Categories
ORIN SOLOMONI

ORIN SOLOMONI 7

1 Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà,

ìwọ, ọmọ aládé.

Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́,

tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe.

2 Ìdodo rẹ dàbí abọ́,

tí kì í gbẹ fún àdàlú waini,

ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà,

tí a fi òdòdó lílì yíká.

3 Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji,

tí wọn jẹ́ ìbejì.

4 Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́.

Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni,

tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu.

Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni,

tí ó dojú kọ ìlú Damasku.

5 Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli,

irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́

irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.

6 O dára, o wuni gan-an,

olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.

7 Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ,

ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.

8 Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún,

kí n di odi rẹ̀ mú.

Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà,

kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù.

9 Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ,

tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun,

tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín.

10 Olùfẹ́ mi ló ni mí,

èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.

11 Máa bọ̀, olùfẹ́ mi,

jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá,

kí á lọ sùn ní ìletò kan.

12 Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu,

kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé,

bóyá ó ti ń tanná;

kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná,

níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.

13 Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde,

ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni,

tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi,

ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *