Categories
ORIN SOLOMONI

ORIN SOLOMONI 1

1 Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí:

Orin Kinni

2 Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu,

nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ.

3 Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn,

orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde;

nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.

4 Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,

ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.

Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ

a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;

abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!

5 Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,

mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà,

mo dàbí àgọ́ Kedari,

mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni.

6 Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú,

oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀.

Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi,

wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà,

ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.

7 Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́:

níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko?

Níbo ni wọ́n ti ń sinmi,

nígbà tí oòrùn bá mú?

Kí n má baà máa wá ọ kiri,

láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?

8 Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin,

bí o kò bá mọ ibẹ̀,

ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran.

Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko

lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.

9 Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao.

10 Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,

ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.

11 A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà,

tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ.

12 Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀,

turari mi ń tú òórùn dídùn jáde.

13 Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá,

bí ó ti sùn lé mi láyà.

14 Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi,

ninu ọgbà àjàrà Engedi.

15 Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi;

o lẹ́wà pupọ.

Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà.

16 Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi,

o lẹ́wà gan-an ni.

Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa.

17 Igi Kedari ni òpó ilé wa,

igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *