọ̀ 1:9-11

Ìdẹwò ati ìdánwò 1:12-18

Gbígbọ́ ati ṣíṣe 1:19-27

Ìkìlọ̀ nípa yíya àwọn kan sọ́tọ̀ 2:1-13

Igbagbọ ati iṣẹ́ 2:14-26

Onigbagbọ ati ahọ́n rẹ̀ 3:1-18

Onigbagbọ ati ayé 4:1–5:6

Oríṣìíríṣìí ìlànà 5:7-20

Categories
JAKỌBU

JAKỌBU 1

Ìkíni

1 Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín!

Igbagbọ ati Ọgbọ́n

2 Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín.

3 Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà.

4 Ẹ níláti ní ìfaradà títí dé òpin, kí ẹ lè di pípé, kí ẹ sì ní ohun gbogbo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láìsí ìkùnà kankan.

5 Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún.

6 Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè.

7-8 Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé òun óo rí nǹkankan gbà lọ́dọ̀ Oluwa: ọkàn rẹ̀ kò papọ̀ sí ọ̀nà kan, ó ń ṣe ségesège, ó ń ṣe iyè meji.

Mẹ̀kúnnù ati Ọlọ́rọ̀

9 Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga.

10 Bẹ́ẹ̀ ni kí ọlọ́rọ̀ kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, nítorí bí òdòdó koríko ìgbẹ́ ni ọlọ́rọ̀ kò ní sí mọ́.

11 Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Ìlò Ìdánwò

12 Ẹni tí ó bá fi ara da ìdánwò kú oríire, nítorí nígbà tí ó bá yege tán, yóo gba adé ìyè tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.

13 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìdánwò má ṣe sọ pé, “Láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìdánwò yìí ti wá.” Nítorí kò sí ẹni tí ó lè fi nǹkan burúkú dán Ọlọrun wò. Ọlọrun náà kò sì jẹ́ fi nǹkan burúkú dán ẹnikẹ́ni wò.

14 Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn olukuluku ni ó ń tàn án, tí ó ń fa ìdánwò.

15 Nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá lóyún, á bí ẹ̀ṣẹ̀; nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá gbilẹ̀ tán á bí ikú.

16 Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má tan ara yín jẹ.

17 Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.

18 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀.

Gbígbọ́ ati Ṣíṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọrun

19 Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú.

20 Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́.

21 Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là.

22 Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ.

23 Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí.

24 Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí.

25 Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù.

26 Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀.

27 Ẹ̀sìn tí ó pé, tí kò lábàwọ́n níwájú Ọlọrun Baba ni pé kí eniyan máa ran àwọn ọmọ tí kò ní òbí ati àwọn opó lọ́wọ́ ninu ipò ìbànújẹ́ wọn, kí eniyan sì pa ara rẹ̀ mọ́ láìléèérí ninu ayé.

Categories
JAKỌBU

JAKỌBU 2

Ẹ Má Ṣe Ojuṣaaju

1 Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju.

2 Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá wọ àwùjọ yín, tí ó fi òrùka wúrà sọ́wọ́, tí ó wọ aṣọ tí ń dán, tí talaka kan náà bá wọlé tí ó wọ aṣọ tí ó dọ̀tí;

3 ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.”

4 Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú.

5 Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.

6 Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù!

7 Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín!

8 Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.”

9 Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju, ẹ di arúfin, ati ẹni ìbáwí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí arúfin.

10 Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin.

11 Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin.

12 Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira.

13 Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́.

Igbagbọ ati Iṣẹ́

14 Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là?

15 Bí arakunrin kan tabi arabinrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí kò jẹun fún odidi ọjọ́ kan,

16 tí ẹnìkan ninu yín wá sọ fún un pé, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun yóo pèsè aṣọ ati oúnjẹ fún ọ,” ṣugbọn tí kò fún olúwarẹ̀ ní ohun tí ó nílò, anfaani wo ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣe?

17 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni.

18 Ṣugbọn ẹnìkan lè sọ pé, “Ìwọ ní igbagbọ, èmi ní iṣẹ́.” Fi igbagbọ rẹ hàn mí láìsí iṣẹ́, èmi óo fi igbagbọ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ mi.

19 Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn.

20 Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú?

21 Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ?

22 O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé.

23 Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun.

24 Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan?

25 Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ?

26 Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́.

Categories
JAKỌBU

JAKỌBU 3

Ahọ́n

1 Ẹ̀yin ará mi, kí ọpọlọpọ yín má máa jìjàdù láti jẹ́ olùkọ́ni, kí ẹ mọ̀ pé ìdájọ́ ti àwa olùkọ́ni yóo le.

2 Nítorí gbogbo wa ni à ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá wà tí kò ṣi ọ̀rọ̀ sọ rí, a jẹ́ pé olúwarẹ̀ pé, ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu.

3 Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́.

4 Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́.

5 Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀.

Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá!

6 Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára.

7 Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀.

8 Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá.

9 Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun.

10 Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀.

11 Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde?

12 Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde.

Ọgbọ́n láti Òkè Wá

13 Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn.

14 Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́.

15 Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú.

16 Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀.

17 Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè.

18 Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia.

Categories
JAKỌBU

JAKỌBU 4

Bíbá Ayé Rẹ́

1 Níbo ni ogun ti ń wá? Níbo ni ìjà sì ti ń wá sáàrin yín? Ṣebí nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yín tí ó ń jagun ninu àwọn ẹ̀yà ara yín ni.

2 Ẹ̀ ń fẹ́ nǹkankan, ọwọ́ yín kò sì tẹ̀ ẹ́; ẹ bá ń tìtorí rẹ̀ paniyan; ẹ̀ ń jowú nítorí nǹkankan, ọwọ́ yín kò bá ohun tí ẹ̀ ń jowú lé lórí, ẹ bá sọ ọ́ di ọ̀ràn ìjà ati ogun. Ọwọ́ yín kò tẹ ohun tí ẹ fẹ́ nítorí pé ẹ kò bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun.

3 Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín.

4 Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun.

5 Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?”

6 Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

7 Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín.

8 Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì.

9 Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín bàjẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, ẹ sọkún; ẹ má rẹ́rìn-ín mọ́, ńṣe ni kí ẹ fajúro. Ẹ máa banújẹ́ dípò yíyọ̀ tí ẹ̀ ń yọ̀.

10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga.

Dídá Arakunrin Wa Lẹ́jọ́

11 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa arakunrin rẹ̀ tabi tí ó bá ń dá arakunrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí òfin, ó tún ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí ó bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ òfin dípò olùṣe ohun tí òfin wí.

12 Ẹnìkan ṣoṣo ni ó fúnni lófin, tí ó jẹ́ onídàájọ́. Òun ni ẹni tí ó lè gba ẹ̀mí là, tí ó sì lè pa ẹ̀mí run; Ṣugbọn ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?

Ìkìlọ̀ nípa Fífọ́nnu

13 Ẹ gbọ́ ná, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé, “Lónìí, tabi lọ́la, a óo lọ sí ibi báyìí, a óo ṣe ọdún kan níbẹ̀; a óo ṣòwò, a óo sì jèrè.”

14 Ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín, tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́.

15 Ohun tí ẹ̀ bá máa wí ni pé “Bí Oluwa bá dá ẹ̀mí sí, a óo ṣe báyìí báyìí.”

16 Ṣugbọn ẹ̀ ń lérí, ẹ̀ ń fọ́nnu; irú ìlérí báyìí kò dára.

17 Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà.

Categories
JAKỌBU

JAKỌBU 5

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọlọ́rọ̀

1 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀. Ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa ké gidi nítorí ìṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣẹ́ yín.

2 Ọrọ̀ yín ti bàjẹ́. Kòkòrò ti jẹ gbogbo aṣọ yín.

3 Wúrà yín ati fadaka yín ti dógùn-ún. Dídógùn-ún wọn ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fun yín, nítorí yóo jẹ ara yín bí ìgbà tí iná bá ń jó nǹkan. Inú ayé tí ó fẹ́rẹ̀ dópin ni ẹ̀ ń to ìṣúra jọ sí!

4 Owó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní oko yín, tí ẹ kò san fún wọn ń pariwo yín. Igbe àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ba yín kórè oko yín sì ti dé etí Oluwa Ọlọrun Olodumare.

5 Ẹ̀ ń ṣe fàájì ninu ayé, ẹ̀ ń jẹ, ẹ̀ ń mu. Ẹ wá sanra bíi mààlúù, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ tí wọn yóo dumbu mààlúù ló kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí.

6 Ẹ gbé ẹ̀bi fún aláre, ẹ sì pa á, kò lè rú pútú.

Sùúrù ati Adura

7 Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn.

8 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin gan-an mú sùúrù. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, nítorí Oluwa fẹ́rẹ̀ dé.

9 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà.

10 Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú.

11 Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa.

12 Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́.

13 Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá wà ninu ìyọnu, kí olúwarẹ̀ gbadura. Bí inú ẹnikẹ́ni ninu yín bá dùn, kí olúwarẹ̀ máa kọ orin ìyìn.

14 Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ń ṣàìsàn, kí ó pe àwọn àgbà ìjọ jọ, kí wọ́n gbadura fún un, kí wọ́n fi òróró pa á lára ní orúkọ Oluwa.

15 Adura pẹlu igbagbọ yóo mú kí ara aláìsàn náà yá. Oluwa yóo gbé e dìde, a óo sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá jì í.

16 Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn. Adura àtọkànwá olódodo lágbára, nítorí Ọlọrun a máa fi àṣẹ sí i.

17 Eniyan ẹlẹ́ran-ara bí àwa ni Elija. Ó fi tọkàntọkàn gbadura pé kí òjò má rọ̀. Òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún odidi ọdún mẹta ati oṣù mẹfa.

18 Ó tún gbadura, òjò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ láti òkè, ilẹ̀ sì hu ohun ọ̀gbìn jáde.

19 Ẹ̀yin ará mi, bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí ẹnìkan bá tọ́ ọ sọ́nà,

20 ẹ mọ̀ dájú pé ẹni tí ó bá mú ẹlẹ́ṣẹ̀ pada kúrò ninu ìṣìnà rẹ̀ gba ọkàn ẹni náà lọ́wọ́ ikú, ó sì mú kí ìgbàgbé bá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀.