Categories
GALATIA

GALATIA 2

Àwọn Aposteli yòókù Gba Paulu Bí Aposteli

1 Lẹ́yìn ọdún mẹrinla ni mo tó tún gòkè lọ sí Jerusalẹmu pẹlu Banaba. Mo mú Titu lọ́wọ́ pẹlu.

2 Ọlọrun ni ó fihàn mí lójúran ni mo fi lọ. Mo wá ṣe àlàyé níwájú àwọn aṣaaju nípa ìyìn rere tí mò ń waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Níkọ̀kọ̀ ni a sọ̀rọ̀ kí gbogbo iré-ìje tí mò ń sá ati èyí tí mo ti sá má baà jẹ́ lásán.

3 Kì í ṣe ọ̀ranyàn ni pé kí á kọ Titu tí ó wà pẹlu mi nílà nítorí pé ọmọ ẹ̀yà Giriki ni.

4 Àwọn tí ó gbé ọ̀rọ̀ nípa ìkọlà Titu jáde ni àwọn arakunrin èké tí wọ́n yọ́ wá wo òmìnira wa tí a ní ninu Kristi Jesu, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú òfin.

5 Ṣugbọn a kò fi ìgbà kankan gbà wọ́n láyè rárá, kí ó má dàbí ẹni pé ọ̀rọ̀ tiwọn ni ó borí, kí òtítọ́ ìyìn rere lè wà pẹlu yín.

6 Ṣugbọn àwọn tí wọn ń pè ní aṣaaju ninu wọn kò kọ́ mi ní ohun titun kan. Ohun tí ó mú kí n sọ̀rọ̀ báyìí ni pé kò sí ohun tí ó kàn mí ninu ọ̀rọ̀ a-jẹ́-aṣaaju tabi a-kò-jẹ́-aṣaaju. Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.

7 Ṣugbọn wọ́n wòye pé a ti fi iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà fún mi ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti fún Peteru ní iṣẹ́ ajíyìnrere fún àwọn tí ó kọlà.

8 Nítorí ẹni tí ó fún Peteru ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí wọ́n kọlà ni ó fún mi ní agbára láti ṣiṣẹ́ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.

9 Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà.

10 Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe.

Paulu Bá Peteru Wí ní Antioku

11 Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí.

12 Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà.

13 Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn!

14 Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?”

Igbagbọ Ni Ọ̀nà Ìgbàlà fún Gbogbo Eniyan

15 Àwa tí a bí ní Juu, tí a kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀,

16 mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin.

17 Nígbà tí à ń wá ọ̀nà ìdáláre ninu Kristi, bí a bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwa náà, ṣé Kristi wá di iranṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o!

18 Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ ni mo tún ń kọ́, èmi náà di ẹlẹ́ṣẹ̀.

19 Nítorí nípa òfin, mo ti kú sinu òfin kí n lè wà láàyè lọ́dọ̀ Ọlọrun. A ti kàn mí mọ́ agbelebu pẹlu Kristi.

20 Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi.

21 Kì í ṣe pé mo pa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tì. Nítorí bí eniyan bá lè di olódodo nípa ṣíṣe iṣẹ́ òfin, a jẹ́ pé Kristi kàn kú lásán ni.

Categories
GALATIA

GALATIA 3

Òfin tabi Igbagbọ

1 Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba!

2 Nǹkankan péré ni mo fẹ́ bi yín: ṣé nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ fi gba Ẹ̀mí ni tabi nípa ìgbọràn igbagbọ?

3 Àṣé ẹ ṣiwèrè tóbẹ́ẹ̀! Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹlu nǹkan ti ẹ̀mí, ẹ wá fẹ́ fi nǹkan ti ara parí!

4 Gbogbo ìyà tí ẹ ti jẹ á wá jẹ́ lásán? Kò lè jẹ́ lásán!

5 Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á?

6 Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo,

7 kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu.

8 Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.”

9 Èyí ni pé àwọn tí ó gbàgbọ́ rí ibukun gbà, bí Abrahamu ti rí ibukun gbà nítorí pé ó gbàgbọ́.

10 A ti fi gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ òfin gégùn-ún. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí kò bá máa ṣe ohun gbogbo tí a kọ sinu ìwé òfin.”

11 Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa òfin, nítorí a kà á pé, “Olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”

12 Ṣugbọn òfin kì í ṣe igbagbọ, nítorí a kà á pé, “Ẹni tí ó bá ń pa gbogbo òfin mọ́ yóo wà láàyè nípa wọn.”

