Ọlọrun Ọba Atóbijù
1 OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;
ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.
2 OLUWA tóbi ní Sioni,
ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
3 Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,
mímọ́ ni OLUWA!
4 Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,
o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;
o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu.
5 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,
ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;
mímọ́ ni OLUWA!
6 Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀;
Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀;
wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn.
7 Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;
wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;
wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn.
8 OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;
Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;
ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn.
9 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,
kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;
nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.