Categories
HEBERU

HEBERU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Àwọn onigbagbọ kan tí wọn ń dojú kọ ọpọlọpọ ìṣòro àtakò, tí wọ́n sì wà ninu ewu kíkọ ẹ̀sìn igbagbọ sílẹ̀ ni wọ́n kọ

Ìwé sí Àwọn Heberu

sí. Ẹni tí ó kọ ìwé náà gbà wọ́n ní ìyànjú ninu igbagbọ wọn pé, fífi hàn tí Jesu fi bí Ọlọrun ti rí hàn wá ni ìfihàn òtítọ́ ati ti ìkẹyìn nípa Ọlọrun. Ninu àlàyé rẹ̀ lórí ìfihàn yìí, ó tẹnu mọ́ àwọn òtítọ́ mélòó kan: (1) Jesu ni Ọmọ ayérayé Ọlọrun tí ó ti ipa ìjìyà ati ìfaradà kọ́ nípa bí a ti ń gbọ́ràn sí Baba lẹ́nu nítòótọ́. Nítorí pé Jesu jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, ó ju àwọn wolii inú Majẹmu Laelae lọ, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn angẹli tabi Mose pàápàá. (2) Ọlọrun ti sọ gbangba pé Jesu jẹ́ alufaa ayérayé tí ó ju àwọn alufaa inú Majẹmu Laelae lọ. (3) Nípasẹ̀ Jesu ni onigbagbọ ti rí ìgbàlà ninu ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀rù, ati ikú, ati pé Jesu tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ni ó pèsè ìgbàlà tòótọ́. Àwòjíìji lásán ni ìlànà ẹ̀sìn ati ìfi-ẹran-rúbọ ti ẹ̀sìn àwọn Heberu jẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ ìgbàlà tòótọ́ yìí.

Paulu mẹ́nuba àpẹẹrẹ igbagbọ àwọn eniyan pataki ninu ìran Israẹli (Orí 11), ó sì rọ àwọn olùka ìwé rẹ̀ láti túbọ̀ máa jẹ́ olóòótọ́. Ninu orí kejila ó tún rọ àwọn olùka ìwé rẹ̀ láti máa ṣe olóòótọ́ títí dé òpin. Ó ní kí wọ́n ṣá tẹjúmọ́ Jesu, kí wọ́n farada ìjìyàkíjìyà ati inúnibíni- kínúnibíni tí wọ́n lè bá pàdé. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn ati ìkìlọ̀ mìíràn ni ẹni tí ó kọ ìwé náà fi parí rẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: Kristi fi Ọlọrun hàn ní ọ̀nà tí ó pé 1:1-3

Bí Kristi ṣe ju àwọn angẹli lọ 1:4–2:18

Bí Kristi ṣe ju Mose ati Joṣua lọ 3:1–4:13

Bí Kristi ṣe tayọ gbogbo alufaa yòókù 4:14–7:28

Bí Kristi ṣe ju Majẹmu laelae lọ 8:1–9:28

Bí Kristi ṣe ju gbogbo ẹbọ yòókù lọ 10:1-39

Bí ìfẹ́ ṣe ju gbogbo nǹkan lọ 11:1–12:29

Ọ̀rọ̀ ìyànjú ìkẹyìn ati ọ̀rọ̀ ìparí 13:1-25

Categories
HEBERU

HEBERU 1

Ọlọrun Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀

1 Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀.

2 Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé.

3 Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ.

Ọmọ Ọlọrun Ju Àwọn Angẹli Lọ

4 Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ.

5 Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,

“Ìwọ ni ọmọ mi,

lónìí ni mo bí ọ?”

Tabi tí ó sọ fún pé,

“Èmi yóo jẹ́ baba fún un,

òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?”

6 Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé,

“Kí gbogbo àwọn angẹli

Ọlọrun foríbalẹ̀ fún un.”

7 Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé,

“Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù,

tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

8 Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé,

“Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun,

ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

9 O fẹ́ràn òdodo, o kórìíra ẹ̀ṣẹ̀.

Nítorí èyí, Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, fi òróró yàn ọ́

láti gbé ọ ga ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

10 Ó tún sọ pé,

“O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa,

ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀.

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run.

11 Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ óo wà títí.

Gbogbo wọn óo gbó bí aṣọ.

12 Gẹ́gẹ́ bí eniyan tií ká aṣọ ni ìwọ óo ká wọn.

Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, a óo pààrọ̀ wọn.

Ṣugbọn ní tìrẹ, bákan náà ni o wà.

Kò sí òpin sí iye ọdún rẹ.”

13 Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,

“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,

títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?”

14 Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.

Categories
HEBERU

HEBERU 2

Ìgbàlà Ńlá

1 Nítorí náà, ó yẹ kí á túbọ̀ ṣe akiyesi àwọn ohun tí à ń gbọ́, kí á má baà gbá wa lọ bí ìgbà tí odò gbá nǹkan lọ.

2 Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu àwọn angẹli sọ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí gbogbo ìwà àìṣedéédé ati ìwà àìgbọràn bá gba ìbáwí tí ó tọ́ sí wọn,

3 báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.

4 Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

Ẹni tí Ó Ṣe Ọ̀nà Ìgbàlà

5 Nítorí kì í ṣe àwọn angẹli ni ó fún ní àṣẹ láti ṣe àkóso ayé tí ń bọ̀, èyí tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀.

6 Ó wà ní àkọsílẹ̀ níbi tí ẹnìkan ti sọ pé,

“Kí ni eniyan, tí o fi ń ranti rẹ̀,

tabi ọmọ eniyan tí o fi ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

7 O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀.

O sì fi ògo ati ọlá dé e ládé.

8 O fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.”

Nítorí pé ó fi gbogbo nǹkan wọnyi sí ìkáwọ́ rẹ̀, kò ku nǹkankan tí kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nígbà náà, a kò ì tíì rí i, pé gbogbo nǹkan ni ó ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

9 Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan.

10 Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ.

11 Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀.

12 Ó ní,

“Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi.

Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.”

13 Ó tún sọ pé,

“Èmi ní tèmi, èmi óo gbẹ́kẹ̀lé e.”

Ati pé,

“Èmi nìyí ati àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún mi.”

14 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀, Jesu pàápàá di ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wọn, kí ó lè ti ipasẹ̀ ikú rẹ̀ sọ agbára Satani tí ó ní ikú ní ìkáwọ́ di asán.

15 Ó wá dá àwọn tí ẹ̀rù ikú ti sọ di ẹrú ninu gbogbo ìgbé-ayé wọn sílẹ̀.

16 Nítorí ó dájú pé, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún bíkòṣe àwọn ọmọ Abrahamu.

17 Nítorí náà, dandan ni kí òun alára jọ àwọn arakunrin rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, kí ó lè jẹ́ Olórí Alufaa tí ó láàánú, tí ó sì ṣe é gbójú lé nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níwájú Ọlọrun fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan.

18 Nítorí níwọ̀n ìgbà tí òun alára ti jìyà, ó lè ran àwọn tí wọ́n wà ninu ìdánwò lọ́wọ́.

Categories
HEBERU

HEBERU 3

Jesu Ju Mose Lọ

1 Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa.

2 Ẹ rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí Ọlọrun tí ó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣe oloòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun.

3 Nítorí bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti ní ọlá ju ilé tí ó kọ́ lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jesu yìí ní ọlá ju Mose lọ.

4 Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo.

5 Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni.

6 Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa.

Ìsinmi fún Àwọn Eniyan Ọlọrun

7 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí,

“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

8 ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀,

ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀,

9 nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò,

tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún.

10 Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn.

Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn.

Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’

11 Ni mo bá búra pẹlu ibinu,

pé wọn kò ní dé ibi ìsinmi mi.”

12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ó má ṣe sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo ní inú burúkú tóbẹ́ẹ̀ ti kò ní ní igbagbọ, tí yóo wá pada kúrò lẹ́yìn Ọlọrun alààyè.

13 Ṣugbọn ẹ máa gba ara yín níyànjú lojoojumọ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ “Òní” tí Ìwé Mímọ́ sọ bá ti bá àwa náà wí, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà tan ẹnikẹ́ni lọ, kí ó sì mú kí ó ṣe agídí sí Ọlọrun.

14 Nítorí a ti di àwọn tí ó ń bá Kristi kẹ́gbẹ́ bí a bá fi ọkàn tán an títí dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti fi ọkàn tán an ní ìbẹ̀rẹ̀ igbagbọ wa.

15 Bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,

“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

ẹ má ṣe agídí gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ọ̀tẹ̀.”

16 Mò ń bèèrè, àwọn ta ni ó gbọ́ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn tí wọ́n bá Mose jáde kúrò ní Ijipti ni.

17 Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀.

18 Àwọn ta ni ó búra pé wọn kò ní wọ inú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn aláìgbọràn ni.

19 A rí i pé wọn kò lè wọ inú ìsinmi yìí nítorí wọn kò gbàgbọ́.

Categories
HEBERU

HEBERU 4

1 Nítorí náà níwọ̀n ìgbà tì ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ tún wà, ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra gidigidi kí ẹnikẹ́ni ninu yín má baà kùnà láti wọ̀ ọ́.

2 Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìyìn rere bí àwọn tọ̀hún ti gbọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí àwọn gbọ́ kò ṣe wọ́n ní anfaani, nítorí wọn kò ní igbagbọ ninu ohun tí wọ́n gbọ́.

3 Àwa tí a gbàgbọ́ ni a wọ inú ìsinmi náà. Nígbà tí Ọlọrun sọ pé,

“Mo búra pẹlu ibinu pé,

wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”

Ó sọ bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé.

4 Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ níbìkan nípa ọjọ́ keje pé, “Ọlọrun sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ keje.”

5 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tí ó sọ ní ibí yìí ni pé, “Wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”

6 Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ará àtijọ́ tí wọ́n gbọ́ ìyìn rere kò wọ inú ìsinmi náà nítorí àìgbọràn, nítorí náà ó ku àwọn kan tí wọn yóo wọ inú rẹ̀.

7 Ọlọrun wá tún yan ọjọ́ mìíràn. Ninu ìwé Dafidi, tí ó kọ lẹ́yìn ọdún pupọ, ó sọ pé, “Lónìí”, níbi tí atọ́ka sí, tí ó kà báyìí pé,

“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

Ẹ má ṣe agídí.”

8 Bí ó bá jẹ́ pé Joṣua fún wọn ní ìsinmi ni, Ọlọrun kò ní tún sọ nípa ọjọ́ mìíràn mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ pupọ.

9 Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun.

10 Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀.

11 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn.

12 Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan.

13 Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.

Jesu Olórí Alufaa Ńlá

14 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ní Olórí Alufaa ńlá tí ó ti kọjá lọ sí ọ̀run tíí ṣe Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí á di ohun ti a fi igbagbọ jẹ́wọ́ mú ṣinṣin.

15 Nítorí Olórí Alufaa tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn ninu àwọn àìlera wa. Ṣugbọn ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi wa, ṣugbọn òun kò dẹ́ṣẹ̀.

16 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́, kí á lè rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.

Categories
HEBERU

HEBERU 5

1 Nítorí ẹnikẹ́ni tí a bá yàn láàrin àwọn eniyan láti jẹ́ olórí alufaa, a yàn án bí aṣojú àwọn eniyan níwájú Ọlọrun, kí ó lè máa mú àwọn ọrẹ ati ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá siwaju Ọlọrun.

2 Ó lè fi sùúrù bá àwọn tí wọ́n ṣìnà nítorí wọn kò gbọ́ lò, nítorí pé eniyan aláìlera ni òun náà.

3 Nítorí èyí, bí ó ti ń rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti òun alára.

4 Kò sí ẹni tíí yan ara rẹ̀ sí ipò yìí. Ṣugbọn àwọn tí Ọlọrun bá pè ni à ń yàn, bíi Aaroni.

5 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Kristi náà kò yan ògo yìí fúnrarẹ̀, láti jẹ́ olórí alufaa. Ọlọrun ni ó yàn án. Ọlọrun ni ó sọ fún un pé,

“Ìwọ ni Ọmọ mi,

lónìí ni mo bí ọ.”

6 Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé,

“Alufaa ni ọ́ títí laelae

gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”

7 Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà.

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ.

9 Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́.

10 Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.

Ìkìlọ̀ nípa Àwọn tí Ó Kúrò ninu Ẹ̀sìn Igbagbọ

11 A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí.

12 Nítorí ó ti yẹ kí ẹ di olùkọ́ni ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Sibẹ ẹ tún wà ninu àwọn tí a óo máa kọ́ ní “A, B, D,” nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun. Ẹ wà ninu àwọn tí a óo máa fi wàrà bọ́, ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi.

13 Nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá sì ń mu wàrà, kò tíì mọ ẹ̀kọ́ nípa òdodo, nítorí ọmọ-ọwọ́ ni irú wọn.

14 Ṣugbọn oúnjẹ gidi ni àgbàlagbà máa ń jẹ, àwọn tí ìrírí wọn fún ọjọ́ pípẹ́ ti fún ní òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan rere ati nǹkan burúkú.

Categories
HEBERU

HEBERU 6

1 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti ìsìn igbagbọ tì, kí á tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Kí á má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ bí ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà kúrò ninu àwọn iṣẹ́ tí ó yọrí sí ikú, ẹ̀kọ́ nípa igbagbọ ninu Ọlọrun;

2 ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn.

3 Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a óo sì ṣe, bí Ọlọrun bá fẹ́.

4 Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́,

5 tí wọ́n ti tọ́ ire tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò, ati agbára ayé tí ó ń bọ̀,

6 tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà.

7 Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni.

8 Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà.

10 Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii.

11 Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin;

12 kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun.

Ìlérí Ọlọrun Tí Ó Dájú

13 Nítorí nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu, ara rẹ̀ ni ó fi búra nígbà tí kò sí ẹnìkan tí ó tóbi bíi rẹ̀ tí ìbá fi búra.

14 Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.”

15 Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù.

16 Ẹni tí ó bá juni lọ ni a fi í búra. Ọ̀rọ̀ tí eniyan bá sì ti búra lé lórí, kò sí àríyànjiyàn lórí rẹ̀ mọ́.

17 Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í.

18 Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú.

19 A di ìlérí náà mú. Ó dàbí ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Ìlérí yìí dájú, ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Ó ti wọ inú yàrá tí ó wà ninu, lẹ́yìn aṣọ ìkélé,

20 níbi tí Jesu aṣiwaju wa ti wọ̀ lọ, tí ó di olórí alufaa títí lae gẹ́gẹ́ bíi Mẹlikisẹdẹki.

Categories
HEBERU

HEBERU 7

Irú Alufaa tí Mẹlikisẹdẹki Jẹ́

1 Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu.

2 Abrahamu fún un ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun. Ní àkọ́kọ́, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “ọba òdodo.” Lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ ọba Salẹmu, èyí ni “ọba alaafia.”

3 Kò sí àkọsílẹ̀ pé ó ní baba tabi ìyá; kò ní ìtàn ìdílé. Kò sí àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tabi òpin ìgbé-ayé rẹ̀. Ó jẹ́ àwòrán Ọmọ Ọlọrun. Ó jẹ́ alufaa nígbà gbogbo.

4 Ẹ kò rí bí ọkunrin yìí ti jẹ́ eniyan pataki tó, tí Abrahamu baba-ńlá wa fi fún un ní ìdámẹ́wàá àwọn nǹkan àṣàyàn ninu ìkógun rẹ̀.

5 Àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n ní àṣẹ láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan wọn tí wọ́n jẹ́ ìran Abrahamu.

6 Ṣugbọn Mẹlikisẹdẹki tí kì í ṣe ìran Abrahamu gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì súre fún Abrahamu tí ó rí àwọn ìlérí Ọlọrun gbà.

7 Láìṣe àní-àní, ẹni tí ó bá tóbi ju eniyan lọ níí súre fún un.

8 Ati pé, àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gba ìdámẹ́wàá, ẹni tí yóo kú ni wọ́n. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ sọ nípa Mẹlikisẹdẹki pé ó wà láàyè.

9 A lè sọ pé nígbà tí Abrahamu san ìdámẹ́wàá, Lefi tí ń gba ìdámẹ́wàá náà san ìdámẹ́wàá,

10 nítorí a lè sọ pé ó wà ní ara Abrahamu baba-ńlá rẹ̀ nígbà tí Mẹlikisẹdẹki pàdé rẹ̀.

11 Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé ètò iṣẹ́ alufaa ti ìdílé Lefi kò ní àbùkù, tí ó sì jẹ́ pé nípa rẹ̀ ni àwọn eniyan fi gba òfin, kí ló dé tí a fi tún ṣe ètò alufaa ní ìgbésẹ̀ Mẹlikisẹdẹki, tí kò fi jẹ́ ti Aaroni?

12 Nítorí bí a bá yí ètò iṣẹ́ alufaa pada, ó níláti jẹ́ pé a yí òfin náà pada.

13 Ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá láti inú ẹ̀yà mìíràn. Ninu ẹ̀yà yìí ẹ̀wẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ní nǹkankan ṣe pẹlu ẹbọ rírú.

14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí.

Oyè Alufaa Titun, Gẹ́gẹ́ Bíi ti Mẹlikisẹdẹki

15 Ohun tí à ń sọ hàn kedere nígbà tí a rí i pé a yan alufaa mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwòrán Mẹlikisẹdẹki,

16 ẹni tí ó di alufaa nípa agbára ìyà tí kò lópin, tí kì í ṣe nípa ìlànà àṣẹ tí a ti ọwọ́ eniyan ṣe ètò.

17 Nítorí a rí ẹ̀rí níbìkan pé,

“Ìwọ yóo jẹ́ alufaa títí lae,

gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”

18 A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò.

19 Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun.

20 Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra.

21 Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé,

“Oluwa ti búra,

kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada:

‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ”

22 Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ.

23 Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé.

24 Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀.

25 Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.

26 Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run.

27 Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.

28 Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae.

Categories
HEBERU

HEBERU 8

Olórí Alufaa ti Majẹmu Titun

1 Kókó ohun tí à ń sọ nìyí, pé a ní irú Olórí Alufaa báyìí, ẹni tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọlá ńlá ní ọ̀run.

2 Òun yìí ni òjíṣẹ́ ní ilé ìsìn tí ó mọ́ jùlọ tíí ṣe àgọ́ tòótọ́, tí Oluwa fúnrarẹ̀ kọ́, kì í ṣe èyí tí eniyan kọ́.

3 Nítorí gbogbo Olórí Alufaa tí a bá yàn, a yàn wọ́n pé kí wọ́n máa mú ẹ̀bùn ati ẹbọ àwọn eniyan wá siwaju Ọlọrun ni. Bákan náà ni òun náà níláti ní àwọn ohun tí yóo máa mú wá siwaju Ọlọrun.

4 Bí ó bá jẹ́ pé ó wà ninu ayé, kì bá tí jẹ́ alufaa rárá, nítorí àwọn alufaa wà tí wọn ń mú ẹ̀bùn àwọn eniyan lọ siwaju Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.

5 Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.”

6 Ṣugbọn nisinsinyii iṣẹ́ ìsìn ti Olórí Alufaa wa dára pupọ ju ti àwọn ọmọ Lefi lọ, nítorí pé majẹmu tí ó jẹ́ alárinà fún dára ju ti àtijọ́ lọ, ìdí ni pé ìlérí tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ ni majẹmu yìí dúró lé lórí.

7 Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀.

8 Nítorí Ọlọrun rí ẹ̀ṣẹ̀ kà sí wọn lọ́rùn ni ó fi sọ pé,

“Oluwa wí pé:

Ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi yóo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun.

9 Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dá

ní ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́,

mo bá kẹ̀yìn sí wọn.

10 Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.

11 Kì yóo sí ìdí tí ẹnìkan yóo fi kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀, pé,

‘Mọ Oluwa.’

Nítorí pé gbogbo wọn ni wọn óo mọ̀ mí,

ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí àwọn mẹ̀kúnnù inú wọn títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki.

12 Nítorí n óo fi àánú fojú fo ìwà burúkú wọn,

n kò sì ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

13 Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa majẹmu titun, ohun tí ó ń sọ ni pé ti àtijọ́ ti di ògbólógbòó. Ohun tí ó bá sì ti di ògbólógbòó, kò níí pẹ́ parẹ́.

Categories
HEBERU

HEBERU 9

Ilé Ìsìn Ti Ayé ati Ti Ọ̀run

1 Majẹmu àkọ́kọ́ ni àwọn ètò ìsìn ati ilé ìsìn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ti ayé ni.

2 Nítorí wọ́n pa àgọ́ àkọ́kàn, ninu rẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà ati tabili wà. Lórí tabili yìí ni burẹdi máa ń wà, níwájú Oluwa nígbà gbogbo. Èyí ni à ń pè ní Ibi Mímọ́.

3 Lẹ́yìn aṣọ ìkélé keji ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ jùlọ wà.

4 Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí.

5 Ní òkè àpótí yìí ni àwọn kerubu ògo Ọlọrun wà, tí òjìji wọn bo ìtẹ́ àánú. N kò lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí fínnífínní ní àkókò yìí.

6 Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn.

7 Ṣugbọn, Olórí Alufaa nìkan ní ó máa ń wọ inú àgọ́ keji. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún sì ni. Òun náà kò sì jẹ́ wọ ibẹ̀ láì mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí yóo fi rúbọ fún ara rẹ̀ ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn eniyan bá ṣèèṣì dá.

8 Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn nípa èyí pé ọ̀nà ibi mímọ́ kò ì tíì ṣí níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ ekinni bá wà.

9 Àkàwé ni gbogbo èyí jẹ́ fún àkókò yìí. Àwọn ẹ̀bùn ati ẹbọ tí wọn ń rú nígbà náà kò lè fún àwọn tí ó ń rú wọn ní ìbàlẹ̀ àyà patapata.

10 Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.

11 Ṣugbọn Kristi ti dé, òun sì ni Olórí Alufaa àwọn ohun rere tí ó wà. Ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ninu àgọ́ tí ó pé tí ó sì tóbi ju ti àtijọ́ lọ, àgọ́ tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí kì í sì í ṣe ti ẹ̀dá ayé yìí.

12 Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ tabi ti mààlúù bíkòṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀, ni ó fi rúbọ, nígbà tí ó wọ inú Ibi Mímọ́ jùlọ lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ṣe ìràpadà ayérayé fún wa.

13 Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara,

14 mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè.

15 Nítorí èyí, òun ni alárinà majẹmu. Ó kú kí ó lè ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan dá lábẹ́ majẹmu àkọ́kọ́, kí àwọn tí Ọlọrun pè lè gba ìlérí ogún ayérayé.

16 Nítorí bí eniyan bá ṣe ìwé bí òun ti fẹ́ kí wọ́n pín ogún òun, ìdánilójú kọ́kọ́ gbọdọ̀ wà pé ó ti kú kí ẹnikẹ́ni tó lè mú ìwé náà lò.

17 Ìwé ìpíngún kò wúlò níwọ̀n ìgbà tí ẹni tí ó ṣe é bá wà láàyè. Ó di ìgbà tí ó bá kú.

18 Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé pẹlu ẹ̀jẹ̀ ni a fi ṣe majẹmu àkọ́kọ́.

19 Gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin, nígbà tí Mose bá ti ka gbogbo àṣẹ Ọlọrun fún àwọn eniyan tán, a mú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ mààlúù ati ti ewúrẹ́ pẹlu omi, ati òwú pupa ati ẹ̀ka igi hisopu, a fi wọ́n Ìwé Òfin náà ati gbogbo àwọn eniyan.

20 A wá sọ pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí Ọlọrun pa láṣẹ fun yín.”

21 Bákan náà ni yóo fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ara àgọ́ náà ati gbogbo ohun èèlò ti ìsìn.

22 Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Ẹbọ tí Jesu Rú Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù

23 Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ pé a níláti fi ẹbọ sọ ẹ̀dà àwọn nǹkan ti ọ̀run di mímọ́, a rí i pé àwọn nǹkan ti ọ̀run fúnra wọn nílò ẹbọ tí ó dára ju èyí tí ẹ̀dà wọn gbà lọ.

24 Nítorí kì í ṣe àgọ́ tí a fi ọwọ́ kọ́ ni Kristi wọ̀ lọ, èyí tíí ṣe ẹ̀dà ti àgọ́ tòótọ́. Ṣugbọn ọ̀run gan-an ni ó wọ̀ lọ, nisinsinyii ó wà níwájú Ọlọrun nítorí tiwa.

25 Kì í sìí ṣe pé à-rú-tún-rú ni yóo máa fi ara rẹ̀ rúbọ, bí Olórí Alufaa ti ìdílé Lefi ti máa ń wọ Ibi Mímọ́ jùlọ lọ ní ọdọọdún pẹlu ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.

26 Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọpọlọpọ ìgbà ni ìbá ti máa jìyà láti ìgbà tí a ti fi ìdí ayé sọlẹ̀. Ṣugbọn ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nígbà tí àkókò òpin dé, láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù nípa ẹbọ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó fi ara rẹ̀ rú.

27 Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn.

28 Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.