13 Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.”

14 Ìdí rẹ̀ ni pé kí ibukun Abrahamu lè kan àwọn tí kì í ṣe Juu nípasẹ̀ Kristi Jesu, kí á lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa igbagbọ.

Òfin ati Ìlérí

15 Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí á lo àkàwé kan ninu ìrírí eniyan. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, nígbà tí a bá ti ṣe majẹmu tán, kò sí ẹni tí ó lè yí i pada tabi tí ó lè fi gbolohun kan kún un.

16 Nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu ati irú-ọmọ rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ ni Ọlọrun ń sọ, ṣugbọn ọmọ kanṣoṣo ni ó tọ́ka sí. Ó sọ pé, “Ati fún irú-ọmọ rẹ.” Ọmọ náà ni Kristi.

17 Kókó ohun tí mò ń sọ ni pé òfin tí ó dé lẹ́yìn ọgbọnlenirinwo (430) ọdún kò lè pa majẹmu tí Ọlọrun ti ṣe rẹ́. Ìlérí tí Ọlọrun ti ṣe kò lè torí rẹ̀ di òfo.

18 Nítorí bí eniyan bá lè di ajogún nípa òfin, a jẹ́ pé kì í tún ṣe ìlérí mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni nípa ìlérí ni Ọlọrun fún Abrahamu ní ogún.

19 Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin.

20 Ètò tí alárinà bá lọ́wọ́ sí ti kúrò ní ti ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọrun.

Ọmọ ati Ẹrú

21 Ǹjẹ́ òfin wá lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọrun ni bí? Rárá o! Bí ó bá jẹ́ pé òfin tí a fi fúnni lè sọ eniyan di alààyè, eniyan ìbá lè di olódodo nípa òfin.

22 Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ohun gbogbo wà ninu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ kí á lè fi ìlérí nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́.

23 Ṣugbọn kí àkókò igbagbọ yìí tó tó, a wà ninu àtìmọ́lé lábẹ́ òfin, a sé wa mọ́ títí di àkókò igbagbọ yìí.

24 Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ.

25 Nígbà tí àkókò igbagbọ ti dé, a kò tún nílò olùtọ́ mọ́.

26 Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.

27 Nítorí gbogbo ẹni tí ó ti ṣe ìrìbọmi nípa igbagbọ ninu Kristi ti gbé Kristi wọ̀.

28 Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu.

29 Tí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, a jẹ́ pé ẹ jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, ẹ sì di ajogún ìlérí.

Categories
GALATIA

GALATIA 4

1 Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀.

2 Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá.

3 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí.

4 Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu,

5 kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ.

6 Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́.

7 Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun.

Paulu Ní Àníyàn fún Àwọn Ará Galatia

8 Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun.

9 Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn?

10 Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún!

11 Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!

12 Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá.

13 Ẹ mọ̀ pé àìlera ni ó mú kí n waasu ìyìn rere fun yín ní àkọ́kọ́.

14 Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu.

15 Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi!

16 Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín!

17 Kì í ṣe ire yín ni àwọn tí wọn ń ṣaájò yín ń wá. Ohun tí wọn ń wá ni kí wọ́n lè fi yín sinu àhámọ́, kí ẹ lè máa wá wọn.

18 Ó dára kí á máa wá ara ẹni ninu ohun rere nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo bá wà pẹlu yín nìkan.

19 Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi.

20 Ó wù mí bíi pé kí n wà lọ́dọ̀ yín nisinsinyii, kí n yí ohùn mi pada, nítorí ọ̀rọ̀ yín rú mi lójú.

Àkàwé Hagari ati Sara

21 Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí?

22 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira.

23 Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun.

24 Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari.

25 Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀.

26 Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa.

27 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,

“Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí.

Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.

Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.”

28 Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín.

29 Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí.

30 Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.”

31 Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá.

Categories
GALATIA

GALATIA 5

Òmìnira Onigbagbọ

1 Irú òmìnira yìí ni a ní. Kristi ti sọ wá di òmìnira. Ẹ dúró ninu rẹ̀, kí ẹ má sì tún gbé àjàgà ẹrú kọ́rùn mọ́.

2 Èmi Paulu ni mo wí fun yín pé bí ẹ bá kọlà, Kristi kò ṣe yín ní anfaani kankan.

3 Mo tún wí pé gbogbo ẹni tí a bá kọ nílà di ajigbèsè; ó níláti pa gbogbo òfin mọ́.

4 Ẹ ti ya ara yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ ìdáláre nípa òfin. Ẹ ti yapa kúrò ní ọ̀nà oore-ọ̀fẹ́.

5 Ṣugbọn ní tiwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni à ń retí ìdáláre nípa igbagbọ.

6 Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.

7 Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́?

8 Ìyípadà ọkàn yín kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó pè yín.

9 Ìwúkàrà díẹ̀ níí mú kí gbogbo ìyẹ̀fun wú sókè.

10 Mo ní ìdánilójú ninu Oluwa pé ẹ kò ní ní ọkàn mìíràn. Ṣugbọn ẹni tí ó ń yọ yín lẹ́nu yóo gba ìdájọ́ Ọlọrun, ẹni yòówù kí ó jẹ́.

11 Ará, tí ó bá jẹ́ pé iwaasu pé kí eniyan kọlà ni mò ń wà, kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ǹjẹ́ a ti mú ohun ìkọsẹ̀ agbelebu Kristi kúrò?

12 Ìbá wù mí kí àwọn tí ó ń yọ yín lẹ́nu kúkú gé ara wọn sọnù patapata!

13 Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́.

14 Nítorí gbolohun kan kó gbogbo òfin já, èyí ni pé “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”

15 Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run.

Èso Ti Ẹ̀mí ati Àwọn Iṣẹ́ Ti Ara

16 Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé kí ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ.

17 Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe.

18 Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.

19 Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà;

20 ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí;

21 inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun.

22 Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,

23 ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.

24 Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara.

25 Bí a bá wà láàyè nípa Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí á máa gbé ìgbé-ayé ti Ẹ̀mí.

26 Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa.

Categories
GALATIA

GALATIA 6

Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́

1 Ará, bí ẹ bá ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ẹnìkan lọ́wọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ̀mí ń darí ìgbé-ayé yín mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò pẹlu ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ṣọ́ra rẹ, kí á má baà dán ìwọ náà wò.

2 Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ.

3 Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ.

4 Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn.

5 Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀.

6 Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀.

7 Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká.

8 Nítorí àwọn tí ó bá ń gbin nǹkan ti Ẹ̀mí yóo ká àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí, tíí ṣe ìyè ainipẹkun.

9 Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá.

10 Nítorí náà, bí a bá ti ń rí ààyè kí á máa ṣe oore fún gbogbo eniyan, pàápàá fún àwọn ìdílé onigbagbọ.

Gbolohun Ìparí

11 Ọwọ́ ara mi ni mo fi kọ ìwé yìí si yín, ẹ wò ó bí ó ti rí gàdàgbà-gadagba!

12 Gbogbo àwọn tí wọn ń fẹ́ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn mọ̀ wọ́n ní ẹni rere ni wọ́n fẹ́ fi ipá mu yín kọlà, kí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn má baà ṣe inúnibíni sí wọn nítorí agbelebu Kristi.

13 Nítorí àwọn tí wọ́n kọlà pàápàá kì í pa gbogbo òfin mọ́. Ṣugbọn wọ́n fẹ́ kí ẹ kọlà kí wọ́n máa fi yín fọ́nnu pé àwọn mu yín kọlà.

14 Ṣugbọn ní tèmi, kí á má rí i pé mò ń fọ́nnu kiri àfi nítorí agbelebu Oluwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ayé yìí ti di ohun tí a kàn mọ́ agbelebu lójú mi, tí èmi náà sì di ẹni tí a kàn mọ́ agbelebu lójú rẹ̀.

15 Nítorí ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó já mọ́ nǹkankan. Ohun tí ó ṣe pataki ni ẹ̀dá titun.

16 Kí alaafia ati àánú Ọlọrun kí ó wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá ń gbé ìgbé-ayé wọn nípa ìlànà yìí, ati pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun.

17 Láti ìgbà yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́, nítorí ojú pàṣán wà ní ara mi tí ó fihàn pé ti Jesu ni mí.

18 Ará, kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa wa kí ó wà pẹlu yín. Amin.

Categories
EFESU

EFESU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Pataki ohun tí Paulu sọ̀rọ̀ bá ninu ìwé yìí ni ètò tí Ọlọrun ṣe láti kó gbogbo ẹ̀dá jọ pọ̀, ati láti fihàn pé Kristi ni orí ohun gbogbo: ìbáà jẹ́ láyé ni tabi lọ́run (1:10). Ìwé yìí tún jẹ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo eniyan Ọlọrun láti máa gbé irú ìgbé-ayé tí yóo jẹ́ kí àwọn eniyan rí ìtumọ̀ ètò Ọlọrun fún ìṣọ̀kan gbogbo eniyan nípa pé kí á ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi.

Ninu apá kinni

Ìwé Efesu

, Paulu ṣe àlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa ìṣọ̀kan, tíí ṣe kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ninu àlàyé rẹ̀, ó mẹ́nuba bí Ọlọrun Baba ti yan àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ṣe dáríjì wọ́n, bí ó ṣe dá wọn nídè kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀, ati bí Ọlọrun ṣe rán Ẹ̀mí Mímọ́ láti fún wa ní ìdánilójú pé ìlérí ńlá Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé. Ninu apá keji ìwé yìí Paulu rọ gbogbo àwọn tí wọ́n bá ka ìwé yìí láti gbé irú ìgbé-ayé tí yóo jẹ́ kí ìṣọ̀kan wọn kúrò ní àfẹnujẹ́ ninu ìgbépọ̀ wọn.

Oríṣìíríṣìí èdè àpèjúwe ni Paulu lò láti fihàn pé ọ̀kan náà ni gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí wọ́n bá ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi. Ìjọ dàbí ara eniyan: Kristi ni ó dàbí orí. Ó tún fi ìjọ wé ilé, Kristi sì jẹ́ òkúta igun ilé. Ohun tí a tún lè fi ìjọ wé ni iyawo, Kristi ni ọkọ. Èdè tí ẹni tí ó kọ ìwé yìí lò bẹ̀rẹ̀ sí dùn mọ́ eniyan létí sí i bí ìrònú lórí oore-ọ̀fẹ́ ninu Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀ sí i. A rí gbogbo nǹkan ninu ìfẹ́ Kristi ati ìrúbọ rẹ̀, ìdáríjì rẹ̀, oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ati jíjẹ́ mímọ́ rẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2

Kristi ati ìjọ 1:3–3:21

Ìgbé-ayé titun ninu Kristi 4:1–6:20

Ọ̀rọ̀ ìparí 6:21-24

Categories
EFESU

EFESU 1

Ìkíni

1 Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Efesu,àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi Jesu.

2 Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín.

Ibukun ti Ẹ̀mí Nípa Kristi

3 Ẹ jẹ́ kí á fi ìyìn fún Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, tí ó ti fi ọpọlọpọ ibukun ti ẹ̀mí fún wa lọ́run nípasẹ̀ Kristi.

4 Òun ni ó yàn wá nípasẹ̀ Kristi kí ó tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ó yàn wá kí á lè jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀, tí kò ní àléébù níwájú rẹ̀, tí ó sì kún fún ìfẹ́.

5 Ó ti pinnu tẹ́lẹ̀ láti fi wá ṣe ọmọ rẹ̀ nípasẹ̀ Jesu Kristi, ohun tí ó fẹ́ tí inú rẹ̀ sì dùn sí nìyí;

6 kí á lè mọyì ẹ̀bùn rẹ̀ tí ó lógo tí ó fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ Kristi àyànfẹ́ rẹ̀.

7 Nípasẹ̀ Kristi ni a ti ní ìdáǹdè nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti rí ìdáríjì gbà fún àwọn ìrékọjá wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.

8 A ní oore-ọ̀fẹ́ yìí lọpọlọpọ!

Ó fún wa ní gbogbo ọgbọ́n ati òye.

9 Ó jẹ́ kí á mọ àṣírí ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètò tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ tí ó ti ṣe ninu Kristi.

10 Èyí ni pé, nígbà tí àkókò bá tó, kí ó lè ṣe ohun gbogbo ní àṣeparí ninu Kristi nígbà tí ó bá yá, ìbáà ṣe àwọn ohun tí ó wà ninu àwọn ọ̀run, tabi àwọn ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, kí ó lè sọ wọ́n di ọ̀kan ninu Kristi.

11 Nípasẹ̀ Kristi kan náà ni Ọlọrun ti pín wa ní ogún. Ètò tí ó ti ṣe fún wa nìyí, òun tí ó ń mú ohun gbogbo ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.

12 Àyọrísí gbogbo èyí ni pé kí àwa Juu tí a kọ́kọ́ ní ìrètí ninu Kristi lè yìn ín lógo.

13 Ninu Kristi kan náà ni ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, tíí ṣe ìyìn rere ìgbàlà yín tí ẹ gbàgbọ́. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọrun ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ṣe ìlérí fun yín bí èdìdì.

14 Ẹ̀mí Mímọ́ yìí jẹ́ onídùúró ogún tí a óo gbà nígbà tí Ọlọrun bá dá àwọn eniyan rẹ̀ nídè, kí á lè yin Ọlọrun lógo.

Adura Paulu

15 Nítorí èyí, láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa igbagbọ yín ninu Oluwa Jesu, ati ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn onigbagbọ, èmi náà

16 kò sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, mo sì ń ranti yín ninu adura mi.

17 Mò ń gbadura pé kí Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba ológo, lè fun yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n, kí ó sì jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ tí ó kún nípa òun alára.

18 Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ,

19 ati bí agbára rẹ̀ ti tóbi tó fún àwa tí a gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ títóbi agbára rẹ̀.

20 Ó fi agbára yìí hàn ninu Kristi nígbà tí ó jí i dìde ninu òkú, tí ó mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lọ́run.

21 Ó ga ju gbogbo àwọn ọlọ́lá ati aláṣẹ ati àwọn alágbára ati àwọn olóye tí wọ́n wà lójú ọ̀run lọ. Ó tún ga ju gbogbo orúkọ tí eniyan lè dá lọ, kì í ṣe ní ayé yìí nìkan, ṣugbọn ati ní ayé tí ń bọ̀ pẹlu.

22 Ọlọrun ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ Kristi yìí kan náà ó fi ṣe orí fún gbogbo ìjọ onigbagbọ.

23 Ìjọ ni ara Kristi, Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun gbogbo. Òun ni ó ń mú ohun gbogbo kún.

Categories
EFESU

EFESU 2

Láti Inú Ikú sí Inú Ìyè

1 Nígbà kan rí ẹ jẹ́ òkú ninu ìwàkiwà ati ẹ̀ṣẹ̀ yín.

2 Nígbà náà ẹ̀ ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ayé yìí, ẹ̀ ń gbọ́ràn sí aláṣẹ àwọn ẹ̀mí tí ó wà ninu òfuurufú lẹ́nu, àwọn ẹ̀mí wọnyi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí ninu àwọn ọmọ tí kò gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu.

3 Gbogbo àwa yìí náà ti wà lára irú wọn rí, nígbà tí à ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ara bá fẹ́ ati àwọn ohun tí ọkàn bá ti rò. Nígbà náà, nípa ti ẹ̀dá ara, àwa náà wà ninu àwọn ọmọ tí Ọlọrun ìbá bínú sí, gẹ́gẹ́ bí àwọn eniyan yòókù.

4 Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa,

5 ó sọ wá di alààyè pẹlu Kristi nígbà tí a ti di òkú ninu ìwàkíwà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là.

6 Ọlọrun tún jí wa dìde pẹlu Kristi Jesu, ó wá fi wá jókòó pẹlu rẹ̀ lọ́run,

7 kí ó lè fihàn ní àkókò tí ó ń bọ̀ bí ọlá oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tóbi tó, nípa àánú tí ó ní sí wa ninu Kristi Jesu.

8-9 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga.

10 Nítorí òun ni ó dá wa bí a ti rí, ó dá wa fún iṣẹ́ rere nípasẹ̀ Kristi Jesu, àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, pé kí á máa ṣe.

Ọ̀kan ninu Kristi

11 Nítorí náà, ẹ ranti pé nígbà kan rí, ẹ jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí ipò tí a bi yín sí. Àwọn tí wọ́n kọlà ti ara, tí wọ́n fi ọwọ́ kọ sì ń pè yín ní aláìkọlà.

12 Nígbà náà ẹ wà ní ipò ẹni tí kò mọ Kristi. Ẹ jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ Israẹli. Àwọn majẹmu tí ó ní ìlérí Ọlọrun ninu sì tún ṣe àjèjì si yín. Ẹ wà ninu ayé láìní ìrètí ati láìní Ọlọrun.

13 Ṣugbọn nisinsinyii, ninu Kristi Jesu, ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn nígbà kan rí, ti súnmọ́ ìtòsí nípa ẹ̀jẹ̀ tí Kristi ta sílẹ̀.

