Categories
TIMOTI KEJI

TIMOTI KEJI 1

1 Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè tí ó wà ninu Kristi Jesu, èmi ni mò ń kọ ìwé yìí–

2 Sí Timoti, àyànfẹ́ ọmọ mi.

Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu, Oluwa wa, wà pẹlu rẹ.

Ìdúpẹ́ ati Ọ̀rọ̀ Ìwúrí

3 Nígbà tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura mi tọ̀sán-tòru, èmi a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí mò ń sìn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba-ńlá mi ti ṣe.

4 Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún.

5 Mo ranti igbagbọ rẹ tí kò lẹ́tàn, tí ó kọ́kọ́ wà ninu Loisi ìyá-ìyá rẹ, ati ninu Yunisi ìyá rẹ, tí ó sì dá mi lójú pé ó wà ninu ìwọ náà.

6 Ìdí nìyí tí mo fi ń rán ọ létí pé kí o máa rú ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ Ọlọrun sókè, tí a fi fún ọ nípa ọwọ́ mi tí mo gbé lé ọ lórí.

7 Nítorí kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọrun fún wa bíkòṣe ẹ̀mí agbára ati ti ìfẹ́ ati ti ìkóra-ẹni-níjàánu.

8 Nítorí náà má ṣe tijú láti jẹ́rìí fún Oluwa wa tabi fún èmi tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gba ìjìyà tìrẹ ninu iṣẹ́ ìyìn rere pẹlu agbára Ọlọrun,

9 tí ó gbà wá là, tí ó pè wá láti ya ìgbé-ayé wa sọ́tọ̀. Kì í ṣe pé ìwà wa ni ó dára tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pè wá. Ṣugbọn ó pè wá gẹ́gẹ́ bí ètò tí òun fúnrarẹ̀ ti ṣe, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fi fún wa nípasẹ̀ Kristi Jesu láti ayérayé.

10 Ètò yìí ni ó wá hàn kedere nisinsinyii nípa ìfarahàn olùgbàlà wa Kristi Jesu, tí ó gba agbára lọ́wọ́ ikú, tí ó mú ìyè ati àìkú wá sinu ìmọ́lẹ̀ nípa ìyìn rere.

11 Ọlọrun yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli ati olùkọ́ni.

12 Ìdí nìyí tí mo fi ń jìyà báyìí. Ṣugbọn ojú kò tì mí. Nítorí mo mọ ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé. Ó sì dá mi lójú pé ó lè pa ìṣúra tí mo fi pamọ́ sí i lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ ńlá náà.

13 Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu.

14 Pa ìṣúra rere náà mọ́ pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú rẹ.

15 O kò ní ṣàìmọ̀ pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè Esia ti sá kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó fi mọ́ Fugẹlọsi ati Hemogenesi.

16 Kí Oluwa ṣàánú ìdílé Onesiforosi. Kò ní iye ìgbà tí ó ti tù mí ninu, ninu ìṣòro mi. Kò tijú pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí.

17 Nígbà tí ó dé Romu, ó fi ìtara wá mi kàn, ó sì rí mi.

18 Kí Oluwa jẹ́ kí ó lè rí àánú rẹ̀ gbà ní ọjọ́ ńlá náà. Iṣẹ́ iranṣẹ tí ó ṣe ní Efesu kò ṣe àjèjì sí ìwọ alára.

Categories
TIMOTI KEJI

TIMOTI KEJI 2

Ọmọ-Ogun Rere Ti Kristi Jesu

1 Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára.

2 Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.

3 Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu.

4 Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn.

5 Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́.

6 Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko.

7 Gba ohun tí mò ń sọ rò. Oluwa yóo jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ yé ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

8 Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí.

9 Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

10 Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae.

11 Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé,

“Bí a bá bá a kú,

a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀.

12 Bí a bá faradà á,

a óo bá a jọba.

Bí a bá sẹ́ ẹ,

òun náà yóo sẹ́ wa.

13 Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé,

òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo,

nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”

Òṣìṣẹ́ Tí Ó Yege

14 Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú.

15 Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ.

16 Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni.

17 Ọ̀rọ̀ wọn dàbí egbò-rírùn tí ó ń kẹ̀ siwaju. Irú wọn ni Himeneu ati Filetu,

18 àwọn tí wọ́n ti ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí wọn ń sọ pé ajinde tiwa ti ṣẹlẹ̀, tí wọn ń mú kí igbagbọ ẹlòmíràn yẹ̀.

19 Ṣugbọn Ọlọrun ti fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀, tí ó dúró gbọningbọnin. Àkọlé tí a kọ sára èdìdì tí ó wà lára rẹ̀ nìyí: “Ọlọrun mọ àwọn ẹni tirẹ̀,” ati pé, “Gbogbo àwọn tí ó bá ń pe orúkọ Oluwa níláti kúrò ninu ibi.”

20 Kì í ṣe àwọn ohun èèlò wúrà ati ti fadaka nìkan ni ó ń wà ninu ilé ńlá. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi igi ati amọ̀ ṣe wà níbẹ̀ pẹlu. À ń lo àwọn kan fún nǹkan pataki; à ń lo àwọn mìíràn fún ohun tí kò ṣe pataki tóbẹ́ẹ̀.

21 Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ yóo di ohun èèlò tí ó níye lórí, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó wúlò fún baálé ilé. Yóo di ẹni tí ó ṣetán láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere.

22 Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́. Máa lépa òdodo ati ìṣòtítọ́, ìfẹ́, ati alaafia, pẹlu àwọn tí ó ń képe Oluwa pẹlu ọkàn mímọ́.

23 Má bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ati ọ̀rọ̀ òpè. Ranti pé ìjà ni wọ́n ń dá sílẹ̀.

24 Iranṣẹ Oluwa kò sì gbọdọ̀ jà. Ṣugbọn ó níláti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo eniyan, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà.

25 Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́,

26 kí wọ́n lè bọ́ kúrò ninu tàkúté Satani, tí ó ti fi mú wọn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Categories
TIMOTI KEJI

TIMOTI KEJI 3

Ìwà tí Àwọn Eniyan Yóo Máa Hù ní Ọjọ́ Ìkẹyìn

1 Kí o mọ èyí pé àkókò ìṣòro ni ọjọ́ ìkẹyìn yóo jẹ́.

2 Nítorí àwọn eniyan yóo wà tí ó jẹ́ pé ara wọn ati owó nìkan ni wọn óo fẹ́ràn. Wọn óo jẹ́ oníhàlẹ̀, onigbeeraga, ati onísọkúsọ. Wọn yóo máa ṣe àfojúdi sí àwọn òbí wọn. Wọn óo jẹ́ aláìmoore; aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun,

3 onínú burúkú; akọ̀mágbẹ̀bẹ̀, abanijẹ́; àwọn tí kò lè kó ara wọn níjàánu, òǹrorò; àwọn tí kò fẹ́ ohun rere;

4 ọ̀dàlẹ̀, jàǹdùkú, àwọn tí ó jọ ara wọn lójú pupọ, àwọn tí wọ́n fẹ́ràn fàájì, dípò kí wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun.

5 Ní òde, ara wọn dàbí olùfọkànsìn, ṣugbọn wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ìwọ jìnnà sí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀.

6 Ara wọn ni àwọn tíí máa tọ ojúlé kiri, tí wọn máa ń ki àwọn aṣiwèrè obinrin mọ́lẹ̀, àwọn obinrin tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

7 Àwọn obinrin wọnyi ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, sibẹ wọn kò lè ní ìmọ̀ òtítọ́.

8 Bí Janesi ati Jamberesi ti tako Mose, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin wọnyi tako òtítọ́. Orí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ ti kú, a sì ti ṣá wọn tì ní ti igbagbọ.

9 Ṣugbọn wọn kò lè máa bá irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ pẹ́ títí. Nítorí pé ìwà wèrè wọn yóo hàn kedere sí gbogbo eniyan, gẹ́gẹ́ bí ti Janesi ati Jamberesi ti hàn.

A Tún Kìlọ̀ fún Timoti

10 Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi,

11 ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn.

12 Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn.

13 Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ.

14 Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, dúró gbọningbọnin ninu àwọn ohun tí o ti kọ́, tí ó sì dá ọ lójú. Ranti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí o ti kọ́ wọn.

15 Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.

16 Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọrun, ó sì wúlò fún ẹ̀kọ́, fún ìbáwí, fún ìtọ́nisọ́nà, fún ìlànà nípa ìwà òdodo,

17 kí eniyan Ọlọrun lè jẹ́ ẹni tí ó pé, tí ó múra sílẹ̀ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere.

Categories
TIMOTI KEJI

TIMOTI KEJI 4

1 Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀.

2 Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní.

3 Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn.

4 Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́.

5 Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ.

6 Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó.

7 Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà.

8 Nisinsinyii adé òdodo náà wà nílẹ̀ fún mi, tí Oluwa onídàájọ́ òdodo yóo fún mi ní ọjọ́ náà. Èmi nìkan kọ́ ni yóo sì fún, yóo fún gbogbo àwọn tí wọn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ retí ìfarahàn rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìparí

9 Sa gbogbo ipá rẹ láti tètè wá sọ́dọ̀ mi.

10 Demasi ti fi mí sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ràn nǹkan ayé yìí. Ó ti lọ sí Tẹsalonika. Kirẹsẹnsi ti lọ sí Galatia. Titu ti lọ sí Dalimatia.

11 Luku nìkan náà ni ó kù lọ́dọ̀ mi. Mú Maku lọ́wọ́ bí o bá ń bọ̀ nítorí ó wúlò fún mi bí iranṣẹ.

12 Mo ti rán Tukikọsi lọ sí Efesu.

13 Nígbà tí o bá ń bọ̀, bá mi mú agbádá tí mo fi sọ́dọ̀ Kapu ní Tiroasi bọ̀. Bá mi mú àwọn ìwé mi náà bọ̀, pataki jùlọ àwọn ìwé aláwọ mi.

14 Alẹkisanderu, alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí nǹkan! Kí Oluwa san ẹ̀san fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

15 Kí ìwọ náà ṣọ́ra lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí títa ni ó ń tako àwọn ohun tí à ń sọ.

16 Nígbà tí mo níláti jà fún ara mi ní ẹẹkinni, kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbèjà mi: gbogbo wọn ni wọ́n fi mí sílẹ̀. Kí Ọlọrun má kà á sí wọn lọ́rùn.

17 Ṣugbọn Oluwa dúró tì mí, ó fún mi lágbára tí mo fi waasu ìyìn rere lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu fi gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe bọ́ lẹ́nu kinniun.

18 Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin.

Ìdágbére

19 Kí Pirisila ati Akuila ati ìdílé Onesiforosi.

20 Erastu ti dúró ní Kọrinti. Mo fi Tirofimọsi sílẹ̀ ní Miletu pẹlu àìlera.

21 Sa ipá rẹ láti wá kí ó tó di àkókò òtútù.

Yubulọsi kí ọ, ati Pudẹsi, Linọsi, Kilaudia ati gbogbo àwọn arakunrin.

22 Kí Oluwa wà pẹlu ẹ̀mí rẹ.

Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín.

Categories
TITU

TITU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Titu kì í ṣe Juu, ṣugbọn ó di onigbagbọ. Ó sì di alábàáṣiṣẹ́ ati olùrànlọ́wọ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere. Paulu kọ ìwé tí à ń pè ní Ìwé Paulu sí Titu sí ọdọmọkunrin olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ yìí ní Kirete. Paulu ni ó fi Titu sí Kirete pé kí ó máa mójútó iṣẹ́ ìjọ níbẹ̀. Àwọn nǹkan àfiyèsí mẹta ni ìwé yìí mẹ́nubà.

Lákọ̀ọ́kọ́, Paulu rán Titu létí irú ìwà tí ó yẹ kí àwọn aṣaaju ninu ìjọ máa hù, pataki jùlọ, nítorí ìwà burúkú ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará Kirete. Lẹ́yìn èyí, Paulu gba Titu ní ìmọ̀ràn lórí bí ó ṣe yẹ kí ó máa kọ́ oríṣìíríṣìí ìṣọ̀wọ́ àwọn eniyan ninu ìjọ: àwọn bíi àgbà ọkunrin ati àwọn àgbà obinrin (àwọn àgbà obinrin ni Paulu ní kí ó máa kọ́ àwọn ọdọmọbinrin), lẹ́yìn náà àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn ẹrú. Ní ìparí, Paulu gba Titu ní ìmọ̀ràn nípa ìhùwàsí onigbagbọ, pataki jùlọ bí onigbagbọ ti níláti máa wá alaafia ati ìrẹ́pọ̀, tí yóo sì máa yẹra fún ìkórìíra, iyàn jíjà, ati ìyapa ninu ìjọ.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-4

Àwọn olóyè ìjọ 1:5-16

Iṣẹ́ oríṣìíríṣìí ìṣọ̀wọ́ àwọn ọmọ ìjọ 2:1-15

Ìgbani-níyànjú ati ìkìlọ̀ 3:1-11

Ọ̀rọ̀ ìparí 3:12-15

Categories
TITU

TITU 1

Ìkíni

1 Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí.

Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn,

2 ati ìrètí ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun tí kì í purọ́ ti ṣèlérí láti ayérayé.

3 Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn ní àkókò tí ó wọ̀ fún un ninu iwaasu tí ó ti fi lé mi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ọlọrun Olùgbàlà wa.

4 Mò ń kọ ìwé yìí sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ ninu ẹ̀sìn igbagbọ kan náà.

Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Olùgbàlà wa, wà pẹlu rẹ̀.

Iṣẹ́ Titu ní Kirete

5 Ìdí tí mo ṣe fi ọ́ sílẹ̀ ní Kirete ni pé kí o ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó kù tí kò dára tó, kí o sì yan àwọn àgbà lórí ìjọ ní gbogbo ìlú, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlànà fún ọ.

6 Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, tí ó ní ẹyọ iyawo kan, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onigbagbọ, tí ẹnìkan kò lè fi ẹ̀sùn kàn pé ó ń hùwà wọ̀bìà tabi pé ó jẹ́ alágídí.

7 Nítorí alabojuto ìjọ níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọrun. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí yóo máa ṣe ti inú ara rẹ̀, tabi kí ó jẹ́ onínúfùfù. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà, tabi ẹni tí ó ní ìwọ̀ra nípa ọ̀rọ̀ owó.

8 Ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ati máa ṣe àlejò, tí ó sì fẹ́ ohun rere, ó yẹ kí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, olódodo, olùfọkànsìn, ẹni tí ó ń kó ara rẹ̀ níjàánu.

9 Kí ó di ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí a ti fi kọ́ ọ mú ṣinṣin, kí ó baà lè ní ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ẹ̀kọ́ tí ó yè, kí ó sì lè bá àwọn alátakò wí.

10 Nítorí àwọn alágídí pọ̀, tí wọn ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn ẹlẹ́tàn, pàápàá jùlọ lára àwọn ọ̀kọlà.

11 Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ.

12-13 Ẹnìkan ninu wọn tí ó jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn wolii wọn sọ pé, “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kirete, ẹhànnà, ẹranko, ọ̀lẹ, alájẹkì.” Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí náà má gbojú fún wọn, bá wọn wí kí wọ́n lè ní igbagbọ tí ó pé.

14 Kí wọn má máa lo àkókò wọn lórí ìtàn àròsọ àwọn Juu ati ìlànà àwọn eniyan tí wọ́n ti yapa kúrò lọ́nà òtítọ́.

15 Gbogbo nǹkan ni ó mọ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ṣugbọn kò sí nǹkankan tí ó mọ́ fún àwọn alaigbagbọ tí èrò wọn ti wọ́, nítorí èrò wọn ati ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọ́.

16 Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.

Categories
TITU

TITU 2

Ẹ̀kọ́ tí ó Yè Kooro

1 Ní tìrẹ, àwọn ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro mu ni kí ó máa ti ẹnu rẹ jáde.

2 Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà.

3 Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere.

4 Kí wọn máa fi òye kọ́ àwọn ọdọmọbinrin wọn láti fẹ́ràn ọkọ wọn ati ọmọ wọn.

5 Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

6 Bákan náà, máa gba àwọn ọdọmọkunrin níyànjú láti fara balẹ̀.

7 Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ.

8 Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa.

9 Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì.

10 Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo.

11 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti farahàn fún ìgbàlà gbogbo eniyan.

12 Ó ń tọ́ wa sọ́nà pé kí á kọ ìwà aibikita fún Ọlọrun ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé sílẹ̀, kí á máa farabalẹ̀. Kí á máa gbé ìgbé-ayé òdodo, kí á sì jẹ́ olùfọkànsìn ní ayé yìí.

13 Kí á máa dúró de ibukun tí à ń retí, ati ìfarahàn ògo Ọlọrun ẹni ńlá, ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi,

14 ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.

15 Báyìí ni kí o máa wí fún wọn, kí o máa fi gbà wọ́n níyànjú kí o sì máa bá wọn wí nígbà gbogbo pẹlu àṣẹ. Má gbà fún ẹnikẹ́ni láti fojú tẹmbẹlu rẹ.

Categories
TITU

TITU 3

Ìlànà nípa Ìwà Tí Ó Dára

1 Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo.

2 Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò.

3 Nítorí nígbà kan rí, àwa náà ń ṣe wérewère, à ń ṣe àìgbọràn, ayé ń tàn wá jẹ, a jẹ́ ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a sì ń jẹ ayé ìjẹkújẹ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. À ń hùwà ìkà ati ìlara. A jẹ́ ohun ìríra fún àwọn eniyan. Àwa náà sì kórìíra ọmọnikeji wa.

4 Ṣugbọn nígbà tí Ọlọrun fi inú rere ati ìfẹ́ rẹ̀ sí àwa eniyan hàn, ó gbà wá là;

5 kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun.

6 Ó da Ẹ̀mí yìí lé wa lórí lọpọlọpọ láti ọwọ́ Jesu Kristi Olùgbàlà wa.

7 Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun.

8 Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí.

Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani.

9 Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá.

10 Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un.

11 Mọ̀ pé ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti wọ́, ó ń dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.

Gbolohun Ìparí

12 Nígbà tí mo bá rán Atemasi tabi Tukikọsi sí ọ, sa ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi ní ìlú Nikopoli, nítorí níbẹ̀ ni mo pinnu láti wà ní àkókò òtútù.

13 Sa gbogbo ipá rẹ láti ran Senasi, lọ́yà, ati Apolo lọ́wọ́ kí wọn lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, kí o sì rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́.

14 Àwọn eniyan wa níláti kọ́ láti ṣe iṣẹ́ rere kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà wọn; wọn kò gbọdọ̀ jókòó tẹtẹrẹ láìṣe nǹkankan.

15 Gbogbo àwọn ẹni tí ó wà lọ́dọ̀ mi ní kí n kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa ninu igbagbọ.

Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín.

Categories
FILEMONI

FILEMONI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Eniyan pataki kan tí ó jẹ́ onigbagbọ ni Filemoni; bóyá ọmọ ìjọ Kolose ni. Ó ní ẹrú kan tí ń jẹ́ Onisimu. Ẹrú yìí ti kọ́ sálọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹrú yìí ṣe alábàápàdé Paulu tí ó wà ninu ẹ̀wọ̀n ní àkókò yìí, ó sì ti ipasẹ̀ Paulu di onigbagbọ. Ìwé ẹ̀bẹ̀ ni Ìwé Paulu sí Filemoni jẹ́ sí ọkunrin tí ń jẹ́ Filemoni yìí, pé kí ó gba Onisimu, ẹrú rẹ̀, tí Paulu ń rán pada sí i, tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní kì í ṣe pé kí ó gbà á pada bí ẹrú tí a dáríjì nìkan ṣugbọn bí arakunrin ninu igbagbọ.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1-3

Ìyìn Filemoni 4-7

Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu 8-22

Ọ̀rọ̀ ìparí 23-25

Categories
FILEMONI

FILEMONI 1

1 Èmi Paulu, ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Kristi Jesu, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Filemoni, àyànfẹ́ wa ati alábàáṣiṣẹ́ wa,

2 ati sí Afia, arabinrin wa ati sí Akipu: ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ wa fún Kristi, ati sí ìjọ tí ó wà ninu ilé rẹ̀.

3 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu yín ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi.

Ìfẹ́ ati Igbagbọ Tí Filemoni Ní

4 Nígbà gbogbo tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun.

5 Mò ń gbọ́ ìròyìn ìfẹ́ ati igbagbọ tí o ní sí Oluwa Jesu, ati sí gbogbo àwọn onigbagbọ.

6 Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi.

7 Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi.

Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu

8 Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ ní ìgboyà pupọ ninu Kristi láti pàṣẹ ohun tí ó yẹ fún ọ,

9 ṣugbọn nítorí ìfẹ́ tí ó wà láàrin wa, ẹ̀bẹ̀ ni n óo kúkú bẹ̀. Èmi Paulu, ikọ̀ Kristi, tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nisinsinyii nítorí ti Kristi Jesu,

10 mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n.

11 Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi.

12 Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ.

13 Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere.

14 Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.

15 Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà;

16 kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

17 Nítorí náà bí o bá kà mí sí ẹni tí a jọ gba nǹkankan náà gbọ́, kí o gbà á pada tọwọ́-tẹsẹ̀ bí ẹni pé èmi alára ni o gbà.

18 Ohunkohun tí ó bá ti ṣe sí ọ láìdára, tabi ohun tí ó bá jẹ ọ́, èmi ni kí o kà á sí lọ́rùn.

19 Èmi, Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ọ́ pé, n óo san án pada fún ọ. Kò tún nílò kí n sọ fún ọ pé ìwọ fúnrarẹ, o jẹ mí ní gbèsè ara rẹ.

20 Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.

21 Pẹlu ìdánilójú pé o óo ṣe bí mo ti wí ni mo fi kọ ìwé yìí sí ọ; mo sì mọ̀ pé o óo tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

22 Ó ku nǹkankan: Tọ́jú ààyè sílẹ̀ dè mí, nítorí mo ní ìrètí pé, nípa adura yín, Ọlọrun yóo jẹ́ kí wọ́n dá mi sílẹ̀ fun yín.

Ìdágbére

23 Epafirasi, ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi nítorí ti Kristi Jesu, kí ọ.

24 Bẹ́ẹ̀ ni Maku, ati Arisitakọsi, ati Demasi ati Luku, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu ẹ̀mí yín.