14 Nítorí pé Kristi yìí ni alaafia wa. Òun ni ó sọ àwọn tí wọ́n kọlà ati àwọn tí kò kọlà di ọ̀kan. Nígbà tí ó gbé ara eniyan wọ̀, ó wó ògiri ìkélé tí ó wà láàrin wọn tí wọ́n fi ń yan ara wọn lódì.

15 Ó sọ òfin ati àwọn ìlànà ati àṣẹ di nǹkan yẹpẹrẹ, kí ó lè sọ àwọn mejeeji di ẹ̀dá titun kan náà ninu ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú alaafia wá sáàrin wọn.

16 Ó làjà láàrin àwọn mejeeji, ó sọ wọ́n di ara kan lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa agbelebu. Ó ti mú odì yíyàn dópin lórí agbelebu.

17 Nígbà tí ó dé, ó waasu ìyìn rere alaafia fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn, ó sì waasu ìyìn rere alaafia fún àwọn tí ó wà nítòsí.

18 Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà.

19 Nítorí náà, ẹ kì í tún ṣe àlejò ní ìlú àjèjì mọ́, ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ pẹlu àwọn onigbagbọ, ẹ sì di mọ̀lẹ́bí ninu agbo-ilé Ọlọrun.

20 Lórí àwọn aposteli ati àwọn wolii ni a ti fi ìpìlẹ̀ ìdílé yìí lélẹ̀, Kristi Jesu fúnrarẹ̀ sì ni òkúta igun ilé.

21 Òun ni ó mú kí gbogbo ilé dúró dáradára, tí ó sì mú un dàgbà láti di ilé ìsìn mímọ́ fún Oluwa.

22 Ẹ̀mí ń kọ́ àwa ati ẹ̀yin papọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi kí á lè di ibùgbé Ọlọrun.

Categories
EFESU

EFESU 3

Iṣẹ́ Paulu láàrin Àwọn Tí Kì í Ṣe Juu

1 Ìdí rẹ̀ nìyí tí èmi Paulu fi di ẹlẹ́wọ̀n fún Kristi Jesu nítorí ti ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe Juu.

2 Ẹ óo ṣá ti gbọ́ nípa iṣẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ láti ṣe fun yín.

3 Ọlọrun ni ó fi àṣírí yìí hàn mí lójú ìran, gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ọ́ sinu ìwé ní ṣókí tẹ́lẹ̀.

4 Nígbà tí ẹ bá kà á, ẹ óo rí i pé mo ní òye àṣírí Kristi,

5 tí Ọlọrun kò fihan àwọn ọmọ eniyan ní ìgbà àtijọ́, ṣugbọn tí ó fihan àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ ati àwọn wolii rẹ̀ nisinsinyii, ninu ẹ̀mí.

6 Àṣírí yìí ni pé àwọn tí kì í ṣe Juu ní anfaani láti pín ninu ogún pẹlu àwọn Juu, ara kan náà sì ni wọ́n pẹlu àwọn tí wọ́n jọ ní ìlérí ninu Kristi Jesu nípasẹ̀ ìyìn rere rẹ̀.

7 Èyí ni iṣẹ́ tí a fi fún mi nípa ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

8 Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi.

9 Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́,

10 kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà.

11 Ọlọrun ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ètò rẹ̀, láti ayérayé, tí ó mú ṣẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

12 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ.

13 Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín.

Ìfẹ́ Tí Kristi Ní

14 Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba,

15 tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé.

16 Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun;

17 kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́,

18 kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó;

19 kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun.

20 Ògo ni fún ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu wa.

21 Kí ògo yìí wà fún un ninu ìjọ ati ninu Kristi Jesu láti ìrandíran títí laelae. Amin.

Categories
EFESU

EFESU 4

Ìṣọ̀kan Ara Kristi

1 Nítorí náà, èmi tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Oluwa, ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, bí irú ìpè tí Ọlọrun pè yín.

2 Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà.

3 Ẹ ní ìtara láti pa ìṣọ̀kan ti Ẹ̀mí mọ́ ninu alaafia tí ó so yín pọ̀.

4 Ara kan ni ó wà, ati Ẹ̀mí kan, gẹ́gẹ́ bí ìpè tí a ti pè yín ti jẹ́ ti ìrètí kan.

5 Oluwa kan ṣoṣo ni ó wà, ati igbagbọ kan, ati ìrìbọmi kan.

6 Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba gbogbo eniyan, òun ni olórí ohun gbogbo, tí ó ń ṣiṣẹ́ ninu ohun gbogbo, tí ó sì wà ninu ohun gbogbo.

7 Ṣugbọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹ̀bùn tí Kristi fi fún wa.

8 Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé,

“Nígbà tí ó lọ sí òkè ọ̀run,

ó kó àwọn ìgbèkùn lẹ́yìn,

ó sì fi ẹ̀bùn fún àwọn eniyan.”

9 Nígbà tí ó sọ pé, “Ó lọ sí òkè ọ̀run,” ìtumọ̀ èyí kò lè yéni tóbẹ́ẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ wá sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

10 Òun kan náà tí ó wá sí ìsàlẹ̀ ni ó lọ sí òkè, tí ó tayọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́run, kí ó lè sọ gbogbo nǹkan di kíkún.

11 Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti jẹ́ aposteli, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ wolii, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ ajíyìnrere, àwọn ẹlòmíràn, láti jẹ́ alufaa ati olùkọ́ni.

12 Àwọn ẹ̀bùn wọnyi wà fún lílò láti mú kí ara àwọn eniyan Ọlọrun lè dá ṣáṣá kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, ati láti mú kí ara Kristi lè dàgbà.

13 Báyìí ni gbogbo wa yóo fi dé ìṣọ̀kan ninu igbagbọ ati ìmọ̀ Ọmọ Ọlọrun, tí a óo fi di géńdé, tí a óo fi dàgbà bí Kristi ti dàgbà.

14 A kì í tún ṣe ọmọ-ọwọ́ mọ́, tí ìgbì yóo máa bì sọ́tùn-ún, sósì, tabi tí afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àrékérekè àwọn tí wọn ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ láti fi tan eniyan jẹ yóo máa fẹ́ káàkiri.

15 Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí.

16 Òun ni ó mú kí gbogbo ẹ̀yà ara wà ní ìṣọ̀kan, tí gbogbo oríkèé-ríkèé ara wa sì wà ní ipò wọn, pẹlu iṣan tí ó mú wọn dúró, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipò olukuluku wọn, tí gbogbo ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan fi ń dàgbà, tí ó ń mú kí gbogbo ara rẹ̀ dàgbà ninu ìfẹ́.

Ìgbé-Ayé ti Àtijọ́ ati ti Ìsinsìnyìí

17 Nítorí náà, mò ń sọ fun yín, mo sì ń bẹ̀ yín ní orúkọ Oluwa pé, kí ẹ má máa hùwà bíi ti àwọn abọ̀rìṣà mọ́, àwọn tí wọn ń hùwà gẹ́gẹ́ bí èrò asán ọkàn wọn.

18 Ọkàn àwọn yìí ti ṣókùnkùn, ó sì ti yàtọ̀ pupọ sí irú ìgbé-ayé tí Ọlọrun fẹ́. Nítorí òpè ni wọ́n, ọkàn wọn ti le.

19 Wọn kò bìkítà: wọ́n ti fi ara wọn fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara nípa oríṣìíríṣìí ìwà burúkú nítorí ojúkòkòrò.

20 Ṣugbọn a kò kọ́ ẹ̀yin bẹ́ẹ̀ nípa Kristi.

21 Ẹ ti gbọ́ nípa Jesu, a sì ti fi òtítọ́ rẹ̀ kọ yín,

22 pé kí ẹ jìnnà sí irú ìwà àtijọ́ tí ẹ ti ń hù, ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tíí máa tan eniyan lọ sinu ìparun.

23 Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ yín di ẹni titun ninu ọkàn yín.

24 Kí ẹ wá gbé ẹni titun nnì tí Ọlọrun dá wọ̀, kí ẹ lè máa ṣe òdodo, kí ẹ sì máa hu ìwà mímọ́ ninu òtítọ́.

Ìlànà fún Ìgbé-Ayé Titun

25 Nítorí náà, ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa bá ẹnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí gbogbo wa jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà.

26 Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu.

27 Ẹ má fi ààyè gba Èṣù.

28 Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní.

29 Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani.

30 Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà.

31 Ẹ níláti mú gbogbo inú burúkú, ìrúnú, ibinu, ariwo ati ìsọkúsọ kúrò láàrin yín ati gbogbo nǹkan burúkú.

32 Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.